Ọ̀run Tuntun àti Ayé Tuntun
Orí 42
Ọ̀run Tuntun àti Ayé Tuntun
1. Kí ni Jòhánù sọ pé òun rí nígbà tí áńgẹ́lì náà dá a padà sí ìbẹ̀rẹ̀ Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà?
JÒHÁNÙ ò tíì rí ìran ológo tó ń rí náà parí. Áńgẹ́lì tó ń fi ìran ọ̀hún hàn án dá a padà sí ìbẹ̀rẹ̀ Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà. Kí ló rí? Ó sọ fún wa pé: “Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan; nítorí ọ̀run ti ìṣáájú àti ilẹ̀ ayé ti ìṣáájú ti kọjá lọ, òkun kò sì sí mọ́.” (Ìṣípayá 21:1) Dájúdájú, ìran ológo àrímáleèlọ, àwò-ò-padà-sẹ́yìn, ni Jòhánù rí!
2. (a) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun ṣe ṣẹ sára àwọn Júù tá a dá padà sí ilẹ̀ wọn lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Kristẹni? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yóò tún ní ìmúṣẹ mìíràn, báwo sì ni ìlérí yìí yóò ṣe ṣẹ?
2 Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà ayé Jòhánù, Jèhófà sọ fún Aísáyà pé: “Èmi yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun; àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.” (Aísáyà 65:17; 66:22) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ rẹ̀ àkọ́kọ́ nígbà táwọn Júù olóòótọ́ padà sí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Kristẹni lẹ́yìn tí wọ́n ti lo àádọ́rin [70] ọdún nígbèkùn Bábílónì. Nígbà tá a dá wọn padà sí ilẹ̀ wọn, wọ́n di àwùjọ ta a wẹ̀ mọ́, ìyẹn “ayé tuntun,” lábẹ́ ètò àkóso tuntun kan, ìyẹn “ọ̀run tuntun.” Àmọ́, àpọ́sítélì Pétérù fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ náà yóò tún ní ìmúṣẹ mìíràn, ó ní: “Ṣùgbọ́n ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí àwa ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Jòhánù wá fi hàn pé ìlérí yìí yóò nímùúṣẹ ní ọjọ́ Olúwa. “Ọ̀run ti ìṣáájú àti ilẹ̀ ayé ti ìṣáájú,” ìyẹn ètò àwọn nǹkan Sátánì àti ìjọba èèyàn tó jẹ́ apá kan rẹ̀, èyí tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń darí, yóò kọjá lọ. “Òkun,” ìyẹn aráyé ọlọ̀tẹ̀, oníwà búburú, kò ní sí mọ́. Ohun tó máa wá rọ́pò rẹ̀ ni “ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan.” Ilẹ̀ ayé tuntun yìí ni àwùjọ èèyàn tuntun lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ “ọ̀run tuntun kan,” ìyẹn àkóso tuntun ti Ìjọba Ọlọ́run.—Fi wé Ìṣípayá 20:11.
3. (a) Kí ni Jòhánù sọ pé òun rí, kí sì ni Jerúsálẹ́mù Tuntun? (b) Báwo ni Jerúsálẹ́mù Tuntun ṣe ‘sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run’?
3 Jòhánù ń bá a lọ láti sọ ohun tó rí, ó ní: “Mo rí ìlú ńlá mímọ́ náà pẹ̀lú, Jerúsálẹ́mù Tuntun, tí ń ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, a sì múra rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀.” (Ìṣípayá 21:2) Jerúsálẹ́mù tuntun jẹ́ ìyàwó Kristi. Àwọn tó sì para pọ̀ jẹ́ ìyàwó yìí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ títí tí wọ́n fi kú tá a sì jí dìde láti di ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Jésù tí Ọlọ́run ti ṣe lógo. (Ìṣípayá 3:12; 20:6) Bí Jerúsálẹ́mù orí ilẹ̀ ayé ṣe di ibi tí ìjọba Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un fìdí kalẹ̀ sí, bẹ́ẹ̀ ni Jerúsálẹ́mù Tuntun tó lógo àti Ọkọ rẹ̀ ṣe di ìjọba tó máa ṣàkóso lórí ètò àwọn nǹkan tuntun. Ìjọba yìí ni ọ̀run tuntun náà. ‘Ìyàwó náà sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run’ ní ti pé ó darí àfiyèsí rẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, kì í ṣe pé ó wá sórí ilẹ̀ ayé gan-an. Ìyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò máa ṣèrànlọ́wọ́ fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà láìyẹsẹ̀ láti ṣe àkóso òdodo lórí gbogbo aráyé. Dájúdájú, ìbùkún lèyí á jẹ́ fún ayé tuntun!
4. Ìlérí wo ni Ọlọ́run ṣe tó jọ èyí tó ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀?
4 Jòhánù tún sọ fún wa pé: “Pẹ̀lú ìyẹn, mo gbọ́ tí ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wí pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn.’” (Ìṣípayá 21:3) Nígbà tí Jèhófà bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un dá májẹ̀mú Òfin nígbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀, ó ṣèlérí pé: “Dájúdájú, èmi yóò . . . gbé àgọ́ ìjọsìn mi kalẹ̀ sí àárín yín, ọkàn mi kì yóò sì kórìíra yín tẹ̀gàntẹ̀gàn. Ní ti gidi, èmi yóò rìn ní àárín yín, èmi yóò sì fi hàn pé èmi ni Ọlọ́run yín, ẹ̀yin ní tiyín, yóò sì fi hàn pé ẹ jẹ́ ènìyàn mi.” (Léfítíkù 26:11, 12) Jèhófà tún ṣèlérí tó jọ èyí fáwọn èèyàn olóòótọ́ nínú ìran tí Jòhánù rí. Ní Ọjọ́ Ìdájọ́ ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún náà, wọ́n á di àkànṣe èèyàn fún un.
5. (a) Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe bá aráyé gbé nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà? (b) Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe máa bá aráyé gbé lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà?
5 Nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà, Jèhófà yóò máa bá aráyé “gbé” nípasẹ̀ ìṣètò onígbà kúkúrú, ẹni tó sì máa ṣojú fún un ni Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ Ọba. Àmọ́, tí Jésù bá fi Ìjọba lé Baba rẹ̀ lọ́wọ́ ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà, a ò ní nílò ọba tó ń ṣojú fún Jèhófà tàbí ẹni tí á máa bá wa bẹ̀bẹ̀ mọ́. Jèhófà á máa bá àwọn “ènìyàn rẹ̀” gbé nípa tẹ̀mí títí láé, á sì jẹ́ ní tààràtà láìsí pé ẹnì kan ń ṣojú fún un. (Fi wé Jòhánù 4:23, 24.) Ẹ ò rí i pé àǹfààní tó ga lèyí á jẹ́ fún aráyé tá a mú bọ̀ sípò!
6, 7. (a) Àwọn ìlérí àgbàyanu wo ni Jòhánù jẹ́ ká mọ̀, ta ló sì máa gbádùn àwọn ìbùkún náà? (b) Báwo ni Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe Párádísè kan tó máa jẹ́ Párádísè nípa tẹ̀mí àti nípa tara?
6 Jòhánù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:4) Èyí tún rán wa létí àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ti ṣe níṣàájú. Bí àpẹẹrẹ, Aísáyà náà wọ̀nà fún àkókò tí ikú àti ọ̀fọ̀ ò ní sí mọ́ tí ayọ̀ á sì rọ́pò ìbànújẹ́. (Aísáyà 25:8; 35:10; 51:11; 65:19) Jòhánù wá fi hàn pé, dájúdájú, àwọn ìlérí wọ̀nyí á nímùúṣẹ àgbàyanu ní Ọjọ́ Ìdájọ́ ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún náà. Ogunlọ́gọ̀ ńlá ló máa kọ́kọ́ gbádùn àwọn ìbùkún náà. “Ọ̀dọ́ Àgùntàn, tí ó wà ní àárín ìtẹ́ náà,” tí ń bá a nìṣó láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, “yóò sì máa ṣamọ̀nà wọn lọ sí àwọn ìsun omi ìyè. Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.” (Ìṣípayá 7:9, 17) Ṣùgbọ́n lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ gbogbo àwọn tó bá jí dìde tí wọ́n sì lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun tí Jèhófà pèsè yóò dara pọ̀ mọ́ wọn láti jọ gbádùn párádísè nípa tẹ̀mí àti nípa tara.
7 Aísáyà sọ pé: “Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí.” Bẹ́ẹ̀ ni, “ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.” (Aísáyà 35:5, 6) Kò mọ síbẹ̀ o, lákòókò yẹn, “dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Aísáyà 65:21, 22) Bẹ́ẹ̀ ni, a kì yóò pa wọ́n run kúrò lórí ilẹ̀ ayé.
8. Kí ni Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ nípa bí àwọn ìlérí àgbàyanu wọ̀nyí ṣe jẹ́ ohun tó ṣeé gbára lé?
8 Kò sí àní-àní pé à ń fojú inú rí àwọn ìbùkún ológo náà bá a ṣe ń ronú lórí àwọn ìlérí wọ̀nyí! Àwọn ohun àgbàyanu tí aráyé olóòótọ́ máa gbádùn lábẹ́ ìjọba ọ̀run ti wà ní sẹpẹ́. Ǹjẹ́ ìlérí ẹnu-dùn-ún-ròfọ́ làwọn ìlérí wọ̀nyí? Ṣé ńṣe ni wọ́n wulẹ̀ jẹ́ àlá tí ò lè ṣẹ tí ọkùnrin arúgbó kan tí wọ́n mú nígbèkùn ní erékùṣù Pátímọ́sì lá? Jèhófà fúnra rẹ̀ ló dáhùn. Ìṣípayá sọ pé: “Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ sì wí pé: ‘Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wí pé: ‘Kọ̀wé rẹ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.’ Ó sì wí fún mi pé: ‘Wọ́n ti ṣẹlẹ̀! Èmi ni Ááfà àti Ómégà, ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti òpin.’”—Ìṣípayá 21:5, 6a.
9. Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú hán-únhán-ún pé àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú yóò nímùúṣẹ?
9 Ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ ń fọwọ́ sí ìwé ẹ̀rí ìmúdánilójú tàbí ìwé ẹ̀rí jíjẹ́ oníǹkan láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún aráyé onígbọràn pé wọ́n á gba àwọn ìbùkún wọ̀nyí lọ́jọ́ iwájú. Ta ló gbójúgbóyà láti bi Ọlọ́run Olódùmarè tó mú àwọn ohun wọ̀nyí dá wa lójú, pé ṣé wọ́n á ṣẹ tàbí wọn kò ní ṣẹ? Àní àwọn ìlérí wọ̀nyí dájú débi pé Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa wọn bíi pé wọ́n ti nímùúṣẹ, ó ní: “Wọ́n ti ṣẹlẹ̀!” Ẹ tiẹ̀ gbọ́ ná, ṣé kì í ṣe Jèhófà ni “Ááfà àti Ómégà . . . , ẹni náà tí ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀, Olódùmarè”? (Ìṣípayá 1:8) Òun mà ni! Kódà òun fúnra rẹ̀ polongo pé: “Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn, yàtọ̀ sí mi, kò sí Ọlọ́run kankan.” (Aísáyà 44:6) Nítorí náà, ó lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ kó sì mú un ṣẹ láìkù síbì kan. Ẹ ò rí i pé ìyẹn mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára gan-an ni! Ó tún ṣèlérí pé: “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun”! Dípò ká máa béèrè bóyá àwọn ohun àgbàyanu wọ̀nyí á ṣẹlẹ̀ lóòótọ́, ńṣe ló yẹ ká máa bi ara wa pé: ‘Kí ni mo ní láti ṣe kí n lè rí àwọn ìbùkún wọ̀nyí gbà?’
“Omi” fún Ẹni Tí Òùngbẹ Ń Gbẹ
10. “Omi” wo ni Jèhófà ń fúnni, kí ló sì dúró fún?
10 Jèhófà fúnra rẹ̀ ló polongo pé: “Ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ ni èmi yóò fi fún láti inú ìsun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣípayá 21:6b) Kẹ́nì kan tó lè pa òùngbẹ yẹn, ẹni náà ní láti mọ̀ pé òun jẹ́ aláìní nípa tẹ̀mí kó sì fẹ́ láti tẹ́wọ́ gba “omi” tí Jèhófà ń pèsè. (Aísáyà 55:1; Mátíù 5:3) “Omi” wo ni? Jésù dáhùn ìbéèrè yẹn nígbà tó ń wàásù fún obìnrin kan lẹ́bàá kànga ní Samáríà. Ó sọ fún un pé: “Ẹni yòówù tí ó bá ń mu láti inú omi tí èmi yóò fi fún un, òùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ láé, ṣùgbọ́n omi tí èmi yóò fi fún un yóò di ìsun omi nínú rẹ̀ tí ń tú yàà sókè láti fi ìyè àìnípẹ̀kun fúnni.” “Ìsun omi ìyè” yẹn jẹ́ ohun tí Ọlọ́run pèsè láti dá aráyé padà sí ìjẹ́pípé, ó sì ń ṣàn wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi. Bíi ti obìnrin ará Samáríà yẹn, ó yẹ ká ní ìháragàgà gan-an láti mumi tó pọ̀ láti inú ìsun yẹn! Ó tún yẹ ká ṣe bíi ti obìnrin yẹn, ká pa ìfẹ́ tá a ní nínú àwọn ohun tara tì ká lè máa kéde ìhìn rere náà fáwọn èèyàn!—Jòhánù 4:14, 15, 28, 29.
Àwọn Tó Bá Ṣẹ́gun
11. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe, àwọn wo ló sì kọ́kọ́ ṣẹ sí lára?
11 Àwọn tó ń mu “omi” atunilára yẹn gbọ́dọ̀ ṣẹ́gun pẹ̀lú. Ìyẹn ni Jèhófà sọ tẹ̀ lé e, pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹ́gun yóò jogún nǹkan wọ̀nyí, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, yóò sì jẹ́ ọmọ mi.” (Ìṣípayá 21:7) Ìlérí yìí jọ àwọn ìlérí tá a rí nínú iṣẹ́ tí Jésù rán sí àwọn ìjọ méje náà; nítorí náà, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣẹ sára àwọn ọmọlẹ́yìn tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. (Ìṣípayá 2:7, 11, 17, 26-28; 3:5, 12, 21) Ọjọ́ pẹ́ táwọn arákùnrin Jésù nípa tẹ̀mí ti ń fi ìháragàgà retí àǹfààní jíjẹ́ ara Jerúsálẹ́mù Tuntun. Bí wọ́n bá ṣẹ́gun bí Jésù ṣe ṣẹ́gun, ọwọ́ wọn á tẹ ohun tí wọ́n ń retí.—Jòhánù 16:33.
12. Báwo ni ìlérí Jèhófà nínú Ìṣípayá 21:7 yóò ṣe ṣẹ sára ogunlọ́gọ̀ ńlá?
12 Ogunlọ́gọ̀ ńlá láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ń retí ìmúṣẹ ìlérí yìí. Àwọn náà gbọ́dọ̀ ṣẹ́gun, kí wọ́n máa sin Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ títí tí wọ́n á fi jáde láti inú ìpọ́njú ńlá. Ìgbà náà ni wọ́n á rí ogún wọn ti orí ilẹ̀ ayé gbà, ‘ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún wọn láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.’ (Mátíù 25:34) Àwọn tó jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí àtàwọn àgùntàn Olúwa yòókù lórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n bá yege ìdánwò ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún la pè ní “àwọn ẹni mímọ́.” (Ìṣípayá 20:9) Ìbátan mímọ́ tó jẹ́ ti baba sí ọmọ yóò wà láàárín àwọn àti Jèhófà Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá wọn, wọ́n á jẹ́ ara ètò àgbáyé rẹ̀.—Aísáyà 66:22; Jòhánù 20:31; Róòmù 8:21.
13, 14. Ká tó lè rí àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣèlérí gbà, àwọn àṣà wo la gbọ́dọ̀ pinnu pé a ò ní lọ́wọ́ sí, kí sì nìdí?
13 Pẹ̀lú ohun àgbàyanu tá à ń retí yìí, ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an ni, pé ní báyìí, káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà ní mímọ́ tónítóní, ká má ṣe jẹ́ kí àwọn ohun aláìmọ́ tó wà nínú ayé Sátánì sọ wá di aláìmọ́! A ní láti jẹ́ alágbára, ká jẹ́ aláìyẹhùn, ká sì pinnu pé a ò ní jẹ́ kí Èṣù fà wá lọ láti di ara àwọn tí Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ nípa wọn, pé: “Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ojo àti àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ àti àwọn tí ń ríni lára nínú èérí wọn àti àwọn òṣìkàpànìyàn àti àwọn àgbèrè àti àwọn tí ń bá ẹ̀mí lò àti àwọn abọ̀rìṣà àti gbogbo òpùrọ́, ìpín tiwọn yóò wà nínú adágún tí ń fi iná àti imí ọjọ́ jó. Èyí túmọ̀ sí ikú kejì.” (Ìṣípayá 21:8) Dájúdájú, ẹni tó bá máa rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà gbà ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà tó ti sọ ètò ògbólógbòó yìí di aláìmọ́. Ó ní láti ṣẹ́gun, bó sì ṣe máa ṣẹ́gun ni pé kó máa bá a lọ láti jẹ́ olóòótọ́ láìfi gbogbo ìṣòro àti ìdẹwò pè.—Róòmù 8:35-39.
14 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sọ pé àwọn ni ìyàwó Kristi, síbẹ̀, àwọn àṣà akóninírìíra tí Jòhánù sọ kún ọwọ́ wọn. Nítorí náà, ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yóò lọ sínú ìparun ayérayé pa pọ̀ mọ́ ìyókù Bábílónì Ńlá. (Ìṣípayá 18:8, 21) Bákan náà, tí ẹnikẹ́ni lára àwọn ẹni àmì òróró tàbí ogunlọ́gọ̀ ńlá bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi irú àwọn ìwà búburú bẹ́ẹ̀ ṣèwà hù tàbí tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbé e lárugẹ, ẹni náà á dojú kọ ìparun àìnípẹ̀kun. Tí ò bá yéé ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní rí ìmúṣẹ ìlérí náà gbà. Bákan náà, nínú ayé tuntun, tí ẹnikẹ́ni bá gbìyànjú láti gbé irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ lárugẹ, kíákíá lẹni náà á pa run, á sì lọ sínú ikú kejì tí kò ti ní sí ìrètí àjíǹde.—Aísáyà 65:20.
15. Àwọn wo ló ta yọ lára àwọn tó ṣẹ́gun, ìran wo ló sì mú Ìṣípayá wá sí ìparí rẹ̀ ológo?
15 Àwọn tó ta yọ lára àwọn tó ṣẹ́gun ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Jésù Kristi, àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ìyàwó rẹ̀, tí í ṣe Jerúsálẹ́mù Tuntun. Nítorí náà, ó bá a mu gan-an ni pé kí ìran nípa Jerúsálẹ́mù Tuntun tí ògo rẹ̀ ta yọ mú Ìṣípayá wá sí ìparí rẹ̀ ológo! Ní báyìí, Jòhánù máa ṣàpèjúwe ìran kan ṣoṣo tó gbẹ̀yìn.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 302]
Nínú ayé tuntun, gbogbo èèyàn á gbádùn iṣẹ́ aláyọ̀ àti ìfararora alárinrin