Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwòkọ́ṣe—Ásáfù

Àwòkọ́ṣe—Ásáfù

Àwòkọ́ṣe—Ásáfù

Nǹkan ò rọgbọ fún Ásáfù rárá. Ó ń ráwọn èèyàn tí wọ́n ń rú òfin Ọlọ́run tó sì dà bíi pé wọ́n ń mú un jẹ! Ìyẹn wá jẹ́ kí Ásáfù máa ronú pé àbí àṣejù lòún ń ṣe láti máa pa òfin Ọlọ́run mọ́ ni? Ó sọ pé: “Dájúdájú, lásán ni mo wẹ ọkàn-àyà mi mọ́, tí mo sì wẹ ọwọ́ mi ní àìmọwọ́mẹsẹ̀.” Lẹ́yìn tí Ásáfù ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yẹn, ó yí èrò rẹ̀ pa dà. Ó wá rí i pé gbogbo ìgbádùn àwọn èèyàn burúkú ò lè ju ìgbà díẹ̀ lọ. Ibo ló wá parí ọ̀rọ̀ sí? Ó sọ fún Jèhófà nínú orin tó kọ pé: “Yàtọ̀ sí ìwọ, èmi kò ní inú dídùn mìíràn lórí ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 73:3, 13, 16, 25, 27.

Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà máa rò ó lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé àṣejù lèèyàn ń ṣe bó bá ń fàwọn ìlànà Ọlọ́run ṣèwà hù. Àmọ́, ó yẹ kí ìwọ náà ro àròjinlẹ̀ bíi ti Ásáfù. Wo bí nǹkan ṣe máa ń rí fáwọn tó bá ń rú òfin Jèhófà. Ṣé ọkàn wọn balẹ̀ lóòótọ́? Ṣé wọ́n ti mọ àṣírí kan tó ń fún wọn láyọ̀ táwọn tó ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run ò mọ̀? Bó o bá ro ọ̀rọ̀ yìí dáadáa, ó dájú pé ìwọ náà á fẹ́ tún ọ̀rọ̀ Ásáfù sọ, pé: “Sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.”—Sáàmù 73:28.