Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Yíyan Ọ̀rẹ́ Níléèwé?

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Yíyan Ọ̀rẹ́ Níléèwé?

ORÍ 17

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Yíyan Ọ̀rẹ́ Níléèwé?

“Nígbà míì tí mo bá ráwọn ẹgbẹ́ mi níléèwé, mo máa ń ronú pé, ‘Káì, àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà rèé. Ó máa ń wù mí ká jọ máa ṣọ̀rẹ́.’”—Joe.

“Kì í ṣòro fún mi láti lọ́rẹ̀ẹ́ níléèwé. Bí ẹní ń fi àkàrà jẹ̀kọ ni. Ìyẹn gan-an sì lolórí ìṣòro mi.”—Maria.

GBOGBO èèyàn ló fẹ́ kóun lọ́rẹ̀ẹ́, àwọn èèyàn tó ṣeé bá da nǹkan pọ̀, tí wọ́n sì lè dúró tini lọ́jọ́ ìṣòro. Jésù lọ́rẹ̀ẹ́, wọ́n sì jọ máa ń gbádùn ara wọn. (Jòhánù 15:15) Nígbà tó sì tákòókò fún un láti kú lórí igi oró, Jòhánù tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, “ọmọ ẹ̀yìn tí ó nífẹ̀ẹ́,” wà nítòsí. (Jòhánù 19:25-27; 21:20) Irú àwọn ọ̀rẹ́ tíwọ náà fẹ́ nìyẹn, àwọn ọ̀rẹ́ lọ́jọ́ dídùn àti lọ́jọ́ kíkan!

Bóyá o lè máa ronú pé o ti rírú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ níléèwé, ìyẹn ọ̀kan tàbí méjì lára àwọn ọmọ kíláàsì ẹ tẹ́ ẹ jọ mọwọ́ ara yín. Àwọn nǹkan kan wà tẹ́ ẹ jọ fẹ́ràn, ẹ sì máa ń gbádùn bíbára yín sọ̀rọ̀. Lójú tìẹ, wọ́n lè má yẹ lẹ́ni téèyàn lè pè ní ‘ẹgbẹ́ búburú.’ (1 Kọ́ríńtì 15:33) Anne sọ pé: “Ojoojúmọ́ lèèyàn máa ń ráwọn ọmọléèwé ẹni. Torí náà, ara máa ń tuni béèyàn bá wà lọ́dọ̀ wọn. Kì í dà bí ìgbà téèyàn wà lọ́dọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tó ti máa béèrè pé kéèyàn tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ láwọn ìgbà míì kó má bàa ṣìwà hù. O lè túra ká níléèwé.” Yàtọ̀ síyẹn, ó lè jẹ́ pé ojú tí Lois fi ń wo ọ̀ràn náà nìwọ pẹ̀lú fi ń wò ó. Ó sọ pé: “Mo fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ mi níléèwé rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò yàtọ̀ sáwọn yòókù bí wọ́n ṣe máa ń rò, mo fẹ́ kí wọ́n rí i pé àwa náà lajú.” Ṣáwọn ìdí tó bọ́gbọ́n mu tó fi yẹ kó o yan àwọn ọmọléèwé ẹ lọ́rẹ̀ẹ́ nìyí?

Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Ṣọ́ra

Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Maria, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí yẹ̀ wò. Ọlọ́yàyà èèyàn ni, torí náà kì í pẹ́ táwọn míì fi máa ń mú un lọ́rẹ̀ẹ́, àmọ́ ó máa ń ṣòro fún un láti mọ irú àwọn tó yẹ kó bá ṣọ̀rẹ́ gan-an. Ó gbà pé: “Ó máa ń wù mí kí tọkùnrin tobìnrin fẹ́ràn mi. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ mo bẹ̀rẹ̀ sí í bára mi nínú ìṣòro tí mi ò ti ní lè tètè jàjàbọ́.” Bọ́rọ̀ ti Lois náà ṣe rí nìyẹn. Ó sọ pé: “Àwọn ẹgbẹ́ mi kó ìwà wọn ràn mí. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bíi tiwọn.”

Kò yani lẹ́nu pé ibi tọ́rọ̀ náà já sí nìyẹn. Ó ṣe tán, kí ìwọ àtẹnì kan tó lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, ó gbọ́dọ̀ ní nǹkan kan tó pa yín pọ̀. Bó bá jẹ́ pé ìwọ àtàwọn èèyàn tí kì í fàwọn ìlànà inú Ìwé Mímọ́ ṣèwà hù tí wọ́n sì gba ohun tó yàtọ̀ sí tìẹ gbọ́ lò ń bá ṣọ̀rẹ́, mọ̀ dájú pé ó máa nípa lórí ìwà tó ò ń hù. (Òwe 13:20) Ìyẹn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.”—2 Kọ́ríńtì 6:14.

Ohun Tó O Lè Ṣe

Ṣé ohun tí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù túmọ̀ sí ni pé kó o yẹra pátápátá fáwọn ọmọléèwé ẹ, kó o wá máa gbé ìgbé ayé kóńkó jabele? Ó tì o! Káwọn Kristẹni bàa lè ṣe ojúṣe wọn láti “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,” wọ́n gbọ́dọ̀ mọ bí wọ́n á ṣe máa bá onírúurú èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin sọ̀rọ̀ láìka ẹ̀yà, ìsìn, tàbí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn sí.—Mátíù 28:19.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀ fún wa nípa èyí. Ó mọ bó ṣe lè bá “ènìyàn gbogbo” sọ̀rọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó gbà gbọ́ yàtọ̀ sí tiwọn. (1 Kọ́ríńtì 9:22, 23) O lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù. Máa fìfẹ́ hàn sáwọn ojúgbà ẹ. Mọ bó o ṣe lè máa bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń gbéni ró. Àmọ́, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àti ìwà ẹ dà bíi tiwọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, láìfi àkókò falẹ̀ rárá, fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé ìdí tó o fi ń fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù fún wọn.—2 Tímótì 2:25.

Lóòótọ́, wàá yàtọ̀ sáwọn ẹgbẹ́ ẹ, ìyẹn kì í sì í rọrùn. (Jòhánù 15:19) Àmọ́, o ò ṣe wo ọ̀ràn náà báyìí? Bó o bá wà nínú ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi ń gbẹ̀mí là, táwọn èèyàn tó já sómi sì wà yí ẹ ká, báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Ṣé nípa bíbẹ́ sómi ni? Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀!

Bákan náà, àwọn èèyàn tí kò sí lábẹ́ ààbò Jèhófà tíwọ wà ló yí ẹ ká. (Sáàmù 121:2-8) Bó o bá wá ní láti fàwọn ìlànà Jèhófà sílẹ̀ nítorí àtimáa ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú wọn, ńṣe lo wulẹ̀ máa fi àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà sínú ewu tí wàá sì ba ayọ̀ tó yẹ kó o ní jẹ́. (Éfésù 4:14, 15; Jákọ́bù 4:4) Wo bí ì bá ti dáa tó bó o bá gbìyànjú láti ran àwọn ọmọléèwé ẹ lọ́wọ́ láti dara pọ̀ mọ́ ẹ, nínú ohun tá a lè pè ní ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi ń gbẹ̀mí là, nípa fífi bí wọ́n ṣe lè sin Jèhófà hàn wọ́n. Àbí ọ̀nà wo ló dára ju yẹn lọ tó o lè gbà fi hàn pé ọ̀rẹ́ àtàtà ni ẹ́?

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Mo ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè di alájọpín nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.1 Kọ́ríńtì 9:23.

ÌMỌ̀RÀN

Bó o bá rí lára àwọn ọmọ kíláàsì ẹ tí wọ́n ń fẹ́ láti mọ̀ nípa àwọn ohun tó o gbà gbọ́, jẹ́ káwọn náà sọ èrò tiwọn. Tẹ́tí sí wọn tọkàntọkàn. Bó o bá sì máa sọ̀rọ̀, sọ ọ́ “pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”—1 Pétérù 3:15.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń sin Ọlọ́run lónìí ló jẹ́ pé látọ̀dọ̀ àwọn ọmọléèwé wọn tí wọ́n fìgboyà sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ni wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí mo bá rí i pé wọlé wọ̀de èmi àti ọmọ kíláàsì mi kan ti fẹ́ máa pọ̀ jù, màá

Bí ọmọléèwé mi kan bá ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ohun tí mo gbà gbọ́, ohun tí màá ṣe ni pé

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí ló mú kó o rò pé ó máa rọrùn láti yan ọ̀rẹ́ níléèwé ju kéèyàn yan ọ̀rẹ́ nínú ìjọ Ọlọ́run lọ?

● Àwọn ewu wo ló wà nínú kéèyàn máa ṣe fàájì pẹ̀lú ọmọléèwé ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lẹ́yìn iléèwé?

● Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú jíjẹ́ káwọn ọmọléèwé ẹ mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 143]

“Mo máa ń ṣe bíi tàwọn ẹgbẹ́ mi níléèwé, torí náà ó rọrùn láti rẹ́ni bá ṣọ̀rẹ́ níbẹ̀. Àmọ́, mo kẹ́kọ̀ọ́ lára àṣìṣe tí mo ṣe. Ní báyìí, inú ìjọ ni mo lọ́rẹ̀ẹ́ sí, àwọn ọ̀rẹ́ tí mo lè gbára lé.”—Daniel

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 146]

Ọ̀nà wo ló dáa jù lọ láti gbà ran ẹni tó bá já sómi lọ́wọ́, ṣé nípa bíbẹ́ sómi ni àbí nípa bíbá a wá ohun tó lè gbẹ̀mí ẹ̀ là?