Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Yẹ Kí N Ṣèrìbọmi?

Ṣó Yẹ Kí N Ṣèrìbọmi?

ORÍ 37

Ṣó Yẹ Kí N Ṣèrìbọmi?

Fàmì sí òótọ́ tàbí irọ́ nínú àwọn gbólóhùn wọ̀nyí:

Gbogbo Kristẹni ló yẹ kó ṣèrìbọmi.

□ Òótọ́

□ Irọ́

Ó yẹ kéèyàn ṣèrìbọmi, kó má bàa máa dẹ́ṣẹ̀.

□ Òótọ́

□ Irọ́

Ìrìbọmi máa jẹ́ kó o lè ní ìgbàlà.

□ Òótọ́

□ Irọ́

Bó ò bá tíì ṣèrìbọmi, gbogbo nǹkan tó o bá ń ṣe ò kan Ọlọ́run.

□ Òótọ́

□ Irọ́

Táwọn ọ̀rẹ́ ẹ bá ti ń ṣèrìbọmi, ìwọ náà ti lè ṣèrìbọmi nìyẹn.

□ Òótọ́

□ Irọ́

BÓ O bá ti ń fàwọn ìlànà Ọlọ́run ṣèwà hù, tó ò ń bá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́, tó o sì ń sọ àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì, kò burú tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ṣíṣèrìbọmi. Àmọ́, báwo lo ṣe máa mọ̀ pé o ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn gbólóhùn tó o fàmì òótọ́ tàbí irọ́ sí wọ̀nyẹn.

Gbogbo Kristẹni ló yẹ kó ṣèrìbọmi.

Òótọ́. Jésù pàṣẹ pé gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ló gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi. (Mátíù 28:19, 20) Kódà òun pàápàá ṣèrìbọmi. Bó o bá fẹ́ di ọmọlẹ́yìn Kristi, o gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi tó o bá ti dàgbà tó láti pinnu pó o fẹ́ ṣèrìbọmi, tó sì wù ẹ́ látọkàn wá.

Ó yẹ kéèyàn ṣèrìbọmi, kó má bàa máa dẹ́ṣẹ̀.

Irọ́. Ìrìbọmi ló ń fi hàn ní gbangba pé o ti yara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ìyàsímímọ́ tó o bá ṣe kì í ṣe àdéhùn abàmì tó ń ká ẹ lọ́wọ́ kò láti má ṣohun tí ò dáa. Àmọ́, ṣe lo yara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà torí pé o fẹ́ láti máa fàwọn ìlànà ẹ̀ ṣèwà hù.

Ìrìbọmi máa jẹ́ kó o lè ní ìgbàlà.

Òótọ́. Bíbélì sọ pé ìrìbọmi wà lára ìgbésẹ̀ pàtàkì téèyàn gbọ́dọ̀ gbé kó tó lè rí ìgbàlà. (1 Pétérù 3:21) Èyí ò wá mú kí ìrìbọmi dà bí owó ìbánigbófò, ìyẹn insurance, téèyàn máa ń san láti fi dáàbò bo ara ẹ̀ lọ́jọ́ tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀. Ìdí tó o fi fẹ́ ṣèrìbọmi gbọ́dọ̀ jẹ́ torí pó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, o sì fẹ́ máa fi tọkàntọkàn sìn ín títí ayé.—Máàkù 12:29, 30.

Bó ò bá tíì ṣèrìbọmi, gbogbo nǹkan tó o bá ń ṣe ò kan Ọlọ́run.

Irọ́. Jákọ́bù 4:17 sọ pé: “Bí ẹnì kan bá mọ bí a ti ń ṣe ohun tí ó tọ́, síbẹ̀ tí kò ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un,” yálà ẹni yẹn ti ṣèrìbọmi tàbí kò tíì ṣe é. Torí náà, tó o bá ti mọ nǹkan tó tọ́, tó o sì ti dàgbà tó láti ronú nípa nǹkan tó o fẹ́ fayé ẹ ṣe, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé, àkókò ti tó nìyẹn láti bá mọ́mì tàbí dádì ẹ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, o sì lè sọ fún arákùnrin tàbí arábìnrin míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀. Ìyẹn ló máa jẹ́ kó o mọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti kúnjú ìwọ̀n fún ìrìbọmi.

Báwọn ọ̀rẹ́ ẹ bá ti ń ṣèrìbọmi, ìwọ náà ti lè ṣèrìbọmi nìyẹn.

Irọ́. Ìwọ fúnra ẹ lo gbọ́dọ̀ pinnu látọkàn wá pó o fẹ́ ṣèrìbọmi. (Sáàmù 110:3) Ìgbà tó o bá ti mọ ohun tó túmọ̀ sí, dáadáa, láti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó o sì ti ṣe tán láti ṣe àwọn ojúṣe tó bá jẹ mọ́ ọn lo tó lè ṣèrìbọmi.—Oníwàásù 5:4, 5.

Ìrìbọmi Máa Ń Yí Ayé Ẹni Pa Dà

Ìrìbọmi jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì tó máa ń yí ayé ẹni pa dà tó sì máa ń mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá. Ó tún máa ń gbé ojúṣe pàtàkì kan léni lọ́wọ́, ìyẹn ni láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ tó o ṣe sí Jèhófà.

Ṣéwọ náà ti ń fẹ́ láti yara ẹ sí mímọ́? Bó o bá ti ń fẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kínú ẹ máa dùn. Àǹfààní tó tóbi jù lọ lo fẹ́ yẹn, ìyẹn ni àǹfààní láti máa fi tọkàntọkàn sin Jèhófà, kó o sì máa gbé ìgbésí ayé ẹ lọ́nà tó máa fi hàn pé lóòótọ́ lo ti yara ẹ sí mímọ fún un.—Mátíù 22:36, 37.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Kọ́ bí wàá ṣe máa ní àfojúsùn káyé ẹ lè dáa.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.Róòmù 12:1.

ÌMỌ̀RÀN

Ìwọ àtàwọn òbí ẹ lè jọ wá ẹnì kan, nínú ìjọ yín, tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.—Ìṣe 16:1-3.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Ìrìbọmi jẹ́ apá pàtàkì lára “àmì” tó ń fi hàn pé o yẹ fún ìgbàlà.—Ìsíkíẹ́lì 9:4-6.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Mo fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì wọ̀nyí, kí n lè tẹ̀ síwájú láti ṣèrìbọmi: ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tí ìrìbọmi fi jẹ́ ìgbésẹ̀ tó ṣe pàtàkì?

● Kí ló lè mú kí ìrìbọmi yá jù fún ọ̀dọ́ kan?

● Kí lohun tí kò bọ́gbọ́n mu tó lè mú kí ọ̀dọ́ kan máà fẹ́ láti ṣèrìbọmi?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 306]

“Mímọ̀ tí mo mọ̀ pé mo ti ṣèrìbọmi máa ń ràn mí lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, ó sì máa ń jẹ́ kí n máa sá fáwọn nǹkan tó lè fa wàhálà.”—Holly

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 307]

Àwọn Ìbéèrè Tó Sábà Máa Ń Wáyé Nípa Ìrìbọmi

Kí ni ìrìbọmi túmọ̀ sí? Rírì tí wọ́n bá rì ẹ́ bọmi tí wọ́n sì gbé ẹ jáde túmọ̀ sí pé o ti kú, tó bá dọ̀rọ̀ ṣíṣe ìfẹ́ tara ẹ, o sì ti wá wà láàyè láti máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà.

Kí ló túmọ̀ sí láti yara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà? Ó túmọ̀ sí pé o ò ní ṣe ìfẹ́ inú ara ẹ mọ́, o sì wá ṣèlérí pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni wàá máa fi ṣáájú ohun gbogbo. (Mátíù 16:24) Ó yẹ kó o gbàdúrà láti fi yara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà kó o tó ṣèrìbọmi.

Irú ìgbésí ayé wo ló yẹ kó o ti máa gbé kó o tó ṣèrìbọmi? Ó yẹ kó o ti máa fàwọn nǹkan tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèwà hù, kó o sì ti máa sọ àwọn ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì. O gbọ́dọ̀ ti máa bá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́ nípasẹ̀ àdúrà gbígbà, kó o sì ti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó gbọ́dọ̀ wù ẹ́ látọkàn wá láti máa sin Jèhófà, kì í ṣe torí pé àwọn ẹlòmíì ń fipá mú ẹ láti sìn ín.

Ọmọ ọdún mélòó lèèyàn gbọ́dọ̀ jẹ́ kó tó lè ṣèrìbọmi? Ọjọ́ orí kọ́ la fi ń ṣèrìbọmi. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ dàgbà tó, kó o sì lè ronú dáadáa, kó o bàa lè mọ ohun tó túmọ̀ sí láti yara ẹ sí mímọ́.

Ká sọ pé o fẹ́ ṣèrìbọmi, táwọn òbí ẹ sì wá ń sọ pé kó o ṣì ní sùúrù ńkọ́? Ó lè jẹ́ pé wọ́n fẹ́ kó o túbọ̀ nírìírí dáadáa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Mọrírì ìmọ̀ràn wọn, kó o sì lo àǹfààní yẹn láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.—1 Sámúẹ́lì 2:26.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 308, 309]

Tí mo kọ èrò mi sí

Ṣó O Ti Ń Ronú Láti Ṣèrìbọmi?

Yẹ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí wò láti fi mọ̀ bóyá ò ń tẹ̀ síwájú láti ṣèrìbọmi. Rí i dájú pé o yẹ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a kọ síbẹ̀ wò, kó o tó kọ ìdáhùn.

Àwọn ọ̀nà wo lò ń gbà fi hàn báyìí pé o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?Sáàmù 71:5. ․․․․․

Báwo lo ṣe ń fi hàn pé o ti kọ́ agbára ìrònú rẹ láti máa fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́?Hébérù 5:14. ․․․․․

Báwo lo ṣe máa ń gbàdúrà lemọ́lemọ́ tó? ․․․․․

Báwo làdúrà ẹ ṣe máa ń sọ ojú abẹ níkòó tó, kí sì ni àdúrà ẹ ń fi hàn nípa bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà sí?Sáàmù 17:6. ․․․․․

Kọ àwọn ohun tó o fẹ́ fi ṣe àfojúsùn ẹ lórí ọ̀rọ̀ àdúrà gbígbà sórí ìlà yìí. ․․․․․

Báwo lo ṣe máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé tó?Jóṣúà 1:8. ․․․․․

Àwọn nǹkan wo lo máa ń ṣe bó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́? ․․․․․

Kọ àwọn ohun tó o fẹ́ fi ṣe àfojúsùn ẹ lórí ọ̀rọ̀ dídá kẹ́kọ̀ọ́ sórí ìlà yìí. ․․․․․

Ṣó o máa ń wàásù lọ́nà tó já fáfá? (Bí àpẹẹrẹ: Ṣó o lè ṣàlàyé àwọn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì fáwọn ẹlòmíì? Ṣó o máa ń pa dà lọ bẹ àwọn tó bá fìfẹ́ hàn wò? Ṣó ò ń sapá láti máa darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?)

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

Ṣó o máa ń lọ sóde ẹ̀rí báwọn òbí ẹ ò bá tiẹ̀ lọ?Ìṣe 5:42.

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

Kọ àwọn ohun tó o fẹ́ fi ṣe àfojúsùn ẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù síbí.2 Tímótì 2:15.

Ṣó o máa ń lọ sáwọn ìpàdé ìjọ déédéé àbí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan?Hébérù 10:25. ․․․․․

Àwọn ọ̀nà wo lo máa ń gbà lóhùn sáwọn ìpàdé? ․․․․․

Ṣó o máa ń lọ sípàdé, báwọn òbí ẹ ò bá tiẹ̀ lè lọ (àmọ́ tí wọ́n ní kó o lọ)?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

Ṣóòótọ́ ni inú ẹ máa ń dùn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?Sáàmù 40:8.

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

Ṣó o lè sọ àwọn ìgbà tó o ti kọ̀ láti jẹ́ káwọn ojúgbà ẹ sọ ẹ́ dà bí wọ́n ṣe dà?Róòmù 12:2. ․․․․․

Kí làwọn nǹkan tó o ní lọ́kàn láti ṣe kó o lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?Júúdà 20, 21. ․․․․․

Ṣé wàá ṣì máa sin Jèhófà bí dádì àti mọ́mì ẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ bá láwọn ò sìn ín mọ́?Mátíù 10:36, 37.

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 310]

Bí ìgbéyàwó ṣe máa ń yí ìgbésí ayé ẹni pa dà náà ni ìrìbọmi máa ń ṣe. Èèyàn gbọ́dọ̀ rò ó dáadáa