Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Rèé O Ẹ̀yin Òbí

Ọ̀rọ̀ Rèé O Ẹ̀yin Òbí

Ọ̀rọ̀ Rèé O Ẹ̀yin Òbí

Lójú àwọn ọ̀dọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń rìn lórí pákó tẹ́ẹ́rẹ́ tí wọ́n gbé sórí kòtò gìrìwò. Á máa ṣe onítọ̀hún bíi pé ó máa ṣubú, ẹ̀rù á sì máa bà á. Nígbà míì, ẹ̀yin òbí ò tiẹ̀ ní fẹ́ káwọn ọmọ yín rin irú ìrìn yìí, èyí tá a lè fi wé bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Àmọ́, ẹ ò lè sọ pé kí wọ́n má dàgbà, síbẹ̀ ẹ máa kín wọn lẹ́yìn kí wọ́n má bàa ṣubú sí kòtò. Ẹ̀yin lẹ wà nípò tó dára jù lọ láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́, kí wọ́n má bàa ṣi ẹsẹ̀ gbé, kí wọ́n má sì dàgbà tí kò wúlò.

Àbí àsọdùn ọ̀rọ̀ nìyẹn? Rárá o. Gbogbo ẹ náà rèé bí àná yìí, tọ́mọ yín kékeré ń da ilé rú; àmọ́ ní báyìí ńṣe ló ń lọ nílọ ẹ̀, kì í sì í fẹ́ sọ tinú ẹ̀. Ó sì lè jẹ́ pé gbogbo ibi tẹ́ ẹ bá fẹ lọ ni ọmọbìnrin yín kékeré máa ń fẹ́ báa yín lọ nígbà kan, àmọ́ ní báyìí, ojú máa ń tì í láti báa yín jáde!

Síbẹ̀, kò yẹ kẹ́ ẹ rò pé ẹ ò mọṣẹ́ yín níṣẹ́ báwọn ìyípadà bí èyí bá bẹ̀rẹ̀ sí wáyé. Ẹ láǹfààní láti wá ọgbọ́n lọ sọ́dọ̀ ẹni tó lè fún ẹ̀yin àti ọmọ yín ní ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé. Orísun ọgbọ́n yẹn ni Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

A dìídì ṣe ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì, káwọn ọmọ yín lè mọ bí wọ́n á ṣe máa ronú lọ́nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Bẹ́ ẹ bá wo àtẹ Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí, lójú ìwé 4 àti 5, á jẹ́ kẹ́ ẹ mọ ọ̀kan-ò-jọ̀kan àkòrí tó wà níbẹ̀. Àmọ́, kì í wulẹ̀ ṣe pé ìwé yìí ń da ọ̀rọ̀ sílẹ̀ wuuruwu lásán o, àwọn àpẹẹrẹ kan rèé:

(1) Ìwé náà ní iṣẹ́ tó máa fún ẹni tó bá kà á ṣe. Ọ̀pọ̀ ibi ló wà nínú ìwé náà tá a ti máa retí pé kí ọmọ rẹ ṣe àkọsílẹ̀ èrò rẹ̀ nípa àwọn ìbéèrè àtàwọn gbólóhùn kan. Bí àpẹẹrẹ, wàá rí àkọlé náà, “Mímúra Sílẹ̀ De Ìṣòro” lójú ìwé 132 àti 133. Èyí máa ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn ìṣòro tó máa ń bá pàdé àti ohun tó lè ṣe nípa àwọn ìṣòro náà. Síwájú sí i, apá mẹ́sàn-án ni ìwé náà pín sí, ojú ìwé tó parí apá kọ̀ọ̀kan sì ní àkọlé náà, “Ohun Tí Mo Rò.” Lẹ́yìn tí ọmọ rẹ bá ti ka ohun tó wà nínú apá kọ̀ọ̀kan tán, ó lè kọ èrò rẹ̀ nípa ohun tó kà àti bó ṣe rí lára ẹ̀ sí ojú ìwé yẹn.

(2) Ìwé náà á fún ìwọ àti ọmọ rẹ láǹfààní láti fọ̀rọ̀ wérọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àpótí kan wà lójú ìwé 63 àti 64 tó ní àkọlé náà, “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bá Dádì tàbí Mọ́mì Sọ̀rọ̀ Nípa Ìbálòpọ̀?” Bákan náà, ní ìparí orí kọ̀ọ̀kan, àpótí kan wà tá a pè ní “Kí Lèrò Ẹ?” Kì í ṣe àtúnyẹ̀wò nìkan ni àpótí yìí wà fún, àmọ́ ẹ tún lè lò ó gẹ́gẹ́ bíi kókó tẹ́yin àtàwọn ọmọ yín máa jíròrò. Ní àfikún sí ìyẹn, orí kọ̀ọ̀kan ní àkọlé náà “Ohun Tí Màá Ṣe!” ní apá tó gbẹ̀yìn níbẹ̀ la ti ní káwọn ọmọ parí gbólóhùn yìí: “Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni . . . ” Èyí máa ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti máa wá ìmọ̀ràn tí kò fì síbì kan lọ sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn bí wọ́n ti ń fojú winá ìṣòro ìgbà ìbàlágà.

Ọ̀rọ̀ ìṣọ́ra kan rèé: Káwọn ọmọ ẹ bàa lè máa kọ ohun tó wà lọ́kàn wọn gan-an sínú ìwé yìí, ọwọ́ wọn ni kó o jẹ́ kí ìwé náà máa gbé. Bó bá yá, àwọn fúnra wọn lè wá fẹnu ara wọn ṣàlàyé ohun tí wọ́n kọ síbẹ̀.

Rí i pé o ní ìwé yìí lọ́wọ́, kó o sì kà á tinú tẹ̀yìn. Bó o bá sì ṣe ń kà á, gbìyànjú láti máa rántí bọ́rọ̀ ṣe rí, bó o ṣe dààmú àti bó o ṣe ń ṣàníyàn nígbà tíwọ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà. Bó bá sì tó àkókò, sọ àwọn ohun tójú rí wọ̀nyí fún ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ. Ìyẹn á sì ran àwọn ọmọ ẹ lọ́wọ́ láti máa sọ tinú wọn fún ẹ. Bí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, máa fetí sílẹ̀! Bí gbogbo ọgbọ́n tó ò ń dá láti bá wọn sọ̀rọ̀ bá ń já sí pàbó, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Bó ti wù kó dà bíi pé àwọn ọmọ ò kọbi ara sóhun tó ò ń bá wọn sọ tó, òótọ́ ibẹ̀ ni pé wọ́n máa ń mọrírì ìmọ̀ràn àwọn òbí wọn ju tàwọn ojúgbà wọn lọ.

Inú wa dùn láti ṣe ìwé tá a gbé karí Bíbélì yìí, kí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ lè máa lò ó, àdúrà wa sì ni pé kí ìwé yìí ràn yín lọ́wọ́.

Àwa Òǹṣèwé