Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Òbí Rẹ

Àwọn Òbí Rẹ

APÁ 6

Àwọn Òbí Rẹ

Àǹfààní gbáà ni ìrírí táwọn òbí ní jẹ́ fún wọn. Wọ́n ti kojú àwọn ìyípadà tó máa ń dé bá ara àti onírúurú èrò tó máa ń wá síni lọ́kàn nígbà ìbàlágà. Ó ṣe wẹ́kú nígbà náà pé àwọn gan-an ló lè tọ́ sọ́nà kó o má bàa kó síṣòro bíwọ náà ṣe ń gòkè àgbà. Àmọ́ ṣá, ó lè dà bíi pé ńṣe làwọn òbí ń dá kún ìṣòro dípò kí wọ́n yanjú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè máa kojú ọ̀kan lára àwọn ìṣòro wọ̀nyí:

Àwọn òbí mi kì í yé rí sí mi.

Dádì tàbí Mọ́mì ti ki àṣejù bọ ọtí mímu tàbí lílo oògùn olóró.

Ńṣe làwọn òbí mi máa ń jà ṣáá.

Àwọn òbí mi ti fira wọn sílẹ̀.

Orí 21 sí 25 nínú ìwé yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tó o lè ṣe nípa àwọn ìṣòro yìí àtàwọn ìṣòro míì.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 172, 173]