Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Kí N Ṣe Báwọn Òbí Mi Bá Ń Jà?

Kí Ni Kí N Ṣe Báwọn Òbí Mi Bá Ń Jà?

ORÍ 24

Kí Ni Kí N Ṣe Báwọn Òbí Mi Bá Ń Jà?

Ṣé dádì àti mọ́mì ẹ ti bára wọn jà lójú ẹ rí? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, èwo nínú àwọn nǹkan tá a tò síbí yìí ló máa ń fa ìjà wọn?

□ Owó

□ Iṣẹ́ ilé

□ Àwọn mọ̀lẹ́bí

□ Ìwọ

Kí ló wù ẹ́ kó o sọ fún mọ́mì àti dádì ẹ nípa bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ? Kọ ọ́ síbí yìí.

․․․․․

KÒ SÍ àníàní pé, bí dádì àti mọ́mì ẹ bá ń jà, ó máa rí bákan lára ẹ. Ó ṣe tán, o fẹ́ràn wọn, àwọn ló sì ń bọ́ ẹ. Torí náà, bó o bá ń gbọ́ táwọn méjèèjì ń sọ̀rọ̀ síra wọn, inú ẹ lè má dùn sí i. Ó ṣeé ṣe kó o fara mọ́ ohun tí ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Marie sọ, ó ní: “Ó máa ń ṣòro fún mi láti bọ̀wọ̀ fáwọn òbí mi nígbà táwọn náà ò bọ̀wọ̀ fúnra wọn.”

Bó o bá rí i tí dádì àti mọ́mì ẹ ń bára wọn jà, ìyẹn á jẹ́ kó o mọ òótọ́ ọ̀rọ̀ kan, ìyẹn ni pé, kò yẹ kó o máa ronú pé àwọn òbí ẹ ò lè ṣàṣìṣe. Òótọ́ ọ̀rọ̀ tó o mọ̀ yìí wá lè jẹ́ kẹ́rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà ẹ́. Àgàgà bí wọn ò bá yéé jà tí ìjà wọn sì ń le sí i, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé wọn ò ní pẹ́ tú ká. Marie sọ pé: “Bí mo bá ti ń gbọ́ tí dádì àti mọ́mì mi ń bára wọn jà, mo máa ń rò pé wọn ò ní pẹ́ kọra wọn sílẹ̀, á wá di pé kí n yan ẹni ti màá bá lọ nínú wọn. Mo tún máa ń wò ó pé èmi àtàwọn àbúrò mi á wá máa gbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.”

Kí nìdí táwọn òbí fi máa ń jà, kí lo sì lè ṣe nígbà tíjà bá ṣẹlẹ̀?

Ìdí Táwọn Òbí Fi Máa Ń Jà

Àwọn òbí ẹ lè ṣègbọràn sófin tó sọ pé kí wọ́n máa ‘fara dà á fún ara wọn lẹ́nì kìíní kejì nínú ìfẹ́.’ (Éfésù 4:2) Àmọ́, Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Aláìpé làwọn òbí ẹ. Torí náà, má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu báwọn nǹkan tí kò tẹ́ wọn lọ́rùn bá ń fa ìjà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

Tún rántí pé, “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” la wà yìí. (2 Tímótì 3:1) Wàhálà àtijẹ àtimu, bí wọ́n ṣe fẹ́ sanwó ilé, owó omi, owó iná àtàwọn nǹkan míì tẹ́ ẹ̀ ń lò, títí kan àwọn ìṣòro tí wọ́n ń bá yí nibi iṣẹ́, gbogbo ẹ̀ wà lára ohun tó ń fa rògbòdìyàn nínú ilé. Bó bá sì jẹ́ pé àwọn méjèèjì ló ń ṣiṣẹ́ oṣù, bí wọ́n ṣe fẹ́ mọ ẹni tá á máa ṣàwọn iṣẹ́ kan nínú ilé lè fa awuyewuye.

Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé, bí dádì àti mọ́mì ẹ bá ń bára wọn jà, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé wọ́n máa kọra wọn sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló ṣì wà pé wọ́n fẹ́ràn ara wọn bérò wọn ò tiẹ̀ dọ́gba lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan.

Jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí: Ṣé ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ ti jọ wo fíìmù kan rí, tó o wá rí i pé ohun tó wà lọ́kàn ẹ yàtọ̀ sí tiwọn? Ó lè ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ kòríkòsùn pàápàá lè yàtọ̀ síra lórí àwọn ọ̀ràn kan. Ó lè jẹ́ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín dádì ẹ àti mọ́mì ẹ náà nìyẹn. Ọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe fẹ́ gbọ́ bùkátà ìdílé lè jẹ àwọn méjèèjì lógún, àmọ́ kó jẹ́ pé èrò wọn ò dọ́gba lórí bí wọ́n ṣe fẹ́ ṣọ́ owó ná; àwọn méjèèjì lè máa ronú nípa bí ìdílé ṣe fẹ́ lọ gbafẹ́, àmọ́ kó jẹ́ pé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lohun tí wọ́n ní lọ́kàn nípa bó ṣe yẹ kéèyàn jẹ̀gbádùn; àwọn méjèèjì ló fẹ́ kó o ṣe dáadáa níléèwé, àmọ́ nǹkan ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà lọ́kàn wọn nípa bí wọ́n ṣe fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Ohun tó wà níbẹ̀ ni pé, nǹkan tó wà lọ́kàn àwọn méjì tó fẹ́ràn ara wọn lè yàtọ̀ síra nígbà míì. Àmọ́, inú ẹ ṣì lè má dùn tó o bá ń gbọ́ táwọn òbí ẹ ń jà. Kí lo lè ṣe tàbí tó o lè sọ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa fara dà á?

Ohun Tó O Lè Ṣe

Máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Ó rọrùn gan-an láti bẹ̀rẹ̀ sí í bínú sáwọn òbí tó bá ń bára wọn jà. Àwọn ṣáà ló yẹ kó fàpẹẹrẹ lélẹ̀ fún ẹ, kì í ṣe ìwọ ló yẹ kó o kọ́ wọn lóhun tí wọ́n máa ṣe. Bó o bá wá ń ṣe gbọ́ńkúgbọ́ńkú sí wọn, ṣe lo tún ń dá kún wàhálà tó wà nílẹ̀. Pàtàkì jù lọ ni pé, Jèhófà Ọlọ́run pàṣẹ pé kó o bọ̀wọ̀ fáwọn òbí ẹ, kó o sì máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, kódà bí kò bá rọrùn fún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Ẹ́kísódù 20:12; Òwe 30:17.

Bó bá wá lọ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tìẹ ló fa ìjà àwọn òbí ẹ ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn òbí ẹ ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ tí ẹnì kejì kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ńkọ́? Wàhálà ẹ̀sìn lè wáyé tó máa nílò pé kó o ṣe ìpinnu tó máa jẹ́ kó o lè sin Jèhófà pẹ̀lú èyí tó bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú àwọn méjèèjì. (Mátíù 10:34-37) Rí i dájú pé o ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú “inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” Àpẹẹrẹ bó o ṣe ń hùwà lórí ọ̀rọ̀ yìí lè mú kí òbí ẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn wá sin Jèhófà nígbà tó bá yá.—1 Pétérù 3:15.

Má gbè sẹ́yìn ẹnikẹ́ni. Kí lo lè ṣe bí dádì tàbí mọ́mì ẹ bá fẹ́ kó o gbè sẹ́yìn ẹnì kan lórí ọ̀rọ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ kàn ẹ́? Gbìyànjú láti má gbè sẹ́yìn ẹnikẹ́ni. O lè fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ yọra ẹ kúrò tó o bá sọ fún wọn pé: “Mo fẹ́ràn ẹ̀yin méjèèjì. Àmọ́ ẹ máà jẹ́ kí n gbè sẹ́yìn ẹnì kankan. Ẹyìn méjèèjì náà lẹ máa yanjú ọ̀rọ̀ yìí láàárín ara yín.”

Bá wọn sọ̀rọ̀. Jẹ́ káwọn òbí ẹ mọ bí ìjà wọn ṣe máa ń rí lára ẹ. Bá wọn sọ̀rọ̀ nígbà tó o bá rò pé wọ́n á fara balẹ̀ gbọ́rọ̀ ẹ, kó o sì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ bí ìjà wọn ṣe máa ń bà ẹ́ nínu jẹ́, tó máa ń múnú bí ẹ tàbí bó ṣe máa ń dẹ́rù bà ẹ́ pàápàá.—Òwe 15:23; Kólósè 4:6.

Ohun Tó Ò Gbọ́dọ̀ Ṣe

Má sọra ẹ di agbọ̀ràndùn. Ọ̀dọ́ ṣì ni ẹ́, o ò kúnjú ìwọ̀n láti báwọn òbí ẹ parí ìjà. Jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí: Bó o bá wà nínú ọkọ̀ òfuurufú kan, tó o wá ń gbọ́ tẹ́ni tó ń wakọ̀ yẹn àtẹni tó ń ràn án lọ́wọ́ ń bára wọn jiyàn, báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yẹn á kọ ẹ́ lóminú. Àmọ́ kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó o bá bẹ́, tó o lọ sọ bí awakọ̀ yẹn ṣe máa wakọ̀ fún un tàbí tó o lọ gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ pátápátá?

Bákan náà, tó o bá lọ ‘gbaṣẹ́ lọwọ́ àwọn òbí ẹ,’ tó o lọ ń dá sí ọ̀rọ̀ lọ́kọláya tó wà láàárín wọn, ṣe ni wàá tún máa dá kún wàhálà tó ti wà nílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Nípasẹ̀ ìkùgbù, kìkì ìjàkadì ni ẹnì kan ń dá sílẹ̀, ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùn lukùn.” (Òwe 13:10) Ó ṣeé ṣe kí dádì àti mọ́mì ẹ yanjú wàhálà tó bá wà láàárín wọn bí wọ́n bá jọ sọ̀rọ̀ ọ̀hún láàárín ara wọn.—Òwe 25:9.

Má ṣe dá sí i. Ariwo èèyàn méjì ò dùn-ún gbọ́ létí. Bó o bá tún wá lọ fi tìẹ kún un, ìjà ìgboro lo fẹ́ dá sílẹ̀ yẹn. Kò sí bó ṣe lè máa wù ẹ́ pé kó o bá wọn dá sí ọ̀rọ̀ náà tó, òótọ́ ibẹ̀ ni pé ojúṣe àwọn òbí ẹ ni láti parí ìjà wọn, ìyẹn kì í ṣe wàhálà tìẹ. Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò pé kó o ‘má ṣe máa yọjú sí ọ̀ràn ọlọ́ràn.’ (1 Tẹsalóníkà 4:11) Má ṣe dá sí ìjà wọn.

Má ṣe forí àwọn òbí ẹ gbára. Àwọn ọ̀dọ́ kan sábà máa ń dá kún ìjà àwọn òbí wọn nípa mímú kí wọ́n forí gbára. Bí mọ́mì wọn bá ní kí wọ́n má ṣe nǹkan kan, wọ́n á fọgbọ́n sọ fún dádì wọn, kó lè gbà fún wọn. Bó o bá ń fọgbọ́n yí ọ̀rọ̀ po, ìyẹn lè jẹ́ kó o máa ráyè ṣe nǹkan tó o bá fẹ́ lóòótọ́, àmọ́ bó pẹ́ bó yá, ó máa dá wàhálà sílẹ̀.

Má ṣe jẹ́ kí ìwà wọn nípa lórí ìwà tìẹ. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Peter rí i nígbà tó yá pé ìwà tóun ń hù sí dádì òun, torí bó ṣe máa ń ṣe, ò bá ti Kristẹni mu. Ó sọ pé: “Mo fẹ́ ṣe nǹkan tó máa dùn wọ́n. Mo kórìíra wọn gan-an torí bí wọ́n ṣe máa ń ṣe sí èmi, àbúrò mi àti mọ́mì mi.” Kò pẹ́ sígbà tá à ń wí yìí, lojú Peter wá já gbogbo nǹkan tó ń ṣe. Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa? Bó o bá bẹ̀rẹ̀ sí hùwàkiwà, ṣe ni wàá tún máa dá kún wàhálà tó ti wà nínú ilé yín.—Gálátíà 6:7.

Èwo nínú àwọn nǹkan tá a sọ nínú orí yìí lo rí i pé ó yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí jù lọ? Kọ ọ́ sórí ìlà yìí. ․․․․․

Ó dájú pé o ò lè ní káwọn òbí ẹ má jà. Àmọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé, Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kojú ìdààmú ọkàn tí ìjà wọn máa ń mú bá ẹ.—Fílípì 4:6, 7; 1 Pétérù 5:7.

Sa gbogbo ipá ẹ láti fàwọn àbá tó wà nínú orí yìí ṣèwà hù. Bó pẹ́ bó yá, dádì àti mọ́mì ẹ á rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa yanjú wàhálà èyíkéyìí tó bá jẹ yọ. Ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n má ṣe bára wọn jà mọ́.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Báwo lo ṣe lè kojú ìṣòro téèyàn máa ń ní nínú ìdílé olóbìí kan?

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́.Kólósè 4:6.

ÌMỌ̀RÀN

Báwọn òbí ẹ ò bá yéé jà tí ìjà wọn sì ń le sí i, fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ fún wọn pé kí wọ́n wẹ́ni ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ṣó o Mọ̀ Pé . . . ?

Ìjà máa ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láàárín àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí dádì àti mọ́mì mi bá ń jà, ohun tí màá ṣe ni pé ․․․․․

Bí wọ́n bá fẹ́ kí n gbè sẹ́yìn ẹnì kan, màá sọ pé ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

Kí nìdí táwọn òbí kan fi máa ń bára wọn jà?

Kí nìdí tí kì í fi í ṣe ẹ̀bi ẹ bí dádì àti mọ́mì ẹ bá ń jà?

Ẹ̀kọ́ wo lo lè rí kọ́ látinú ìwà tí dádì àti mọ́mì ẹ ń hù?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 201]

“Mímọ̀ tí mo mọ̀ pé aláìpé làwọn òbí mi àti pé bí mo ṣe níṣòro tèmi làwọn náà ní tiwọn, ti jẹ́ kí n máa fara dà á bí wọ́n bá ń tahùn síra wọn.”—Kathy

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 206]

Bí Dádì Àti Mọ́mì Mi Bá Fira Wọn Sílẹ̀ Ńkọ́?

Bí dádì àti mọ́mì ẹ bá fira wọn sílẹ̀, báwo lo ṣe lè hùwà tó bọ́gbọ́n mu, láìka bọ́rọ̀ yẹn ṣe dùn ẹ́ tó sí? Gbé àwọn àbá wọ̀nyí yẹ̀ wò:

Má retí nǹkan tí ò ṣeé ṣe. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bó o ṣe fẹ́ parí ìjà láàárín àwọn òbí ẹ ló máa kọ́kọ́ wá sí ẹ lọ́kàn. Anne rántí pé: “Lẹ́yìn tí dádì mi àti mọ́mì mi ti fira wọn sílẹ̀, àwọn méjèèjì ṣì jọ máa ń mú wa jáde lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Èmi àti ẹ̀gbọ́n mi máa ń sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ síra wa létí pé, ‘Jẹ́ ká ṣeré lọ ká fàwọn méjèèjì nìkan sílẹ̀.’ Àmọ́, ó dà bíi pé ìyẹn ò yanjú ìṣòro yẹn. Àwọn méjèèjì ò fẹ́ra wọn mọ́.

Òwe 13:12 sọ pé: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn.” Bó o bá ń rántí pé, o ò láṣẹ lórí nǹkan táwọn òbí ẹ bá ń ṣe, o ò ní máa kó ìdààmú bára ẹ. Ìwọ kọ́ lo pín wọn níyà, kò sì sóhun tó o lè ṣe sí ìgbéyàwó wọn.—Òwe 26:17.

Má ṣe kórìíra ẹnì kankan. Bó o bá ń bínú tàbí tó o bá kórìíra mọ́mì tàbí dádì ẹ, ìyẹn lè ṣàkóbá tí kò mọ níwọ̀n fún ìwọ náà. Tom rántí bọ́rọ̀ yẹn ṣe máa ń rí lára ẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìlá [12], ó ní: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí bínú sí dádì mi gan-an. Mi ò fẹ́ sọ pé mo “kórìíra” wọn, àmọ́ inú mi ò dùn sí wọn rárá. Mi ò mọ bí wọ́n ṣe lè sọ pé àwọ́n fẹ́ràn wa nígbà tí wọ́n pa wá tì.”

Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ìpínyà máa ń túmọ̀ sí pé ẹnì kan nínú àwọn òbí ẹni jẹ̀bi tí èkejì sì jàre. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, àwọn òbí ẹ lè má sọ gbogbo nǹkan tó fa ìjà wọn fún ẹ; ọ̀rọ̀ ọ̀hún lè má ye àwọn náà pàápàá. Torí náà, má ṣèdájọ́ ẹnikẹ́ni láìmọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀. (Òwe 18:13) Ó ṣe tán, ó máa ń rọrùn gan-an láti bínú, ọ̀rọ̀ yẹn sì lè ká ẹ lára fúngbà díẹ̀. Àmọ́, tó o bá ń bínú, tó o sì ń fẹ́ gbẹ̀san, ìyẹn lè nípa lórí bó o ṣe ń hùwà. Ọ̀rọ̀ gidi ni Bíbélì sọ fún wa nígbà tó sọ pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀.”—Sáàmù 37:8.

Mọ ohun tó tọ́. Dípò káwọn ọ̀dọ́ kan kórìíra òbí tó fi wọ́n sílẹ̀ yẹn, wọ́n á ki àṣejù bọ̀ ọ́ nípa fífẹ́ràn ẹ̀ débi pé wọ́n á fẹ́rẹ̀ẹ́ sọ ọ́ di ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́ kan tí dádì ẹ̀ máa ń mutí lámujù, tó máa ń ṣèṣekúṣe, tó máa ń filé sílẹ̀ láìmọye ìgbà, tó sì wá kọ mọ́mì ẹ̀ sílẹ̀ nígbà tó yá rántí pé òun fẹ́rẹ̀ẹ́ lè máa forí balẹ̀ fún dádì òun!

Ohun tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ sì máa ń ṣe nìyẹn. Lórílẹ̀-èdè kan, nǹkan bíi mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá àwọn ọ̀dọ́ táwọn òbí wọn ti kọra wọn sílẹ̀ ló ń gbé lọ́dọ̀ mọ́mì wọn, tó sì jẹ́ pé ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni wọ́n máa ń lọ sọ́dọ̀ dádì wọn. Torí náà, ọrùn màmá wọn ni gbogbo bùkátà ojoojúmọ́ àti títọ́ àwọn ọmọ wọ̀nyẹn wà. Láìka gbogbo owó táwọn màmá wọ̀nyẹn ń rí gbà lóṣooṣù látọ̀dọ̀ ẹni tó kọ̀ wọ́n sílẹ̀ sí, awọ kì í sábàá kájú ìlù fún wọn. Àmọ́ nǹkan sábà máa ń ṣẹnuure fáwọn bàbá ní ti ìṣúnná owó. Ohun tíyẹn wá túmọ̀ sí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ ni pé, tí wọ́n bá lọ sọ́dọ̀ dádì wọn, wọ́n sábà máa ń gbádùn ara wọn. Àmọ́ tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ mọ́mì wọn, òfin ti máa ń pọ̀ jù, wọn ò sì ní lè náwó bó ṣe wù wọ́n. Ó ṣeni láàánú pé, àwọn ọ̀dọ́ kan ti fi òbí wọn tó jẹ́ Kristẹni sílẹ̀, kí wọ́n lè lọ máa gbé lọ́dọ̀ èyí tí kì í ṣe Kristẹni tó lówó lọ́wọ́ tó sì máa fàyè gbà wọ́n láti máa ṣohun tó bá wù wọ́n.—Òwe 19:4.

Bó bá jẹ́ pé ohun tíwọ náà fẹ́ ṣe nìyẹn, ó yẹ kó o rò ó dáadáa, kó o mọ ohun tó o kà sí pàtàkì jù. Má gbàgbé pé o nílò ìtọ́sọ́nà àti ìbáwí. Kò sóhun tí òbí kan lè fún ẹ tó máa dáa tó kí wọ́n tọ́ ẹ sọ́nà kí wọ́n sì bá ẹ wí, torí pé ìyẹn ló máa jẹ́ kó o mọ̀wà hù, káyé ẹ lè dáa. —Òwe 4:13.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 203]

Ọ̀dọ́ tó bá ń dá sí ìjà àwọn òbí ẹ̀ dà bí ẹni tí ò dákan mọ̀ tó lọ ń kọ́ awàkọ òfuurufú bó ṣe máa wakọ̀