Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

ORÍ 35

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

Nígbà tí nǹkan kan ṣẹlẹ̀ sí Jeremy ló tó mọ àǹfààní tó wà nínú kéèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ó ṣàlàyé pé, “Dádì mi fi wá sílẹ̀ nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá [12]. Mo wá ń gbàdúrà sí Jèhófà lórí bẹ́ẹ̀dì mi lọ́jọ́ kan pé kó jẹ́ kí dádì mi pa dà wá sílé.”

Nígbà tọ́kàn Jeremy dà rú, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì. Nígbà tó ka Sáàmù 10:14, nǹkan tó kà níbẹ̀ wú u lórí gan-an. Ẹsẹ yẹn sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ ni aláìrìnnàkore, ọmọdékùnrin aláìníbaba, fi ara rẹ̀ lé lọ́wọ́. Ìwọ tìkára rẹ ti di olùrànlọ́wọ́ rẹ̀.” Jeremy sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé Jèhófà ń bá mi sọ̀rọ̀ tó sì ń sọ fún mi pé òun ni olùrànlọ́wọ́ mi, òun sì ni Bàbá mi. Bàbá míì wo ni mo tún lè ní tó máa dà bíi Jèhófà?”

BÓYÁ irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Jeremy yìí ló ń ṣẹlẹ̀ síwọ náà tàbí irú ẹ̀ kọ́, Bíbélì fi hàn pé Jèhófà fẹ́ kó o jẹ́ ọ̀rẹ́ òun. Ó sọ pé kó o ‘sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ ẹ.’ (Jákọ́bù 4:8) Ronú nípa ohun táwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn túmọ̀ sí: Bó ò tiẹ̀ lè rí Ọlọ́run sójú, tí kì í sì í ṣe ẹgbẹ́ ẹ lọ́nàkọnà, Jèhófà Ọlọ́run ń pè ẹ́ pé kó o wá jẹ́ ọ̀rẹ́ òun!

Àmọ́ tó o bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, àfi kó o ṣe àwọn nǹkan kan. Jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí: Bó o bá gbin òdòdó sínú ilé, o mọ̀ pé kò kàn lè máa dàgbà fúnra ẹ̀. Àfi kó o máa bomi sí i déédéé, kó o sì gbé e síbi tó ti máa lè hù dáadáa. Béèyàn ṣe gbọ́dọ̀ sapá láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run náà nìyẹn. Báwo lo ṣe lè máa bá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́?

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ṣe Pàtàkì

Téèyàn bá ń bá ẹlòmíì ṣọ̀rẹ́, èèyàn á máa fetí sílẹ̀, èèyàn á sì máa sọ tinú ẹ̀. Ohun téèyàn gbọ́dọ̀ máa ṣe tó bá ń bá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́ náà nìyẹn. Bá a bá ń ka Bíbélì, inú ẹ̀ la ti máa ń gbọ́ àwọn ohun tí Ọlọ́run ní í sọ fún wa.— Sáàmù 1:2, 3.

Ká sòótọ́, o lè máà nífẹ̀ẹ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́. Ó tẹ́ ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lọ́rùn láti máa wo tẹlifíṣọ̀n, kí wọ́n máa ṣeré, tàbí kí wọ́n kàn máa ṣe fàájì láàárín àwọn ọ̀rẹ́ wọn ju kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ. Àmọ́, tó o bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kò sọ́gbọ́n tó o lè dá sí i. Àfi kó o máa fetí sí i nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Fọkàn ẹ balẹ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò dà bí iṣẹ́ ilé. O lè gbádùn ẹ̀ kódà tó ò bá kí í kẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀. Nǹkan tó o ní láti kọ́kọ́ ṣe ni pé kó o wáyè láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Lais sọ pé: “Mo ní ètò tí mo ṣe. Mo máa ń ka orí kọ̀ọ̀kan látinú Bíbélì láràárọ̀.” Bí Maria tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ṣe ṣètò ara ẹ̀ yàtọ̀ síyẹn. Ó sọ pé: “Mo máa ń ka Bíbélì kí n tó sùn lálaalẹ́.”

Bó o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ láyè ara ẹ, wo  àpótí tó wà lójú ìwé 292. Kó o wá kọ ìgbà tó o lè máa lo nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ìṣẹ́jú láti máa fi kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sórí ìlà yìí:

․․․․․

Ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni wíwá àkókò láti máa ka Bíbélì jẹ́ o. Bó o bá ti bẹ̀rẹ̀, wàá wá rí i pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ló rọrùn láti máa ka Bíbélì. O lè fara mọ́ ohun tí Jezreel, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá [11], sọ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n, pé “Àwọn apá ibì kan nínú Bíbélì ṣòro lóye, àwọn ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀ ò sì dùn.” Bó bá jẹ́ pé ohun tíwọ náà rò nìyẹn, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Máa wo ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí ìgbà tí Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ, ń bá ẹ sọ̀rọ̀. Bó pẹ́ bó yá, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì á bẹ̀rẹ̀ sí dùn mọ́ ẹ, wàá sì máa jàǹfààní ẹ̀ bó o bá ṣe fẹ́ ẹ sí!

Àdúrà Ṣe Pàtàkì

Àdúrà la fi ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Ìwọ náà wo irú ẹ̀bùn àtàtà tí àdúrà jẹ́! O lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nígbàkigbà, bóyá lọ́sàn-án tàbí lóru. Kò sígbà tá ò lè bá a sọ̀rọ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó tún fẹ́ láti gbọ́ ohun tó o bá ní í sọ. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà ẹ́ níyànjú pé: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6.

Ẹsẹ Bíbélì yẹn fi hàn pé ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè bá Jèhófà sọ. Títí kan àwọn ìṣòro tó o bá ní àti ohunkóhun tó bá ń gbé ẹ lọ́kàn. Ó sì tún yẹ kó o dúpẹ́ fáwọn nǹkan tó bá ṣe fún ẹ. Ó ṣe tán, o ṣáà máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n bá ṣe ẹ́ lóore. Ó yẹ kó o máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà náà, ẹni tó ti ṣohun tí ọ̀rẹ́ kan ò lè ṣe fún ẹ.—Sáàmù 106:1.

Kọ àwọn nǹkan tó ò ń dúpẹ́ pé Jèhófà ti ṣe fún ẹ sórí ìlà yìí.✎

․․․․․

Kò sí àníàní pé o máa ń ṣàníyàn, àwọn nǹkan kan sì máa ń gbé ẹ lọ́kàn sókè lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Sáàmù 55:22 sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.”

Kọ àwọn nǹkan tó ń gbé ẹ lọ́kàn sókè, tó o fẹ́ fi sínú àdúrà ẹ sórí ìlà yìí.

․․․․․

Ìrírí Tó O Ní

Nǹkan kan tún wà nípa jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tí kò yẹ kó o gbójú fò dá. Dáfídì, tó wà lára àwọn tó kọ Sáàmù, kọ̀wé pé: “Tọ́ ọ wò, [kó o] sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.” (Sáàmù 34:8) Dáfídì ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ nǹkan kan tí ò bá ti gbẹ̀mí ẹ̀ ni nígbà tó kọ Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n [34]. Ibi tó ti ń sá fún Sọ́ọ̀lù Ọba tó fẹ́ pa á, ló bá sá lọ sáàárín àwọn Filísínì tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá rẹ̀. Nígbà tó rí i pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n pa òun, ló bá ṣe bí ẹni tórí ẹ̀ ti yí, kó lè bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.—1 Sámúẹ́lì 21:10-15.

Dáfídì ò sọ pé mímọ̀ ọ́n ṣe òun ni. Àmọ́, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Ó sọ nínú Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n yẹn pé: “Mo wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì dá mi lóhùn, Ó sì dá mi nídè nínú gbogbo jìnnìjìnnì mi. (Sáàmù 34:4) Ìrírí tí Dáfídì fúnra ẹ̀ ní ló jẹ́ kó sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n ‘tọ́ ọ wò, kí wọ́n sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.” *

Ṣó o lè rántí ohun kan tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, tó fi hàn pé Jèhófà ò fi ẹ́ sílẹ̀? Bó o bá rántí, kọ ọ́ sínú àlàfo tó wà nísàlẹ̀ yìí. Fi sọ́kàn pé: Kì í ṣe dandan pé kó jẹ́ nǹkan àràmàǹdà. Gbìyànjú láti ronú lórí àwọn nǹkan kan, tó o tiẹ̀ lè má kà sí pàápàá, èyí tí Jèhófà ń ṣe fún ẹ lójoojúmọ́.

․․․․․

Ó ṣeé ṣe káwọn òbí ẹ ti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni, ìyẹn dáa gan-an. Àmọ́, ìwọ fúnra ẹ ṣì ní láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Bó ò bá tíì di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, àwọn nǹkan tá a sọ nínú orí yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jèhófà máa bù kún ìsapá ẹ. Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí.”—Mátíù 7:7.

KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 38 ÀTI 39 NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣó máa ń ṣòro fún ẹ láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn? Kọ́ bó o ṣe lè ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o gbà gbọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 24 Àwọn Bíbélì kan túmọ̀ “tọ́ ọ wò” kó o “sì rí i” sí, “wádìí fúnra ẹ,” “wá a rí fúnra ẹ” àti “tó bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, wàá rí i.”Ìtumọ̀ Contemporary English Version, Today’s English Version àti The Bible in Basic English.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kànMátíù 5:3.

ÌMỌ̀RÀN

Bó o bá ń ka ojú ìwé mẹ́rin péré nínú Bíbélì lójoojúmọ́, wàá parí odindi Bíbélì láàárín ọdún kan.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Bó o ṣe ń kàwé yìí, tó o sì ń fàwọn ìmọ̀ràn tá à ń mú jáde látinú Bíbélì ṣèwà hù fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ.Jòhánù 6:44.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Kí n lè rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ sí i kọ́ bí mo bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, màá ․․․․․

Ohun tí màá ṣe kí n bàa lè túbọ̀ máa gbàdúrà déédéé ni pé ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Báwo lo ṣe lè túbọ̀ máa gbádùn dídá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

● Kí nìdí tí Jèhófà fi máa ń fẹ́ láti gbọ́ àdúrà àwa èèyàn aláìpé?

● Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí àdúrà tó ò ń gbà túbọ̀ máa nítumọ̀?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 291]

“Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo máa ń sọ àsọtúnsọ bí mo bá ń gbàdúrà. Àmọ́ ní báyìí, àwọn nǹkan tó dáa àtàwọn nǹkan tí kò dáa tó bá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan ni mo máa ń fi sínú àdúrà. Níwọ̀n bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ ò sì ti dọ́gba, mi ò sọ àsọtúnsọ mọ́.”—Eve

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 292]

 Mọ Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì Ẹ

1. Yan ìtàn Bíbélì tó bá wù ẹ́ láti kà. Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ lọ́gbọ́n kóun tó o bá kà lè yé ẹ.

2. Fara balẹ̀ ka ìtàn náà. Má ṣe sáré kà á. Bó o bá ṣe ń kà á, máa fọkàn yàwòrán nǹkan tó o bá ń kà. Pọkàn pọ̀ sórí ohun tó ò ń kà, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn, bíi pé ò ń gbọ́ ohùn àwọn èèyàn yẹn, bíi pé ò ń gbóòórùn tí wọ́n ń gbọ́, ò ń bá wọn jẹun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Jẹ́ kó dà bíi pé ìtàn yẹn ń ṣẹlẹ̀ lójú ẹ!

3. Ronú nípa ohun tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà yẹn. Kó o máa bi ara ẹ láwọn ìbéèrè bíi:

● Kí nìdí tí Jèhófà fi ní kí wọ́n kọ ìtàn yìí sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀?

● Àpẹẹrẹ ta ni mo lè tẹ̀ lé nínú ìtàn yìí, àpẹẹrẹ ta ló sì yẹ kí n fi ṣàríkọ́gbọ́n?

● Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni mo lè rí kọ́ nínú ìtàn tí mo kà yìí?

● Kí ni ìtàn yìí kọ́ mi nípa Jèhófà àti ọ̀nà tó ń gbà ṣe nǹkan?

4. Gbàdúrà ṣókí sí Jèhófà. Sọ ẹ̀kọ́ tó o rí kọ́ látinú Bíbélì fún Jèhófà nígbà tó o bá ń gbàdúrà, àti bó o ṣe fẹ́ fi sílò. Máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ẹ̀bùn tó fún ẹ, ìyẹn Bíbélì Mímọ́ tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀!

[Àwòrán]

“Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.” —Sáàmù 119:105.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 294]

Kọ́kọ́ Ṣohun Tó Yẹ

Sọ́wọ́ ẹ máa ń dí jù láti gbàdúrà? Àbí o kì í ráyè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ohun tó máa ń pinnu bóyá wàá ráyè ni ohun tó o bá kà sí pàtàkì.

Gbìyànjú kiní yìí wò ná: Kó òkúta tó pọ̀ díẹ̀ sínú ike kan. Kó o wá rọ iyẹ̀pẹ̀ sínú ike náà títí tó fi máa kún. Ó túmọ̀ sí pé iyẹ̀pẹ̀ àti òkúta ló wà nínú ike náà.

Wá kó gbogbo nǹkan tó wà nínú ike náà kúrò. Kó o sì tún kó gbogbo ẹ̀ padà sínú ẹ̀, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, iyẹ̀pẹ̀ ni kó o kọ́kọ́ kó sí i, kó o tó kó òkúta sínú ẹ̀. Ṣó gba gbogbo òkúta náà? Kò lè gbà á torí pé iyẹ̀pẹ̀ yẹn lo kọ́kọ́ kó sínú rẹ̀.

Kí nìyẹn kọ́ wa? Bíbélì sọ pe ká “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Bó o bá lọ fàwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì bí eré ìtura sípò àkọ́kọ́, o ò ní ráyè fún nǹkan tó ṣe pàtàkì, ìyẹn àwọn nǹkan tẹ̀mí. Àmọ́, bó o bá fetí sí ìmọ̀ràn Bíbélì, wàá rí i pé o máa ráyè fáwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run, wàá sì tún ráyè níwọ̀nba láti ṣeré ìtura. Ohun tó máa pinnu gbogbo ẹ̀ lohun tó o bá kọ́kọ́ kó sínú ike ẹ!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 290]

Béèyàn ṣe gbọ́dọ̀ máa tọ́jú òdòdó tó bá gbìn sínú ilé, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ kó o máa ṣàwọn ohun tá á mú kó o máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run