Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àṣírí Mímọ́ ti Ọlọ́run—Ọ̀nà Ológo Tó Gbà Parí!

Àṣírí Mímọ́ ti Ọlọ́run—Ọ̀nà Ológo Tó Gbà Parí!

Orí 26

Àṣírí Mímọ́ ti Ọlọ́run—Ọ̀nà Ológo Tó Gbà Parí!

1. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé a ti mú àṣírí ọlọ́wọ̀ náà wá sí ìparí? (b) Kí nìdí tí ogunlọ́gọ̀ àwọn áńgẹ́lì fi gbóhùn sókè?

 ǸJẸ́ o rántí ọ̀rọ̀ ìbúra tí áńgẹ́lì alágbára náà sọ, èyí tó wà nínú Ìṣípayá 10:1, 6, 7? Ó sọ pé: “Kì yóò sí ìjáfara kankan mọ́; ṣùgbọ́n ní àwọn ọjọ́ ìró ti áńgẹ́lì keje, nígbà tí ó máa tó fun kàkàkí rẹ̀, àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ìhìn rere tí ó polongo fún àwọn ẹrú tirẹ̀, àwọn wòlíì ni a mú wá sí ìparí ní tòótọ́.” Àkókò ti tó lójú Jèhófà láti mú kí kàkàkí ìkẹyìn náà dún! Nítorí náà, báwo la ṣe mú àṣírí ọlọ́wọ̀ náà wá sí ìparí? Inú Jòhánù dùn gan-an láti sọ fún wa! Ó kọ̀wé pé: “Áńgẹ́lì keje sì fun kàkàkí rẹ̀. Ohùn rara sì dún ní ọ̀run, pé: ‘Ìjọba ayé di ìjọba Olúwa wa àti ti Kristi rẹ̀, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé àti láéláé.’” (Ìṣípayá 11:15) Ó yẹ kí ogunlọ́gọ̀ àwọn áńgẹ́lì yẹn gbóhùn wọn sókè lóòótọ́, kódà kí ìró ohùn wọn máa dún bí ààrá pàápàá! Nítorí pé tayé-tọ̀run ni ìkéde mánigbàgbé yìí kàn. Gbogbo ẹ̀dá alààyè pátá ló kàn gbọ̀ngbọ̀n.

2. Ìgbà wo ni Jèhófà mú àṣírí ọlọ́wọ̀ náà wá sí ìparí aláyọ̀, kí ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà náà?

2 Tayọ̀tayọ̀ ni àṣírí ọlọ́wọ̀ náà wá sí òpin rẹ̀! Ọ̀nà ológo, ọ̀nà tó ga lọ́lá, la gbà mú un wá sí ìparí aláyọ̀ lọ́dún 1914, nígbà tí Olúwa Jèhófà gbé Kristi rẹ̀ gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Rẹ̀. Nígbà tí Jésù Kristi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso láàárín aráyé tó jẹ́ ọ̀tá, ńṣe ló ń ṣojú fún Baba rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Irú-Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí, ó di Ọba kó bàa lè sọ Ejò náà àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ di òfo kó sì sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè padà, tí àlàáfíà yóò wà nínú rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Sáàmù 72:1, 7) Gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba, Jésù yóò tipa báyìí mú Ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣẹ yóò sì fi Baba rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí “Ọba ayérayé,” ẹni tó gbọ́dọ̀ ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọba Aláṣẹ “títí láé àti láéláé.”—1 Tímótì 1:17.

3. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọba ni Jèhófà Ọlọ́run lọ́jọ́kọ́jọ́, kí nìdí tó fi fàyè sílẹ̀ kí àwọn ọba mìíràn wà lórí ilẹ̀ ayé?

3 Àmọ́, báwo ni “ìjọba ayé [ṣe] di ìjọba Olúwa wa,” Jèhófà? Ṣebí Ọba ni Jèhófà Ọlọ́run lọ́jọ́kọ́jọ́? Òótọ́ ni, nítorí pé ọmọ Léfì náà, Ásáfù, kọrin pé: “Ọlọ́run ni Ọba mi láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.” Onísáàmù mìíràn sì kéde pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba! . . . Ìtẹ́ rẹ fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn; ìwọ wà láti àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sáàmù 74:12; 93:1, 2) Àmọ́, ọgbọ́n Jèhófà ti mú kó yọ̀ǹda fáwọn ọba mìíràn láti wà lórí ilẹ̀ ayé. Nípa báyìí, ọ̀ràn tí Èṣù dá sílẹ̀ ní Édẹ́nì ní ti bóyá àwọn èèyàn lè ṣàkóso ara wọn láìsí ọwọ́ Ọlọ́run níbẹ̀ la ti dán wò lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ìṣàkóso èèyàn ti kùnà, ó sì ti fa ìbànújẹ́ gan-an. Láìsí àní-àní, òótọ́ lọ̀rọ̀ tí wòlíì Ọlọ́run kan sọ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Àtìgbà táwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run ni gbogbo ilẹ̀ ayé pátá ti bọ́ sábẹ́ àkóso “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà,” Sátánì. (Ìṣípayá 12:9; Lúùkù 4:6) Àkókò ti wá tó báyìí fún ìyípadà kan tó fa kíki! Kí Jèhófà lè fi hàn kedere pé ipò òun gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run tọ́ sí òun, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lo àṣẹ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lọ́nà tuntun, ìyẹn ni nípasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà tó gbé kalẹ̀.

4. Nígbà tí fífun àwọn kàkàkí náà ń bá a lọ lọ́dún 1922, kí la gbé lárugẹ? Ṣàlàyé.

4 Nígbà tí fífun kàkàkí méje náà ń bá a lọ lọ́dún 1922, Arákùnrin J. F. Rutherford sọ àsọyé kan tó dá lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà, “Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀” ní àpéjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Cedar Point, Ohio. (Mátíù 4:17, Bibeli Mimọ) Ó wá fi gbólóhùn yìí kádìí àsọyé náà pé: “Nígbà náà ẹ padà sí pápá, ẹyin ọmọ Ọlọ́run ọ̀gá ògo jù lọ! Ẹ di ìhámọ́ra yín! Ẹ ṣe gírí, ẹ wà lójúfò, ẹ jẹ́ aláápọn, ẹ jẹ́ akíkanjú. Ẹ jẹ́ ẹlẹ́rìí tó ṣeé gbíyè lé àti olóòótọ́ fún Olúwa. Ẹ tẹ̀ síwájú nínú ìjà náà títí tí gbogbo ìràlẹ̀rálẹ̀ Bábílónì yóò fi dahoro. Ẹ kéde ìhìn náà jìnnà réré. Ayé gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run àti pé Jésù Kristi ni Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa. Ọjọ́ gbogbo àwọn ọjọ́ ni èyí. Ẹ kíyè sí i, Ọba náà ti ń jọba! Ẹ̀yin sì ni aṣojú tó ń lò láti ṣe ìpolongo. Nítorí náà ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.” Ìjọba Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi Jésù wá di èyí tá a gbé lárugẹ, èyí sì mú kí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà tẹ̀ síwájú gan-an. Lára àwọn ohun tí iṣẹ́ ìwàásù yìí sì dá lé lórí ní ìdájọ́ táwọn áńgẹ́lì tó ń fun àwọn kàkàkí méjèèje náà ń kéde.

5. Lọ́dún 1928, kí ló ṣẹlẹ̀ ní àpéjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì èyí tó tẹnu mọ́ ìró kàkàkí keje?

5 Ní àpéjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wáyé nílùú Detroit, ìpínlẹ̀ Michigan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní July 30 sí August 6, ọdún 1928, ìró kàkàkí áńgẹ́lì keje fara hàn nínú àwọn kókó àpéjọ náà. Lákòókò yẹn, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn mẹ́tàdínláàádọ́fà [107] lo gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà jáde bó ti ń lọ lọ́wọ́. Ìwé ìròyìn tó ń jẹ́ The New York Times pe ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ní ‘títa ọ̀rọ̀ orí rédíò látagbà, èyí tó tíì gbówó lórí jù lọ látọjọ́ táláyé ti dáyé.’ Tayọ̀tayọ̀ làwọn tó pé jọ náà fi tẹ́wọ́ gba ìkéde kan tó lágbára, ìyẹn ni “Ìpolongo Láti Ta Ko Sátánì àti Láti Ṣètìlẹyìn fún Jèhófà,” èyí tó ń tọ́ka sí ìbìṣubú Sátánì àti ètò ibi rẹ̀ ní Amágẹ́dọ́nì àti dídá gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo sílẹ̀ lóko ẹrú. Inú àwọn adúróṣinṣin ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run dùn gan-an nígbà tí wọ́n gba ìtẹ̀jáde kan ní àpéjọ náà, ìyẹn ìwé olójú ewé 368 tó ń jẹ́ Government. Ìwé yìí pèsè àwọn àmì tó ṣe kedere jù lọ “pé Ọlọ́run gbé Ọba rẹ̀ tó jẹ́ Ẹni Àmì Òróró ka orí ìtẹ́ lọ́dún 1914.”

Jèhófà Gba Àkóso

6. Báwo ni Jòhánù ṣe ròyìn ìkéde náà pé a gbé Kristi gorí ìtẹ́ nínú Ìjọba Ọlọ́run?

6 Kristi gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba Ìjọba Ọlọ́run, ẹ sì wo bí ìkéde yìí ṣe yọrí sí ayọ̀ ńláǹlà! Jòhánù ròyìn pé: “Àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún tí wọ́n jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn sì dojú bolẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run, wí pé: ‘A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè, Ẹni tí ń bẹ, tí ó sì ti wà, nítorí o ti gba agbára ńlá rẹ, o sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba.’”—Ìṣípayá 11:16, 17.

7. (a) Báwo ni àṣẹ́kù àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún ìṣàpẹẹrẹ náà ṣe fi ọpẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé? (b) Báwo làwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún ìṣàpẹẹrẹ tá a ti jí dìde sí ipò wọn ní ọ̀run ṣe fi ọpẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run?

7 Àwọn tó ń fi ọpẹ́ yìí fún Jèhófà Ọlọ́run làwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] náà, tí wọ́n dúró fáwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi nínú ipò wọn ní ọ̀run. Láti ọdún 1922 síwájú ni ọwọ́ àṣẹ́kù ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] àwọn ẹni àmì òróró tó ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé wọ̀nyí ti dí lẹ́nu iṣẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu nípasẹ̀ àwọn ìró kàkàkí náà. Wọ́n wá túbọ̀ lóye bí àmì inú Mátíù 24:3–25:46 ṣe ṣe pàtàkì gan-an tó. Àmọ́ ṣá o, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa pàápàá, àwọn ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n ti “jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú” la ti jí dìde sí ipò wọn ní ọ̀run kí wọ́n bàa lè máa ṣojú nísinsìnyí fún àwùjọ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà [144,000] lápapọ̀, láti dojú bolẹ̀ fún Jèhófà kí wọ́n sì fìbà fún un. (Ìṣípayá 1:10; 2:10) Gbogbo àwọn wọ̀nyí kún fún ọpẹ́ gan-an pé Olúwa Ọba Aláṣẹ wọn kò jáfara láti mú àṣírí mímọ́ rẹ̀ wá sí ìparí pátápátá!

8. (a) Ìyọrísí wo ni fífun kàkàkí keje ní lórí àwọn orílẹ̀-èdè? (b) Ta làwọn orílẹ̀-èdè ń bínú sí?

8 Àmọ́ ṣá o, fífun kàkàkí keje kò mú ìdùnnú kankan wá fún àwọn orílẹ̀-èdè. Àkókò ti tó fún wọn láti rí ìbínú Jèhófà. Gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ṣe sọ: “Ṣùgbọ́n àwọn orílẹ̀-èdè kún fún ìrunú, ìrunú tìrẹ sì dé, àti àkókò tí a yàn kalẹ̀ láti ṣèdájọ́ àwọn òkú, àti láti fi èrè wọn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ wòlíì àti fún àwọn ẹni mímọ́ àti fún àwọn tí ń bẹ̀rù orúkọ rẹ, ẹni kékeré àti ẹni ńlá, àti láti run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) Látọdún 1914 wá làwọn orílẹ̀-èdè ayé ti ń bínú kíkankíkan sí ara wọn, sí Ìjọba Ọlọ́run àti pàápàá jù lọ sáwọn ẹlẹ́rìí méjì ti Jèhófà.—Ìṣípayá 11:3.

9. Báwo làwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń pa ilẹ̀ ayé run, kí sì ni Ọlọ́run ti pinnu láti ṣe nípa rẹ̀?

9 Látìgbà ìwáṣẹ̀ làwọn orílẹ̀-èdè ti ń run ilẹ̀ ayé nítorí ogun tí wọ́n ń jà nígbà gbogbo àti nítorí ọ̀nà tí kò bójú mu tí wọ́n ń gbà bójú tó àwọn nǹkan. Ṣùgbọ́n láti ọdún 1914, bí wọ́n ṣe ń ba ilẹ̀ ayé jẹ́ yìí ti wá le sí i débi tó fi ń kó ìdààmú báni. Ìwọra àti ìwà ìbàjẹ́ ti mú kí ọ̀pọ̀ ilẹ̀ túbọ̀ máa di aṣálẹ̀ tí àwọn ilẹ̀ tó lè mú oúnjẹ jáde sì ń pòórá lọ́nà tó kàmàmà. Omi òjò tó ní èròjà olóró nínú ti ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbègbè jẹ́. Ọ̀pọ̀ ibi ti oúnjẹ ti ń wá làwọn èèyàn ti sọ di eléèérí. Atẹ́gùn tá à ń mí sínú àti omi tá à ń mu sì ti di eléèérí. Àwọn ìdọ̀tí tó ń wá látinú àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá fẹ́ fòpin sí ìwàláàyè àwọn nǹkan tó ń gbé lórí ilẹ̀ àti nínú òkun. Àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ alágbára láyé tiẹ̀ fẹ́ pa ayé run pátápátá nígbà kan nípa fífi ohun ìjà runlérùnnà pa ìran èèyàn run yán-ányán-án. Àmọ́ a láyọ̀ pé, Jèhófà yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” Yóò mú ìdájọ́ wá sórí àwọn agbéraga èèyàn tí wọn ò bẹ̀rù Ọlọ́run wọ̀nyẹn, tí wọ́n mú kí ilẹ̀ ayé wà ní ipò burúkú tó wà. (Diutarónómì 32:5, 6; Sáàmù 14:1-3) Ìdí nìyí tí Jèhófà fi ṣe ṣètò fún ègbé kẹta, kó lè mú kí àwọn oníwà àìtọ́ yìí dáhùn fún àwọn ohun tí wọ́n ṣe.—Ìṣípayá 11:14.

Ègbé Ni Fáwọn Tó Ń Ba Ilẹ̀ Ayé Jẹ́!

10. (a) Kí ni ègbé kẹta? (b) Ọ̀nà wo ni ègbé kẹta gbà mú ohun tó ju ìdálóró lọ wá?

10 Ègbé kẹta ọ̀hún nìyí. Ó sì ń bọ̀ kíákíá! Òun ni Jèhófà yóò lò láti mú ìparun wá sórí àwọn tí ń ba “àpótí ìtìsẹ̀” rẹ̀ jẹ́, ìyẹn ilẹ̀ ayé tó lẹ́wà tí à ń gbé yìí. (Aísáyà 66:1) Ìjọba Mèsáyà, tó jẹ́ àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run ló mú egbé yìí wá. Ègbé méjì àkọ́kọ́ ti dá àwọn ọ̀tá Ọlọ́run lóró, pàápàá àwọn aṣáájú ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì. Ìdálóró yìí sì wá ní pàtàkì látinú ìyọnu eéṣú àti agbo àwọn agẹṣinjagun. Ṣùgbọ́n ohun tó máa jẹ́ àbájáde ègbé kẹta tó ti ọwọ́ Ìjọba Jèhófà fúnra rẹ̀ wá yóò ju ìdálóró lọ. (Ìṣípayá 9:3-19) Yóò fa ọgbẹ́ ikú ní ti pé á lé àwùjọ ẹ̀dá èèyàn tí ń ṣèparun àtàwọn olùṣàkóso rẹ̀ jáde. Èyí ni Jèhófà yóò fi ṣe àṣekágbá ìdájọ́ rẹ̀ ní Amágẹ́dọ́nì. Bí Dáníẹ́lì ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́ ló rí pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [àwọn alákòóso tí ń pa ilẹ̀ ayé run], Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Bí òkè títóbi kan, Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe àkóso lé ayé lórí, ìyẹn ilẹ̀ ayé tí a ó sọ di ológo, yóò sì fi hàn pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mú ìdùnnú ayérayé wá fún aráyé.—Dáníẹ́lì 2:35, 44; Aísáyà 11:9; 60:13.

11. (a) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ aláyọ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ wo ni àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ nípa rẹ̀? (b) Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí wo la máa rí gbà, ọ̀nà wo la ó fi rí i gbà, ta ló sì fi fúnni?

11 Àwọn nǹkan aláyọ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí tí yóò sì máa ṣẹlẹ̀ nìṣó ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé jálẹ̀ ọjọ́ Olúwa, ń bá ègbé kẹta rìn. Ó jẹ́ àkókò ‘fún ṣíṣèdájọ́ àwọn òkú, àti fún Ọlọ́run láti fi èrè fún àwọn ẹrú rẹ̀ wòlíì àti fún àwọn ẹni mímọ́ àti fún àwọn tí ń bẹ̀rù orúkọ rẹ̀.’ Àjíǹde kúrò nínú ikú lèyí túmọ̀ sí o! Ní ti àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ẹni mímọ́ tí wọ́n ti sùn nínú ikú, èyí ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa. (1 Tẹsalóníkà 4:15-17) Bí àkókò ti ń lọ, àwọn ẹni mímọ́ tí wọ́n ṣẹ́ kù ń dara pọ̀ mọ́ àwọn wọ̀nyí nípasẹ̀ àjíǹde ojú ẹsẹ̀. Àwọn yòókù pẹ̀lú ni a ó san èrè fún, títí kan àwọn ẹrú Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ wòlíì láyé ìgbàanì àti gbogbo àwọn yòókù lára aráyé tí wọ́n bẹ̀rù orúkọ Jèhófà. Yálà wọ́n jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá tí yóò la ìpọ́njú ńlá já tàbí wọ́n jẹ́ ara “àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré,” tí yóò jí dìde sí ìyè nígbà Ẹgbẹ̀rún ọdún Ìjọba Kristi. Níwọ̀n bí Mèsáyà Ọlọ́run tó jẹ́ Ọba ti ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Hédíìsì lọ́wọ́, Ìjọba rẹ̀ á mú kó ṣeé ṣe fún un láti fi ìyè àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tó sapá láti gba ìpèsè tó ṣeyebíye yẹn. (Ìṣípayá 1:18; 7:9, 14; 20:12, 13; Róòmù 6:22; Jòhánù 5:28, 29) Yálà ìyè àìleèkú ní ọ̀run tàbí ìyè ayérayé lórí ilẹ̀ ayé ló jẹ́ ti ẹnì kan, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ẹ̀bùn ìyè yìí jẹ́, èyí tí ẹnì kọ̀ọ̀kan tó bá rí i gbà ní láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún títí láé!—Hébérù 2:9.

Wo Àpótí Májẹ̀mú Rẹ̀!

12. (a) Níbàámu pẹ̀lú Ìṣípayá 11:19, kí ni Jòhánù rí ní ọ̀run? (b) Àmì kí ni àpótí májẹ̀mú náà jẹ́ nígbà kan, kí ló sì ṣẹlẹ̀ sí i lẹ́yìn tí Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì?

12 Jèhófà ti ń ṣàkóso! Nípasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà rẹ̀, ọ̀nà àgbàyanu ló gbà ń lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lórí aráyé. Ohun tí Jòhánù rí báyìí túbọ̀ mú èyí dájú. Ó ní: “A sì ṣí ibùjọsìn tẹ́ńpìlì Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run, a sì rí àpótí májẹ̀mú rẹ̀ nínú ibùjọsìn tẹ́ńpìlì rẹ̀. Mànàmáná àti ohùn àti ààrá àti ìsẹ̀lẹ̀ àti yìnyín ńlá sì ṣẹlẹ̀.” (Ìṣípayá 11:19) Èyí nìkan ni ìgbà tá a mẹ́nu kan àpótí májẹ̀mú Ọlọ́run nínú ìwé Ìṣípayá. Àpótí ẹ̀rí jẹ́ àmì tó ṣeé fojú rí pé Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀, Ísírẹ́lì. Inú ibi Mímọ́ Jù Lọ ni wọ́n máa ń gbé e sí nínú àgọ́ ìjọsìn àti nínú tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì wá kọ́ lẹ́yìn náà. Ṣùgbọ́n nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni, Jerúsálẹ́mù di ahoro, àpótí májẹ̀mú náà sì pòórá. Ìgbà yẹn làwọn tó jẹ́ aṣojú fún ilé Dáfídì dẹ́kun ‘jíjókòó sórí ìtẹ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba.’—1 Kíróníkà 29:23. a

13. Kí ni rírí tá a rí àpótí májẹ̀mú Ọlọ́run nínú tẹ́ńpìlì ti ọ̀run túmọ̀ sí?

13 Ní báyìí, lẹ́yìn ohun tó ti lé ní ẹgbẹ̀tàlá ọdún [2,600] ọdún, a tún rí Àpótí náà lẹ́ẹ̀kan sí i. Ṣùgbọ́n nínú ìran tí Jòhánù rí, kì í ṣe inú tẹ́ńpìlì orí ilẹ̀ ayé ni àpótí yìí wà. Inú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní ọ̀run ló ti fara hàn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà tún ń ṣàkóso nípasẹ̀ ọba kan tó wá láti ìran Dáfídì, ìran ọlọ́ba. Ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí, Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run la ti gbé Ọba náà, ìyẹn Kristi Jésù gun orí ìtẹ́, èyí sì jẹ́ ipò tó ga gan-an níbi tó ti ń mú àwọn ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ. (Hébérù 12:22) Àwọn orí tó tẹ̀ lé e nínú ìwé ìṣípayá yóò jẹ́ ká rí ìwọ̀nyí.

14, 15. (a) Ní Jerúsálẹ́mù ìgbàanì, ta lẹnì kan ṣoṣo tó máa ń rí àpótí májẹ̀mú náà, kí sì nìdí? (b) Nínú ibùjọsìn tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní ọ̀run, àwọn wo ló ń rí àpótí májẹ̀mú rẹ̀?

14 Ní Jerúsálẹ́mù orí ilẹ̀ ayé ti ìgbàanì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbo gbòò kì í rí Àpótí náà, kódà àwọn àlùfáà tó ń sìn nínú tẹ́ńpìlì pàápàá kì í rí i. Ìdí ni pé inú ibi Mímọ́ Jù Lọ, tí aṣọ ìkélé tó wà ní Ibi Mímọ́ máa ń bò, ló máa ń wà. (Númérì 4:20; Hébérù 9:2, 3) Àlùfáà àgbà nìkan ló máa ń rí i nígbà tó bá wọ ibi Mímọ́ Jù Lọ ní Ọjọ́ Ètùtù tó jẹ́ ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún. Síbẹ̀, nígbà tí wọ́n ṣí ibùjọsìn tẹ́ńpìlì ní ọ̀run, kì í ṣe kìkì Jésù Kristi tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ti Jèhófà nìkan ló rí àpótí ìṣàpẹẹrẹ náà, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tó jẹ́ àlùfáà lábẹ́ rẹ̀, náà rí i, títí kan Jòhánù.

15 Àwọn tá a ti kọ́kọ́ jí dìde sí ọ̀run ń rí àpótí ìṣàpẹẹrẹ yìí ní kedere, nítorí wọ́n ti wà ní àyè wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] tó yí ìtẹ́ Jèhófà ká. Ẹ̀mí Jèhófà sì ti la ẹgbẹ́ Jòhánù lórí ilẹ̀ ayé lọ́yẹ̀ láti rí i pé Jèhófà wà nínú tẹ́ńpìlì Rẹ̀ ti ẹ̀mí. Bẹ́ẹ̀ làwọn àmì sì ti wà láti mú kí aráyé ní gbogbo gbòò mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu yìí. Ìran tí Jòhánù rí sọ nípa mànàmáná, ohùn, ààrá, ìsẹ̀lẹ̀, àti yìnyín. (Fi wé Ìṣípayá 8:5.) Kí làwọn wọ̀nyí dúró fún?

16. Ọ̀nà wo ni mànàmáná, ohùn, ààrá, ìsẹ̀lẹ̀, àti yìnyín ńláǹlà ti gbà ṣẹlẹ̀?

16 Láti ọdún 1914 ni rúgúdù tó légbá kan ti ń ṣẹlẹ̀ lágbo ìsìn. Àmọ́, a láyọ̀ pé bí “ìsẹ̀lẹ̀” yìí ti ń sẹ̀ ni ohùn àwọn tó yara wọn sí mímọ́ ń kéde ìhìn tó ṣe kedere nípa Ìjọba Ọlọ́run tá a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀. Wọ́n ń kéde ‘àwọn ìkìlọ̀ tó dà bí ìjì’ èyí tó ń sán bí ààrá látinú Bíbélì. Bíi mànàmáná, òye tó jinlẹ̀ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ń bù yẹ̀rì lù wọ́n, wọ́n sì ń sọ ọ́ fáyé gbọ́. Wọ́n ti tú àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run tó dà bíi “yìnyín” alunibolẹ̀ dà sórí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti gbogbo ìsìn èké lápapọ̀. Ó yẹ kí gbogbo èyí gba àfiyèsí àwọn èèyàn. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé bíi ti àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù lákòókò Jésù, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn kọ̀ láti kíyè sí ìmúṣẹ àwọn àmì inú ìwé Ìṣípayá yìí.—Lúùkù 19:41-44.

17, 18. (a) Báwọn áńgẹ́lì méje náà ti ń fun kàkàkí wọn, iṣẹ́ wo ló já lé àwọn Kristẹni tó ti ṣe ìyàsímímọ́ léjìká? (b) Báwo làwọn Kristẹni wọ̀nyí ṣe ń rí i dájú pé àwọn ń ṣe iṣẹ́ yìí?

17 Àwọn áńgẹ́lì méje náà ń fun kàkàkí wọn nìṣó, tó jẹ́ àmì àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé níbí. Iṣẹ́ ńlá ló já lé àwọn Kristẹni tó ti ṣèyàsímímọ́ léjìká láti máa pòkìkí àwọn ìkéde wọ̀nyí nìṣó fún aráyé. Tìdùnnú-tìdùnnú ni wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ yẹn! A rí ẹ̀rí èyí ní ti pé, láàárín ogún ọdún péré, ìyẹn látọdún 1986 sí ọdún 2005, iye wákàtí tí wọ́n lò lọ́dọọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn kárí ayé fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì iye tí wọ́n ń ròyìn tẹ́lẹ̀. Ó lọ sókè láti 680,837,042 sí 1,278,235,504. Ká sòótọ́, títí dé “ìkángun ilẹ̀ ayé tí a ń gbé” ni wọ́n ń sọ “àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ìhìn rere” di mímọ̀.—Ìṣípayá 10:7; Róòmù 10:18.

18 Nísinsìnyí, àwọn ìran mìíràn ń dúró dè wá bí a ti ń ṣí àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run payá nìṣó.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Róòmù kan tó ń jẹ́ Tacitus sọ pé nígbà tí wọ́n gba ìlú Jerúsálẹ́mù lọ́dún 63 ṣááju Sànmánì Kristẹni, tí Cneius Pompeius sì wọnú ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì náà, kò rí ohunkóhun níbẹ̀. Àpótí májẹ̀mú kò sí nínú rẹ̀.—Ìwé History ti Tacitus, 5.9.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 173]

Àwọn Kókó Pàtàkì Inú Ìdájọ́ Jèhófà Tó Ń Dún Bíi Kàkàkí

1. 1922, ní Cedar Point, Ohio: A ké sáwọn aṣáájú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ìsìn, ìṣèlú, àti òwò aládàá ńlá pé kí wọ́n ṣàlàyé ìdí tí wọn ò fi lè mú àlàáfíà, aásìkí, àti ayọ̀ wá. A kéde pé Ìjọba Mèsáyà ló lè yanjú ìṣòro.

2. 1923, ní Los Angeles, California: A fi àsọyé náà, “Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Ló Ń Lọ sí Amágẹ́dọ́nì, Ṣùgbọ́n Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tí Wọ́n Wà Láàyè Nísinsìnyí Kì Yóò Kú Láé” ké sí “àwọn àgùntàn” tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà pé kí wọ́n kúrò nínú òkun ìran èèyàn tí ń ṣekú pani.

3. 1924, ní Columbus, Ohio: A sọ ní gbangba pé Ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà jẹ́ agbéraga wọ́n sì kọ̀ láti wàásù Ìjọba Mèsáyà. Àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ wàásù ẹ̀san Ọlọ́run kí wọ́n sì tu ìran èèyàn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú.

4. 1925, ní Indianapolis, Indiana: A kéde ọ̀rọ̀ ìrètí tó ń sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín òkùnkùn tẹ̀mí nínú èyí tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì wà, àti ìlérí Ìjọba Ọlọ́run tí ń múnú ẹni dùn èyí tí yóò mú àlàáfíà, aásìkí, ìlera, ìyè, òmìnira àti ayọ̀ ayérayé wá.

5. 1926, ní London, England: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà bá àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn àlùfáà wọn, a tú àṣírí bí wọ́n ṣe kọ Ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀, tí wọn ò sì pòkìkí ìbí ìjọba yẹn.

6. 1927, ní Tòróńtò, Kánádà: Ìpè kan, tó dà bíi pé agbo àwọn agẹṣinjagun ló ń gbé e jáde, ké sáwọn èèyàn pé kí wọ́n kúrò nínú ‘ẹ̀sìn táwọn èèyàn dá sílẹ̀’ kí wọ́n sì fara mọ́ Jèhófà Ọlọ́run àti Ọba rẹ̀ àti Ìjọba rẹ̀.

7. 1928, ní Detroit, Michigan: Ìkéde kan tá a fi ta ko Sátánì tá a sì fi ṣètìlẹ́yìn fún Jèhófà sọ ní kedere pé Ọba tí Ọlọ́run yàn, tó gbé gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914, yóò pa ètò Sátánì tó jẹ́ ibi run, yóò sì dá aráyé nídè kúrò lóko ẹrú.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 175]

Rírun Ilẹ̀ Ayé

“Ní gbogbo ìṣẹ́jú àáyá mẹ́ta ni wọ́n ń pa igbó ẹgàn tó tóbi tó pápá ìṣeré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá run. . . . Pípa àwọn igbó ẹgàn run ń mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀wọ́ àwọn ewéko àti ẹran pa run.”—Illustrated Atlas of the World (Rand McNally).

“Láàárín ọ̀rúndún méjì táwọn èèyàn fi gbé àgbègbè [àwọn adágún omi tá à ń pè ní Great Lakes], wọ́n di adágún omi tó lẹ́gbin jù lọ lágbàáyé.”—The Globe and Mail (Kánádà).

Ní April 1986 ìbúgbàù àti iná tó wáyé nílé iṣẹ́ ẹ̀rọ kan tí wọ́n ti ń ṣe ohun ìjà runlé-rùnnà ní Chernobyl, lórílẹ̀-èdè Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí, “ni ìṣẹ̀lẹ̀ runlé-rùnnà tó kàmàmà jù lọ . . . bá a bá yọwọ́ àdó olóró tí wọ́n jù sí ìlú Hiroshima àti Nagasaki.” Ìdí ni pé, ìṣẹ̀lẹ̀ náà tú “kẹ́míkà olóró tí kò tán bọ̀rọ̀ sínú atẹ́gùn, ilẹ̀ àti omi ayé, èyí sì tó gbogbo àdó olóró tí wọ́n ti jù gẹ́gẹ́ bí ìdánrawò.”—JAMA; The New York Times.

Ní Minamata, Japan, ilé iṣẹ́ kan tó ń ṣe egbòogi tú èròjà olóró methylmercury sínú odò kan tó ya láti ara òkun. Nígbà táwọn èèyàn sì jẹ ẹja àti edé tó ti ní èròjà náà lára, ó fa àrùn Minamata (MD), ìyẹn “akọ àrùn ọpọlọ. . . . Títí di àkókò yìí [1985], ẹgbẹ̀jọ dín méjìlélógún [2,578] èèyàn jákèjádò Japan làwọn dókítà ti rí i pé wọ́n ní àrùn Minamata.”—International Journal of Epidemiology.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 176]

Àwọn ìkéde rírinlẹ̀ tó wà nínú Ìṣípayá 11:15-19 jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń sọ nípa àwọn ìran tó tẹ̀ lé e. Ìṣípayá orí Kejìlá jẹ́ àtúnyẹ̀wò tó ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí àwọn ìkéde àgbàyanu inú Ìṣípayá 11:15, 17. Orí Kẹtàlá fúnni ní ìsọfúnni tí ń lani lóye nípa orí Kọkànlá ẹsẹ kejìdínlógún, nítorí ó sọ ọ̀nà tí ètò ìṣèlú Sátánì tó ti mú ìparun wá sórí ilẹ̀ ayé gbà pilẹ̀ṣẹ̀ tó sì gbèrú. Orí Kẹrìnlá àti Ìkarùndínlógún ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé síwájú sí i nípa àwọn ìdájọ́ Ìjọba Ọlọ́run, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú fífun kàkàkí keje àti ègbé kẹta.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 174]

Jèhófà yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé”