Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Bí Ìjọba Ọlọ́run!

A Bí Ìjọba Ọlọ́run!

Orí 27

A Bí Ìjọba Ọlọ́run!

Ìran 7—Ìṣípayá 12:1-17

Ohun tó dá lé: Obìnrin ti ọ̀run náà bímọ, Máíkẹ́lì bá Sátánì jagun ó sì jù ú sí ilẹ̀ ayé

Ìgbà tó nímùúṣẹ: Látìgbà tí Kristi Jésù gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914 títí dìgbà ìpọ́njú ńlá

1. Báwo ni lílóye àwọn àmì tí Ìṣípayá orí 12 sí 14 ṣàpèjúwe ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

 ÀṢÍRÍ ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run ni a ti ṣí payá. (Ìṣípayá 10:7) Ìjọba Jèhófà tí Mèsáyà rẹ̀ ń jọba lé lórí ti bẹ̀rẹ̀. Ó ti ń ṣàkóso! Bó sì ṣe bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso yìí fi hàn pé ègbé ń bọ̀ sórí Sátánì àti irú-ọmọ rẹ̀, àti pé Irú-Ọmọ apá tòkè ọ̀run lára ètò Ọlọ́run yóò ja àjàṣẹ́gun. Ṣùgbọ́n, áńgẹ́lì keje náà kò tíì parí fífun kàkàkí rẹ̀, torí pé ó ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti ṣí payá fún wa nípa ègbé kẹta. (Ìṣípayá 11:14) Àwọn àmì tí Ìṣípayá orí 12 sí 14 ṣàpèjúwe yóò jẹ́ ká túbọ̀ mọ gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ègbé yìí àti bí àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run yóò ṣe wá sí ìparí.

2. (a) Àmì ńlá wo ni Jòhánù rí? (b) Ìgbà wo la sọ ìtumọ̀ àmì ńlá náà?

2 Wàyí o, Jòhánù rí àmì ńlá kan, èyí táwọn èèyàn Ọlọ́run fẹ́ láti mọ̀ nípa rẹ̀. Àmì yìí ló bẹ̀rẹ̀ ìran alásọtẹ́lẹ̀ kan tí ń múni lórí yá, èyí tá a kọ́kọ́ tẹ ìtumọ̀ rẹ̀ jáde nínú Ilé Ìṣọ́ March 1, 1925 lédè Gẹ̀ẹ́sì nínú àpilẹ̀kọ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ìbí Orílẹ̀-Èdè Náà.” Lẹ́yìn náà lọ́dún 1926, a tún tẹ ìtumọ̀ rẹ̀ jáde nínú ìwé náà, Idande. Òye Bíbélì tó túbọ̀ ṣe kedere yìí jẹ́ ohun mánigbàgbé nínú bí iṣẹ́ Jèhófà ṣe ń tẹ̀ síwájú. Nítorí náà jẹ́ kí Jòhánù ṣàpèjúwe àmì náà bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí payá. Ó ní: “Àmì ńlá kan sì di rírí ní ọ̀run, obìnrin kan tí a fi oòrùn ṣe ní ọ̀ṣọ́, òṣùpá sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, adé oníràwọ̀ méjìlá sì ń bẹ ní orí rẹ̀, ó sì lóyún. Ó sì ké jáde nínú ìrọbí rẹ̀ àti nínú ìroragógó rẹ̀ láti bímọ.”—Ìṣípayá 12:1, 2.

3. Ta ni obìnrin tí Jòhánù rí ní ọ̀run?

3 Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Jòhánù rí obìnrin kan ní ọ̀run. Àmọ́ o, obìnrin náà kì í ṣe èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ àmì, tàbí àpẹẹrẹ. (Ìṣípayá 1:1) Kí wá ni obìnrin náà ṣàpẹẹrẹ? Nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì, ìgbà míì wà táwọn obìnrin máa ń dúró fún ètò táwọn ẹni jàǹkànjàǹkàn máa ń “gbé níyàwó.” Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ̀rọ̀ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí aya Jèhófà Ọlọ́run. (Jeremáyà 3:14) Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì sì sọ pé ìjọ àwọn ẹni àmì òróró Kristẹni jẹ́ ìyàwó Kristi. (Ìṣípayá 21:9-14) Obìnrin tí Jòhánù rí níhìn-ín pẹ̀lú lẹnì kan gbé níyàwó, ó sì máa tó bímọ. Ta ni ọkọ rẹ̀? Ohun kan ni pé lẹ́yìn tó bímọ náà tán, ọmọ náà ni a “gbà . . . lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run àti síbi ìtẹ́ rẹ̀.” (Ìṣípayá 12:5) Nípa báyìí, Jèhófà gba ọmọ náà gẹ́gẹ́ bíi tirẹ̀. Nítorí náà, obìnrin tí Jòhánù rí ní láti jẹ́ aya ìṣàpẹẹrẹ ti Jèhófà.

4. Àwọn wo ni ọmọ aya ìṣàpẹẹrẹ ti Ọlọ́run, kí sì ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe obìnrin tí Jòhánù rí?

4 Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́jọ ṣáájú, Jèhófà sọ fún aya ìṣàpẹẹrẹ yìí pé: “Gbogbo ọmọ rẹ yóò sì jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Aísáyà 54:5, 13) Jésù fa ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí yọ, ó sì fi hàn pé olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn òun làwọn ọmọ wọ̀nyí tí wọ́n wá para pọ̀ di ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lẹ́yìn náà. (Jòhánù 6:44, 45) Nítorí náà, àwọn tó wà nínú ìjọ yìí, tí Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, tún jẹ́ àwọn ọmọ aya ìṣàpẹẹrẹ ti Ọlọ́run. (Róòmù 8:14) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àlàyé kan gbè é lẹ́sẹ̀ báyìí pé: “Jerúsálẹ́mù ti òkè jẹ́ òmìnira, òun sì ni ìyá wa.” (Gálátíà 4:26) Nítorí náà, “Jerúsálẹ́mù ti òkè” ni “obìnrin” tí Jòhánù rí.

5. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìràwọ̀ méjìlá ni wọ́n fi dé aya ìṣàpẹẹrẹ Jèhófà ládé, kí wá ni Jerúsálẹ́mù ti òkè jẹ́ gan-an?

5 Ṣùgbọ́n, kí ni Jerúsálẹ́mù ti òkè gan-an? Níwọ̀n bí Pọ́ọ̀lù ti pè é ní ti “òkè,” tí Jòhánù sì rí i ní ọ̀run, èyí fi hàn kedere pé kì í ṣe ìlú ńlá kan tó wà lórí ilẹ̀ ayé níbí; kì í sì í ṣe ohun kan náà pẹ̀lú “Jerúsálẹ́mù Tuntun,” nítorí pé ìyàwó Kristi ni Jerúsálẹ́mù Tuntun yìí, kì í ṣe aya Jèhófà. (Ìṣípayá 21:2) Kíyè sí i pé ìràwọ̀ méjìlá ni wọ́n fi dé obìnrin náà ládé. Méjìlá sì jẹ́ iye kan tó jẹ mọ́ ìpépérépéré tó bá dọ̀rọ̀ ètò. a Nítorí náà, ó jọ pé ńṣe ni ìràwọ̀ méjìlá wọ̀nyí ń fi hàn pé obìnrin náà jẹ́ ètò kan ní ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí Jerúsálẹ́mù ìgbàanì ti jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé. Jerúsálẹ́mù ti òkè ni ètò Jèhófà lókè ọ̀run, ìyẹn àpapọ̀ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó dà bí aya fún Jèhófà nípa sísìn ín àti nípa bíbí ọmọ.

6. (a) Kí ni fífi tí wọ́n fi oòrùn wọ obìnrin tí Jòhánù rí láṣọ, tí òṣùpá wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, tó sì ní adé oníràwọ̀ fi hàn? (b) Kí ni ìrora ìrọbí obìnrin tó lóyún náà ṣàpẹẹrẹ?

6 Jòhánù rí obìnrin yìí gẹ́gẹ́ bí ẹni tá a fi oòrùn wọ̀ láṣọ, tí òṣùpá sì ń bẹ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Tá a bá wá fi adé oníràwọ̀ rẹ̀ kún un, a jẹ́ pé àwọn ìmọ́lẹ̀ ọ̀run ló yí i ká látòkè délẹ̀. Ńṣe ni ojú rere Ọlọ́run ń tàn sára rẹ̀ bí oòrùn lọ́sàn-án àti lóru. Ẹ ò rí i pé ohun tí wọ́n fi ṣàpẹẹrẹ ètò Jèhófà ti ọ̀run tó ga lọ́lá yìí bá a mu gan-an! Yàtọ̀ síyẹn, obìnrin náà lóyún, ó ń fara da ìrora ìrọbí. Bó ṣe ń kígbe pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ fi hàn pé ó ti tó àkókò fún un láti bímọ. Nínú Bíbélì, ìrora ìrọbí máa ń ṣàpẹẹrẹ iṣẹ́ àṣekára téèyàn ní láti ṣe kó tó lè ṣe ohun kan láṣeyanjú. (Fi wé Sáàmù 90:2; Òwe 25:23; Aísáyà 66:7, 8.) Láìsí àní-àní, ètò Jèhófà ti ọ̀run ní irú ìrora ìrọbí yìí nígbà tó fẹ́ bímọ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí.

Dírágónì Ńlá Aláwọ̀ Iná

7. Kí ni àmì mìíràn tí Jòhánù rí ní ọ̀run?

7 Kí ni Jòhánù rí lẹ́yìn ìyẹn? “Àmì mìíràn sì di rírí ní ọ̀run, sì wò ó! dírágónì ńlá aláwọ̀ iná, tí ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá àti adé dáyádémà méje ní àwọn orí rẹ̀; ìrù rẹ̀ sì wọ́ ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì fi wọ́n sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé. Dírágónì náà sì dúró pa síwájú obìnrin tí ó máa tó bímọ, pé, nígbà tí ó bá bímọ, kí ó lè pa ọmọ rẹ̀ jẹ.”—Ìṣípayá 12:3, 4.

8. (a) Ta ni dírágónì ńlá aláwọ̀ iná náà? (b) Kí ni níní tí dírágónì náà ní orí méje, ìwo mẹ́wàá, àti adé dáyádémà kan ní orí kọ̀ọ̀kan fi hàn?

8 Sátánì ni dírágónì yìí, “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà.” (Ìṣípayá 12:9; Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ó jẹ́ òǹrorò apanirun, dírágónì olórí méje, tàbí apanijẹ, tó lè gbé ohun tọ́wọ́ rẹ̀ bá tẹ̀ mì pátápátá. Abàmì gbáà ni! Orí méje àti ìwo mẹ́wàá tó ní fi hàn pé òun ni babaàsàlẹ̀ fún ẹranko ẹhànnà tó dúró fún ìjọba ayé, èyí tí Ìṣípayá orí 13 yóò ṣàpèjúwe láìpẹ́. Orí méje àti ìwo mẹ́wàá ni ẹranko ẹhànnà náà ní. Níwọ̀n bí Sátánì ti ní adé dáyádémà ní orí kọ̀ọ̀kan, tó jẹ́ méje lápapọ̀, ó dá wa lójú pé abẹ́ ìṣàkóso Sátánì làwọn ìjọba ayé tí ẹranko ẹhànnà yẹn dúró fún wà. (Jòhánù 16:11) Ó bá a mu gan-an láti fi ìwo mẹ́wàá náà ṣàpẹẹrẹ gbogbo agbára tí Sátánì ń lò nínú ayé yìí.

9. Kí ni wíwọ́ tí ìrù dírágónì náà “wọ́ ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run” jù sí ilẹ̀ ayé fi hàn?

9 Dírágónì náà lágbára lórí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí pẹ̀lú. Ó fi ìrù rẹ̀ “wọ́ ìdá mẹ́ta àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run.” Àwọn ìràwọ̀ lè dúró fún àwọn áńgẹ́lì. (Jóòbù 38:7) Bí ibí yìí ṣe mẹ́nu kan “ìdá mẹ́ta” fi hàn kedere pé púpọ̀ lára àwọn áńgẹ́lì ni Sátánì ti ṣì lọ́nà. Bí wọ́n bá sì ti bọ́ sábẹ́ Sátánì, ọwọ́ ṣìnkún tẹ̀ wọ́n nìyẹn. Kò lè ṣeé ṣe fún wọn láti padà sínú ètò Ọlọ́run tó jẹ́ mímọ́. A jẹ́ pé wọ́n di ẹ̀mí èṣù, tí Sátánì, ọba àti olùṣàkóso wọn, wọ́ lọ. (Mátíù 12:24) Sátánì tún fi wọ́n sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé. Ó dájú pé ìgbà ayé Nóà ṣáájú Ìkún Omi lèyí ń tọ́ka sí, nígbà tí Sátánì mú káwọn aláìgbọràn ọmọ Ọlọ́run wá sórí ilẹ̀ ayé láti wá máa gbé pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin èèyàn. Ọlọ́run fìyà jẹ àwọn ‘áńgẹ́lì tí wọ́n ṣẹ̀’ wọ̀nyí nípa sísọ wọn sínú ipò tó dà bí ẹ̀wọ̀n, tó ń jẹ́ Tátárọ́sì.—Jẹ́nẹ́sísì 6:4; 2 Pétérù 2:4; Júúdà 6.

10. Àwọn ètò tó ta kora wo ló yọjú, kí sì nìdí tí dírágónì náà fi ń wọ́nà láti pa ọmọ tí obìnrin náà fẹ́ bí?

10 Nípa báyìí, ètò méjì tí ń ta ko ara wọ́n ti fara hàn kedere, ìyẹn ètò Jèhófà ti ọ̀run èyí tí obìnrin náà dúró fún àti ètò elèṣù ti Sátánì tó ń pe ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run níjà. Àríyànjiyàn ńlá nípa ẹni tó yẹ kó jẹ́ ọba aláṣẹ gbọ́dọ̀ yanjú. Lọ́nà wo? Sátánì, tó ṣì ń wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù lọ tuuru pẹ̀lú ara rẹ̀, dà bí òǹrorò ẹranko apẹranjẹ tó ń fi kọ̀rọ̀ ojú wo ẹran tó máa pa jẹ. Sátánì ń dúró kí obìnrin náà bímọ. Ó fẹ́ pa ọmọ jòjòló tá à ń retí yìí nítorí ó mọ̀ pé tọ́mọ náà bá yè òun ò ní lè máa wà láàyè nìṣó, òpin á sì dé bá ayé tóun ń jọba lé lórí.—Jòhánù 14:30.

Ọmọkùnrin Kan, Akọ

11. Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe bí obìnrin náà ṣe bi ọmọ rẹ̀, kí sì nìdí tó fi pe ọmọ náà ní “ọmọkùnrin kan, akọ”?

11 Àkókò tá a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè láti ṣàkóso láìní ọwọ́ Ọlọ́run nínú dópin lọ́dún 1914. (Lúùkù 21:24) Ìgbà yẹn gan-an ni àkókò tó gẹ́lẹ́, tí obìnrin náà sì bí ọmọ rẹ̀. Ìwé Ìṣípayá wá ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Ó sì bí ọmọkùnrin kan, akọ, ẹni tí yóò fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn orílẹ̀-èdè. A sì gba ọmọ rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run àti síbi ìtẹ́ rẹ̀. Obìnrin náà sì sá lọ sí aginjù, níbi tí Ọlọ́run pèsè àyè sílẹ̀ sí fún un, pé kí wọ́n máa bọ́ ọ níbẹ̀ fún ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà ọjọ́.” (Ìṣípayá 12:5, 6) Ọmọ náà jẹ́ “ọmọkùnrin kan, akọ.” Kí nìdí tí Jòhánù fi lo èdè àpèjúwe méjì yìí? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ láti jẹ́ ká mọ̀ pé ọmọ náà kúnjú ìwọ̀n ó sì lágbára tó tó agbára láti máa fi ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè. Ó tún jẹ́ ká mọ bí ìbí ọmọ náà ṣe ṣe pàtàkì àti bó ṣe jẹ́ àkókò aláyọ̀ tó! Ó kó ipa pàtàkì nínú mímú àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run wá sí ìparí. Àní ọmọ tó jẹ́ akọ yìí yóò “fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn orílẹ̀-èdè”!

12. (a) Níbi tí Jèhófà ti sàsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù nínú ìwé Sáàmù, ìlérí wo ló ṣe nípa Jésù? (b) Kí ni bíbí tí obìnrin náà bí ọmọkùnrin kan “tí yóò fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn orílẹ̀-èdè” dúró fún?

12 Ǹjẹ́ o ti gbọ́ gbólóhùn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí rí? Bẹ́ẹ̀ ni, nínú àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù, Jèhófà ṣèlérí pé: “Ìwọ yóò fi ọ̀pá aládé irin ṣẹ́ wọn, bí ohun èlò amọ̀kòkò ni ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú.” (Sáàmù 2:9) Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé: “Ọ̀pá okun rẹ ni Jèhófà yóò rán jáde láti Síónì, pé: ‘Máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá rẹ.’” (Sáàmù 110:2) Nítorí náà, ìbímọ tí Jòhánù rí yìí kan Jésù Kristi gbọ̀ngbọ̀n. Àmọ́ o, kì í ṣe bíbí tí wúńdíá kan bí Jésù ṣáájú ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni ni èyí o; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọ̀rọ̀ jíjí tí Ọlọ́run jí Jésù dìde sí ìwàláàyè tẹ̀mí lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni. Bákan náà sì ni kì í ṣe ọ̀ràn àtúnwáyé nínú ara mìíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ìbí Ìjọba Ọlọ́run tó wáyé lọ́dún 1914, nígbà tí Ọlọ́run gbé Jésù tó ti tó ẹgbàá [2,000] ọdún báyìí tó ti wà lọ́run gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba.—Ìṣípayá 12:10.

13. Kí ni gbígbà tí a “gba” ọmọ náà tó jẹ́ akọ “lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run àti síbi ìtẹ́ rẹ̀” fi hàn?

13 Láéláé, Jèhófà ò ní fàyè gba Sátánì láti pa aya Rẹ̀ tàbí ọmọkùnrin tí aya Rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bí! Lẹ́yìn tí aya Ọlọ́run bí ọmọkùnrin yìí, a ‘gbà á lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run àti síbi ìtẹ́ rẹ̀.’ Nípa bẹ́ẹ̀, ó bọ́ sábẹ́ ààbò Jèhófà, ẹni tí yóò tọ́jú Ìjọba tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí yìí dáadáa. Ìjọba náà ni Jèhófà máa lò láti sọ orúkọ mímọ́ Rẹ̀ di mímọ́. Obìnrin tó bímọ náà sá lọ síbi tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ fún un nínú aginjù. A ṣì máa rí kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí ìyẹn! Sátánì ńkọ́? Ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì kan máa wáyé tí kò ní í mú kó ṣeé ṣe fún un láé láti gbógun ti Ìjọba náà ní ọ̀run. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo nìyẹn?

Ogun Jà Lọ́run!

14. (a) Gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ṣe sọ, ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni ò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún Sátánì mọ́ láti gbógun ti Ìjọba náà? (b) Sàkáání ibo ni wọ́n há Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ mọ́?

14 Jòhánù sọ fún wa pé: “Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jagun ṣùgbọ́n kò borí, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni a fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” (Ìṣípayá 12:7-9) Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pípabanbarì tó mú àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run wá sí ìparí ṣẹlẹ̀. Máíkẹ́lì àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ lé Sátánì kúrò lọ́run, wọ́n sì fi òun àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Sátánì tó ti ṣi gbogbo ayé lọ́nà tó sì tún di ọlọ́run rẹ̀ wá dẹni tí wọ́n ká lọ́wọ́ kò, tí wọn ò jẹ́ kó lè kúrò ní sàkáání ilẹ̀ ayé, ilẹ̀ ayé ọ̀hún ló sì kúkú ti bẹ̀rẹ̀ ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 4:3, 4.

15, 16. (a) Ta ni Máíkẹ́lì, báwo la sì ṣe mọ̀? (b) Kí nìdí tó fi bá a mu rẹ́gí pé Máíkẹ́lì lẹni tó fi Sátánì sọ̀kò sísàlẹ̀ látọ̀run?

15 Ta ló ja àjàṣẹ́gun ńlá yìí ní orúkọ Jèhófà? Bíbélì sọ pé Máíkẹ́lì àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n ta ni Máíkẹ́lì? Orúkọ náà “Máíkẹ́lì” túmọ̀ sí “Ta Ni Ó Dà Bí Ọlọ́run?” Nítorí náà, Máíkẹ́lì ní láti nífẹ̀ẹ́ sí fífihàn pé Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run nípa fífi ẹ̀rí hàn pé kò sẹ́nì kankan tá a lè fi wé E. Nínú Júúdà ẹsẹ 9, a pè é ní “Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì.” Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, Bíbélì lo orúkọ oyè náà “olú-áńgẹ́lì” níbòmíràn tó sì jẹ́ pé Jésù Kristi nìkan ṣoṣo ló tọ́ka sí. b Pọ́ọ̀lù sọ nípa rẹ̀ pé: “Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú ìpè àṣẹ, pẹ̀lú ohùn olú-áńgẹ́lì àti pẹ̀lú kàkàkí Ọlọ́run.” (1 Tẹsalóníkà 4:16) Orúkọ oyè náà “olú-áńgẹ́lì” túmọ̀ sí “olórí àwọn áńgẹ́lì.” Nítorí náà kò yani lẹ́nu pé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ nípa “Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.” Láwọn ibòmíràn tí Bíbélì ti fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì wà ní ìtẹríba fún ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tó jẹ́ olódodo, Jésù ló tọ́ka sí. Ìyẹn ni Pọ́ọ̀lù fi sọ̀rọ̀ nípa “ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára.”—2 Tẹsalóníkà 1:7; tún wo Mátíù 24:30, 31; 25:31.

16 Ìwọ̀nyí àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn jẹ́ ká mọ̀ láìsí iyèméjì kankan pé Máíkẹ́lì kì í ṣe ẹlòmíràn bí kò ṣe Jésù Kristi Olúwa nínú ipò rẹ̀ ní ọ̀run. Nísinsìnyí tá a ti wà ní ọjọ́ Olúwa, kò wulẹ̀ sọ fún Sátánì mọ́ pé: “Kí Jèhófà bá ọ wí lọ́nà mímúná.” Níwọ̀n bí èyí ti jẹ́ àkókò ìdájọ́, Jésù tí í ṣe Máíkẹ́lì, fi Sátánì ẹni ibi náà àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ látọ̀run. (Júúdà 9; Ìṣípayá 1:10) Òun gan-an ló yẹ kó ṣe èyí, nítorí pé Òun ni Ọba tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé gorí ìtẹ́. Jésù tún ni Irú-Ọmọ náà tí Ọlọ́run ṣèlérí ní Édẹ́nì, tí yóò tẹ orí Ejò náà fọ́, tí yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ pa á run títí gbére. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Bí Jésù sì ṣe lé Sátánì kúrò lọ́run fi hàn pé ó ti sún mọ́ ìgbà tó máa tẹ orí ejò náà fọ́ pátápátá.

“Ẹ Máa Yọ̀ Ṣẹ̀ṣẹ̀, Ẹ̀yin Ọ̀run”

17, 18. (a) Kí ni Jòhánù sọ pé àwọn tó wà lọ́rùn ṣe nígbà tí Máíkẹ́lì lé Sátánì kúrò níbẹ̀? (b) Ibo ló ṣeé ṣe kí ohùn rara tí Jòhánù gbọ́ ti wá?

17 Jòhánù ròyìn bí inú àwọn tó wà lọ́run ṣe dùn tó pé Sátánì ṣubú yakata, ó ní: “Mo sì gbọ́ tí ohùn rara kan ní ọ̀run wí pé: ‘Nísinsìnyí ni ìgbàlà dé àti agbára àti ìjọba Ọlọ́run wa àti ọlá àṣẹ Kristi rẹ̀, nítorí pé olùfisùn àwọn arákùnrin wa ni a ti fi sọ̀kò sísàlẹ̀, ẹni tí ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tọ̀sán-tòru níwájú Ọlọ́run wa! Wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà àti nítorí ọ̀rọ̀ ìjẹ́rìí wọn, wọn kò sì nífẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lójú ikú pàápàá. Ní tìtorí èyí, ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn!’”—Ìṣípayá 12:10-12a.

18 Ohùn rara ta ni Jòhánù gbọ́? Bíbélì kò sọ. Ṣùgbọ́n igbe tó jọ ọ́ tí Ìṣípayá 11:17 sọ nípa rẹ̀ wá látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún tá a jí dìde tí wọ́n wà ní ipò wọn lọ́run, níbi tí wọ́n ti lè ṣojú fún àwọn ẹni mímọ́ tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000]. (Ìṣípayá 11:18) Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ń fojú winá inúnibíni, tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé ni ohùn náà pè ní “àwọn arákùnrin wa,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún yẹn kan náà ló sọ̀rọ̀ yìí. Kò sí iyè méjì kankan pé àwọn olùṣòtítọ́ wọ̀nyí lè pa ohùn wọn pọ̀, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kété lẹ́yìn tí Máíkẹ́lì àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá fi Sátánì àti ògìdìgbó àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ̀kò kúrò lọ́run ni wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ sí í jíǹde.

19. (a) Kí ni dídé tí àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run dé ìparí rẹ̀ mú kí Jésù ṣe? (b) Kí ni pípè tá a pe Sátánì ní “olùfisùn àwọn arákùnrin wa” fi hàn?

19 Dídé tí àṣírí ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run dé ìparí rẹ̀ mú kó di dandan pé kí Jésù di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Bó ṣe di Ọba yìí ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún Ọlọ́run láti ṣe ohun ńlá tó ní lọ́kàn láti ṣe, ìyẹn ni láti dá àwọn olóòótọ́ èèyàn nídè. Kì í ṣe kìkì àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé nísinsìnyí nìkan ni Jésù máa gbà là, á tún gba ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn òkú tí wọ́n wà nínú ìrántí Ọlọ́run là. (Lúùkù 21:27, 28) Pípè tá a pe Sátánì ní “olùfisùn àwọn arákùnrin wa” fi hàn pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀sùn tó fi kan Jóòbù jẹ́ èké, kò yéé pe ìwà títọ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé níjà. Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti tún ẹ̀sùn rẹ̀ sọ pé èèyàn á fi gbogbo ohun tó ní ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọkàn rẹ̀. Asán ni gbogbo ìsapá Sátánì!—Jóòbù 1:9-11; 2:4, 5.

20. Báwo làwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ ṣe ṣẹ́gun Sátánì?

20 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tá a kà sí olódodo “nítorí ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” ń bá a lọ láti máa jẹ́rìí Ọlọ́run àti Jésù Kristi láìka inúnibíni sí. Ó ti lé ní ọgọ́fà ọdún tí ẹgbẹ́ Jòhánù, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró, ti ń sọ nípa àwọn àríyànjiyàn ńlá tó jẹ mọ́ mímú Àwọn Àkókò Kèfèrí wá sópin lọ́dún 1914. (Lúùkù 21:24) Ogunlọ́gọ̀ ńlá sì ń fi ìdúróṣinṣin sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú wọn nísinsìnyí. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìgbésí ayé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fi hàn léraléra lákòókò tiwa yìí, kò sí ìkankan nínú wọn tó “bẹ̀rù àwọn tí ń pa ara ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ọkàn.” Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu wọn àti ìwà wọn tó bá ìlànà Kristẹni mu, wọ́n ti ṣẹ́gun Sátánì, wọ́n sì ń fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. (Mátíù 10:28; Òwe 27:11; Ìṣípayá 7:9) Nígbà táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bá sì jíǹde sí ọ̀run, ó dájú pé ayọ̀ wọn á pọ̀ gan-an nítorí pé Sátánì ò sí lọ́run mọ́ láti fẹ̀sùn kan àwọn arákùnrin wọn! Ní tòótọ́, ó jẹ́ àkókò fún ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì láti fi tayọ̀tayọ̀ tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ náà, pé: “Ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn!”

Ègbé Tí Sátánì Fà Jẹ́ Àfarawé Lásánlàsàn!

21. Báwo ni Sátánì ṣe mú ègbé bá ilẹ̀ ayé àti òkun?

21 Inú tó bí Sátánì nítorí ègbé kẹta mú kó pète láti fi ègbé tirẹ̀ alára pọ́n aráyé lójú. Ìṣípayá sọ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:12b) Lílé tí wọ́n lé Sátánì kúrò lọ́run mú ègbé bá ilẹ̀ ayé, ìyẹn ayé táwọn èèyàn onímọtara-ẹni-nìkan tí wọ́n wà lábẹ́ àkóso Sátánì ń pa run. (Diutarónómì 32:5) Ìyẹn nìkan kọ́ o, ìlànà ‘ìṣàkóso tìpá-tìkúùkù’ tí Sátánì ń lò ń mú ègbé bá ilẹ̀ ayé ìṣàpẹẹrẹ, ìyẹn ètò àwọn ẹ̀dá èèyàn, ó tún ń mú ègbé ba òkun ìṣàpẹẹrẹ, ìyẹn ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ ọmọ aráyé onírúkèrúdò. Nígbà ogun àgbáyé méjèèjì, ìbínú àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ Sátánì fi hàn pé inú ń bí Sátánì, irú ìbínú ran-n-to bẹ́ẹ̀ sì ń bá a lọ títí di òní olónìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní í pẹ́ dópin! (Máàkù 13:7, 8) Ṣùgbọ́n, bó ti wù kí ọ̀nà tí Èṣù gbà ń bínú burú tó, ègbé tó máa fà kò ní í tó ègbé kẹta tí Ìjọba Ọlọ́run yóò fi ṣe apá tó ṣeé fójú rí nínú ètò Sátánì bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú!

22, 23. (a) Kí ni Jòhánù sọ pé ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti fi dírágónì náà sọ̀kò sí ilẹ̀ ayé? (b) Báwo ni dírágónì náà ṣe ṣenúnibíni sí “obìnrin tí ó bí ọmọ náà tí ó jẹ́ akọ”?

22 Látìgbà tí wọ́n ti lé Sátánì síta làwọn arákùnrin Kristi tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé ti ń fojú winá ìbínú rẹ̀. Jòhánù sọ pé: “Wàyí o, nígbà tí dírágónì náà rí i pé a ti fi òun sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, ó ṣe inúnibíni sí obìnrin tí ó bí ọmọ náà tí ó jẹ́ akọ. Ṣùgbọ́n a fún obìnrin náà ní ìyẹ́ apá méjì ti idì ńlá, kí ó lè fò lọ sínú aginjù sí àyè rẹ̀; níbẹ̀ ni a ti bọ́ ọ fún àkókò kan àti àwọn àkókò àti ààbọ̀ àkókò kúrò ní ojú ejò náà.”—Ìṣípayá 12:13, 14.

23 Ìṣípayá 12:13, 14 tá a kà tán yìí tún ń bá ọ̀rọ̀ tá a kà ní ẹsẹ kẹfà nìṣó, èyí tó sọ fún wa pé lẹ́yìn tí obìnrin náà bí ọmọ rẹ̀, ó sá lọ sínú aginjù, kúrò lọ́dọ̀ dírágónì náà. A lè máa ṣe kàyéfì nípa bí dírágónì náà ṣe lè ṣenúnibíni sí obìnrin náà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀run ni obìnrin náà wà tí wọ́n sì ti lé dírágónì náà jù sí ilẹ̀ ayé báyìí. Ó dáa, ṣó o rántí pé obìnrin náà ní àwọn ọmọ lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn irú-ọmọ rẹ̀? Nígbà tó yá nínú ìran yìí, wọ́n sọ fún wa pé Sátánì fi ìrunú rẹ̀ hàn sí obìnrin náà nípa ṣíṣe inúnibíni sí irú-ọmọ rẹ̀. (Ìṣípayá 12:17) Ohunkóhun tó bá ń ṣẹlẹ̀ sí irú-ọmọ obìnrin náà lórí ilẹ̀ ayé, a lè sọ pé obìnrin náà fúnra rẹ̀ ló ń ṣẹlẹ̀ sí. (Fi wé Mátíù 25:40.) Àti pé àwọn alábàákẹ́gbẹ́ irú-ọmọ náà tí iye wọn ń pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé yóò fojú winá inúnibíni wọ̀nyí.

Orílẹ̀-Èdè Tuntun Kan

24. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó fara jọ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe rí ìdáǹdè kúrò ní Íjíbítì?

24 Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní ń lọ lọ́wọ́, àwọn arákùnrin Jésù ń fi ìṣòtítọ́ bá iṣẹ́ ìjẹ́rìí wọn nìṣó débí tí wọ́n lè ṣeé dé. Wọ́n ń ṣe èyí bí Sátánì àtàwọn òǹrorò ẹmẹ̀wà rẹ̀ tiẹ̀ ń ṣàtakò tó gbóná janjan sí wọn. Níkẹyìn, wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ dá iṣẹ́ ìwàásù táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń ṣe dúró. (Ìṣípayá 11:7-10) Nígbà yẹn, ojú wọn rí màbo bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n pọ́n lójú nílẹ̀ Íjíbítì. Nígbà tí wọ́n pọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú, Jèhófà mú wọn wá síbi ààbò ní aṣálẹ̀ Sínáì pẹ̀lú ìyára, bí ẹni pé lórí ìyẹ́ apá idì. (Ẹ́kísódù 19:1-4) Bákan náà, lẹ́yìn inúnibíni gbígbóná janjan tó wáyé lọ́dún 1918 sí ọdún 1919, Jèhófà dá àwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀, tí ń ṣojú fún obìnrin rẹ̀, nídè sínú ipò tẹ̀mí tó jẹ́ ibi ààbò fún wọn gẹ́gẹ́ bí aṣálẹ̀ náà ti jẹ́ ibi ààbò fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Èyí jẹ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dáhùn àdúrà wọn.—Fi wé Sáàmù 55:6-9.

25. (a) Kí ni Jèhófà sọ di orílẹ̀-èdè lọ́dún 1919, gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè nínú aginjù? (b) Àwọn wo ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè yìí, inú kí ni Ọlọ́run sì ti mú wọn wọ̀?

25 Jèhófà sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè nínú aginjù, ó sì tún pèsè fún wọn nípa tẹ̀mí àti nípa tara. Bákan náà, bẹ̀rẹ̀ látọdún 1919, Jèhófà sọ irú-ọmọ obìnrin náà di orílẹ̀-èdè tẹ̀mí. Èyí kì í ṣe Ìjọba Mèsáyà tó ti ń ṣàkóso láti ọ̀run látọdún 1914 o. Kàkà bẹ́ẹ̀, orílẹ̀-èdè tuntun yìí ni àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ẹlẹ́rìí lórí ilẹ̀ ayé, tí Ọlọ́run mú wọnú ipò ológo nípa tẹ̀mí lọ́dún 1919. Níwọ̀n bí wọ́n ti ń rí “ìwọ̀n ìpèsè oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” nísinsìnyí, èyí fún wọn lókun láti lè ṣe iṣẹ́ tó wà níwájú wọn.—Lúùkù 12:42; Aísáyà 66:8.

26. (a) Báwo ni sáà àkókò tí Ìṣípayá 12:6, 14 mẹ́nu kan ṣe gùn tó? (b) Kí ni àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀ náà wà fún, ìgbà wo ló bẹ̀rẹ̀, ìgbà wo ló sì parí?

26 Báwo ni àkókò tí irú-ọmọ obìnrin Ọlọ́run yìí fi wà láginjù ṣe gùn tó? Ìṣípayá 12:6 sọ pé ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà [1,260] ọjọ́ ni. Ìṣípayá 12:14 sọ pé ó jẹ́ àkókò kan, àwọn àkókò, àti ààbọ̀ àkókò, tó túmọ̀ sí àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀. Ní tòótọ́, gbólóhùn méjèèjì dúró fún ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀, èyí tó jẹ́ pé ní Àríwá Ìlàjì Ayé, ó bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ìrúwé ọdún 1919 títí dé ìgbà ìkórè ọdún 1922. Àkókò yẹn ni ẹgbẹ́ Jòhánù jèrè okun padà tí wọ́n sì ṣe àtúntò.

27. (a) Gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ṣe sọ, kí ni dírágónì náà ṣe lẹ́yìn ọdún 1922? (b) Kí nìdí tí Sátánì fi ń ṣe inúnibíni tó pọ̀ gan-an sáwọn Ẹlẹ́rìí?

27 Dírágónì náà ò yéé ṣenúnibíni! Jòhánù sọ pé: “Ejò náà sì pọ omi jáde bí odò láti ẹnu rẹ̀ tẹ̀ lé obìnrin náà, láti mú kí odò náà gbé e lọ.” (Ìṣípayá 12:15) Kí ni “omi . . . bí odò,” tàbí “àkúnya omi” (Bíbélì The New English Bible) yìí túmọ̀ sí? Dáfídì Ọba ìgbàanì sọ pé àwọn èèyàn burúkú tí wọ́n ń ṣàtakò sóun dà bí “ìkún omi ayaluni lójijì ti àwọn èèyàn tí kò dára fún ohunkóhun” [tàbí “ìṣàn omi ti àwọn aláìníláárí,” Bíbélì Young]. (Sáàmù 18:4, 5, 16, 17) Bó sì ṣe rí náà nìyẹn, àwọn aláìníláárí tàbí “àwọn èèyàn tí kò dára fún ohunkóhun” ni Sátánì ń lò láti fi ṣenúnibíni. Lẹ́yìn ọdún 1922, inúnibíni tí Sátánì ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí pọ̀ gan-an ni, ńṣe ló dà bí ìkún omi. (Mátíù 24:9-13) Lára inúnibíni ọ̀hún ni pé wọ́n lù wọ́n nílùkulù, wọ́n “fi àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n,” wọ́n fi wọn sẹ́wọ̀n, wọ́n yẹgi fún àwọn kan lára wọn, wọ́n yìnbọn pa àwọn míì, wọ́n sì bẹ́ àwọn míì lórí. (Sáàmù 94:20) Nítorí pé kò ṣeé ṣe fún Sátánì tí wọ́n ti rẹ̀ nípò wálẹ̀ láti dé ọ̀dọ̀ obìnrin Ọlọ́run ti ọ̀run ní tààràtà, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìbínú gbógun ti irú-ọmọ obìnrin náà tó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé ó sì fẹ́ pa wọ́n run, ní tààràtà tàbí nípa bíba ìwà títọ́ wọn jẹ́ kí wọ́n má bàa rí ojú rere Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ńṣe ni ìpinnu wọn dà bíi ti Jóòbù tó sọ pé: “Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!”—Jóòbù 27:5.

28. Báwo ni inúnibíni tó dà bí ikùn omi yìí ṣe wá le gan-an nígbà Ogun Àgbáyé Kejì?

28 Inúnibíni rírorò yìí dé góńgó nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Nílẹ̀ Yúróòpù, nǹkan bí ẹgbàafà [12,000] Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n há mọ́ ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti ọgbà ẹ̀wọ̀n Násì, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ló sì kú. Àwọn ọ̀gágun tó ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè Ítálì, Japan, Kòríà, àti Taiwan náà fojú àwọn Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ rí màbo. Kódà láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ oníjọba tiwa-n-tiwa pàápàá, àwọn Ajagun Kátólíìkì gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n fi ọ̀dà tí wọ́n fi ń ṣe títì kùn wọ́n, wọ́n wá lẹ ìyẹ́ mọ́ wọn lára, wọ́n sì lé wọn kúrò nílùú. Àwọn kan da àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí rú, àwọn aláṣẹ sì tún lé àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí kúrò nílé ìwé.

29. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ìtura tó dé láti orísun tí a kò retí? (b) Báwo ló ṣe jẹ́ pé “ilẹ̀ ayé wá ṣe ìrànlọ́wọ́ fún obìnrin náà”? (d) Kí ni dírágónì náà ò yéé ṣe?

29 Ìtura dé láti orísun kan tí a kò retí. Ìṣípayá sọ pé: “Ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé wá ṣe ìrànlọ́wọ́ fún obìnrin náà, ilẹ̀ ayé sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé odò náà mì, èyí tí dírágónì náà pọ̀ jáde láti ẹnu rẹ̀. Dírágónì náà sì kún fún ìrunú sí obìnrin náà, ó sì lọ láti bá àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ rẹ̀ ja ogun, àwọn ẹni tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 12:16, 17) “Ilẹ̀ ayé,” ìyẹn àwọn ètò ẹ̀dá èèyàn tí ń bẹ nínú ètò àwọn nǹkan Sátánì, bẹ̀rẹ̀ sí í gbé “odò,” tàbí “ìkún omi” náà mì. Láàárín ọdún 1940 sí 1949, àwọn Ẹlẹ́rìí rí ojú rere Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àti tàwọn alágbára tí ń ṣàkóso láwọn ilẹ̀ mìíràn, tí wọ́n mọrírì òmìnira ìsìn. Níkẹyìn, àwọn orílẹ̀-èdè Alájùmọ̀ṣepọ̀ gbé ìjọba Násì òun ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ tó jẹ́ òǹrorò mì pátápátá, èyí sì jẹ́ kára tu àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ti jìyà lábẹ́ àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ oníkà. Àmọ́ inúnibíni ò dáwọ́ dúró pátápátá o, nítorí pé ìbínú dírágónì náà ṣì ń bá a lọ títí dòní, kò sì yéé gbógun ti àwọn tí wọ́n “ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn Ẹlẹ́rìí adúróṣinṣin ṣì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, síbẹ̀ àwọn kan ṣì ń kú nítorí ìwà títọ́ wọn. Àmọ́ láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn aláṣẹ sábà máa ń dẹwọ́ inúnibíni tí wọ́n ń ṣe, èyí sì ń jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí ní òmìnira ìsìn. c Nípa báyìí, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe wí, ilẹ̀ ayé ń bá a lọ láti gbé omilẹgbẹ inúnibíni mì.

30. (a) Kí ni ilẹ̀ ayé ti pèsè ìtura tó pọ̀ tó fún láti ṣẹlẹ̀? (b) Kí ni ìwà títọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run ti yọrí sí?

30 Lọ́nà yìí, ilẹ̀ ayé ti pèsè ìtura tó pọ̀ tó láti jẹ́ kí iṣẹ́ Ọlọ́run gbòòrò dé òjìlénígba ó dín márùn-ún [235] ilẹ̀ àti láti mú ohun tó ju mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn olùṣòtítọ́ oníwàásù ìhìn rere jáde. Yàtọ̀ sáwọn tó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ obìnrin náà, ogunlọ́gọ̀ ńlá èèyàn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ jákèjádò ayé ń pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ ní ti pé wọ́n yà sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé, wọ́n ń hu ìwà rere, wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wọn, wọ́n sì ń jẹ́rìí nípa Ìjọba Mèsáyà. Ìwà títọ́ wọn ń fi hàn pé irọ́ funfun báláú ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi pẹ̀gàn Ọlọ́run, ó sì tún fi hàn pé ìparun ò ní pẹ́ dé bá Sátánì àti ètò àwọn nǹkan rẹ̀.—Òwe 27:11.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fi wé ẹ̀yà méjìlá ti Ísírẹ́lì nípa tara, àpọ́sítélì méjìlá, ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì tẹ̀mí, àti ibodè méjìlá, áńgẹ́lì méjìlá, àti ìpìlẹ̀ àwọn òkúta méjìlá ti Jerúsálẹ́mù Tuntun.—Ìṣípayá 21:12-14.

b Àmọ́ o, kíyè sí i pé Ìṣípayá 12:9 sọ̀rọ̀ nípa “dírágónì ńlá náà . . . [àti] àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.” Nítorí náà, kì í ṣe kìkì pé Èṣù sọ ara rẹ̀ di ayédèrú ọlọ́run nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún gbìyànjú láti di olú-áńgẹ́lì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò fìgbà kankan fún un lórúkọ oyè yẹn.

c Àwọn ilé ẹjọ́ gíga jù lọ ní àwọn ilẹ̀ bíi mélòó kan fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lómìnira. Díẹ̀ lára ìpinnu ilé ẹjọ́ wọ̀nyí wà lójú ìwé 92.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 185]

‘Ilẹ̀ La Ẹnu Rẹ̀’

Sátánì ń ṣe ọ̀pọ̀ inúnibíni sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Àmọ́ ṣá o, àwọn nǹkan tó ń wáyé nínú ètò Sátánì sábà máa ń mú kí inúnibíni náà dáwọ́ dúró.

Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyànkéèyàn gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí, tí àwọn aláṣẹ sì ju àwọn kan sẹ́wọ̀n. Àmọ́ àwọn ìpinnu tó bára dé tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe láwọn ọdún 1940 fòpin sí gbogbo èyí.

1945: Àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè mélòó kan tó pawọ́ pọ̀ jagun nígbà Ogun Àgbáyé Kejì ló dáwọ́ inúnibíni rírorò tí wọ́n ń ṣe sáwọn èèyàn Ọlọ́run dúró làwọn ilẹ̀ tí Jámánì àti Japan ń ṣàkóso.

Nígbà tí wọ́n fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Dominican Republic, wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n nà wọ́n lẹ́gba, wọ́n tún fìdí ìbọn lù wọ́n. Lọ́dún 1960, aáwọ̀ tó wáyé láàárín aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ náà Rafael Trujillo àti Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ló jẹ́ kí wọ́n mú òfin tí wọ́n fi de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò.

Nígbà ogun abẹ́lé ní Nàìjíríà, wọ́n ń yìnbọn pa àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n ń dáná sun wọn, wọ́n ń fipá bá obìnrin wọn lò pọ̀, wọ́n ń lù wọ́n nílùkulù, wọ́n sì ń dá wọn lóró. Àmọ́ gbogbo rẹ̀ wá sópin lọ́dún 1970 nígbà táwọn ọmọ ogun ìjọba ṣẹ́gun ìpínlẹ̀ tó yapa kúrò, ìyẹn níbi tí nǹkan wọ̀nyí ti ń ṣẹlẹ̀.

Lórílẹ̀-èdè Sípéènì, wọ́n fọ́ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n ní kí wọ́n sanwó ìtanràn, wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn pé ìwà ọ̀daràn ni wọ́n ń hù bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run tí wọ́n sì ń ṣe ìpàdé. Inúnibíni yìí dópin nígbẹ̀yìngbẹ́yín lọ́dún 1970, nígbà tí wọ́n yọ̀ǹda fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ òfin gẹ́gẹ́ bí àbájáde ìyípadà tó bá ìlànà ìjọba lórí ọ̀ràn àwọn ẹ̀sìn tí kì í ṣe Kátólíìkì.

Lórílẹ̀-èdè Potogí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ilé ni wọ́n tú wò láìgbàṣẹ. Wọ́n fi lílù ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí léṣe, wọ́n sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n tún gbẹ́sẹ̀ lé Bíbélì wọn. Ìwà ìkà tí wọ́n ń hù sáwọn Ẹlẹ́rìí yìí dópin lọ́dún 1974, nígbà tí àyípadà kan táwọn ológun ń rúná sí mú kí ìjọba mìíràn rọ́pò ti tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ṣe òfin tó jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí lómìnira láti máa pé jọ.

Nígbà tí orílẹ̀-èdè Ajẹntínà wà lábẹ́ ìjọba ológun, wọ́n lé àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò nílé ìwé, wọ́n tún fàṣẹ ọba mú àwọn Ẹlẹ́rìí káàkiri orílẹ̀-èdè náà nítorí pé wọ́n ń wàásù ìhìn rere. Inúnibíni yìí dópin nígbẹ̀yìngbẹ́yín lọ́dún 1984 nígbà tí ìjọba tí ń ṣàkóso nígbà yẹn fọwọ́ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin.

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 183]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

1914 Ìbí Ìjọba

1919 Ìbí orílẹ̀-èdè tuntun

1919-1922 Àkókò tí wọ́n fi ń kọ́fẹ

1922- Ọ̀pọ̀ inúnibíni

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 182]

Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé