Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọjọ́ Ìdájọ́ Ọlọ́run—Àbájáde Rẹ̀ Aláyọ̀!

Ọjọ́ Ìdájọ́ Ọlọ́run—Àbájáde Rẹ̀ Aláyọ̀!

Orí 41

Ọjọ́ Ìdájọ́ Ọlọ́run—Àbájáde Rẹ̀ Aláyọ̀!

Ìran 15—Ìṣípayá 20:11-21:8

Ohun tó dá lé: Àjíǹde gbogbo gbòò, Ọjọ́ Ìdájọ́, àti àwọn ìbùkún ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun

Ìgbà tó nímùúṣẹ: Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi

1. (a) Kí ni aráyé pàdánù nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣẹ̀? (b) Àwọn ohun wo ni Ọlọ́run ní lọ́kàn tí kò tíì yí padà, báwo la sì ṣe mọ̀?

 ỌLỌ́RUN dá àwa èèyàn láti wà láàyè títí láé. Ká sọ pé Ádámù àti Éfà ti ṣègbọràn sáwọn àṣẹ Ọlọ́run ni, wọn ì bá máà kú. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:8, 16, 17; Oníwàásù 3:10, 11) Àmọ́, nígbà tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sọ ìjẹ́pípé àti ìyè nù fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ wọn, ikú sì wá jọba lórí aráyé bí ọ̀tá tí kò lójú àánú. (Róòmù 5:12, 14; 1 Kọ́ríńtì 15:26) Síbẹ̀, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn pé àwọn èèyàn pípé yóò wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé kò yí padà. Nítorí ìfẹ́ ńláǹlà tí Ọlọ́run ní fún aráyé, ó rán Jésù, Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sí ayé, ẹni tó fi ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èèyàn pípé ṣe ìràpadà fún “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn” tó jẹ́ ọmọ Ádámù. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16) Jésù lè wá lo ìtóye ẹbọ rẹ̀ yìí láti mú àwọn èèyàn tó jẹ́ onígbàgbọ́ wà láàyè kí wọ́n sì di pípé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (1 Pétérù 3:18; 1 Jòhánù 2:2) Ẹ o rí i pé ìdí pàtàkì gan-an lèyí jẹ́ fọ́mọ aráyé láti ‘kún fún ìdùnnú kí wọ́n sì máa yọ̀’!—Aísáyà 25:8, 9.

2. Kí ni Jòhánù sọ nínú Ìṣípayá 20:11, kí sì ni “ìtẹ́ ńlá funfun” náà?

2 Lẹ́yìn tí Sátánì bá ti dèrò ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso ológo ti Jésù á bẹ̀rẹ̀. Ìyẹn ni “ọjọ́” tí Ọlọ́run “pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí à ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó ti yàn sípò.” (Ìṣe 17:31; 2 Pétérù 3:8) Jòhánù sọ pé: “Mo sì rí ìtẹ́ ńlá funfun kan àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀. Ilẹ̀ ayé àti ọ̀run sá lọ kúrò níwájú rẹ̀, a kò sì rí àyè kankan fún wọn.” (Ìṣípayá 20:11) Kí ni “ìtẹ́ ńlá funfun” yìí? Kò lè jẹ́ ohunkóhun mìíràn bí kò ṣe ìjókòó ìdájọ́ “Ọlọ́run Onídàájọ́ gbogbo ènìyàn.” (Hébérù 12:23) Yóò wá ṣèdájọ́ aráyé báyìí láti mọ àwọn tí yóò jàǹfààní látinú ẹbọ ìràpadà Jésù.—Máàkù 10:45.

3. (a) Kí ni jíjẹ́ tí ìtẹ́ Ọlọ́run jẹ́ “ńlá” àti “funfun” fi hàn? (b) Àwọn wo ni yóò ṣèdájọ́ ní Ọjọ́ Ìdájọ́, kí ni wọ́n sì máa gbé ìdájọ́ wọn kà?

3 Ìtẹ́ Ọlọ́run jẹ́ “ńlá,” ìyẹn sì tẹnu mọ́ ìtóbilọ́lá Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọba Aláṣẹ, ó sì tún jẹ́ “funfun,” èyí tó pe àfiyèsí sí òdodo rẹ̀ tí kò ní àléébù. Òun ni Onídàájọ́ aráyé tó ga jù lọ. (Sáàmù 19:7-11; Aísáyà 33:22; 51:5, 8) Àmọ́ ṣá o, ó ti wá gbé iṣẹ́ ṣíṣe ìdájọ́ lé Jésù Kristi lọ́wọ́, Bíbélì sọ pé: “Baba kì í ṣèdájọ́ ẹnikẹ́ni rárá, ṣùgbọ́n ó ti fi gbogbo ìdájọ́ ṣíṣe lé Ọmọ lọ́wọ́.” (Jòhánù 5:22) Ọ̀dọ̀ Jésù làwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ wà, àwọn ni “a sì fún . . . ní agbára ṣíṣèdájọ́ . . . fún ẹgbẹ̀rún ọdún.” (Ìṣípayá 20:4) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn òfin àti ìlànà tí Jèhófà gbé kalẹ̀ ló máa pinnu ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan ní Ọjọ́ Ìdájọ́.

4. Kí ló túmọ̀ sí pé “ilẹ̀ ayé àti ọ̀run sá lọ”?

4 Báwo ni “ilẹ̀ ayé àti ọ̀run ṣe sá lọ”? Èyí jẹ́ ọ̀run kan náà tó lọ kúrò gẹ́gẹ́ bí àkájọ ìwé nígbà tí Jésù ṣí èdìdì kẹfà, ìyẹn àwọn ẹ̀dá èèyàn tó ń ṣàkóso tá a “tò jọ pa mọ́ fún iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” (Ìṣípayá 6:14; 2 Pétérù 3:7) Ilẹ̀ ayé ni ètò àwọn nǹkan, èyí tó wà lábẹ́ àwọn ẹ̀dá èèyàn tó ń ṣàkóso. (Ìṣípayá 8:7) Ìparun ẹranko ẹhànnà náà àtàwọn ọba ilẹ̀ ayé àti ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun wọn, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó gba àmì ẹranko ẹhànnà náà àtàwọn tó jọ́sìn ère rẹ̀, ni sísá tí ọ̀run àti ilẹ̀ ayé sá lọ yìí. (Ìṣípayá 19:19-21) Lẹ́yìn tí Onídàájọ́ Ńlá mú ìdájọ́ ṣẹ sórí ilẹ̀ ayé àti ọ̀run tó jẹ ti Sátánì, ó ṣètò Ọjọ́ Ìdájọ́ mìíràn.

Ọjọ́ Ìdájọ́ Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún

5. Lẹ́yìn tí ilẹ̀ ayé ògbólógbòó àti ọ̀run ògbólógbòó bá ti sá lọ, àwọn wo ló kù tá a ó ṣèdájọ́ wọn?

5 Àwọn wo ló kù tá a óò dá lẹ́jọ́ lẹ́yìn tí ilẹ̀ ayé ògbólógbòó àti ọ̀run ògbólógbòó bá ti sá lọ? Kì í ṣe ìyókù àwọn ẹni àmì òróró tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], nítorí pé a ti ṣèdájọ́ wọn, a sì ti fi èdìdì dì wọ́n. Bí àwọn ẹni àmì òróró kan bá ṣì kù lórí ilẹ̀ ayé lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, wọ́n gbọ́dọ̀ kú kété lẹ́yìn náà kí wọ́n sì gba èrè wọn ti ọ̀run nípasẹ̀ àjíǹde. (1 Pétérù 4:17; Ìṣípayá 7:2-4) Àmọ́, ọ̀kẹ́ àìmọye ogunlọ́gọ̀ ńlá tí wọ́n ti jáde láti inú ìpọ́njú ńlá wá dúró síbi tí kò fara sin rárá “níwájú ìtẹ́” náà. Ní báyìí ná, àwọn wọ̀nyí la ti kà sí olódodo fún lílàájá nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù tó ta sílẹ̀, ṣùgbọ́n ṣíṣe ìdájọ́ wọn yóò máa bá a nìṣó ní gbogbo ẹgbẹ̀rún ọdún yẹn bí Jésù ti ń bá a lọ ní ṣíṣamọ̀nà wọn lọ sí “àwọn ìsun omi ìyè.” Nígbà tí wọ́n bá ti di ẹni pípé tá a sì dán wọn wò lẹ́yìn náà, a óò wá polongo wọn ní olódodo ní gbogbo ọ̀nà. (Ìṣípayá 7:9, 10, 14, 17) Àárín ẹgbẹ̀rún ọdún yẹn náà la ó ṣèdájọ́ àwọn ọmọ tó la ìpọ́njú ńlá já àtàwọn ọmọ èyíkéyìí táwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá bá bí nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi.—Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 9:7; 1 Kọ́ríńtì 7:14.

6. (a) Ọ̀pọ̀ èèyàn wo ni Jòhánù rí, kí sì ni ọ̀rọ̀ náà “ẹni ńlá àti ẹni kékeré” túmọ̀ sí? (b) Báwo la óò ṣe jí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó wà nínú ìrántí Ọlọ́run dìde?

6 Àmọ́ o, Jòhánù wá rí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n pọ̀ gan-an ju ogunlọ́gọ̀ ńlá tó là á já. Iye wọn á máa lọ sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀kẹ́ àìmọye! “Mo sì rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré, tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀.” (Ìṣípayá 20:12a) “Ẹni ńlá àti ẹni kékeré” làwọn èèyàn tó lókìkí àtàwọn èèyàn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lókìkí, tí wọ́n ti wà láàyè rí tí wọ́n sì ti kú lórí ilẹ̀ ayé yìí láàárín ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ọdún tó ti kọjá sẹ́yìn. Nínú Ìhìn Rere tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ ní kò pẹ́ lẹ́yìn tó kọ ìwé Ìṣípayá, Jésù sọ nípa Baba rẹ̀ pé: “Ó sì ti fún un [ìyẹn Jésù] ní ọlá àṣẹ láti ṣe ìdájọ́, nítorí pé Ọmọ ènìyàn ni òun jẹ́. Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:27-29) Iṣẹ́ ńlá mà lèyí o! Yóò mú àwọn tí ikú ti ń pa látijọ́ yìí padà wá sí ìyè, yóò sọ ibojì wọn dòfo! Kò sí àní-àní pé ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé la óò jí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tí Ọlọ́run rántí dìde kó bàa lè ṣeé ṣe fún ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí kò pọ̀ tó àwọn tó jíǹde náà, láti mójú tó àwọn ìṣòro tó bá yọjú. Ìdí ni pé àwọn tá a jí dìde lè kọ́kọ́ fẹ́ máa gbé ìgbésí ayé wọn bí wọ́n ṣe ń gbé e tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wọn àti ẹ̀mí ayé.

Àwọn Wo La Jíǹde Tá A sì Dá Lẹ́jọ́?

7, 8. (a) Àkájọ ìwé wo la ṣí sílẹ̀, kí ló sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? (b) Àwọn wo ni kò ní jíǹde?

7 Jòhánù fi kún un pé: “Ṣùgbọ́n a ṣí àkájọ ìwé mìíràn sílẹ̀; àkájọ ìwé ìyè ni. A sì ṣèdájọ́ àwọn òkú láti inú nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn. Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́, a sì ṣèdájọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn.” (Ìṣípayá 20:12b, 13) Dájúdájú, ìran àrímáleèlọ ni! Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun tí Jòhánù mẹ́nu kàn yìí, ìyẹn ‘òkun, ikú, àti Hédíìsì,’ ló ní ipa tó kó, àmọ́ kíyè sí i pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò dá dúró lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ láìtan-mọ́ra wọn. a Nígbà tí Jónà wà nínú ikùn ẹja tó sì tipa bẹ́ẹ̀ wà ní àárín agbami òkun, ó sọ pé òun wà nínú Ṣìọ́ọ̀lù, tàbí Hédíìsì. (Jónà 2:2) Bó bá jẹ́ pé ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù ló gbẹ̀mí ẹnì kan, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú Hédíìsì lonítọ̀hún wà. Àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí mú un dá wa lójú dáadáa pé kò sẹ́nì kankan tójú máa fò.

8 Àmọ́ ṣáá o, àìmọye èèyàn la ò ní jí dìde. Lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí tí wọn ò ronú pìwà dà tí wọ́n kọ Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀, bákan náà “ọkùnrin oníwà àìlófin” tí ìsìn wà lára wọn, àtàwọn Kristẹni ẹni àmì òróró “tí wọ́n ti yẹsẹ̀.” (2 Tẹsalóníkà 2:3; Hébérù 6:4-6; Mátíù 23:29-33) Jésù tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tó ń hùwà bí ewúrẹ́ nígbà òpin ayé. Àwọn wọ̀nyí yóò lọ sínú “iná àìnípẹ̀kun tí a ti pèsè sílẹ̀ fún Èṣù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀,” ìyẹn ni, “ìkékúrò àìnípẹ̀kun.” (Mátíù 25:41, 46) Kò sí àjíǹde kankan fún àwọn wọ̀nyí!

9. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé àwọn kan wà tí Ọlọ́run máa ṣe ojú rere sí lákànṣe nígbà àjíǹde, àwọn wo ló sì wà lára àwọn wọ̀nyí?

9 Àmọ́ o, àwọn kan wà tí Ọlọ́run máa ṣe ojú rere sí lákànṣe nígbà àjíǹde. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi èyí hàn nígbà tó sọ pé: “Mo sì ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọ́run . . . pé àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Nínú àjíǹde ti orí ilẹ̀ ayé, àwọn tó máa wà lára “àwọn olódodo” yẹn làwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tó jẹ́ olóòótọ́ láyé ìgbàanì, ìyẹn àwọn bí Ábúráhámù, Ráhábù, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn tá a polongo ní olódodo nítorí pé wọ́n bá Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́. (Jákọ́bù 2:21, 23, 25) Àwọn àgùntàn mìíràn tó jẹ olódodo wà lára àwọn tá à ń sọ yìí, ìyẹn àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà títí di ọjọ́ ikú wọn lákòókò tá a wà yìí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé gbogbo irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, tí wọ́n ṣe ìfẹ́ Jèhófà láìyẹsẹ̀ la óò jí dìde ní ìbẹ̀rẹ̀ Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Jésù. (Jóòbù 14:13-15; 27:5; Dáníẹ́lì 12:13; Hébérù 11:35, 39, 40) Ó dájú pé ọ̀pọ̀ lára àwọn olódodo tá a jí dìde yìí la óò fún láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti bójú tó iṣẹ́ bàǹtàbanta ti sísọ àwọn nǹkan dọ̀tun nínú Párádísè.—Sáàmù 45:16; fi wé Aísáyà 32:1, 16-18; 61:5; 65:21-23.

10. Àwọn wo ni “àwọn aláìṣòdodo” lára àwọn tá a máa jí dìde?

10 Àmọ́, àwọn wo ni “àwọn aláìṣòdodo” tá a mẹ́nu kàn nínú Ìṣe 24:15? Àwọn tó máa wà lára àwọn wọ̀nyí ní ẹgbàágbèje èèyàn tó ti kú látìgbà táláyé ti dáyé, àgàgà àwọn tó gbé ayé ní “àwọn àkókò àìmọ̀.” (Ìṣe 17:30) Àwọn wọ̀nyí kò láǹfààní kankan láti kọ́ béèyàn ṣe ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, nítorí ibi tá a bí wọn sí àti àkókò tí wọ́n gbé ayé. Yàtọ̀ sáwọn yẹn, àwọn kan lè wà tí wọ́n ti gbọ́ ìhìn rere ìgbàlà, àmọ́ tí wọn ò tíì pinnu láti sin Jèhófà lákòókò yẹn tàbí tí wọ́n kú kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ débi tí wọ́n á ti ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n á sì ṣèrìbọmi. Nígbà àjíǹde, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní láti tún inú wọn rò dáadáa, kí wọ́n sì yí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn padà bí wọn bá fẹ́ jàǹfààní tó ṣí sílẹ̀ fún wọn láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun yìí.

Àkájọ Ìwé Ìyè

11. (a) Kí ni “àkájọ ìwé ìyè,” orúkọ àwọn wo ló sì wà sínú àkájọ ìwé yìí? (b) Kí nìdí tá a fi máa ṣí àkájọ ìwé ìyè náà sílẹ̀ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi?

11 Jòhánù sọ̀rọ̀ nípa “àkájọ ìwé ìyè.” Èyí ni ibi tá a kọ orúkọ àwọn tí Jèhófà máa fún láǹfààní láti ní ìyè àìnípẹ̀kun sí. A ti kọ orúkọ àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù, orúkọ àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá, àti táwọn olóòótọ́ ìgbàanì, bíi Mósè, sínú àkájọ ìwé yìí. (Ẹ́kísódù 32:32, 33; Dáníẹ́lì 12:1; Ìṣípayá 3:5) Títí di àkókò náà, kò sí èyíkéyìí lára àwọn “aláìṣòdodo” tá a jí dìde tí orúkọ rẹ̀ tíì wà nínú àkájọ ìwé ìyè. Nítorí náà, àkájọ ìwé ìyè yìí yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi láti lè máa kọ orúkọ àwọn mìíràn tí wọ́n bá kúnjú ìwọ̀n lákòókò yẹn sínú rẹ̀. Àwọn tá ò bá kọ orúkọ wọn sínú àkájọ ìwé náà, ìyẹn ìwé ìyè, la óò “fi sọ̀kò sínú adágún iná.”—Ìṣípayá 20:15; fi wé Hébérù 3:19.

12. Kí ló máa mú ká kọ orúkọ ẹnì kan sínú àkájọ ìwé ìyè tó wà ní ṣíṣí sílẹ̀, báwo sì ni Onídàájọ́ tí Jèhófà yàn ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀?

12 Kí ló wá máa mú kí orúkọ ẹnì kan wọnú àkájọ ìwé ìyè tó máa wà ní ṣíṣí sílẹ̀ lákòókò yẹn? Ohun pàtàkì tó máa mú kí èyí ṣeé ṣe ni ohun kan náà tá a ni kí Ádámù àti Éfà ṣe: ìyẹn ni ìgbọràn sí Jèhófà. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé sáwọn olùfẹ́ ọ̀wọ́n tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:4-7, 17) Tá a bá ń sọ nípa ìgbọràn, Onídàájọ́ tí Jèhófà yàn sípò ti fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Bí [Jésù] tilẹ̀ jẹ́ Ọmọ, ó kọ́ ìgbọràn láti inú àwọn ohun tí ó jìyà rẹ̀; àti lẹ́yìn tí a ti sọ ọ́ di pípé, ó di ẹni tí ó ní ẹrù iṣẹ́ fún mímú ìgbàlà àìnípẹ̀kun wá fún gbogbo àwọn tí ń ṣègbọràn sí i.”—Hébérù 5:8, 9.

Ṣíṣí Àwọn Àkájọ Ìwé Mìíràn

13. Ọ̀nà wo làwọn tá a jí dìde gbọ́dọ̀ gbà fi hàn pé àwọn jẹ́ onígbọràn, àwọn ìlànà wo sì ni wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé?

13 Àwọn tó jíǹde wọ̀nyí gbọ́dọ̀ fi hàn pé àwọn jẹ́ onígbọràn. Báwo ni wọ́n ṣe máa fi hàn? Jésù fúnra rẹ̀ tọ́ka sí àwọn àṣẹ méjì tó tóbi jù, pé: “Èkíní ni, ‘Gbọ́, Ìwọ Ísírẹ́lì, Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ Jèhófà kan ṣoṣo, kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.’ Èkejì nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’” (Máàkù 12:29-31) Jèhófà tún ní àwọn ìlànà tí kì í yí padà tí wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé, irú bíi, má jalè, má parọ́, má pànìyàn àti má ṣèṣekúṣe.—1 Tímótì 1:8-11; Ìṣípayá 21:8.

14. Àwọn àkájọ ìwé mìíràn wo la ṣí sílẹ̀, kí ló sì wà nínú wọn?

14 Jòhánù tún mẹ́nu kan àwọn àkájọ ìwé mìíràn tá a óò ṣí nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi náà. (Ìṣípayá 20:12) Àwọn àkájọ ìwé wo nìyẹn? Láwọn ìgbà kan tó ti kọjá, Jèhófà fáwọn èèyàn ní àwọn ìtọ́ni pàtó kan tí wọ́n á máa tẹ̀ lé ní àwọn ipò kan pàtó. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé Mósè, ó fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní onírúurú òfin. Pípa àwọn òfin náà mọ́ ni yóò jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìyè. (Diutarónómì 4:40; 32:45-47) Ní ọ̀rúndún kìíní, ó fún àwọn olóòótọ́ láwọn ìtọ́ni tuntun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà lábẹ́ ètò àwọn nǹkan ti Kristẹni. (Mátíù 28:19, 20; Jòhánù 13:34; 15:9, 10) Jòhánù sì sọ pé àwọn òkú ni a óò ‘ṣèdájọ́ wọn láti inú nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn.’ Nítorí náà, ó hàn gbangba pé ṣíṣí àwọn àkájọ ìwé wọ̀nyí yóò jẹ́ kí aráyé mọ ohun tó wà nínú wọn, ìyẹn kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun tí Jèhófà fẹ́ kí ọmọ aráyé ṣe lákòókò ẹgbẹ̀rún ọdún náà. Táwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn bá fi àwọn ìlànà àti àṣẹ inú àwọn àkájọ ìwé wọ̀nyẹn sílò nínú ìgbésí ayé wọn, yóò ṣeé ṣe fún wọn láti wà láàyè fún àkókò gígùn, wọ́n á sì ní ìyè àìnípẹ̀kun nígbẹ̀yìngbẹ́yín.

15. Irú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wo làwọn èèyàn máa ṣe nígbà àjíǹde, ọ̀nà wo ló sì ṣeé ṣe kí àjíǹde náà gbà wáyé?

15 Ẹ̀kọ́ tá a máa kọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run lákòókò yẹn á mà gadabú o! Lọ́dún 2005, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé darí ìpíndọ́gba mílíọ̀nù mẹ́fà, ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gọ́ta, ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [6,061,534] ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní onírúurú ibi. Ṣùgbọ́n nígbà àjíǹde, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn la óò kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tó dá lórí Bíbélì àtàwọn àkájọ ìwé tuntun wọ̀nyẹn! Gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run ló máa di olùkọ́ lákòókò náà tí wọ́n á sì fi gbogbo okun wọn ṣe iṣẹ́ náà. Láìsí àní-àní, bí àwọn tá a jí dìde bá ṣe ń lóye ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ làwọn náà á máa kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó máa kárí ayé yìí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí àjíǹde náà ṣe máa wáyé ni pé, àwọn tó wà láàyè á láǹfààní láti kí àwọn ará ilé wọn àtàwọn ojúlùmọ̀ wọn tẹ́lẹ̀ káàbọ̀, wọ́n á sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn wọ̀nyí náà yóò wá máa kí àwọn ẹlòmíràn káàbọ̀, wọ́n á sì máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Fi wé 1 Kọ́ríńtì 15:19-28, 58.) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà, tí wọ́n ń ṣe gudugudu méje yààyàà mẹ́fà nínú títan òtítọ́ kálẹ̀ lónìí ń fi ìpìlẹ̀ tó dáa lélẹ̀ de àwọn àǹfààní tí wọ́n ń retí láti ní nígbà àjíǹde.—Aísáyà 50:4; 54:13.

16. (a) Àwọn wo la ò ní kọ orúkọ wọn sínú àkájọ ìwé náà, tàbí ìwé ìyè? (b) Àwọn wo ni àjíǹde wọn yóò já sí “ìyè”?

16 Ohun tí Jésù sọ nípa àjíǹde ti orí ilẹ̀ ayé ni pé ‘àwọn tí wọ́n ṣe ohun rere yóò jáde wá sí àjíǹde ìyè, àwọn tí wọ́n sọ ohun bíburú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.’ Níhìn-ín, “ìyè” àti “ìdájọ́” yàtọ̀ sí ara wọn, tó fi hàn pé àwọn tá a jí dìde tí wọ́n tún “sọ ohun bíburú dàṣà” lẹ́yìn tá a ti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ látinú Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí àtàwọn àkájọ ìwé la óò dá lẹ́jọ́ pé wọn kò yẹ fún ìyè. A ò ní kọ orúkọ wọn sínú àkájọ ìwé náà, tàbí ìwé ìyè. (Jòhánù 5:29) Bákan náà ló ṣe máa rí fún ẹnikẹ́ni tó ń tọ ipa ọ̀nà tòótọ́ tẹ́lẹ̀ àmọ́, tó wá tìtorí àwọn ìdí kan yí padà nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi náà. Pípa la ó pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò nínú ìwé ìyè. (Ẹ́kísódù 32:32, 33) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, orúkọ àwọn tó fi ìgbọràn tẹ̀ lé àwọn ohun tá a kọ sínú àkájọ ìwé náà yóò máa wà nínú ìwé àkọsílẹ̀ náà tàbí àkájọ ìwé ìyè títí lọ, wọ́n á sì máa wà láàyè títí lọ fáàbàdà. Àjíǹde “ìyè” ni àjíǹde irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yóò já sí.

Òpin Ikú àti Hédíìsì

17. (a) Nǹkan àgbàyanu wo ni Jòhánù ṣàpèjúwe? (b) Ìgbà wo la óò sọ Hédíìsì dòfo? (d) Ìgbà wo la óò sì fi ikú tó wá látọ̀dọ̀ Ádámù “sọ̀kò sínú adágún iná”?

17 Ẹ̀yìn ìyẹn ni Jòhánù tún wá ṣàpèjúwe ohun kan tó jẹ́ àgbàyanu! Ó ní: “A sì fi ikú àti Hédíìsì sọ̀kò sínú adágún iná. Èyí túmọ̀ sí ikú kejì, adágún iná náà. Síwájú sí i, ẹnì yòówù tí a kò rí pé a kọ sínú ìwé ìyè ni a fi sọ̀kò sínú adágún iná náà.” (Ìṣípayá 20:14, 15) Nígbà tó bá fi máa di òpin Ọjọ́ Ìdájọ́ ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún náà, “ikú àti Hédíìsì” la óò ti mú kúrò pátápátá. Kí nìdí tí èyí fi jẹ́ fún ẹgbẹ̀rún ọdún? Ṣé ẹ rí i, Hédíìsì, tí í ṣe ipò òkú, la óò sọ dòfo nígbà tá a bá jí ẹni tó kẹ́yìn nínú àwọn tó wà nínú ìrántí Ọlọ́run dìde. Àmọ́ bí àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá yẹn bá ṣì kù sára ẹnikẹ́ni, a jẹ́ pé ikú tó wá látọ̀dọ̀ Ádámù kò tíì kásẹ̀ nílẹ̀ tán nìyẹn. Gbogbo àwọn tá a jí dìde sórí ilẹ̀ ayé, àti ogunlọ́gọ̀ ńlá tó la Amágẹ́dọ́nì já, ló máa di dandan fún láti ṣègbọràn sí ohun tá a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé títí dìgbà tí ìtóye ẹbọ ìràpadà Jésù yóò fi mú àìsàn, ọjọ́ ogbó, àtàwọn àbùkù ara mìíràn tá a jogún bá kúrò pátápátá. Ìgbà yẹn ni ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù, pa pọ̀ pẹ̀lú Hédíìsì, yóò di èyí tá a “fi sọ̀kò sínú adágún iná.” Wọn ò ní sí mọ́ láé!

18. (a) Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe àṣeyọrí ìṣàkóso Jésù Ọba? (b) Kí ni Jésù yóò ṣe fún àwọn èèyàn tá a ti sọ di pípé? (d) Àwọn nǹkan mìíràn wo ló máa ṣẹlẹ̀ ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún náà?

18 Nípa bẹ́ẹ̀, ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì yóò nímùúṣẹ pátápátá. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nítorí [Jésù] gbọ́dọ̀ ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí Ọlọ́run yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú [tá a jogún lọ́dọ̀ Ádámù] ni a óò sọ di asán.” Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e? Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé, “nígbà tí a bá ti fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ tán, nígbà náà ni Ọmọ fúnra rẹ̀ pẹ̀lú yóò fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ẹni tí ó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀.” Ní èdè mìíràn, Jésù yóò “fi ìjọba lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:24-28) Bẹ́ẹ̀ ni o, lẹ́yìn tí Jésù bá ti tipasẹ̀ ìtóye ẹbọ ìràpadà rẹ̀ ṣẹ́gun ikú tó wá látọ̀dọ̀ Ádámù, yóò wá fa ìdílé èèyàn tá a ti sọ di pípé lé Jèhófà, Baba rẹ̀, lọ́wọ́. Ó hàn gbangba pé àkókò yẹn gan-an, ìyẹn òpin ẹgbẹ̀rún ọdún ni a óò tú Sátánì sílẹ̀ tí ìdánwò ìkẹyìn yóò sì wáyé láti mọ àwọn tí a ó fi orúkọ wọn sílẹ̀ títí láé nínú àkọsílẹ̀ àkájọ ìwé ìyè. “Ẹ tiraka tokuntokun” kí orúkọ yín lè wà lára wọn!—Lúùkù 13:24; Ìṣípayá 20:5.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn oníwà ìbàjẹ́ tó ṣègbé nínú Àkúnya omi ọjọ́ Nóà kò ní sí lára àwọn tá a jí dìde látinú òkun yẹn, ìparun yẹn ni òpin wọn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa rí fáwọn tí Jèhófà bá pa run nínú ìpọ́njú ńlá.—Mátíù 25:41, 46; 2 Pétérù 3:5-7.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 298]

Orúkọ “àwọn aláìṣòdodo” tá a jí dìde tí wọ́n sì ṣègbọràn sí àkájọ ìwé tá a ṣí nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso náà la lè kọ sínú àkájọ ìwé ìyè pẹ̀lú