Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìyípadà Ara

Ìyípadà Ara

APÁ 2

Ìyípadà Ara

Ǹjẹ́ inú ẹ dùn sí bí ara ẹ ṣe ń yí pa dà?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

Ṣé ọ̀nà tára ẹ gbà ń yí pa dà bó o ṣe ń bàlágà ń mú kó o rò pé o dá yàtọ̀, ṣó ń mú kí nǹkan máa tojú sú ẹ tàbí kẹ́rù máa bà ẹ́?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

Ṣé ọ̀rọ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin ló máa ń gbà ẹ́ lọ́kàn ṣáá?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

Bí ìdáhùn rẹ sí èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè tó wà lókè yìí bá jẹ́ “bẹ́ẹ̀ ni,” ìyẹn ò túmọ̀ sí pé nǹkan kan ń ṣe ẹ́ o! Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, bákan méjì lọ̀rọ̀ ìyípadà tó máa ń wáyé nínú ara àti nínú ọ̀nà téèyàn ń gbà ronú nígbà ìbàlágà. Èèyàn lè kún fáyọ̀, èèyàn sì lè sorí kọ́ tàbí kó tiẹ̀ má mọ bó ṣe ń ṣòun. Lóòótọ́ ni pé wàá fẹ́ dàgbà, àmọ́ ó lè má rọrùn tó bó o ṣe rò tẹ́lẹ̀! Orí 6 sí 8 nínú ìwé yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìyípadà náà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 56, 57]