Àwòkọ́ṣe—Pọ́ọ̀lù
Àwòkọ́ṣe—Pọ́ọ̀lù
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ò fọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ rárá nípa ohun tó ń rò lọ́kàn. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi.” Pọ́ọ̀lù kì í ro èròkerò, torí ó sọ pé: “Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú.” Kí wá nìṣòro Pọ́ọ̀lù? Ó sọ pé: “Mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.” Àwọn àṣìṣe Pọ́ọ̀lù kò múnú ẹ̀ dùn. Ó tiẹ̀ ké gbàjarè pé: “Èmi abòṣì ènìyàn!”—Róòmù 7:21-24.
Ṣáwọn àṣìṣe rẹ máa ń bà ẹ́ nínú jẹ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, rántí pé láwọn ìgbà míì, bó ṣe máa ń rí lára Pọ́ọ̀lù náà nìyẹn. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú mọ̀ pé àwọn èèyàn bíi tòun ni Kristi kú fún, èyí tó mú kó sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!” (Róòmù 7:25) Pọ́ọ̀lù ka ìràpadà sí ẹ̀bùn tóun rí gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó kọ̀wé pé: “Ọmọ Ọlọ́run . . . nífẹ̀ẹ́ mi, ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” (Gálátíà 2:20) Bí ọkàn rẹ bá rẹ̀wẹ̀sì, ronú lórí ìràpadà. Báwọn ìkùdíẹ̀-káàtó rẹ bá sì mú kí nǹkan tojú sú ẹ, má ṣe gbà gbé pé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni Kristi kú fún, kì í ṣàwọn èèyàn pípé.