Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ohun Tó Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀ Láìpẹ́

Àwọn Ohun Tó Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀ Láìpẹ́

Orí 3

Àwọn Ohun Tó Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀ Láìpẹ́

1. Báwo lo ṣe lè yè bọ́ lọ́wọ́ ìmúṣẹ ìdájọ́ Ọlọ́run lórí ayé yìí?

 Ó YẸ káwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé lónìí jẹ ọ́ lọ́kàn. Èé ṣe tó fi yẹ kó máa jẹ ọ́ lọ́kàn? Ìdí ni pé ayé yìí kò lè bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. Àmọ́ ìwọ lè yè bọ́. O lè yè bọ́ nípa ‘ṣíṣàìjẹ́ apá kan ayé’ tá a ti dájọ́ ìparun fún. Èyí kò túmọ̀ sí gbígbé ìgbésí ayé afìṣẹ́-ṣẹ́ra-ẹni ti àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé o. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé bó o tiẹ̀ ń gbádùn ìgbésí ayé tó sunwọ̀n tó sì nítumọ̀, síbẹ̀ o ya ara rẹ sọ́tọ̀ kúrò nínú ìwà ìbàjẹ́ ìṣèlú, kúrò nínú ìṣòwò oníwọra, àti kúrò nínú ìsìn tí ń tàbùkù sí Ọlọ́run, àti pẹ̀lú kúrò nínú ìwà ipá àti ìṣekúṣe. Bákan náà, o gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìlànà aláìgbagbẹ̀rẹ́ ti Ọlọ́run kó o sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Jòhánù 17:14-16; Sefanáyà 2:2, 3; Ìṣípayá 21:8) Ìwé Ìṣípayá ṣàfihàn bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kó o máa lo ara rẹ tọkàntara nínú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí, kó o ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ nínú ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ.

2. Báwo ni àpọ́sítélì Jòhánù ṣe nasẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ńlá Ìṣípayá, ta ni Ọlọ́run sì fi ìhìn pàtàkì yìí fún?

2 Àpọ́sítélì Jòhánù fi gbólóhùn kan nasẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ńlá yìí, ó ní: “Ìṣípayá láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi, èyí tí Ọlọ́run fi fún un, láti fi han àwọn ẹrú rẹ̀, àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́.” (Ìṣípayá 1:1a) Èyí fi hàn pé Jésù Kristi tó ti jí dìde ló gba ìhìn pàtàkì yìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ẹsẹ yìí fi hàn pé Jésù rẹlẹ̀ sí Baba rẹ̀, pé kì í ṣe apá kan Mẹ́talọ́kan tí ò ṣeé ṣàlàyé. Lọ́nà kan náà, “àwọn ẹrú” tí wọ́n para pọ̀ di ìjọ Kristẹni ń ṣègbọràn sí Jésù Kristi, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ‘ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tó bá ń lọ.’ (Ìṣípayá 14:4; Éfésù 5:24) Ṣùgbọ́n àwọn wo lónìí ni “àwọn ẹrú” Ọlọ́run ní tòótọ́, báwo sì ni Ìṣípayá ṣe ṣàǹfààní fún wọn?

3. (a) Àwọn wo ni “àwọn ẹrú” tí wọ́n ń ṣègbọràn sí Jésù Kristi? (b) Iṣẹ́ wo ni “àwọn ẹrú” olóòótọ́ náà ń ṣe lábẹ́ ìdarí àwọn áńgẹ́lì?

3 Àpọ́sítélì Jòhánù tó kọ Ìṣípayá sọ pé irú ẹrú bẹ́ẹ̀ lòun. Òun ni àpọ́sítélì tó gbẹ̀yìn ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó para pọ̀ di “àwọn ẹrú” tá a fi ẹ̀mí yàn tí yóò jogún ìyè àìleèkú ní ọ̀run. Lónìí, kìkì ẹgbẹ̀rún díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí ló ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé. Ọlọ́run tún ní àwọn ìránṣẹ́ mìíràn, ogunlọ́gọ̀ ńlá ni wọ́n, ìyẹn àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé, tí iye wọn ti wọ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù nísinsìnyí. Lábẹ́ ìdarí àwọn áńgẹ́lì, àwọn wọ̀nyí ń jùmọ̀ bá “àwọn ẹrú” náà tá a fòróró yàn polongo ìhìn rere àìnípẹ̀kun fún gbogbo aráyé. Ẹ sì wo bí gbogbo “àwọn ẹrú” wọ̀nyí ti ń lo ara wọn tó láti lè ran àwọn onínú tútù ilẹ̀ ayé lọ́wọ́ láti rí ìgbàlà! (Mátíù 24:14; Ìṣípayá 7:9, 14; 14:6) Ìṣípayá fi ohun tó o gbọ́dọ̀ ṣe kó o lè jàǹfààní nínú ìhìn rere tí ń fúnni láyọ̀ náà hàn.

4. (a) Níwọ̀n bó ti ju ẹ̀ẹ́dẹ̀gbàá [1,900] ọdún lọ tí Jòhánù ti kọ ìwé Ìṣípayá, báwo ló ṣe lè sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́”? (b) Kí ni ẹ̀rí wá fi hàn nísinsìnyí nípa àwọn ohun tá a ti sọ tẹ́lẹ̀?

4 Ṣùgbọ́n, báwo ni Jòhánù ṣe lè sọ pé a óò fi “àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́” han “àwọn ẹrú” wọ̀nyí? Àbí kò ti ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbàá [1,900] ọdún lọ báyìí tó ti sọ ọ́? Ṣẹ́ ẹ rí i, lójú Jèhófà tí odindi ẹgbẹ̀rún ọdún ‘dà bí àná,’ àkókò kúkúrú ni ẹ̀ẹ́dẹ́gbàá [1,900] ọdún jẹ́ tá a bá fi wé àìmọye ọdún tó fi ṣẹ̀dá tó sì fi pèsè ilẹ̀ ayé sílẹ̀ fún àwa èèyàn láti máa gbé. (Sáàmù 90:4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa “ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà àti ìrètí” tí òun fúnra rẹ̀ ní, nítorí pé kò sí iyè méjì pé àkókò tó máa gba èrè rẹ̀ gan-an jọ bí ẹní sún mọ́lé lójú rẹ̀. (Fílípì 1:20) Àmọ́ o, lónìí, ẹ̀rí pọ̀ jaburata pé gbogbo àwọn ohun tá a ti sọ tẹ́lẹ̀ yóò ṣẹlẹ̀ ní àkókò tá a là kalẹ̀ fún un. Kò tíì sí ìgbà kankan rí tí lílà á já aráyé wà nínú ewu tó bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run nìkan ló mọ ojútùú rẹ̀!—Aísáyà 45:21.

Ọ̀nà Tí Ìhìn Náà Gbà Wá

5. Báwo ni ìwé Ìṣípayá ṣe tẹ àpọ́sítélì Jòhánù lọ́wọ́, báwo ló sì ṣe dé ọ̀dọ̀ àwọn ìjọ lẹ́yìn náà?

5 Ìṣípayá 1:1b, 2 sọ pé: “Ó [ìyẹn Jésù] sì rán áńgẹ́lì rẹ̀ jáde, ó sì gbé e [ìyẹn Ìṣípayá] kalẹ̀ nípa àwọn àmì nípasẹ̀ rẹ̀ fún ẹrú rẹ̀ Jòhánù, ẹni tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fúnni àti sí ẹ̀rí tí Jésù Kristi jẹ́, àní sí gbogbo ohun tí ó rí.” Nípa báyìí, Jòhánù gba àkọsílẹ̀ onímìísí náà nípasẹ̀ ońṣẹ́ kan tó jẹ́ áńgẹ́lì. Ó kọ ọ́ sínú àkájọ ìwé kan, ó sì fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ tí ń bẹ nígbà ayé rẹ̀. Ó mú wa láyọ̀ pé Ọlọ́run ti tọ́jú rẹ̀, kó lè fún iye ìjọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] tí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan lórí ilẹ̀ ayé lónìí níṣìírí.

6. Kí ni Jésù pe ọ̀nà tí òun yóò lò láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún ‘àwọn ẹrú’ rẹ̀ lónìí?

6 Ọlọ́run ní ọ̀nà tó ṣètò tí ìwé Ìṣípayá gbà wá nígbà ayé Jòhánù, Jòhánù sì jẹ́ apá kan ọ̀nà náà lórí ilẹ̀ ayé. Bákan náà, Ọlọ́run ní ọ̀nà tó gbà ń fún ‘àwọn ẹrú’ rẹ̀ ní oúnjẹ tẹ̀mí lónìí. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ ńlá rẹ̀ nípa òpin ètò àwọn nǹkan, Jésù jẹ́ ká mọ ọ̀nà yìí sí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀, láti fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mátíù 24:3, 45-47) Ó ń lo ẹgbẹ́ Jòhánù yìí láti jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀.

7. (a) Kí ló yẹ káwọn àmì tá a rí nínú ìwé Ìṣípayá sún wa ṣe? (b) Báwo ló ti pẹ́ tó tí àwọn kan lára ẹgbẹ́ Jòhánù ti ń nípìn-ín nínú ìmúṣẹ àwọn ìran inú ìwé Ìṣípayá?

7 Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé Jésù fi Ìṣípayá hàn “nípa àwọn àmì,” tàbí àwọn ìṣàpẹẹrẹ. Àwọn wọ̀nyí ṣe kedere, a ó sì gbádùn ṣíṣàyẹ̀wò wọn. Wọ́n fi ìgbòkègbodò tó lágbára hàn, nítorí náà, ó yẹ kó ru àwa náà sókè láti fi ìtara sapá láti jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn mọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí àti ìtumọ̀ rẹ̀. Ìṣípayá fi ọ̀pọ̀ ìran amúnitakìjí hàn wá, Jòhánù sì kópa yálà ní tààràtà tàbí gẹ́gẹ́ bí òǹwòran nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ara ẹgbẹ́ Jòhánù, tí àwọn kan lára wọn ti nípìn-ín nínú ìmúṣẹ ìran wọ̀nyí fún ọ̀pọ̀ ọdún, láyọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọ́run ti ṣí ìtumọ̀ rẹ̀ payá kí wọ́n bàa lè ṣàlàyé rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn.

8. (a) Kí lohun tó ṣe kedere nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìran inú ìwé Ìṣípayá? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ohun tí ẹranko inú ìwé Ìṣípayá jẹ́?

8 Ìwé Ìṣípayá kò to àwọn ìran wọ̀nyí tẹ̀ léra wọn ní bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló ní àkókò ìmúṣẹ tirẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ìran náà ṣe àtúnsọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìṣáájú tó mú ká rí ojútùú ìtumọ̀ àwọn ìran inú ìwé Ìṣípayá. Bí àpẹẹrẹ, àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ṣàpèjúwe ẹranko ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ mẹ́rin, ó ní àwọn ẹranko náà dúró fún àwọn agbára tí ń ṣàkóso lórí ilẹ̀ ayé. Nípa báyìí, èyí ràn wá lọ́wọ́ láti lóye pé àwọn ẹranko inú ìwé Ìṣípayá dúró fún àwọn ìjọba ayé, títí kan àwọn tí wọ́n wà nísinsìnyí.—Dáníẹ́lì 7:1-8, 17; Ìṣípayá 13:2, 11-13; 17:3.

9. (a) Bíi ti Jòhánù, kí ni ẹgbẹ́ Jòhánù ti òde òní ti ṣe? (b) Báwo ni Jòhánù ṣe fi ọ̀nà bá a ṣe lè di aláyọ̀ hàn wá?

9 Jòhánù fi ìṣòtítọ́ jẹ́rìí sí ìhìn tí Ọlọ́run fi fún un nípasẹ̀ Jésù Kristi. Ó ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àpèjúwe “gbogbo ohun tí ó rí.” Ẹgbẹ́ Jòhánù ti fi gbogbo ọkàn wá ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti Jésù Kristi láti lè lóye àsọtẹ́lẹ̀ náà ní kíkún kí wọ́n sì sọ àwọn kókó inú rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run. Fún àǹfààní ìjọ àwọn ẹni àmì òróró (àti àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ẹni tí Ọlọ́run yóò pa mọ́ láàyè la ìpọ́njú ńlá náà já), Jòhánù kọ̀wé pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè àti àwọn tí ń gbọ́, tí wọ́n sì ń pa àwọn ohun tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́; nítorí àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti sún mọ́lé.”—Ìṣípayá 1:3.

10. Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe sí ìwé Ìṣípayá kí ọwọ́ wa bàa lè tẹ ayọ̀?

10 Wàá jàǹfààní gidigidi tó o bá ka ìwé Ìṣípayá, pàápàá tó o bá pa àwọn ohun tá a kọ sínú rẹ̀ mọ́. Jòhánù ṣàlàyé nínú ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà rẹ̀ pé: “Nítorí èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira, nítorí ohun gbogbo tí a ti bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ń ṣẹ́gun ayé. Èyí sì ni ìṣẹ́gun tí ó ti ṣẹ́gun ayé, ìgbàgbọ́ wa.” (1 Jòhánù 5:3, 4) Wàá ní ayọ̀ tó gọntíọ tó o bá sapá láti ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀!

11. (a) Èé ṣe tó fi jẹ́ kánjúkánjú pé ká pa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà mọ́? (b) Àkókò wo ló gbọ́dọ̀ ti sún mọ́lé gan-an báyìí lọ́nà tó léwu?

11 Ó jẹ́ kánjúkánjú pé ká pa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà mọ́, “nítorí àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti sún mọ́lé.” Àkókò tí a yàn fún kí ni? Fún ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìṣípayá, títí kan àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run. Àkókò náà ti sún mọ́lé fún Ọlọ́run àti Jésù Kristi láti mú ìdájọ́ ìkẹyìn ṣẹ sórí ayé ètò Sátánì. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ pé Baba òun nìkan ṣoṣo ló mọ “ọjọ́ yẹn tàbí wákàtí náà.” Bí Jésù ṣe rí àrítẹ́lẹ̀ àwọn wàhálà tó ti wá pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé ní àkókò wa yìí, ó tún sọ pé: “Ìran yìí kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀.” Nítorí náà àkókò tí a yàn fún mímú ìpinnu Ọlọ́run ṣẹ gbọ́dọ̀ ti sún mọ́lé gan-an báyìí lọ́nà tó léwu. (Máàkù 13:8, 30-32) Gẹ́gẹ́ bí Hábákúkù 2:3 ti wí: “Ìran náà ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀, ó sì ń sáré lọ ní mímí hẹlẹhẹlẹ sí òpin, kì yóò sì purọ́. Bí ó bá tilẹ̀ falẹ̀, máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un; nítorí yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́.” Tá a bá máa rí ìgbàlà la ìpọ́njú ńlá náà já, a gbọ́dọ̀ pa Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run mọ́.—Mátíù 24:20-22.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]

Ká tó lè lóye ìwé Ìṣípayá ó pọn dandan pé

● Ká gba ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Jèhófà

● Ká fòye mọ ìgbà tí ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀

● Ká mọ ẹrú olóòótọ́ àti olóye lónìí dájú