Ègbé Àkọ́kọ́—Àwọn Eéṣú
Orí 22
Ègbé Àkọ́kọ́—Àwọn Eéṣú
1. Nígbà táwọn áńgẹ́lì bá ti fun kàkàkí wọn, àwọn wo ló ń polongo ìró rẹ̀, kí sì ni ìró kàkàkí karùn-ún kéde?
ÁŃGẸ́LÌ karùn-ún ń múra sílẹ̀ láti fun kàkàkí rẹ̀. Kàkàkí mẹ́rin ló ti dún látọ̀run, ìyọnu mẹ́rin sì ti dà sórí ìdá mẹ́ta tí Jèhófà kà séyìí tó jẹ̀bi jù lọ nínú ayé, ìyẹn àwùjọ oníṣọ́ọ̀ṣì. Àṣírí ti tú pé inú àìsàn tó máa pa á ló wà. Báwọn áńgẹ́lì ṣe ń fọn kàkàkí wọn yìí, àwọn èèyàn ń polongo rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Nísinsìnyí kàkàkí áńgẹ́lì karùn-ún máa tó kéde ègbé àkọ́kọ́, tó jẹ́ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ju àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ ṣáájú pàápàá. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ìyọnu eéṣú tó ń ṣẹ̀rù bani. Àmọ́ ṣá, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táá ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ìyọnu ọ̀hún.
2. Ìwé Bíbélì wo ló ṣàpèjúwe ìyọnu àwọn eéṣú kan tó jọ èyí tí Jòhánù rí, ipa wo ló sì ní lórí Ísírẹ́lì ìgbàanì?
2 Ìwé Jóẹ́lì nínú Bíbélì, tí wọ́n kọ ní ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣááju Sànmánì Kristẹni, ṣàpèjúwe ìyọnu oríṣiríṣi kòkòrò, tó fi mọ́ eéṣú, tó jọ èyí tí Jòhánù rí. (Jóẹ́lì 2:1-11, 25) a Ó máa kó ìrora tó pọ̀ bá Ísírẹ́lì tó ti di apẹ̀yìndà ṣùgbọ́n á tún mú káwọn Júù ronú pìwà dà lọ́kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n sì padà rí ojú rere Jèhófà. (Jóẹ́lì 2:6, 12-14) Nígbà tí àkókò yẹn bá tó, Jèhófà á tú ẹ̀mí rẹ̀ jáde “sára gbogbo onírúurú ẹran ara,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àmì abanilẹ́rù àtàwọn àmì àgbàyanu akódàágìrì-báni ló máa ṣáájú “kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà tó dé.”—Jóẹ́lì 2:11, 28-32.
Ìyọnu Ọ̀rúndún Kìíní
3, 4. (a) Ìgbà wo ni Jóẹ́lì orí kejì ní ìmúṣẹ kan, báwo ló sì ṣe ní ìmúṣẹ? (b) Báwo ni ìyọnu tó ń ya luni bí eéṣú ṣe wà ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, báwo ló sì ṣe pẹ́ tó tí wọ́n fi ń mú ìyọnu náà wá sórí àwọn èèyàn?
3 Jóẹ́lì orí kejì ní ìmúṣẹ lọ́nà kan ní ọ̀rúndún kìíní. Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà àjọ̀dún Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tá a tú ẹ̀mí mímọ́ jáde, tí ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àkọ́kọ́ tó sì fún wọn lágbára láti sọ àwọn “ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè. Látàrí èyí, ogunlọ́gọ̀ ńlá pé jọ. Àpọ́sítélì Pétérù bá àwọn òǹwòran tẹ́nu ń yà sọ̀rọ̀, ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Jóẹ́lì 2:28, 29 ó sì ṣàlàyé pé ìmúṣẹ rẹ̀ ni wọ́n ń rí yẹn. (Ìṣe 2:1-21) Ṣùgbọ́n kò sí àkọsílẹ̀ pé ìyọnu kòkòrò gidi dé bá ẹnì kankan láti fa ìnira fún wọn kó sì mú kí wọ́n ronú pìwà dà.
4 Ǹjẹ́ ìyọnu kankan ṣẹlẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ lákòókò yẹn bí? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ó ṣẹlẹ̀ látàrí ìwàásù táwọn Kristẹni tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ fi òróró yàn ń ṣe láìdáwọ́dúró. b Nípasẹ̀ wọn, Jèhófà ń pe àwọn Júù tó bá máa fetí sílẹ̀ láti ronú pìwà dà kí wọ́n sì gbádùn àwọn ìbùkún rẹ̀. (Ìṣe 2:38-40; 3:19) Àwọn tí wọ́n gbọ́ràn nínú wọn rí ojú rere rẹ̀ dé àyè kan. Ṣùgbọ́n fáwọn tó fi gbígbọ́ ṣaláìgbọ́, ṣe làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní dà bí àwọn eéṣú tó ń ya lù wọ́n tó sì ń jẹ wọ́n run. Láti Jerúsálẹ́mù, wọ́n tàn ká gbogbo Jùdíà àti Samáríà. Láìpẹ́ wọ́n tàn débi gbogbo, bí wọ́n sì ṣe ń pòkìkí àjíǹde Jésù ní gbangba, tí wọ́n tún ń sọ ohun tí àjíǹde náà túmọ̀ sí, ṣe ni wọ́n ń dá àwọn Júù aláìgbàgbọ́ lóró. (Ìṣe 1:8; 4:18-20; 5:17-21, 28, 29, 40-42; 17:5, 6; 21:27-30) Wọ́n ń bá a nìṣó láti máa mú ìyọnu náà wá sórí àwọn èèyàn títí di “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù,” ìyẹn lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Jèhófà mú káwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù kọ lu Jerúsálẹ́mù láti pa á run. Kìkì àwọn Kristẹni tó fi ìgbàgbọ́ ké pe orúkọ Jèhófà ló rí ìgbàlà.—Jóẹ́lì 2:32; Ìṣe 2:20, 21; Òwe 18:10.
Ìyọnu Eéṣú Lóde Òní
5. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ti ṣe ń ní ìmúṣẹ látọdún 1919 wá?
5 Ó bọ́gbọ́n mu láti fojú sọ́nà pé kí àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ní ìmúṣẹ ìkẹyìn rẹ̀ ní àkókò òpin. Òótọ́ pọ́ńbélé sì nìyẹn wá já sí! Ní àpéjọ àgbègbè àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílùú Cedar Point, ní ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ní September 1 sí 8, ọdún 1919, ẹ̀mí Jèhófà tó tú jáde lọ́nà tó kàmàmà mú káwọn èèyàn Jèhófà di alákitiyan lẹ́nu ṣíṣètò iṣẹ́ ìwàásù tó gba ayé kan. Nínú gbogbo àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni, àwọn èèyàn Jèhófà nìkan ṣoṣo ló ń ṣe gbogbo ohun tó wà lágbára wọn láti máa kéde ìhìn rere yẹn káàkiri torí wọ́n mọ̀ dájú ṣáká pé Jèhófà ti gbé Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba ní ọ̀run. Bí wọ́n ṣe ń wàásù láìdẹwọ́ yẹn, gẹ́gẹ́ bí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ṣe ló dà bí ìyọnu adánilóró fáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì apẹ̀yìndà.—Mátíù 24:3-8, 14; Ìṣe 1:8.
6. (a) Kí ni Jòhánù rí nígbà tí áńgẹ́lì karùn-ún fun kàkàkí rẹ̀? (b) Ta ni “ìràwọ̀” yìí ṣàpẹẹrẹ, kí sì nìdí ẹ̀?
6 Ìwé Ìṣípayá, tí Jòhánù kọ ní nǹkan bí ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù, tún ṣàpèjúwe ìyọnu yẹn. Kí ló wá fi kún àpèjúwe Jóẹ́lì o? Ẹ jẹ́ ká gbé àkọsílẹ̀ náà yẹ̀ wò gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ti ròyìn rẹ̀, pé: “Áńgẹ́lì karùn-ún sì fun kàkàkí rẹ̀. Mo sì rí ìràwọ̀ kan tí ó ti jábọ́ láti ọ̀run sí ilẹ̀ ayé, a sì fún un ní kọ́kọ́rọ́ kòtò ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.” (Ìṣípayá 9:1) “Ìràwọ̀” yìí yàtọ̀ sí èyí tó wà nínú Ìṣípayá 8:10 tí Jòhánù rí bó ṣe ń já bọ̀. “Ìràwọ̀ kan tí ó ti jábọ́ láti ọ̀run sí ilẹ̀ ayé” ló rí báyìí àti pé ó ní iṣẹ́ kan tí ìràwọ̀ náà ní í ṣe nínú ọ̀ràn ilẹ̀ ayé yìí. Ṣé ẹni ẹ̀mí ni ẹni yìí àbí èèyàn ẹlẹ́ran ara? Ẹni tó ní “kọ́kọ́rọ́ kòtò ọ̀gbun àìnísàlẹ̀” yìí lọ́wọ́ ni Ìṣípayá wá sọ nígbà tó yá pé ó fi Sátánì sọ̀kò sínú “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.” (Ìṣípayá 20:1-3) Torí ìdí èyí, ó ní láti jẹ́ ẹni ẹ̀mí alágbára ńlá. Nínú Ìṣípayá 9:11, Jòhánù sọ fún wa pé àwọn eéṣú yẹn ní “ọba kan . . . , áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.” Níwọ̀n bó sì ti bọ́gbọ́n mu pé áńgẹ́lì tó mú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà dání ní láti jẹ́ áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjèèjì yìí ní láti máa tọ́ka sí ẹnì kan náà. Bákan náà, ìràwọ̀ náà ní láti ṣàpẹẹrẹ Ọba tí Jèhófà yàn sípò, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé, Jésù Kristi ni Ọba kan ṣoṣo tó jẹ́ áńgẹ́lì táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mọ̀ lọ́ba.—Kólósè 1:13; 1 Kọ́ríńtì 15:25.
7. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí áńgẹ́lì náà ṣí “kòtò ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà”? (b) Kí ni “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà,” ta sì ló lo àkókò kúkúrú nínú rẹ̀?
7 Ìròyìn náà ń bá a lọ pé: “Ó sì ṣí kòtò ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, èéfín sì gòkè wá láti inú kòtò náà bí èéfín ìléru ńlá, oòrùn sì ṣókùnkùn, àti afẹ́fẹ́ pẹ̀lú, nípasẹ̀ èéfín kòtò náà. Àwọn eéṣú sì jáde wá sórí ilẹ̀ ayé láti inú èéfín náà; a sì fún wọn ní ọlá àṣẹ, irú ọlá àṣẹ kan náà tí àwọn àkekèé ilẹ̀ ayé ní.” (Ìṣípayá 9:2, 3) Bí Ìwé Mímọ́ ṣe máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀,” ó jẹ́ ibi tẹ́nì kan ò ti lè ṣiṣẹ́ mọ́, ipò ikú pàápàá. (Fi wé Róòmù 10:7; Ìṣípayá 17:8; 20:1, 3.) Ẹgbẹ́ àwọn arákùnrin Jésù tí wọ́n kéré lo àkókò kúkúrú nínú irú “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀,” níbi tá a ti lè sọ pé wọn ò ṣiṣẹ́ mọ́, ní òpin Ogun Àgbáyé Kìíní (ìyẹn lọ́dún 1918 sí ọdún 1919). Ṣùgbọ́n nígbà tí Jèhófà tú ẹ̀mí rẹ̀ dà sórí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ronú pìwà dà lọ́dún 1919, wọ́n tú jáde láti dàyà kọ iṣẹ́ tó wà níwájú wọn.
8. Báwo ló ṣe jẹ́ pé “èéfín” púpọ̀ làwọn eéṣú náà bá jáde nígbà tí áńgẹ́lì náà tú wọn sílẹ̀?
8 Gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ṣe kíyè sí i, bí áńgẹ́lì náà ṣe tú àwọn eéṣú yẹn sílẹ̀, ṣe ni èéfín púpọ̀ bá wọn jáde, irú èyí tó dà bí “èéfín ìléru ńlá” kan. c Ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn lọ́dún 1919. Gbogbo nǹkan ṣókùnkùn fáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti fáráyé lápapọ̀. (Fi wé Jóẹ́lì 2:30, 31.) Ìtìjú ńlá gbáà ló jẹ́ fún ẹgbẹ́ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì bí áńgẹ́lì náà ṣe tú àwọn eéṣú, ìyẹn ẹgbẹ́ Jòhánù sílẹ̀ torí pé wọ́n ti di rìkíṣí, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti dojú iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run bolẹ̀ títí láé, tí wọ́n sì ti pa Ìjọba Ọlọ́run tì báyìí. Àmì pé èéfín kan ṣú dẹ̀dẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tàn ká orí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì apẹ̀yìndà bí Ọlọ́run ṣe fún agbo eéṣú yẹn ní àṣẹ látọ̀run tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lo àṣẹ náà láti pòkìkí àwọn ìkéde ìdájọ́ tó lágbára. “Oòrùn” àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ìyẹn ohun tó dà bí ìlàlóye tí wọ́n ní, ti wọ òkùnkùn, àwọn ìpolongo ìdájọ́ Ọlọ́run sì ti gba inú “afẹ́fẹ́” kan bó ṣe di pé ó hàn gbangba pé “olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́” ayé yìí ni ọlọ́run àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì.—Éfésù 2:2; Jòhánù 12:31; 1 Jòhánù 5:19.
Àwọn Eéṣú Yẹn Mà Ń Dáni Lóró O!
9. Àṣẹ wo làwọn eéṣú yẹn ní láti máa tẹ̀ lé lójú ogun?
9 Àṣẹ wo làwọn eéṣú yẹn ní láti máa tẹ̀ lé lójú ogun? Jòhánù ròyìn pé: “A sì sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe pa ewéko ilẹ̀ ayé kankan lára tàbí ohun títutùyọ̀yọ̀ èyíkéyìí tàbí igi èyíkéyìí, bí kò ṣe kìkì àwọn ènìyàn tí kò ní èdìdì Ọlọ́run ní iwájú orí wọn. A sì yọ̀ǹda fún àwọn eéṣú náà, láti má ṣe pa wọ́n, ṣùgbọ́n pé kí a mú àwọn wọ̀nyí joró fún oṣù márùn-ún, oró náà lára wọn sì dà bí oró àkekèé nígbà tí ó bá ta ènìyàn. Ní ọjọ́ wọnnì, àwọn ènìyàn náà yóò wá ikú, ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i lọ́nàkọnà, wọn yóò sì fẹ́ láti kú, ṣùgbọ́n ikú yóò máa sá fún wọn.”—Ìṣípayá 9:4-6.
10. (a) Àwọn wo ní pàtàkì ni ìyọnu náà dé bá, ipa wo ló sì ní lórí wọn? (b) Irú ìdálóró wo ló fà fún wọn? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
10 Kíyè sí i pé kì í ṣàwọn èèyàn tàbí àwọn sàràkí sàràkí láàárín wọn, ìyẹn ‘ewéko àti àwọn igi ilẹ̀ ayé’ ni ìyọnu yìí kọ́kọ́ dé bá. (Fi wé Ìṣípayá 8:7.) Kìkì àwọn táwọn eéṣú náà ní láti pa lára ni àwọn tí kò ní èdìdì Ọlọ́run ní iwájú orí wọn, ìyẹn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n sọ pé a ti fi èdìdì di àwọn ṣùgbọ́n tí ohun tó wà lákọọ́lẹ̀ pé wọ́n ṣe fi wọ́n hàn ní elékèé. (Éfésù 1:13, 14) Ìdí nìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn aṣáájú ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì làwọn eéṣú òde òní yẹn dojú àwọn ọ̀rọ̀ tó ń dáni lóró tó ń tẹnu wọn jáde kọ. Àbí ẹ ò rí i báwọn ọkùnrin ajọra-ẹni-lójú yẹn á ṣe máa joró tó nígbà tí wọ́n ń gbọ́ táwọn èèyàn Ọlọ́run kéde ní gbangba pé kì í ṣe pé wọ́n kùnà láti ṣamọ̀nà àwọn agbo wọn lọ sí ọ̀run nìkan ni ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn ò ní í débẹ̀! d Lóòótọ́, àfi bí ‘afọ́jú tó ń fọ̀nà han afọ́jú’!—Mátíù 15:14.
11. (a) Báwo ni àkókò táwọn eéṣú náà láṣẹ láti dá àwọn ọ̀tá Ọlọ́run lóró ti gùn tó, kí sì nìdí tá ò fi lè sọ pé àkókò yẹn kúrú? (b) Báwo ni oró náà á ṣe mú àwọn tí wọ́n ń dá lóró tó?
11 “Oṣù márùn-ún” làwọn eéṣú náà fi dá wọn lóró. Àkókò yẹn ò wa dà bí ẹní kúrú bí? Bá a bá fojú eéṣú gidi wò ó, kò kúrú. Oṣù márùn-ún ṣàpèjúwe bí ẹ̀mí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kòkòrò yẹn ṣe máa ń gùn tó. Èyí fi hàn pé níwọ̀n ìgbà táwọn eéṣú òde òní yìí bá ṣì wà láàyè, wọ́n á máa ta àwọn ọ̀tá Ọlọ́run lọ ni ràì. Yàtọ̀ síyẹn, títa náà rorò tó bẹ́ẹ̀ débi táwọn èèyàn fi ń wá ikú. Lóòótọ́, a ò rí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé ẹnikẹ́ni nínú àwọn táwọn eéṣú náà ta gbìyànjú láti pa ara wọn ní ti gidi. Ṣùgbọ́n gbólóhùn yẹn jẹ́ ká lè fojú inú wo bí títa ríro náà á ṣe pọ̀ tó—àfi bí ẹni pé àwọn àkekèé ń ta èèyàn fàì fàì. Ó dà bí ìyà tí Jeremáyà rí tẹ́lẹ̀ pé ó ń bọ̀ lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòtítọ́ yẹn nígbà táwọn ará Bábílónì ajagunṣẹ́gun bá tú wọn ká, wọ́n á fẹ́ ikú ju ìyè lọ nígbà yẹn.—Jeremáyà 8:3; tún wo Oníwàásù 4:2, 3.
12. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé oró nìkan la yọ̀ǹda fáwọn eéṣú náà láti dá àwọn aṣáájú ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì nípa tẹ̀mí, ṣùgbọ́n kí wọ́n má ṣe pa wọ́n?
12 Kí nìdí tó fi jẹ́ pé oró nìkan la ní káwọn eéṣú yìí máa dá àwọn wọ̀nyí nípa tẹ̀mí kí wọ́n má ṣe pa wọ́n? Ègbé àkọ́kọ́ rèé nínú títú àwọn irọ́ àtàwọn ìkùnà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fó. Ṣùgbọ́n nígbà tó bá yá, bí ọjọ́ Olúwa ti ń tẹ̀ síwájú, wọ́n ṣì ń bọ̀ wá kéde gbangba gbàǹgbà pé inú ipò òkú làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì wà nípa tẹ̀mí. Ìgbà ègbé kejì ni ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn náà máa kú.—Ìṣípayá 1:10; 9:12, 18; 11:14.
Àwọn Eéṣú Tá A Ti Dira Ogun Fún
13. Báwo làwọn eéṣú yẹn ṣe rí?
13 Ìrísí àwọn eéṣú yẹn mà pabanbarì o! Jòhánù ṣàpèjúwe ìrísí wọn pé: “Ìrí àwọn eéṣú náà sì jọ àwọn ẹṣin tí a múra sílẹ̀ fún ìjà ogun; àti ní orí wọn ni ohun tí ó rí bí adé tí ó dà bí wúrà wà, ojú wọn sì dà bí ojú ènìyàn, ṣùgbọ́n wọ́n ní irun bí irun obìnrin. Eyín wọn sì dà bí ti kìnnìún; wọ́n sì ní àwo ìgbàyà bí àwo ìgbàyà irin. Ìró ìyẹ́ apá wọn sì dà bí ìró àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ti ọ̀pọ̀ ẹṣin tí ń sáré lọ sínú ìjà ogun.”—Ìṣípayá 9:7-9.
14. Kí nìdí tí àpèjúwe Jòhánù nípa ìrísí àwọn eéṣú náà fi bá àwùjọ àwọn Kristẹni tá a mú sọ jí lọ́dún 1919 mu?
14 Èyí ṣàpèjúwe bí àwùjọ àwọn Kristẹni adúróṣinṣin tá a mú sọ jí lọ́dún 1919 ṣe rí. Àfi bí ẹṣin, wọ́n ti ṣe tán ogun, wọ́n hára gàgà láti jà fún òtítọ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe ìjà náà. (Éfésù 6:11-13; 2 Kọ́ríńtì 10:4) Jòhánù ráwọn nǹkan tó rí bí adé wúrà lórí wọn. Kò ní í bójú mu fún wọn láti ní adé gidi nítorí wọn ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso nígbà tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. (1 Kọ́ríńtì 4:8; Ìṣípayá 20:4) Ṣùgbọ́n lákòókò yẹn lọ́dún 1919, ọlá ọba ti hàn lára wọn. Arákùnrin Ọba náà ni wọ́n, adé wọn sì ń dúró dè wọ́n lọ́run bí wọ́n bá lè jẹ́ olóòótọ́ títí dópin.—2 Tímótì 4:8; 1 Pétérù 5:4.
15. Ní tàwọn eéṣú náà, kí ni ìwọ̀nyí tọ́ka sí (a) àwo ìgbàyà irin? (b) ojú bíi ti èèyàn? (d) irun bíi tobìnrin? (e) eyín bíi ti kìnnìún? (ẹ) pípa ọ̀pọ̀ ariwo?
15 Nínú ìran náà, àwọn eéṣú náà ní àwo ìgbàyà onírin, tó ń ṣàpẹẹrẹ ìwà òdodo tí kò lè fọ́. (Éfésù 6:14-18) Pẹ̀lúpẹ̀lù wọ́n ní ojú èèyàn, èyí ń tọ́ka sí ànímọ́ ìfẹ́, níwọ̀n bí Ọlọ́run, ẹni tí ó jẹ́ ìfẹ́, ti ṣe èèyàn ní àwòrán rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26; 1 Jòhánù 4:16) Irun wọn gùn bíi tobìnrin, èyí tó jẹ́ àpẹẹrẹ pé wọ́n ń tẹrí ba fún Ọba wọn, tí í ṣe áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà. Eyín wọn sì jọ eyín kìnnìún. Kìnnìún máa ń fi eyín ẹ̀ fa ẹran ya. Látọdún 1919 wá, ẹgbẹ́ Jòhánù tún ti gba agbára láti jẹ oúnjẹ líle látinú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pàápàá àwọn òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run tí “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà,” Jésù Kristi, ń ṣàkóso. Bí kìnnìún ti ṣàpẹẹrẹ ìgboyà gẹ́lẹ́, ìgboyà ńlá ló gbà láti lóye ọ̀rọ̀ ìkéde yìí, ká sì tẹ́ ẹ̀ jáde ká tó wá pín in káàkiri ilẹ̀ ayé. Àwọn eéṣú ìṣàpẹẹrẹ yìí ti pa ariwo púpọ̀, bí “ìró àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ti ọ̀pọ̀ ẹṣin tí ń sáré lọ sínú ìjà ogun.” Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tí wọ́n ń tẹ̀ lé, wọn ò ní in lọ́kàn láti dákẹ́ jẹ́ẹ́.—1 Kọ́ríńtì 11:7-15; Ìṣípayá 5:5.
16. Kí ni ìtumọ̀ níní táwọn eéṣú náà ní ‘ìrù, tí wọ́n sì ń tani bí àkekèé’?
16 Ìwàásù yìí kọjá ọ̀rọ̀ ẹnu lásán! “Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n ní ìrù, wọ́n sì ń tani bí àkekèé; àti ní ìrù wọn ni ọlá àṣẹ wọn wà láti ṣe àwọn ènìyàn náà lọ́ṣẹ́ fún oṣù márùn-ún.” (Ìṣípayá 9:10) Kí lèyí lè túmọ̀ sí o? Báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tí wọn ń ṣe, wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu àtàwọn ìwé tí wọ́n tẹ̀ sọ àṣẹ ọ̀rọ̀ tó wá látinú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń kéde ní oró bíi ti àkekèé nítorí wọ́n ń kìlọ̀ nípa ọjọ́ ẹ̀san Jèhófà tó ń sún mọ́lé. (Aísáyà 61:2) Kí gbogbo àwọn eéṣú tẹ̀mí yìí tó parí ìgbésí ayé wọn, iṣẹ́ tí Ọlọ́run pàṣẹ fún wọn, pé kí wọ́n máa polongo àwọn ìdájọ́ òun, á parí—oró ńlá ló máa jẹ́ fún gbogbo àwọn asọ̀rọ̀-òdì tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn líle.
17. (a) Kí ni nǹkan tí wọ́n kéde ní àpéjọ àgbègbè àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tọdún 1919, èyí tí yóò máa mú kí oró ìjẹ́rìí wọn gbóná janjan sí i? (b) Báwo ni wọ́n ṣe dá àwùjọ àwọn àlùfáà lóró, báwo sì làwọn àlùfáà ṣe dáhùn padà?
17 Ayọ̀ agbo eéṣú yẹn kún àkúnwọ́sílẹ̀ nígbà tí wọ́n kéde ní àpéjọ àgbègbè wọn lọ́dún 1919 pé ìwé ìròyìn tuntun kan, ìyẹn The Golden Age ti jáde. Ẹ̀ẹ̀mejì lóṣù ni ìwé ìròyìn yìí á máa jáde, ìdí tí wọ́n sì fi ń tẹ̀ ẹ́ jáde ni láti mú kí oró ìjẹ́rìí wọn múná janjan sí i. e Ìtẹ̀jáde rẹ̀ Nọnba 27, ti September 29, 1920, túdìí àṣírí bí ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà ṣe ń fẹ̀jẹ̀ sínú tutọ́ funfun jáde lórí inúnibíni tí wọ́n ṣe sáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láàárín ọdún 1918 sí 1919. Jálẹ̀ ọdún 1920 wọ ọdún 1930, ìwé ìròyìn The Golden Age tún dá àwùjọ àwọn àlùfáà lóró sí i nípasẹ̀ àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn àwòrán ẹ̀fẹ̀ tó ń tani bí oró, èyí tó túdìí àṣírí báwọn àlùfáà ṣe fi àrékérekè yọjúràn sí ìṣèlú, àti àdéhùn táwọn Kátólíìkì ṣe pẹ̀lú àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ ti ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ àti Násì. Èyí mú kí àwùjọ àwọn àlùfáà “fi òfin dìmọ̀ ìwà ìkà” wọ́n sì kó àwọn èèyàn kéèyàn sòdí láti hùwà ipá sáwọn èèyàn Ọlọ́run.—Sáàmù 94:20.
Wọ́n Kìlọ̀ Fáwọn Olùṣàkóso Ayé
18. Iṣẹ́ wo ni àwọn eéṣú náà ní láti ṣe, kí ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìró kàkàkí karùn-ún dún?
18 Àwọn eéṣú òde òní ní iṣẹ́ pàtàkì láti ṣe. Wọ́n ní láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà. Wọ́n ní láti túdìí àwọn ìṣìnà. Wọ́n ní láti wá àwọn àgùntàn tó sọ nù rí. Báwọn eéṣú náà ti ń bá iṣẹ́ wọ̀nyí lọ, ó di dandan fún ayé láti kíyè sí i. Ní ìgbọràn sí ìró kàkàkí àwọn áńgẹ́lì, ẹgbẹ́ Jòhánù ti ń bá a lọ láti tú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fó pé wọ́n yẹ fún ìdájọ́ Jèhófà. Nígbà tí kàkàkí karùn-ún dún, wọ́n tẹnu mọ́ apá kan pàtó lára ìdájọ́ wọ̀nyí ní àpéjọ àgbègbè kan táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe nílùú London, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ní May 25 sí 31, ọdún 1926. Wọ́n tẹ́wọ́ gba ìpinnu kan níbẹ̀, èyí tí wọ́n pè ní “Ẹ̀rí fún Àwọn Olùṣàkóso Ayé,” wọ́n sì gbọ́ àsọyé kan fún gbogbo èèyàn ní gbọ̀ngàn Royal Albert Hall lórí “Ìdí Táwọn Agbára Ayé Fi Ń Ta Gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n—Ojútùú Rẹ̀.” Ọ̀kan nínú ìwé ìròyìn tó gbajúmọ̀ jù lọ nílùú London gbé ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìpinnu àti àsọyé yẹn jáde lọ́jọ́ kejì lẹ́yìn tí àpéjọ náà parí. Lẹ́yìn náà, agbo eéṣú náà pín àádọ́ta mílíọ̀nù [50,000,000] ẹ̀dà ìwé àṣàrò kúkúrú tó gbé ìpinnu yẹn jáde káàkiri ayé. Àbí ẹ ò rí i pé oró ńlá ló dá àwùjọ àwọn àlùfáà! Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà làwọn èèyàn ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi ń sọ̀rọ̀ nípa ìtúfó tó ń tani yìí.
19. Ohun ìjà mìíràn wo làwọn eéṣú ìṣàpẹẹrẹ náà tún rí gbà, kí sì ló ní í sọ nípa ìpolongo ìlú London náà?
19 Ní àpéjọ àgbègbè yìí, àwọn eéṣú ìṣàpẹẹrẹ náà tún gba ohun ìjà mìíràn, ìyẹn ìwé tuntun kan tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ Idande. Ìjíròrò kan wà nínú rẹ̀ tó dá lórí Ìwé Mímọ́ nípa àmì tó fi hàn pé a ti bí ‘ọmọ ọkùnrin’ náà tó jẹ́ ìjọba, ìyẹn Ìjọba ọ̀run ti Kristi, látọdún 1914. (Mátíù 24:3-14; Ìṣípayá 12:1-10) Lẹ́yìn náà, ó gbé ìpolongo kan jáde èyí táwọn àlùfáà mẹ́jọ tí wọ́n sọ pé wọ́n jẹ́ “ara àwọn oníwàásù tó lókìkí jù lọ lágbàáyé,” fọwọ́ sí, tí wọ́n sì tẹ̀ nílùú London lọ́dún 1917. Àwọn àlùfáà náà wá látinú àwọn ìsìn tó lókìkí jù lọ nínú àwọn ẹ̀ka ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì, ìyẹn látinú ijọ Onítẹ̀bọmi, ìjọ Congregational, ìjọ Presbyterian, ìjọ Episcopalian, àti ìjọ Mẹ́tọ́díìsì. Nínú ìpolongo tí wọ́n fọwọ́ sí yìí, wọ́n pòkìkí pé “yánpọnyánrin tó ń lọ lọ́wọ́ yìí fi hàn pé òpin àkókò àwọn Kèfèrí ti dé” àti pé “ìṣípayá Olúwa la lè retí nígbàkigbà.” Dájúdájú, èyí fi hàn pé àwọn àlùfáà yìí ti rí àmì wíwàníhìn-ín Jésù kedere! Ṣùgbọ́n ṣé wọ́n fẹ́ láti ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀ bí? Ìwé náà, Idande, sọ fún wa pé: “Eyiti o yani lẹnu julọ nínú ọran na ni eyi pe àwọn ẹni gãn ti o fi ọwọ si ọrọ na tun yipada lẹhinna nwọn si kọ̀ àwọn ẹri ti o tọka si pe a wà li opin aiye àti ni ọjọ dide Olúwa lẹ̃keji.”
20. (a) Kí ni àwùjọ àwọn àlùfáà ti yàn láti ṣe lórí ọ̀ràn agbo eéṣú náà àti Ọba wọn? (b) Ta ni Jòhánù sọ pé ó wà lórí agbo eéṣú náà, kí sì ni orúkọ rẹ̀?
20 Kàkà kí wọ́n kéde Ìjọba Ọlọ́run tó ń bọ̀, àwùjọ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti yàn láti fara mọ́ ayé Sátánì. Wọn ò fẹ́ láti ní ìpín kankan pẹ̀lú agbo eéṣú náà àti Ọba wọn, àwọn tí Jòhánù sọ nípa wọn báyìí pé: “Wọ́n ní ọba kan lórí wọn, áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà. Lédè Hébérù, orúkọ rẹ̀ ni Ábádónì [tó túmọ̀ sí “Ìparun”], ṣùgbọ́n lédè Gíríìkì, ó ní orúkọ náà Ápólíónì [tí ó túmọ̀ sí “Apanirun”].” (Ìṣípayá 9:11) Gẹ́gẹ́ bí “áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀” àti “Apanirun,” Jésù ti tú ègbé tó ń kó ìyọnu báni sórí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lóòótọ́. Àmọ́, ó kù ni ìbọn ń ró!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fi Jóẹ́lì 2:4, 5, 7 (tó sọ pé àwọn kòkòrò náà dà bí ẹṣin, èèyàn, àtàwọn ọkùnrin, tó sì ní wọ́n ń dún bíi kẹ̀kẹ́ ẹṣin) wé Ìṣípayá 9:7-9; bákan náà, fi Jóẹ́lì 2:6, 10 (tó ń ṣàpèjúwe ìrora ìyọnu kòkòrò náà) wé Ìṣípayá 9:2, 5.
b Wo àpilẹ̀kọ náà “Wiwa ni Irẹpọ Lodisi Àwọn Orilẹ-ede ni Afonifoji Idajọ” nínú Ile-Iṣọ Na ti November 1, 1962.
c Kíyè sí i pé a ò lè lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí láti fi hàn pé iná ń bẹ nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, bí ẹni pé ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà jẹ́ hẹ́ẹ̀lì oníná. Jòhánù sọ pé òun rí èéfín tó nípọn “bí,” tàbí tó dà bí, èéfín ìléru ńlá. (Ìṣípayá 9:2) Kò sọ pé òun ráwọn ọwọ́ iná gidi nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà.
d Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a lò níhìn-ín wá láti inú ọ̀rọ̀ náà ba·sa·niʹzo, èyí tá a máa ń lò nígbà mìíràn fún ìdálóró gidi. Ṣùgbọ́n, a tún lè lò ó fún ohun tó ń da èèyàn lọ́kàn rú bíi pé ó ń dá a lóró. Bí àpẹẹrẹ, ní 2 Pétérù 2:8, a kà pé Lọ́ọ̀tì “ń mú ọkàn òdodo rẹ̀ joró” nítorí ìwà ibi tó rí ní Sódómù. Àwọn aṣáájú ìsìn ayé ìgbà àwọn àpọ́sítélì fara gbá irú ìdálóró ọkàn bẹ́ẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó dájú pé, nǹkan míì tó yàtọ̀ pátápátá ló fà á.
e Lọ́dún 1937, a yí orúkọ ìwé ìròyìn yìí padà sí Consolation, a sì yí i padà sí Awake! (Jí!) lọ́dún 1946.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 143]
Nígbà tí wọ́n fun kàkàkí karùn-ún, ó mú èkíní nínú ègbé mẹ́ta náà wá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 146]
Àwọn ọfà rẹ mú ní ọkàn-àyà àwọn ọ̀tá Ọba. (Sáàmù 45:5) Àwòrán ẹ̀fẹ̀ yìí, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí, jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ẹ̀ tá a tẹ̀ jáde láàárín ọdún 1930 sí 1940 èyí tó ta “àwọn èèyàn tí kò ní èdìdì Ọlọ́run”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 147]
Gbọ̀ngàn Royal Albert Hall, níbi tí wọ́n ti mú ìwé náà Idande jáde tí wọ́n sì ti tẹ́wọ́ gba ìpinnu náà “Ẹ̀rí fún Àwọn Olùṣàkóso Ayé”