Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Nǹkan Ṣe Ń rí Lára Ẹ

Bí Nǹkan Ṣe Ń rí Lára Ẹ

APÁ 7

Bí Nǹkan Ṣe Ń rí Lára Ẹ

Èwo nínú àwọn gbólóhùn yìí ló sọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an?

□ Mo máa ń bínú sódì.

□ Kò sí ohun tí mo lè mọ̀-ọ́n ṣe.

□ Ìgbà gbogbo ni inú mi máa ń bà jẹ́. N kì í fìgbà kankan láyọ̀.

□ Èrò nípa ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tèmi ló máa ń gbà mí lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.

□ Ọkàn mi máa ń fà sí ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tèmi nígbà míì.

Bó o bá mú èyíkéyìí nínú àwọn gbólóhùn tó wà lókè yìí, má fòyà! Orí 26 sí 29 nínú ìwé yìí á jẹ́ kó o mọ ibi tí wàá máa darí ọkàn ẹ sí, kó má bàa máa darí ẹ síbi tó wù ú.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 216, 217]