Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ló Yẹ Kí N Sọ Fún Bí Mo Bá Ń Yọ́ Ìwà Tí Kò Tọ́ Hù?

Ta Ló Yẹ Kí N Sọ Fún Bí Mo Bá Ń Yọ́ Ìwà Tí Kò Tọ́ Hù?

ORÍ 16

Ta Ló Yẹ Kí N Sọ Fún Bí Mo Bá Ń Yọ́ Ìwà Tí Kò Tọ́ Hù?

□ Mímu ọtí líle

□ Kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn táwọn òbí ẹ kà sí ẹgbẹ́ búburú

□ Gbígbọ́ orinkórin

□ Lílọ síbi àríyá aláriwo

□ Fífẹ́ra ẹni ní bòókẹ́lẹ́

□ Wíwo fíìmù tí wọ́n ti ń hùwà ipá tàbí tí wọ́n ti ń ṣèṣekúṣe tàbí fífi eré orí kọ̀ǹpútà hùwà ipá

□ Ṣíṣépè

WO ÀWỌN gbólóhùn tá a tò sójú ìwé tó ṣáájú èyí tó ò ń kà yìí. Ǹjẹ́ o máa ń yọ́ èyíkéyìí lára àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ṣe táwọn òbí ẹ ò bá sí níbẹ̀? Bó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ náà ò ní ṣaláìmọ̀ pé ohun tó ò ń ṣe ò dáa. Ẹ̀rí ọkàn tiẹ̀ lè máa dá ẹ lẹ́bi. (Róòmù 2:15) Síbẹ̀, kò sẹ́ni tó máa wù láti sọ àwọn àṣìṣe ẹ̀ fáwọn òbí ẹ̀. Bó o bá sì ro ti bó ṣe máa dun àwọn òbí ẹ tó, ó ṣeé ṣe kí èrò náà pé “Ohun táwọn òbí mi ò bá mọ̀ ò lè bà wọ́n lọ́kàn jẹ́” bọ́gbọ́n mu lójú ẹ. Àmọ́, ṣó o ti rò ó wò pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé o ti ń yọ́ ìwà tí kò tọ́ hù? Kí ló lè fà á tó o fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ yẹn ná?

Fífẹ́ Láti Wà Lómìnira

Bíbélì sọ pé bó bá yá “ọkùnrin [á] fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Bọ́rọ̀ obìnrin náà sì ṣe máa ń rí nìyẹn. Ó bá ìwà ẹ̀dá mu pé kéèyàn fẹ́ láti dàgbà, kó máa dá ronú, kó sì máa dá ṣe ìpinnu. Àmọ́, nígbà táwọn òbí bá kọ̀ láti yọ̀ǹda fáwọn ọmọ láti ṣe ohun tí wọ́n rí i pé kò bọ́gbọ́n mu tàbí tí wọ́n rí i pé kò dára, ńṣe làwọn ọ̀dọ́ kan máa ń yawọ́.

Lóòótọ́, ó lè dà bíi pé àwọn òbí kan ti le koko jù. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Kim ṣàròyé pé: “Wọn kì í jẹ́ ká wo fíìmù kankan.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Dádì mi ti ṣòfin pé àwọn ò gbọ́dọ̀ rí i ká tẹ́tí sí orin èyíkéyìí!” Báwọn ọ̀dọ́ kan bá dojú kọ irú ìkálọ́wọ́kò tí wọ́n kà sí èyí tí kò bọ́gbọ́n mu bí èyí, ńṣe ni wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí jowú àwọn ojúgbà wọn, tó dà bíi pé wọ́n ń gbádùn òmìnira tó ju tiwọn lọ.

Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Tammy ṣàlàyé ìdí mìíràn táwọn kan fi máa ń yọ́ ìwà tí kò tọ́ hù, ìyẹn ni káwọn ọmọléèwé wọn bàa lè gba tiwọn. Tammy rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Orí kí n máa ṣépè níléèwé ni mo ti bẹ̀rẹ̀. Ó máa ń ṣe mí bíi pé èmi náà ti tẹ́gbẹ́. Nígbà tó yá mo tọ́ sìgá mímu wò. Mo tún máa ń mu ọtí líle títí tá á fi máa pa mí. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kó ọ̀rẹ́kùnrin jọ ní bòókẹ́lẹ́ torí pé àwọn òbí mi le koko, wọn ò sì gbà kí n máa bá ọkùnrin jáde.”

Bọ́ràn ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Pete náà ṣe rí nìyẹn. Ó sọ pé: “Wọ́n tọ́ mi dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ ẹ̀rù pé wọ́n á fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ ń bà mí.” Ọgbọ́n wo wá ni Pete dá sí ẹ̀rù tó ń bà á? Ó sọ pé: “Mo gbìyànjú láti di gbajúmọ̀. Mo máa ń purọ́, mo sì máa ń wí àwíjàre láti ṣàlàyé ìdí tí mi kì í fi í gbẹ̀bùn ọdún.” Kò pẹ́ kò jìnnà tí Pete bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn ìlànà Kristẹni lójú díẹ̀díẹ̀ títí tó fi dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì.

Kò Sóhun Tó Fara Sin fún Jèhófà

Kéèyàn máa yọ́ ìwà tí kò tọ́ hù kì í ṣe nǹkan tuntun. Àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì náà dá a bí ọgbọ́n láwọn ìgbà kan. Àmọ́, wòlíì Aísáyà kìlọ̀ fún wọn pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń lọ jinlẹ̀-jinlẹ̀ nínú fífi ète pa mọ́ kúrò lójú Jèhófà tìkára rẹ̀, àti àwọn tí iṣẹ́ wọn ti wáyé ní ibi tí ó ṣókùnkùn, nígbà tí wọ́n ń sọ pé: ‘Ta ní ń rí wa, ta sì ni ó mọ̀ nípa wa?’” (Aísáyà 29:15) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà gbé pé Ọlọ́run ń rí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. Nígbà tí àsìkò tó lójú ẹ̀, ó mú kí wọ́n dáhùn fún gbogbo àṣìṣe wọn.

Bọ́ràn ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Bó bá tiẹ̀ ṣeé ṣe fún ẹ láti fi ìwà tí kò tọ́ pa mọ́ fáwọn òbí ẹ, o ò lè fi ìwà tó ò ń hù pa mọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run. Hébérù 4:13 sọ pé: “Kò sì sí ìṣẹ̀dá tí kò hàn kedere sí ojú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” Kí wá nìdí fún bíbo ohun tí ò ṣeé bò? Rántí o, o ò lè tan Ọlọ́run jẹ nípa wíwulẹ̀ fìtara hàn nípa lílọ sáwọn ìpàdé ìjọ. Jèhófà mọ̀ bó bá jẹ́ pé ‘ètè lásán lèèyàn fi ń bọlá fún un, àmọ́ tí ọkàn onítọ̀hún jìnnà sí i.’—Máàkù 7:6.

Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn tó ń yọ́ ìwà tí kò tọ́ hù kì í múnú Jèhófà dùn? Ṣóòótọ́ nìyẹn ṣá? Dájúdájú! Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì kọ òfin Jèhófà sílẹ̀, “wọ́n ṣe ohun tí ó dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.” (Sáàmù 78:41) Ẹ sì wá wo bó ṣe máa dùn ún tó nígbà táwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n fi “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà” kọ́ bá ń yọ́ àwọn nǹkan tí kò dáa ṣe!—Éfésù 6:4.

Mú Àwọn Ọ̀ràn Tọ́

Dandan ni pé kó o jẹ́wọ́ fáwọn òbí ẹ bó o bá ti ń yọ́ ìwà tí kò tọ́ hù. Òótọ́ ni pé ìyẹn lè kótìjú bá ẹ, ó sì lè mú kó o rí ìbínú àwọn òbí ẹ pàápàá. (Hébérù 12:11) Bí àpẹẹrẹ, bó bá ti mọ́ ẹ lára láti máa purọ́ kó o sì máa tan àwọn òbí ẹ jẹ, wàá ti mú kí wọ́n sọ ìgbẹ́kẹ̀lé tí wọ́n ní nínú ẹ nù. Torí náà, má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu bí wọ́n bá ń ká ẹ lọ́wọ́ kò ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Síbẹ̀, jíjẹ́wọ́ ìwà àìtọ́ tó o bá ń hù lohun tó dáa jù lọ. Kí nìdí?

Gbé àkàwé yìí yẹ̀ wò: Jẹ́ ká sọ pé ìwọ, àwọn òbí ẹ, àtàwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ẹ gbafẹ́ lọ síbì kan táwọn nǹkan ọ̀gbìn pọ̀ sí. Kó wá ṣẹlẹ̀ pé nígbà tóhun kan gbàfiyèsí àwọn òbí ẹ, o pa dà lẹ́yìn wọn, o sì gba apá ibòmíì lọ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kìlọ̀ fún ẹ pé kó o má ṣe bẹ́ẹ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, o ò mọ̀nà mọ́. Nígbà tó tiẹ̀ yá, o bẹ̀rẹ̀ sí í rì sínú irà. Ṣé ojú máa tì ẹ́ láti lọgun pé kí wọ́n wá ràn ẹ́ lọ́wọ́? Ṣé ìgbà yẹn ni wàá máa ronú pé àwọn òbí ẹ lè bá ẹ wí torí pé o ṣàìgbọràn sí ìkìlọ̀ tí wọ́n fún ẹ? Rárá o! Ńṣe lo máa figbe ta pé kí wọ́n wá fà ẹ́ yọ.

Bó ṣe rí náà nìyẹn bó o bá ń yọ́ ìwà tí kò tọ́ hù. Rántí pé kò sóhun tó o lè ṣe nípa ìwà tó o ti hù kọjá, àmọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè ṣe nípa ìwà tó ò tíì hù. Torí náà, bó ti wù kó nira tó, irú ìṣòro yòówù tí ì báà fà, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o wá ìrànlọ́wọ́ kó tó di pé wàá para ẹ tàbí ìdílé ẹ lára ju bó ṣe yẹ lọ. Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo kábàámọ̀ ìwà tó ò ń hù, Jèhófà máa fàánú hàn sí ẹ.—Aísáyà 1:18; Lúùkù 6:36.

Torí náà, sọ òtítọ́ fáwọn òbí ẹ. Gbà pé lóòótọ́ ló yẹ kọ́rọ̀ náà dùn wọ́n. Gba ìbáwí tí wọ́n bá fún ẹ. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá mú inú àwọn òbí ẹ àti inú Jèhófà Ọlọ́run dùn. Ọkàn ẹ á sì tún balẹ̀ pé o ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ gaara.—Òwe 27:11; 2 Kọ́ríńtì 4:2.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń da ìwọ àtàwọn ọmọléèwé yín pọ̀. Àmọ́, kí lo gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa bíbá àwọn ọmọléèwé ẹ ṣọ̀rẹ́?

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.Òwe 28:13.

ÌMỌ̀RÀN

Má ṣe máa fọ̀rọ̀ bo àṣìṣe rẹ mọ́lẹ̀, má sì tún le koko mọ́ra ẹ jù. Rántí pé Jèhófà múra tán láti dárí jini.—Sáàmù 86:5.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Ó dáa kí ọkàn ẹni máa dáni lẹ́bi; ìyẹn ló máa jẹ́ kéèyàn tètè tún ìwà tí kò bá tọ́ ṣe. Àmọ́, béèyàn bá ń bá a nìṣó láti máa dẹ́ṣẹ̀, ńṣe lá máa ba ẹ̀rí ọkàn ara ẹ̀ jẹ́. Ẹ̀rí ọkàn ò wá ní dá a lẹ́bi mọ́, torí pé á ti gíràn-án.—1 Tímótì 4:2.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí mo bá ti ń yọ́ ìwà tí kò tọ́ hù, màá sọ fún ․․․․․

Mo lè fara mọ́ ìbáwí èyíkéyìí tí wọ́n bá fún mi nípa ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí ló fà á táwọn ọ̀dọ́ kan fi máa ń yọ́ ìwà tí kò tọ́ hù?

● Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tó máa ń yọrí sí béèyàn bá ń yọ́ ìwà tí kò tọ́ hù?

● Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn jáwọ́ nínú gbígbé irú ìgbé ayé bẹ́ẹ̀?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 140]

“Mo ronú pé ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa tètè jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tó gbọ́dọ̀ máa hùwà títọ́ nígbà gbogbo. Bí wọ́n bá ṣe jẹ́ kó pẹ́ tó káwọn èèyàn tó mọ̀ ni nǹkan á ṣe nira fún wọn tó.”—Linda

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 141]

Bí yíyọ́ ìwà tí kò tọ́ hù bá ti mú kọ́rọ̀ ẹ dà bíi tẹni tó ń rì sínú irà, àfi kó o tètè kígbe fún ìrànlọ́wọ́