Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwòkọ́ṣe—Opó Aláìní

Àwòkọ́ṣe—Opó Aláìní

Àwòkọ́ṣe—Opó Aláìní

Jésù ń wo àwọn olówó bí wọ́n ṣe ń ju owó sínú àpótí ọrẹ tó wà nínú tẹ́ńpìlì. Ó tajú kán rí opó aláìní kan tó ju “ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọn kéré gan-an” sínú àpótí náà. (Lúùkù 21:2) Jésù gbóríyìn fún un nítorí ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀. Kí nìdí? Torí àwọn tó kù ṣètìlẹ́yìn “láti inú àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n, láti inú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní sínú rẹ̀, gbogbo ohun ìní ìgbésí ayé rẹ̀.”—Máàkù 12:44.

Ṣé ohun tó ṣe pàtàkì jù sí obìnrin yẹn ló ṣe pàtàkì síwọ náà? Ṣé ìwọ náà lè fi àkókò rẹ àti owó rẹ sin Ọlọ́run? Bíi ti opó aláìní yẹn, o lè fowó ṣètìlẹ́yìn fún títún àwọn ibi ìjọsìn wa ṣe. O tún lè lo àkókò àti owó rẹ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run. Inú Jèhófà dùn sí owó kékeré tí opó yẹn fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Inú Ọlọ́run á dùn sí ìwọ náà, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá fi ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ ṣe ohun àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ—Mátíù 6:33.