Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Í Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Mi Kó Ìwà Tí Ò Dáa Ràn Mí?

Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Í Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Mi Kó Ìwà Tí Ò Dáa Ràn Mí?

ORÍ 15

Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Í Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Mi Kó Ìwà Tí Ò Dáa Ràn Mí?

“Ọ̀pọ̀ ìṣòro ló máa ń dojú kọni níléèwé, bíi mímu sìgá, lílo oògùn olóró àti ìṣekúṣe. Ìwọ fúnra ẹ mọ̀ pé ohun táwọn ojúgbà ẹ fẹ́ kó o ṣe ò mọ́gbọ́n dání. Àmọ́, wọ́n á bá a débi tíwọ alára fi máa fẹ́ láti fi hàn wọ́n pé o kì í ṣe ọ̀dẹ̀.”—Eve.

KÒ SẸ́NI ti kì í fẹ́ káwọn míì gba tòun. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń rọrùn fáwọn ojúgbà ẹni láti kó ìwà tí ò dáa ranni. Bí àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ pé Kristẹni làwọn òbí ẹ, wàá ti mọ̀ pé àwọn nǹkan bíi kéèyàn ní ìbálòpọ̀ kó tó ṣègbéyàwó tàbí kó máa mutí nímukúmu kò bá Bíbélì mu. (Gálátíà 5:19-21) Àmọ́, irú àwọn nǹkan tí èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ojúgbà ẹ máa fi lọ̀ ẹ́ nìyẹn. Ṣé lẹ́yìn tí wọ́n ti ronú lórí ọ̀rọ̀ náà ni wọ́n pinnu pé ohun táwọn máa ṣe ní tàwọn nìyẹn? Kò dájú. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń jẹ́ pé ẹgbẹ́ tí wọ́n ń kó ló ń nípa lórí wọn. Wọn ò fẹ́ dá yàtọ̀, torí náà wọ́n máa ń jẹ́ káwọn míì yí wọn lọ́kàn pa dà. Ṣé bọ́ràn tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Àbí o nígboyà tó láti má ṣe gba ohun tí kò dáa láyè?

Ó kéré tán, ìgbà kan wà tí ẹ̀gbọ́n Mósè, ìyẹn Áárónì, gba ohun tí kò dáa láyè. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣùrù bò ó, tí wọ́n sì sọ pé kó ṣe ọlọ́run fáwọn, ohun tó ṣe gan-an nìyẹn! (Ẹ́kísódù 32:1-4) Ṣáà rò ó wò ná, Áárónì yìí kan náà ló ko Fáráò lójú, tó sì fìgboyà kéde ìdájọ́ Ọlọ́run lé e lórí. (Ẹ́kísódù 7:1, 2, 16) Àmọ́ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tiẹ̀ kó wàhálà lé e láyà, ó juwọ́ sílẹ̀. Dájúdájú, ó rọrùn fún un láti fìgboyà dúró níwájú Fáráò, ọba Íjíbítì ju kó dàyà kọ àwọn ojúgbà rẹ̀ lọ!

Ìwọ ńkọ́? Ṣó máa ń ṣòro fún ẹ láti dúró lórí ohun tó o bá mọ̀ pé ó tọ́? Ṣó máa wù ẹ́ pé kó o fara balẹ̀ ṣe ohun tó tọ́ níwájú àwọn ojúgbà ẹ láìbẹ̀rù? O ṣe bẹ́ẹ̀! Bó o ṣe lè ṣe é ni pé kó o ti rí i pé wàhálà ń bọ̀ kó o sì pinnu ohun tó o máa ṣe kó tó dé. Àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́rin tó wà nísàlẹ̀ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó yẹ.

1. Fojú sọ́nà. (Òwe 22:3) Èèyàn ti máa ń mọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà pé wàhálà ń bọ̀. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé o rí àwọn ọmọ iléèwé yín kan tí wọ́n ń mu sìgá lọ́ọ̀ọ́kán. Ṣó ṣeé ṣe kí wọ́n fi sìgá yẹn lọ̀ ẹ́? Bó o bá ti ronú ìṣòro tó lè jẹ yọ, wàá ti múra wọn sílẹ̀, yálà láti sọ pé o ò mu tàbí kó o wá bó o ṣe máa gbara ẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn.

2. Ronú. (Hébérù 5:14) O lè bi ara ẹ léèrè pé, ‘Ibo lọ̀rọ̀ yìí á pàpà já sí bí mo bá ṣe ohun táwọn ojúgbà mi ń ṣe?’ Bó o bá ṣèfẹ́ inú àwọn ojúgbà ẹ, ó dájú pé wọ́n á gba tìẹ fúngbà díẹ̀. Àmọ́, bó bá yá ńkọ́, tó bá kù ẹ́ ku àwọn òbí ẹ tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni? Ṣó o ti ṣe tán láti pàdánù ìdúró rere tó o ní lọ́dọ̀ Ọlọ́run nítorí kó o lè tẹ́ àwọn ọmọ iléèwé ẹ lọ́rùn?

3. Pinnu. (Diutarónómì 30:19) Bó pẹ́ bó yá, gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní láti pinnu yálà káwọn jẹ́ olóòótọ́ káwọn sì kó èrè tó wà nídìí ẹ̀ tàbí káwọn jẹ́ aláìṣòótọ́ káwọn sì jìyà àbájáde kíkorò tó máa ń mú wá. Àwọn ọkùnrin bíi Jósẹ́fù, Jóòbù àti Jésù ṣe ìpinnu tó tọ́, àmọ́, Kéènì, Ísọ̀ àti Júdásì yan ohun tí kò tọ́. Ó ti wá kàn ẹ́ báyìí. Kí lo máa ṣe?

4. Ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀. O lè rò pé ohun tó nira jù gan-an nìyí. Ó tì o! Bó o bá ti ronú nípa ibi tó ṣeé ṣe kọ́rọ̀ náà já sí, tó o sì ti pinnu ohun tó o máa ṣe, wẹ́rẹ́ báyìí lo máa sọ ibi tó o dúró sí lórí ọ̀ràn náà, wàá sì rí i pé ohun tó dáa kó o ṣe gan-an nìyẹn. (Òwe 15:23) Má yọra ẹ lẹ́nu, kò dìgbà tó o bá ṣàlàyé rẹpẹtẹ fáwọn ojúgbà ẹ. Bó o bá ṣáà ti sọ pé o ò fẹ́, ọ̀rọ̀ bùṣe. Bó o bá sì fẹ́ mú un dá wọn lójú pé kò sóhun tó lè yí èrò rẹ lórí ọ̀ràn náà pa dà, o lè sọ pé:

“Mi ò sí fún yẹn o!”

“Èmi kì í lọ́wọ́ sírú nǹkan bẹ́ẹ̀ yẹn!”

“Kí ló dé, ó yẹ kẹ́ ẹ ti mọ̀ pé mi ò ní báa yín dá sírú nǹkan bẹ́ẹ̀ yẹn!”

Àṣírí ibẹ̀ ṣáà ni pé kó o tètè jẹ́ kí wọ́n mọ ibi tó o dúró sí, kó o sì sọ ọ́ pẹ̀lú ìdánilójú. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa yà ẹ́ lẹ́nu pé àwọn ojúgbà ẹ máa fi ẹ́ sáyè ẹ̀! Àmọ́, bí wọ́n bá ń fi ẹ́ ṣẹlẹ́yà ńkọ́? Bí wọ́n bá sọ fún ẹ pé, “Kí ló rọ́ lù ẹ́ ná, ìwọ ojo lásán làsàn yìí?” Má ṣe jẹ́ kíyẹn tu irun kankan lára ẹ, ṣe ni wọ́n fẹ́ kó ìwà tí ò dáa ràn ẹ́. Báwo ni wàá ṣe dá wọn lóhùn? Ó kéré tán, ohun mẹ́ta ló wà tó o lè ṣe.

O lè gba èébú náà mọ́ra. (“Kò sírọ́ ńbẹ̀, ojo gbáà ni mí!” Kó o wá ṣàlàyé ìdí tó ò fi lè bá wọn lọ́wọ́ sóhun tí wọ́n ń ṣe.)

O lè bomi paná yẹ̀yẹ́ tí wọ́n fẹ́ fi ẹ́ ṣe nípa sísọ ojú tó o fi wo ọ̀ràn náà, láìbá wọn fà á.

O lè dà á sí wọn lára. Sọ ìdí tó ò fi bá wọn lọ́wọ́ sí i, kó o wá da ọ̀rọ̀ náà sí wọn lára. (“Ṣó tún yẹ kírú yín máa mu sìgá ni!”)

Báwọn ojúgbà ẹ ò bá dẹ́kun láti máa fi ẹ́ ṣẹlẹ́yà, kúrò lọ́dọ̀ wọn! Bó o bá ṣe pẹ́ lọ́dọ̀ wọn tó ni wàá ṣe máa fún wọn lágbára tó. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ṣì máa kúrò lọ́dọ̀ wọn, rántí pé: O kápá wọn. O ò jẹ́ kí wọ́n kó ìwà tí ò dáa ràn ẹ́!

Àwọn kan lára àwọn ojúgbà ẹ lè fi ẹ́ ṣẹlẹ́yà kí wọ́n sì sọ pé o ò lè dá ronú. Àmọ́ ìwọ gan-an lo mọnú rò! Kódà, Jèhófà fẹ́ kó o máa mú un dára lójú pé ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ lohun tó dára jù lọ. (Róòmù 12:2) Wàá ṣe wá jẹ́ káwọn ojúgbà ẹ sọ ẹ́ di ẹni tí wọ́n á máa tì síbí tì sọ́hùn-ún? (Róòmù 6:16) Orí ohun tó o bá ṣáà ti mọ̀ pé ó jẹ́ òótọ́ ni kó o dúró lé!

Òótọ́ tí kò ṣeé já ní koro ni pé àwọn ojúgbà ẹ ò lè ṣe kí wọ́n má kó wàhálà tiwọn lé ẹ láyà. Àmọ́, ìwọ lo mohun tó o fẹ́, ìwọ lo lè sọ ohun tó o fẹ́ fún wọn, ìwọ náà lo sì lè bomi paná wàhálà tí wọ́n bá gbé wá. Torí náà, ọwọ́ ẹ ni gbogbo ẹ̀ kù sí!—Jóṣúà 24:15.

KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 9, NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣó ò ń yọ́ ìwà tí kò tọ́ hù? Kí lo máa rí gbà nídìí ẹ̀ báwọn òbí ẹ bá mọ̀ nípa ẹ̀?

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.Òwe 13:20.

ÌMỌ̀RÀN

Kí ìgboyà tó o ní lè pọ̀ sí i, ka ìrírí tá a tẹ̀ jáde nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní tí wọ́n ti ṣàṣeyọrí nípa dídúró lórí ohun tó tọ́.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Lẹ́yìn ọdún kan tẹ́ ẹ bá ti jáde kúrò níléèwé, kì í ṣe gbogbo àwọn ọmọléèwé yín ni wàá máa rí. Ọ̀pọ̀ lára wọn tiẹ̀ lè máà rántí orúkọ ẹ mọ́. Àmọ́, gbogbo ìgbà lọ̀rọ̀ rẹ á máa jẹ àwọn aráalé ẹ àti Jèhófà Ọlọ́run lógún.—Sáàmù 37:23-25.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Káwọn ojúgbà mi má bàa kó ìwà tí ò dáa ràn mí, màá ․․․․․

Báwọn ojúgbà mi bá fẹ́ fipá mú mi láti lọ́wọ́ sí ìwà tí ò dáa, màá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Lábẹ́ àwọn ipò wo làwọn ìgbésẹ̀ mẹ́rin tá a ṣàlàyé nínú orí yìí ti lè wúlò fún ẹ?

● Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bó o bá ṣe ohun táwọn ojúgbà ẹ fẹ́ kó o ṣe?

● Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà jẹ́ káwọn ojúgbà ẹ mọ èrò ẹ nípa ohun tí wọ́n fi lọ̀ ẹ́?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 131]

“Ọ̀pọ̀ lára àwọn bọ̀bọ́ yẹn ló mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí ni mí, wọ́n sì máa ń fọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí. Bí wọ́n bá fẹ́ bára wọn sọ̀rọ̀ tí kò dáa, wọ́n á ní, ‘Mike, a fẹ́ bọ́ o, bó o bá fẹ́ o lè bẹ́sẹ̀ ẹ sọ̀rọ̀ ká tó bẹ̀rẹ̀.”—Mike

[Àtẹ tó wà ní ojú ìwé 132, 133]

Tí mo kọ èrò mi sí

Mímúra Sílẹ̀ De Ìṣòro

Àpẹẹrẹ

1 Fojú Sọ́nà

Kí nìṣòro náà? Mímu sìgá.

Ibo ló ṣeé ṣe kí n ti bá ìṣòro yìí pà dé? Ẹ̀yin kíláàsì.

2 Ronú

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ bí mo bá ṣe ohun tí wọ́n fi lọ̀ mí?

Màá ba àwọn òbí mi àti Jèhófà nínú jẹ́. Ẹ̀rí ọkàn mi á bà jẹ́. Ó máa ṣòro fún mi láti sọ pé mi ò ṣe tó bá dìgbà míì.

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ bí mi ò bá gbà fún wọn?

Wọ́n lè fi mí ṣẹ̀sín tàbí kí wọ́n máa pè mí lórúkọ tí mi ò jẹ́. Àwọn kan lára àwọn ọmọléèwé mi lè máa sá fún mi. Àmọ́, màá múnú Jèhófà dùn, màá sì túbọ̀ lẹ́mìí àtimáa ṣe ohun tó tọ́.

3 Pinnu

Bí mo bá gbà fáwọn ojúgbà mi, á jẹ́ nítorí pé

Mi ò múra sílẹ̀ dáadáa láti kojú wàhálà tí wọ́n gbé kà mí láyà. Tàbí kí n rò pé ó sàn káwọn ojúgbà mi gba tèmi ju kí n rí ojúure Jèhófà lọ.

Màá kọ ohun tí wọ́n fi lọ̀ mí torí pé

Mo mọ̀ pé inú Jèhófà ò dùn sí sìgá mímu àti pé ó lè ba ìlera mi jẹ́.

4 Ṣe Nǹkan Kan Nípa Ẹ̀

Màá

sọ pé mi ò ṣe, màá sì kúrò níbẹ̀.

Yẹ̀yẹ́ Táwọn Ojúgbà Lè Fi Mí Ṣe

Bí ojúgbà mi bá sọ pé: “Gba sìgá mu jọ̀ọ́. Àbí ẹ̀rù ń bà ẹ́ ni?”

Ohun tí mo lè ṣe ni pé kí n

Gbà á mọ́ra

“O ríyẹn sọ o. Ẹ̀rù sìgá bà mí. Mi ò fẹ́ lárùn káńsà.”

Bomi paná ẹ̀

“Ẹ má wulẹ̀ fi sìgá yín ṣòfò.”

Dà á sí wọn lára

“Ẹ ṣeun, mi ò fẹ́. Èmi ò rò pé irú yín ló yẹ kẹ́ ẹ máa mu sìgá!”

ÀKÍYÈSÍ: Tètè bá ẹsẹ̀ rẹ sọ̀rọ̀ báwọn ojúgbà ẹ ò bá fi ẹ́ lọ́rùn sílẹ̀. Bó o bá ṣe pẹ́ lọ́dọ̀ wọn tó ni wọ́n á ṣe máa yọ ẹ́ lẹ́nu tó. Wàyí o, kọ àwọn ohun tí wàá ṣe sínú àlàfo tó wà lójú ìwé tó kàn.

Mímúra Sílẹ̀ De Ìṣòro

Ṣàdàkọ ojú ìwé yìí!

1 Fojú Sọ́nà

Kí nìṣòro náà? ․․․․․

Ibo ló ṣeé ṣe kí n ti bá ìṣòro yìí pà dé? ․․․․․

2 Ronú

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ bí mo bá ṣe ohun tí wọ́n fi lọ̀ mí?

․․․․․

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ bí mi ò bá gbà fún wọn?

․․․․․

3 Pinnu

Bí mo bá gbà fáwọn ojúgbà mi, á jẹ́ nítorí pé . . .

․․․․․

Màá kọ ohun tí wọ́n fi lọ̀ mí torí pé . . .

․․․․․

4 Ṣe Nǹkan Kan Nípa Ẹ̀

․․․․․

Màá . . .

․․․․․

Yẹ̀yẹ́ Táwọn Ojúgbà Lè Fi Mí Ṣe

Bí ojúgbà mi bá sọ pé: ․․․․․

Ohun tí mo lè ṣe ni pé kí n

Gbà á mọ́ra

․․․․․

Bomi paná ẹ̀

․․․․․

Dà á sí wọn lára

․․․․․

Ìwọ àti òbí ẹ tàbí ọ̀rẹ́ ẹ kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ lè fàwọn ìdáhùn ẹ dánra wò.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 135]

Bó o bá jẹ́ káwọn ojúgbà ẹ nípa lórí ẹ, ò ń fún wọn lágbára láti máa darí gbogbo nǹkan tó o bá ń ṣe nìyẹn o