Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Irú Aṣọ Wo Ló Yẹ Kí N Wọ̀?

Irú Aṣọ Wo Ló Yẹ Kí N Wọ̀?

ORÍ 11

Irú Aṣọ Wo Ló Yẹ Kí N Wọ̀?

Ẹnu ya àwọn òbí Heather gan-an nígbà tí wọ́n rí aṣọ tí ọmọ wọn fẹ́ wọ̀ jáde.

Dádì rẹ̀ wá kígbe pé: “Ṣé aṣọ tó o fẹ́ wọ̀ jáde nìyí?”

Ohun tí dádì rẹ̀ sọ yìí yà á lẹ́nu, ó wá béèrè pé: “Kí ló ṣe é? Ṣebí èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi kàn fẹ́ lọ sọ́jà ni.”

Mọ́mì ẹ̀ wá sọ pé: “Aṣọ yìí kọ́ lo máa wọ̀ lọ o!”

Ni Heather wá ráhùn pé: “Mọ́mì, aṣọ táwọn èèyàn ń wọ̀ ńsìnyí rèé, . . . àti pé, ó lóhun tó ń sọ!”

Dádì ẹ̀ dá a lóhùn pé: “Ohun tó ń sọ yẹn gan-an la ò fẹ́! Ó yá lọ sókè kó o lọ wá aṣọ gidi wọ̀, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ o ò lọ síbì kankan!”

ỌJỌ́ pẹ́ tí ọ̀rọ̀ aṣọ wíwọ̀ ti máa ń dá wàhálà sílẹ̀. Àwọn òbí rẹ pàápàá ti lè ní irú ìṣòro kan náà pẹ̀lú àwọn òbí wọn nígbà tí wọ́n ṣì kéré bíi tìẹ. Ó sì lè jẹ́ pé bọ́ràn náà ṣe rí lára rẹ báyìí, ló ṣe rí lára tiwọn náà nígbà yẹn! Àmọ́ ní báyìí àwọn náà ti di òbí, ọ̀ràn irú aṣọ tó yẹ kó o wọ̀ sì wá ń dá wàhálà sílẹ̀ ní gbogbo ìgbà.

O sọ pé: Ó tẹ́ mi lọ́rùn.

Wọ́n ní: Kò dúró dáadáa lára.

O sọ pé: Ó wà pa gan-an!

Wọ́n ní: Ó fi ara sílẹ̀, ó sì fún pinpin.

O sọ pé: Owó ẹ̀ ò wọ́n rárá.

Wọ́n ní: Owó ẹ̀ ṣe máa wọ́n, . . . ìgbà tó jẹ́ ìdajì aṣọ lo rà wálé!

Ṣé nǹkan kan wà tó o lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà? Bẹ́ẹ̀ ni! Ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23] kan tó ń jẹ́ Megan mọ ohun téèyàn lè ṣe. Ó sọ pé: “Kò sídìí tí wàá fi máa báwọn òbí rẹ jiyàn. Ẹ lè jọ fohùn ṣọ̀kan nípa irú aṣọ tó yẹ kó o wọ̀.” Kẹ́ ẹ jọ fohùn ṣọ̀kan kẹ̀! Ṣé pé kó o máa wá múra bí arúgbó? Rárá o, bíi tìyẹn kọ́! Ohun tó túmọ̀ sí ni pé kí ìwọ àtàwọn òbí rẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa irú aṣọ tó yẹ kó o máa wọ̀, kẹ́ ẹ wá fẹnu kò lórí irú èyí tínú wọn àtìwọ náà máa dùn sí. Àǹfààní wo ló wà níbẹ̀?

1. Ìmúra rẹ á dáa gan-an, wàá sì gbayì lójú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.

2. Àwọn òbí ẹ ò ní máa fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ sí ẹ nítorí aṣọ tó o bá wọ̀.

3. Bí àwọn òbí rẹ bá ti kíyè sí i pé o ti ń dá pinnu aṣọ tó bójú mu, wọ́n lè yọ̀ǹda fún ẹ láti máa ṣe àwọn nǹkan míì.

Jẹ́ ká wá bẹ̀rẹ̀ báyìí. Ronú nípa aṣọ kan tó wù ẹ́ gan-an tó o rí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí ní ṣọ́ọ̀bù kan. Ohun tó yẹ kó o kọ́kọ́ ṣe ni pé kó o . . .

Ronú Nípa Àwọn Ìlànà Bíbélì

Kó o sì máa wò ó, Bíbélì ò tiẹ̀ wá sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa aṣọ wíwọ̀. Kódà, o lè ka gbogbo ìtọ́ni tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa aṣọ wíwọ̀ láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan péré! Síbẹ̀, láàárín àkókò yẹn, wàá rí ìtọ́ni tó wúlò tó o lè tẹ̀ lé. Bí àpẹẹrẹ:

● Bíbélì fún àwọn obìnrin nímọ̀ràn pé kí wọ́n ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́ “pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú.” *​—1 Tímótì 2:9, 10.

Ọ̀rọ̀ náà “ìmẹ̀tọ́mọ̀wà” lè máa dà ẹ́ lọ́kàn rú. O lè máa ronú pé: ‘Ṣé aṣọ tó dà bí àpò ni kí n wá máa wọ̀ ni?’ Ìyẹn kọ́ là ń sọ o! Nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn ohun tí ìmẹ̀tọ́mọ̀wà túmọ̀ sí ni pé, kí aṣọ tó o wọ̀ fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún ara rẹ, àti pé o bọ̀wọ̀ fún èrò àwọn ẹlòmíì. (2 Kọ́ríńtì 6:3) Ọ̀pọ̀ aṣọ ló sì wà tó bá ohun tá a sọ yìí mu. Ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23] kan tó ń jẹ́ Danielle sọ pé: “Ó lè ṣòro lóòótọ́, àmọ́ o ṣì lè múra lọ́nà tó gbayì láì wọ aṣọ tó fi ara sílẹ̀ tàbí èyí tó fún pinpin.”

● Bíbélì sọ pé tó bá kan ìrísí wa, ohun tó yẹ ká máa fún láfiyèsí jù ni “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà,” ìyẹn irú ẹni tá a jẹ́ nínú ọkàn wa lọ́hùn-ún.​—1 Pétérù 3:4.

Lóòótọ́, bó o bá wọ aṣọ tó fara sílẹ̀ tàbí èyí tó fún pinpin, àwọn kan lè yíjú wò ẹ́ fúngbà díẹ̀, àmọ́ irú ẹni tó o jẹ́ nínú lọ́hùn-ún ló máa jẹ́ káwọn àgbà àtàwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ lè máa bọ̀wọ̀ fún ẹ. Àwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ pàápàá lè rí i pé wíwọ aṣọ tó fara sílẹ̀ tàbí èyí tó fún pinpin kò bọ́gbọ́n mu. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan tó ń jẹ́ Brittany sọ pé: “Ó ń kóni nírìíra láti rí báwọn obìnrin ṣe máa ń tara wọn lọ́pọ̀ fáwọn ọkùnrin nípa irú aṣọ tí wọ́n ń wọ̀!” Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Kay náà gbà pé òótọ́ ni Brittany sọ. Ó wá sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ nígbà kan, ó ní: “Àwọn aṣọ tó ń pàfiyèsí ló máa ń wọ̀. Ó máa ń fẹ́ káwọn ọkùnrin máa wo òun ṣáá, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn aṣọ tó máa ń fa ọkùnrin mọ́ra gan-an ló sábà máa ń wọ̀.”

Jẹ́ Káwọn Òbí Rẹ Sọ Èrò Wọn Nípa Rẹ̀

Kò dára kó o máa fi aṣọ tí kò bójú mu sínú àpò ilé ìwé rẹ, kó o wá lọ wọ̀ ọ́ ní ilé ìwé. Àwọn òbí rẹ á túbọ̀ fọkàn tán ẹ bí o kì í bá ń fọ̀rọ̀ pa mọ́ tó o sì ń sọ òótọ́ fún wọn, tó fi mọ́ àwọn ọ̀ràn tó o rò pé wọn ò ní lè mọ̀. Ohun tó tiẹ̀ dáa jù ni pé tó o bá fẹ́ ra aṣọ, kọ́kọ́ mọ èrò wọn nípa rẹ̀ kó o tó rà á. (Òwe 15:22)​—Lo àtẹ “Èrò Nípa Irú Aṣọ Tó Yẹ Kó O Wọ̀” lójú ìwé 82 àti 83.

Kí nìdí tó fi yẹ kó o mọ èrò wọn? O lè máa wò ó pé àwọn òbí rẹ á máa dí ẹ lọ́wọ́ láti wọ àwọn aṣọ tó wù ẹ́, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́, èrò ti dádì àti mọ́mì rẹ lè yàtọ̀ sí tìẹ, àmọ́ ó máa ń dáa bẹ́ẹ̀ nígbà míì. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Nataleine sọ pé: “Mo mọrírì ìmọ̀ràn àwọn òbí mi, torí mi ò fẹ́ dójú ti ara mi tí mo bá ń lọ níta tàbí káwọn èèyàn wá máa sọ ohun tí ò dáa nípa mi nítorí bí mo ṣe múra.”

Ká tiẹ̀ sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà: Títí tó o fi máa kúrò nílé, abẹ́ àṣẹ àwọn òbí rẹ lo ṣì wà. (Kólósè 3:20) Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá lóye ohun tí wọ́n ń fẹ́, táwọn náà sì mọ ohun tí ò ń fẹ́, ó máa yà ẹ́ lẹ́nu pé lọ́pọ̀ ìgbà ẹ ò ní máa jiyàn. Gbogbo awuyewuye yín lórí ọ̀rọ̀ irú aṣọ tó yẹ kó o máa wọ̀ sì lè wá yanjú!

Ìmọ̀ràn Lórí Aṣọ Tó Bójú Mu: Bó o bá ń wọ aṣọ kan wò, má ṣe fi ohun tó o rí nínú dígí nìkan pinnu pé aṣọ náà ti dáa. Aṣọ tó dà bíi pé ó dáa lè máà bójú mu tó o bá jókòó tàbí tó o bẹ̀rẹ̀ láti mú nǹkan. O lè ní kí òbí rẹ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan tó jẹ́ olóye sọ ohun tó rò nípa aṣọ náà.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣé ìwọ gan-an lo kórìíra ara rẹ jù? Kí lo lè ṣe tí ọ̀rọ̀ ara rẹ bá kàn máa ń bí ẹ nínú ṣáá?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 23 Lóòótọ́, àwọn obìnrin ni Bíbélì fún ní ìmọ̀ràn yìí, àmọ́ ìlànà tó wà níbẹ̀ kan àwọn ọkùnrin náà.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Kí ọ̀ṣọ́ yín má sì jẹ́ ti . . . wíwọ àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè, ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà.”​—1 Pétérù 3:3, 4.

ÌMỌ̀RÀN

Yẹra fún wíwọ aṣọ tó lè mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe. Wọ́n máa jẹ́ kó dà bíi pé ṣe lò ń wá ọkùnrin (tàbí obìnrin) lójú méjèèjì àti pé tara ẹ nìkan lo mọ̀.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Ìmúra rẹ làwọn èèyàn máa kọ́kọ́ fi pinnu irú èèyàn tó ṣeé ṣe kó o jẹ́.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Ẹnì kan nínú ìdílé wa tàbí ọ̀rẹ́ mi kan tó jẹ́ olóye tí mo lè fọ̀rọ̀ aṣọ tí mo fẹ́ rà lọ̀ ni ․․․․․

Tí n bá tún fẹ́ ra aṣọ nígbà míì, àwọn ohun tí màá fi sọ́kàn ni ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tí èrò àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn òbí fi máa ń ta kora lórí ọ̀rọ̀ aṣọ wíwọ̀?

● Kí làwọn nǹkan tó o máa mọ̀ ọ́n ṣe tó o bá fi kọ́ra láti máa bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ nípa irú aṣọ tó yẹ kó o wọ̀?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 81]

“Tí mo bá rí àwọn obìnrin tó wọ aṣọ tí kò bójú mu, ṣe ni wọ́n máa ń tẹ́ lójú mi. Àmọ́ tí mo bá rí àwọn èèyàn tó wọ aṣọ tó bójú mu tó sì fani mọ́ra, mo máa ń sọ fún ara mi pé, ‘Bí mo ṣe fẹ́ kí ìmúra mi máa dára lójú àwọn èèyàn nìyí.’”​—Nataleine

[Àpótí/​Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 82, 83]

Tí mo kọ èrò mi sí

Èrò Nípa Irú Aṣọ Tó Yẹ Kó O Wọ̀

Ìtọ́ni: Ṣe ẹ̀dà ojú ìwé méjì yìí. Ní káwọn òbí ẹ kọ nǹkan sí àwọn àyè tó wà lápá ọ̀tún, kí ìwọ sì kọ tìrẹ sí àyè tó wà lápá òsì. Wá gba èyí táwọn òbí ẹ kọ, kó o sì fún wọn ní tìẹ, kẹ́ ẹ wá jọ jíròrò àwọn ìdáhùn yín. Ǹjẹ́ ẹ rí ohun tó yà yín lẹ́nu nínú ìdáhùn kálukú yín? Àwọn nǹkan wo lẹ ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa èrò ara yín tí ẹ ti wá mọ̀ báyìí?

Àyè Tìrẹ Nìyí Ronú nípa aṣọ kan tó o fẹ́ wọ̀ tàbí tó o fẹ́ rà.

Kí nìdí tí aṣọ yìí fi wù ẹ́? Kọ nọ́ńbà síwájú àwọn ìdí tó wà nísàlẹ̀ yìí, kó o bẹ̀rẹ̀ látorí èyí tó ṣe pàtàkì sí ẹ jù.

․․․․․ Orúkọ tí wọ́n ń pè é

․․․․․ Bó ṣe máa fa obìnrin tàbí ọkùnrin mọ́ra tó

․․․․․ Àwọn ọ̀rẹ́ mi máa gba tiẹ̀

․․․․․ Bó ṣe máa rí lára mi

․․․․․ Iye owó ẹ̀

․․․․․ Nǹkan míì ․․․․․

Ohun tó ṣeé ṣe káwọn òbí mi sọ bí wọ́n bá kọ́kọ́ rí aṣọ yìí ni pé

□ “Aṣọ yìí ò dáa!”

□ “Tó o bá ní dandan ìyẹn ló wù ẹ́.”

□ “Ó dáa gan-an.”

Ohun tó lè mú kí wọ́n má gba ti aṣọ náà ni pé

□ “Ó fi ara sílẹ̀, ó sì fún pinpin.”

□ “Kò dúró dáadáa lára.”

□ “Aṣọ táyé gba wèrè ẹ̀ ni.”

□ “Kò pọ́n àwa òbí rẹ lé.”

□ “Ó ti wọ́n jù.”

□ Nǹkan míì ․․․․․

Ǹjẹ́ A Lè Jọ Wá Nǹkan Ṣe Sí I?

Kí ni mo rí pé ó ṣe pàtàkì nínú ohun táwọn òbí mi sọ nípa aṣọ yìí?

․․․․․

Kí ni mo lè ṣe sí aṣọ yìí táá fi ṣeé wọ̀?

․․․․․

Àyè Ti Òbí Rẹ Nìyí Ẹ ronú nípa aṣọ kan tí ọmọ yín fẹ́ wọ̀ tàbí tó fẹ́ rà.

Kí lẹ rò pé ó mú kí aṣọ yìí wu ọmọ yín? Ẹ kọ nọ́ńbà síwájú àwọn ìdí tó wà nísàlẹ̀ yìí, kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ látorí èyí tẹ́ ẹ rò pé ó ṣe pàtàkì sí ọmọ yín jù.

․․․․․ Orúkọ tí wọ́n ń pè é

․․․․․ Bó ṣe máa fa obìnrin tàbí ọkùnrin mọ́ra tó

․․․․․ Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa gba ti aṣọ náà

․․․․․ Bó ṣe máa rí lára

․․․․․ Iye owó ẹ̀

․․․․․ Nǹkan míì ․․․․․

Ohun tí màá sọ tí mo bá kọ́kọ́ rí i ni pé

□ “Aṣọ yìí ò dáa!”

□ “Tó o bá ní dandan ìyẹn ló wù ẹ́.”

□ “Ó dáa gan-an.”

Ohun tó lè mú kí n má gba ti aṣọ náà ni pé

□ “Ó fi ara sílẹ̀, ó sì fún pinpin.”

□ “Kò dúró dáadáa lára.”

□ “Aṣọ táyé gba wèrè ẹ̀ ni.”

□ “Kò pọ́n àwa òbí rẹ lé.”

□ “Ó ti wọ́n jù.”

□ Nǹkan míì ․․․․․

Ǹjẹ́ A Lè Jọ Wá Nǹkan Ṣe Sí I?

Ṣé torí pé aṣọ yìí kò wù wá la ṣe sọ pé kò dáa?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Ó jọ bẹ́ẹ̀ □ Rárá

Ǹjẹ́ nǹkan kan wà téèyàn lè ṣe sí aṣọ yìí táá fi ṣeé wọ̀?

․․․․․

Ìpinnu Wa ․․․․․

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 84]

Àwọn Ọkùnrin Wá Ńkọ́?

Ìlànà Bíbélì tá a jíròrò nínú orí yìí kan àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà. Ẹ jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà. Ẹ jẹ́ káwọn èèyàn lè tipasẹ̀ ìmúra yín mọ irú ẹni tẹ́ ẹ jẹ́ nínú ọkàn yín lọ́hùn-ún, ìyẹn ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà yín. Kó o tó ra aṣọ kan, kọ́kọ́ bi ara rẹ pé: ‘Irú ẹni wo ni aṣọ yìí máa sọ pé mo jẹ́? Ṣé ohun tó ń sọ nípa mi bá irú ẹni tí mo jẹ́ gan-an mu?’ Rántí pé, èèyàn máa ń fi aṣọ tó wọ̀ sọ nǹkan kan nípa ara rẹ̀. Máa wọṣọ tó máa jẹ́ káwọn èèyàn ní èrò tó dáa nípa rẹ!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 80]

Ṣe ni aṣọ tó o bá wọ̀ máa ń dà bí àkọlé tó ń sọ irú ẹni tó o jẹ́ fáwọn èèyàn. Irú ẹni wo ni aṣọ rẹ wá ń sọ pé o jẹ́?