Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Iṣẹ́ Jèhófà Tóbi Wọ́n sì Jẹ́ Àgbàyanu

Àwọn Iṣẹ́ Jèhófà Tóbi Wọ́n sì Jẹ́ Àgbàyanu

Orí 31

Àwọn Iṣẹ́ Jèhófà Tóbi Wọ́n sì Jẹ́ Àgbàyanu

Ìran 10—Ìṣípayá 15:1–16:21

Ohun tó dá lé: Jèhófà nínú ibùjọsìn rẹ̀; àwọn àwokòtò ìrunú rẹ̀ méje ni a dà sí ilẹ̀ ayé

Ìgbà tó nímùúṣẹ: Ọdún 1919 sí Amágẹ́dọ́nì

1, 2. (a) Àmì kẹta wo ni Jòhánù sọ pé òun rí? (b) Ojúṣe àwọn áńgẹ́lì wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́?

 OBÌNRIN kan ń rọbí, ó fẹ́ bí ọmọkùnrin kan! Dírágónì ńlá kan ń wá ọ̀nà láti pa ọmọ náà jẹ! Ìṣípayá orí 12 ṣàpèjúwe àwọn àmì méjì tí Jòhánù rí lọ́run yìí lọ́nà tó ṣe kedere. Àwọn àmì náà jẹ́ kó yé wa kedere pé àríyànjiyàn àtọdúnmọ́dún tó wà láàárín Irú-Ọmọ obìnrin Ọlọ́run àti Sátánì àti irú-ọmọ ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ti ń lọ sópin. Nígbà tí Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn àmì wọ̀nyí, ó ní: “Àmì ńlá kan sì di rírí ní ọ̀run . . . Àmì mìíràn sì di rírí.” (Ìṣípayá 12:1, 3, 7-12) Nísinsìnyí Jòhánù wá sọ̀rọ̀ nípa àmì kẹta: “Mo sì rí àmì mìíràn ní ọ̀run, títóbi àti àgbàyanu, áńgẹ́lì méje tí wọ́n ní ìyọnu àjàkálẹ̀ méje. Àwọn wọ̀nyí ni ó kẹ́yìn, nítorí pé nípasẹ̀ wọn ni a mú ìbínú Ọlọ́run wá sí ìparí.” (Ìṣípayá 15:1) Ohun tí àmì kẹta yìí pẹ̀lú túmọ̀ sí ṣe pàtàkì fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà.

2 Kíyè sí àwọn nǹkan pàtàkì táwọn áńgẹ́lì tún ń ṣe láti mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe. Ọjọ́ pẹ́ táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti mọ̀ pé wọ́n ń ṣe ohun kan lórí èyí. Àní, olórin ìgbàanì kan tiẹ̀ bá irú àwọn áńgẹ́lì bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nígbà tí Ọlọ́run mí sí i, ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀, tí ẹ tóbi jọjọ nínú agbára, tí ẹ ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, nípa fífetísí ohùn ọ̀rọ̀ rẹ̀”! (Sáàmù 103:20) Nísinsìnyí, nínú ìran tuntun yìí, Ọlọ́run yan àwọn áńgẹ́lì láti tú ìyọnu méje tó gbẹ̀yìn jáde.

3. Kí ni ìyọnu méje náà, kí sì ni ìtújáde wọn túmọ̀ sí?

3 Kí ni ìyọnu wọ̀nyí? Bíi ti ìró kàkàkí méje náà, wọ́n jẹ́ ìkéde ìdájọ́ amú-bí-iná tó ń kéde ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀kan-kò-jọ̀kan ẹ̀ka ayé yìí àti ìkìlọ̀ nípa àbárèbábọ̀ ìkẹyìn àwọn ìpinnu ìdájọ́ Jèhófà. (Ìṣípayá 8:1–9:21) Títú àwọn ìyọnu yẹn jáde túmọ̀ sí mímú àwọn ìdájọ́ yẹn ṣẹ, nígbà tí ìparun máa dé bá àwọn ohun tí Jèhófà ń bínú sí ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀ jíjófòfò. (Aísáyà 13:9-13; Ìṣípayá 6:16, 17) Nípa báyìí, nípasẹ̀ ìyọnu wọ̀nyẹn “a mú ìbínú Ọlọ́run wá sí ìparí.” Ṣùgbọ́n kí Jòhánù tó ṣàpèjúwe ìtújáde ìyọnu wọnnì, ó sọ fún wa nípa àwọn èèyàn kan táwọn ìyọnu náà kò ní kọ lù. Níwọ̀n bí àwọn adúróṣinṣin wọ̀nyí ti kọ àmì ẹranko ẹhànnà náà, wọ́n ń kọ orin ìyìn sí Jèhófà bí wọ́n ti ń pòkìkí ọjọ́ ẹ̀san rẹ̀.—Ìṣípayá 13:15-17.

Orin Mósè àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn Náà

4. Kí ni Jòhánù rí nísinsìnyí?

4 Nísinsìnyí, Jòhánù wá rí ìran kan tó pẹtẹrí. Ó ròyìn pé: “Mo sì rí ohun tí ó jọ òkun bí gíláàsì tí ó dà pọ̀ mọ́ iná, àti àwọn tí ó jagunmólú lọ́wọ́ ẹranko ẹhànnà náà àti lọ́wọ́ ère rẹ̀ àti lọ́wọ́ nọ́ńbà orúkọ rẹ̀ tí wọ́n dúró níbi òkun bí gíláàsì náà, wọ́n ní háàpù Ọlọ́run lọ́wọ́.”—Ìṣípayá 15:2.

5. Kí ni “òkun bí gíláàsì tí ó dà pọ̀ mọ́ iná” náà dúró fún?

5 “Òkun bí gíláàsì” náà ni èyí tí Jòhánù rí ní ìṣáájú, tó wà níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run. (Ìṣípayá 4:6) Ó jọ “òkun dídà” (ìyẹn agbada omi) tó wà nínú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì, níbi táwọn àlùfáà ti ń bu omi láti fi wẹ ara wọn mọ́. (1 Àwọn Ọba 7:23) Nípa bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ àpẹẹrẹ tó báa mu fún “ìwẹ̀ omi,” ìyẹn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí Jésù fi wẹ ìjọ àlùfáà ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mọ́. (Éfésù 5:25, 26; Hébérù 10:22) Òkun bíi gíláàsì yìí “dà pọ̀ mọ́ iná,” èyí tó fi hàn pé àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí ni a dán wò tí a sì fọ̀ mọ́ tónítóní bí wọ́n ti ń ṣègbọràn sáwọn ìlànà tí kò gba gbẹ̀rẹ́ tí a fi lélẹ̀ fún wọn. Síwájú sí i, ó rán wa létí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún ní àwọn ọ̀rọ̀ ìdájọ́ amú-bí-iná lòdì sí àwọn ọ̀tá rẹ̀ nínú. (Diutarónómì 9:3; Sefanáyà 3:8) Ìyọnu méje tó gbẹ̀yìn tí wọ́n máa tó tú jáde náà jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára àwọn ìdájọ́ amú-bí-iná wọ̀nyí.

6. (a) Àwọn wo làwọn akọrin tí wọ́n dúró níwájú òkun bíi gíláàsì tó wà lọ́run, báwo la sì ṣe mọ̀? (b) Lọ́nà wo ni wọ́n gbà “jagunmólú”?

6 Òkun dídà tó wà nínú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì wà fún ìlò àwọn àlùfáà, èyí tó fi hàn pé àwọn akọrin tí wọ́n dúró níwájú òkun bíi gíláàsì tó wà lọ́run yìí jẹ́ agbo àlùfáà. Wọ́n ní “háàpù Ọlọ́run,” ìyẹn sì jẹ́ ká gbà pé wọ́n jẹ́ ara àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], níwọ̀n bí àwùjọ wọ̀nyí pẹ̀lú ti ń ta háàpù bí wọ́n ṣe ń kọrin. (Ìṣípayá 5:8; 14:2) Àwọn akọrin tí Jòhánù rí “jagunmólú lọ́wọ́ ẹranko ẹhànnà náà àti lọ́wọ́ ère rẹ̀ àti lọ́wọ́ nọ́ńbà orúkọ rẹ̀.” Nítorí náà wọ́n ní láti jẹ́ àwọn tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000]. Tá a bá wo gbogbo wọn lápapọ̀, kò sí àní-àní pé wọ́n ń jagun mólú. Fún nǹkan bí àádọ́rùn-ún [90] ọdún láti ọdún 1919, wọ́n ti kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba àmì ẹranko ẹhànnà náà tàbí láti wojú ère rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo tí ọmọ aráyé ní fún àlàáfíà. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ti fara dà á pẹ̀lú ìṣòtítọ́ títí dójú ikú, ó sì dájú pé nísinsìnyí tí wọ́n ti wà lọ́run, inú wọn ń dùn gan-an bí wọ́n ṣe ń fọkàn tẹ̀ lé orin táwọn arákùnrin wọn tó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé ń kọ.—Ìṣípayá 14:11-13.

7. Báwo ni wọ́n ṣe ń lo háàpù ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, ipa wo ló sì yẹ kí wíwà tí àwọn háàpù Ọlọ́run wà nínú ìran Jòhánù ní lórí wa?

7 Àwọn adúróṣinṣin aṣẹ́gun wọ̀nyí ní háàpù Ọlọ́run. Èyí mú kí wọ́n dà bí àwọn ọmọ Léfì inú tẹ́ńpìlì ìgbàanì, tí wọ́n ń fi orin jọ́sìn Jèhófà bí wọ́n ṣe ń ta háàpù. Àwọn kan tún ń sọ tẹ́lẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ta háàpù. (1 Kíróníkà 15:16; 25:1-3) Ohùn dídùn háàpù àwọn ọmọ Léfì ń mú kí àwọn orin ayọ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kọ sí Jèhófà àti àdúrà ìyìn òun ọpẹ́ tí wọ́n ń gbà túbọ̀ dùn sí i. (1 Kíróníkà 13:8; Sáàmù 33:2; 43:4; 57:7, 8) A kì í gbọ́ ohùn háàpù ní àkókò ìbànújẹ́ tàbí ní oko òǹdè. (Sáàmù 137:2) Ó yẹ kí wíwà tí àwọn háàpù Ọlọ́run wà nínú ìran yìí mú kí ara wa túbọ̀ wà lọ́nà fún orin ayọ̀ àti orin ìṣẹ́gun tó wà fún yíyin Ọlọ́run lógo àti dídúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. a

8. Orin wo ni wọ́n ń kọ, kí sì làwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀?

8 Ohun tí Jòhánù ròyìn ni pé: “Wọ́n sì ń kọ orin Mósè ẹrú Ọlọ́run àti orin Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, pé: ‘Títóbi àti àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè. Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ, Ọba ayérayé. Ta ni kì yóò bẹ̀rù rẹ ní ti gidi, Jèhófà, tí kì yóò sì yin orúkọ rẹ lógo, nítorí pé ìwọ nìkan ni adúróṣinṣin? Nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì jọ́sìn níwájú rẹ, nítorí a ti fi àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ rẹ tí ó jẹ́ òdodo hàn kedere.’”—Ìṣípayá 15:3, 4.

9. Kí nìdí tí a fi sọ pé orin náà jẹ́ orin Mósè?

9 Àwọn ajagunmólú wọ̀nyí ń kọ “orin Mósè,” ìyẹn orin kan tó jọ irú èyí tí Mósè kọ nígbà ìṣẹ́gun. Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fojú rí ìyọnu mẹ́wàá ní Íjíbítì àti ìparun àwọn ọmọ ogun Íjíbítì ní Òkun Pupa, Mósè ṣáájú wọn nínú irú orin ìṣẹ́gun bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi yin Jèhófà, ó pòkìkí pé: “Jèhófà yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” (Ẹ́kísódù 15:1-19) Ẹ wo bó ti bá a mu tó pé àwọn akọrin inú ìran Jòhánù, tí wọ́n ja àjàbọ́ lọ́wọ́ ẹranko ẹhànnà náà tí wọ́n sì ń lọ́wọ́ nínú pípòkìkí ìyọnu méje tó gbẹ̀yìn, tún ní láti kọ orin sí “Ọba ayérayé”!—1 Tímótì 1:17.

10. Orin mìíràn wo ni Mósè kọ, báwo ni ẹsẹ tó gbẹ̀yìn orin náà sì ṣe kan ogunlọ́gọ̀ ńlá ti òde òní?

10 Nínú orin mìíràn, tí Mósè kọ bí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ti ń múra sílẹ̀ fún ìṣẹ́gun Kénáánì, Mósè, tó ti darúgbó nígbà yẹn, sọ fún orílẹ̀-èdè yẹn pé: “Èmi yóò polongo orúkọ Jèhófà. Ẹ gbé ìtóbi fún Ọlọ́run wa ní ti gidi!” Ẹsẹ tó gbẹ̀yìn orin yìí tún fún àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì níṣìírí, ọ̀rọ̀ yìí tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí Mósè láti kọ sílẹ̀ sì kan ogunlọ́gọ̀ ńlá ti òde òní, pé: “Ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.” Kí nìdí tí wọ́n fi ní láti máa yọ̀? Nítorí pé nísinsìnyí Jèhófà “yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, òun yóò sì san ẹ̀san padà fún àwọn elénìní rẹ̀.” Ìmúṣẹ ìdájọ́ òdodo yìí yóò mú kí gbogbo àwọn tí wọ́n nírètí nínú Jèhófà hó ìhó ayọ̀.—Diutarónómì 32:3, 43; Róòmù 15:10-13; Ìṣípayá 7:9.

11. Báwo ni orin tí Jòhánù gbọ́ ṣe ń bá a lọ láti nímùúṣẹ títí di báyìí?

11 Ẹ wo bí Mósè fúnra rẹ̀ ì bá ti yọ̀ tó ká ní ó wà ní ọjọ́ Olúwa nísinsìnyí, kí òun náà máa kọrin pa pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ akọrin ti ọ̀run pé: “Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì jọ́sìn níwájú rẹ”! Àgbà orin yìí ṣì ń ní ìmúṣẹ lọ́nà tó ń wúni lórí gan-an lónìí, bá a ti ń rí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn láti inú “àwọn orílẹ̀-èdè” tí wọ́n ń fi ìdùnnú wọ́ lọ sínú apá ti orí ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà, èyí kì í ṣe nínú ìran lásán ṣùgbọ́n ohun tó ń ṣẹlẹ̀ tá à ń rí gan-an ni.

12. Kí nìdí tá a tún fi pe orin àwọn ajagunmólú náà ní “orin Ọ̀dọ́ Àgùntàn”?

12 Àmọ́ o, orin yìí kì í ṣe ti Mósè nìkan ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ ti “Ọ̀dọ́ Àgùntàn” pẹ̀lú. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Mósè jẹ́ wòlíì Jèhófà fún Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n Mósè fúnra rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé Jèhófà yóò gbé wòlíì mìíràn dìde bíi tòun. Ẹ̀rí fi hàn pé Ẹni náà ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Jésù Kristi. Nígbà tó jẹ́ pé Mósè jẹ́ “ẹrú Ọlọ́run,” Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù jẹ́, nípa bẹ́ẹ̀, òun ni Mósè Títóbijù. (Diutarónómì 18:15-19; Ìṣe 3:22, 23; Hébérù 3:5, 6) Fún ìdí yìí, a lè sọ pé àwọn akọrin náà tún ń kọ “orin Ọ̀dọ́ Àgùntàn.”

13. (a) Báwo ni Jésù ṣe dà bíi Mósè bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tóbi ju Mósè lọ? (b) Báwo la ṣe lè wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn akọrin náà?

13 Bíi ti Mósè, Jésù kọrin ìyìn sí Ọlọ́run ní gbangba, ó sì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìjagunmólú Rẹ̀ lórí gbogbo àwọn ọ̀tá. (Mátíù 24:21, 22; 26:30; Lúùkù 19:41-44) Jésù pẹ̀lú wọ̀nà fún àkókò tí àwọn orílẹ̀-èdè yóò wọlé wá láti yin Jèhófà, bó sì ṣe jẹ́ pé òun ni “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run” tó máa fi ara rẹ̀ rúbọ, ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ láti mú kí èyí ṣeé ṣe. (Jòhánù 1:29; Ìṣípayá 7:9; fi wé Aísáyà 2:2-4; Sekaráyà 8:23.) Gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè sì ti wá mọrírì orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, tó sì kókìkí orúkọ yẹn, bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù ṣe fi orúkọ Ọlọ́run hàn ní gbangba. (Ẹ́kísódù 6:2, 3; Sáàmù 90:1, 17; Jòhánù 17:6) Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ adúróṣinṣin, kò sí àní-àní pé àwọn ìlérí rẹ̀ tó ń mọ́kàn yọ̀ máa ní ìmúṣẹ. Nígbà náà, ó dájú pé a wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn akọrin adúróṣinṣin wọ̀nyí, pẹ̀lú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, àti pẹ̀lú Mósè, bá a ṣe ń fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ orin náà tó sọ pé: “Ta ni kì yóò bẹ̀rù rẹ ní ti gidi, Jèhófà, tí kì yóò sì yin orúkọ rẹ lógo?”

Àwọn Áńgẹ́lì Tó Gbé Àwokòtò Dání

14. Àwọn wo ni Jòhánù rí tí wọ́n ń jáde láti inú ibùjọsìn, kí sì ni a fi fún wọn?

14 Ó bá a mu rẹ́gí pé ká gbọ́ orin àwọn ẹni àmì òróró aṣẹ́gun wọ̀nyí. Kí nìdí? Nítorí pé wọ́n ti polongo àwọn ìdájọ́ tó wà nínú àwọn àwokòtò tó kún fún ìbínú Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n kì í ṣe àwọn ẹ̀dá èèyàn lásánlàsàn nìkan lọ̀rọ̀ nípa ìtújáde ohun tó wà nínú àwọn àwokòtò wọ̀nyí kàn, gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú ohun tí Jòhánù kọ sílẹ̀ báyìí, ó ní: “Àti lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo rí, a sì ṣí ibùjọsìn àgọ́ ẹ̀rí sílẹ̀ ní ọ̀run, àwọn áńgẹ́lì méje tí wọ́n ní ìyọnu àjàkálẹ̀ méje náà sì yọ láti inú ibùjọsìn náà, a wọ̀ wọ́n ní aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó mọ́, tí ń tàn yòyò, a sì fi àmùrè wúrà di igẹ̀ wọn yí ká. Ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà sì fún àwọn áńgẹ́lì méje náà ní àwokòtò méje oníwúrà tí ó kún fún ìbínú Ọlọ́run, ẹni tí ó wà láàyè títí láé àti láéláé.”—Ìṣípayá 15:5-7.

15. Kí nìdí tí kò fi yani lẹ́nu pé àwọn áńgẹ́lì méje náà jáde láti inú ibùjọsìn náà?

15 Nínú tẹ́ńpìlì Ísírẹ́lì, èyí táwọn ohun tó ṣàpẹẹrẹ àwọn ohun ti ọ̀run wà nínú rẹ̀, àlùfáà àgbà nìkan ló lè wọ ibi Mímọ́ Jù Lọ, tí ibí yìí pè ní “ibùjọsìn.” (Hébérù 9:3, 7) Ibùjọsìn yìí ṣàpèjúwe ibi tí Jèhófà wà ní ọ̀run. Àmọ́, ní ọ̀run, kì í ṣe kìkì Àlùfáà Àgbà náà, Jésù Kristi nìkan ló ní àǹfààní láti wọlé sí iwájú Jèhófà, ṣùgbọ́n àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú ní àǹfààní náà. (Mátíù 18:10; Hébérù 9:24-26) Nígbà náà, kò yani lẹ́nu pé Jòhánù rí àwọn áńgẹ́lì méje tí wọ́n ń jáde bọ̀ láti inú ibùjọsìn ní ọ̀run. Wọ́n ní iṣẹ́ kan tí Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ gbé lé wọn lọ́wọ́: Ẹ da ìbínú Ọlọ́run tó kún inú àwokòtò náà jáde.—Ìṣípayá 16:1.

16. (a) Kí ló fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì méje náà kúnjú ìwọ̀n dáadáa fún iṣẹ́ wọn? (b) Kí ló fi hàn pé àwọn mìíràn ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ńlá ti dída ohun tó wà nínú àwọn àwokòtò ìṣàpẹẹrẹ náà jáde?

16 Àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí kúnjú ìwọ̀n dáadáa fún iṣẹ́ yìí. A fi aṣọ ọ̀gbọ̀ mímọ́ tónítóní, tí ń tàn yòò wọ̀ wọ́n, tó fi hàn pé wọ́n mọ́ tónítóní wọ́n sì jẹ́ mímọ́ nípa tẹ̀mí, wọ́n jẹ́ olódodo lójú Jèhófà. Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n di àmùrè wúrà. Àmùrè làwọn èèyàn sábà máa ń lò nígbà tí wọ́n bá ń gbára dì fún iṣẹ́ tí wọ́n bá fẹ́ ṣe. (Léfítíkù 8:7, 13; 1 Sámúẹ́lì 2:18; Lúùkù 12:37; Jòhánù 13:4, 5) Nítorí náà, àwọn áńgẹ́lì náà ni a dì ní àmùrè láti ṣiṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, àmùrè wúrà ni wọ́n dì. Nínú àgọ́ ìjọsìn ìgbàanì, wúrà ṣàpẹẹrẹ àwọn ohun ti ọ̀run. (Hébérù 9:4, 11, 12) Èyí túmọ̀ sí pé àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí ní iṣẹ́ ìsìn ṣíṣeyebíye kan tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ láti ṣe. Àwọn mìíràn ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ńlá yìí pẹ̀lú. Ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ló gbé àwọn àwokòtò náà gan-an lé wọn lọ́wọ́. Láìsí iyèméjì, ẹni yẹn ni ẹ̀dá alààyè àkọ́kọ́, èyí tó jọ kìnnìún, tó ṣàpẹẹrẹ àìṣojo àti ìgboyà tí kò ṣeé borí tí ẹni tó máa pòkìkí àwọn ìdájọ́ Jèhófà nílò.—Ìṣípayá 4:7.

Jèhófà Nínú Ibùjọsìn Rẹ̀

17. Kí ni Jòhánù sọ fún wa nípa ibùjọsìn náà, báwo ni ìyẹn sì ṣe rán wa létí ibùjọsìn ní Ísírẹ́lì ìgbàanì?

17 Níkẹyìn, nígbà tí Jòhánù ń kádìí apá yìí nínú ìran tó rí, ó sọ fún wa pé: “Ibùjọsìn náà sì wá kún fún èéfín nítorí ògo Ọlọ́run àti nítorí agbára rẹ̀, kò sì sí ẹnì kankan tí ó lè wọnú ibùjọsìn náà títí di ìgbà tí ìyọnu àjàkálẹ̀ méje ti àwọn áńgẹ́lì méje náà fi parí.” (Ìṣípayá 15:8) Àwọn àkókò kan wà nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí àwọsánmà bo ibùjọsìn gidi náà, tí ìfihàn ògo Jèhófà yìí sì ṣèdíwọ́ fún àwọn àlùfáà láti wọ ibẹ̀. (1 Àwọn Ọba 8:10, 11; 2 Kíróníkà 5:13, 14; fi wé Aísáyà 6:4, 5.) Ìwọ̀nyí jẹ́ àkókò tí Jèhófà ń lọ́wọ́ nínú àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní tààràtà.

18. Ìgbà wo làwọn áńgẹ́lì náà yóò padà láti jábọ̀ fún Jèhófà?

18 Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé jẹ Jèhófà lógún gan-an nísinsìnyí pẹ̀lú. Ó fẹ́ kí àwọn áńgẹ́lì méje náà parí iṣẹ́ wọn. Ó jẹ́ àkókò pàtàkì fún ìdájọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Sáàmù 11:4-6 pé: “Jèhófà ń bẹ nínú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀. Jèhófà—ọ̀run ni ìtẹ́ rẹ̀. Ojú rẹ̀ ń wò, ojú rẹ̀ títàn yanran ń ṣàyẹ̀wò àwọn ọmọ ènìyàn. Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá. Òun yóò rọ̀jò pańpẹ́, iná àti imí ọjọ́ sórí àwọn ẹni burúkú àti ẹ̀fúùfù tí ń jóni gbẹ, gẹ́gẹ́ bí ìpín ife wọn.” Títí a ó fi tú ìyọnu méje wọ̀nyí jáde sórí àwọn ẹni burúkú, àwọn áńgẹ́lì méje náà kì yóò padà sí iwájú Jèhófà tó jẹ́ ibi ológo.

19. (a) Ta ló pa àṣẹ, kí sì ni àṣẹ náà? (b) Ìgbà wo ni ìtújáde ohun tó wà nínú àwọn àwokòtò ìṣàpẹẹrẹ náà ti ní láti bẹ̀rẹ̀?

19 Àṣẹ bíbanilẹ́rù kan sán jáde bí ààrá: “Mo sì gbọ́ tí ohùn rara kan láti inú ibùjọsìn náà wí fún àwọn áńgẹ́lì méje náà pé: ‘Ẹ lọ da àwokòtò méje ìbínú Ọlọ́run jáde sí ilẹ̀ ayé.’” (Ìṣípayá 16:1) Ta ló pàṣẹ yìí? Ó ní láti jẹ́ Jèhófà fúnra rẹ̀, níwọ̀n bí ìrànyòò ògo àti agbára rẹ̀ kò ti jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọ ibùjọsìn náà. Jèhófà wá sínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ nípa tẹ̀mí fún ìdájọ́ lọ́dún 1918. (Málákì 3:1-5) Nígbà náà, ó ti ní láti jẹ́ pé kété lẹ́yìn àkókò yẹn ló pàṣẹ pé kí wọ́n da ohun tó wà nínú àwọn àwokòtò ìbínú Ọlọ́run jáde. Kódà, ọdún 1922 la ti bẹ̀rẹ̀ sí í pòkìkí àwọn ìdájọ́ tí ń bẹ nínú àwọn àwokòtò ìṣàpẹẹrẹ náà kíkankíkan. Ìpòkìkí wọn sì ń lọ sókè gan-an ni lónìí.

Àwọn Àwokòtò Náà àti Àwọn Ìró Kàkàkí

20. Kí ni àwọn àwokòtò ìbínú Jèhófà ń ṣí payá tó sì tún ń kìlọ̀ nípa rẹ̀, báwo sì ni wọ́n ṣe ń da ohun tó wà nínú wọn jáde?

20 Àwọn àwokòtò ìbínú Jèhófà ń kéde èrò Jèhófà nípa àwọn ọ̀kan-kò-jọ̀kan ẹ̀ka ayé yìí, wọ́n sì ń kìlọ̀ nípa àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà yóò mú ṣẹ. Àwọn áńgẹ́lì náà ń tú àwọn àwokòtò náà jáde nípasẹ̀ ẹgbẹ́ Jòhánù tó ń ṣojú fún ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn àwọn tó ń kọ orin Mósè àti orin Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. Bí ẹgbẹ́ Jòhánù ṣe ń pòkìkí Ìjọba náà gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere, wọ́n ti fi àìṣojo ṣí àwọn ohun tí ń bẹ nínú àwọn àwokòtò ìbínú wọ̀nyí payá. (Mátíù 24:14; Ìṣípayá 14:6, 7) Nípa bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ wọn tó pín sí apá méjì yìí jẹ́ alálàáfíà ní ti pé wọ́n ń pòkìkí òmìnira fún aráyé, ṣùgbọ́n ó tún dà bíi ti ológun ní ti pé wọ́n ń kìlọ̀ “ọjọ́ ẹ̀san níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa.”—Aísáyà 61:1, 2.

21. Báwo ló ṣe jẹ́ pé ibi tí wọ́n dẹnu ìró kàkàkí mẹ́rin àkọ́kọ́ kọ ni wọ́n da àwokòtò ìbínú Ọlọ́run mẹ́rin àkọ́kọ́ sí, ìyàtọ̀ wo ló sì wà láàárín wọn?

21 Àwọn ibì tí wọ́n dẹnu ìró kàkàkí mẹ́rin àkọ́kọ́ kọ náà ni wọ́n da àwokòtò ìbínú Ọlọ́run mẹ́rin àkọ́kọ́ sí. Ìwọ̀nyí sì ni ilẹ̀ ayé, òkun, àwọn odò àtàwọn ìsun omi, àti àwọn orísun ìmọ́lẹ̀ ọ̀run. (Ìṣípayá 8:1-12) Ṣùgbọ́n orí “ìdá mẹ́ta” làwọn ìró kàkàkí náà kéde àwọn ìyọnu lé, nígbà tó jẹ́ pé gbogbo èèyàn pátápátá ni ìtújáde àwọn àwokòtò ìbínú Ọlọ́run pọ́n lójú. Nípa báyìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, gẹ́gẹ́ bí “ìdá mẹ́ta,” ni ìyọnu náà kọ́kọ́ dé bá ní ọjọ́ Olúwa, kò sí apá kankan lára ètò Sátánì tó bọ́ lọ́wọ́ ìyọnu ìkéde ìdájọ́ Jèhófà àti ìbànújẹ́ tó ń mú bá wọn.

22. Báwo ni ìró kàkàkí mẹ́ta tó gbẹ̀yìn ṣe yàtọ̀, báwo sì ni wọ́n ṣe kan àwọn àwokòtò ìbínú Jèhófà mẹ́ta tó gbẹ̀yìn?

22 Ìró kàkàkí mẹ́ta tó gbẹ̀yìn yàtọ̀, nítorí ègbé la pè wọ́n. (Ìṣípayá 8:13; 9:12) Méjì àkọ́kọ́ lára àwọn ègbé mẹ́ta náà jẹ́ àwọn eéṣú àti agbo àwọn agẹṣinjagun, nígbà tí ẹ̀kẹta kéde ìbí Ìjọba Jèhófà. (Ìṣípayá 9:1-21; 11:15-19) Bá a ṣe máa rí i, àwọn àwokòtò ìrunú Ọlọ́run mẹ́ta tó gbẹ̀yìn náà kan díẹ̀ lára àwọn nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n wọ́n yàtọ̀ láwọn ọ̀nà kan sí ègbé mẹ́ta náà. Ẹ jẹ́ ká wá fiyè sí àwọn ìkéde amúnijígìrì tó jẹ yọ látinú dída àwọn àwokòtò ìbínú Jèhófà jáde.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àní lọ́dún 1921, ẹgbẹ́ Jòhánù tẹ ìwé Duru Ọlọrun jáde káwọn èèyàn lè máa lò ó fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì lé ní mílíọ̀nù márùn-ún ìwé yìí ní èdè tó ju ogún lọ tí wọ́n pín kiri. Ó wà lára ohun tó mú káwọn ẹni àmì òróró akọrin púpọ̀ sí i wọlé.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]