Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Owó Ná?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Owó Ná?

ORÍ 19

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Owó Ná?

Báwo ló ṣe máa ń ṣe ẹ́ tó pé owó ọwọ́ ẹ ò tó ẹ ná?

□ Kò ṣẹlẹ̀ rí

□ Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan

□ Gbogbo ìgbà

Báwo lo ṣe máa ń ra àwọn nǹkan tówó ẹ ò ká tó?

□ Kò ṣẹlẹ̀ rí

□ Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan

□ Gbogbo ìgbà

Báwo lo ṣe máa ń ra ohun tó ò nílò tó kìkì nítorí pé o ti rí i lọ́jà?

□ Kò ṣẹlẹ̀ rí

□ Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan

□ Gbogbo ìgbà

ṢÓ O máa ń rò pé owó kì í tó ẹ ná? Ká ló o rówó díẹ̀ sí i ni, o ò bá ra fóònù alágbèéká tó wù ẹ́ yẹn. Ká ní owó oṣù ẹ pọ̀ jùyẹn lọ ni, o ò bá ra bàtà tó o rò pé o nílò yẹn. Ó sì lè jẹ́ pé bíi ti Joan lọ̀rọ̀ tìẹ náà rí, ó sọ pé: “Nígbà míì, àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń fẹ́ ká jọ ra àwọn nǹkan tó wọ́n. Ó sì máa ń wù mí kémi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi jọ máa gbádùn ara wa. Kò sẹ́ni tá á fẹ́ sọ pé, ‘Ẹ jọ̀ọ́, mi ò ní lè báa yín jáde.’”

Dípò kó o jẹ́ kí àìlówó tó tó ẹ ná máa dà ẹ́ láàmú, o ò ṣe kọ́ bó o ṣe lè máa ṣọ́ ìwọ̀nba owó tó bá ń wọlé fún ẹ ná? O lè ló o fẹ́ dúró dìgbà tó o bá ń dá gbé kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ́ owó ná. Àmọ́, rò ó wò ná, ṣé wàá kọ́kọ́ bẹ́ sómi kó o tó mọ̀wẹ̀? Lóòótọ́, ẹni tó bẹ́ sómi láìmọ̀wẹ̀ rọ́gbọ́n ta sí i o. Àmọ́, báwo ni ì bá ti dáa tó bó bá kọ́kọ́ kọ́ béèyàn ṣe ń lúwẹ̀ẹ́ kó tó bẹ́ sómi!

Bákan náà, ìgbà tó o ṣì wà lábẹ́ àwọn òbí ẹ, tí wàhálà àtirówó gbọ́ bùkátà ò tíì máa fẹjú mọ́ ẹ, ló dáa jù lọ fún ẹ láti kọ́ béèyàn ṣe ń ṣọ́ owó ná. Sólómọ́nì Ọba kọ̀wé pé: “Owó . . . jẹ́ fún ìdáàbòbò.” (Oníwàásù 7:12) Àmọ́, ó dìgbà tó o bá kọ́ bó o ṣe lè máa ṣọ́ owó ná kówó tó lè máa dáàbò bò ẹ́. Èyí á jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé wàá mowó ná, á sì jẹ́ káwọn òbí ẹ túbọ̀ fọkàn tán ẹ.

Kọ́ Bó O Ṣe Lè Máa Dá Gbé Bùkátà

Ṣó o ti sọ fáwọn òbí ẹ rí pé kí wọ́n ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ń gbọ́ bùkátà ìdílé yín fún ẹ? Bí àpẹẹrẹ, ṣó o mọ iye tí wọ́n ń ná sórí iná àti omi lóṣooṣù tó fi mọ́ iye tí wọ́n ń ná sórí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, iye tí wọ́n fi ń ra oúnjẹ àti iye owó ilé tàbí ẹ̀yáwó tí wọ́n ń san pa dà fún báńkì? Má gbàgbé pé gbogbo yín lẹ jọ jẹ gbèsè yẹn o, bó o bá sì bẹ̀rẹ̀ sí í dá gbé, ìwọ náà á bẹ̀rẹ̀ sí í náwó lé àwọn nǹkan wọ̀nyẹn lórí. Torí náà, ó yẹ kó o mọ bí owó tí wàá máa ná ṣe máa pọ̀ tó bó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í dá gbé. Sọ fáwọn òbí ẹ pé kí wọ́n jẹ́ kó o rí díẹ̀ lára àwọn ìwé owó náà, kó o sì tẹ́tí sí wọn dáadáa bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé owó tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fáwọn ìnáwó náà.

Òwe inú Bíbélì kan sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i, ẹni òye sì ni ènìyàn tí ó ní ìdarí jíjáfáfá.” (Òwe 1:5) Anna béèrè fún irú ìdarí jíjáfáfá bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn òbí ẹ̀. Ó sọ pé: “Dádì mi kọ́ mi béèyàn ṣe ń ya owó tó máa ná sórí oríṣiríṣi nǹkan sọ́tọ̀, wọ́n sì jẹ́ kí n rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn wà létòlétò nípa bó ṣe ń ná owó tó jẹ́ ti ìdílé.”

Màmá Anna náà ò gbẹ́yìn, ó kọ́ ọ láwọn ẹ̀kọ́ mìíràn tó gbámúṣé. Anna sọ pé: “Mọ́mì jẹ́ kí n rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa nájà wò ní ọ̀nà méjì mẹ́ta. Bọ́wọ́ Mọ́mì bá tẹ owó kékeré, wọ́n lè fi ra nǹkan tó pọ̀.” Ẹ̀kọ́ wo ni Anna rí kọ́ nínú èyí? Ó sọ pé: “Ó ti wá ṣeé ṣe fún mi báyìí láti máa gbọ́ bùkátà ara mi. Mo máa ń náwó tìṣọ́ratìṣọ́ra, nítorí náà ọkàn mi máa ń balẹ̀ pé mi ò ní kó sí gbèsè.”

Mọ̀ Pé Kò Rọrùn Láti Ṣọ́ Owó Ná

Ibi tọ́rọ̀ wá wà ni pé ṣíṣọ́ owó ná dùn-ún sọ lẹ́nu, àmọ́ ó ṣòroó ṣe, pàápàá jù lọ bó ò bá tíì máa dá gbé, tó sì jẹ́ pé àwọn òbí ẹ ń fún ẹ lówó tàbí tó ò ń rówó láti ibi iṣẹ́ kan. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn òbí ẹ ló ń san ọ̀pọ̀ lára owó tẹ́ ẹ bá ná. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó o máa ná èyí tó pọ̀ jù lára owó tó ń wọlé fún ẹ bó o bá ṣe fẹ́. Owó sì máa ń dùn ún ná o jàre.

Ibi tọ́rọ̀ náà wá burú sí ni pé àwọn ojúgbà ẹ lè máa yọ ẹ́ lẹ́nu pé kó o náwó kọjá agbára ẹ. Ellena, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21], sọ pé: “Láàárín àwọn ojúgbà mi, ká máa ra tibí ra tọ̀hún ti di eré ìnàjú pàtàkì. Bá a bá jọ jáde báyìí, ṣe ló máa ń dà bíi pé bá ò bá tíì náwó, a ò lè gbádùn ara wa.”

Kò sí ẹ̀dá tí kì í wù pé kóun àtàwọn ọ̀rẹ́ òun jọ gba tara àwọn. Ṣùgbọ́n, bi ara ẹ pé, ‘Ṣé ohun tó ń mú kí èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi jọ máa náwó ni pé agbára mi gbé e àbí mo ronú pé mo gbọ́dọ̀ náwó?’ Torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ máa gbayì lójú àwọn ọ̀rẹ́ àti alábàákẹ́gbẹ́ wọn ni wọ́n ṣe ń náwó. Wọ́n máa ń fẹ́ láti fi ohun tí wọ́n ní ṣe fọ́rífọ́rí fáwọn ẹlòmíì dípò kí wọ́n jẹ́ kí wọ́n mọyì àwọn ànímọ́ rere táwọn ní. Bó o bá ń ronú báyìí, o ò ní pẹ́ kó sí gbèsè, àgàgà tó o bá tún wá lọ ní káàdì ìrajà. Kí lo wá lè ṣe tó ò fi ní kó sí gbèsè?

Kọ́ Béèyàn Ṣe Ń Ṣọ́ Owó Ná

Dípò tí wàá fi máa ná gbogbo owó tó bá wà nínú káàdì ìrajà ẹ tàbí tí wàá fi ná gbogbo owó oṣù ẹ tán láàárín ọjọ́ kan ṣoṣo, o ò ṣe gbìyànjú láti ṣe bíi ti Ellena? Ó sọ pé: “Bí mo bá báwọn ọ̀rẹ́ mi lọ sóde, màá ti mọ̀ nínú ara mi pé mi ò ní ná ju iye pàtó kan lọ. Tààràtà lowó oṣù mi máa ń kọjá lọ sí báńkì, iye tí mo bá máa ná lóde tá à ń lọ ni mo sì máa ń mú dání. Mo tún rí i pé ó bọ́gbọ́n mu láti máa lọ sọ́jà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi tí kì í náwó nínàákúnàá, àwọn tó máa gbà mí níyànjú pé kí n nájà káàkiri, kí n má sì ra ohun tí mo bá kọ́kọ́ rí.”

Àwọn àbá díẹ̀ mìíràn rèé tó o lè fi sílò bó o bá ní káàdì ìrajà.

● Máa ṣàkọsílẹ̀ gbogbo ohun tó o bá ń rà kó o sì máa fi wọ́n wéra pẹ̀lú àkọsílẹ̀ ọjà oṣooṣù láti rí i pé wọn ò yọ owó ọjà tó ò rà.

● Má ṣe fi sísan gbèsè orí káàdì ìrajà rẹ falẹ̀. Bó bá ṣeé ṣe pàápàá, ṣe ni kó o san án tán.

● Má ṣe fi nọ́ńbà káàdì ìrajà rẹ tàbí déètì ìgbà tí kò ní wúlò mọ́ ránṣẹ́ sí ẹnikẹ́ni lórí fóònù tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

● Má ṣe máa lo káàdì ìrajà rẹ láti gba owó fún ìlò pàjáwìrì, torí èlé orí irú owó àgbàsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń pọ̀ gan-an.

● Má ṣe yá ẹnikẹ́ni, tó fi mọ́ ọ̀rẹ́ rẹ, ní káàdì ìrajà rẹ.

Bówó tó ń wọlé sí ẹ lọ́wọ́ bá pọ̀ sí i, ṣéyẹn ò lè tán ìṣòro owó tó o ní ni? Bóyá ni! Àpèjúwe kan rèé: Bó o bá ń wakọ̀, tí ọkọ̀ náà sì ń yà bàrà sọ́tùn-ún sósì mọ́ ẹ lọ́wọ́, tàbí tó jẹ́ pé ńṣe lo máa ń dijú wakọ̀, ṣé ọ̀nà tó o lè gbà débi tó ò ń lọ láyọ̀ ni pé kó o túbọ̀ rọ epo sínú mọ́tò rẹ? Bọ́rọ̀ owó níná náà ṣe rí nìyẹn. Bó ò bá kọ́ béèyàn ṣe máa ń ṣọ́ owó ná, àníkún owó ò lè tán ìṣòro rẹ.

Bóyá o sì lérò pé o ti mọ bó o ṣe lè máa ṣọ́ owó ná. Àmọ́, bí ara ẹ pé: ‘Èló ni mo ná lóṣù tó kọjá? Kí ni mo náwó ọ̀hún lé lórí?’ O ò lè sọ, àbí? Ó dáa, ọgbọ́n tó o lè dá rèé tí wàá fi máa ṣọ́ bó o ṣe ń náwó kó tó di pé o di onínàákúnàá.

1. Máa kọ àkọsílẹ̀. Ó kéré tán, láàárín oṣù kan, máa kọ àkọsílẹ̀ iye owó tó ń wọlé fún ẹ àti ọjọ́ tó o rí owó náà gbà. Kọ ohun tó o bá rà àti iye tó o fi rà á sílẹ̀ níkọ̀ọ̀kan. Níparí oṣù yẹn, ṣe àròpọ̀ gbogbo owó tó wọlé fún ẹ àti iye owó tó o ná.

2. Ṣètò bí wàá ṣe máa náwó ẹ. Wo  àtẹ tó wà lójú ìwé 163. Kọ gbogbo owó tó o retí pé kó wọlé fún ẹ lóṣù sínú òpó ìlà àkọ́kọ́. Nínú òpó ìlà kejì, ṣe àkọsílẹ̀ bó o ṣe fẹ́ ná owó ẹ síbẹ̀; o lè tẹ̀ lé àwọn ohun tó wà nínú àkọsílẹ̀ tó o kọ́kọ́ kọ gẹ́gẹ́ bá a ṣe dábàá ẹ̀ nínú ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́. Bí oṣù yẹn ti ń lọ, wá kọ iye owó tó o ná gan-an sórí àwọn ohun tó o ti wéwèé láti rà sínú òpó ìlà kẹta. Tún kọ gbogbo owó tó o ná láìròtẹ́lẹ̀ síbẹ̀.

3. Ṣe ìyípadà tó bá yẹ. Bó o bá ń ná ju iye tó o rò tẹ́lẹ̀ lọ sórí àwọn nǹkan tó o rà tí gbèsè sì ṣẹ́ jọ sí ẹ lọ́rùn, ṣe ìyípadà tó bá yẹ. San gbèsè tó wà lọ́rùn ẹ. Máa ṣọ́ bó o ṣe ń náwó.

Kòṣeémáàní lowó bá a bá lò ó lọ́nà tó yẹ. Kódà, ọ̀pọ̀ èèyàn tiẹ̀ gbà pé ṣíṣe iṣẹ́ owó àti ṣíṣọ́ owó ná jẹ́ àpá pàtàkì nínú ìgbé ayé ẹ̀dá. Àmọ́, ṣe ohun gbogbo níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Matthew sọ pé: “Owó ní àyè tiẹ̀, àmọ́ owó kọ́ lohun gbogbo. Owó ò gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì ju ìdílé wà tàbí Jèhófà lọ.”

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣé tálákà làwọn òbí ẹ? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe sí i?

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Owó . . . jẹ́ fún ìdáàbòbò; ṣùgbọ́n àǹfààní ìmọ̀ ni pé ọgbọ́n máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.Oníwàásù 7:12.

ÌMỌ̀RÀN

Ṣe àkọsílẹ̀ ohun tó o máa rà kó o tó lọ sọ́jà. Ìwọ̀nba owó tó o nílò ni kó o mú dání lọ, má sì ṣe rà kọjá ohun tó o kọ sílẹ̀.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Bó o bá jẹ gbèsè ₦200,000, tó o sì ní láti máa san ₦1,400 àti èlé orí ẹ̀ tó jẹ́ ₦100 padà lóṣooṣù, odindi ọdún mọ́kànlá lo máa fi san gbèsè yẹn, àròpọ̀ èlé orí ẹ̀ lásán sì máa tó ₦13,200.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Mo lè máa dín iye tí mò ń ná kù nípa ․․․․․

Kí n tó ra nǹkan láwìn màá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tó fi yẹ kó o mọ béèyàn ṣe ń fọgbọ́n náwó nígbà tó o ṣì ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí ẹ?

● Kí nìdí tó fi lè ṣòro fún ẹ láti máa fọgbọ́n náwó ẹ?

● Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà máa fi owó ẹ ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 162]

“Bí mo bá fètò sí bí màá ṣe máa náwó, owó máa ń dúró sí mi lọ́wọ́. Mi kì í ra ohun tí mi ò bá nílò.”—Leah

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 158]

Owó Lè Sọrú Ẹni Téèyàn Jẹ́

Kí lo máa ń fowó ẹ ṣe? Bó o bá sábà máa ń fowó ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, a jẹ́ pé o fẹ́ràn wọn dénú nìyẹn. (Jákọ́bù 2:14-17) Bó o bá sì ń fowó sínú àpótí ọrẹ déédéé láti ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn, ò ń “fi àwọn ohun ìní rẹ tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà” nìyẹn. (Òwe 3:9) Àmọ́, bó bá jẹ́ pé orí ohun tó wù ẹ́ àti ohun tó o nílò nìkan lo máa ń náwó lé nígbà gbogbo, kí lowó tó o ní ń sọ nípa irú ẹni tó o jẹ́?

[Àtẹ/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 163]

 Tí mo kọ èrò mi sí

Ètò Ìnáwó Mi Lóṣooṣù

Ṣe ẹ̀dà ojú ìwé yìí!

Owó Tó Ń Wọlé

OWÓ TÁWỌN ÒBÍ MI Ń FÚN MI

IṢẸ́ ÀFIPAWỌ́

ÀWỌN NǸKAN MÍÌ

Àròpọ̀

$․․․․․

Iye Tí Mo Fẹ́ Ná

OÚNJẸ

․․․․․

AṢỌ

․․․․․

FÓÒNÙ

․․․․․

ERÉ ÌNÀJÚ

․․․․․

ỌRẸ

․․․․․

OWÓ TÍ MÒ Ń TỌ́JÚ

․․․․․

ÀWỌN NǸKAN MÍÌ

․․․․․

Àròpọ̀

$․․․․․

Iye Tí Mo Ná

OÚNJẸ

․․․․․

AṢỌ

․․․․․

FÓÒNÙ

․․․․․

ERÉ ÌNÀJÚ

․․․․․

ỌRẸ

․․․․․

OWÓ TÍ MÒ Ń TỌ́JÚ

․․․․․

ÀWỌN NǸKAN MÍÌ

․․․․․

Àròpọ̀

$․․․․․

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 160]

Ẹní bá ń náwó nínàákúnàá dà bí ẹni tó ń dijú wakọ̀