Ìlú Ológo
Orí 43
Ìlú Ológo
Ìran 16—Ìṣípayá 21:9–22:5
Ohun tó dá lé: Àpèjúwe Jerúsálẹ́mù Tuntun
Ìgbà tó nímùúṣẹ: Lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá tí wáyé tí Sátánì sì ti dèrò ọ̀gbun àìnísàlẹ̀
1, 2. (a) Ibo ni áńgẹ́lì kan mú Jòhánù lọ láti lè rí Jerúsálẹ́mù Tuntun, ìyàtọ̀ wo la kíyè sí? (b) Kí nìdí tí èyí fi jẹ́ ìparí ológo ti Ìṣípayá?
ÁŃGẸ́LÌ kan ti mú Jòhánù lọ sínú aginjù kan láti fi Bábílónì Ńlá hàn án. Nísinsìnyí ọ̀kan nínú àwùjọ áńgẹ́lì kan náà yìí mú Jòhánù lọ sí òkè gíga fíofío kan. Ohun tó rí níbẹ̀ mà yàtọ̀ púpọ̀ o! Ibi tó rí yìí kì í ṣe ìlú aláìmọ́, oníwà pálapàla bíi ti Bábílónì aṣẹ́wó náà, ṣùgbọ́n ó jẹ́ Jerúsálẹ́mù Tuntun—mímọ́ gaara, ti ẹ̀mí, tó jẹ́ mímọ́—tó sì ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run gan-an.—Ìṣípayá 17:1, 5.
2 Kódà Jerúsálẹ́mù orí ilẹ̀ ayé kò tíì ní irú ògo yìí rí. Jòhánù sọ fún wa pé: “Ọ̀kan nínú àwọn áńgẹ́lì méje tí wọ́n ní àwokòtò méje lọ́wọ́ tí ó kún fún ìyọnu àjàkálẹ̀ méje ìkẹyìn sì wá, ó sì bá mi sọ̀rọ̀, ó sì wí pé: ‘Wá níhìn-ín, dájúdájú, èmi yóò fi ìyàwó hàn ọ́, aya Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.’ Nítorí náà, ó gbé mi nínú agbára ẹ̀mí lọ sí òkè ńlá títóbi tí ó ga fíofío, ó sì fi ìlú ńlá mímọ́ náà Jerúsálẹ́mù hàn mí tí ń ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó sì ní ògo Ọlọ́run.” (Ìṣípayá 21:9-11a) Láti orí ibi tí ojú ti tólẹ̀ dáadáa lórí òkè gàgàrà yẹn, Jòhánù wo ìlú ẹlẹ́wà náà káàkiri, ó rí i tinú tòde pẹ̀lú gbogbo ẹwà rẹ̀. Àwọn ẹni ìgbàgbọ́ ti ń hára gàgà pé kó dé látìgbà táráyé ti ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Òun ló dé nígbẹ̀yìngbẹ́yín yìí! (Róòmù 8:19; 1 Kọ́ríńtì 15:22, 23; Hébérù 11:39, 40) Ìlú tẹ̀mí ọlọ́lá ńlá ni ìlú yìí, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n jẹ́ olùpa-ìwà-títọ́-mọ́ àti adúróṣinṣin ló para pọ̀ jẹ́ ìlú náà, ìlú ológo ni, ó sì jẹ́ mímọ́, bó ṣe ń tàn nínú ògo Jèhófà. Èyí ni ìparí ológo ti Ìṣípayá!
3. Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ẹwà Jerúsálẹ́mù Tuntun?
3 Jerúsálẹ́mù Tuntun jẹ́ àrímáleèlọ nínú ẹwà rẹ̀: “Ìtànyinrin rẹ̀ dà bí òkúta ṣíṣeyebíye jù lọ, bí òkúta jásípérì tí ń dán bí kírísítálì tí ó mọ́ kedere. Ó ní ògiri ńlá gíga fíofío, ó sì ní ẹnubodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnubodè náà, áńgẹ́lì méjìlá, a sì kọ àkọlé àwọn orúkọ tí ó jẹ́ àwọn ti ẹ̀yà méjìlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹnubodè mẹ́ta wà ní ìlà-oòrùn, àti ní àríwá, ẹnubodè mẹ́ta, àti ní gúúsù, ẹnubodè mẹ́ta, àti ní ìwọ̀-oòrùn, ẹnubodè mẹ́ta. Ògiri ìlú ńlá náà tún ní òkúta ìpìlẹ̀ méjìlá, àti lára wọn, orúkọ méjìlá ti àwọn àpọ́sítélì méjìlá ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣípayá 21:11b-14) Ẹ wo bó ṣe bá a mu tó, pé ohun àkọ́kọ́ tí Jòhánù kọ sílẹ̀ nípa ìlú náà ni ìmọ́lẹ̀ tó ń tàn yòò! Títàn tí Jerúsálẹ́mù Tuntun ń tàn tàbí bó ṣe ń dán gbinrin bí ìyàwó ọ̀ṣìngín yìí fi hàn pé òun gan-an ni olorì tó yẹ Kristi. Dídán ló sì yẹ kó máa dán gbinrin lóòótọ́ nítorí iṣẹ́ ọwọ́ “Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá” ni.—Jákọ́bù 1:17.
4. Kí ló fi hàn pé Jerúsálẹ́mù Tuntun kì í ṣe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ti ara?
4 Wọ́n kọ orúkọ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá sára ibodè méjìlá rẹ̀. Nítorí náà, àwọn tó para pọ̀ di ìlú ìṣàpẹẹrẹ yìí ni ọ̀kẹ́ méje o lé ẹgbàajì [144,000] àwọn tí a fi èdìdì dì “láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Ìṣípayá 7:4-8) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, àwọn òkúta ìpìlẹ̀ náà ní orúkọ àwọn àpọ́sítélì méjìlá ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lára. Bó ṣe rí nìyẹn, Jerúsálẹ́mù Tuntun kì í ṣe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ti ara tí ìpìlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ àwọn ọmọkùnrin méjìlá Jékọ́bù. Ísírẹ́lì tẹ̀mí ni, tí ìpìlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn wòlíì.”—Éfésù 2:20.
5. Kí ni a tọ́ka sí nípa “ògiri ńlá gíga fíofío” tó yí Jerúsálẹ́mù Tuntun po àti nípa òtítọ́ náà pé àwọn áńgẹ́lì ni a yàn sí ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan?
5 Ìlú ìṣàpẹẹrẹ náà ní ògiri títóbi kan. Láyé àtijọ́, torí káwọn ọ̀tá má lè wọlé ní wọ́n ṣe máa ń mọ ògiri yí ìlú po. “Ògiri ńlá gíga fíofío” tó yí Jerúsálẹ́mù Tuntun po fi hàn pé ó wà lábẹ́ ààbò nípa tẹ̀mí. Kò sí ọ̀tá òdodo kankan, kò sí aláìmọ́ tàbí alábòsí kankan, táá lè ráàyè wọbẹ̀ láéláé. (Ìṣípayá 21:27) Ṣùgbọ́n fáwọn tá a yọ̀ǹda fún láti wọlé, wíwọ inú ìlú ẹlẹ́wà yìí dà bíi wíwọ Párádísè ni. (Ìṣípayá 2:7) Lẹ́yìn tí Jèhófà lé Ádámù kúrò nínú Párádísè ìpilẹ̀ṣẹ̀, ó fàwọn kérúbù síwájú ibẹ̀ láti má ṣe jẹ́ káwọn èèyàn aláìmọ́ wọlé. (Jẹ́nẹ́sísì 3:24) Lọ́nà kan náà, àwọn áńgẹ́lì wà ní ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan ìlú Jerúsálẹ́mù láti rí i dájú pé ìlú náà wà lábẹ́ ààbò tẹ̀mí. Ní tòótọ́, ní gbogbo àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn áńgẹ́lì ti ń dáàbò bo ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí wọ́n di Jerúsálẹ́mù Tuntun, èyí ni ò jẹ́ kí Bábílónì lè kó èérí bá wọn.
Wíwọn Ìlú Náà
6. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ìwọ̀n ìlú náà, kí sì ni wíwọ̀n tí áńgẹ́lì yìí wọ̀n ọ́n fi hàn? (b) Báwo la ṣe lè ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ pé òṣùwọ̀n tó lò jẹ́ “ní ìbámu pẹ̀lú òṣùwọ̀n ènìyàn, tí ó tún jẹ́ ti áńgẹ́lì lẹ́sẹ̀ kan náà”? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
6 Jòhánù ń bá ìròyìn rẹ̀ lọ pé: “Wàyí o, ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀ mú ọ̀pá esùsú oníwúrà kan lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n, kí ó lè wọn ìlú ńlá náà àti àwọn ẹnubodè rẹ̀ àti ògiri rẹ̀. Ìlú ńlá náà sì gbalẹ̀ ní igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, òró rẹ̀ sì tóbi gẹ́lẹ́ bí ìbú rẹ̀. Ó sì fi ọ̀pá esùsú náà wọn ìlú ńlá náà, ẹgbẹ̀rún méjìlá ìwọ̀n fọ́lọ́ǹgì; òró àti ìbú àti gíga rẹ̀ jẹ́ ọgbọọgba. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wọn ògiri rẹ̀, ogóje ó lé mẹ́rin ìgbọ̀nwọ́, ní ìbámu pẹ̀lú òṣùwọ̀n ènìyàn, tí ó tún jẹ́ ti áńgẹ́lì lẹ́sẹ̀ kan náà.” (Ìṣípayá 21:15-17) Nígbà tí wọ́n wọn ibùjọsìn tẹ́ńpìlì, ohun tó fi hàn ni pé ó dájú pé Jèhófà á mú ohun tó ní lọ́kàn fún tẹ́ńpìlì náà ṣẹ. (Ìṣípayá 11:1) Bákan náà, bí áńgẹ́lì náà ṣe wọn Jerúsálẹ́mù Tuntun fi hàn pé ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún ìlú ológo yìí kò ṣeé yí padà. a
7. Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ìdíwọ̀n ìlú náà?
7 Ìlú yìí mà ṣàrà ọ̀tọ̀ o! Ìwọ̀n ẹ̀ wà ní dọ́gba-n-dọ́gba níbùú lóròó, ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlá [12,000] fọ́lọ́ǹgì (nǹkan bí okòólélẹ́gbọ̀kànlá [2,220] kìlómítà) yí ká, ìwọ̀n gíga ògiri tó sì yí i ká jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlélógóje [144], ìyẹn mítà mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64] tàbí igba ó lé mẹ́wàá [210] ẹsẹ̀ bàtà. Kò sí ìlú ńlá gidi kankan tó lè ní irú ìdiwọ̀n bẹ́ẹ̀ láé. Irú ìlú bẹ́ẹ̀ á gbà tó ìlọ́po mẹ́rìnlá àgbègbè tí Ísírẹ́lì òde òní gbà, yóò sì fẹ́rẹ̀ẹ́ fi ọ̀tàlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [560] kìlómítà ga lọ sójú òfuurufú! Ká rántí pé ńṣe la fún Jòhánù ní Ìṣípayá gẹ́gẹ́ bí àmì. Torí náà, kí ni ìdiwọ̀n wọ̀nyí sọ fún wa nípa Jerúsálẹ́mù Tuntun ti ọ̀run?
8. Kí ló túmọ̀ sí pé (a) àwọn ògiri ìlú náà ga ní ìwọ̀n 144 ìgbọ̀nwọ́? (b) ìdíwọ̀n ìlú náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlá [12,000] fọ́lọ́ǹgì? (d) ìrísí ìlú náà jẹ́ dọ́gba-n-dọ́gba níbùú àti lóròó?
8 Àwọn ògiri tó jẹ́ 144 ìgbọ̀nwọ́ ní gíga rán wa létí pé 144,000 àwọn tí Ọlọ́run tipasẹ̀ ẹ̀mí sọ dọmọ ni wọ́n para pọ̀ di ìlú náà. Nọ́ńbà náà 12 tó fara hàn nínú ìdíwọ̀n ẹgbẹ̀rún méjìlá [12,000] fọ́lọ́ǹgì ti ìlú náà—pẹ̀lú gígùn, ìbú, àti gíga tó dọ́gba—jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣètò nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Nítorí náà, Jerúsálẹ́mù Tuntun jẹ́ ètò tó mọ́yán lórí tí Ọlọ́run ṣe láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Àwọn tó wà nínú Ìjọba Jèhófà ni Jerúsálẹ́mù Tuntun, pẹ̀lú Ọba náà Jésù Kristi. Ká tún wá wo ìrísí ìlú náà: dọ́gba-n-dọ́gba ni níbùú àti lóròó. Nínú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì, dọ́gba-n-dọ́gba ni ìwọ̀n ibi Mímọ́ Jù Lọ níbùú àti lóròó, ohun tó ń ṣàpẹẹrẹ pé Jèhófà wà níbẹ̀ sì wà nínú ẹ̀. (1 Àwọn Ọba 6:19, 20) Ẹ wá wo bó ṣe bá a mu tó pé Jerúsálẹ́mù Tuntun, tí ògo Jèhófà fúnra rẹ̀ tànmọ́lẹ̀ sí, ni Jòhánù rí i tó tóbi tó sì gùn dọ́gba níbùú àti lóròó! Ìwọ̀n gbogbo apá ibi tí wọ́n wọ̀n lára rẹ̀ ló rí géérégé. Ìlú tí kò ní àìṣedéédéé tàbí àbùkù ni.—Ìṣípayá 21:22.
Àwọn Nǹkan Ìkọ́lé Ṣíṣeyebíye
9. Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe àwọn nǹkan ìkọ́lé tí wọ́n fi kọ́ ìlú náà?
9 Jòhánù ń bá àpèjúwe rẹ̀ lọ pé: “Wàyí o, ìgbékalẹ̀ ògiri rẹ̀ jẹ́ òkúta jásípérì, ìlú ńlá náà sì jẹ́ ògidì wúrà bí gíláàsì tí ó mọ́ kedere. Àwọn ìpìlẹ̀ ògiri ìlú ńlá náà ni a fi gbogbo onírúurú òkúta ṣíṣeyebíye ṣe lọ́ṣọ̀ọ́: ìpìlẹ̀ kìíní jẹ́ jásípérì, ìkejì sàfáyà, ìkẹta kásídónì, ìkẹrin ẹ́mírádì, ìkarùn-ún sádónísì, ìkẹfà sádíọ́sì, ìkeje kírísóláítì, ìkẹjọ bérílì, ìkẹsàn-án tópásì, ìkẹwàá kírísópírásì, ìkọkànlá háyásíǹtì, ìkejìlá ámétísì. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹnubodè méjìlá náà jẹ́ péálì méjìlá; ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹnubodè náà ni a fi péálì kan ṣe. Ọ̀nà fífẹ̀ ìlú ńlá náà sì jẹ́ ògidì wúrà, bí gíláàsì tí ń fi òdì-kejì hàn kedere.”—Ìṣípayá 21:18-21.
10. Kí ló túmọ̀ sí pé jásípérì, wúrà, àti “gbogbo onírúurú òkúta ṣíṣeyebíye” ni wọ́n fi kọ́ ìlú náà?
10 Ká sóòótọ́, ìlú ológo ni ìlú yẹn! Kàkà kí wọ́n fi àwọn ohun èlò ìkọ́lé kan ṣáá, tí wọ́n fi ń kọ́lé láyé, bí amọ̀ tàbí òkúta kọ́ ọ, ohun tá a kà pé wọ́n fi kọ́ ọ ni jásípérì, ògidì wúrà, àti “gbogbo onírúurú òkúta ṣíṣeyebíye.” Dájúdájú, àwọn ohun èlò tó ṣeé ṣàkàwé ilé ti ọ̀run gan-an nìwọ̀nyí! Kò sí nǹkan tó tún lè ní ògo ju ìwọ̀nyí lọ. Ògidì wúrà ni wọ́n fi bo àpótí májẹ̀mú ìgbàanì, àwọn nǹkan tó dára tó tún ṣeyebíye ni wúrà sì sábà máa ń dúró fún nínú Bíbélì. (Ẹ́kísódù 25:11; Òwe 25:11; Aísáyà 60:6, 17) Ṣùgbọ́n tínú tòde Jerúsálẹ́mù Tuntun, tó fi mọ́ ọ̀nà rẹ̀ fífẹ̀ pàápàá, jẹ́ kìkì “ògidì wúrà bí gíláàsì tí ó mọ́ kedere,” èyí fi hàn pé ẹwà rẹ̀ àti ìníyelórí rẹ̀ kọjá ohun tá a lè finú yàwòrán.
11. Kí ló mú kó dájú pé àwọn tí wọ́n para pọ̀ di Jerúsálẹ́mù Tuntun á máa tàn yòò pẹ̀lú ọlá ńlá, tí wọ́n á sì mọ́ gaara nípa tẹ̀mí?
11 Kò sí ayọ́rin ayé kankan tó lè ṣe irú ojúlówó wúrà bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n Jèhófà ni Ọ̀gá Olùyọ́hunmọ́. Ó jókòó “gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń yọ́ fàdákà, tí ó sì ń fọ̀ ọ́ mọ́,” ó sì ń yọ́ àwọn olùṣòtítọ́ ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí mọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan “bí wúrà àti bí fàdákà,” ní mímú gbogbo èérí kúrò lára wọn. Kìkì àwọn tí Jèhófà yọ́ mọ́ tó sì ti wẹ̀ mọ́ ní tòótọ́ ló máa para pọ̀ jẹ́ Jerúsálẹ́mù Tuntun níkẹyìn. Nípa báyìí, àwọn ààyè ohun èlò ìkọ́lé, tó ń tàn yòò pẹ̀lú ọlá ńlá, tó sì mọ́ gaara nípa tẹ̀mí, ni Jèhófà fi kọ́ ìlú náà.—Málákì 3:3, 4.
12. Kí ni (a) òkúta iyebíye ni Jèhófà fi ṣe àwọn ìpìlẹ̀ ìlú náà méjèèjìlá lọ́ṣọ̀ọ́ fi hàn? (b) jíjẹ́ tí àwọn ibodè ìlú náà jẹ́ péálì fi hàn?
12 Kódà àwọn ìpìlẹ̀ ìlú náà lẹ́wà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òkúta ṣíṣeyebíye méjìlá ni Jèhófà fi ṣe wọ́n lọ́ṣọ̀ọ́. Èyí múni rántí àlùfáà àgbà àwọn Júù látijọ́, láwọn ọjọ́ ayẹyẹ, ó máa ń wọ ẹ̀wù éfódì kan tí wọ́n to òkúta ṣíṣeyebíye méjìlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sí lára, èyí dà bí ẹní jọ àwọn ohun tí Jòhánù ń ṣàpèjúwe yìí. (Ẹ́kísódù 28:15-21) Ó dájú pé èyí ò ṣèèṣì jọra! Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ká rí iṣẹ́ àlùfáà Jerúsálẹ́mù Tuntun, èyí tí Jésù, Àlùfáà Àgbà ńlá náà, jẹ́ “fìtílà” fún. (Ìṣípayá 20:6; 21:23; Hébérù 8:1) Bákan náà, nípasẹ̀ Jerúsálẹ́mù Tuntun làwọn àǹfààní iṣẹ́ Jésù, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà fi ń nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ aráyé. (Ìṣípayá 22:1, 2) Ibodè méjìlá ìlú náà, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ jẹ́ péálì tí ẹwà ẹ̀ jojú ní gbèsè, ránni létí àkàwé tí Jésù fi fi Ìjọba Ọlọ́run wé péálì iyebíye kan. Gbogbo àwọn tó ń gba ẹnu ibodè wọ̀nyẹn wọlé ti ní láti máa fi ojúlówó ìmọrírì hàn fáwọn ohun tẹ̀mí.—Mátíù 13:45, 46; fi wé Jóòbù 28:12, 17, 18.
Ìlú Ìmọ́lẹ̀
13. Kí ni Jòhánù sọ tẹ̀ lé e nípa Jerúsálẹ́mù Tuntun, kí ló sì dé tí ìlú náà ò fi nílò tẹ́ńpìlì èyíkéyìí?
13 Nígbà ayé Sólómọ́nì, ohun tó ṣe pàtàkì jù ní Jerúsálẹ́mù ni tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ sí ibi gíga jù lọ nílùú náà lórí Òkè Móráyà tó wà níhà àríwá. Ṣùgbọ́n ti Jerúsálẹ́mù Tuntun ńkọ́? Jòhánù wí pé: “Èmi kò sì rí tẹ́ńpìlì kan nínú rẹ̀, nítorí Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹ́ńpìlì rẹ̀, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Ìlú ńlá náà kò sì nílò oòrùn tàbí òṣùpá láti ràn sórí rẹ̀, nítorí ògo Ọlọ́run mú un mọ́lẹ̀ kedere, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà sì ni fìtílà rẹ̀.” (Ìṣípayá 21:22, 23) Lóòótọ́, kò sí ìdí láti kọ́ tẹ́ńpìlì gidi kan síbẹ̀. Àpẹẹrẹ lásán ni tẹ́ńpìlì àwọn Júù ìgbàanì jẹ́, tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí, tí tẹ́ńpìlì àwọn Júù ṣe àpẹẹrẹ rẹ̀, ti wà látìgbà tí Jèhófà ti fòróró yan Jésù gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni. (Mátíù 3:16, 17; Hébérù 9:11, 12, 23, 24) Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí tẹ́ńpìlì kan bá wà, àwùjọ àwọn àlùfáà tó ń rú ẹbọ sí Jèhófà nítorí àwọn èèyàn ní láti wà. Ṣùgbọ́n àlùfáà ni gbogbo àwọn tó jẹ́ ara Jerúsálẹ́mù Tuntun. (Ìṣípayá 20:6) Àti pé ẹbọ ńlá náà, tó jẹ́ ìwàláàyè èèyàn pípé Jésù, ni Jésù ti rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, láìní í tún un ṣe mọ́ láé. (Hébérù 9:27, 28) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, olúkúlùkù ẹni tó ń gbé ìlú náà ló lè dé ọ̀dọ̀ Jèhófà gan-an.
14. (a) Kí nìdí tí Jerúsálẹ́mù Tuntun ò fi nílò kí oòrùn àti òṣùpá ràn sórí ẹ̀? (b) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa ètò Jèhófà lápapọ̀ láyé àti lọ́run, báwo sì lèyí ṣe kan Jerúsálẹ́mù Tuntun?
14 Nígbà tí ògo Jèhófà gba iwájú Mósè kọjá lórí Òkè Sínáì, ó mú kí ojú Mósè tàn yòò tó bẹ́ẹ̀ tí Mósè fi ní láti bo ojú ẹ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tiẹ̀. (Ẹ́kísódù 34:4-7, 29, 30, 33) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ o ò rí i pé ìlú náà tí ògo Jèhófà ń tànmọ́lẹ̀ sí nígbà gbogbo á máa tàn yòò gan-an ni? Ilẹ̀ ò ní ṣú ní irú ìlú bẹ́ẹ̀. Kò nílò oòrùn tàbí òṣùpá gidi. Títí ayé ni yóò máa tan ìmọ́lẹ̀ jáde. (Fi wé 1 Tímótì 6:16.) Bí ìmọ́lẹ̀ Jerúsálẹ́mù Tuntun ṣe ń tàn yòò nìyẹn. Ní tòótọ́, ìyàwó yìí àti Ọkọ rẹ̀ Ọba di olú ìlú ètò Jèhófà lápapọ̀ láyé àti lọ́run, ìyẹn “obìnrin” rẹ̀ tó jẹ́ “Jerúsálẹ́mù ti òkè.” Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé: “Oòrùn kì yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ mọ́ ní ọ̀sán, òṣùpá pàápàá kì yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀ mọ́ fún ìtànyòò. Jèhófà yóò sì di ìmọ́lẹ̀ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin fún ọ, Ọlọ́run rẹ yóò sì di ẹwà rẹ. Oòrùn rẹ kì yóò wọ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá rẹ kì yóò wọ̀ọ̀kùn; nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò di ìmọ́lẹ̀ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin fún ọ, àwọn ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ yóò sì parí dájúdájú.”—Aísáyà 60:1, 19, 20; Gálátíà 4:26.
Ìmọ́lẹ̀ Fáwọn Orílẹ̀-Èdè
15. Àwọn ọ̀rọ̀ Ìṣípayá wo nípa Jerúsálẹ́mù Tuntun ló jọra pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà?
15 Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí kan náà tún sọ pé: “Dájúdájú, àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì lọ sínú ìmọ́lẹ̀ rẹ, àwọn ọba yóò sì lọ sínú ìtànyòò tí ó wá láti inú ìtànjáde rẹ.” (Aísáyà 60:3) Ìṣípayá ní tirẹ̀ fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí yóò kan Jerúsálẹ́mù Tuntun, ó ní: “Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa rìn nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, àwọn ọba ilẹ̀ ayé yóò sì mú ògo wọn wá sínú rẹ̀. A kì yóò sì sé ẹnubodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán, nítorí òru kì yóò sí níbẹ̀. Wọn yóò sì mú ògo àti ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú rẹ̀.”—Ìṣípayá 21:24-26.
16. Àwọn wo ni “àwọn orílẹ̀-èdè” tí yóò rìn nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ Jerúsálẹ́mù Tuntun?
16 Àwọn wo ni “àwọn orílẹ̀-èdè” wọ̀nyí tí wọ́n ń rìn nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ Jerúsálẹ́mù Tuntun? Àwọn làwọn èèyàn, tí wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ ara àwọn orílẹ̀-èdè ayé burúkú yìí, tí wọ́n ti wá sínú ìmọ́lẹ̀ tí ìlú ológo ti ọ̀run yìí ń tàn. Pàtàkì láàárín wọn ni ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí wọ́n ti jáde látinú “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” tí wọ́n sì ń jọ́sìn Ọlọ́run tọ̀sán-tòru pẹ̀lú ẹgbẹ́ Jòhánù. (Ìṣípayá 7:9, 15) Lẹ́yìn tí Jerúsálẹ́mù Tuntun bá ti sọ̀ kalẹ̀ látọ̀run tí Jésù sì lo kọ́kọ́rọ́ ikú àti Hédíìsì láti fi jí àwọn òkú dìde, ọ̀kẹ́ àìmọye púpọ̀ sí i, látinú “àwọn orílẹ̀-èdè” yóò dara pọ̀ mọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá, ìyẹn àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, Ọ̀dọ́ Àgùntàn, Ọkọ Jerúsálẹ́mù Tuntun.—Ìṣípayá 1:18.
17. Àwọn wo ni “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” tí yóò “mú ògo wọn wá” sínú Jerúsálẹ́mù Tuntun?
17 Àwọn wo wá ni “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” tí wọ́n “mú ògo wọn wá sínú rẹ̀”? Wọn kì í ṣe àwọn ọba ilẹ̀ ayé gidi gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, nítorí wọ́n ti pa run nígbà tí wọ́n ń bá Ìjọba Ọlọ́run jà ní Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:14, 16; 19:17, 18) Àwọn ọba náà ha lè jẹ́ àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n di ara ogunlọ́gọ̀ ńlá bí, àbí wọ́n lè jẹ́ àwọn ọba tí wọ́n jí dìde tí wọ́n tẹrí ba fún Ìjọba Ọlọ́run nínú ayé tuntun? (Mátíù 12:42) Kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀, torí pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ògo irú àwọn ọba bẹ́ẹ̀ ló jẹ́ tayé ó sì ti ṣá tipẹ́tipẹ́. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” tí wọ́n mú ògo wọn wá sínú Jerúsálẹ́mù Tuntun ní láti jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí Jèhófà ti “rà . . . láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè” láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Jésù Kristi. (Ìṣípayá 5:9, 10; 22:5) Wọ́n mú ògo tí Ọlọ́run fi fún wọn wá sínú ìlú náà láti fi kún ìtànyòò rẹ̀.
18. (a) Àwọn wo ni ò ní dé inú Jerúsálẹ́mù Tuntun? (b) Kìkì àwọn wo ló máa láǹfààní láti wọnú ìlú náà?
18 Jòhánù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí kì í ṣe ọlọ́wọ̀ àti ẹnikẹ́ni tí ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun ìríra àti ní pípurọ́ kì yóò wọnú rẹ̀ lọ́nàkọnà; àyàfi àwọn tí a kọ sínú àkájọ ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni yóò wọnú rẹ̀.” (Ìṣípayá 21:27) Kò sí ohun kan tí ètò àwọn nǹkan ti Sátánì ti kó àbààwọ́n bá tó lè di ara Jerúsálẹ́mù Tuntun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà gbogbo làwọn ibodè rẹ̀ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, kò sẹ́ni tó “ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun ìríra àti ní pípurọ́” tó máa láǹfààní láti wọlé. Kò ní sáwọn apẹ̀yìndà kankan tàbí ẹnikẹ́ni tó wá látinú Bábílónì Ńlá nínú ìlú yẹn. Bí ẹnikẹ́ni bá sì gbìyànjú láti sọ ìlú náà di ẹlẹ́gbin nípa sísọ àwọn tó máa wà nínú rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú dìbàjẹ́ nígbà tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé, asán ni ìsapá wọn máa já sí. (Mátíù 13:41-43) Kìkì “àwọn tí a kọ sínú àkájọ ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” ìyẹn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], ló máa dénú Jerúsálẹ́mù Tuntun nígbẹ̀yìngbẹ́yín. b—Ìṣípayá 13:8; Dáníẹ́lì 12:3.
Odò Omi Ìyè Náà
19. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe mímú tí Jerúsálẹ́mù Tuntun á mú káwọn ìbùkún ṣàn wá sọ́dọ̀ aráyé? (b) Ìgbà wo ni “odò omi ìyè” ń ṣàn, báwo sì la ṣe mọ̀?
19 Jerúsálẹ́mù Tuntun ológo náà yóò mú káwọn ìbùkún títóbilọ́lá ṣàn wá sọ́dọ̀ aráyé lórí ilẹ̀ ayé. Èyí ni ohun tó wá yé Jòhánù báyìí. Ó ní: “Ó sì fi odò omi ìyè kan hàn mí, tí ó mọ́ kedere bí kírísítálì, tí ń ṣàn jáde láti ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà wá sí ìsàlẹ̀ gba àárín ọ̀nà fífẹ̀ rẹ̀.” (Ìṣípayá 22:1, 2a) Nígbà wo ni “odò” yìí ń ṣàn? Níwọ̀n bó ti ń ṣàn “jáde láti ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” ìgbà kan ṣoṣo tó lè jẹ́ náà ni ẹ̀yìn tí ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. Ìgbà yẹn ni àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ tí kàkàkí keje polongo ṣẹlẹ̀, tí ìkéde ọlọ́lá ńlá náà sì dún pé: “Nísinsìnyí ni ìgbàlà dé àti agbára àti ìjọba Ọlọ́run wa àti ọlá àṣẹ Kristi rẹ̀.” (Ìṣípayá 11:15; 12:10) Ní àkókò òpin, ẹ̀mí àti ìyàwó ń pe àwọn tó ní ọkàn tó dáa pé kí wọ́n wá gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. Omi tó wá láti inú odò yìí yóò máa wà fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ títí di òpin ètò àwọn nǹkan yìí, lẹ́yìn náà, yóò máa bá a lọ nínú ayé tuntun nígbà tí Jerúsálẹ́mù Tuntun ‘bá sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.’—Ìṣípayá 21:2.
20. Kí ló fi hàn pé ìwọ̀n omi ìyè díẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó nísinsìnyí?
20 Èyí kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí omi tí ń fúnni ní ìyè máa wà fáráyé. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ̀rọ̀ nípa omi tí ń fúnni ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 4:10-14; 7:37, 38) Síwájú sí i, Jòhánù máa tó gbọ́ ìkésíni onífẹ̀ẹ́ náà pé: “Àti ẹ̀mí àti ìyàwó ń bá a nìṣó ní sísọ pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí ń gbọ́ sì wí pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣípayá 22:17) Ìkésíni yìí là ń polongo títí di ìsinsìnyí pàápàá, èyí sì fi hàn pé ìwọ̀n omi ìyè díẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó báyìí ná. Ṣùgbọ́n nínú ayé tuntun, àwọn omi yẹn yóò ṣàn wá láti ibi ìtẹ́ Ọlọ́run lọ́pọ̀ yanturu, á sì jẹ́ nípasẹ̀ Jerúsálẹ́mù Tuntun.
21. Kí ni “odò omi ìyè” náà dúró fún, báwo sì ni ìran Ìsíkíẹ́lì nípa odò yìí ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀?
21 Kí ni “odò omi ìyè” yìí? Omi gidi jẹ́ ohun kan tó ṣe pàtàkì púpọ̀ féèyàn láti wà láàyè. Láìsí oúnjẹ èèyàn lè wà láàyè fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan, ṣùgbọ́n tí ò bá sómi èèyàn á kú ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan. A tún máa ń fi omi fọ nǹkan, ó sì wúlò gidigidi fún ìlera. Nípa báyìí, omi ìyè náà ní láti dúró fún ohun kan tó jẹ́ kò-ṣeé-mánìí fún ìwàláàyè ẹ̀dá àti ìlera aráyé. Jèhófà fi ìràn kan nípa “odò omi ìyè” yìí han wòlíì Ìsíkíẹ́lì, nínú ìran tó sì rí ọ̀hún, odò náà ṣàn jáde látinú tẹ́ńpìlì lọ sínú Òkun Òkú. Lẹ́yìn náà ló wá ṣe iṣẹ́ ìyanu tó ju iṣẹ́ ìyanu lọ! Omi tí èròjà olóró kún inú ẹ̀, tí kò sì sí ohun alààyè kankan nínú ẹ̀ dédé yí padà, ó di omi tó mọ́ gaara tí ẹja wá pọ̀ nínú ẹ̀! (Ìsíkíẹ́lì 47:1-12) Àní sẹ́, odò inú ìran náà mú kí ohun tó ti kú tẹ́lẹ̀ jí padà wá sí ìyè, ìyẹn sì jẹ́ ẹ̀rí pé odò omi ìyè náà ṣàpẹẹrẹ ìpèsè tí Ọlọ́run tipasẹ̀ Jésù Kristi ṣe fún mímú kí ìran èèyàn tó ti di “òkú” padà ní ìwàláàyè pípé. Odò yìí “mọ́ kedere bí kírísítálì,” èyí tó fi hàn pé àwọn ìpèsè Ọlọ́run mọ́ lóló. Kò dà bí “àwọn omi” aṣekúpani tàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, tí ẹ̀jẹ̀ pọ̀ nínú ẹ̀.—Ìṣípayá 8:10, 11.
22. (a) Ibo ni orísun odò náà, kí sì nìdí tó fi yẹ bẹ́ẹ̀? (b) Kí ló wà nínú omi ìyè náà, kí ni odò ìṣàpẹẹrẹ yìí sì tún ní nínú?
22 Ibi “ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” ni orísun odò yìí. Èyí bá a mu gẹ́ẹ́, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé lọ́lá ẹbọ ìràpadà náà ni Jèhófà fi pèsè ohun tó máa fún wa ní ìyè. Ìdí tí Jèhófà sì fi pèsè ẹ̀ ni pé ó “nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Omi ìyè náà tún ní í ṣe pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí Bíbélì sábà máa ń pè ní omi. (Éfésù 5:26) Àmọ́, kì í ṣe òtítọ́ nìkan ni odò omi ìyè náà, ó tún kan gbogbo ìpèsè tí Jèhófà ṣe fún wa lọ́lá ẹbọ Jésù, láti gba aráyé sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, àti láti fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 1:29; 1 Jòhánù 2:1, 2.
23. (a) Kí nìdí tó fi bá a mu láti sọ pé odò omi ìyè náà ń ṣàn gba agbedeméjì ọ̀nà fífẹ̀ Jerúsálẹ́mù Tuntun? (b) Ìlérí Ọlọ́run fún Ábúráhámù wo ni yóò nímùúṣẹ nígbà tí omi ìyè náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í tàkòtó wá lọ́pọ̀ yanturu?
23 Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà, iṣẹ́ àlùfáà Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] àlùfáà tó ń sìn lábẹ́ rẹ̀ yóò mú àǹfààní ìràpadà náà wá lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ó bá a mu nígbà náà, láti sọ pé odò omi ìyè náà ṣàn gba agbedeméjì ọ̀nà fífẹ̀ Jerúsálẹ́mù Tuntun kọjá. Jerúsálẹ́mù Tuntun yìí ni Ísírẹ́lì tẹ̀mí, tí àwọn àti Jésù para pọ̀ jẹ́ ojúlówó irú-ọmọ Ábúráhámù. (Gálátíà 3:16, 29) Nítorí náà, nígbà tí omi ìyè bá ń tàkòtó lọ́pọ̀ yanturu gba agbedeméjì ọ̀nà fífẹ̀ ìlú ìṣàpẹẹrẹ náà kọjá, “gbogbo orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé” ló máa ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àǹfààní láti bù kún ara wọn nípasẹ̀ irú-ọmọ Ábúráhámù. Ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù á wá nímùúṣẹ pátápátá.—Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18.
Àwọn Igi Ìyè
24. Kí ni Jòhánù rí nísinsìnyí níhà méjèèjì odò omi ìyè náà, kí sì ni wọ́n ṣàpẹẹrẹ?
24 Nínú ìran Ìsíkíẹ́lì, odò náà tilẹ̀ di àgbàrá, wòlíì yìí sì rí onírúurú gbogbo igi tó ń so èso bí wọ́n ṣe ń hù ní ìhà rẹ̀ méjèèjì. (Ìsíkíẹ́lì 47:12) Ṣùgbọ́n kí ni Jòhánù rí ní tiẹ̀? Òun rèé: “Àwọn igi ìyè tí ń mú irè oko méjìlá ti èso jáde sì wà níhà ìhín odò náà àti níhà ọ̀hún, tí ń so àwọn èso wọn ní oṣooṣù. Ewé àwọn igi náà sì wà fún wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn.” (Ìṣípayá 22:2b) “Àwọn igi ìyè” wọ̀nyí pẹ̀lú ní láti jẹ́ àpẹẹrẹ ara ìpèsè Jèhófà láti fún àwọn tó gbọ́ràn láàárín aráyé ní ìyè ayérayé.
25. Ìpèsè wọ̀ǹtìwọnti wo ni Jèhófà ṣe fáwọn tó ní etíìgbọ́ àti àyà ìgbàṣe nínú Párádísè tó kárí ayé?
25 Àbí ẹ ò rí ìbùkún yàbùgà yabuga tí Jèhófà pèsè fáwọn tó ní etíìgbọ́ àti àyà ìgbàṣe! Kì í ṣe pé wọ́n lè bù mu nínú omi atura wọ̀nyẹn nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún lè ká onírúurú àwọn èso tó ń tẹ́ni lọ́rùn tí ò yéé so lórí àwọn igi ìyẹn. Ì bá máa dáa o, ká ní àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti jẹ́ kí irú igi “tí ó dára” bí èyí, tó wà nínú Párádísè Édẹ́nì tẹ́ àwọn lọ́rùn! (Jẹ́nẹ́sísì 2:9) Ṣùgbọ́n, báyìí Párádísè tó kárí ayé ti dé, àti pé gan-an, Jèhófà ti tipasẹ̀ àwọn ewé igi ìṣàpẹẹrẹ ṣètò fún “wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn.” c Gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ làwọn ewé ìṣàpẹẹrẹ fi ta yọ gbogbo oògùn, egbòogi tàbí ohun èyíkéyìí mìíràn, tá à ń fi tọ́jú ara lónìí, bí aráyé onígbàgbọ́ bá ṣe ń lò ó, bẹ́ẹ̀ láá ṣe máa mú kí wọ́n ní ìlera nípa tara àti nípa tẹ̀mí títí wọ́n á fi dé ìjẹ́pípé.
26. Kí ló ṣeé ṣe kí àwọn igi ìyè tún ṣàpẹẹrẹ, kí sì nìdí?
26 Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó ṣeé ṣe kí àwọn igi tí odò náà ń bomi rin dáadáa, ṣàpẹẹrẹ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ìyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. Nígbà tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé, àwọn náà mu nínú ìpèsè tí Ọlọ́run tipasẹ̀ Jésù Kristi ṣe fún ìyè. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tiẹ̀ pe àwọn arákùnrin Jésù tí Jèhófà fẹ̀mí yàn wọ̀nyí ní “igi ńlá òdodo.” (Aísáyà 61:1-3; Ìṣípayá 21:6) Wọ́n ti mú èso ti ẹ̀mí púpọ̀ jáde, sí ìyìn Jèhófà. (Mátíù 21:43) Àti pé, nígbà Ẹgbẹ̀rúndún Ìṣàkóso náà, wọ́n á kópa nínú pínpín àwọn ìpèsè ìràpadà tí yóò wà fún “wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn” kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Fi wé 1 Jòhánù 1:7.
Òru Kò Sí Mọ́
27. Àwọn àfikún ìbùkún wo ni Jòhánù sọ pé ó wà fáwọn tí wọ́n láǹfààní láti wọlé sínú Jerúsálẹ́mù Tuntun, kí sì nìdí tó fi sọ pé “kì yóò sì sí ègún kankan mọ́”?
27 Dájúdájú, kò lè sí àǹfààní àgbàyanu kankan tó lè ju wíwọlé sínú Jerúsálẹ́mù Tuntun lọ! Tiẹ̀ rò ó wò ná—àwọn ẹ̀dá èèyàn rírẹlẹ̀, tó jẹ́ aláìpé nígbà kan rí, á lọ bá Jésù lọ́run láti di ara irú ìṣètò ológo yìí! (Jòhánù 14:2) Jòhánù sọ díẹ̀ fún wa nípa àwọn ìbùkún táwọn wọ̀nyí yóò gbádùn, ó wí pé: “Kì yóò sì sí ègún kankan mọ́. Ṣùgbọ́n ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò wà nínú ìlú ńlá náà, àwọn ẹrú rẹ̀ yóò sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un; wọn yóò sì rí ojú rẹ̀, orúkọ rẹ̀ yóò sì wà ní iwájú orí wọn.” (Ìṣípayá 22:3, 4) Nígbà tí ẹgbẹ́ àlùfáà Ísírẹ́lì di oníwà ìbàjẹ́, ó forí gba ègún Jèhófà. (Málákì 2:2) Jésù sọ pé a pa “ilé” Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ aláìnígbàgbọ́ tì. (Mátíù 23:37-39) Ṣùgbọ́n nínú Jerúsálẹ́mù Tuntun, Jòhánù sọ pé “kì yóò sì sí ègún kankan mọ́.” (Fi wé Sekaráyà 14:11.) Gbogbo àwọn táá gbé inú ẹ̀ ni àdánwò bí iná ti dán wò lórí ilẹ̀ ayé níbí, níwọ̀n bí wọ́n sì ti borí, wọ́n á ti ‘gbé àìdíbàjẹ́ àti àìkú wọ̀.’ Jèhófà mọ̀ pé ní tiwọn, wọn ò ní í ṣubú láé, gẹ́gẹ́ bó ti mọ ti Jésù náà. (1 Kọ́ríńtì 15:53, 57) Síwájú sí i, “ìtẹ́ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” yóò wà níbẹ̀, èyí á mú kí ìlú náà wà láìsí mìmì kan tó lè mì ín títí ayérayé.
28. Kí nìdí tí orúkọ Ọlọ́run fi wà ní iwájú orí àwọn tó máa jẹ́ ara Jerúsálẹ́mù Tuntun, ìrètí tí ń mórí yá wo sì ni wọ́n ní?
28 Bíi ti Jòhánù fúnra ẹ̀, gbogbo àwọn tó máa wà nínú ìlú ńlá òkè ọ̀run yẹn lọ́jọ́ iwájú jẹ́ “ẹrú” Ọlọ́run. Nítorí ìyẹn, orúkọ Ọlọ́run wà ní iwájú orí wọn ketekete, èyí sì fi hàn pé òun ni Ẹni tó ni wọ́n. (Ìṣípayá 1:1; 3:12) Wọn á kà á sí àǹfààní tí kò ṣeé díye lé láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ara Jerúsálẹ́mù Tuntun. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó ṣe ìlérí tí ń mórí yá fún irú àwọn olùṣàkóso yẹn, pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà, níwọ̀n bí wọn yóò ti rí Ọlọ́run.” (Mátíù 5:8) Ẹ wo báwọn ẹrú yìí á ti láyọ̀ tó lóòótọ́ láti rí Jèhófà fúnra rẹ̀ tí wọ́n á sì máa jọ́sìn rẹ̀!
29. Èé ṣe tí Jòhánù fi sọ pé ní Jerúsálẹ́mù Tuntun ti ọ̀run, “òru kì yóò sí mọ́”?
29 Jòhánù tẹ̀ síwájú pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, òru kì yóò sí mọ́, wọn kò sì nílò ìmọ́lẹ̀ fìtílà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò nílò ìmọ́lẹ̀ oòrùn, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run yóò tan ìmọ́lẹ̀ sórí wọn.” (Ìṣípayá 22:5a) Bó ṣe rí láwọn ìlú èyíkéyìí míì lórí ilẹ̀ ayé, ìmọ́lẹ̀ oòrùn ni wọ́n ń lò lọ́sàn-án ní Jerúsálẹ́mù àtijọ́, ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àti ìmọ́lẹ̀ míì táwọn èèyàn ṣe ni wọ́n ń lò lóru. Ṣùgbọ́n nínú Jerúsálẹ́mù Tuntun ti ọ̀run, wọn ò ní nílò irú ìmọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀. Jèhófà fúnra rẹ̀ ló máa tànmọ́lẹ̀ sí ìlú náà. A lè lo “òru” pẹ̀lú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó lè tọ́ka sí ìpọ́njú tàbí yíya nǹkan sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà. (Míkà 3:6; Jòhánù 9:4; Róòmù 13:11, 12) Kò lè sí irú òru bẹ́ẹ̀ láé níwájú Ọlọ́run Olódùmarè ológo tó ń ràn yòò.
30. Ọ̀rọ̀ wo ni Jòhánù fi mú ìran ológo náà wá sí òpin, kí sì ni Ìṣípayá mú dá wa lójú?
30 Jòhánù parí ìran ológo yìí nípa sísọ nípa àwọn ẹrú Ọlọ́run wọ̀nyí pé: “Wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé àti láéláé.” (Ìṣípayá 22:5b) Lóòótọ́, lópin ẹgbẹ̀rún ọdún, Jésù á ti nawọ́ àwọn àǹfààní ìràpadà sáwọn èèyàn tán, á sì kó ìran èèyàn tó ti di pípé wá síwájú Baba rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:25-28) A ò mọ ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] lẹ́yìn ìyẹn. Ṣùgbọ́n Ìṣípayá mú un dá wa lójú pé títí ayérayé ni àǹfààní iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wọn sí Jèhófà yóò máa bá a lọ.
Ìparí Aláyọ̀ Ìṣípayá
31. (a) Kí ni ìran Jerúsálẹ́mù Tuntun fi hàn pé ó máa ṣẹlẹ̀ ní ìparí pátápátá? (b) Kí ni Jerúsálẹ́mù Tuntun á ṣe fáwọn olùṣòtítọ́ yòókù lára aráyé?
31 Ìmúṣẹ ìran yìí nípa Jerúsálẹ́mù Tuntun, ìyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn, ni ìparí aláyọ̀ tí Ìṣípayá tọ́ka sí, ó sì yẹ bẹ́ẹ̀. Gbogbo àwọn Kristẹni arákùnrin Jòhánù ní ọ̀rúndún kìíní, tó dìídì kọ ìwé náà sí ń dúró de ìgbà tí wọ́n máa wọnú ìlú yẹn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí aláìleèkú tí wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù Kristi. Ìrètí kan náà ni àṣẹ́kù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣì wà láàyè lónìí lórí ilẹ̀ ayé ní. Nípa báyìí, bí àwọn tó para pọ̀ jẹ́ ìyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn ṣe ń dara pọ̀ mọ́ Ọ̀dọ́ Àgùntàn kí iye wọn lè pé pérépéré, Ìṣípayá ń tẹ̀ síwájú nìṣó sí ìparí rẹ̀ ológo. Lẹ́yìn náà, Jerúsálẹ́mù Tuntun á wá nawọ́ àwọn àǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù sí aráyé, kó bàa lè jẹ́ pé gbogbo àwọn olùṣòtítọ́ ni yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Lọ́nà yìí, ìyàwó náà, Jerúsálẹ́mù Tuntun, á nípìn-ín nínú sísọ ilẹ̀ ayé di ayé tuntun òdodo títí ayérayé, gẹ́gẹ́ bí ìyàwó adúrótini fún Ọkọ rẹ̀ Ọba. Gbogbo rẹ̀ á sì wá já sí ògo Jèhófà Olúwa wa Ọba Aláṣẹ.—Mátíù 20:28; Jòhánù 10:10, 16; Róòmù 16:27.
32, 33. Kí la ti kọ́ látinú Ìṣípayá, kí sì ló yẹ ká ṣe nípa rẹ̀ látọkànwá?
32 Ẹ ò rí bí ayọ̀ wa ti pọ̀ tó, bó ṣe kù díẹ̀ ká parí àgbéyẹ̀wò ìwé Ìṣípayá! A ti rí i táwọn ìsapá ìkẹyìn Sátánì àti irú-ọmọ rẹ̀ já sí pàbó, àti bí Jèhófà ṣe mú àwọn ìdájọ́ òdodo rẹ̀ ṣẹ pátápátá. Ó di dandan, Bábílónì Ńlá gbọ́dọ̀ dàwátì títí láé, gbogbo ìyókù àwọn oníwà ìbàjẹ́ tí wọn ò lé yí padà mọ́ nínú ayé Sátánì yóò sì tẹ̀ lé e. Sátánì fúnra rẹ̀ àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ á dèrò ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, wọ́n á sì pa run nígbà tó bá yá. Jerúsálẹ́mù Tuntun yóò máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi látọ̀run bí àjíǹde àti ìdájọ́ bá ṣe ń bá a lọ. Àwọn ọmọ aráyé tó ti di pípé yóò wá máa gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè ilẹ̀ ayé níkẹyìn. Ẹ wo bí Ìṣípayá ṣe ṣàpèjúwe gbogbo nǹkan wọ̀nyí kedere! Ẹ sì wo bó ti mú ká túbọ̀ pinnu láti ‘polongo ìhìn rere àìnípẹ̀kun yìí gẹ́gẹ́ bí àwọn làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn’ lórí ilẹ̀ ayé lónìí! (Ìṣípayá 14:6, 7) Ǹjẹ́ ò ń lo ara rẹ dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ ńlá yìí?
33 Pẹ̀lú ọkàn wa tó kún fún ìmoore yìí, ẹ jẹ́ ká wá kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ tó parí Ìṣípayá.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Pé ìwọ̀n tí áńgẹ́lì náà lò jẹ́ “ní ìbámu pẹ̀lú òṣùwọ̀n ènìyàn, tí ó tún jẹ́ ti áńgẹ́lì lẹ́sẹ̀ kan náà” lè ní í ṣe pẹ̀lú òtítọ́ náà pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n para pọ̀ di ìlú náà jẹ́ èèyàn látilẹ̀wá, ṣùgbọ́n tí wọ́n ti di ẹ̀dá ẹ̀mí láàárín àwọn áńgẹ́lì.
b Ṣàkíyèsí pé orúkọ àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] Ísírẹ́lì tẹ̀mí nìkan ló wà nínú “àkájọ ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Àgùntàn.” Nípa báyìí, ó yàtọ̀ sí “àkájọ ìwé ìyè” tí orúkọ àwọn tó gba ìyè lórí ilẹ̀ ayé wà nínú rẹ̀.—Ìṣípayá 20:12.
c Kíyè sí i pé ọ̀rọ̀ náà, “àwọn orílẹ̀-èdè” sábà máa ń tọ́ka sí àwọn tí kì í ṣe ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí. (Ìṣípayá 7:9; 15:4; 20:3; 21:24, 26) Bí Ìwé Mímọ́ ṣe lo ọ̀rọ̀ náà níbí kò túmọ̀ sí pé aráyé á tún ṣì wà nínú àwùjọ orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nígbà Ẹgbẹ̀rúndún Ìṣàkóso náà.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]