Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Dá Ara Mi Lójú?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Dá Ara Mi Lójú?

ORÍ 12

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Dá Ara Mi Lójú?

Bẹ́ẹ̀ ni Rárá

Bó o bá wo ara rẹ nínú dígí, ṣé inú rẹ máa ń dùn sí bó o ṣe rí? □ □

Ǹjẹ́ o gbà pé o lè ṣe àwọn nǹkan kan tó lè mú káwọn èèyàn yìn ẹ́? □ □

Táwọn ojúgbà rẹ bá fẹ́ kó o ṣohun tí kò dáa, ṣé o lè sọ pé o ò ṣe? □ □

Bí ẹnì kan bá sọ ohun tó o ṣe tí kò dáa, ṣé wàá bínú? □ □

Báwọn ẹnì kan bá ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa rẹ, ṣé o ò ní fara ya? □ □

Ǹjẹ́ o tiẹ̀ rò pé àwọn èèyàn fẹ́ràn rẹ? □ □

Ṣé o máa ń tọ́jú ara rẹ? □ □

Ǹjẹ́ inú rẹ máa ń dùn táwọn ẹlòmíì bá ṣàṣeyọrí? □ □

Ṣé o lè ka ara rẹ sẹ́ni tó máa ń ṣe nǹkan láṣeyọrí? □ □

Bí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ rárá sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè yìí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé o ti ka ara rẹ sí ẹni tí kì í mọ nǹkan kan ṣe ni kò jẹ́ kó o rí àwọn ibi tó o dáa sí. Orí tá a wà yìí máa jẹ́ kó o lè mọ àwọn ibi tó o dáa sí!

Ọ̀PỌ̀ ọ̀dọ́ ni ọkàn wọn kì í balẹ̀ nípa ìrísí wọn àti àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe, wọ́n máa ń ronú pé àwọn kì í mọ nǹkan ṣe bíi ti àwọn ojúgbà àwọn. Ṣé ohun tá a sọ yìí máa ń ṣe ìwọ náà? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ lo ní irú èrò yìí.

“Inú mi kì í dùn torí mi kì í lè ṣe àwọn nǹkan dáadáa tó bó ṣe yẹ. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé, èmi ni mo máa ń rí sí ara mi jù.”​—Leticia.

“Kò sí bó o ṣe lè dáa tó lọ́kùnrin tàbí bó o ṣe lè rẹwà tó lóbìnrin, wàá tún máa rí i pé àwọn ẹlòmíì rẹwà jù ẹ́ lọ ṣáá ni.”​—Haley.

“Ṣe ni mo máa ń ṣọ́ra mi gan-an bí mo bá wà láàárín àwọn èèyàn. Ẹ̀rù máa ń bà mí pé mi ò ní lè ṣe nǹkan tó máa dáa lójú wọn.”​—Rachel.

Bí ìwọ náà bá ń ronú bíi tàwọn ọ̀dọ́ tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ yìí, fọkàn ẹ balẹ̀. O rí ìrànlọ́wọ́. Jẹ́ ká wo àwọn nǹkan mẹ́ta tó máa jẹ́ kó o lè dá ara rẹ lójú, tó sì máa jẹ́ kó o rí àwọn ibi tó o dáa sí.

Máa Ran Àwọn Ẹlòmíì Lọ́wọ́

Ohun tí Bíbélì sọ. “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”​—Ìṣe 20:35.

Ohun tó túmọ̀ sí. Tó o bá ń ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, ṣe lò ń ran ara rẹ náà lọ́wọ́. Lọ́nà wo? Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “A óò mú ọkàn tí ó lawọ́ sanra, ẹni tí ó sì ń bomi rin àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà, a ó bomi rin òun náà ní fàlàlà.” (Òwe 11:25) Ká sòótọ́, inú èèyàn máa ń dùn gan-an téèyàn bá ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́! *

“Mo ronú nípa ohun tí mo lè ṣe fáwọn ẹlòmíì, mo wá ń ṣèrànwọ́ fún ẹni tó bá nílò ìrànlọ́wọ́ nínú ìjọ wa. Ara mi máa ń yá gágá bí mo ṣe ń yọ̀ mọ́ àwọn èèyàn, tí mo sì ń fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ mí lógún.”​—Breanna.

“Àǹfààní púpọ̀ wà nínú wíwàásù, torí pé kò ní jẹ́ kó o máa ronú nípa ara rẹ, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa àwọn ẹlòmíì.”​—Javon.

Ohun tó yẹ kó o ṣọ́ra fún: Má ṣe ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ nítorí ohun tó o máa rí gbà níbẹ̀. (Mátíù 6:2-4) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ní ṣe ẹ́ láǹfààní. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa hàn pé ohun tó o ṣe kò ti ọkàn rẹ wá, pé ẹ̀tàn lásán ni!​—1 Tẹsalóníkà 2:5, 6.

Ọ̀rọ̀ náà kàn ẹ́. Ronú nípa ẹnì kan tó o ti ràn lọ́wọ́ nígbà kan rí. Ta ni ẹni yẹn, kí lo sì ṣe fún un?

․․․․․

Báwo ló ṣe wá rí lára rẹ lẹ́yìn náà?

․․․․․

Tún ronú nípa ẹlòmíì tó o lè ràn lọ́wọ́, kó o sì kọ ohun tó o lè ṣe láti ran ẹni náà lọ́wọ́.

․․․․․

Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Dáa

Ohun tí Bíbélì sọ. “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”​—Òwe 17:17.

Ohun tó túmọ̀ sí. Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń dúró tini gbágbáágbá lọ́jọ́ ìṣòro. (1 Sámúẹ́lì 18:1; 19:2) Tó o bá tiẹ̀ ń rántí pé o lẹ́nì kan tí kì í fọ̀rọ̀ rẹ ṣeré, ìyẹn lè fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 16:17, 18) Torí náà, máa sún mọ́ àwọn tó máa nípa rere lórí rẹ.

“Àwọn ọ̀rẹ́ gidi máa gbé ẹ ró nígbà tó o bá rẹ̀wẹ̀sì.”​—Donnell.

“Nígbà míì, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé, kéèyàn ṣáà ti mọ̀ pé òun lẹ́nì kan tí kì í fọ̀rọ̀ òun ṣeré rárá. Ìyẹn lè jẹ́ kéèyàn rí i pé òun ṣe pàtàkì lójú àwọn kan.”​—Heather.

Ohun tó yẹ kó o ṣọ́ra fún: Rí i dájú pé kì í ṣe àwọn táá jẹ́ kó o máa díbọ́n, tí wàá máa fi irú ẹni tó o jẹ́ pa mọ́ láàárín wọn lo yàn lọ́rẹ̀ẹ́. (Òwe 13:20; 18:24; 1 Kọ́ríńtì 15:33) Tó o bá ń ṣe àwọn ohun tí kò bójú mu kínú àwọn ẹlòmíì lè dùn sí ẹ, ṣe ni wàá kàn máa rí i pé ò ń fira ẹ wọ́lẹ̀, o sì ń jẹ́ káwọn ẹlòmíì máa darí ẹ síbi tó wù wọ́n.​—Róòmù 6:21.

Ọ̀rọ̀ náà kàn ẹ́. Kọ orúkọ ọ̀rẹ́ rẹ kan tó lè jẹ́ kó o dẹni tó túbọ̀ ń dára rẹ̀ lójú sórí ìlà yìí.

․․․․․

O ò ṣe wáyè kó o túbọ̀ sún mọ́ ẹni tó o kọ orúkọ rẹ̀ yìí?​—Fi sọ́kàn pé: Kì í ṣe ọ̀ranyàn kí ẹni náà jẹ́ ojúgbà rẹ.

Má Rẹ̀wẹ̀sì Torí Àwọn Àṣìṣe Rẹ

Ohun tí Bíbélì sọ. “Nítorí gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.”​—Róòmù 3:23.

Ohun tó túmọ̀ sí. Ohun kan tó dájú ni pé, aláìpé ni ẹ́. Ìyẹn fi hàn pé o lè ṣe àṣìṣe nígbà míì, kó o sọ ohun tí kò tọ́ tàbí kó o ṣe ohun tí kò dáa. (Róòmù 7:21-23; Jákọ́bù 3:2) Lóòótọ́, kò sí bó o ṣe ní máa ṣàṣìṣe o, àmọ́ o mọ bó o ṣe ní jẹ́ kí ìyẹn máa dà ẹ́ láàmú jù. Bíbélì sọ pé: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú.”​—Òwe 24:16.

“Nígbà míì, tá a bá ń fi ibi tá a kù sí wéra pẹ̀lú ibi tí àwọn ẹlòmíì dáa sí, ìyẹn lè mú ká máa ka ara wa sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan.”​—Kevin.

“Gbogbo èèyàn ló ní ibi tí ìwà ẹ̀ dáa sí àti ibi tó kù sí. Ó yẹ kínú wa máa dùn nítorí ibi tá a dáa sí, ká sì máa ṣàtúnṣe sí àwọn ibi tá a kù sí.”​—Lauren.

Ohun tó yẹ kó o ṣọ́ra fún: Má torí pé o jẹ́ aláìpé, kó o wá máa fi ẹ̀ṣẹ̀ ṣomi mu. (Gálátíà 5:13) Tó o bá ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tí kò dáa, ìyẹn ò ní jẹ́ kó o ní ìtẹ́wọ́gbà ẹni tó ṣe pàtàkì jù, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run!​—Hébérù 10:26, 27.

Ọ̀rọ̀ náà kàn ẹ́. Kọ ìwà tó wù ẹ́ pé kó o túbọ̀ ní sórí ìlà yìí.

․․․․․

Kọ déètì òní sí ẹ̀gbẹ́ ìwà tó o kọ yìí. Ṣe ìwádìí lórí bó o ṣe lè túbọ̀ ní ìwà náà, kó o sì wá wo bó o ti ṣe sí lẹ́yìn oṣù kan.

Bí O Ti Ṣe Pàtàkì Tó

Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ.” (1 Jòhánù 3:20) Èyí túmọ̀ sí pé àwọn nǹkan kan wà tí Ọlọ́run máa mọyì lára rẹ, tí ìwọ fúnra rẹ lè má ronú kàn. Àmọ́, ṣé ojú tí Ọlọ́run fi ń wò ẹ́ máa wá yí pa dà torí o jẹ́ aláìpé? Fojú inú wò ó pé o ní ẹgbẹ̀rún náírà (₦1,000.00) odindi lọ́wọ́, àmọ́ ó ya létí. Ṣé wàá torí ìyẹn sọ ọ́ nù tàbí kó o máa wò ó pé kò wúlò mọ́? Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Ẹgbẹ̀rún náírà náà ṣì ni, yálà ó ya létí tàbí kò ya.

A lè fi èyí wé bó o ti ṣe pàtàkì tó lójú Ọlọ́run. Ọlọ́run ṣì máa fojú pàtàkì wò ẹ́, láìka ti pé o ní àwọn ibi tó o kù sí. Ó ń kíyè sí bó o ṣe ń sapá láti múnú rẹ̀ dùn, ó sì mọyì rẹ̀, bí àwọn ìsapá rẹ bá tiẹ̀ dà bíi pé kò já mọ́ nǹkan kan lójú tìrẹ! Kódà, Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”​—Hébérù 6:10.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣé inú rẹ kì í dùn rárá nígbà míì? Kí lo wá lè ṣe sí i?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 21 Tó o bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wo bí inú rẹ ṣe máa dùn tó, bó o bá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn ẹlòmíì!​—Aísáyà 52:7.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.”​—Gálátíà 6:4.

ÌMỌ̀RÀN

Má ṣe máa sọ fún ara rẹ pé, ‘Mi kì í ṣe dáadáa ní tèmi’ tàbí kó o máa sọ pé ‘Kò sí nǹkan tí mo máa ń mọ̀ ọ́n ṣe láyé tèmi.’ Ṣe ni irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ á kàn tún máa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o ṣiṣẹ́ lórí àwọn ibi tó o kù sí, síbẹ̀ kó o tún mọ àwọn ibi tó o dáa sí.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Ojú tó o bá fi wo ara rẹ lè nípa lórí irú ojú táwọn ẹlòmíì máa fi wò ẹ́ . . . àti irú ìwà tí wọ́n máa hù sí ẹ pàápàá.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Táwọn ojúgbà mi bá ń rí sí mi, màá ․․․․․

Tí mo bá rí i pé ibi tí mo kù sí nìkan ni mo máa ń rò ní gbogbo ìgbà, màá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ ni kì í sábà dá ara wọn lójú?

● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn níyì lójú ara ẹ̀ déwọ̀n àyè kan?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 88]

“Èèyàn lè jẹ́ arẹwà, kó sì máa rò pé òun burẹ́wà. Èèyàn sì lè má fi bẹ́ẹ̀ lẹ́wà, síbẹ̀ kó máa rò pé òun lòun rẹwà jù níbi tóun wà. Ó wà lọ́wọ́ irú ojú tí kálukú bá fi wo ara rẹ̀.”​—Alyssa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 90]

Iye tí owó kan jẹ́ kì í dín kù torí pé ó ya. Bákan náà, bó o ti ṣe pàtàkì tó lójú Ọlọ́run kò ní dín kù torí pé o jẹ́ aláìpé