Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Ohun Tó Ń Ṣe Mí Mọ́ra?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Ohun Tó Ń Ṣe Mí Mọ́ra?

ORÍ 26

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Ohun Tó Ń Ṣe Mí Mọ́ra?

KÍ LO ti rò ó sí, ṣé iná dára àbí kò dára? Ó ṣeé ṣe kó o sọ pé ìyẹn sinmi lórí ojú téèyàn bá fi wò ó. Lọ́wọ́ alẹ́ tí òtútù bá ń mú, ara máa ń móoru téèyàn bá ń yáná. Ìyẹn dára. Àmọ́, bí kò bá sí àbójútó tó yẹ, iná tó ń jó lè gbèèràn kó sì jó odidi ilé kanlẹ̀. Ìyẹn ò dára.

Bí ìmọ̀lára rẹ ṣe rí náà nìyẹn. Ó ṣàǹfààní bó o bá pa á mọ́ra, torí pé á jẹ́ kó o lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. Àmọ́, bó o bá ní kó o fi bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ hùwà, àjọṣe tó wà láàárín ìwọ àtàwọn ẹlòmíì lè bà jẹ́.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́langba, ìgbà míì wà tínú á máa bí ẹ tọ́kàn rẹ á sì bà jẹ́ gidigidi. Kí lo lè ṣe tọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká jíròrò wọn lọ́kọ̀ọ̀kan.

Bó O Ṣe Lè Fọwọ́ Wọ́nú

Kì í rọrùn láti fara da ìrẹ́jẹ ó sì máa ń dunni gan-an. Àwọn kan tiẹ̀ wà tí wọn ò lè pa irú ẹ̀ mọ́ra rárá. Kódà, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tí wọ́n ń “fi ara fún ìbínú” àti àwọn tó ń “fi ara fún ìhónú.” (Òwe 22:24; 29:22) Ọ̀ràn kékeré kọ́ nìyẹn o. Bí ìbínú bá mú kéèyàn fara ya, ó lè mú kéèyàn hùwà tó máa wá kábàámọ̀. Torí náà báwo lo ṣe lè pa ìbínú mọ́ra bí wọ́n bá rẹ́ ẹ jẹ?

Kọ́kọ́ ro ọ̀ràn náà síwá sẹ́yìn, kó o lè mọ̀ bóyá ohun tí wàá kàn gbàgbé nípa ẹ̀ ni. * (Sáàmù 4:4) Rántí pé tó o bá fi “ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe” wàá wulẹ̀ mú kọ́ràn náà burú sí i ni. (1 Tẹsalóníkà 5:15) Lẹ́yìn tó o bá ti gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò, tó o sì ti gbàdúrà nípa ẹ̀, o lè rí i pé ó ṣeé ṣe fún ẹ láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà parí síbẹ̀, ìbínú yẹn á sì kúrò lọ́kàn ẹ.—Sáàmù 37:8.

Àmọ́ bọ́ràn náà ò bá yé dùn ẹ́ ńkọ́? Bíbélì sọ pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀,” wà. (Oníwàásù 3:7) Ṣé wàá kúkú tọ ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́ lọ? Bó o bá sì rò pé ìyẹn ò dáa tó, o lè sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fáwọn òbí ẹ tàbí ọ̀rẹ́ kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. Bí ẹnì kan bá ń mọ̀ọ́mọ̀ fayé ni ẹ́ lára, ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti máa hùwà rere sí onítọ̀hún.  Àtẹ tó wà lójú ìwé 221 lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ronú nípa àwọn nǹkan míì tó o lè sọ tàbí tó o lè ṣe nípa àwọn ọ̀ràn tó o máa ń torí ẹ̀ gbaná jẹ tẹ́lẹ̀.

Rí i dájú pé o gbàdúrà sí Jèhófà, kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe máa fi ẹni tó bá ṣẹ̀ ẹ́ sínú. Má sì gbàgbé pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ò lè yí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ pa dà, o lè bó ṣe rí lára ẹ pa dà. Bó o bá jẹ́ kí ìbínú ru bò ẹ́ lójú, ṣe lọ̀rọ̀ ẹ máa dà bí ẹja tó gbé ìwọ̀ mì. Wàá jẹ́ kí ẹlòmíì máa darí èrò àti ìmọ̀lára ẹ. Ṣé kò wá ní wù ẹ́ kó kúkú jẹ́ pé ìwọ ni wàá máa darí ara ẹ?—Róòmù 12:19.

Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Ìbànújẹ́ Dorí Ẹ Kodò

Laura, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], sọ pé: “Lẹ́nu àìpẹ́ yìí mo máa ń kanra, kò sì sóhun tí mo ṣe tó dáa lójú mi. Ohunkóhun ò fún mi láyọ̀ mọ́. Ẹkún ni mo máa ń sun títí tí oorun á fi gbé mi lọ.” Bíi ti Laura, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni wàhálà ìgbésí ayé ti wọ̀ lọ́rùn. Ìwọ ńkọ́? Ohun táwọn òbí ẹ, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ àtàwọn olùkọ́ ẹ ń retí pé kó o ṣe; àwọn ìyípadà tó ń dé bá ara ẹ bó o ṣe ń bàlágà; tàbí rírò tó o máa ń rò pé o ò lè ṣe ohunkóhun yọrí, gbogbo ẹ̀ ti tó láti mú kí agara dá ẹ.

Àwọn ọ̀dọ́ kan tiẹ̀ máa ń tìtorí ẹ̀ dọ́gbẹ́ síra wọn lára kí wọ́n bàa lè dín wàhálà tó bá wọn kù. * Bọ́rọ̀ tìẹ náà bá ti dà bẹ́ẹ̀, gbìyànjú láti ronú lórí ohun tó fà á. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń dọ́gbẹ́ síra wọn lára láti kojú àwọn nǹkan tó ń da ọkàn wọn láàmú. Ṣé ohun kan wà, nínú ilé tàbí láàárín àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, tó máa ń da ọkàn tìẹ náà láàmú?

Ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ téèyàn lè gbà yanjú ìṣòro ìdààmú ọkàn ni pé kéèyàn fọ̀rọ̀ lọ òbí tàbí ẹnì kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè wá dà bí ẹni tá a “bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Liliana, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], sọ bó ṣe ń ṣe é fáwọn arábìnrin kan nínú ìjọ. Ó sọ pé: “Níwọ̀n bí wọ́n ti dàgbà jù mí lọ, ìmọ̀ràn wọn mọ́gbọ́n dání. Wọ́n ti wá di ọ̀rẹ́ mi.” * Dana, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], sọ pé ohun tó gba òun sílẹ̀ ni fífi tóun fi kún ipa tóun ń kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Ó sọ pé: “Ohun tó dáa jù lọ tí mo lè ṣe nìyẹn. Kódà, mi ò tíì rí ohun tó fún mi láyọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí látọjọ́ tí mo ti dáyé!”

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, bínú ẹ bá bà jẹ́, tí nǹkan sì tojú sú ẹ, má ṣe gbàgbé láti gbàdúrà. Dáfídì tóun náà fojú winá ìṣòro kọ̀wé pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.” (Sáàmù 55:22) Jèhófà mọ̀ pé ò ń fojú winá ìṣòro. Kò sì ní dá ẹ dá a, torí pé ó “bìkítà fún [ẹ].” (1 Pétérù 5:7) Bí ọkàn rẹ bá dá ẹ lẹ́bi, rántí pé ‘Ọlọ́run tóbi ju ọkàn rẹ lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.’ (1 Jòhánù 3:20) Ó lóye ìdí tó o fi ní ìdààmú ọkàn ju ìwọ alára lọ, ó sì lè sọ òkè ìṣòro rẹ di pẹ̀tẹ́lẹ̀.

Bí inú ẹ bá ṣì ń bà jẹ́, ó lè jẹ́ pé o ní àìlera ni, irú bí ìsoríkọ́. * Bọ́ràn bá wá rí bẹ́ẹ̀, ó máa dáa kó o lọ rí dókítà fún àyẹ̀wò. Bó o bá dágunlá sí ọ̀rọ̀ náà, ṣe ló máa dà bí ìgbà tó ò ń jẹ́ kí rédíò inú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ máa ké tantan, kó lè bo ariwo ẹ́ńjìnnì tó ti fẹ́ bà jẹ́ mọ́lẹ̀. Ì bá kúkú sàn kó o tún ẹ́ńjìnnì náà ṣe. Ṣó o rí i, kò sídìí kankan tí ipò tó o wà fi gbọ́dọ̀ máa tì ẹ́ lójú. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó ní ìsoríkọ́ àtàwọn àìlera míì ló ti rí ìtọ́jú gbà lọ́dọ̀ dókítà.

Má gbàgbé pé bí iná ni ìmọ̀lára rẹ rí. Ó ṣàǹfààní bó o bá pa á mọ́ra; bó o bá sì ní bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ ni wàá ṣe hùwà, wàhálà lè bẹ́ sílẹ̀. Torí náà, sa gbogbo ipá rẹ láti má ṣe máa gbaná jẹ. Nígbà míì, ó ṣeé ṣe kó o sọ ohun kan tàbí kó o ṣe ohun tó o máa kábàámọ̀ ẹ̀ bó bá yá. Àmọ́, ṣáà máa ní sùúrù. Bó bá yá, wàá mọ béèyàn ṣe ń pa nǹkan mọ́ra, kó má bàa jẹ́ pé bí nǹkan bá ṣe rí lára ni wàá máa fi hùwà.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣé o kì í fẹ́ ṣe àṣìṣe kankan? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo lo ṣe lè máa fojú tó tọ́ wo àṣìṣe?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 8 Bó bá jẹ́ pé ẹnì kan ló ń yọ ẹ́ lẹ́nu níléèwé, wo àwọn àbá tó lè wúlò fún ẹ ní Orí 14 nínú ìwé yìí. Àmọ́, bó bá jẹ́ pé ọ̀rẹ́ ẹ ló ṣe ohun tó bí ẹ nínú, ìsọfúnni tó wà ní Orí 10 lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

^ ìpínrọ̀ 13 Onírúurú ọ̀nà làwọn tó máa ń dọ́gbẹ́ síra wọn lára máa ń gbà ṣe é, wọ́n lè fi nǹkan gé ara wọn, wọ́n lè fi iná jó ara wọn, wọ́n lè dá ọgbẹ́ sára tàbí kí wọ́n bo awọ ara wọn.

^ ìpínrọ̀ 14 Bójú bá ń tì ẹ́ láti sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fẹ́nì kan lójúkojú, gbìyànjú láti kọ lẹ́tà tàbí kó o bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀ lórí fóònù. Ohun tó sábà máa ń ran èèyàn lọ́wọ́ jù lọ láti borí ìdààmú ọkàn ni pé kó sọ bó ṣe ń ṣe é fún ẹlòmíì.

^ ìpínrọ̀ 16 Bó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìsoríkọ́, wo orí 13 nínú Apá Kìíní ìwé yìí.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.Róòmù 12:21.

ÌMỌ̀RÀN

Máa sọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún Dádì tàbí Mọ́mì lójoojúmọ́, bó ti wù kí nǹkan náà kéré tó. Bó bá wá di pé ìṣòro dé, á lè rọrùn fún ẹ láti sọ fún wọn. Á sì túbọ̀ rọrùn fún wọn láti tẹ́tí sí ẹ.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Bí o kì í bá fún ara ẹ nísinmi tó pọ̀ tó, kó o sì máa jẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore, ó máa ṣòro fún ẹ láti pa ohun tó ń ṣe ẹ́ mọ́ra.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Ohun tó máa ń ṣòroó pa mọ́ra fún mi jù lọ ni ․․․․․

Ohun tí màá ṣe nípa rẹ̀ ni ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tínú Ọlọ́run ò fi dùn sí kéèyàn máa bínú sódì?

● Àwọn ọ̀nà wo ni bíbínú láìgbẹ̀bẹ̀ lè gbà pani lára?

● Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà fara da ohun tó bá ń bà ẹ́ nínú jẹ́?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 223]

“Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ fún mi ni mímọ̀ tí mo mọ̀ pé ẹnì kan bìkítà nípa mi, pé ẹnì kan wà tí mo lè fọ̀rọ̀ lọ̀ lọ́jọ́ ìṣòro.”—Jennifer

[Àtẹ/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 221]

 Tí mo kọ èrò mi sí

Fọwọ́ wọ́nú

Kọ ohun tó o máa ṣe sínú àtẹ yìí

Ohun tó ṣẹlẹ̀

Ọmọléèwé mi fi mí ṣe yẹ̀yẹ́

Fífìbínú dáhùn

Èmi náà bú u

Bó ṣe yẹ kó o dáhùn

Mi ò kọbi ara sóhun tó sọ, mo sì jẹ́ kó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ò ní múnú bí mi

Ohun tó ṣẹlẹ̀

Àbúrò mi kó àwọn bàtà tó wù mí jù lọ láìsọ fún mi

Fífìbínú dáhùn

Èmi náà kó àwọn nǹkan tiẹ̀ láìjẹ́ kó mọ̀

Bó ṣe yẹ kó o dáhùn

․․․․․

Ohun tó ṣẹlẹ̀

Àwọn òbí mi ká mi lọ́wọ́ kò

Fífìbínú dáhùn

․․․․․

Bó ṣe yẹ kó o dáhùn

․․․․․

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 220]

Bí ẹja tó gbé ìwọ̀ mì lẹni bá ń gbé ìbínú sọ́kàn, ẹlòmíì ló ń darí àwọn méjèèjì