Àwòkọ́ṣe—Àwọn Hébérù Mẹ́ta
Àwòkọ́ṣe—Àwọn Hébérù Mẹ́ta
Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà wà lórí ìdúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà, nítòsí Bábílónì. Gbogbo àwọn èèyàn tó wà yí wọn ká forí balẹ̀ fún ère gàgàrà kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ojúgbà wọn, títí kan ọba, ń fẹ́ káwọn náà forí balẹ̀, àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà ò yí ìpinnu wọn pa dà. Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, àmọ́ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ ni wọ́n sọ fún ọba Nebukadinésárì pé kò sóhun tó lè yí ìpinnu àwọn láti sin Jèhófà pa dà.—Dáníẹ́lì 1:6; 3:17, 18.
Ọ̀dọ́ làwọn ọkùnrin wọ̀nyí nígbà tí wọ́n kó wọn lọ sí Bábílónì. Bí wọ́n ṣe jẹ́ olóòótọ́ nígbà tí wọ́n ṣì wà lọ́mọdé, tí wọ́n sì kọ̀ láti jẹ oúnjẹ tí Ọlọ́run sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ, mú kí wọ́n gbára dì láti dojú kọ àwọn ìṣòro tó jẹ yọ lẹ́yìn tí wọ́n ti dàgbà. (Dáníẹ́lì 1:6-20) Ìrírí ti fi kọ́ wọn pé jíjẹ́ onígbọràn sí Jèhófà lohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ. Ṣé ìwọ náà ti pinnu láti máa fàwọn ìlànà Ọlọ́run ṣèwà hù bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ojúgbà rẹ lè máa yọ ẹ́ lẹ́nu? Bó o bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà nígbà tó o ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, àní nínú àwọn ohun tó dà bíi pé kò tó nǹkan pàápàá, á túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti jẹ́ olóòótọ́ nígbà tó o bá dojú kọ àwọn ìṣòro tó pọ̀ sí i bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́.—Òwe 3:5, 6; Lúùkù 16:10.