Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Sá Fún Bíbá Ọkùnrin Tàbí Obìnrin Bíi Tèmi Lò Pọ̀?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Sá Fún Bíbá Ọkùnrin Tàbí Obìnrin Bíi Tèmi Lò Pọ̀?

ORÍ 28

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Sá Fún Bíbá Ọkùnrin Tàbí Obìnrin Bíi Tèmi Lò Pọ̀?

“Kí n tó pọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] lọkàn mi ti ń fà sáwọn ọkùnrin bíi tèmi. Mo sì mọ̀ lọ́kàn mi pé irú èrò bẹ́ẹ̀ ò dáa.”—Olef.

“Ó tó ẹ̀ẹ̀kan sí ẹ̀ẹ̀mejì témi àti obìnrin bíi tèmi ti fẹnu kora wa lẹ́nu. Àmọ́, torí pé mo ṣì ń nífẹ̀ẹ́ sáwọn ọkùnrin, mo wá ń wò ó pé àfàìmọ̀ kí n má ya ẹni tó máa nífẹ̀ẹ́ sí bíbá ọkùnrin àti obìnrin lò pọ̀.”—Sarah.

LÓDE òní, díẹ̀ làwọn tó máa jiyàn pé gbangba wálíà làwọn èèyàn ti ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀, èyí tí kò sì rí bẹ́ẹ̀ ní nǹkan bí ogójì [40] ọdún sẹ́yìn. O ò sì jẹ́ sọ pé kò wù ẹ́! Tó o bá sọ bẹ́ẹ̀ pẹ́nrẹ́n, ńṣe ni wọ́n máa dẹnu bò ẹ́. Amy, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] sọ pé: “Ọmọbìnrin kan sọ fún mi pé ó ní láti jẹ́ pé mo ni ẹ̀tanú sáwọn tí wọ́n ti ibòmíì wá, torí pé ohun tí èrò mi nípa àwọn tó ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀ já sí náà nìyẹn, ẹ̀tanú ni!”

Ìwà ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ inú ayé òde òní ti sún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ láti máa bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀. Becky, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbìnrin níléèwé wa máa ń sọ pé obìnrin tó ń bá obìnrin lò pọ̀ tàbí obìnrin tó ń bá tọkùnrin tobìnrin lò pọ̀ làwọn. Àwọn míì á sì sọ pé kò séyìí táwọn ò nífẹ̀ẹ́ sí nínú méjèèjì.” Ọmọbìnrin ọlọ́dún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Christa sọ pé bọ́ràn ṣe rí níléèwé òun náà nìyẹn. Ó ní: “Méjì lára àwọn ọmọbìnrin tá a jọ wà ní kíláàsì ti wá bá mi pé kí n jẹ́ ká bára wa lò pọ̀. Nínú ìwé tí ọ̀kan lára wọn kọ sí mi, ó bi mí bóyá màá fẹ́ láti mọ bí ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin bíi tèmi ṣe máa ń rí.”

Léyìí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti wá ń lọ́wọ́ nínú bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀ láìfi bò mọ́ yìí, ó lè máa ṣe ẹ́ ní kàyéfì pé: “Kí ló burú nínú kéèyàn máa bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ lò pọ̀? Bí ọkàn mi bá ń fà sí ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tèmi ńkọ́? Ṣé ìyẹn máa fi hàn pé mo jẹ́ ẹni tó ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tèmi lò pọ̀?’

Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wò Ó?

Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn, tó fi mọ́ àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì, ni ò fọwọ́ tó le mú ọ̀ràn bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tẹni lò pọ̀. Síbẹ̀, Bíbélì ò firọ́ pé òótọ́ fún wa lórí irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Ó sọ fún wa pé Jèhófà Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin, àárín àwọn méjèèjì tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya yìí ló sì fẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ mọ sí. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; 2:24) Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé Bíbélì sọ pé bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tẹni lò pọ̀ kò dáa.—Róòmù 1:26, 27.

Àmọ́ ṣá o, àwọn kan máa ń sọ pé Bíbélì ò bágbà mu mọ́. Kí lo rò pé ó fà á tí wọ́n fi tètè máa ń sọ bẹ́ẹ̀? Ṣé torí pé Bíbélì ta ko ohun tó wù wọ́n ni? Ọ̀pọ̀ èèyàn ò fara mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run torí pé ohun tó fi ń kọ́ni yàtọ̀ sóhun tí wọ́n fẹ́ láti gbà gbọ́. Èrò òdì nìyẹn ṣá o, a kò sì gbọ́dọ̀ gba ọkàn wa láyè láti máa ro ìròkurò bẹ́ẹ̀!

Bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ọkàn ẹ ń fà sí ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ ńkọ́? Ṣé ìyẹn ti yáa wá túmọ̀ sí pé ẹni tó ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ lò pọ̀ ni ẹ́? Rárá o. Rántí pé o ṣì wà ní “ìgbà ìtànná òdòdó èwe,” àkókò tí ara ẹ á máa ṣàdédé wà lọ́nà fún ìbálòpọ̀. (1 Kọ́ríńtì 7:36) Bí ọkàn ẹ bá ń fà sí ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìyẹn ò túmọ̀ sí pé o ti di ẹni tó ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ lò pọ̀. Kì í pẹ́ tírú èrò bẹ́ẹ̀ fi máa ń lọ. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ rí i pé o ò lọ́wọ́ sí bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ lò pọ̀. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

Fi ọ̀ràn náà sínú àdúrà. Gbàdúrà sí Jèhófà bíi ti Dáfídì, tó bẹ̀bẹ̀ pé: “Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn-àyà mi. Wádìí mi wò, kí o sì mọ àwọn ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè, kí o sì rí i bóyá ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára wà nínú mi, kí o sì ṣamọ̀nà mi ní ọ̀nà àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sáàmù 139:23, 24) Jèhófà lè sọ ẹ́ di alágbára nípa fífún ẹ ní àlàáfíà tó “ta gbogbo ìrònú yọ.” Àlàáfíà yìí á ‘máa ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ àti agbára èrò orí rẹ’ á sì fún ẹ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” èyí tí ò ní jẹ́ kó o hùwà búburú.—Fílípì 4:6, 7; 2 Kọ́ríńtì 4:7.

Fèrò tí ń gbéni ró kúnnú ọkàn rẹ. (Fílípì 4:8) Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Má ṣe fojú kéré agbára tí Bíbélì ní láti mú kó o máa ronú lọ́nà rere kó o sì máa fẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́. (Hébérù 4:12) Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jason sọ pé: “Nínú Bíbélì, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10 àti Éfésù 5:3, nípa lórí mi gidigidi. Mo máa ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí nígbàkigbà tí èrò búburú bá wá sí mi lọ́kàn.”

Sá fún àwọn nǹkan tó bá ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe àti ohunkóhun tó bá ń gbé bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tẹni lò lárugẹ. (Kólósè 3:5) Máa sá fún ohunkóhun tó bá máa mú èròkerò wá sí ẹ lọ́kàn. Lára irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni àwòrán oníhòòhò, àwọn eré kan tí wọ́n máa ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n àti nínú fíìmù, tàbí àwọn ìwé oge ṣíṣe tàbí ti eré ìmárale tí wọ́n máa ń ní àwòrán àwọn òrékelẹ́wà tí wọ́n wọṣọ tó fi ara sílẹ̀. Máa yára fi èrò tó dáa rọ́pò èrò tí kò tọ́. Ọmọ kan tí kò tíì pé ogún ọdún sọ pé: “Nígbàkigbà tí èrò bíbá ọkùnrin bíi tèmi lò pọ̀ bá wá sí mi lọ́kàn, mo máa ń ṣàṣàrò lórí ẹsẹ Bíbélì tí mo fẹ́ràn jù lọ.”

Àmọ́ ṣá o, àwọn kan lè sọ pé àwọn ò rí sí ṣíṣe gbogbo èyí tá à ń sọ yìí o jàre, wọ́n á ní, ó sàn ‘kéèyàn kúkú fara mọ́ ìbálòpọ̀ èyíkéyìí tó bá ti bá a lára mu, kó sì gbà pé bọ́rọ̀ tòun ṣe rí nìyẹn.’ Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ pé o lè ṣe ohun tó dáa jùyẹn lọ! Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fún wa nípa àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ti bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀ rí, àmọ́ tí wọ́n yí pa dà. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Ìwọ pẹ̀lú lè ja ìjà náà ní àjàyè, kódà bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé o ṣì ń rò ó lọ́kàn ni.

Bí èrò bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ lò pọ̀ ò bá yé wá sí ẹ lọ́kàn ńkọ́? Má ṣe juwọ́ sílẹ̀! Gbogbo ọ̀nà téèyàn lè gbà bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ lò pọ̀ pátá ni Jèhófà sọ pé kò dáa. Torí náà, bí èrò bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tẹni lò pọ̀ bá ń da ẹnì kan láàmú, ọ̀ràn irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò tíì kọjá àtúnṣe—ẹnu kí onítọ̀hún pinnu pé òun ò ní gba irú èrò bẹ́ẹ̀ láyè ni.

Àpèjúwe kan rèé: Ẹnì kan lè jẹ́ ẹni tó máa ń “fi ara [ẹ̀] fún ìhónú.” (Òwe 29:22) Kírú ẹni bẹ́ẹ̀ tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó lè jẹ́ pé kọ́rọ̀ tó ṣe bí ọ̀rọ̀ ló ti máa fara ya. Àmọ́ lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ti wá mọ̀ pé ó pọn dandan kóun máa kóra òun níjàánu. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ìbínú ò tún ní ru sókè nínú ẹ̀ mọ́ láé? Ó tì o. Àmọ́, torí pé ó mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa kéèyàn máa fàbínú yọ, ṣe ló máa yára kóra ẹ̀ níjàánu.

Bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn nínú ọ̀ràn ẹni tí ọkàn rẹ̀ bá ń fà sí bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ lò pọ̀ àmọ́ tó ti wá mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Èrò tí ò tọ́ ṣì lè máa wá sọ́kàn ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, bó bá ń rí i bí ohun tí Jèhófà sọ pé kò dáa, á ní okun àtinúwá tó fi máa fòpin sí irú èròkérò bẹ́ẹ̀.

Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀!

Bí ohun tó o máa ṣe nípa irú èrò yìí bá ṣì ń dà ẹ́ láàmú, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi ti ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó sọ pé: “Mo ti gbìyànjú láti yí èrò mi pa dà. Mo ti gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́. Mo ka Bíbélì. Mo ti gbọ́ ọ̀pọ̀ àsọyé Bíbélì tó dá lé e lórí. Ṣùgbọ́n mi ò mọ ohun tó yẹ kí n ṣe.”

Bó bá jẹ́ pé bọ́ràn tìẹ náà ṣe rí nìyí, a jẹ́ pé o gbọ́dọ̀ sapá gidigidi. Kì í rọrùn láti bọ́ lọ́wọ́ èròkerò. Síbẹ̀, ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ láti ṣe ohun tó wu Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa fi ìlànà ìwà rere Rẹ̀ ṣèwà hù kó sì ta kété sí ìṣekúṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Má gbàgbé pé gbogbo bó o ṣe ń gbìyànjú láti borí èrò ọkàn rẹ yé Ọlọ́run, ó sì máa ń yọ́nú sáwọn tó ń sìn ín. * (1 Jòhánù 3:19, 20) Nígbàkigbà tó o bá ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run, ó dájú pé á rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ lé ẹ lórí. Kódà, “èrè ńlá wà” fáwọn tó bá ń pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. (Sáàmù 19:11) Àní nísinsìnyí pàápàá, wàá gbádùn ìgbé ayé tó dára jù lọ nínú ayé oníwàhálà yìí.

Torí náà gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, má sì ṣe gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ láyè. (Gálátíà 6:9) Sapá láti “kórìíra ohun burúkú” kó o sì “rọ̀ mọ́ ohun rere.” (Róòmù 12:9) Bó ò bá jẹ́ kó sú ẹ, bó pẹ́ bó yá, wàá rí i pé èrò burúkú yẹn ò ní wá sí ẹ lọ́kàn mọ́. Jù gbogbo ẹ̀ lọ, bó o bá sá fún bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ lò pọ̀, wàá lè máa fojú sọ́nà fún gbígbé títí láé nínú ayé tuntun òdodo tí Ọlọ́run ṣèlérí.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Kí lo lè ṣe bí ọkàn rẹ bá ń fà sí ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 21 Bí Kristẹni kan bá ti lọ́wọ́ nínú ìwà ìṣekúṣe èyíkéyìí, ó gbọ́dọ̀ wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà ìjọ.—Jákọ́bù 5:14, 15.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Wádìí mi wò, kí o sì mọ àwọn ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè, kí o sì rí i bóyá ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára wà nínú mi.Sáàmù 139:23, 24.

ÌMỌ̀RÀN

Kó o bàa lè ní èrò tó tọ́ nípa bó o ṣe lè fi hàn pé ọkùnrin ni ẹ́, kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù. (1 Pétérù 2:21) Àpẹẹrẹ pípé ló jẹ́ nípa bí ọkùnrin ṣe lè fìwà pẹ̀lẹ́ lo agbára rẹ̀.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ò lágbára kankan lórí àwọn èrò tó bá ń wá sí ẹ lọ́kàn, ọwọ́ ẹ ni ohun tó o máa ṣe nípa irú èrò bẹ́ẹ̀ wà. O lè pinnu pó ò ní ṣe ohun búburú tó bá wá sí ẹ lọ́kàn.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí ẹnikẹ́ni bá bi mí pé kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé kò dáa kéèyàn máa bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ lò pọ̀, màá sọ pé ․․․․․

Bí ẹnikẹ́ni bá sọ pé ojú àtijọ́ ni Bíbélì fi ń wo ọ̀ràn náà, màá bá a ronú pọ̀ nípa sísọ pé ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

Kí nìdí tí inú Ọlọ́run ò fi dùn sí kéèyàn máa bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ lò pọ̀?

Kí làwọn ohun tó bọ́gbọ́n mu pé kó o ṣe kó o má bàa kó sínú páńpẹ́ bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ lò pọ̀?

Bó o bá ń wo ọ̀ràn bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ lò pọ̀ bí Ọlọ́run ṣe ń wò ó, ṣé ìyẹn á túmọ̀ sí pé àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ lo dìídì kórìíra?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 236]

“Èrò òdì táwọn èèyàn ní nípa ìbálòpọ̀ nípa lórí ìrònú mi kò sì jẹ́ kí n mọ ohun tí ǹ bá ṣe. Àmọ́ ní báyìí ṣá o, n kì í ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni tó bá ń gbé èrò bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tẹni lò pọ̀ lárugẹ.”—Anna

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 233]

Àwọn ọ̀dọ́ ní láti yan ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe, yálà kí wọ́n fara mọ́ èrò òdì táyé ní, pé èèyàn lè firú ìbálòpọ̀ tó bá wù ú tẹ́ra ẹ̀ lọ́rùn, tàbí kí wọ́n máa fi ìlànà tí kò gba gbẹ̀rẹ́, tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣèwà hù