Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwòkọ́ṣe—Dáfídì

Àwòkọ́ṣe—Dáfídì

Àwòkọ́ṣe—Dáfídì

Dáfídì nífẹ̀ẹ́ sí orin. Ó lẹ́bùn orin kíkọ, ó sì mọ béèyàn ṣe ń kọ ọ̀rọ̀ tó máa wá di orin. Kódà, òun fúnra ẹ̀ ló máa ń ṣe àwọn ohun èlò orin tó ń lò. (2 Kíróníkà 7:6) Dáfídì mọ orin kọ débi pé ọba Ísírẹ́lì máa ń pè é pé kó wá ṣeré fún wọn láàfin. (1 Sámúẹ́lì 16:15-23) Dáfídì sì máa ń gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ kò sọ orin kíkọ di ohun tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni jẹ́ kí orin tó ń kọ gbà á lọ́kàn débi tá á fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fi ẹ̀bùn tó ní yin Jèhófà.

Ṣó o fẹ́ràn orin? O lè máà lẹ́bùn orin kíkọ, àmọ́ o ṣì lè fara wé Dáfídì. Lọ́nà wo? Ìyẹn tíwọ náà ò bá jẹ́ kí orin tó ò ń gbọ́ máa darí ohun tó ò ń ṣe tàbí kó mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí ṣohun tí ò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o máa fi orin gbádùn ara ẹ. Ọlọ́run ló fún wa lẹ́bùn láti kọ orin àti láti máa tẹ́tí sí i. (Jákọ́bù 1:17) Ọ̀nà tó múnú Jèhófà dùn ni Dáfídì gbà lo ẹ̀bùn yìí. Ṣéwọ náà á ṣe bẹ́ẹ̀?