Ọba Ajagun Náà Ṣẹ́gun ní Amágẹ́dọ́nì
Orí 39
Ọba Ajagun Náà Ṣẹ́gun ní Amágẹ́dọ́nì
Ìran 13—Ìṣípayá 19:11-21
Ohun tó dá lé: Jésù ṣáájú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run láti pa ètò àwọn nǹkan Sátánì run
Ìgbà tó nímùúṣẹ: Ẹ̀yìn ìparun Bábílónì Ńlá
1. Kí ni Amágẹ́dọ́nì, kí ló sì fà á?
AMÁGẸ́DỌ́NÌ! Ọ̀rọ̀ tó ń ba ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́rù ni. Ṣùgbọ́n fáwọn olùfẹ́ òdodo, ó ṣàpẹẹrẹ ọjọ́ tá a ti ń retí tipẹ́tipẹ́ tí Jèhófà yóò mú ìdájọ́ ìkẹyìn wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè. Amágẹ́dọ́nì kì í ṣe ogun èèyàn bí kò ṣe “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” tí í ṣe ọjọ́ tí yóò gbẹ̀san lára àwọn alákòóso ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 16:14, 16; Ìsíkíẹ́lì 25:17) Nígbà tí Bábílónì Ńlá bá pa run, ìpọ́njú ńlá yóò ti bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Sátánì yóò mú kí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà àti ìwo rẹ̀ mẹ́wàá gbéjà ko àwọn èèyàn Jèhófà. Inú ń bí Èṣù sí ètò Ọlọ́run tó dà bí obìnrin, àkókò yìí sì ni inú tó ń bí i yìí tíì le jù lọ, èyí ló mú kó pinnu láti lo àwọn tó ti tàn jẹ láti máa gbógun ti àwọn tó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ obìnrin náà. (Ìṣípayá 12:17) Àǹfààní ìkẹyìn tí Sátánì ní ló ń lò yìí!
2. Ta ni Gọ́ọ̀gù ará Mágọ́gù, báwo sì ni Jèhófà ṣe mú kó gbéjà ko àwọn èèyàn òun?
2 Ìwé Ìsíkíẹ́lì orí kéjìdínlógójì ṣàlàyé bí Èṣù ṣe ń gbéjà koni lọ́nà rírorò. Ó pe Sátánì tí Jèhófà ti rẹ̀ nípò wálẹ̀ ní “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù.” Jèhófà yóò fi ìwọ̀ ìṣàpẹẹrẹ kọ́ páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ Gọ́ọ̀gù, á fi fa òun àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ púpọ̀ rẹpẹtẹ kí wọ́n lè gbéjà koni. Báwo ni Jèhófà yóò ṣe ṣe èyí? Yóò ṣe bẹ́ẹ̀ nípa mímú kí Gọ́ọ̀gù rò pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ àwọn èèyàn tí kò ní olùgbèjà, “tí a kó jọpọ̀ láti inú àwọn orílẹ̀-èdè, èyí tí ń kó ọlà àti dúkìá jọ rẹpẹtẹ, àwọn tí ń gbé ní àárín ilẹ̀ ayé.” Àwọn wọ̀nyí wà láàárín ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí àwùjọ èèyàn kan ṣoṣo tó kọ̀ láti jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà àti ère rẹ̀. Okun àti aásìkí tẹ̀mí tí wọ́n ní nínú ìjọsìn Ọlọ́run ń múnú bí Gọ́ọ̀gù gan-an. Nítorí náà Gọ́ọ̀gù àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, tó fi mọ́ ẹranko ẹhànnà tó ti inú òkun wá pẹ̀lú ìwo rẹ̀ mẹ́wàá, jáde wá láti pa wọ́n. Àmọ́, ọ̀ràn àwọn èèyàn mímọ́ Ọlọ́run kò ní dà bíi ti Bábílónì Ńlá, Ọlọ́run yóò dáàbò bò wọ́n!—Ìsíkíẹ́lì 38:1, 4, 11, 12, 15; Ìṣípayá 13:1.
3. Báwo ni Jèhófà yóò ṣe palẹ̀ àwọn agbo ológun Gọ́ọ̀gù mọ́?
3 Báwo ni Jèhófà yóò ṣe palẹ̀ Gọ́ọ̀gù àti gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀ mọ́? Fetí sílẹ̀! “‘Dájúdájú, èmi yóò sì pe idà kan jáde lòdì sí i jákèjádò ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá mi,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. ‘Idà olúkúlùkù yóò wá lòdì sí arákùnrin rẹ̀.’” Ṣùgbọ́n àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà tàbí ìbọn àti idà kò ní wúlò nínú ìjà yẹn, nítorí Jèhófà polongo pé: “Ṣe ni èmi yóò mú ara mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ̀, pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn àti ẹ̀jẹ̀; àti eji wọwọ tí ń kún àkúnya àti òkúta yìnyín, iná àti imí ọjọ́ ni èmi yóò rọ̀ lé e lórí àti sórí àwùjọ ọmọ ogun rẹ̀ àti sórí ọ̀pọ̀ èèyàn tí yóò wà pẹ̀lú rẹ̀. Dájúdájú, èmi yóò sì gbé ara mi ga lọ́lá, èmi yóò sì sọ ara mi di mímọ́, èmi yóò sì sọ ara mi di mímọ̀ lójú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè; wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”—Ìsíkíẹ́lì 38:21-23; 39:11; fi wé Jóṣúà 10:8-14; Onídàájọ́ 7:19-22; 2 Kíróníkà 20:15, 22-24; Jóòbù 38:22, 23.
Ẹni Tí A Pè Ní “Aṣeégbíyèlé àti Olóòótọ́”
4. Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe Jésù Kristi nínú ìjáde ogun?
4 Jèhófà yóò pe idà kan jáde. Ta ló máa lo idà náà? Nígbà tá a padà wo ìwé Ìṣípayá, a rí ìdáhùn náà nínú ìran mìíràn tó ń mórí ẹni wú. Jòhánù rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀ láti ṣí ohun kan tó ń múni kún fún ẹ̀rù gan-an payá, ìyẹn Jésù Kristi fúnra rẹ̀ nínú ìjáde ogun! Jòhánù sọ fún wa pé: “Mo sì rí tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó! ẹṣin funfun kan. Ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni a ń pè ní Aṣeégbíyèlé àti Olóòótọ́, ó ń ṣèdájọ́, ó sì ń bá ogun lọ nínú òdodo. Ojú rẹ̀ jẹ́ ọwọ́ iná ajófòfò, adé dáyádémà púpọ̀ sì wà ní orí rẹ̀.”—Ìṣípayá 19:11, 12a.
5, 6. Kí ni àwọn nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí, (a) “ẹṣin funfun”? (b) orúkọ náà “Aṣeégbíyèlé àti Olóòótọ́”? (d) àwọn ojú bí “ọwọ́ iná ajófòfò”? (e) “adé dáyádémà púpọ̀”?
5 Bíi ti ẹṣin funfun tí Jòhánù rí nínú ìran ẹlẹ́ṣin mẹ́rin tó rí níṣàájú, “ẹṣin funfun” yìí jẹ́ àmì tó ṣàpẹẹrẹ ogun òdodo. (Ìṣípayá 6:2) Ǹjẹ́ ẹnì kan sì wà láàárín àwọn ọmọ Ọlọ́run tó tún lè jẹ́ olódodo ju Ajagun alágbára ńlá yìí? Níwọ̀n bá a ti pè é ní “Aṣeégbíyèlé àti Olóòótọ́,” ó ní láti jẹ́ pé òun ni “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́ [náà],” Jésù Kristi. (Ìṣípayá 3:14) Ó ń jagun láti lè mú àwọn ìdájọ́ òdodo Jèhófà wá sórí àwọn tó tọ́ sí. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ń lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ tí Jèhófà yàn, “Ọlọ́run Alágbára Ńlá.” (Aísáyà 9:6) Ojú rẹ̀ ń múni kún fún ẹ̀rù, ó rí bí “ọwọ́ iná ajófòfò,” ó ń wọ̀nà fún ìgbà tí ìparun amú-bí-iná máa dé bá àwọn ọ̀tá rẹ̀.
6 Adé dáyádémà wà lórí Ọba Ajagun yìí. Ẹranko ẹhànnà tí Jòhánù rí tó ń jáde bọ̀ láti inú òkun ní adé dáyádémà mẹ́wàá, tó ṣàpẹẹrẹ ìṣàkóso rẹ̀ onígbà kúkúrú lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 13:1) Ṣùgbọ́n, Jésù ní “adé dáyádémà púpọ̀.” Ìṣàkóso rẹ̀ ológo kò lẹ́gbẹ́, nítorí òun ni “Ọba àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti Olúwa àwọn tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí olúwa.”—1 Tímótì 6:15.
7. Kí ni orúkọ tá a kọ tí Jésù ń jẹ́?
7 Jòhánù ń bá àpèjúwe rẹ̀ lọ pé: “Ó ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnì kankan kò mọ̀ bí kò ṣe òun fúnra rẹ̀.” (Ìṣípayá 19:12b) Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ Bíbélì ti fi àwọn orúkọ bíi Jésù, Ìmánúẹ́lì, àti Máíkẹ́lì pe Ọmọ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ó dà bíi pé “orúkọ” tí ẹnì kankan kò mọ̀ yìí dúró fún ipò tí Jésù wà àtàwọn àǹfààní tó ní ní ọjọ́ Olúwa. (Fi wé Ìṣípayá 2:17.) Nígbà tí Aísáyà ń ṣàpèjúwe ipò Jésù látọdún 1914, ó sọ pé: “Orúkọ rẹ̀ ni a ó . . . máa pè ní Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára Ńlá, Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” (Aísáyà 9:6) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé orúkọ Jésù ní í ṣe pẹ̀lú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn gíga tí Jésù ní. Ó kọ̀wé pé: “Ọlọ́run . . . gbé [Jésù] sí ipò gíga, tí ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, kí ó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba.”—Fílípì 2:9, 10.
8. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jésù nìkan ló mọ orúkọ tá a kọ náà, àwọn wo ló sì fún ní díẹ̀ lára àwọn àǹfààní gíga tó ní?
8 Àwọn àǹfààní tí Jésù ní jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́. Yàtọ̀ sí Jèhófà fúnra rẹ̀, Jésù nìkan ṣoṣo ló lè mọ ohun tí wíwà ní irú ipò gíga bẹ́ẹ̀ túmọ̀ sí. (Fi wé Mátíù 11:27.) Nítorí náà, nínú gbogbo ẹ̀dá Ọlọ́run, Jésù nìkan ṣoṣo ló lè mọ ohun tí orúkọ yìí túmọ̀ sí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jésù fún ìyàwó rẹ̀ ní díẹ̀ lára àwọn àǹfààní wọ̀nyí. Nítorí náà, ó ṣèlérí yìí pé: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun . . . èmi yóò sì kọ . . . orúkọ mi tuntun yẹn sára rẹ̀.”—Ìṣípayá 3:12.
9. Kí ni (a) ‘fífi tá a fi ẹ̀wù àwọ̀lékè tá a fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n ṣe Jésù lọ́ṣọ̀ọ́’ fi hàn? (b) pípè tá a pe Jésù ní “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” fi hàn?
9 Jòhánù fi kún un pé: “A sì fi ẹ̀wù àwọ̀lékè tí a fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n ṣe é ní ọ̀ṣọ́, orúkọ tí a sì ń pè é ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Ìṣípayá 19:13) “Ẹ̀jẹ̀” ta nìyí? Ó lè jẹ́ ẹ̀jẹ̀ ìwàláàyè Jésù, tá a ta sílẹ̀ nítorí aráyé. (Ìṣípayá 1:5) Ṣùgbọ́n, nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó dà sílẹ̀ nígbà tó mú ìdájọ́ Jèhófà wá sórí wọn. Èyí rán wa létí ìran ìṣáájú níbi tí wọ́n ti kórè àjàrà ilẹ̀ ayé tí wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ nínú ìfúntí ńlá ti ìrunú Ọlọ́run títí ẹ̀jẹ̀ náà fi ga sókè “dé ìjánu ẹṣin” tó ń ṣàpẹẹrẹ ṣíṣẹ́gun tá a ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Ọlọ́run lọ́nà tó kàmàmà. (Ìṣípayá 14:18-20) Bákan náà, ẹ̀jẹ̀ tá a bù wọ́n ẹ̀wù àwọ̀lékè Jésù fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìṣẹ́gun rẹ̀ jẹ́ àṣekágbá àti àṣepé. (Fi wé Aísáyà 63:1-6.) Wàyí o, Jòhánù tún sọ̀rọ̀ nípa pípè tá a pe Jésù ní orúkọ kan. Lọ́tẹ̀ yìí, ó jẹ́ orúkọ kan tí wọ́n mọ̀ níbi gbogbo, ìyẹn “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” èyí tó fi Ọba Ajagun yìí hàn gẹ́gẹ́ bí Olórí Agbọ̀rọ̀sọ Jèhófà àti Alátìlẹyìn òtítọ́.—Jòhánù 1:1; Ìṣípayá 1:1.
Àwọn Ajagun Ẹlẹgbẹ́ Jésù
10, 11. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe fi hàn pé Jésù kò dánìkan jà ogun náà? (b) Kí ni jíjẹ́ táwọn ẹṣin náà jẹ́ funfun àti bí àwọn ẹlẹ́ṣin náà ṣe wọ “aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, funfun, tí ó mọ́” túmọ̀ sí? (d) Àwọn wo ni àwọn “ẹgbẹ́ ọmọ ogun” ọ̀run náà?
10 Jésù kò dánìkan ja ogun yìí. Jòhánù sọ fún wa pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń bẹ ní ọ̀run ń tẹ̀ lé e lórí àwọn ẹṣin funfun, wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, funfun, tí ó mọ́.” (Ìṣípayá 19:14) Jíjẹ́ táwọn ẹṣin náà jẹ́ “funfun” fi hàn pé ogun òdodo ni. “Aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà” yẹ àwọn agẹṣin Ọba àti pé fífunfun tí aṣọ náà funfun lọ́nà tó ń tan yinrin tó sì mọ́ tónítóní fi hàn pé wọ́n mọ́ wọ́n sì jẹ́ olódodo níwájú Jèhófà. Àwọn wo wá ni “ẹgbẹ́ ọmọ ogun” wọ̀nyí? Láìṣiyèméjì, àwọn áńgẹ́lì mímọ́ wà lára wọn. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa ni Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ fi Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ̀kò kúrò ní ọ̀run. (Ìṣípayá 12:7-9) Síwájú sí i, “gbogbo àwọn áńgẹ́lì” yóò ṣèránṣẹ́ fún Jésù bó ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ ológo tó sì ń ṣèdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn èèyàn ilẹ̀ ayé. (Mátíù 25:31, 32) Dájúdájú, nínú ogun àjàkẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù bá ń mú ìdájọ́ Ọlọ́run tó kẹ́yìn wá sórí àwọn tó tọ́ sí, àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ yóò tún tẹ̀ lé e.
11 Ọ̀rọ̀ náà yóò kan àwọn mìíràn pẹ̀lú. Nínú iṣẹ́ tí Jésù rán sí ìjọ tó wà ní Tíátírà, ó ṣèlérí pé: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, tí ó sì pa àwọn iṣẹ́ mi mọ́ títí dé òpin ni èmi yóò fún ní ọlá àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn tó bẹ́ẹ̀ tí a óò fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ bí àwọn ohun èlò amọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti gbà láti ọwọ́ Baba mi.” (Ìṣípayá 2:26, 27) Láìsí àní-àní, nígbà tí àkókò náà bá tó, àwọn tó ti wà ní ọ̀run nísinsìnyí lára àwọn arákùnrin Kristi yóò ní ipa nínú fífi ọ̀pá irin yẹn ṣolùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn àtàwọn orílẹ̀-èdè.
12. (a) Ṣé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé máa kópa nínú ìjà Amágẹ́dọ́nì? (b) Báwo ni Amágẹ́dọ́nì ṣe kan àwọn èèyàn Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé?
12 Àmọ́ ṣá o, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé? Ẹgbẹ́ Jòhánù kì yóò kó ipa kankan nínú ìjà Amágẹ́dọ́nì; bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń wọ́ tìrítìrí sínú ilé ìjọsìn Jèhófà nípa tẹ̀mí. Àwọn èèyàn tí ń wá àlàáfíà wọ̀nyí ti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀. (Aísáyà 2:2-4) Síbẹ̀, ọ̀ràn náà kàn wọ́n gan-an ni! Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkíyèsí tẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn Jèhófà tí wọ́n jọ ẹni tí kò lólùgbèjà ni Gọ́ọ̀gù àti gbogbo ogunlọ́gọ̀ rẹ̀ yóò gbéjà kò lọ́nà rírorò. Ìyẹn á jẹ́ àmì tó máa sọ fún Ọba Ajagun tí Jèhófà yàn tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run sì ń ṣètìlẹyìn fún, pé kó bẹ̀rẹ̀ sí i ja ogun tó máa pa àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn run pátápátá. (Ìsíkíẹ́lì 39:6, 7, 11; fi wé Dáníẹ́lì 11:44-12:1.) Gẹ́gẹ́ bí òǹwòran, àwọn èèyàn Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé yóò fẹ́ láti mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an. Amágẹ́dọ́nì yóò yọrí sí ìgbàlà fún wọn, wọ́n á fojú rí ogun ńlá tí Jèhófà fi dá ara rẹ̀ láre, wọn yóò sì wà láàyè títí láé.
13. Báwo la ṣe mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò lòdì sí gbogbo ìjọba?
13 Ṣe èyí túmọ̀ sí pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòdì sí gbogbo ìjọba? Rárá o! À ń ṣe ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga.” A mọ̀ pé níwọ̀n ìgbà tí ètò ìsinsìnyí bá ṣì ń bá a lọ, “àwọn aláṣẹ onípò gíga” wọ̀nyẹn wà nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Ọlọ́run láti lè mú kí àwùjọ èèyàn wà létòletò dé àyè kan. Nípa báyìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń san owó orí, à ń pa òfin mọ́, à ń tẹ̀ lé ìlànà tó ń darí ìrìnnà ọkọ̀, à ń tẹ̀ lé ètò ìforúkọsílẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Róòmù 13:1, 6, 7) Kò mọ síbẹ̀ o, à ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì ní ti pé à ń ṣòótọ́, a kì í ṣe màkàrúrù; à nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa; à ń jẹ́ kí ìdílé wa dúró sán-ún kó sì ní ìwà rere; à ń tọ́ àwọn ọmọ wa láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere láwùjọ. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé yàtọ̀ sí pé à ń san “àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì,” a tún ń san “àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Lúùkù 20:25; 1 Pétérù 2:13-17) Níwọ̀n bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti fi hàn pé fún ìgbà díẹ̀ làwọn ìjọba ayé yìí máa wà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń múra sílẹ̀ báyìí fún ìwàláàyè tí a óò gbádùn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ìyẹn ìwàláàyè gidi, èyí tí a óò gbádùn láìpẹ́ lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Kristi. (1 Tímótì 6:17-19) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ní kó ipa kankan nínú pípa àwọn ìjọba ayé yìí run, síbẹ̀ à ń ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún ohun tí Bíbélì Mímọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ìdájọ́ tí Jèhófà máa tó mú wá sórí àwọn ọ̀tá rẹ̀ ní Amágẹ́dọ́nì.—Aísáyà 26:20, 21; Hébérù 12:28, 29.
Ogun Àjàkẹ́yìn Yá!
14. Kí ni “idà gígùn mímú” tó yọ látẹnu Jésù ṣàpẹẹrẹ?
14 Àṣẹ wo ni Jésù yóò fi parí ìṣẹ́gun rẹ̀? Jòhánù sọ fún wa pé: “Idà gígùn mímú sì yọ jáde láti ẹnu rẹ̀, kí ó lè fi í ṣá àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn.” (Ìṣípayá 19:15a) “Idà gígùn mímú” yẹn ṣàpẹẹrẹ àṣẹ tí Ọlọ́run fún Jésù láti pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn tí wọ́n kọ̀ láti fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run run. (Ìṣípayá 1:16; 2:16) Ohun ìṣàpẹẹrẹ tó ṣe kedere yìí bá ohun tí Aísáyà sọ mu pé: “Ó [Jèhófà] sì tẹ̀ síwájú láti ṣe ẹnu mi bí idà mímú. Inú òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi mí pa mọ́ sí. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó sọ mí di ọfà dídán.” (Aísáyà 49:2) Nínú ẹsẹ yìí, Aísáyà ṣàpẹẹrẹ Jésù, tó pòkìkí àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run tó sì mú wọn ṣẹ, bí ẹni pé ó lo ọfà atamátàsé.
15. Lákòókò yẹn, ta la ó ti tú fó tí a ó sì ti ṣèdájọ́ rẹ̀, kí sì nìyẹn máa fi hàn pé ó ti bẹ̀rẹ̀?
15 Lákòókò yẹn, Jésù yóò ti gbégbèésẹ̀ láti mú àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ṣẹ pé: “Ní tòótọ́, nígbà náà ni a óò ṣí aláìlófin náà payá, ẹni tí Jésù Olúwa yóò fi ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ pa, tí yóò sì sọ di asán nípasẹ̀ ìfarahàn wíwàníhìn-ín rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, látọdún 1914 ni títú àṣírí ẹni àìlófin náà, ìyẹn ẹgbẹ́ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, àti ṣíṣe ìdájọ́ rẹ̀ ti fi wíwàníhìn-ín Jésù (lédè Gíríìkì, pa·rou·siʹa) hàn kedere. Yóò túbọ̀ hàn gbangba pé ó ti wà níhìn-ín nígbà tí ìwo mẹ́wàá ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò náà bá mú ìdájọ́ yẹn ṣẹ sórí ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì tó sì pa á run pátápátá, pa pọ̀ mọ́ àwọn ìsìn tó kù tó jẹ́ ara Bábílónì Ńlá. (2 Tẹsalóníkà 2:1-3, 8) Ìgbà yẹn ni ìpọ́njú ńlá náà yóò bẹ̀rẹ̀! Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù yóò yíjú sí ohun tó bá ṣẹ́ kù lára ètò Sátánì, tí yóò bá àsọtẹ́lẹ̀ náà mu tó sọ pé: “Yóò sì fi ọ̀pá ẹnu rẹ̀ lu ilẹ̀ ayé; yóò sì fi ẹ̀mí ètè rẹ̀ fi ikú pa ẹni burúkú.”—Aísáyà 11:4.
16. Báwo ni Sáàmù àti Jeremáyà ṣe ṣàpèjúwe ipa tí Ọba Ajagun tí Jèhófà yàn náà máa kó?
16 Ọba Ajagun náà tí Jèhófà yàn yóò fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn tí yóò là á já àtàwọn tí yóò kú. Nígbà tí Jèhófà, ń bá Ọmọ rẹ̀ yìí sọ̀rọ̀ lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀, ó ní: “Ìwọ yóò fi ọ̀pá aládé irin ṣẹ́ wọn [ìyẹn àwọn alákòóso ilẹ̀ ayé], bí ohun èlò amọ̀kòkò ni ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú.” Jeremáyà sì sọ fún irú àwọn aṣáájú ìjọba oníwà ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀ àtàwọn dọ̀bọ̀sìyẹsà ìránṣẹ́ wọn, pé: “Ẹ hu, ẹ̀yin olùṣọ́ àgùntàn, kí ẹ sì ké jáde! Ẹ yíràá, ẹ̀yin ọlọ́lá ọba inú agbo ẹran, nítorí ọjọ́ pípa yín àti títú yín ká ti pé, ẹ ó sì já bọ́ bí ohun èlò fífani-lọ́kàn-mọ́ra!” Bó ti wù kí àwọn alákòóso wọ̀nyẹn dára tó lójú ayé búburú yìí, ọ̀pá irin Ọba náà yóò fọ́ wọn túútúú tó bá kọ lù wọ́n lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ńṣe ló máa dà bí ẹní fọ́ ohun èlò amọ̀ tó jojú ní gbèsè túútúú. Bí Dáfídì ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jésù Olúwa ló máa rí, pé: “Ọ̀pá okun rẹ ni Jèhófà yóò rán jáde láti Síónì, pé: ‘Máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá rẹ.’ Jèhófà tìkára rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò fọ́ àwọn ọba sí wẹ́wẹ́ dájúdájú ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀. Òun yóò mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún láàárín àwọn orílẹ̀-èdè; òun yóò ṣokùnfà ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn òkú.”—Sáàmù 2:9, 12; 83:17, 18; 110:1, 2, 5, 6; Jeremáyà 25:34.
17. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe bí Ọba Ajagun náà ṣe máa mú ìdájọ́ ṣẹ? (b) Sọ díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó fi bí ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run yóò ṣe jẹ́ àjálù ńlá fún àwọn orílẹ̀-èdè hàn?
17 Ọba Ajagun alágbára ńlá yìí tún fara hàn lẹ́ẹ̀kan sí i nínú ìran yìí. Jòhánù ní: “Bákan náà, ó ń tẹ ìfúntí wáìnì ìbínú ìrunú Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìṣípayá 19:15b) Nínú ìran tó ṣáájú, Jòhánù ti rí títẹ “ìfúntí wáìnì . . . ti ìbínú Ọlọ́run.” (Ìṣípayá 14:18-20) Aísáyà pẹ̀lú ṣàpèjúwe ìfúntí wáìnì tí a ó ti mú ìdájọ́ ṣẹ sórí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run, àwọn wòlíì mìíràn sì sọ̀rọ̀ nípa bí ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run yóò ṣe jẹ́ àjálù ńlá fún gbogbo orílẹ̀-èdè.—Aísáyà 24:1-6; 63:1-4; Jeremáyà 25:30-33; Dáníẹ́lì 2:44; Sefanáyà 3:8; Sekaráyà 14:3, 12, 13; Ìṣípayá 6:15-17.
18. Kí ni wòlíì Jóẹ́lì sọ nípa bí Jèhófà yóò ṣe ṣèdájọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè?
18 Wòlíì Jóẹ́lì sọ pé ìfúntí wáìnì ní í ṣe pẹ̀lú dídé Jèhófà láti wá “ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yíká-yíká.” Kò sì sí àní-àní pé Jèhófà ló pàṣẹ fún Jésù tó jẹ́ Onídàájọ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Rẹ̀ àtàwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ọ̀run pé: “Ẹ ti dòjé bọ̀ ọ́, nítorí ìkórè ti pọ́n. Ẹ wá, ẹ sọ̀ kalẹ̀, nítorí ìfúntí wáìnì ti kún. Àwọn ẹkù ìfúntí ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ ní ti tòótọ́; nítorí ìwà búburú wọn ti pọ̀ yanturu. Ogunlọ́gọ̀, ogunlọ́gọ̀ wà ní pètẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu, nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu. Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn dájúdájú, gbogbo àwọn ìràwọ̀ yóò sì fawọ́ mímọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn dájúdájú. Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò sì ké ramúramù láti Síónì, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerúsálẹ́mù. Dájúdájú, ọ̀run àti ilẹ̀ ayé yóò mì jìgìjìgì; ṣùgbọ́n Jèhófà yóò jẹ́ ibi ìsádi fún àwọn èèyàn rẹ̀, àti odi agbára fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.”—Jóẹ́lì 3:12-17.
19. (a) Báwo la ó ṣe dáhùn ìbéèrè tá a béèrè ní 1 Pétérù 4:17? (b) Orúkọ wo la kọ sára ẹ̀wù àwọ̀lékè Jésù, kí nìdí tó fi yẹ bẹ́ẹ̀?
19 Lóòótọ́, ọjọ́ ègbé ni yóò jẹ́ fáwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbọràn, àmọ́ ọjọ́ ìtura ni yóò jẹ́ fún gbogbo àwọn tí wọ́n ti fi Jèhófà àti Ọba Ajagun tó yàn ṣe ibi ìsádi wọn! (2 Tẹsalóníkà 1:6-9) Ìdájọ́ tó bẹ̀rẹ̀ nílé Ọlọ́run lọ́dún 1918 yóò ti dé ìparí rẹ̀, tí yóò dáhùn ìbéèrè 1 Pétérù 4:17 pé: “Kí ni yóò jẹ́ òpin àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere Ọlọ́run?” Aṣẹ́gun ológo náà yóò ti tẹ ìfúntí wáìnì náà tán, tó fi hàn pé òun ni Ẹni gíga tí Jòhánù sọ nípa rẹ̀ pé: “Àti pé lórí ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀, àní lórí itan rẹ̀, ó ní orúkọ kan tí a kọ, Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa.” (Ìṣípayá 19:16) Ó ti fẹ̀rí hàn pé òun lágbára tó pọ̀ ju ti alákòóso ayé èyíkéyìí, ju ọba tàbí olúwa èyíkéyìí tó jẹ́ èèyàn. Iyì àti ògo rẹ̀ ta yọ. Ó ti gẹṣin “nítorí òtítọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ àti òdodo” ó sì ṣẹ́gun ó tún ṣẹ́ ọ̀tẹ̀, láé kò ní sí pé ogun kan tún wà tó máa ṣẹ́ mọ́! (Sáàmù 45:4) Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ẹni tí Jésù ń tì lẹ́yìn ló fún Jésù ní orúkọ tó wà lára ẹ̀wù Jésù tí ẹ̀jẹ̀ wọ́n sí!
Oúnjẹ Alẹ́ Ńlá ti Ọlọ́run
20. Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe “oúnjẹ alẹ́ ńlá ti Ọlọ́run,” àsọtẹ́lẹ̀ ìṣáájú wo tó jọ èyí ló sì mú wá sọ́kàn ẹni?
20 Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, lẹ́yìn ìparun àwọn ogunlọ́gọ̀ Gọ́ọ̀gù, àwọn ẹyẹ àtàwọn ẹranko ìgbẹ́ la pè wá síbi àsè kan! Wọ́n palẹ̀ àwọn òkú mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ nípa jíjẹ òkú àwọn ọ̀tá Jèhófà. (Ìsíkíẹ́lì 39:11, 17-20) Ọ̀rọ̀ tí Jòhánù sọ tẹ̀ lé e mú àsọtẹ́lẹ̀ ìṣáájú yẹn wá sọ́kàn wa lọ́nà tó ṣe kedere, ó ní: “Mo tún rí áńgẹ́lì kan tí ó dúró nínú oòrùn, ó sì ké jáde pẹ̀lú ohùn rara, ó sì wí fún gbogbo ẹyẹ tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run pé: ‘Ẹ wá níhìn-ín, ẹ kóra jọpọ̀ síbi oúnjẹ alẹ́ ńlá ti Ọlọ́run, kí ẹ lè jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara àwọn ọba àti àwọn ibi kìkìdá ẹran ara àwọn ọ̀gágun àti àwọn ibi kìkìdá ẹran ara àwọn ọkùnrin alágbára àti àwọn ibi kìkìdá ẹran ara àwọn ẹṣin àti ti àwọn tí ó jókòó sórí wọn, àti àwọn ibi kìkìdá ẹran ara gbogbo ènìyàn, ti òmìnira àti ti ẹrú àti ti àwọn ẹni kékeré àti ńlá.’”—Ìṣípayá 19:17, 18.
21. Kí ni (a) dídúró tí áńgẹ́lì “dúró nínú oòrùn” fi hàn? (b) wíwà táwọn òkú wà lórí ilẹ̀ fi hàn? (d) irú àwọn tá a óò fi òkú wọn sílẹ̀ lórí ilẹ̀ jẹ́ ká mọ̀? (e) gbólóhùn náà, “oúnjẹ alẹ́ ńlá ti Ọlọ́run” fi hàn?
21 Áńgẹ́lì náà “dúró nínú oòrùn,” ìyẹn ibi ipò àṣẹ tó ti máa pe àfiyèsí àwọn ẹyẹ. Ó pè wọn láti wà ní sẹpẹ́ láti jẹ àjẹyó ẹran ara àwọn tí Ọba Ajagun náà máa tó pa àtàwọn tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ọ̀run máa tó pa. Ti pé àwọn òkú á wà lórí ilẹ̀ fi hàn pé wọn yóò kú ikú ìtìjú níta gbangba. Bíi ti Jésíbẹ́lì ìgbà àtijọ́, á kò ní sìnkú wọn lọ́nà ọlá. (2 Àwọn Ọba 9:36, 37) Ohun tí Ìṣípayá sọ nípa àwọn tí a óò fi òkú wọn sílẹ̀ lórí ilẹ̀ láìsin jẹ́ ká mọ onírúurú àwọn tí ìparun náà máa kàn, ìyẹn àwọn bí: àwọn ọba, àwọn olórí ogun, àwọn ọkùnrin alágbára, àwọn tó wà lómìnira àtàwọn ẹrú. Kò sẹ́ni tí kò ní í kàn. Gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọlọ̀tẹ̀ tó ń ta ko Jèhófà ni yóò pa run. Lẹ́yìn èyí, kò ní sí àwọn èèyàn onídàrúdàpọ̀ tó dà bí òkun mọ́. (Ìṣípayá 21:1) Èyí ni “oúnjẹ alẹ́ ńlá ti Ọlọ́run,” nítorí pé Jèhófà ló pe àwọn ẹyẹ náà pé kí wọ́n wá jẹun.
22. Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàkópọ̀ bí ogun àjàkẹ́yìn náà yóò ṣe rí?
22 Jòhánù ṣe àkópọ̀ bí ogun àjàkẹ́yìn náà yóò ṣe rí, ó ní: “Mo sì rí ẹranko ẹhànnà náà àti àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn tí wọ́n kóra jọpọ̀ láti bá ẹni tí ó jókòó sórí ẹṣin àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ja ogun. A sì mú ẹranko ẹhànnà náà, àti pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wòlíì èké tí ó ṣe àwọn iṣẹ́ àmì níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ṣi àwọn tí ó gba àmì ẹranko ẹhànnà náà lọ́nà àti àwọn tí ó ṣe ìjọsìn fún ère rẹ̀. Nígbà tí wọ́n ṣì wà láàyè, àwọn méjèèjì ni a fi sọ̀kò sínú adágún iná tí ń fi imí ọjọ́ jó. Ṣùgbọ́n àwọn ìyókù ni a fi idà gígùn ẹni tí ó jókòó sórí ẹṣin pa tán, idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde. Gbogbo àwọn ẹyẹ sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara wọn ní àjẹyó.”—Ìṣípayá 19:19-21.
23. (a) Ọ̀nà wo ló fi jẹ́ pé “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” yóò jà ní Amágẹ́dọ́nì? (b) Ìkìlọ̀ wo ni “àwọn ọba ilẹ̀ ayé” kò fetí sí, kí ló sì máa yọrí sí fún wọn?
23 Lẹ́yìn tí áńgẹ́lì tú ìbínú Jèhófà tó wà nínú àwokòtò kẹfà jáde, Jòhánù ròyìn pé wọ́n fi ìpolongo ẹ̀mí èṣù kó “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé” jọ pọ̀ sí “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” Ogun yìí yóò jà ní Amágẹ́dọ́nì. Amágẹ́dọ́nì kì í ṣe ibi gidi kan, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ipò kan tó kárí ayé tó máa mú kí Jèhófà mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ. (Ìṣípayá 16:12, 14, 16) Wàyí o, Jòhánù rí ìlà ogun náà. Wọ́n tò gẹ̀ẹ̀rẹ̀ láti gbéjà ko Ọlọ́run, gbogbo “àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn” wà níbẹ̀. Wọ́n fi orí kunkun kọ̀ láti tẹrí ba fún Ọba tí Jèhófà yàn. Jèhófà fi inú rere fún wọn ní ìkìlọ̀ nínú ìkéde tó mí sí pé: “Fi ẹnu ko ọmọ náà lẹ́nu, kí ìbínú [Jèhófà] má bàa ru, kí ẹ má sì ṣègbé ní ọ̀nà náà.” Nítorí pé wọn kò tẹrí ba fún ìṣàkóso Kristi, wọ́n gbọ́dọ̀ kú.—Sáàmù 2:12.
24. (a) Ìdájọ́ wo la mú wá sórí ẹranko ẹhànnà náà àti wòlíì èké náà, kí ló sì túmọ̀ sí pé wọ́n “ṣì wà láàyè”? (b) Kí nìdí tí “adágún iná” náà fi ní láti jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ?
24 Ẹranko ẹhànnà tó tinú òkun wá tó ní orí méje, ìwo mẹ́wàá, tó ṣàpẹẹrẹ ètò ìṣèlú Sátánì, ti dìgbàgbé, bẹ́ẹ̀ sì ni wòlíì èké náà, ìyẹn agbára ayé keje, tún bá a lọ pẹ̀lú. (Ìṣípayá 13:1, 11-13; 16:13) Nígbà tí wọ́n ṣì wà “láàyè,” tàbí tí wọ́n ṣì jọ ń ta ko àwọn èèyàn Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé, a jù wọ́n sínú “adágún iná.” Ṣé adágún iná gidi lèyí? Rárá, nítorí ẹranko ẹhànnà náà àti wòlíì èké náà kì í ṣe ẹranko gidi. Kàkà bẹ́ẹ̀, adágún iná náà ṣàpẹẹrẹ ìparun pátápátá, ìparun ìkẹyìn, ibi àrèmabọ̀. Nígbà tó bá yá, ibẹ̀ yẹn lá máa fi ikú àti Hédíìsì, àti Èṣù fúnra rẹ̀, sọ̀kò sí. (Ìṣípayá 20:10, 14) Dájúdájú, kì í ṣe ibi tí wọ́n ti ń dá àwọn ẹni búburú lóró títí ayérayé, kì í ṣe ibi tó gbóná bí ajere, nítorí èrò pé irú ibi bẹ́ẹ̀ wà jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà.—Jeremáyà 19:5; 32:35; 1 Jòhánù 4:8, 16.
25. (a) Àwọn wo ni a “fi idà gígùn ẹni tí ó jókòó sórí ẹṣin pa”? (b) Ṣé ká máa retí pé èyíkéyìí nínú àwọn tá a “pa” yóò ní àjíǹde?
25 Gbogbo àwọn yòókù tí wọn kì í ṣe apá kan ìjọba ayé ní tààràtà ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ apá kan ayé oníwà ìbàjẹ́ yìí tí wọn kò sì ṣeé yí padà “ni a fi idà gígùn ẹni tí ó jókòó sórí ẹṣin náà pa.” Jésù yóò kéde pé ikú tọ́ sí wọn. Níwọ̀n bí Ìṣípayá kò ti mẹ́nu kan adágún iná nínú ìparun tiwọn, ṣé ká máa retí pé wọn yóò ní àjíǹde ni? Kò sí ibì kankan tá a ti sọ fún wa pé àwọn tí Onídàájọ́ Jèhófà bá pa ní àkókò yẹn yóò ní àjíǹde. Gẹ́gẹ́ bí Jésù fúnra rẹ̀ ti sọ, gbogbo àwọn tí kì í ṣe “àwọn àgùntàn” yóò kọjá lọ sínú “iná àìnípẹ̀kun tí a ti pèsè sílẹ̀ fún Èṣù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀,” èyíinì ni, “sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun.” (Mátíù 25:33, 41, 46) Èyí ló máa mú “ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run” wá sí ìparí.—2 Pétérù 3:7; Náhúmù 1:2, 7-9; Málákì 4:1.
26. Ní ṣókí, sọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde Amágẹ́dọ́nì.
26 Lọ́nà yìí, gbogbo àwọn tó jẹ́ ara ètò Sátánì lórí ilẹ̀ ayé kò ní sí mọ́. “Ọ̀run ti ìṣáájú” tó jẹ́ ìṣàkóso ìṣèlú ti kọjá lọ. “Ilẹ̀ ayé,” ìyẹn ètò tó dà bí ẹni pé yóò wà títí lọ, tí Sátánì ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, á pa run pátápátá. “Òkun” náà, ìyẹn àwùjọ ìran èèyàn burúkú tó ń ta ko Jèhófà, kò ní sí mọ́. (Ìṣípayá 21:1; 2 Pétérù 3:10) Àmọ́ ṣá o, kí ni Jèhófà fi pamọ́ de Sátánì fúnra rẹ̀? Jòhánù máa sọ fún wa.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]