Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwòkọ́ṣe—Jósẹ́fù

Àwòkọ́ṣe—Jósẹ́fù

Àwòkọ́ṣe—Jósẹ́fù

Wàhálà rèé o! Ìyàwó ọ̀gá Jósẹ́fù ń pè é léraléra pé kó wá bá òun sùn. Ó tún ti bẹ̀rẹ̀ o! Àmọ́ Jósẹ́fù ò wojú ẹ̀. Ńṣe ló kọ̀ jálẹ̀. Ó sọ fún obìnrin yẹn pé: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?” Nígbà tíyàwó ọ̀gá Jósẹ́fù fẹ́ fipá mú un balẹ̀, ojú ò tì í láti fẹsẹ̀ fẹ. Àní sẹ́, eré ló jáde kúrò nínú ilé yẹn! Jósẹ́fù fi hàn pé òun ò gbàgbàkugbà.Jẹ́nẹ́sísì 39:7-12.

Ẹnì kan lè fi ìṣekúṣe lọ ìwọ náà. Yàtọ̀ sí pé o gbọ́dọ̀ pinnu lọ́kàn ẹ pé o ò ní ṣe é, ó yẹ kó máa wù ẹ́ láti tẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ lọ́rùn, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. Ṣó o rí i, bó ti ń wù ẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ náà ló ń wu Jósẹ́fù. Àmọ́, Jósẹ́fù ò rídìí tó fi yẹ kóun tẹ́ra òun lọ́rùn lọ́nà tínú Ẹlẹ́dàá ò dùn sí. Ó yẹ kíwọ náà mọ̀ dájú pé inú Ọlọ́run ò dùn sí ìṣekúṣe àtàwọn àṣàkaṣà wọ̀nyẹn, àti pé ńṣe lo máa kábàámọ̀ gbẹ̀yìn. Torí náà, kọ́ ara ẹ bíi ti Jósẹ́fù, kó o sì rí i dájú pé o ò gbàgbàkugbà.