Bí Mi Ò Bá Fẹ́ràn Bí Mo Ṣe Rí Ńkọ́?
ORÍ 7
Bí Mi Ò Bá Fẹ́ràn Bí Mo Ṣe Rí Ńkọ́?
Ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà lo ò kì í fẹ́ràn bó o ṣe rí?
□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá
Ṣó o ti rò ó rí pé wàá lọ ṣe iṣẹ́ abẹ tó máa ń mú kéèyàn lẹ́wà sí i tàbí pé wàá máa ṣọ́ oúnjẹ jẹ torí bó o ṣe rí?
□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá
Ká ní o lè ṣe é, àwọn nǹkan wo ló máa wù ẹ́ pé kó o yí pa dà lára ẹ? (Fàlà sí èyí tó o bá fẹ́.)
Bí mo ṣe ga sí
Bára mi ṣe rí
Àwọ̀ ara mi
Bí mo ṣe tẹ̀wọ̀n tó
Irun mi
Ohùn mi
BÓ O bá dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè méjì àkọ́kọ́ yẹn, tó o sì fàlà sí nǹkan mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ìbéèrè kẹta, ohun kan wà tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Ó ṣeé ṣe kó máà jẹ́ pé irú ojú tó o fi ń wo ara ẹ yẹn làwọn èèyàn fi ń wò ẹ́. Ó máa ń rọrùn gan-an féèyàn láti máa ronú ju bó ṣe yẹ lọ nípa bóun ṣe rí. Ìwádìí kan tiẹ̀ fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́bìnrin ò bẹ̀rù ogun runlé-rùnnà, àrùn káńsà, tàbí ikú àwọn òbí wọn tó bí wọ́n ṣe ń bẹ̀rù láti sanra!
Kò sí àníàní pé bó o bá ṣe rí lè nípa lórí irú ojú tó o fi ń wo ara ẹ, ìyẹn sì lè nípa lórí báwọn ẹlòmíì á ṣe máa wò ẹ́. Maritza tí kò ju ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] lọ sọ pé: “Nígbà táwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin méjèèjì ń bàlágà, àrímáleèlọ ni wọ́n, àmọ́ ńṣe lèmi sanra jọ̀kọ̀tọ̀. Àwọn ọmọléèwé mi máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ gan-an. Àbúrò mọ́mì mi tún máa ń pè mí ní Chubs [Ọ̀rọ̀bọ̀], ìyẹn orúkọ tí wọ́n fún ajá wọn kúńtá kan tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀!” Ohun tójú Julie tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] rí ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síyẹn, ó ní: “Ọmọbìnrin kan máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ níléèwé wa, ó máa ń pè mí ní ‘eléyín ṣámúgà.’ Bó tiẹ̀ dà bíi pé ìyẹn ò tó nǹkan, inú mi kì í dùn bí mo bá rántí, ojú sì máa ń tì mí títí di báyìí torí béyín mi ṣe rí!”
Má Ṣàníyàn Jù!
Kò burú béèyàn bá jẹ́ kí ìrísí òun jẹ òun lọ́kàn. Bíbélì tiẹ̀ sọ̀rọ̀ tó dáa nípa ìrísí àwọn èèyàn kan, 1 Ọba 1:4.
àwọn bíi Sárà, Rákélì, Jósẹ́fù, Dáfídì àti Ábígẹ́lì. Ó ní, obìnrin kan tó ń jẹ́ Ábíṣágì “lẹ́wà dé góńgó.”—Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ti jẹ́ kí ìrísí wọn gbà wọ́n lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀dọ́bìnrin kan gbà pé èèyàn gbọ́dọ̀ jẹ́ lẹ̀pa, kó tó lè jojú ní gbèsè, ó sì dà bíi pé irú àwòrán tí wọ́n máa ń yà sínú àwọn ìwé ìròyìn tí wọ́n fi ń polówó ọjà náà nìyẹn. Wọ́n ti gbàgbé pé ńṣe ni wọ́n fi kọ̀ǹpútà ṣàlékún ẹwà àwọn àwòrán wọ̀nyẹn àti pé àwọn èèyàn tí wọ́n yà síbẹ̀ yẹn ti ní láti febi para wọn kí ìrísí wọn má bàa yí pa dà! O lè kó ìdààmú ọkàn bára ẹ bó o bá lọ ń fira ẹ wé àwọn tó ò ń rí nínú àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyẹn. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni inú ẹ ò dùn sí bó o ṣe rí ńkọ́? O gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ fojú tó tọ́ wora ẹ ná.
Ṣó O Mọ Bó O Ṣe Rí?
Ṣó o ti wora ẹ nínú dígí tí kò dáa rí? Ó lè mú kó dà bíi pé o tóbi tàbí kéré sí bó o ṣe rí. Dígí yẹn ò lè fi bó o ṣe rí gan-an hàn ẹ́.
Bíi ti dígí tí kò dáa yẹn, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni kò mọ báwọn ṣe rí gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan fi hàn pé nǹkan bí ọ̀dọ́bìnrin mẹ́fà nínú mẹ́wàá ló máa ń sọ pé àwọn ti sanra jù, nígbà tó sì jẹ́ pé méjì nínú wọn ló sanra jù lóòótọ́. Ìwádìí míì fi hàn pé àwọn
ìyàwó ilé bíi márùn-ún nínú mẹ́wàá ló máa ń sọ pé àwọn ti sanra jù nígbà tó sì jẹ́ pé wọn ò sanra rárá!Àwọn kan tó máa ń ṣèwádìí sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó máa ń ṣàníyàn pé àwọn ti sanra jù ni ò yẹ kí wọ́n tiẹ̀ gbé e sọ́kàn rárá. Òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí lè má fi bẹ́ẹ̀ fọkàn ẹ balẹ̀, pàápàá jù lọ, bó o bá ki pọ́pọ́. Àmọ́, kí lo tiẹ̀ rò pé ó fà á ná téèyàn fi ń ki pọ́pọ́?
Àwọn èròjà inú sẹ́ẹ̀lì tó máa ń pinnu bí ara ṣe máa rí lè wà lára ohun tó fà á. Àwọn èèyàn kan lè má fi bẹ́ẹ̀ lára lóòótọ́, àmọ́ báwọn èròjà inú sẹ́ẹ̀lì tó máa pinnu bí ara rẹ ṣe máa rí kì í bá ṣe oríṣi tó máa ń mú kéèyàn pẹ́lẹ́ńgẹ́, a jẹ́ pé o máa tóbi nìyẹn. Ó ṣeé ṣe kó máà tẹ́ ẹ lọ́rùn, kódà báwọn dókítà bá tiẹ̀ sọ fún ẹ pé kò sóun tó ṣe ẹ́. Bó o bá ń ṣeré ìmárale, tó o sì ń ṣọ́ oúnjẹ jẹ, ìyàtọ̀ lè wà díẹ̀, àmọ́ ìyẹn ò ní kára ẹ máà rí bó ṣe yẹ kó rí.
Nǹkan míì tó tún lè fà á ni àwọn ìyípadà tó sábà máa ń wà nígbà téèyàn bá ń bàlágà. Tọ́mọbìnrin bá ń bàlágà àwọn ọ̀rá inú ara ẹ̀ sábà máa ń pọ̀ sí i. Bọ́jọ́ bá sì ṣe ń gorí ọjọ́, ọmọdébìnrin ọlọ́dún mọ́kànlá tàbí méjìlá á wá di ọmọge òrékelẹ́wà. Àmọ́, tó bá jẹ́ torí pé o kì í jẹun tó dáa tàbí pé o kì í ṣeré ìmárale ló fà á ńkọ́? Báwọn ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ bá wà tó o fi fẹ́ dín sísanra kù ńkọ́?
Bó O Ṣe Lè Ṣe É Níwọ̀ntúnwọ̀nsì
Bíbélì tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ ká jẹ́ “oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìwà.” (1 Tím. 3:11) Torí náà, rí i dájú pé ò ń jẹun déédéé, má sì ṣe àṣejù nínú bó o ṣe ń ṣọ́ oúnjẹ jẹ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀nà tó dáa jù tó o lè gbà dín sínsanra kù ni pé kó o ṣètò bó o ṣe lè máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore, kó o sì máa seré ìmárale dáadáa.
Má ṣe bá wọn dáṣà ìgbàlódé tó bá dọ̀rọ̀ ṣíṣọ́ oúnjẹ jẹ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn oògun kan tó máa ń dín sísanra kù lè máà mú kó o jẹun púpọ̀ fúngbà díẹ̀ lóòótọ́, àmọ́ kò ní pẹ́ rárá táwọn oògùn wọ̀nyẹn á fi mọ́ ẹ lára, tébi á sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í pa ẹ́. Ará ẹ sì lè yí pa dà bìrí, kó o wá bẹ̀rẹ̀ sí í sanra pa dà. Yàtọ̀ síyẹn àwọn oògùn wọ̀nyẹn ti fa òòyì, ẹ̀jẹ̀ ríru àti àyà jíjá fáwọn kan tí wọ́n lò ó, ó sì ti mú káwọn míì sọ ọ́ di bárakú. Ohun táwọn oògùn tó máa ń dín omi ara kù tàbí àwọn èyí tó máa ń mú káwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara yára ṣiṣẹ́ máa ń ṣe náà nìyẹn.
Àmọ́ ṣá o, tó o bá ń jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore, tó o sì ń ṣeré ìmárale tí kò pọ̀ jù fún ara ẹ déédéé, wàá rí bó ṣe yẹ kó o rí, ìyẹn á sì jẹ́ kára tù ẹ́. Bó o bá ń ṣeré ìmárale, tó ń mú èémí sunwọ̀n sí i déédéé, ìléra ẹ á túbọ̀ jí pépé. Ìgbà míì wà tí gbogbo ohun tó yẹ kó o ṣe ò ju kó o kàn rìn kánmọ́kánmọ́ fún ìṣẹ́jú bíi mélòó kan tàbí kó o máa gun òkè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì léraléra.
Ṣọ́ra fún Ìṣòro Àìjẹun Kánú!
Àwọn ọ̀dọ́ kan tó ń fẹ́ dín sísanra kù ti sọ ara wọn di ẹni tí kì í jẹun kánú, wọ́n máa ń febi para wọn, ìyẹn sì lè gbẹ̀mí wọn. Masami, tó ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ torí ìṣòro àìjẹun kánú, sọ pé: “Táwọn èèyàn bá ń sọ fún mi pé mo wà, mo máa ń rò ó lọ́kàn ara mi pé, ó ní láti jẹ́ pé mo ti ń sanra nìyẹn o. Ìgbà míì wà tí mo máa ń dá sunkún tí mo sì máa ń rò ó pé ‘Ì bá sàn ká
ní mo lè dín bí mo ṣe sanra kù kí n sì rí bí mo ṣe rí lóṣù mẹ́rin sẹ́yìn!”Ẹlòmíì lè má mọ̀ọ́mọ̀ sọ ara ẹ̀ di ẹni tí kì í jẹun kánú. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan lè yàn láti máa ṣọ oúnjẹ jẹ lọ́nà tí kò fi ní pa á lára, torí kó má bàa sanra jù. Àmọ́, lẹ́yìn tó ti dín sísanra kù lóòótọ́, ìyẹn ò tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó sì tún lè máa sọ nígbà tó bá wora ẹ̀ nínú dígí pé, “Mo ṣì sanra jù kẹ̀!” Láá bá sọ pé àfi kóun túbọ̀ dín bóun ṣe tó kù. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, bí àìjẹun kánú ṣe máa bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.
Bó o bá ń rí àmì pé o kì í jẹun kánú, àfi kó o wá ẹni tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Finú han dádì ẹ, mọ́mì ẹ tàbí àgbàlagbà kan tó o bá fọkàn tán. Òwe inú Bíbélì kan sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.
Bó O Ṣe Lè Mọ Ojúlówó Ẹwà
Bá a bá yẹ Bíbélì wò látòkè délẹ̀, ìwọ̀nba lohun tó sọ nípa ìrísí ara. Àmọ́ ó jẹ́ ká mọ̀ pé irú ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún ló Òwe 11:20, 22.
máa pinnu bóyá a lẹ́wà lójú Ọlọ́run tàbí a ò lẹ́wà.—Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa Ábúsálómù ọmọ Dáfídì Ọba. Ó ní: “Kò sí ọkùnrin kankan tí ó lẹ́wà bí Ábúsálómù tí ó yẹ fún ìyìn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ní gbogbo Ísírẹ́lì. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀, kò sí àbùkù kankan lára rẹ̀.” (2 Sámúẹ́lì 14:25) Àmọ́ elétekéte ni Ábúsálómù. Ìgberaga àti fífẹ́ tó ń fẹ́ ipò ọlá mú kó gbìyànjù láti fipá gba ìjọba lọ́wọ́ ọba tí Jèhófà fúnra rẹ̀ yàn sípò. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì ò fi sọ̀rọ̀ Ábúsálómù ní rere, àmọ́ ó jẹ́ ká mọ̀ pé onínú burúkú, apààyàn àti ọ̀dàlẹ̀ tí ò lójútì ni.
Ju gbogbo ẹ̀ lọ, “ọkàn-àyà” ni Jèhófà ń wò, kì í ṣe bí ìbàdí ọmọbìnrin kan bá ṣe rí tàbí bí igẹ̀ ọmọkùnrin kan ṣe tó. (Òwe 21:2) Torí náà, bó o ti ń fi sọ́kàn pé kò sóhun tó burú nínú kó máa wùùyàn pé kóun ní ìrísí tó dáa, má gbàgbé pé ìwà ẹ ló ṣe pàtàkì jù. Ní paríparì ẹ̀, àwọn ànímọ́ tẹ̀mí máa jẹ́ káwọn èèyàn sún mọ́ ẹ ju bí ìrísí ara ẹ ṣe lè ṣe lọ!
KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 10 NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni àìsàn líle koko tàbí àrùn ń bá fínra. Bó bá jẹ́ pé ohun tó ń ṣe ìwọ náà nìyẹn, báwo lo ṣe lè máa bá a yí?
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Ènìyàn . . . ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.”—1 Sámúẹ́lì 16:7.
ÌMỌ̀RÀN
Bó o bá fẹ́ dín sísanra kù . . .
● Máa jẹun àárọ̀ déédéé. Bó ò bá jẹun àárọ̀, ebi tó máa pa ẹ́ lè mú kó o jẹun ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
● Máa mu omi dáadáa kó o tó jẹun. Omi yẹn máa dín ebi tó ń pa ẹ́ kù, ìyẹn ò sì ní í jẹ́ kó o jẹun jù.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Àwọn ọ̀mọ̀wé kan kìlọ̀ pé tó o bá febi para ẹ torí kó o má bàa sanra, àwọn “ohun tó ṣàjèjì” lè bẹ̀rẹ̀ sí í wáyé nínú ara ẹ, ìyẹn sì lè mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í sanra pa dà!
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Kí n lè ní ìlera tó jí pépé, ohun tí màá ṣe ni pé ․․․․․
Irú àwọn eré ìmárale tí màá máa ṣe ni ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí lo rò nípa bó o ṣe rí?
● Kí làwọn ohun tó bọ́gbọ́n mu tó o lè ṣe kí ìrísí ẹ lè dáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?
● Kí lo máa sọ fún ọ̀rẹ́ ẹ kan tí kì í jẹun déédéé?
● Báwo lo ṣe lè ran àbúrò ẹ lọ́wọ́ láti máa fojú tó tọ́ wo ìrísí rẹ̀?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 69]
Ó pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé ojú mi tóbi. Mo máa ń bá wọn rẹ́rìn-ín nígbà tí wọ́n bá sọ bẹ́ẹ̀, mo sì máa ń fọkàn ara mi balẹ̀ torí mo mọ̀ pé ìwà mi dáa. Mo ti gba kámú pẹ̀lú bí mo ṣe rí. Mi ò sì jiyàn pé mi ò rí bẹ́ẹ̀.’’—Amber
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 68]
O lè máa wo ara ẹ bí ìgbà téèyàn ń wo ara ẹ̀ nínú dígí tí kò dáa