Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Yẹ Kí N Máa Ṣeré Orí Kọ̀ǹpútà?

Ṣó Yẹ Kí N Máa Ṣeré Orí Kọ̀ǹpútà?

ORÍ 30

Ṣó Yẹ Kí N Máa Ṣeré Orí Kọ̀ǹpútà?

ỌMỌKÙNRIN kan tó ń jẹ́ Brian sọ pé: “Eré orí kọ̀ǹpútà máa ń dùn gan-an, ó sì máa ń wà pa. Àwọn nǹkan kan wà téèyàn máa ń ṣe nínú eré tó jẹ́ pé èèyàn ò jẹ́ dán wò lójú ayé kéèyàn sì mú un jẹ.” Deborah sọ pé òun náà gbádùn láti máa ṣeré orí kọ̀ǹpútà. Àmọ́, ó fi ọ̀rọ̀ ìṣọ́ra kan kún un, ó ní: “Wọ́n máa ń gba àkókò, kì í sì í rọrùn láti jáwọ́ nínú wọn.”

Kò sí àníàní pé eré orí kọ̀ǹpútà kì í wulẹ̀ ṣe eré tí wọ́n fọgbọ́n ìjìnlẹ̀ gbé kalẹ̀ lásán. Eré tó gba kéèyàn lọ́pọlọ ni, kì í sì í súni bọ̀rọ̀. Kò wá mọ síbẹ̀ yẹn ṣá o. Eré orí kọ̀ǹpútà máa ń jẹ́ kéèyàn já fáfá. Àwọn kan tiẹ̀ wà lára àwọn eré náà tó máa ń jẹ́ kéèyàn túbọ̀ mọ ìṣirò, kó sì mọ̀wé kà dáadáa. Yàtọ̀ síyẹn, èyí tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde lára àwọn eré náà làwọn ọmọléèwé máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Bó o bá sì ti ṣe èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde lára eré náà, a jẹ́ pé ìwọ náà á lẹ́nu ọ̀rọ̀ láàárín àwọn ẹgbẹ́ ẹ nìyẹn.

Ó dájú pé tó o bá fìṣọ́ra yan irú eré orí kọ̀ǹpútà tí wàá máa ṣe, wàá rí èyí tó o máa gbádùn gan-an tí ò sì ní tako àwọn ìlànà Kristẹni. Kí nìdí tó o tún fi ní láti ṣọ́ra?

Ewu Tó Wà Ńbẹ̀

Ó ṣeni láàánú pé kì í ṣe gbogbo eré orí kọ̀ǹpútà téèyàn fi ń dára yá ló dáa. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn eré tí wọ́n ń ṣe jáde báyìí ló ń gbé ìwà àìmọ́ tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ tí Bíbélì sì pè ní “àwọn iṣẹ́ ti ara” lárugẹ lọ́nà tó lékenkà.—Gálátíà 5:19-21.

Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] ni Adrian. Ó ṣàpèjúwe eré orí kọ̀ǹpútà kan tó gbajúmọ̀ pé “àwọn ọmọọ̀ta tó ń bára wọn fa wàhálà ló kún ibẹ̀, wọ́n ń lo oògùn olóró, wọ́n ń bára wọn lò pọ̀, wọ́n ń sọ̀rọ̀ rírùn, wọ́n ń hùwà ipá, wọ́n ń gún àwọn èèyàn yánnayànna, ẹ̀jẹ̀ sì ń ṣàn.” Àwọn eré kan sì wà tó jẹ́ pé iṣẹ́ òkùnkùn ni wọ́n ń gbé lárugẹ. Bí wọ́n bá sì ti ń gbé eré tuntun jáde, ńṣe ló máa ń dà bíi pé ti tẹ́lẹ̀ ò tiẹ̀ burú rárá. Púpọ̀ lára àwọn eré oníwàkiwà yìí làwọn èèyàn sì lè máa báwọn ẹlòmíì ṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ìyẹn sì ti wá sọ àwọn eré wọ̀nyí di ohun tá à bá kúkú máa pè ní àrà mérìíyìírí. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ James sọ pé: “Látorí kọ̀ǹpútà tó wà nínú ilé ẹ, o lè máa báwọn tó ń gbé lápá ibòmíì lórí ilẹ̀ ayé díje.”

Káwọn tó ń ṣeré orí kọ̀ǹpútà máa lo kọ̀ǹpútà láti darí àwọn òṣèré àtọwọ́dá ti wá gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta báyìí. Bí wọ́n ṣe ń ṣe é ni pé, àwọn òṣèré tó jẹ́ èèyàn gidi á yan àwọn òṣèré àtọwọ́dá tí wọ́n á máa fi kọ̀ǹpútà darí, ó lè dà bí èèyàn, ẹranko, tàbí kó jẹ́ ṣènìyàn-ṣẹranko. Ó ní ibì kan táwọn òṣèré àtọwọ́dá tí wọ́n yàn yìí àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún òṣèré àtọwọ́dá tó jẹ́ tàwọn míì máa ń wà lórí ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ilé ìtajà, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ibùgbé, ilé ijó àti ilé aṣẹ́wó tún máa ń wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Ká ṣáà sọ pé ibẹ̀ dà bí ayé kan lọ́tọ̀. Àwọn tó ń fi kọ̀ǹpútà darí àwọn òṣèré àtọwọ́dá náà lè yára máa kọ̀wé ránṣẹ́ síra wọn bí wọ́n bá ṣe ń fàwọn òṣèré náà pitú lọ́wọ́.

Àwọn oníjàgídíjàgan, àwọn tó ń báwọn aṣẹ́wó wá oníbàárà, àwọn aṣẹ́wó, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, àwọn gbájúẹ̀, àtàwọn apààyàn, wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára àwọn òṣèré àtọwọ́dá tí wọ́n fi ń hùwà ipá lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àwọn tó ń ṣe àwọn eré orí kọ̀ǹpútà wọ̀nyí tí sọ àwọn ìwà tí wọn ò jẹ́ dán wò lójú ayé dàṣà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bí wọ́n bá ti tẹ àwọn bọ́tìnnì bíi mélòó kan, àwọn òṣèré àtọwọ́dá náà á bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn lò pọ̀, àwọn èèyàn tó ń fi kọ̀ǹpútà darí wọn á sì máa fi lẹ́tà orí Íńtánẹ́ẹ̀tì bára wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Àwọn eré orí kọ̀ǹpútà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n ṣe láti jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn òṣèré àtọwọ́dá tí wọ́n ṣe bí àgbàlagbà láti máa báwọn òṣèré àtọwọ́dá tí wọ́n ṣe bí ọmọdé lò pọ̀. Àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọminú pé àwọn èèyàn máa tó bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tí kò bófin mu lórúkọ eré.

Rò Ó Kó O Tó Ṣe É

Àwọn tó ń fàwọn òṣèré àtọwọ́dá hùwà ipá tàbí tí wọ́n ń fi wọ́n ṣèṣekúṣe lórí kọ̀ǹpútà lè sọ pé: “Kò sóhun tó fi ń ṣèèyàn. Kì í kúkú ṣòótọ́. Eré lásán ṣáà ni.” Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni firú èrò èké bẹ́ẹ̀ tàn ẹ́ jẹ o!

Bíbélì sọ pé: ‘Ìṣe ọmọdé pàápàá ni a fi í mọ̀ ọ́n, bí ìwà rẹ̀ ṣe rere àti títọ́.’ (Òwe 20:11, Bibeli Mimọ) Bó o bá ń fi kọ̀ǹpútà hùwà ipá, tó o sì fi ń ṣèṣekúṣe, ǹjẹ́ a lè sọ pé o ní ọkàn rere àti ọkàn títọ́? Ìwádìí ti fi hàn léraléra pé wíwò táwọn kan ń wo eré ìnàjú tí wọ́n ti ń hùwà ipá, túbọ̀ ń mú kí wọ́n di oníjàgídíjàgan. Kódà, àwọn tó mọ̀ nípa eré orí kọ̀ǹpútà sọ pé nítorí pé ẹnì kan kì í dá ṣe eré orí kọ̀ǹpútà, ó máa ń nípa lórí àwọn èèyàn ju tẹlifíṣọ̀n lọ.

Ńṣe ni yíyàn láti máa fi kọ̀ǹpútà hùwà ipá tàbí láti máa fi ṣèṣekúṣe dà bí ìgbà téèyàn bá ń fi àlòkù agolo nǹkan olóró ṣeré. Èèyàn lè má tètè rí i pé ó ń ṣèpalára, àmọ́ ó máa pàpà lẹ́yìn. Lọ́nà wo? Béèyàn bá ń fimú kó òórùn ohun olóró lemọ́lemọ́ ó lè ba àgọ́ ara jẹ́ kó sì jẹ́ káwọn kòkòrò àrùn tó wà nínú ìfun rọ́ lọ sínú ẹ̀jẹ̀ tó ń yíká ara, bí àìsàn á ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ bó o bá ń wo ìṣekúṣe àti ìwà ipá, wọ́n lè ba “agbára òye” rẹ jẹ́, kí wọ́n wá jẹ́ kó o máa ro èròkerò kó o sì máa ṣèṣekúṣe.—Éfésù 4:19; Gálátíà 6:7, 8.

Irú Eré Wo Ló Yẹ Kí N Máa Ṣe?

Báwọn òbí rẹ bá gbà pé kó o máa ṣeré orí kọ̀ǹpútà, báwo lo ṣe lè mọ èyí tó yẹ kó o yàn àti bó ṣe yẹ kó o máa pẹ́ tó nídìí ẹ̀? Bi ara ẹ láwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí:

Ojú wo ni Jèhófà máa fi wò mí tó bá ṣàyẹ̀wò irú eré tí mo yàn láti ṣe? Sáàmù 11:5 sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” Ní tàwọn tó ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òkùnkùn, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” (Diutarónómì 18:10-12) Bó o bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ tẹ́tí sí ìmọ̀ràn inú Sáàmù 97:10 tó sọ pé: “Ẹ kórìíra ohun búburú.”

Kí ni eré tí mo bá yàn máa gbìn sí mi lọ́kàn? Bi ara ẹ pé, ‘Bí mo bá ń ṣeré yìí, ṣó máa jẹ́ kó rọrùn fún mi láti “sá fún àgbèrè” àbí ó máa jẹ́ kó ṣòro fún mi? (1 Kọ́ríńtì 6:18) Eré tó bá ń jẹ́ kó o rí àwòrán tó ń mọ́kàn ẹ fà sí ìṣekúṣe tàbí tó ń jẹ́ kó o máa sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ ò ní jẹ́ kó o lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó jẹ́ òdodo, tó jẹ́ mímọ́ níwà, tí kò sì lábààwọ́n.—Fílípì 4:8.

Báwo ló ṣe yẹ kí n máa pẹ́ tó nídìí eré náà? Eré orí kọ̀ǹpútà tó dà bíi pé kò tiẹ̀ léwu rárá pàápàá máa ń gba àkókò tó pọ̀ gan-an. Nítorí náà, máa kọ àkókò tó o fi ń ṣeré orí kọ̀ǹpútà sílẹ̀. Ṣé àkókò tó yẹ kó o máa fi ṣàwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì lo fi máa ń ṣeré orí kọ̀ǹpútà? Bó o bá ń ṣàkọsílẹ̀ bó o ṣe ń lo àkókò ẹ, o ò ní máa fi ohun tó yẹ sílẹ̀ kó o wá máa mú nǹkan míì ṣe.—Éfésù 5:16.

Òótọ́ ni pé Bíbélì ò sọ pé kó o fi gbogbo ọjọ́ ayé ẹ kàwé tàbí kó o máa fi ṣiṣẹ́ ilé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rán gbogbo wa létí pé “ìgbà rírẹ́rìn-ín . . . àti ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri” wà. (Oníwàásù 3:4) Ó dára ká kíyè sí i pé gbólóhùn náà, “títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri” kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ eré ṣíṣe lásán, àmọ́ ó tún ń sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn eré tó gba kéèyàn lo ara ẹ̀. Nítorí náà, o ò ṣe lo díẹ̀ lára àkókò tọ́wọ́ ẹ bá dilẹ̀ láti ṣe eré tó gba pé kó o lo ara ẹ dípò tí wàá fi jókòó gẹlẹtẹ síwájú kọ̀ǹpútà?

Fọgbọ́n Yan Irú Eré Tí Wàá Máa Ṣe

Kò sí iyè méjì pé ṣíṣeré orí kọ̀ǹpútà máa ń dùn mọ́ọ̀yàn, àgàgà téèyàn bá mọwọ́ ẹ̀ dáadáa. Nítorí èyí gan-an ló fi yẹ kó o fọgbọ́n yan irú eré tó o bá fẹ́ máa ṣe. Bi ara ẹ pé, ‘Iṣẹ́ wo ni mo máa ń ṣe dáadáa jù lọ nínú ẹ̀ níléèwé?’ Ìwọ náà mọ̀ pé iṣẹ́ tó o fẹ́ràn jù lọ ni, àbí? Bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn, béèyàn bá ṣe fẹ́ràn iṣẹ́ kan tó, ló ṣe máa nípa lórí èèyàn tó. Wá bi ara ẹ báyìí pé: ‘Eré orí kọ̀ǹpútà wo ni mo kúndùn àtimáa ṣe jù lọ? Ẹ̀kọ́ wo gan-an leré náà sì ń kọ́ mi?’

Dípò kó o kàn máa ṣeré kan torí pé àwọn ẹgbẹ́ ẹ ń ṣerú ẹ̀, dá ìpinnu tìẹ ṣe tìgboyàtìgboyà. Èyí tó sì ṣe pàtàkì ju gbogbo ẹ̀ lọ ni pé kó o fìmọ̀ràn Bíbélì náà sílò pé: “Máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú.”—Éfésù 5:10.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

O fẹ́ràn orin gan-an; kò sóhun tó burú ńbẹ̀. Àmọ́, ṣé orin ló ń darí ìgbésí ayé ẹ?

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ kórìíra ohun búburú.Sáàmù 97:10.

ÌMỌ̀RÀN

Kọ ọ̀rọ̀ ṣókí lórí eré orí kọ̀ǹpútà tó o fẹ́ ṣe, kó o sọ ohun téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe láṣeparí nínú eré yẹn àti béèyàn ṣe máa ṣe é kó lè mókè. Wá fàwọn ìlànà Bíbélì tó o ti kà nínú orí yìí gbé eré náà yẹ̀ wò, bóyá eré tó yẹ kó o ṣe ni tàbí kò yẹ kó o ṣe é.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Ìlú Amsterdam lórílẹ̀-èdè Netherlands ni ilé ìwòsàn àkọ́kọ́ tí wọ́n dìídì ṣe fáwọn tó ti sọ ṣíṣeré kọ̀ǹpútà di bárakú wà, ọdún 2006 ni wọ́n sì dá a sílẹ̀.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí ọ̀rẹ́ mi kan bá ní kí n wá ṣe eré orí kọ̀ǹpútà tó la ìwà ipá tàbí ìṣekúṣe lọ, màá sọ pé ․․․․․

Màá dín iye àkókò tí mo fi ń ṣeré orí kọ̀ǹpútà kù sí ․․․․․ lọ́sẹ̀, mi ò sì ní kọjá àkókò yìí tí mo bá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

Báwo ni eré orí kọ̀ǹpútà ṣe lè nípa lórí béèyàn ṣe ń ronú àti bí nǹkan ṣe ń rí lára èèyàn?

Kí nìdí tó fi yẹ kéèyàn yẹ àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wò kó tó yan eré kan láàyò?

Báwo lo ṣe lè ran àbúrò ẹ kan tó fẹ́ràn láti máa ṣeré orí kọ̀ǹpútà kan tó o mọ̀ pé kò dáa lọ́wọ́?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 249]

“Ọ̀pọ̀ lára eré wọ̀nyí máa ń sọni di ògbólógbòó nínú àwọn nǹkan bí ìwà ipá, ọ̀rọ̀ rírùn àti ìṣekúṣe, ó sì lè jẹ́ kó o kó sínú ìdẹwò báwọn ọ̀ràn míì bá dojú kọ ẹ́. Torí náà, o gbọ́dọ̀ fìṣọ́ra yan irú eré tí wàá máa ṣe.”—Amy

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 250]

Yíyàn láti máa fi kọ̀ǹpútà hùwà ipá tàbí láti máa fi ṣèṣekúṣe dà bí ìgbà téèyàn bá ń fi àlòkù agolo nǹkan olóró ṣeré. Èèyàn lè má tètè rí i pé ó ń ṣèpalára, àmọ́ ó máa pàpà lẹ́yìn