Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run

Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run

APÁ 9

Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run

Èwo ló ṣòro jù fún ẹ lára àwọn gbólóhùn tá a tò sísàlẹ̀ yìí?

□ Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

□ Gbígbàdúrà déédéé sí Jèhófà Ọlọ́run

□ Sísọ ohun tí mo gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì (àgàgà àwọn ojúgbà mi)

□ Lílóye ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti máa fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù

Kọ ohun tó o ní lọ́kàn láti ṣe nípa àwọn ohun tó o fàmì sí pé ó ṣòro fún ẹ jù lọ sórí ìlà yìí.

․․․․․

Orí 34 sí 38 nínú ìwé yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rí bó o ṣe lè mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run fìdí múlẹ̀, bó o ṣe lè máa fi ìlànà Bíbélì ṣèwà hù àti bó o ṣe lè láwọn àfojúsùn tó máa jẹ́ káyé ẹ lójú kó sì nítumọ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 280, 281]