Ọ̀ràn Owó
APÁ 5
Ọ̀ràn Owó
Báwo lowó ti ṣe pàtàkì tó bó o bá fẹ́ máa láyọ̀?
□ Kò ṣe pàtàkì
□ Ó ṣe pàtàkì díẹ̀
□ Kòṣeémánìí ni
Báwo lo ṣe máa ń sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́ tó nípa owó tàbí ohun tó ṣeé fowó rà?
□ Kò wọ́pọ̀
□ Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan
□ Lemọ́lemọ́
Ó ṣeé ṣe káwọn òbí ẹ ti máa tẹ̀ ẹ́ mọ́ ẹ létí gbọnmọgbọnmọ pé owó kì í so lórí igi. Àtàtà ọ̀rọ̀ nìyẹn. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé kó o máa fọgbọ́n náwó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kòṣeémánìí lowó jẹ́, síbẹ̀ ó lè kó ìdààmú ọkàn báni, ó lè ba àárín ọ̀rẹ́ jẹ́, ó sì lè ba àjọṣe ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Dájúdájú, ojú tó o bá fi ń wo owó lè nípa púpọ̀ lórí rẹ. Orí 18 sí 20 nínú ìwé yìí máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè ní èrò tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa owó.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 148, 149]