Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ A Ti Ṣe Tán Láti Ṣègbéyàwó Báyìí?

Ǹjẹ́ A Ti Ṣe Tán Láti Ṣègbéyàwó Báyìí?

ORÍ 30

Ǹjẹ́ A Ti Ṣe Tán Láti Ṣègbéyàwó Báyìí?

O ti rẹ́ni tí wàá fẹ́, ó ti pẹ́ díẹ̀ tẹ́ ẹ ti ń fẹ́ra yín sọ́nà, ìyẹn sì ti jẹ́ kó o mọ̀ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín gan-an. Kẹ́ ẹ ki òrùka bọra yín lọ́wọ́ ló kù báyìí. Àbí kí ló tún kù? Àmọ́ bó o ṣe fẹ́ tọrùn bọ ọ̀kan lára ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé èèyàn yìí, o bẹ̀rẹ̀ sí í dà á rò pé . . .

Ǹjẹ́ A Ti Ṣe Tán Láti Ṣègbéyàwó Báyìí?

KÒ SÓHUN tó burú nínú kéèyàn tún da ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó rò kó tó ṣe é, kódà bí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ bá tiẹ̀ ti wọ̀ dáadáa láàárín yín. Ó dájú pé bó o ṣe ń rí i pé àwọn tọkọtaya tí kò láyọ̀ àtàwọn tó ń kọ ara wọn sílẹ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i, wàá fẹ́ ronú jinlẹ̀ dáadáa bó o ṣe fẹ́ ṣe ohun tó máa yí ìgbésí ayé rẹ pa dà yìí. Báwo lo ṣe máa wá mọ̀ bóyá o ti ṣe tán lóòótọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ yìí? Ohun tó máa dáa ni pé kó o wá máa ronú lórí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ gan-an nínú ìgbéyàwó, dípò àwọn ohun tó ò ń retí pé ó yẹ kó wáyé. Bí àpẹẹrẹ, wo àwọn ohun tó o lè máa retí:

OHUN KÌÍNÍ “Bá a bá ti nífẹ̀ẹ́ ara wa kò ní sí ìṣòro kankan.”

Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ gan-an: Ìfẹ́ tẹ́ ẹ ní síra yín kọ́ ló máa san àwọn gbèsè tẹ́ ẹ bá jẹ, kò sì ní kó owó sí yín lápò. Kódà, àwọn aṣèwádìí ti rí i pé owó ló sábà máa ń fa ìjà jù láàárín tọkọtaya tó sì máa wá di pé wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀. Tí o kò bá fi owó sáyè rẹ̀, ó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ, kó sì ṣàkóbá fún àjọṣe tó wà láàárín ìwọ àti Jèhófà, ó sì tún lè da àárín ìwọ àti ọkọ (tàbí aya) rẹ rú. (1 Tímótì 6:9, 10) Kí lo lè rí kọ́ nínú èyí? Má ṣe jẹ́ kó di ẹ̀yìn ìgbà tẹ́ ẹ bá ṣègbéyàwó tán kẹ́ ẹ tó sọ̀rọ̀ lórí bẹ́ ẹ ó ṣe máa náwó!

Bíbélì sọ pé: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà?”​—Lúùkù 14:28.

Àbá: Kó tó di pé ẹ ṣègbéyàwó, ẹ jọ sọ̀rọ̀ lórí bí ẹ ó ṣe máa náwó lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ṣègbéyàwó. (Òwe 13:10) Ẹ wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bíi: Báwo la ó ṣe máa náwó tó bá ń wọlé fún wa? Ṣé àá jọ máa fowó pa mọ́ sí àkáǹtì kan náà ni àbí kí olúkúlùkù ní àkáǹtì tiẹ̀? Èwo nínú wa ni yóò máa bójú tó bá a ṣe ń náwó táá sì máa san àwọn owó tá a bá jẹ? * Èló ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè fi ra nǹkan láìjẹ́ pé ó sọ fún ẹnì kejì? Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ kẹ́ ẹ ti jọ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀, ẹ má ṣe dúró di ẹ̀yìn ìgbéyàwó!​—Oníwàásù 4:9, 10.

OHUN KEJÌ “Tá a bá fẹ́ra, àá ti lọ mọwọ́ ara wa jù, torí ọ̀rọ̀ wa máa ń bára mu, a kì í ta ko ara wa rárá!”

Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ gan-an: Tí ẹ kì í bá ń ta ko ara yín rárá, ó ní láti jẹ́ pé ṣe lẹ máa ń dọ́gbọ́n pẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó lè mú kẹ́ ẹ ta ko ara yín sílẹ̀. Àmọ́ ẹ ò ní lè rí irú ọgbọ́n yẹn dá mọ́ tẹ́ ẹ bá ṣègbéyàwó tán o! Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kò sí èèyàn aláìpé méjì tó lè mọwọ́ ara wọn tán láìkù síbì kan. Torí náà, kò sí bọ́rọ̀ yín ò ṣe ní máa yàtọ̀ síra lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Róòmù 3:23; Jákọ́bù 3:2) Kì í ṣe bọ́rọ̀ yín ṣe máa ń bára mu tó nìkan ló yẹ kó o máa wò, ó tún yẹ kó o wo ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí èrò yín kò bá dọ́gba lórí ohun kan. Àwọn tọkọtaya tó ṣe ara wọn lọ́kàn sábà máa ń jẹ́ àwọn tó máa ń gbà pé èrò àwọn kò dọ́gba lórí àwọn nǹkan kan lóòótọ́, wọ́n á sì wá fi sùúrù yanjú ọ̀rọ̀ náà láàárín ara wọn.

Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.”​—Éfésù 4:26.

Àbá: Fara balẹ̀ ronú lórí ohun tó o sábà máa ń ṣe nígbà tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín ìwọ àti dádì ẹ tàbí mọ́mì ẹ, tàbí láàárín ìwọ àtàwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹ. Ya àtẹ irú èyí tó wà lójú ìwé 93 nínú ìwé yìí tàbí èyí tó wà ní ojú ìwé 221 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì. Kọ àwọn ohun tó fa èdèkòyédè náà sílẹ̀, ohun tó o ṣe nígbà tó wáyé, kó o sì tún kọ ohun tí ì bá dáa jù kó o ṣe. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé ohun tó o sábà máa ń ṣe nígbà tí èdèkòyédè bá wáyé ni pé wàá bínú lọ sínú yàrá ẹ wàá sì pa ilẹ̀kùn dé gbàgà, wá kọ ohun tí ì bá dáa kó o ṣe tó máa yanjú ọ̀rọ̀ náà dípò táá fi dá kún un. Tó o bá ti wá mọ bí wàá ṣe máa yanjú èdèkòyédè, ohun pàtàkì tó máa jẹ́ kí ìwọ àti ẹni tó o bá fẹ́ máa láyọ̀ lo ti mọ̀ yẹn.

OHUN KẸTA “Tí n bá ti ṣègbéyàwó, mi ò tún níṣòro mọ́ tó bá dọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀.”

Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ gan-an: Pé o ní ọkọ tàbí aya kò fi hàn pé wàá lè máa ní ìbálòpọ̀ nígbàkigbà tó bá ti wù ẹ́. Rántí pé èèyàn ẹlẹ́ran ara lẹni tó o fẹ́, o sì gbọ́dọ̀ máa gba tiẹ̀ rò. Ká sòótọ́, àwọn ìgbà míì máa wà tí kò ní wu ọkọ tàbí aya rẹ pé kó ní ìbálòpọ̀. Pé ẹ ti jọ ṣègbéyàwó kò ní kó o máa sọ ọ́ di dandan pé ẹnì kejì rẹ gbọ́dọ̀ fún ẹ ní ohun tó ò ń fẹ́. (1 Kọ́ríńtì 10:24) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ìkóra-ẹni-níjàánu ṣe pàtàkì fún ẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó àti ẹni tó tiẹ̀ ti ṣègbéyàwó.​—Gálátíà 5:22, 23.

Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá, kì í ṣe nínú ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀ takọtabo.”​—1 Tẹsalóníkà 4:4, 5.

Àbá: Fara balẹ̀ ronú nípa bó ṣe máa ń wù ẹ́ tó láti ní ìbálòpọ̀, kó o sì wá ronú lórí ipa tí ìyẹn lè ní lórí ìwọ àtẹni tó o bá fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ó ti mọ́ ẹ lára láti máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ láti lè tẹ́ ìfẹ́ ara rẹ lọ́rùn? Ṣé ó ti mọ́ ẹ lára láti máa wo àwọn nǹkan tó ń mú kí ọkàn èèyàn máa fà sí ìṣekúṣe? Ṣé olójú kò-mú-kò-lọ ni ẹ́, tó jẹ́ pé o máa ń wo àwọn ọkùnrin tàbí obìnrin pẹ̀lú èrò ìṣekúṣe lọ́kàn? Bi ara rẹ pé, ‘Tó bá ṣòro fún mi nísinsìnyí tí mi ò tíì ṣègbéyàwó láti ṣàkóso bó ṣe máa ń wù mí láti ní ìbálòpọ̀, báwo ni màá ṣe lè ṣàkóso rẹ̀ lẹ́yìn tí mo bá ṣègbéyàwó?’ (Mátíù 5:27, 28) Tún ronú nípa nǹkan míì: Ṣé ẹni tó ti fẹ́ràn ọkùnrin tàbí obìnrin jù ni ẹ́ tó sì máa ń wù ẹ́ kó o ṣáà máa wà pẹ̀lú wọn, débi pé àwọn èèyàn ti wá mọ̀ ẹ́ sí ọkọ ọlọ́mọge tàbí ẹni tó fẹ́ràn kó máa bá ọkùnrin tage? Tó bá jẹ́ pé irú èèyàn bẹ́ẹ̀ ni ẹ́, kí lò ń ronú láti ṣe tí irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ kò fi ní bá ẹ wọnú ìgbéyàwó? Torí pé tó o bá ti ṣègbéyàwó, ọkọ tàbí ìyàwó ẹ nìkan lo gbọ́dọ̀ máa ní ìfẹ́ lọ́kọláya sí?​—Òwe 5:15-17.

OHUN KẸRIN “Ìgbéyàwó á jẹ́ kí n máa láyọ̀.”

Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ gan-an: Ẹni tí kì í láyọ̀ nígbà tí kò tíì ṣègbéyàwó, irú wọn kì í láyọ̀ nígbà tí wọ́n bá ṣègbéyàwó. Kí nìdí tó fi máa ń rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ojú téèyàn bá fi ń wo nǹkan ló máa ń pinnu béèyàn ṣe máa láyọ̀ tó, kì í ṣe ipò téèyàn bá ara rẹ̀. (Òwe 15:15) Àwọn tó máa ń wò ó pé ìgbésí ayé àwọn ò rí báwọn ṣe fẹ́ sábà máa ń ṣàròyé lórí ohun tó kù kí wọ́n ní nínú ìgbéyàwó wọn dípò kí wọ́n gbájú mọ́ ohun tí wọ́n ní. Ó dáa kó o ti máa fayọ̀ gbé ìgbésí ayé rẹ kó tó di pé o ṣègbéyàwó. Tó o bá wá ṣègbéyàwó, wàá mọ bó o ṣe lè mú kí ìwọ àti ẹni tó o fẹ́ máa láyọ̀.

Bíbélì sọ pé: “Ó sàn kó o jẹ́ kí ohun tó o ní tẹ́ ọ lọ́rùn ju kó o máa fi gbogbo ìgbà wá nǹkan tí kò ní.”​—Oníwàásù 6:9, Ìtúmọ̀ Today’s English Version.

Àbá: Nígbà míì, téèyàn bá lọ ń retí ohun tí ọwọ́ rẹ̀ kò lè tẹ̀, ìyẹn kò ní jẹ́ kí onítọ̀hún máa láyọ̀. Mú ìwé kan, kó o wá kọ ohun méjì tàbí mẹ́ta tó ò ń retí nínú ìgbéyàwó sínú rẹ̀. Kà wọ́n, kó o wá bi ara ẹ pé: ‘Ṣé ohun tọ́wọ́ mi lè tẹ̀ ni mo ń retí yìí àbí mo kàn ń tan ara mi jẹ lásán? Ṣé kì í ṣe àwọn ohun tí mo gbọ́ nínú rédíò, tàbí àwọn ohun tí mo rí nínú tẹlifíṣọ̀n, àwọn fíìmù tó dá lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tàbí àwọn ìwé kan ló jẹ́ kí èmi náà máa retí àwọn nǹkan yìí nínú ìgbéyàwó mi? Ṣé àwọn ohun témi máa rí gbà nínú ìgbéyàwó ni mo kàn ń retí, irú bíi pé èmi nìkan kò ní máa dá wà mọ́, màá lè máa ní ìbálòpọ̀ débi tó tẹ́ mi lọ́rùn, tàbí pé àwọn ojúgbà mi á lè máa bọ̀wọ̀ fún mi?’ Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ohun tó kan ìwọ nìkan ló yẹ kó o máa rò, ohun tó kan ẹ̀yin méjèèjì ló yẹ kó o máa rò. Kó o lè mọ bó o ṣe máa ṣe é, kọ nǹkan méjì tàbí mẹ́ta sílẹ̀ tó o fẹ́ nínú ìdílé yín èyí tó kan ìwọ àti ẹni tó o máa fẹ́.

Àwọn ohun táwọn kan máa ń retí nínú ìgbéyàwó lè ṣàkóbá fún ayọ̀ tó yẹ kí wọ́n ní nínú ìdílé wọn. Torí náà, rí i dájú pé o mú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ kúrò lọ́kàn rẹ, kó o sì máa ronú lórí àwọn nǹkan tó dájú pé ọwọ́ rẹ yóò lè tẹ̀. Àwọn ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 216 àti 217 lè ran ìwọ àti àfẹ́sọ́nà rẹ lọ́wọ́ bẹ́ ẹ ṣe ń fojú sọ́nà fún ọ̀kan lára nǹkan rere tó ga jù tọ́wọ́ èèyàn lè tẹ̀ nílé ayé, ìyẹn ìgbéyàwó tó jẹ́ aláyọ̀!​—Diutarónómì 24:5; Òwe 5:18.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣe ló máa ń dà bíi pé wọ́n pani sáyé tẹ́ni téèyàn ń fẹ́ bá jáni jù sílẹ̀. Báwo lo ṣe lè borí ẹ̀dùn ọkàn tí ìyẹn máa ń fà?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 9 Ìwé Òwe 31:10-28 sọ pé “aya tí ó dáńgájíá” ń bójú tó ọ̀pọ̀ ojúṣe pàtàkì nínú ọ̀ràn ìnáwó ìdílé rẹ̀. Ìwọ wo ẹsẹ 13, 14, 16, 18, àti 24.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Ọkùnrin yóò . . . fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ . . . yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.”​—Jẹ́nẹ́sísì 2:24.

ÌMỌ̀RÀN

Bá tọkọtaya kan tí wọ́n ti ṣègbéyàwó láti ọjọ́ tó ti pẹ́ sọ̀rọ̀, bi wọ́n pé ìmọ̀ràn wo ni wọ́n máa fún tọkọtaya kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó nípa bí wọ́n ṣe lè mú kí ìgbéyàwó wọn yọrí sí rere.​—Òwe 27:17.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Àwọn tọkọtaya tí ìdílé wọn jẹ́ ìdílé aláyọ̀ máa ń jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wọn, wọ́n jọ máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa, wọ́n mọ bí wọ́n ṣe ń yanjú èdèkòyédè, wọ́n á sì gbà pé àwọn jọ máa gbé pọ̀ títí ayé ni.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Ìwà mi tí màá rí pé ó túbọ̀ dára sí i kí èmi àti ẹni tí màá fẹ́ lọ́jọ́ iwájú lè mọwọ́ ara wa dáadáa ni ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ dádì tàbí mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tọkọtaya ló ń tú ká. Kí lo rò pé ó fà á tó fi ń rí bẹ́ẹ̀?

● Ewu wo lo rò pé ó wà níbẹ̀ tẹ́nì kan bá ṣègbéyàwó torí kó ṣáà lè bọ́ lọ́wọ́ ipò àìláyọ̀ nínú ilé wọn?

● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nígbà tó o bá ṣe ìgbéyàwó?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 220]

“Ìpinnu ńlá lọ̀rọ̀ ìgbéyàwó jẹ́. Ó ṣe pàtàkì kó o mọ ohun tó o fẹ́ dáwọ́ lé àti ẹni tẹ́ ẹ jọ fẹ́ dáwọ́ lé e.”​—Audra

[Àpótí/​Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 216, 217]

Tí mo kọ èrò mi sí

Ṣé O Ti Ṣe Tán Láti Ṣègbéyàwó?

Ronú lórí àwọn ìbéèrè tó wà lójú ìwé yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e. Ìwọ àti ẹni tó o máa fẹ́ lọ́jọ́ iwájú tiẹ̀ lè jọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè náà. Rí i dájú pé ẹ wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.

Ọ̀rọ̀ Owó

□ Báwo lọ̀rọ̀ owó ṣe máa ń rí lára rẹ?​—Hébérù 13:5, 6.

□ Àwọn ọ̀nà wo lo ti fi hàn pé o mọ bí èèyàn ṣe ń ṣọ́ owó ná?​—Mátíù 6:19-21.

□ Ǹjẹ́ o jẹ gbèsè èyíkéyìí báyìí? Tó o bá jẹ gbèsè, àwọn ìgbésẹ̀ wo lò ń gbé kó o lè san gbèsè náà?​—Òwe 22:7.

□ Èló ni ayẹyẹ ìgbéyàwó yín máa ná yín? Tẹ́ ẹ bá máa yáwó, èló lo rò pé ó bọ́gbọ́n mu kẹ́ ẹ yá láti fi bójú tó ìnáwó yìí?​—Lúùkù 14:28.

□ Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ṣègbéyàwó tán, ṣé ẹ̀yin méjèèjì lẹ ó máa ṣiṣẹ́? Tó bá jẹ́ pé ẹ̀yin méjèèjì lẹ máa ṣiṣẹ́, báwo lẹ ṣe máa ṣètò bí kálukú yín á ṣe máa lọ síbi iṣẹ́ tiẹ̀?​—Òwe 15:22.

□ Ibo ni ìwọ àti ẹnì kejì rẹ yóò máa gbé? Èló ló ṣeé ṣe kẹ́ ẹ máa ná lórí ilé, oúnjẹ, aṣọ, àtàwọn nǹkan míì, báwo lẹ ó sì ṣe máa san àwọn owó náà?​—Òwe 24:27.

Ọ̀rọ̀ Ìdílé

□ Báwo lo ṣe máa ń ṣe sí Dádì àti Mọ́mì àtàwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ?​—Ẹ́kísódù 20:12; Róòmù 12:18.

□ Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, kí lo máa ń ṣe nígbà tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ ẹ́?​—Kólósè 3:13.

□ Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́bìnrin, àwọn ọ̀nà wo lò ń gbà fi “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù” ṣèwà hù?​—1 Pétérù 3:4.

□ Ṣé ó wù ẹ́ láti bímọ? (Sáàmù 127:3) Tí o kò bá fẹ́ bímọ, irú ìfètòsọ́mọbíbí wo lo máa lò?

□ Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin, ètò wo lò ń ṣe nípa bí ìdílé rẹ á ṣe máa jọ́sìn Ọlọ́run?​—Mátíù 5:3.

Ìwà Rẹ

□ Àwọn ọ̀nà wo lo ti jẹ́ kó hàn pé òṣìṣẹ́ kára ni ẹ́?​—Òwe 6:9-11; 31:17, 19, 21, 22, 27.

□ Báwo lo ṣe ń fi hàn pé ò ń lo ara rẹ nítorí àwọn ẹlòmíì?​—Fílípì 2:4.

□ Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin, àwọn ọ̀nà wo lò ń gbà fi hàn pé o lè lo ipò rẹ gẹ́gẹ́ bí olórí lọ́nà tí Kristi gbà ń lo tiẹ̀?​—Éfésù 5:25, 28, 29.

□ Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́bìnrin, ẹ̀rí wo ló fi hàn pé o jẹ́ ẹni tó máa ń tẹrí ba fún àwọn tó láṣẹ lórí rẹ?​—Éfésù 5:22-24.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 219]

Má ṣe bẹ́ sínú ìgbéyàwó bí ìgbà téèyàn kàn bẹ́ sódò láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ mọ bó ṣe jìn tó