Ọ̀rọ̀ Rèé O Ẹ̀yin Òbí
Ọ̀rọ̀ Rèé O Ẹ̀yin Òbí
Ẹ̀bùn wo ló dára jù tó o lè fún ọmọ rẹ? Ohun táwọn ọmọ ń fẹ́ pọ̀ díẹ̀. Wọ́n fẹ́ kó o nífẹ̀ẹ́ àwọn dọ́kàn, kó o máa tọ́ àwọn sọ́nà, kó o sì máa dáàbò bo àwọn. Àmọ́ kò sí ẹ̀bùn tó o lè fún wọn tó lè dà bíi kó o kọ́ wọn nípa Jèhófà, kó o sì tún fi òtítọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wọn. (Jòhánù 17:3) Ìmọ̀ Ọlọ́run tó o bá gbìn sí wọn lọ́kàn máa jẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín láti kékeré.—Mátíù 21:16.
Ọ̀pọ̀ àwọn òbí ti rí i pé tí àwọn bá ń kọ́ ọmọ lẹ́kọ̀ọ́, ó máa ń ṣe ọmọ náà láǹfààní tí kò bá gùn púpọ̀. Torí náà, a láyọ̀ láti gbé ìwé yìí jáde, a pe àkòrí rẹ̀ ní Ẹ̀kọ́ Bíbélì. A ṣe àwọn ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ lọ́nà tó rọrùn. Àwọn àwòrán àtàwọn ọ̀rọ̀ tá a kọ síbẹ̀ rọrùn fún àwọn ọmọ ọdún mẹ́ta àti àwọn tí kò tó bẹ́ẹ̀ láti lóye. A tún sọ àwọn ohun tí ẹ̀yin òbí máa ṣe nínú ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan. Ìwé yìí kì í ṣe ohun ìṣeré fún àwọn ọmọdé o. A dìídì ṣe é kẹ́ ẹ lè fi kọ́ àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́, kẹ́ ẹ sì jọ máa kà á ni.
Ó dá wa lójú pé ìwé yìí máa wúlò fún yín láti fi kọ́ àwọn ọmọ yín ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ látinú Bíbélì “láti ìgbà ọmọdé jòjòló.”—2 Tímótì 3:14, 15.
Àwa arákùnrin yín,
Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]