Ǹjẹ́ Mi Ò Ní Pa Ilé Ìwé Tì Báyìí?
ORÍ 19
Ǹjẹ́ Mi Ò Ní Pa Ilé Ìwé Tì Báyìí?
Ibo lo rò pé ó yẹ kó o kàwé dé? ․․․․․
Ibo làwọn òbí rẹ fẹ́ kó o kàwé dé? ․․․․․
ǸJẸ́ ìdáhùn rẹ sí ìbéèrè méjèèjì yìí bára mu? Tí ìdáhùn méjèèjì bá tiẹ̀ bára mu, nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o pa ilé ìwé tì láìdúró parí ẹ̀kọ́ rẹ. Bóyá ìwọ náà tiẹ̀ ti ronú bíi tàwọn tó sọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí rí.
“Àwọn ìgbà míì wà tó máa ń rẹ̀ mí débi pé mi kì í fẹ́ dìde lórí bẹ́ẹ̀dì láàárọ̀. Mo máa ń ronú pé, ‘Kí nìdí tí màá fi lọ sílé ìwé láti lọ kọ́ àwọn nǹkan tí mi ò ní lò rárá?’”—Rachel.
“Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ilé ìwé máa ń sú mi, tá máa ṣe mí bíi pé kí n pa ilé ìwé tì kí n lọ wá iṣẹ́ kan ṣe. Mo máa ń ronú pé ilé ìwé kò ṣe
mí láǹfààní kankan, pé ó tẹ́ mi lọ́rùn kí n máa fi àkókò mi ṣe nǹkan tá máa mówó wọlé fún mi.”—John.“Àdúgbò tí àwọn ọmọọ̀ta pọ̀ sí ni mo ti lọ sílé ìwé girama, nǹkan ò sì rọrùn fún mi níbẹ̀. Ohun tí wọ́n ń kọ́ wa nílé ìwé yé mi dáadáa o, àmọ́ ṣe ni àwọn ọmọ ilé ìwé wa máa ń pa mí tì, torí náà, èmi nìkan ni mo sábà máa ń dá wà. Kódà, àwọn ọmọ míì tí wọ́n máa ń pa tì bíi tèmi gan-an kì í dá sí mi! Díẹ̀ ló kù kí n kúkú pa ilé ìwé tì pátápátá.”—Ryan.
“Ó máa ń tó wákàtí mẹ́rin tí mo fi ń ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá ní alaalẹ́! Àwọn iṣẹ́ náà máa ń wọ̀ mí lọ́rùn gan-an, kì í sì í tán. Ó le débi pé agbára mi ò fẹ́ gbé e mọ́, ó wá ń ṣe mí bíi pé kí n pa ilé ìwé tì.”—Cindy.
“Nígbà kan, àwọn kan halẹ̀ mọ́ wa pé àwọn máa ju bọ́ǹbù sílé ìwé wa, àwọn mẹ́ta kan gbìyànjú láti pa ara wọn, ẹnì kan tiẹ̀ para ẹ̀, àwọn ọmọkọ́mọ sì máa ń fa wàhálà gan-an. Nígbà míì wàhálà yẹn ti máa ń pọ̀ jù, débi tí mo fi ronú pé mi ò tiẹ̀ ní lọ ilé ìwé mọ́!”—Rose.
Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹ́ bíi tàwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí rí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ tó o fi fẹ́ pa ilé ìwé tì?
․․․․․
Bóyá o tiẹ̀ ti ń múra láti pa ilé ìwé tì. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá ó ti yẹ kó o fi ilé ìwé sílẹ̀ lóòótọ́, àbí torí pé ilé ìwé kàn sú ẹ lo ṣe fẹ́ pa á tì? Ká tó dáhùn ìbéèrè yìí, á dáa ká mọ ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn pa ilé ìwé tì.
Ṣé O Ti Parí Ilé Ìwé Ni àbí O Kàn Fẹ́ Pa Ilé Ìwé Tì?
Kí ni ìyàtọ̀ tó o rò pé ó wà láàárín kéèyàn parí ilé ìwé àti kéèyàn pa ilé ìwé tì?
․․․․․
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé láwọn orílẹ̀-èdè kan, ọ̀dọ́ kan lè fi ọdún márùn-ún sí mẹ́jọ parí ilé ìwé rẹ̀? Láwọn orílẹ̀-èdè míì sì rèé, ó kéré tán, àwọn ọmọléèwé gbọ́dọ̀ lo ọdún mẹ́wàá sí méjìlá ní
ilé ìwé. Torí náà, ọjọ́ orí téèyàn gbọ́dọ̀ parí ilé ìwé àti ibi tó yẹ kéèyàn kàwé dé kò bára mu níbi gbogbo.Bákan náà, láwọn orílẹ̀-èdè kan tàbí láwọn ìpínlẹ̀ kan, òfin gba àwọn ọmọ láyè láti máa gbélé kàwé. Wọ́n lè ka àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ kan tàbí gbogbo ẹ̀kọ́ wọn nílé, láìjẹ́ pé wọ́n ń lọ sí ilé ìwé. Tí àwọn òbí ọmọ kan bá fọwọ́ sí i pé kó gbélé kàwé, irú ọmọ bẹ́ẹ̀ kò pa ilé ìwé tì.
Yálà ò ń lọ sí ilé ìwé tàbí ò ń gbélé kàwé, bó o bá ń ronú láti fòpin sí ẹ̀kọ́ rẹ ṣáájú ìgbà tó yẹ kó o gba ìwé ẹ̀rí, ó yẹ kó o gbé àwọn ìbéèrè yìí yẹ̀ wò:
Kí ni òfin sọ? Bá a ti sọ ṣáájú, òfin nípa ibi tó yẹ kéèyàn kàwé dé kò dọ́gba láti ibì kan sí òmíràn. Ní àgbègbè ibi tó o wà, ibo ni òfin sọ pé, ó kéré tán, ó yẹ kéèyàn kàwé dé? Ṣé o ti kàwé débẹ̀? Tí o kò bá ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé kí á “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga,” tó o wá kọ̀ láti kàwé dé ibi tí òfin sọ pé, ó kéré tán, ó yẹ kéèyàn kàwé dé, ṣe lo pa ilé ìwé tì.—Róòmù 13:1.
Ṣé mo ti kàwé débi tọ́wọ́ mi á fi lè tẹ ohun tí mo fẹ́ ṣe? Kí làwọn nǹkan tó wù ẹ́ kó o lè ṣe tó o bá parí ilé ìwé rẹ? Ó yẹ kó o mọ ohun tó o fẹ́ fi ẹ̀kọ́ rẹ ṣe o. Bí o kò bá tíì mọ̀ ọ́n, ńṣe lọ̀rọ̀ rẹ máa dà bíi ti ẹni tó wọ ọkọ̀ àmọ́ tí kò mọ ibi tó ń lọ. Torí náà, ṣe ni kí ìwọ àtàwọn òbí rẹ jọ kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sí àwọn àlàfo tó wà lábẹ́ àkòrí náà, “ Àwọn Ohun Tí Mo Fẹ́ Fi Ẹ̀kọ́ Mi Ṣe,” ní ojú ìwé 139. Ìyẹn á jẹ́ kó o fọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ, kó o má sì ronú pé wàá fi ilé ìwé sílẹ̀ ṣáájú ìgbà tó yẹ, ìwọ àtàwọn òbí rẹ á sì tún lè jọ pinnu iye ìwé tó o máa kà.—Òwe 21:5.
Ó dájú pé àwọn olùkọ́ rẹ àtàwọn ẹlòmíì máa gbà ẹ́ nímọ̀ràn nípa ibi tó yẹ kó o kàwé dé. Àmọ́, àwọn òbí rẹ ló máa pinnu iye ìwé tó yẹ kó o kà. (Òwe 1:8; Kólósè 3:20) Bí o bá kàn fi ilé ìwé sílẹ̀ nígbà tí ọwọ́ rẹ kò tíì lè tẹ àwọn ohun tí ìwọ àtàwọn òbí rẹ jọ sọ pé o fẹ́ ṣe, á jẹ́ pé o pa ilé ìwé tì nìyẹn.
Jeremáyà 17:9) Nígbà tí àwa èèyàn bá fẹ́ ṣe ohun tó kàn wù wá, oríṣiríṣi àwáwí la máa ń ṣe.—Jákọ́bù 1:22.
Kí nìdí tí mo fi fẹ́ pa ilé ìwé tì? Má ṣe tan ara rẹ jẹ. (Kọ àwọn ìdí tó o rò pé ó bọ́gbọ́n mu tó o fi fẹ́ fòpin sí ẹ̀kọ́ ìwé rẹ láìjẹ́ pé o ti parí ilé ìwé.
․․․․․
Kọ àwọn àwáwí tó o lè ṣe tó bá jẹ́ pé ó kàn ń wù ẹ́ kó o pa ilé ìwé tì, síbí.
․․․․․
Àwọn ìdí tó bọ́gbọ́n mu wo lo kọ sílẹ̀? Ara ohun tó o kọ lè jẹ́ torí kó o lè ṣèrànwọ́ lórí ọ̀rọ̀ gbígbọ́ bùkátà ìdílé yín tàbí kó o lè yọ̀ǹda ara rẹ láti lọ ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. Ara àwáwí tó o kọ lè jẹ́ torí kó o má bàa ṣe àwọn ìdánwò ilé ìwé tàbí àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kó o ronú jinlẹ̀ láti lè mọ ìdí gan-an tó o fi fẹ́ kúrò ní ilé ìwé. Ṣé ìdí tó bọ́gbọ́n mu ni àbí àwáwí lásán?
Tún pa dà wo àwọn ohun tó o kọ sílẹ̀ pé ó jẹ́ ìdí tó o fi fẹ́ kúrò ní ilé ìwé, kó o wá kọ nọ́ńbà sí ẹ̀gbẹ́ wọn, bẹ̀rẹ̀ láti 1 sí 5 (kó o tò ó látorí èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì dórí èyí tó ṣe pàtàkì jù). Tó bá jẹ́ torí kó o kàn lè sá fún àwọn ìṣòro lo ṣe fẹ́ pa ilé ìwé tì, àfàìmọ̀ ni ọ̀rọ̀ náà kò ní yọrí sí àbámọ̀.
Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Pa Ilé Ìwé Tì?
Tó o bá pa ilé ìwé tì, ṣe ló dà bí ìgbà tó o bẹ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú irin kó o tó dé ibi tó ò ń lọ. Òótọ́ ni pé ara lè má tù ẹ́ bó o ṣe wà nínú ọkọ̀ náà, àwọn tẹ́ ẹ jọ wọkọ̀ sì lè máa kanra. Àmọ́,
tó o bá bẹ́ jáde nínú ọkọ̀ náà, o ò ní lè dé ibi tó ò ń lọ, o sì lè tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ara rẹ léṣe gan-an. Bákan náà, tó o bá pa ilé ìwé tì, o ò ní lè ṣe àwọn nǹkan tó o fẹ́ fi ẹ̀kọ́ rẹ ṣe, o sì lè wá tipa bẹ́ẹ̀ fa àwọn ìṣòro kan fún ara rẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ àti lọ́jọ́ iwájú. Lára irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ rèé:Àwọn ìṣòro tó lè jẹ yọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀: Ó lè ṣòro fún ẹ láti rí iṣẹ́. Tó o bá sì rí iṣẹ́, owó oṣù tí wọ́n á máa san fún ẹ lè má pọ̀ tó èyí tí wàá máa gbà ká ní o parí ilé ìwé rẹ. Kó o tó lè gbọ́ bùkátà ara rẹ, á wá di pé kó o máa ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó ní àyíká ibi tó tiẹ̀ tún lè burú ju ti ilé ìwé rẹ lọ.
Àwọn ìṣòro tó lè jẹ yọ lọ́jọ́ iwájú: Ìwádìí fi hàn pé àwọn tó pa ilé ìwé tì kì í sábà lè tọ́jú ara wọn dáadáa, wọ́n sábà máa ń ṣe ohun tó lè mú kí wọ́n ṣẹ̀wọ̀n, wọ́n sì lè dẹni tó ń gbára lé ètò ìrànwọ́ tó wà fáwọn mẹ̀kúnnù kí wọ́n tó lè jẹun.
Òótọ́ ni pé tó o bá dúró parí ẹ̀kọ́ rẹ, ìyẹn kò fi hàn dájú pé o kò ní láwọn ìṣòro tá a sọ yìí. Síbẹ̀, kò ní bọ́gbọ́n mu pé kó o ṣàkóbá fún ara rẹ nípa pípa ilé ìwé tì.
Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Kó O Dúró Parí Ẹ̀kọ́ Rẹ
Tó o bá fìdí rẹmi nínú ìdánwò ráńpẹ́ tẹ́ ẹ kàn ṣe lọ́jọ́ kan, tàbí ìyà jẹ ẹ́ ní ilé ìwé lọ́jọ́ kan, o lè fẹ́ pa ilé ìwé tì. Àwọn ìṣòro tí ìyẹn lè fà lọ́jọ́ iwájú tiẹ̀ lè dà bíi
pé kò tó nǹkan tó o bá fi wé àwọn ohun tó ń dùn ẹ́ báyìí. Àmọ́ kó o tó ṣe ohun tó dà bíi pé ó rọ̀ ẹ́ lọ́rùn jù yìí, wo ohun tí àwọn ọmọ ilé ìwé tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ níṣàájú sọ nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn dúró parí ẹ̀kọ́ rẹ̀.“Mo ti kọ́ béèyàn ṣe ń ní ìforítì, kí n lè di ẹni tó ń ronú jinlẹ̀. Mo tún ti kẹ́kọ̀ọ́ pé téèyàn bá fẹ́ gbádùn ohun kan, èèyàn ní láti nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan ọ̀hún dáadáa. Mo ti túbọ̀ mọ ohun tí mò ń kọ́ ní ilé ìwé dáadáa, ó sì máa ṣe mí làǹfààní tó pọ̀ gan-an lẹ́yìn tí mo bá jáde ilé ìwé.”—Rachel.
“Mo ti wá mọ̀ pé tí n bá ṣiṣẹ́ kára, ọwọ́ mi á lè tẹ àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe tí mo bá jáde ilé ìwé. Iṣẹ́ tí mò ń kọ́ ní ilé ìwé báyìí máa jẹ́ kí n dẹni tó lè ṣe iṣẹ́ tó wù mí láti ṣe, ìyẹn iṣẹ́ títún ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ṣe.”—John.
“Torí pé mo tẹra mọ́ ẹ̀kọ́ mi, mo ti mọ béèyàn ṣe ń kàwé àti béèyàn ṣe ń kọ̀wé dáadáa. Ẹ̀kọ́ ilé ìwé ti jẹ́ kí n mọ bí mo ṣe lè máa fara balẹ̀ gba àṣìṣe mi àti bí mo ṣe lè máa ṣàlàyé ara mi yékéyéké. Èyí sì máa wúlò fún mi lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run.”—Ryan.
“Ilé ìwé tí mo lọ ti jẹ́ kí n mọ béèyàn ṣe lè yanjú ìṣòro, yálà ní ilé ìwé tàbí níbòmíì. Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ nípa bí mo ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro tó jẹ mọ́ ẹ̀kọ́ ilé ìwé, àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì àtàwọn ìṣòro míì, ti jẹ́ kí n dẹni tó lóye dáadáa.”—Cindy.
“Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ní ilé ìwé ti jẹ́ kí n mọ ohun tí mo lè ṣe sí àwọn ohun tó bá wáyé níbi iṣẹ́. Bákan náà, àwọn nǹkan kan máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà míì tó máa ń mú kí n tún ronú lórí ìdí tí mo fi ń sin Ọlọ́run. Torí náà, lílọ sí ilé ìwé ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára.”—Rose.
Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n ọba kọ̀wé pé: “Òpin ọ̀ràn kan ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ sàn ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ. Onísùúrù sàn ju onírera ní ẹ̀mí.” (Oníwàásù 7:8) Torí náà, dípò tí wàá kàn fi pa ilé ìwé tì, ńṣe ni kó o fara balẹ̀ ronú nípa àwọn ohun tó o lè ṣe sí àwọn ìṣòro rẹ ní ilé ìwé. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ rẹ á dára gan-an ni.
Tó bá jẹ́ torí pé o ò mọ ohun tó o lè ṣe sí ìṣòro tó o ní tìtorí olùkọ́ kan ni kò jẹ́ kí ilé ìwé wù ẹ́ lọ mọ́ ńkọ́?
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.”—Òwe 21:5.
ÌMỌ̀RÀN
Tó o bá ń ní ìṣòro gan-an ní ilé ìwé, o lè ṣèwádìí nípa àwọn ìdánwò míì tó o lè ṣe tí wàá fi lè tètè parí ẹ̀kọ́ rẹ kó o sì gbàwé ẹ̀rí tó o nílò.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Àwọn ọmọ tó bá ń pa ilé ìwé jẹ sábà máa ń pa ilé ìwé tì nígbà tó bá yá.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Bí ẹ̀kọ́ kan tá à ń kọ́ ní ilé ìwé kò bá yé mi, dípò kí n pa ilé ìwé tì, màá ․․․․․
Bó bá jẹ́ torí pé nǹkan máa ń sú mi ni mo ṣe fẹ́ pa ilé ìwé tì, ohun tí màá ṣe kí n lè borí ẹ̀ ni ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o mọ béèyàn ṣe ń kàwé, béèyàn ṣe ń kọ̀wé, kó o sì tún mọ ìṣirò dáadáa?
● Tó o bá láwọn nǹkan kan tó ò ń lé nínú ẹ̀kọ́ rẹ, tó sì jẹ́ nǹkan tí ọwọ́ rẹ lè tètè tẹ̀, báwo ló ṣe máa jẹ́ kó o lo àkókò rẹ ní ilé ìwé lọ́nà tó dáa?
● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o mọ àwọn nǹkan kan nípa irú iṣẹ́ tí wàá fẹ́ ṣe nígbà tó o bá jáde nílé ìwé?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 140]
“Kò sí bó o ṣe lè sá lọ fún àwọn ohun tó jẹ́ ìṣòro rẹ. Tó o bá lọ sí ilé ìwé, wàá lè mọ bó o ṣe lè máa yanjú àwọn ìṣòro tó o bá ní, ìyẹn sì máa wúlò fún ẹ níbi iṣẹ́ tàbí níbòmíì.”—Ramona
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 139]
Tí mo kọ èrò mi sí
Àwọn Ohun Tí Mo Fẹ́ Fi Ẹ̀kọ́ Mi Ṣe
Ọ̀kan lára ìdí pàtàkì téèyàn fi ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ni pé kó lè rí iṣẹ́ tó máa fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀, tó bá sì ní ìdílé lọ́jọ́ iwájú, kó lè gbọ́ bùkátà wọn. (2 Tẹsalóníkà 3:10, 12) Ǹjẹ́ o ti pinnu irú iṣẹ́ tó o fẹ́ ṣe tó o bá parí ilé ìwé rẹ, ṣé o sì ti ń fọkàn sí àwọn ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ ní ilé ìwé tó máa jẹ́ kó o lè ṣe iṣẹ́ náà? Kó o lè mọ̀ bóyá ẹ̀kọ́ tí ò ń kọ́ ní ilé ìwé báyìí máa wúlò fún ẹ lẹ́nu iṣẹ́ náà, dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí:
Àwọn ẹ̀bùn wo ni mo ní? (Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ ara rẹ yọ̀ mọ́ àwọn èèyàn, tó o sì mọ bí wọ́n ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ dáadáa? Ṣé ó máa ń wù ẹ́ kó o máa fọwọ́ ara rẹ ṣe àwọn nǹkan tàbí kó o máa tún àwọn nǹkan tó bà jẹ́ ṣe? Ṣé o mọ béèyàn ṣe lè ronú jinlẹ̀ lórí ìṣòro kó sì yanjú rẹ̀?) ․․․․․
Àwọn iṣẹ́ wo ni mo lè ṣe tó máa jẹ́ kí n lè lo àwọn ẹ̀bùn tí mo ní? ․․․․․
Irú àwọn iṣẹ́ wo ló wà tí mo lè ṣe ní àgbègbè ibi tí mò ń gbé? ․․․․․
Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni mò ń kọ́ báyìí tó máa jẹ́ kí n lè rí iṣẹ́? ․․․․․
Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni mò ń kọ́ ní ilé ìwé báyìí tó máa jẹ́ kí ọwọ́ mi lè tètè tẹ ohun tí mo fẹ́ ṣe? ․․․․․
Má gbàgbé pé ìdí tó o fi ń lọ sí ilé ìwé ni pé kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ yege nípa ohun tí wàá lè lò lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, má ṣe ki àṣejù bọ̀ ọ́ kó o wá jókòó pa sí ilé ìwé, torí pé o fẹ́ sá fún àwọn ojúṣe tó máa kàn ẹ́ lẹ́yìn tó o bá parí ilé ìwé. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀ ńṣe lo máa dà bí ẹni tó wọ ọkọ̀, tó sì wá kọ̀ láti sọ̀ kalẹ̀. *
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ ìpínrọ̀ 69 Wo Orí 38 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, fún àlàyé síwájú sí i.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 138, 139]
Tó o bá pa ilé ìwé tì, ṣe ló dà bí ìgbà tó o bẹ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú irin kó o tó dé ibi tó ò ń lọ