Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwọn Òbí Mi Ò Bá Lówó Ńkọ́?

Báwọn Òbí Mi Ò Bá Lówó Ńkọ́?

ORÍ 20

Báwọn Òbí Mi Ò Bá Lówó Ńkọ́?

Gregory, Ọ̀dọ́ kan tó ń gbé ní ìlà oòrùn Yúróòpù ò rówó ra àwọn aṣọ àtàwọn nǹkan abánáṣiṣẹ́ táwọn ọ̀dọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè yẹn ń rà. Bó ṣe ń gbé ìgbésí ayé ẹ̀ ti sú u débi pé ó ti fẹ́ kó lọ sí orílẹ̀-èdè Austria. Ṣó o rò pé akúṣẹ̀ẹ́ ni Gregory?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

Abúlé kan ní gúúsù ilẹ̀ Áfíríkà ni ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Loyiso ń gbé ni tiẹ̀. Inú ahéré kan lòun àtàwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ ń gbé, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí Loyiso jowú “ayé ọba” táwọn ọ̀dọ́ tó ń gbé nílùú kan tí ò jìnnà sábúlé wọn ń jẹ, wọ́n ń lo omi yàà, iná mànàmáná ò sì jẹ́ ká mọ ọ̀sán yàtọ̀ sí alẹ́. Ṣé wàá gbà pé akúṣẹ̀ẹ́ ni Loyiso?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Rárá

Ó TI wá hàn gbangba pé ọ̀rọ̀ náà “akúṣẹ̀ẹ́” kì í ṣe ọ̀rọ̀ téèyàn kàn lè sọ pé ohun báyìí ló túmọ̀ sí, torí ẹni tó jẹ́ akúṣẹ̀ẹ́ lórílẹ̀-èdè kan lè jẹ́ olówó lórílẹ̀-èdè míì. Bí àpẹẹrẹ, Gregory lè rò pé ìṣẹ́ ti wọ òun lẹ́wù, àmọ́ tó o bá fi ọ̀rọ̀ Gregory wé ti Loyiso, wàá rí i pé ayé ọba ni Gregory ń jẹ. Kò sí bó o ṣe lè sọ pé o kúṣẹ̀ẹ́ tó, wàá tún ṣọpẹ́ tìẹ tó o bá ráwọn tó tálákà jù ẹ́ lọ. Síbẹ̀, tó ò bá rí aṣọ tó dáa wọ̀ lọ síléèwé, tó ò sì láwọn nǹkan tó yẹ kó o ní, irú bí omi, ó lè má jọ ẹ́ lójú tẹ́nì kan bá sọ fún ẹ pé tìẹ ṣì dáa lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn kan.

Àwọn ọ̀dọ́ kan tó dàgbà sínú ìṣẹ́ máa ń wo ara wọn bí ẹni tí ò já mọ́ nǹkan kan, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń fi ọtí àtàwọn oògùn olóró pàrònú rẹ́. Àmọ́, gbogbo ìsapá wọn láti gbàgbé ipò tí wọ́n wà wulẹ̀ ń mú nǹkan bà jẹ́ sí i ni. Àwọn tó ń mu ọtí lámupara máa ń rí i pé ńṣe ló ń “buni ṣán gẹ́gẹ́ bí ejò, a sì tu oró jáde gẹ́gẹ́ bí paramọ́lẹ̀.” (Òwe 23:32) Maria tó jẹ́ ọmọ òbí anìkàntọ́mọ tí ò lówó lọ́wọ́ ní South Africa, sọ pé: “Ohun téèyàn bá ṣe láti gbàgbé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ wulẹ̀ máa ń fa ìṣòro ni, ìṣòro tó sì ń fà máa ń ju àǹfààní tó ń ṣe lọ.”

O lè má máa mutí ní tìẹ, o tiẹ̀ lè kórìíra oògùn olóró pàápàá, àmọ́ o lè má gbà pé nǹkan á ṣẹnuure fún ẹ. Ibo lo lè wá ìrànlọ́wọ́ lọ? Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì lè dà bíi kọ́kọ́rọ́ tó máa ṣí ẹ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀fìn, tó sì máa jẹ́ kó o hùwà ọmọlúwàbí. Jẹ́ ká wo bí ìyẹn ṣe lè ṣẹlẹ̀.

Ronú Lórí Àwọn Nǹkan Tó O Ní

Ohun kan tó ṣe pàtàkì tó o lè ṣe ni pé kó o máa ronú lórí àwọn nǹkan tó o ní kì í ṣe àwọn nǹkan tó ò ní. Àwọn nǹkan tó o ní, bí ilé àti ìdílé tó nífẹ̀ẹ́ ẹ, níye lórí ju owó èyíkéyìí tó o lè ní lọ! Òwe inú Bíbélì kan sọ pé: ‘Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wà, ó sàn ju àbọ́pa màlúù lọ òun pẹ̀lú ìríra.’ (Òwe 15:17, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni tún ní ohun tó níye lórí gan-an, ìyẹn sì ni ìtìlẹ́yìn “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.”—1 Pétérù 2:17.

Bóyá o tún lè wá máa fi ojú tó tọ̀nà wo ohun ìní tara. Òótọ́ ni pé ó lè jẹ́ pé ilé tí ò jọjú lẹ̀ ń gbé. O lè máa wọ aṣọ tó ti gbó, tó ti fàya, kódà tí wọ́n ti gán pàápàá, oúnjẹ ọ̀sán sì lè máà bá tòwúrọ̀ nínú ẹ. Àmọ́, ṣó o nílò aṣọ olówó ńlá tàbí ilé tó jojú ní gbèsè kó o tó lè múnú Ọlọ́run dùn? Ṣó o nílò oúnjẹ onímindin-mín-ìndìn láti wà láàyè kára ẹ sì le? Kò dájú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì lórí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ yìí. Ó mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ olówó àtohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ akúṣẹ̀ẹ́. (Fílípì 4:12) Wo ibi tó parí èrò sí. Ó ní: “Bí a bá ti ní [oúnjẹ] àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”—1 Tímótì 6:8.

Eldred, ọkùnrin kan tí wọ́n tọ́ dàgbà ní ìdílé akúṣẹ̀ẹ́ kan lórílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Gbogbo wa kàn ṣáà gbà pé nǹkan ò ṣẹnuure fún wa àti pé gbogbo nǹkan tá a bá fẹ́ kọ́ la máa rí.” Eldred rántí pé nígbà tí ṣòkòtò aṣọ iléèwé òun ya, ńṣe ni màmá òun kàn ń gán an pọ̀ ṣáá! Ó ní: “Mo ní láti fara da èébú díẹ̀. Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé aṣọ wa máa ń mọ́, ó sì wúlò fún nǹkan tá a wọ̀ ọ́ fún.”

Fọ̀wọ̀ Wọ Ara Ẹ

Ọmọ ọdún mọ́kànlá kan tó ń jẹ́ James ń gbé pẹ̀lú màmá ẹ̀ àti àbúrò ẹ̀ obìnrin nínú àwọn ilé àbẹ̀rẹ̀wọ̀ táwọn èèyàn kọ́ síbi tí ìjọba ò fọwọ́ sí nílùú Johannesburg, lórílẹ̀-èdè South Africa. Bá a bá ní ká tibi nǹkan ìní wò ó, wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ máà ní nǹkan kan. Àmọ́, James ṣì ní ohun kan, ìyẹn àkókò àti okun rẹ̀, ó sì fìyẹn ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀, James máa ń yọ̀ọ̀da ara ẹ̀ láti lọ ràn wọ́n lọ́wọ́ níbi tí wọ́n ti ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kì í ṣe pé iṣẹ́ yìí wulẹ̀ jẹ́ kó máa lo àkókò tí ò bá fi máa ronú lọ́nà tó wúlò nìkan ni, àmọ́ ó tún jẹ́ kó lè ṣiṣẹ́ kan tó nítumọ̀, ìyẹn ò sì jẹ́ kó rora ẹ̀ pin. Ó sọ pé: “Lẹ́yìn iṣẹ́ kíkọ́ gbọ̀ngàn lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, ọkàn mi máa ń balẹ̀ pé mo ti ṣe ohun tó yẹ kí n ṣe!”

Iṣẹ́ míì tó ń méso wá ni iṣẹ́ wíwàásù láti ilé dé ilé láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Mátíù 24:14) Àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe iṣẹ́ yìí déédéé. Bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ yìí, ńṣe ni wọ́n ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, wọ́n sì túbọ̀ ń fi kún iyì ara wọn. Òótọ́ ni pé wọn kì í pawó látinú iṣẹ́ yìí. Àmọ́, rántí iṣẹ́ tí Jésù rán sáwọn ará tó wà ní ìjọ Símínà ìgbàanì. Wọ́n kúṣẹ̀ẹ́ nípa tara, àmọ́ nítorí pé wọ́n ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run, Jésù sọ fún wọn pé: “Mo mọ ìpọ́njú àti ipò òṣì [yín]—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni [yín].” Bó bá tó àkókò, wọ́n máa gba ohun tó níye lórí jù lọ, ìyẹn adé ìyè, torí pé wọ́n fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà tí Jésù fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe.—Ìṣípayá 2:9, 10.

Ọjọ́ Ọ̀la Ni Kó O Máa Wò

Yálà olówó ni ẹ́ tàbí tálákà, o lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́rọ̀ àti aláìnílọ́wọ́ ti pàdé ara wọn. Olùṣẹ̀dá gbogbo wọn ni Jèhófà.” (Òwe 22:2) Òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí ti ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ láti fara da ìṣẹ́. Wọ́n mọ̀ pé kíkó ohun ìní jọ kọ́ ló ń fún èèyàn láyọ̀ bí kò ṣe bíbá Jèhófà Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́, torí pé gbogbo àwọn tó bá ṣáà ti fẹ́ sìn ín ló ń gbà wọlé. Ọlọ́run ṣèlérí ọjọ́ ọ̀la nínú ayé tuntun níbi tí òṣì ò ti ní ta àwọn èèyàn mọ́.—2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4.

Ní báyìí ná, ṣáà máa fọgbọ́n lo àwọn ohun tó o ní. Má sọ̀rètí nù. Kó àwọn ìṣúra tẹ̀mí jọ fún ara rẹ. (Mátíù 6:19-21) Wo àìlówó lọ́wọ́ bí ìsòro tó o lè kojú!

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.Lúùkù 12:15.

ÌMỌ̀RÀN

Má ta tẹ́tẹ́, má mu sìgá, má sì sọ ọtí mímu dàṣà. Bá a bá sì rí lára àwọn ará ilé ẹ tó ń ṣàwọn nǹkan wọ̀nyí, fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wọn.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Bó ò tiẹ̀ lówó lọ́wọ́, fífàwọn ìlànà Bíbélì sílò lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ̀wọ̀n ara ẹ.—Fílípì 4:12, 13; 1 Tímótì 6:8; Hébérù 13:5.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Àwọn ohun tí mo ní ni ․․․․․

Màá fàwọn nǹkan tí mo ní ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ nípa ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “akúṣẹ̀ẹ́” fi yàtọ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn?

● Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti máa lo oògùn olóró, láti máa mutí tàbí láti máa ṣàwọn nǹkan míì láti fi pàrònú rẹ́?

● Kí lo lè ṣe láti fara da ipò òṣì?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 168]

“Òótọ́ ni pé mi ò rọ́nà àbáyọ nínú ipò òṣì tí mo bára mi, àmọ́ mo rí i pé kíkó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ tàbí jíjalè ò lè yanjú ẹ̀. Lónìí, púpọ̀ lára àwọn tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ tí wọ́n ti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn layé ti sú, ọtí àti oògùn olóró ti sọ àwọn kan dìdàkudà, àwọn míì sì ti wà lẹ́wọ̀n.”—George

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 164]

Tí mo kọ èrò mi sí

Ṣé Kí N Kó Lọ Sókè Òkun?

Àwọn ọ̀dọ́ kan fẹ́ kó lọ sókè òkun, bóyá kí wọ́n lè rí towó ṣe tàbí kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà àwọn ará ilé wọn. Àwọn míì máa ń kó lọ láti kọ́ èdè àjèjì, láti lọ kàwé sí i, tàbí torí pé wọ́n fẹ́ sá fún ìṣòro tí wọ́n ń dojú kọ nílé. Àwọn ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ Kristẹni sì ti ṣí lọ sáwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Ìpinnu ńlá ni láti kó lọ sí orílẹ̀ èdè míì, èèyàn sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú un. Torí náà, bó o bá ti ń ronú láti ṣí lọ sílẹ̀ òkèrè, ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tò sísàlẹ̀ yìí, kó o sì ronú lé wọn lórí dáadáa. Bi ara ẹ láwọn ìbéèrè tá a kọ síbẹ̀, kó o sì kọ àwọn ìdáhùn rẹ sórí ìwé kan. Lẹ́yìn náà ṣèpinnu rẹ tàdúràtàdúrà.

□ Kí ni òfin ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó bá fẹ́ ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè yẹn?—Róòmù 13:1.

□ Èló ló máa ná mi láti ṣí lọ sókè òkun?—Lúùkù 4:28.

□ Iṣẹ́ wo ló wà lọ́wọ́ mi báyìí tó fi dá mi lójú pé màá lè gbọ́ bùkátà ara mi tí mo bá dókè òkun?—Òwe 13:4.

□ Ìmọ̀ràn wo ni mo ti gbà látọ̀dọ̀ àwọn àgbàlagbà tó ti gbé lókè okùn rí?—Òwe 1:5.

□ Kí ni Dádì àti Mọ́mì sọ sí i?—Òwe 23:22.

□ Kí nìdí tí mo fi fẹ́ lọ sókè òkun?—Gálátíà 6:7, 8.

□ Bó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwọn kan ni mo máa gbé tí mo bá dọ́hùn-ún, ṣé wọ́n á lè máa gbà mí nímọ̀ràn tó bá dọ̀ràn ìjọsìn Ọlọ́run?—Òwe 13:20.

□ Àwọn ewu nípa tara, nípa tẹ̀mí tàbí ti ìwà híhù wo tó lè ba àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ni mo lè dojú kọ?—Òwe 5:3, 4; 27:12; 1 Tímótì 6:9, 10.

□ Ká sòótọ́, àǹfààní wo ni mo máa rí gbà tí mo bá ṣí lọ sókè òkun?—Òwe 14:15.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 167]

Ìmọ̀ràn Bíbélì lè dà bíi kọ́kọ́rọ́ tó máa ṣí ẹ sílẹ̀ kúrò nínú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ àìbalẹ̀ ọkàn