Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ọkùnrin Àti Obìnrin

Ọ̀rọ̀ Ọkùnrin Àti Obìnrin

APÁ 1

Ọ̀rọ̀ Ọkùnrin Àti Obìnrin

Ò ń wo ọmọkùnrin kan àti ọmọbìnrin kan tí wọ́n dira wọn mú tí wọ́n jọ ń rìn lọ nígbà tẹ́ ẹ parí iṣẹ́ kan níléèwé. Báwo ló ṣe rí lára ẹ?

□ Mi ò rí tiwọn rò

□ Mo jowú díẹ̀

□ Ó dà bíi kó jẹ́ èmi

Ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ wà níbi tẹ́ ẹ ti ń wo fíìmù, lo bá dédé rí i pé àwọn ọkùnrin àárín yín ti mú àwọn obìnrin tẹ́ ẹ jọ lọ níkọ̀ọ̀kan, ìwọ nìkan ló ṣẹ́ kù! Báwo ló ṣe rí lára ẹ?

□ Kò ṣe mí bákan

□ Ó ká mi lára díẹ̀

□ Mo jowú gan-an

Ọ̀rẹ́ ẹ tímọ́tímọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gba ti ẹnì kan láìpẹ́ yìí, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra wọn báyìí. Báwo ló ṣe rí lára ẹ?

□ Inú mi dùn sí i

□ Mo jowú díẹ̀

□ Ó bí mi nínú

Ọkùnrin àti obìnrin, obìnrin àti ọkùnrin. Kò síbi tó o yíjú sí tó ò rí wọn, ì báà ṣe níléèwé, lójú pópó àti láwọn ibi ìtajà. Ní gbogbo ìgbà tó o bá rí wọn, á dà bíi pé kó o yan àwọn kan lára wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Àmọ́, ṣó o ti ṣe tán láti wá ẹni tó o máa fẹ́? Bó o bá ti ṣe tán, báwo lo ṣe lè rẹ́ni tíwọ àti ẹ̀ á jọ mọwọ́ ara yín? Bó o bá sì wá rírú ẹni bẹ́ẹ̀, báwo lẹ ò ṣe ní ṣèṣekúṣe ní gbogbo ìgbà tẹ́ ẹ bá fi ń fẹ́ra yín sọ́nà? Wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn ní Orí 1 sí 5 nínú ìwé yìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]