Ṣó Ti Yẹ Kí N Lẹ́ni Tí Mò Ń Fẹ́?
ORÍ 1
Ṣó Ti Yẹ Kí N Lẹ́ni Tí Mò Ń Fẹ́?
“Kò síbi tí mo yíjú sí tí mi ò ti ń rí àwọn nǹkan tó ń jẹ́ kó máa wù mí ṣáá láti lẹ́ni tí mò ń fẹ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ọmọkùnrin tó dáa pọ̀ bí ilẹ̀ bí ẹní.”—Whitney.
“Àwọn ọmọbìnrin kì í fi mí lọ́rùn sílẹ̀, mi ò sì fẹ́ sọ pé mi ò ṣe. Àmọ́ tí mo bá bi àwọn òbí mi pé kí ni wọ́n rí sí i, mo mọ nǹkan tí wọ́n máa sọ.”—Phillip.
Ó SÁBÀ máa ń wùùyàn láti ní olólùfẹ́, kódà nígbà téèyàn wà ní kékeré. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Jenifer sọ pé: “Mi ò tíì ju ọmọ ọdún mọ́kànlá lọ tó ti ń wù mí pé kí n lẹ́ni tí mò ń fẹ́.” Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Brittany náà sọ pé: “Bó o bá wà níléèwé, tí o ò sì lẹ́ni tó ò ń fẹ́, ńṣe ló máa dà bíi pé o ò dákan mọ̀!”
Ṣé bó ṣe ń ṣe ìwọ náà nìyẹn? Ṣó yẹ kó o ti lẹ́ni tí wàá máa
fẹ́? Ká tó lè dáhùn ìbéèrè yìí, ó yẹ ká kọ́kọ́ dáhùn ìbéèrè kan tó ṣe pàtàkì jù:Kí Ni “Ìfẹ́sọ́nà”?
Fàmì sí ohun tó o rò pé ó yẹ kó jẹ́ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí:
Bí ìgbín bá fà ìkarahun a tẹ̀ lé e lọ̀rọ̀ ìwọ àti ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin kan. Ṣé ẹ ti ń fẹ́ra yín sọ́nà nìyẹn?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Ìwọ àti ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin kan nífẹ̀ẹ́ ara yín gan-an, ọ̀pọ̀ ìgbà lójúmọ́ lo sì máa ń kọ̀wé ránṣẹ́ sórí fóònù ẹ̀ tàbí kó o fi fóònù pè é. Ṣẹ́ ẹ ti ń fẹ́ra yín sọ́nà nìyẹn?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìgbà tíwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá ń ṣe fàájì, ó ní bọ̀bọ́ kan tàbí ọmọge kan tíwọ àti ẹ̀ sábà máa ń dá sọ̀rọ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Ṣẹ́ ẹ ti ń fẹ́ra yín sọ́nà nìyẹn?
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
Ó lè má ṣòro fún ẹ láti dáhùn ìbéèrè àkọ́kọ́. Àmọ́ o ti ní láti ronú díẹ̀ lórí ìbéèrè kejì àti ìkẹta kó o tó lè dáhùn wọn. Kí ni ìfẹ́sọ́nà gan-an? Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ́, bí ohunkóhun bá ti ń pa ìwọ àti ẹnì kan pọ̀, tọ́kàn rẹ ń fà sí onítọ̀hún, tónítọ̀hún náà sì nífẹ̀ẹ́ rẹ dọ́kàn, ẹ ti ń fẹ́ra yín sọ́nà nìyẹn. Èyí fi hàn pé bẹ́ẹ̀ ni ni ìdáhùn tó tọ̀nà sáwọn ìbéèrè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Yálà lórí fóònù tàbí lójúkojú, lójú táyé tàbí ní bòókẹ́lẹ́, tíwọ àti ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin kan bá ṣáà ti lè ní ìfẹ́ tó ju ti ọ̀rẹ́ lásán lọ síra yín, tẹ́ ẹ sì ń bára yín sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, a jẹ́ pé ẹ ti ń fẹ́ra yín sọ́nà nìyẹn. Ṣó o wá rò pé o ti ṣe tán láti bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ ẹnì kan sọ́nà báyìí? Bó o bá gbé àwọn ìbéèrè mẹ́ta tá a máa jíròrò báyìí yẹ̀ wò, wàá lè dáhùn ìbéèrè yẹn.
Kí Nìdí Tó O Fi Fẹ́ Lẹ́ni Tí Wàá Fẹ́?
Ọ̀pọ̀ èèyàn làṣà ìlú wọn fàyè gba kí ọkùnrin àti obìnrin máa fẹ́ra wọn sọ́nà, torí pé ọ̀nà táwọn méjèèjì lè gbà mọwọ́ ara wọn nìyẹn. Àmọ́, ó yẹ kó nídìí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí ọkùnrin àti obìnrin á fi
máa fẹ́ra wọn sọ́nà, ìyẹn sì ni láti mọ̀ bóyá àwọn méjèèjì á lè bára wọn kalẹ́ bí wọ́n bá gbéra wọn níyàwó.Òótọ́ ni pé, àwọn ọ̀dọ́ kan ò ka fífẹ́ ara wọn sọ́nà sí nǹkan bàbàrà. Bóyá ńṣe ló kàn máa ń wù wọ́n láti máa wà lọ́dọ̀ ẹnì kan tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn, àmọ́ tí kò sí lọ́kàn wọn láti fẹ́ onítọ̀hún. Àwọn kan tiẹ̀ lè máa wo wíwà pẹ̀lú ọ̀rẹ́bìnrin tàbí ọ̀rẹ́kùnrin tí wọ́n fẹ́ láti máa wà lọ́dọ̀ ẹ̀ yẹn bí àpẹẹrẹ pé àwọn náà ti tẹ́gbẹ́, tàbí bí ohun tó ń mú káwọn máa gbayì láwùjọ. Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà irú yíyan ara ẹni lọ́rẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ kì í tọ́jọ́. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Heather sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀dọ́ tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ló ń fira wọn sílẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ kan sí méjì tí wọ́n pàdé ara wọn. Wọ́n ti sọ àjọṣe tó wà láàárín wọn di ọsàn téèyàn lè mu kó sì sọ nù bí kò bá wù ú mu mọ́, ìyẹn sì ti jẹ́ kí wọ́n máa fi ìkọ̀sílẹ̀ kọ́ra dípò ìgbéyàwó.”
Kò sí àníàní pé bó o bá ti ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà, o ti ń nípa lórí bí nǹkan ṣe ń rí lára onítọ̀hún. Nítorí náà, rí i dájú pé o nídìí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó mú kó o máa fẹ́ ẹ sọ́nà. Rò ó wò ná: Ṣé wàá fẹ́ kẹ́nì kan sọ ìmọ̀lára ẹ di ìṣeré ọmọdé, téèyàn lè fi ṣeré fúngbà díẹ̀ kó sì wá gbé e sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan tó bá yá? Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Chelsea sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà mo máa ń rò pé eré lásán ni kéèyàn máa lọ́kùnrin tàbí obìnrin tó ń fẹ́, àmọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré mọ́ nígbà tẹ́nì kan bá ń ronú nípa ìgbéyàwó tí èkejì ò sì ríyẹn rò rárá.”
Ọmọ Ọdún Mélòó Ni Ẹ́?
Ọmọ ọdún mélòó lo rò pé ó yẹ kéèyàn jẹ́ kó tó lẹ́ni tó ń fẹ́ sọ́nà? ․․․․․
Ó yá, lọ bi Dádì tàbí Mọ́mì, kó o wá kọ ohun tí wọ́n bá sọ síbí yìí. ․․․․․
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọjọ́ orí tí ìwọ rò pé ó dáa kéèyàn ti máa fẹ́ ẹnì kan sọ́nà kéré sí èyí táwọn òbí ẹ sọ. Ó sì lè máà rí bẹ́ẹ̀! Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé o wà lára àwọn ọ̀dọ́ tó gbọ́n débi pé wọ́n fẹ́ mọ ara wọn dunjú kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ ẹnì kan sọ́nà. Ohun tí ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Danielle pinnu láti ṣe náà nìyẹn, ó ní: “Nígbà tí mo wo bó ṣe ń ṣe mí lọ́dún méjì sẹ́yìn, mo rí i pé ohun tí mo máa rí lára ọkùnrin tí màá fi gbà fún un ti yàtọ̀ gan-an báyìí. Kódà, ní báyìí pàápàá, mi ò rò pé ó tíì yá mi láti ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Àmọ́, tí mo bá rí i pé fún nǹkan bí ọdún mélòó kan ohun tó ń wù mí lára ọkùnrin ò yí pa dà, mo lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí wíwá ẹni tí màá fẹ́.”
Ìdí tó tún fi bọ́gbọ́n mu pé kó o dúró díẹ̀ rèé: Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà “ìgbà ìtànná òdòdó èwe” láti ṣàpèjúwe ìgbà téèyàn máa ń fẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ ṣáá, tí ìfẹ́ ọkàn láti máa fara ro ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tèèyàn sì máa ń lágbára gan-an. (1 Kọ́ríńtì 7:36) Bó o bá ti wá lọ lẹ́ni tó ò ń fẹ́ nígbà tó o ṣì wà ní “ìgbà ìtànná òdòdó èwe,” ó lè mú kó o ṣìwà hù. Lóòótọ́, ìyẹn lè máà jẹ́ nǹkan bàbàrà lójú àwọn ojúgbà rẹ, torí púpọ̀ nínú wọn ló máa ń fẹ́ tètè mọ bí ìbálòpọ̀ ṣe ń rí lára. Àmọ́, o lè mú irú ìrònú yẹn kúrò lọ́kàn, kó o sì fìyẹn jù wọ́n lọ! (Róòmù 12:2) Bíbélì ṣáà gbà ẹ́ níyànjú pé kó o “sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Bó o bá dúró dìgbà tí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ ò bá mu ẹ́ lómi tó bẹ́ẹ̀ mọ́, wàá lè “mú ibi kúrò [lórí] ara rẹ.”—Oníwàásù 11:10, Bibeli Ajuwe.
Ṣó O Ti Ṣe Tán Láti Ṣègbéyàwó?
Kó o tó dáhùn ìbéèrè yìí, kọ́kọ́ yẹ ara ẹ wò dáadáa. Àwọn ohun tó yẹ kó o gbé yẹ̀ wò rèé:
Bó o ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn. Báwo lo ṣe ń ṣe sí Dádì àti Mọ́mì, àtàwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ? Ṣó o mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ sọ àbí ńṣe lo máa ń fagídí sọ̀rọ̀ tó o sì máa ń lo àwọn èdè rírùn láti sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ? Kí lo rò pé wọ́n máa sọ nípa ẹ? Bó o bá ṣe ń ṣe sáwọn ará ilé ẹ náà lo ṣe máa ṣe sẹ́ni tó o bá fẹ́.—Ka Éfésù 4:31.
Ìwà ẹ. Ṣó o sábà máa ń lẹ́mìí pé nǹkan máa dáa àbí gbogbo nǹkan ni kì í dáa lójú ẹ? Ṣó o máa ń gba tẹlòmíì rò, àbí tìẹ lo máa ń fẹ́ ṣe ṣáá? Ṣó o máa ń fara balẹ̀ tí wàhálà bá ṣẹlẹ̀? Ṣó o máa ń ní sùúrù? Bó o bá fi èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run ṣèwà hu nísinsìnyí, á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti di aya tàbí ọkọ tó dáńgájíá.—Ka Gálátíà 5:22, 23.
Ṣíṣọ́ owó ná. Ṣó o mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́ owó ná? Ṣó o sábà máa ń jẹ gbèsè? Ṣé tó o bá ríṣẹ́ kì í tètè bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́? Tó bá máa ń tètè bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́, kí ló máa ń fà á? Ṣé iṣẹ́ yẹn ò dáa tó ni àbí àwọn tó gbà ẹ́ síṣẹ́ ni ò ṣe ẹ́ dáadáa? Ṣé ìwà tàbí ohun kan tó yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí ló ń jẹ́ kí wọ́n máa dá ẹ dúró níbi iṣẹ́? Tó ò bá mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́ owó ná, báwo ni wàá ṣe lè gbọ́ bùkátà ìdílé?—Ka 1 Tímótì 5:8.
Àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run. Tó bá jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, àwọn ànímọ́ wo lo ní nípa tẹ̀mí? Ṣó o máa Oníwàásù 4:9, 10.
ń wáyè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣé wọn kì í rán ẹ létí kó o tó lọ sóde ẹ̀rí, ṣé wọn kì í sì í tì ẹ́ lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni? Ẹni tó o máa fẹ́ nílò ẹni tó tóótun tó sì wà lójúfò nípa tẹ̀mí.—KaOhun Tó O Lè Ṣe
Bó bá ń wù ẹ́ láti lẹ́ni tí wàá máa fẹ́ sọ́nà nígbà tí kò tíì yá ẹ láti ṣègbéyàwó, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tó o fẹ́ fi agídí ṣèdánwò àṣekágbá ilé ẹ̀kọ́ girama nígbà tó o ṣì wà níléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Ó dájú pé ìyẹn ò dáa tó! Ó di dandan kó o wáyè láti mọ àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni nílé ẹ̀kọ́ girama, kó o lè mọ ohun tó o máa bá pàdé nínú ìdánwò ọ̀hún.
Bọ́ràn fífẹ́ra ẹni sọ́nà ṣe rí gan-an nìyẹn. Bá a ṣe sọ lókè, fífẹ́ra ẹni sọ́nà kì í ṣe ọ̀ràn eré. Torí náà kó o tó tọrùn bọ̀ ọ́, o ní láti mọ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan dunjú, ìyẹn béèyàn ṣe ń báni dọ́rẹ̀ẹ́. Bó o
bá sì wá rẹ́ni tó tẹ́ ẹ lọ́rùn, wàá lè mọ bó o ṣe lè máa ṣe sí i, kẹ́ ẹ lè dọ̀rẹ́ ara yín. Ó ṣe tán, bí tọkọtaya bá jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wọn, ìgbéyàwó wọn á dùn bí oyin.Má ṣe rò pé o máa léélẹ̀ tó ò bá tètè lẹ́ni tí wàá fẹ́. Ká sòótọ́, ìgbà tó ò bá tíì lẹ́ni tó ò ń fẹ́ gan-an lo máa lómìnira tó pọ̀ jù láti ‘yọ̀ ní ìgbà èwe rẹ.’ (Oníwàásù 11:9) Ìgbà yẹn gan-an lo sì máa ráyè tún ìwà ẹ ṣe, tí wàá sì lè mú kí àjọsẹ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run dán mọ́rán sí i.—Ìdárò 3:27.
Ní báyìí, o lè gbádùn àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ. Báwo lo ṣe lè ṣe é? Ọ̀nà tó dáa jù ni pé kẹ́ ẹ jọ wa pa pọ̀ láàárín àwọn ọ̀rẹ́ níbi táwọn àgbàlagbà wà. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Tammy sọ pé: “Ìyẹn gan-an lodù ẹ̀, ó máa ń dáa kéèyàn lọ́rẹ̀ẹ́ tó pọ̀.” Monica náà ò jiyàn, ó ní: “Pé kéèyàn máa wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀ dáa gan-an, torí wàá rí ọ̀pọ̀ èèyàn tí ànímọ́ wọn yàtọ̀ síra.”
Àmọ́, tó o bá lọ dójú sọ ẹnì kan nígbà tí kò tíì yá ẹ, ẹ̀dùn ọkàn lo máa kó bára ẹ. Torí náà, fara balẹ̀. Fi àsìkò tó o wà yìí kọ́ béèyàn ṣe ń yan ọ̀rẹ́ tí ò sì ní síjà. Bó bá sì yá ẹ láti ní àfẹ́sọ́nà, wàá ti mọ ara ẹ dunjú, wàá sì ti mọ irú ohun tó o máa fẹ́ lára ẹni tó o fẹ́ fi ṣe aya tàbí ọkọ.
KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 29 ÀTI 30 NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ
Ṣó o ti ń ronú nípa fífẹ́ ẹnì kan sọ́nà láìjẹ́ káwọn òbí ẹ mọ̀? Ó léwu ju bó o ṣe rò lọ o.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Òwe 14:15.
ÌMỌ̀RÀN
Tó o bá fẹ́ múra sílẹ̀ de ìgbà tó o máa bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ ẹnì kan sọ́nà tàbí tó o máa ṣègbéyàwó, ka 2 Pétérù 1:5-7, kó o sì fọkàn sí ànímọ́ kan tó yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí. Lẹ́yìn oṣù kan, ṣàyẹ̀wò bó o ṣe mọ ànímọ́ yẹn tó àti bó ṣe hàn nínú ìwà ẹ sí.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Ọ̀pọ̀ ìwádìí táwọn èèyàn ṣe ti fi hàn pé àwọn tó ṣègbéyàwó láì tíì pé ọmọ ogún [20] ọdún sábà máa ń kọ́ra wọn sílẹ̀ láàárín ọdún márùn-ún tí wọ́n fẹ́ra.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Àwọn ànímọ́ tó yẹ kí n ní rèé, tí mo bá fẹ́ múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó: ․․․․․
Àwọn ohun tó lè mú kí n láwọn ànímọ́ yẹn ni pé ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Àwọn ibo ló ti bójú mu láti wà pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ?
● Báwo lo ṣe lè bá àbúrò ẹ tó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹnì kan sọ́nà sọ̀rọ̀ nígbà tó ṣì kéré láti ṣe bẹ́ẹ̀?
● Bó o bá ń fẹ́ ẹnì kan àmọ́ tí kò sí lọ́kàn ẹ láti fẹ̀ ẹ́ tàbí láti jẹ́ kó gbé ẹ sílé, báwo ló ṣe máa rí lára onítọ̀hún?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 18]
Èmi rò pé béèyàn bá mọyì ẹnì kan téèyàn sì rí i pé àjọgbé òun àti ẹ̀ máa wọ̀ ló yẹ kéèyàn tó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹ sọ́nà. Ẹni yẹn ló yẹ kó máa dá ẹ lọ́rùn kì í ṣe àjọṣe tó wà láàárín yín.’’—Amber
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Bó o bá ń fẹ́ ẹnì kan síbẹ̀ tí kò sí lọ́kàn ẹ láti fi ṣe ọkọ tàbí aya, ńṣe lo dà bí ọmọdé tó ń fi bèbí ṣeré, àmọ́ tó wábi jù ú sí nígbà tó yá