Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Mú Àwọn Ẹlẹ́rìí Méjì Náà Sọ Jí

A Mú Àwọn Ẹlẹ́rìí Méjì Náà Sọ Jí

Orí 25

A Mú Àwọn Ẹlẹ́rìí Méjì Náà Sọ Jí

1. Kí ni áńgẹ́lì alágbára náà ké sí Jòhánù láti ṣe?

 KÍ ÈGBÉ kejì tó kọjá lọ tán, áńgẹ́lì alágbára náà ké sí Jòhánù láti kópa nínú ìfihàn mìíràn tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀, èyí sì ní í ṣe pẹ̀lú tẹ́ńpìlì. (Ìṣípayá 9:12; 10:1) Ohun tí Jòhánù sọ nìyí: “A sì fún mi ní esùsú kan tí ó dà bí ọ̀pá bí ó ti wí pé: ‘Dìde, kí o sì wọn ibùjọsìn tẹ́ńpìlì Ọlọ́run àti pẹpẹ àti àwọn tí ń jọ́sìn nínú rẹ̀.’”—Ìṣípayá 11:1.

Ibùjọsìn Tẹ́ńpìlì

2. (a) Tẹ́ńpìlì wo ni yóò wà títí di ọjọ́ wa? (b) Ta ni Àlùfáà Àgbà tẹ́ńpìlì náà, kí sì ni ibi Mímọ́ Jù Lọ tẹ́ńpìlì yìí?

2 Tẹ́ńpìlì tá a mẹ́nu kàn níhìn-ín kò lè jẹ́ tẹ́ńpìlì àfọwọ́kọ́ èyíkéyìí ní Jerúsálẹ́mù, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ará Róòmù ti pa èyí tí wọ́n kọ́ síbẹ̀ kẹ́yìn run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni. Àmọ́ ṣá o, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé kódà ṣáájú ìparun yẹn, tẹ́ńpìlì mìíràn ti fara hàn, èyí tó máa wà títí di ọjọ́ wa. Èyí jẹ́ tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí tí àgọ́ ìjọsìn àtàwọn tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ lẹ́yìn náà ní Jerúsálẹ́mù, dúró fún. Òun ni “àgọ́ tòótọ́, tí Jèhófà gbé ró, kì í sì í ṣe ènìyàn,” Àlùfáà Àgbà rẹ̀ sì ni Jésù, ẹni tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa rẹ̀ pé, ní báyìí, ó ti “jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọba Ọlọ́lá ní ọ̀run.” Ibi Mímọ́ Jù Lọ tẹ́ńpìlì yìí ni ibi tí Jèhófà wà gan-an ní ọ̀run.—Hébérù 8:1, 2; 9:11, 24.

3. Nínú àgọ́ ìjọsìn, kí làwọn nǹkan wọ̀nyí dúró fún (a) aṣọ ìkélé tó ya ibi Mímọ́ Jù Lọ sọ́tọ̀ kúrò lára ibi Mímọ́? (b) fífi ẹran rúbọ? (d) pẹpẹ ìrúbọ?

3 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé aṣọ ìkélé àgọ́ ìjọsìn tó ya ibi Mímọ́ Jù Lọ sọ́tọ̀ kúrò lára ibi Mímọ́, ṣàpẹẹrẹ ẹran ara Jésù. Nígbà tí Jésù fi ìwàláàyè rẹ̀ rúbọ, aṣọ ìkélé yìí ya sí méjì, èyí tó fi hàn pé ẹran ara Jésù kì í ṣe ìdènà mọ́ fún un láti wọlé sí ibi tí Jèhófà wà ní ọ̀run. Lọ́lá ẹbọ Jésù, nígbà tó bá tó àkókò, àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ àlùfáà lábẹ́ àbójútó rẹ̀ náà yóò kọjá lọ sí ọ̀run tí wọ́n bá kú gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́. (Mátíù 27:50, 51; Hébérù 9:3; 10:19, 20) Pọ́ọ̀lù tún sọ pé, fífi tí wọ́n máa ń fi ẹran rúbọ láìdáwọ́dúró nínú àgọ́ ìjọsìn ń tọ́ka sí ẹbọ kan ṣoṣo tí Jésù fi ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn pípé rẹ̀ rú. Pẹpẹ ìrúbọ tó wà ní àgbàlá dúró fún ìpèsè tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu fún wíwo ọlá ẹbọ Jésù mọ́ “ọ̀pọ̀lọpọ̀” lára. Ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró àti, lẹ́yìn náà, àwọn àgùntàn mìíràn tí yóò máa “fi taratara wá a fún ìgbàlà wọn.”—Hébérù 9:28; 10:9, 10; Jòhánù 10:16.

4. Kí làwọn nǹkan wọ̀nyí dúró fún: (a) Ibi Mímọ́? (b) àgbàlá inú lọ́hùn-ún?

4 Látinú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí, a lè sọ pé ipò mímọ́ tí Kristi kọ́kọ́ wà, táwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ẹni àmì òróró ẹgbẹ́ àlùfáà ọlọ́ba náà sì wà pẹ̀lú nígbà tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé, kí wọ́n tó gba ibi “aṣọ ìkélé” wọlé, ni Ibi Mímọ́ inú àgọ́ ìjọsìn náà dúró fún. (Hébérù 6:19, 20; 1 Pétérù 2:9) Èyí ṣe rẹ́gí pẹ̀lú bá a ṣe sọ wọ́n dọmọ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹ̀mí fún Ọlọ́run, àní lọ́nà kan náà tí Ọlọ́run gbà fi hàn pé ọmọ òun ni Jésù, lẹ́yìn ìrìbọmi rẹ̀ nínú odò Jọ́dánì lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni. (Lúùkù 3:22; Róòmù 8:15) Àgbàlá inú lọ́hùn-ún ńkọ́, èyí tó jẹ́ apá ibì kan ṣoṣo nínú àgọ́ ìjọsìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kì í ṣe àlùfáà lè rí tó sì tún jẹ́ ibi tí wọ́n ti ń rú oríṣiríṣi ẹbọ? Èyí dúró fún ìjẹ́pípé ọkùnrin náà, Jésù, èyí tó mú un kúnjú ìwọ̀n láti fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ nítorí aráyé. Ó tún dúró fún ipò jíjẹ́ olódodo gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́, èyí tí Ọlọ́run fi dá àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù lọ́lá nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù nígbà tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé. aRóòmù 1:7; 5:1.

Wíwọn Tẹ́ńpìlì Mímọ́ Náà

5. Nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, kí ni ìtumọ̀ (a) wíwọn Jerúsálẹ́mù? (b) wíwọn tẹ́ńpìlì inú ìran Ìsíkíẹ́lì?

5 Áńgẹ́lì náà sọ fún Jòhánù pé kó “wọn ibùjọsìn tẹ́ńpìlì Ọlọ́run àti pẹpẹ àti àwọn tí ń jọ́sìn nínú rẹ̀.” Kí ni èyí túmọ̀ sí? Nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, irú wíwọ̀n bẹ́ẹ̀ mú un dáni lójú pé ìdájọ́ òdodo yóò tẹni lọ́wọ́ nítorí pé àwọn ìlànà Jèhófà jẹ́ pípé. Nígbà ayé ọba burúkú náà, Mánásè, wíwọ̀n tí wọ́n wọn Jerúsálẹ́mù, jẹ́ àpẹẹrẹ pé ìdájọ́ ìparun tí kò ṣe é yí padà ń bọ̀ lórí ìlú yẹn. (2 Àwọn Ọba 21:13; Ìdárò 2:8) Àmọ́ lẹ́yìn náà, nígbà tí Jeremáyà rí i tí wọ́n wọn Jerúsálẹ́mù, ńṣe nìyẹn túbọ̀ mú kó dájú pé wọ́n á tún ìlú náà kọ́. (Jeremáyà 31:39; tún wo Sekaráyà 2:2-8.) Lọ́nà kan náà, nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, wíwọ̀n tí wọ́n wọn tẹ́ńpìlì inú ìran náà tinú tòde jẹ́ ẹ̀rí tó mú un dá àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì lójú pé a óò mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò ní orílẹ̀-èdè wọn. Ó tún rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé nítorí ìṣìnà wọn, wọ́n ní láti kúnjú ìwọ̀n àwọn ìlànà Ọlọ́run tó jẹ́ mímọ́ látìgbà náà lọ.—Ìsíkíẹ́lì 40:3, 4; 43:10.

6. Àmì kí ni sísọ tá a sọ fún Jòhánù láti wọn tẹ́ńpìlì náà àtàwọn àlùfáà tó ń jọ́sìn nínú rẹ̀ jẹ́? Ṣàlàyé.

6 Nítorí náà, nígbà tá a pàṣẹ fún Jòhánù láti wọn tẹ́ńpìlì náà àtàwọn àlùfáà tó ń jọ́sìn nínú rẹ̀, èyí jẹ́ àmì pé ohunkóhun kò lè ṣèdíwọ́ fún ìmúṣẹ àwọn ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn nípa ètò inú tẹ́ńpìlì náà àtàwọn tó ń jọ́sìn nínú rẹ̀, àti pé àwọn nǹkan wọ̀nyí ti ń sún mọ́ ìparí wọn. Nísinsìnyí tá a ti wá fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ áńgẹ́lì alágbára náà, àkókò ti tó fún “òkè ńlá ilé Jèhófà” láti di èyí tá a “fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá.” (Aísáyà 2:2-4) Ìjọsìn mímọ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ di èyí tá a gbé ga lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti di apẹ̀yìndà. Bákan náà, àkókò ti tó láti jí àwọn olùṣòtítọ́ arákùnrin Jésù tí wọ́n ti kú dìde sí “Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́.” (Dáníẹ́lì 9:24; 1 Tẹsalóníkà 4:14-16; Ìṣípayá 6:11; 14:4) Àwọn tá a fi èdìdì dì kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n jẹ́ “ẹrú Ọlọ́run wa” la sì tún gbọ́dọ̀ wọ̀n níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run, kí wọ́n lè dẹni tó yẹ fún àyè wọn tó máa wà títí lọ nínú ìṣètò tẹ́ńpìlì náà gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ọlọ́run tá a fi ẹ̀mí bí. Ẹgbẹ́ Jòhánù lónìí mọ àwọn ìlànà mímọ́ wọ̀nyẹn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, ó sì ti pinnu láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà.—Ìṣípayá 7:1-3; Mátíù 13:41, 42; Éfésù 1:13, 14; fi wé Róòmù 11:20.

Títẹ Àgbàlá Náà Mọ́lẹ̀

7. (a) Kí nìdí tá a fi sọ fún Jòhánù láti má ṣe wọn àgbàlá náà? (b) Ìgbà wo làwọn orílẹ̀-èdè tẹ ìlú mímọ́ náà mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ fún oṣù méjìlélógójì? (d) Báwo làwùjọ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe kùnà láti pa àwọn ìlànà Jèhófà tó jẹ́ òdodo mọ́ fún oṣù méjìlélógójì?

7 Kí nìdí tí áńgẹ́lì náà fi sọ pé kí Jòhánù má ṣe wọn àgbàlá náà? Ó sọ fún wa pé: “Ṣùgbọ́n ní ti àgbàlá tí ó wà ní ẹ̀yìn òde ibùjọsìn tẹ́ńpìlì, fi í sílẹ̀ pátápátá, má sì wọ̀n ọ́n, nítorí a ti fi í fún àwọn orílẹ̀-èdè, wọn yóò sì tẹ ìlú ńlá mímọ́ náà mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ fún oṣù méjìlélógójì.” (Ìṣípayá 11:2) A ti sọ pé àgbàlá inú lọ́hùn-ún dúró fún jíjẹ́ táwọn Kristẹni tá a fi ẹ̀mí bí lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bá a ó ti rí i, oṣù méjìlélógójì [42] ní ti gidi ni ibí yìí ń tọ́ka sí, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní December ọdún 1914 títí dé June ọdún 1918, nígbà tí gbogbo àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni rí ìdánwò líle koko. Ǹjẹ́ wọ́n pa àwọn ìlànà Jèhófà tó jẹ́ òdodo mọ́ láwọn ọdún tí ogun ń jà wọ̀nyẹn? Ọ̀pọ̀ jù lọ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ni ẹgbẹ́ àlùfáà lápapọ̀ fi ṣáájú ṣíṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run. Níhà méjèèjì ogun náà, èyí tí wọ́n jà ní pàtàkì láwọn ilẹ̀ tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti gbilẹ̀, àwùjọ àlùfáà fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin níṣìírí láti lọ sójú ogun. Ọ̀kẹ́ àìmọye wọn ló sì bógun lọ. Nígbà tó fi máa di àkókò tí ìdájọ́ yẹn bẹ̀rẹ̀ nílé Ọlọ́run lọ́dún 1918, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà náà ti dara pọ̀ nínú ìtàjẹ̀sílẹ̀ yẹn, àwùjọ àlùfáà sì ti jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, èyí tó wá ń ké jáde títí di ìsinsìnyí fún Ọlọ́run láti gbẹ̀san. (1 Pétérù 4:17) Títa tí Ọlọ́run ta wọ́n nù ti wá di èyí tó wà títí lọ, kò sì ṣeé yí pa dà.—Aísáyà 59:1-3, 7, 8; Jeremáyà 19:3, 4.

8. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, kí ni ọ̀pọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀, ṣùgbọ́n kí ni wọn kò lóye rẹ̀ dáadáa?

8 Àmọ́ kí làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n jẹ́ àwùjọ kékeré ṣe? Ṣé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lọ́dún 1914 yẹn la díwọ̀n wọn nípa rírọ̀ tí wọ́n rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run? Rárá o. Bíi tàwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́, a gbọ́dọ̀ dán àwọn náà wò. ‘A yà wọ́n kúrò pátápátá, a sì fi wọ́n fún àwọn orílẹ̀-èdè’ láti dán wọn wò lọ́nà rírorò kí wọ́n sì ṣenúnibíni sí wọn. Ọ̀pọ̀ nínú wọn mọ̀ pé àwọn ò gbọ́dọ̀ lọ pa èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọn kò tíì fi bẹ́ẹ̀ lóye ipò Kristẹni lórí ọ̀ràn àìlọ́wọ́ sógun. (Míkà 4:3; Jòhánù 17:14, 16; 1 Jòhánù 3:15) Nítorí pé àwọn orílẹ̀-èdè fúngun mọ́ wọn gan-an, àwọn kan juwọ́ sílẹ̀.

9. Kí ni ìlú mímọ́ náà táwọn orílẹ̀-èdè tẹ̀ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn, àwọn wo ló sì dúró fún ìlú yìí lórí ilẹ̀ ayé?

9 Àmọ́ ọ̀nà wo làwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn gbà tẹ ìlú mímọ́ náà mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn? Ó hàn gbangba pé kì í ṣe Jerúsálẹ́mù tí wọ́n ti pa run ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ṣáájú kí wọ́n tó kọ ìwé Ìṣípayá lèyí ń tọ́ka sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jerúsálẹ́mù Tuntun ni ìlú mímọ́ náà, èyí tá a wá sọ nípa rẹ̀ nígbà tó yá nínú ìwé Ìṣípayá. Ìyókù Kristẹni ẹni àmì òróró nínú àgbàlá inú lọ́hùn-ún ló wá dúró fún tẹ́ńpìlì yìí nísinsìnyí lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà tó bá yá, àwọn wọ̀nyí yóò tún di apá kan ìlú mímọ́ náà. Nítorí náà títẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ ṣe rẹ́gí pẹ̀lú títẹ ìlú náà fúnra rẹ̀ mọ́lẹ̀.—Ìṣípayá 21:2, 9-21.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Méjì

10. Kí làwọn Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ fún Jèhófà ní láti ṣe nígbà tí wọ́n ṣì ń tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀?

10 Kódà nígbà tí wọ́n tiẹ̀ ṣì tẹ àwọn adúróṣinṣin wọ̀nyí mọ́lẹ̀, wọ́n ń bá a nìṣó ní jíjẹ́ ẹlẹ́rìí olóòótọ́ fún Jèhófà. Fún ìdí yìí, àsọtẹ́lẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “‘Ṣe ni èmi yóò mú kí àwọn ẹlẹ́rìí mi méjì sọ tẹ́lẹ̀ fún ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà ọjọ́ ní wíwọ aṣọ àpò [ìdọ̀họ].’ Àwọn wọ̀nyí ni a fi igi ólífì méjì àti ọ̀pá fìtílà méjì ṣàpẹẹrẹ, wọ́n sì dúró níwájú Olúwa ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 11:3, 4.

11. Kí ló túmọ̀ sí pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró olóòótọ́ ń sọ tẹ́lẹ̀ nínú “aṣọ àpò ìdọ̀họ”?

11 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ yìí nílò ìfaradà, nítorí wọ́n ní láti sọ tẹ́lẹ̀ nínú “aṣọ àpò ìdọ̀họ.” Kí lèyí túmọ̀ sí? Lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, aṣọ àpò ìdọ̀họ sábà máa ń dúró fún ṣíṣọ̀fọ̀. Wíwọ̀ ọ́ jẹ́ àmì pé inú ẹni tó wọ̀ ọ́ bà jẹ́ tàbí pé ìdààmú bá a. (Jẹ́nẹ́sísì 37:34; Jóòbù 16:15, 16; Ìsíkíẹ́lì 27:31) Aṣọ àpò ìdọ̀họ máa ń ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìhìn tó jẹ́ ègbé tàbí ẹ̀dùn ọkàn, èyí tó ń múni ṣọ̀fọ̀, táwọn wòlíì Ọlọ́run ní láti kéde rẹ̀. (Aísáyà 3:8, 24-26; Jeremáyà 48:37; 49:3) Wíwọ aṣọ àpò ìdọ̀họ lè jẹ́ ọ̀nà téèyàn gbà fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tàbí ìrònúpìwàdà hàn lẹ́yìn tó gbọ́ ìkìlọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Jónà 3:5) Ó jọ pé ìfaradà táwọn ẹlẹ́rìí méjì náà ní bí wọ́n ti ń fìrẹ̀lẹ̀ kéde àwọn ìdájọ́ Jèhófà ni aṣọ àpò ìdọ̀họ tí wọ́n wọ̀ náà dúró fún. Wọ́n jẹ́ àwọn ẹlẹ́rìí tó ń kéde ọjọ́ ẹ̀san Jèhófà èyí tí yóò mú ọ̀fọ̀ bá àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú.—Diutarónómì 32:41-43.

12. Kí nìdí tí àkókò tí ìlú mímọ́ náà fi wà ní títẹ̀mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ fi jọ pé kò ní ìtumọ̀ mìíràn?

12 Ẹgbẹ́ Jòhánù ní láti wàásù ìhìn yìí fún àkókò kan tá a sọ ní pàtó, ìyẹn ni ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà [1,260] ọjọ́, tàbí oṣù méjìlélógójì [42], tó jẹ́ iye àkókò kan náà tí ìlú mímọ́ náà á fi wà ní títẹ̀mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀. Ó dà bíi pé sáà àkókò yìí kò ní ìtumọ̀ mìíràn, níwọ̀n bá a ti sọ ọ́ ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó yàtọ̀ síra, a sọ iye oṣù tó jẹ́, a sì tún sọ iye ọjọ́ tó jẹ́. Kò mọ síbẹ̀ o, níbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa, sáà àkókò ọlọ́dún mẹ́ta àtààbọ̀ kan wà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn ìgbà táwọn èèyàn Ọlọ́run rí irú ìnira tá a sọ tẹ́lẹ̀ níbí. Èyí sì bẹ̀rẹ̀ ní December ọdún 1914 títí di June ọdún 1918. (Ìṣípayá 1:10) Wọ́n wàásù ìhìn ‘aláṣọ àpò ìdọ̀họ’ nípa ìdájọ́ tí Jèhófà máa ṣe fáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti ayé.

13. (a) Kí ni fífi tí wọ́n fi àwọn ẹlẹ́rìí méjì ṣàpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró túmọ̀ sí? (b) Àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà wo ni pípè tí Jòhánù pe àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà ní “igi ólífì méjì àti ọ̀pá fìtílà méjì” mú ká rántí?

13 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́rìí méjì la fi ṣàpẹẹrẹ wọn, èyí jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé iṣẹ́ tí wọ́n ń jẹ́ péye, ó sì lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. (Fi wé Diutarónómì 17:6; Jòhánù 8:17, 18.) Jòhánù pè wọ́n ní “igi ólífì méjì àti ọ̀pá fìtílà méjì,” àti pé “wọ́n sì dúró níwájú Olúwa ilẹ̀ ayé.” Ó dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà níbi tó ti rí ọ̀pá fìtílà ẹlẹ́ka méje àti igi ólífì méjì, ni Jòhánù ń sọ̀rọ̀ bá. Àwọn igi ólífì náà la sọ pé wọ́n ṣàpẹẹrẹ “àwọn ẹni àmì òróró méjì,” ìyẹn ni, Gómìnà Serubábélì àti Àlùfáà Àgbà náà Jóṣúà, tí wọ́n “dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ Olúwa gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Sekaráyà 4:1-3, 14.

14. (a) Kí ni ìtumọ̀ ìran tí Sekaráyà rí nípa igi ólífì méjì? àti ọ̀pá fìtílà? (b) Kí làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní?

14 Àkókò tí àtúnkọ́ tẹ́ńpìlì ṣẹlẹ̀ ni Sekaráyà gbé ayé, ìran tó sì rí nípa igi ólífì méjì túmọ̀ sí pé Jèhófà yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ bù kún Serubábélì àti Jóṣúà kí wọ́n lè fún àwọn èèyàn náà lókun fún iṣẹ́ náà. Ìran ọ̀pá fìtílà yẹn rán Sekaráyà létí láti má ṣe “tẹ́ńbẹ́lú ọjọ́ àwọn ohun kékeré” nítorí pé àwọn ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn yóò nímùúṣẹ. Èyí “‘kì í ṣe nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ológun, tàbí nípasẹ̀ agbára, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.” (Sekaráyà 4:6, 10; 8:9) Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run lo àwọn Kristẹni kéréje tí wọ́n jára mọ́ iṣẹ́ mímú ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ tọ aráyé lọ lákòókò Ogun Àgbáyé Kìíní, nínú iṣẹ́ àtúnkọ́ kan. Àwọn náà á máa fúnni ní ìṣírí, àti pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kéré níye, wọ́n kọ́ láti gbára lé okun Jèhófà, wọn ò tẹ́ńbẹ́lú ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ kékeré.

15. (a) Níwọ̀n bá a ti ṣàpèjúwe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹ́rìí méjì, kí lèyí tún rán wa létí rẹ̀? Ṣàlàyé. (b) Irú àwọn iṣẹ́ àmì wo la fún àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà láṣẹ láti ṣe?

15 Pípè tá a pè wọ́n ní ẹlẹ́rìí méjì tún rán wa létí ìyípadà ológo náà. Nínú ìran yẹn, mẹ́ta nínú àwọn àpọ́sítélì Jésù rí Jésù nínú ògo Ìjọba, tí Mósè àti Èlíjà sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Èyí ṣàpẹẹrẹ jíjókòó tí Jésù jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ ológo lọ́dún 1914 láti ṣe iṣẹ́ táwọn wòlíì méjì wọ̀nyẹn dúró fún láṣeparí. (Mátíù 17:1-3) Lọ́nà tó bá a mu rẹ́gí, a wá rí àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà báyìí tí wọ́n ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tó rán wa létí ohun tí Mósè àti Èlíjà ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Jòhánù sọ nípa wọn pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọ́n lára, iná a jáde wá láti ẹnu wọn, a sì jẹ àwọn ọ̀tá wọn run; bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọ́n lára pẹ́nrẹ́n, lọ́nà yìí ni a ó pa á. Àwọn wọ̀nyí ní ọlá àṣẹ láti sé ọ̀run pa kí òjò kankan má bàa rọ̀ ní àwọn ọjọ́ ìsọtẹ́lẹ̀ wọn.”—Ìṣípayá 11:5, 6a.

16. (a) Báwo ni àmì tó ní iná nínú ṣe rán wa létí ìgbà táwọn kan ta ko àṣẹ Mósè ní Ísírẹ́lì? (b) Báwo làwùjọ àlùfáà ṣe ṣàfojúdi sáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì dá wàhálà sílẹ̀ fún wọn nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, báwo sì làwọn wọ̀nyí ṣe jà padà?

16 Èyí rán wa létí ìgbà táwọn kan ń ta ko àṣẹ Mósè nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Wòlíì yẹn sọ àwọn ọ̀rọ̀ mímúná jáde èyí tó jẹ́ ìdájọ́, Jèhófà sì pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà run, ó fi iná gidi láti ọ̀run jó àádọ́talérúgba [250] lára wọn run. (Númérì 16:1-7, 28-35) Lọ́nà kan náà, àwọn aṣáájú ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì ṣàfojúdi sáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n ní wọn ò gboyè jáde láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlẹ́rìí Ọlọ́run wọ̀nyí ní àwọn ẹ̀rí tó ga ju èyí lọ tó fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́. Ẹ̀rí náà ni pé: àwọn onínú tútù èèyàn tẹ̀ lé ohun tí wọ́n ń wàásù rẹ̀ látinú Ìwé Mímọ́. (2 Kọ́ríńtì 3:2, 3) Lọ́dún 1917, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ ìwé kan jáde, ìyẹn The Finished Mystery. Ó jẹ́ àlàyé tó fa kíki nípa ìwé Ìṣípayá àti ìwé Ìsíkíẹ́lì. Lẹ́yìn náà ni wọ́n tún wá pín mílíọ̀nù mẹ́wàá [10,000,000] ẹ̀dà àṣàrò kúkúrú kan tó ní ojú ewé mẹ́rin tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ The Bible Students Monthly (Gẹ̀ẹ́sì) fáwọn èèyàn. Àkọlé àpilẹ̀kọ tó gbé jáde ni, “Ìṣubú Bábílónì—Ìdí Táwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Fi Gbọ́dọ̀ Fojú Winá Àbájáde Ìkẹyìn.” Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwùjọ àlùfáà tínú ń bí, lo rúkèrúdò ìgbà ogun gẹ́gẹ́ bí àwáwí láti mú kí ìjọba fòfin de ìwé náà. Láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, wọ́n yẹ ìwé náà wò kí wọ́n lè yọ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kà sí èyí tí kò bójú mu kúrò nínú rẹ̀. Síbẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ó yéé jà padà nípa lílo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú olójú ewé mẹ́rin tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Ìròyìn Ìjọba (Gẹ̀ẹ́sì), tó ní àwọn ọ̀rọ̀ tó mú bí iná nínú. Bí ọjọ́ Olúwa ti ń tẹ̀ síwájú, àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn mú kó hàn kedere pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti kú nípa tẹ̀mí.—Fi wé Jeremáyà 5:14.

17. (a) Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Èlíjà tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀dá àti iná? (b) Báwo ni iná ṣe jáde látẹnu àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà, ọ̀dá wo ló sì dá?

17 Èlíjà ńkọ́? Nígbà táwọn ọba ń ṣàkóso nílẹ̀ Ísírẹ́lì, wòlíì yìí kéde pé ọ̀dá máa dá, èyí táá fi hàn pé inú ń bí Jèhófà sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń jọ́sìn Báálì. Ọ̀dá náà dá fún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀. (1 Àwọn Ọba 17:1; 18:41-45; Lúùkù 4:25; Jákọ́bù 5:17) Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ọba Ahasáyà aláìṣòótọ́ rán àwọn jagunjagun láti lọ fipá mú Èlíjà wá síwájú òun, wòlíì náà pe iná láti ọ̀run láti wá jó àwọn jagunjagun náà run. Àfìgbà tí olórí ogun kan tó gba Èlíjà ní wòlíì nípa fífi ọ̀wọ̀ fún un ni Èlíjà tó gbà láti bá a lọ sọ́dọ̀ ọba. (2 Àwọn Ọba 1:5-16) Lọ́nà kan náà, láàárín ọdún 1914 sí ọdún 1918, ìyókù àwọn ẹni àmì òróró fi àìṣojo pe àfiyèsí sí ọ̀dá tẹ̀mí, ìyẹn àìrí oúnjẹ tẹ̀mí jẹ, èyí tó ń bá àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fínra, wọ́n sì kìlọ̀ nípa ìdájọ́ mímúná tó ń bọ̀ nígbà “dídé ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà.”—Málákì 4:1, 5; Ámósì 8:11.

18. (a) Àṣẹ wo la fún àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà, báwo lèyí sì ṣe jọ èyí tí Ọlọ́run fún Mósè? (b) Báwo làwọn ẹlẹ́rìí méjì náà ṣe táṣìírí ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì?

18 Jòhánù ń bá a lọ láti sọ nípa àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà pé: “Wọ́n sì ní ọlá àṣẹ lórí àwọn omi láti sọ wọ́n di ẹ̀jẹ̀ àti láti fi gbogbo onírúurú ìyọnu àjàkálẹ̀ kọlu ilẹ̀ ayé nígbàkúùgbà tí wọ́n bá fẹ́.” (Ìṣípayá 11:6b) Láti lè yí Fáráò lọ́kàn padà kó lè dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀, Jèhófà lo Mósè láti mú àwọn ìyọnu kan wá sórí àwọn ará Íjíbítì tó ń ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára, títí kan yíyí omi padà sí ẹ̀jẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, àwọn ará Filísínì tó jẹ́ ọ̀tá Ísírẹ́lì ṣì rántí àwọn ohun tí Jèhófà ṣe sí Íjíbítì dáadáa, èyí tó mú wọn kígbe pé: “Ta ni yóò gbà wá là kúrò lọ́wọ́ Ọlọ́run ọlọ́lá ńlá yìí? Èyí ni Ọlọ́run tí ó jẹ́ olùfi gbogbo onírúurú ìpakúpa [“ìyọnu,” Revised Standard Version] kọlu Íjíbítì ní aginjù.” (1 Sámúẹ́lì 4:8; Sáàmù 105:29) Mósè ṣàpẹẹrẹ Jésù, ẹni tó ní àṣẹ láti kéde àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run sórí àwọn aṣáájú ìsìn ọjọ́ rẹ̀. (Mátíù 23:13; 28:18; Ìṣe 3:22) Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní ṣì ń lọ lọ́wọ́, àwọn arákùnrin Kristi tí í ṣe àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà, tú ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì fó pé “àwọn omi” tó ń fún àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ mu jẹ́ èyí tó ń ṣekú pani.

Wọ́n Pa Àwọn Ẹlẹ́rìí Méjì Náà

19. Níbàámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ inú ìwé Ìṣípayá, kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ẹlẹ́rìí méjì náà parí ìjẹ́rìí wọn?

19 Ìyọnu yìí ká àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lára débi pé, lẹ́yìn táwọn ẹlẹ́rìí méjì náà ti sọ tẹ́lẹ̀ fún oṣù méjìlélógójì [42] nínú aṣọ àpò ìdọ̀họ, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lo agbára tí wọ́n ní nínú ayé láti mú kí wọ́n “pa” àwọn ẹlẹ́rìí náà. Jòhánù kọ̀wé pé: “Nígbà tí wọ́n bá sì ti parí ìjẹ́rìí wọn, ẹranko ẹhànnà tí ó gòkè wá láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ yóò bá wọn jagun, yóò sì ṣẹ́gun wọn, yóò sì pa wọ́n. Òkú wọn yóò sì wà ní ọ̀nà fífẹ̀ ìlú ńlá títóbi náà, èyí tí a ń pè lọ́nà ìtumọ̀ ti ẹ̀mí ní Sódómù àti [Íjíbítì], níbi tí a ti kan Olúwa wọn mọ́gi pẹ̀lú. Àwọn tí ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti orílẹ̀-èdè yóò sì wo òkú wọn fún ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀, wọn kò sì jẹ́ kí a tẹ́ òkú wọn sínú ibojì. Àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé sì yọ̀ lórí wọn, wọ́n sì gbádùn ara wọn, wọn yóò sì fi àwọn ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí pé wòlíì méjì wọ̀nyí mú àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé joró.”—Ìṣípayá 11:7-10.

20. Kí ni “ẹranko ẹhànnà tí ó gòkè wá láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀”?

20 Èyí ni ibi àkọ́kọ́ nínú ibi mẹ́tàdínlógójì [37] tá a ti sọ̀rọ̀ nípa ẹranko ẹhànnà kan nínú ìwé Ìṣípayá. Bó bá yá, a óò jíròrò nípa èyí àtàwọn ẹranko mìíràn lẹ́kún-ún rẹ́rẹ́. Ohun tá a ṣì lè sọ nísinsìnyí ni pé “ẹranko ẹhànnà tí ó gòkè wá láti inú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀” jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Sátánì, ìyẹn ètò ìṣèlú tó wà lẹ́nu iṣẹ́ pẹrẹu báyìí. b—Fi wé Ìṣípayá 13:1; Dáníẹ́lì 7:2, 3, 17.

21. (a) Báwo làwọn onísìn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà ṣe lo àǹfààní àkókò ogun? (b) Kí ni fífi tí wọ́n fi òkú àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà sílẹ̀ láìsin túmọ̀ sí? (d) Báwo ló ṣe yẹ ká lóye sáà ọjọ́ mẹ́ta àtààbọ̀ náà? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

21 Láti ọdún 1914 sí ọdún 1918, àwọn orílẹ̀-èdè gbájú mọ́ Ogun Àgbáyé Kìíní. Ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni jọba lọ́kàn àwọn èèyàn, nígbà tó sì di ìgbà ìrúwé ọdún 1918, àwọn onísìn tó jẹ́ ọ̀tá àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà lo àǹfààní ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Wọ́n fọgbọ́n darí ẹ̀ka ìjọba tó ń rí sí ọ̀rọ̀ òfin débi tí wọ́n fi sọ àwọn òjíṣẹ́ tó wà nípò àbójútó láàárín àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn èké pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ síjọba. Ìyàlẹ́nu lèyí jẹ́ fáwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tó jẹ́ olóòótọ́. Iṣẹ́ ìwàásù nípa Ìjọba náà fẹ́rẹ̀ẹ́ dáwọ́ dúró pátápátá. Ńṣe ló dà bíi pé iṣẹ́ ìwàásù náà ti kú. Lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ohun ẹ̀tẹ́ tó burú jáì ló jẹ́ bí wọn ò bá sin òkú ẹnì kan sínú ibojì ìrántí. (Sáàmù 79:1-3; 1 Àwọn Ọba 13:21, 22) Nítorí náà, ẹ̀gàn ńlá ni fífi tá a fi àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà sílẹ̀ láìsin jẹ́. Nínú oòrùn tó máa ń mú bí iná nílẹ̀ Palẹ́sìnì, òkú tó bá wà lójú pópó gbayawu á bẹ̀rẹ̀ sí í rùn lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àtààbọ̀. c (Fi wé Jòhánù 11:39.) Àlàyé kínníkínní yìí nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí jẹ́ ká tipa báyìí rí ìtìjú táwọn ẹlẹ́rìí méjì náà ní láti fara dà. Kódà wọn ò jẹ́ kí wọ́n gba onídùúró àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀kan pé wọ́n sọ sẹ́wọ̀n nígbà tí ẹjọ́ wọ́n wà nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn. Wọ́n gbé wọn sáyé fún àkókò tó gùn tó láti mú kí wọ́n máa rùn sáwọn olùgbé “ìlú ńlá títóbi náà.” Ṣùgbọ́n kí ni “ìlú ńlá títóbi” yìí?

22. (a) Kí ni ìlú títóbi náà? (b) Báwo làwọn ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn ṣe dara pọ̀ mọ́ àwùjọ àlùfáà láti máa yọ̀ nítorí pípa tí wọ́n pa àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà lẹ́nu mọ́? (Wo àpótí.)

22 Jòhánù sọ àwọn nǹkan tó lè là wá lọ́yẹ̀. Ó sọ pé a kan Jésù mọ́gi níbẹ̀. Nítorí náà, kíákíá lọkàn wa máa lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n ó tún sọ pé a pe ìlú títóbi náà ní Sódómù àti Íjíbítì. Ó dáa, ìgbà kan wà tí Bíbélì pe Jerúsálẹ́mù ní Sódómù nítorí àwọn ohun aláìmọ́ tó ń ṣe. (Aísáyà 1:8-10; fi wé Ìsíkíẹ́lì 16:49, 53-58.) Ìgbà míì sì wà tí Íjíbítì tó jẹ́ agbára ayé kìíní máa ń ṣàpẹẹrẹ ètò àwọn nǹkan ayé yìí. (Aísáyà 19:1, 19; Jóẹ́lì 3:19) Fún ìdí yìí, ìlú ńlá yìí ń ṣàpẹẹrẹ “Jerúsálẹ́mù” tó ti di ẹlẹ́gbin, èyí tó sọ pé òun ń jọ́sìn Ọlọ́run ṣùgbọ́n tó ti di aláìmọ́ àti ẹlẹ́ṣẹ̀ bíi ti Sódómù, tó sì tún ti di apá kan ètò àwọn nǹkan ayé Sátánì yìí bíi ti Íjíbítì. Ó dúró fáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, èyí tó ṣe rẹ́gí lóde òní pẹ̀lú Jerúsálẹ́mù aláìṣòótọ́ ayé ọjọ́un. Inú àwọn tó jẹ́ ara ètò ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì sì dùn gan-an nígbà tí ìjọba dá ìwàásù ayọnilẹ́nu àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà dúró.

Wọ́n Dìde Padà!

23. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹlẹ́rìí méjì náà lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àtààbọ̀, báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ yìí sì ṣe rí lára àwọn ọ̀tá wọn? (b) Ìgbà wo ni Ìṣípayá 11:11, 12 àti àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì nípa mímí tí Jèhófà mí sára àwọn egungun gbígbẹ àfonífojì kan ní ìmúṣẹ ti òde òní?

23 Àwọn ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn dara pọ̀ mọ́ àwùjọ àlùfáà nínú fífi ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ba àwọn èèyàn Ọlọ́run jẹ́. Ìwé ìròyìn kan tiẹ̀ sọ pé: “A ti sọ òpin ìwé The Finished Mystery.” Àmọ́ irọ́ pátápátá gbáà ni èyí. Àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà kò jẹ́ òkú títí lọ. A kà pé: “Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sì wọnú wọn, wọ́n sì dúró lórí ẹsẹ̀ wọn, ẹ̀rù ńlá sì ba àwọn tí ń wò wọ́n. Wọ́n sì gbọ́ tí ohùn rara kan láti ọ̀run wí fún wọn pé: ‘Ẹ máa bọ̀ lókè níhìn-ín.’ Wọ́n sì gòkè lọ sínú ọ̀run nínú àwọsánmà, àwọn ọ̀tá wọn sì rí wọn.” (Ìṣípayá 11:11, 12) Nípa báyìí, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn jọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn egungun gbígbẹ tó wà ní àfonífojì tí Ìsíkíẹ́lì ṣèbẹ̀wò sí nínú ìran. Jèhófà mí sára àwọn egungun gbígbẹ wọ̀nyẹn, wọ́n sì sọ jí, èyí tó ń ṣàpẹẹrẹ títún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì bí lẹ́yìn àádọ́rin [70] ọdún ní ìgbèkùn Bábílónì. (Ìsíkíẹ́lì 37:1-14) Ọdún 1919 làwọn àsọtẹ́lẹ̀ méjì wọ̀nyí, ti inú Ìsíkíẹ́lì àti tinú Ìṣípayá, ní ìmúṣẹ ti òde òní, ó sì jẹ́ lọ́nà tó pabanbarì, ìyẹn nígbà tí Jèhófà mú àwọn “olóògbé” ẹlẹ́rìí rẹ̀ wá sí ìyè tó jí pépé.

24. Nígbà táwọn ẹlẹ́rìí méjì náà sọ jí, báwo lèyí ṣe rí lára àwọn onísìn tó ń ṣenúnibíni sí wọn?

24 Ẹ wo jìnnìjìnnì tí èyí kó bá àwọn tó ń ṣenúnibíni wọ̀nyẹn! Òkú àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà tún sọ jí lójijì wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà ní pẹrẹu. Èyí jẹ́ ohun tí kò bára dé rárá fáwọn àlùfáà wọnnì, pàápàá níwọ̀n bí àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ tí wọ́n di rìkíṣí mọ́ láti fi sẹ́wọ̀n ti wá di òmìnira padà, tí ìjọba sì tún dá wọn láre ní kíkún lẹ́yìn náà. Kò sí àní-àní pé jìnnìjìnnì tó bò wọ́n ti ní láti ga sí i ní September ọdún 1919, nígbà táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe àpéjọ kan ní Cedar Point, Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Níbi àpéjọ yìí ni J. F. Rutherford tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tú sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ti ru àwọn tó pé jọ sókè pẹ̀lú àsọyé kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Kíkéde Ìjọba Náà,” èyí tá a gbé ka Ìṣípayá 15:2 àti Aísáyà 52:7. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ti ẹgbẹ́ Jòhánù tún bẹ̀rẹ̀ sí í “sọ tẹ́lẹ̀,” ìyẹn ni pé wọ́n ń wàásù fáwọn èèyàn. Wọ́n ń ní okun síwájú àti síwájú sí i, wọ́n sì ń tú àgàbàgebè àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fó láìbẹ̀rù.

25. (a) Ìgbà wo ni Jèhófà sọ fáwọn ẹlẹ́rìí méjì náà pé, “Ẹ máa bọ̀ lókè níhìn-ín,” báwo lèyí sì ṣe ṣẹlẹ̀? (b) Báwo ni mímú tí Ọlọ́run mú àwọn Ẹlẹ́rìí náà bọ̀ sípò ṣe kó jìnnìjìnnì bá ìlú títóbi náà?

25 Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tún gbìyànjú léraléra láti tún ní irú ìṣẹ́gun tí wọ́n ní lọ́dún 1918. Wọ́n lo àwọn èèyànkéèyàn láti gbéjà ko àwọn Kristẹni tòótọ́, wọ́n fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n lo òfin, wọ́n lo ìfinisẹ́wọ̀n, àní ìfikúpani pàápàá, síbẹ̀ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí! Lẹ́yìn ọdún 1919, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò ríbi kojú bọ ọ̀ràn ìjọsìn àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà mọ́. Lọ́dún yẹn, Jèhófà wí fún wọ́n pé: “Ẹ máa bọ̀ lókè níhìn-ín,” wọ́n sì ti gòkè lọ sí ipò kan nínú ọ̀ràn ìjọsìn wọn tó ga ju ibi tọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn ti lè tó wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè máa wò wọ́n níbẹ̀. Jòhánù sọ bí ìmúbọ̀sípò wọn ṣe kó jìnnìjìnnì bá ìlú títóbi náà, ó ní: “Ní wákàtí yẹn, ìsẹ̀lẹ̀ ńlá sì sẹ̀, ìdá mẹ́wàá ìlú ńlá náà sì ṣubú; ìsẹ̀lẹ̀ náà sì pa ẹgbẹ̀rún méje ènìyàn, jìnnìjìnnì sì bo àwọn yòókù, wọ́n sì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run.” (Ìṣípayá 11:13) Ká sòótọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mi ìsìn jìgìjìgì gan-an ni. Ńṣe ló dà bíi pé ilẹ̀ yẹ̀ mọ́ àwọn aṣáájú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì jàǹkàn-jàǹkàn lẹ́sẹ̀ bí ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run mú sọ jí yìí ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Ìdá mẹ́wàá ìlú wọn, ìyẹn ẹgbẹ̀rún méje [7,000] èèyàn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ni ọ̀ràn náà kàn débi tí ẹsẹ yìí fi sọ nípa wọn pé a pa wọ́n.

26. Àwọn wo ni “ìdá mẹ́wàá ìlú náà” àti “ẹgbẹ̀rún méje [7,000]” inú Ìṣípayá 11:13 dúró fún? Ṣàlàyé.

26 Gbólóhùn náà, “ìdá mẹ́wàá ìlú ńlá náà,” rán wa létí pé Aísáyà sàsọtẹ́lẹ̀ nípa Jerúsálẹ́mù ìgbàanì pé ìdá mẹ́wàá yóò la ìparun ìlú náà já gẹ́gẹ́ bí irú-ọmọ mímọ́ kan. (Aísáyà 6:13) Bákan náà, iye náà, ẹgbẹ̀rún méje [7,000], rán wa létí pé nígbà tí Èlíjà rò pé òun nìkan ṣoṣo ni olùṣòtítọ́ tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì, Jèhófà sọ fún un pé, àwọn ẹgbẹ̀rún méje [7,000] èèyàn míì ṣì wà tí kò forí balẹ̀ fún Báálì. (1 Àwọn Ọba 19:14, 18) Ní ọ̀rúndún kìíní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn ẹgbẹ̀rún méje [7,000] èèyàn yìí dúró fún àṣẹ́kù àwọn Júù tí wọ́n ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Kristi. (Róòmù 11:1-5) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ràn wá lọ́wọ́ láti lóye pé “ẹgbẹ̀rún méje” àti “ìdá mẹ́wàá ìlú ńlá” náà tá a kà nínú Ìṣípayá 11:13 jẹ́ àwọn tí wọ́n ṣègbọràn sóhun táwọn ẹlẹ́rìí méjì tá a mú bọ̀ sípò wọ̀nyẹn ń sọ, wọ́n sì pa ìlú títóbi ẹlẹ́ṣẹ̀ náà tì. Lójú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, àwọn wọ̀nyí ti kú. Ni wọ́n bá yọ orúkọ wọn kúrò lára orúkọ àwọn ọmọ ìjọ wọn. Lójú wọn, wọn ò sí mọ́. d

27, 28. (a) Báwo ni ‘àwọn ìyókù ṣe fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run’? (b) Kí ni àwùjọ àlùfáà gbà ní tipátipá?

27 Ṣùgbọ́n ọ̀nà wo wá ni ‘ìyókù [àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì] gbà fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run’? Dájúdájú kì í ṣe nípa pípa ìsìn apẹ̀yìndà wọn tì, tí wọ́n sì di ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ lọ́nà tí ìwé Word Studies in the New Testament, ti Vincent, gbà ṣàlàyé rẹ̀ nígbà tó ń jíròrò ọ̀rọ̀ náà “fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run.” Níbẹ̀, ó sọ pé: “Gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà kò túmọ̀ sí ìyílọ́kànpadà, tàbí ìrònúpìwàdà, tàbí ìdúpẹ́, bí kò ṣe ìjẹ́wọ́, tó jẹ́ ohun tó sábà máa ń túmọ̀ sí nínú Ìwé Mímọ́. Fi wé Jóṣ. vii. 19 (Sept.). Jòh. ix. 24; Ìṣe xii. 23; Róòmù iv. 20.” Ohun ìbànújẹ́ ló jẹ́ fáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, síbẹ̀, wọ́n ní láti gbà pé Ọlọ́run àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà ti ṣe ohun ribiribi ní ti pé ó mú wọn padà sẹ́nu ìgbòkègbodò Kristẹni.

28 Ó lè jẹ́ pé ẹgbẹ́ àlùfáà yìí kàn gbà lọ́kàn ara wọn ni, tàbí kó jẹ́ pé wọ́n wulẹ̀ rò pé bó ṣe yẹ kó jẹ́ nìyẹn. Ohun tó ṣáà dájú ni pé kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé wọ́n sọ ní gbangba pé àwọ́n fara mọ́ Ọlọ́run àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà. Ṣùgbọ́n àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà nípasẹ̀ Jòhánù ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, ó sì jẹ́ ká mọ ìjákulẹ̀ tó mú ìtìjú bá wọn èyí tí wọ́n rí lọ́dún 1919. Láti ọdún yẹn lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣọ́ọ̀ṣì ń sapá torí tọrùn láti wonkoko mọ́ àwọn àgùntàn rẹ̀, àwùjọ àlùfáà rí i bí “ẹgbẹ̀rún méje [7,000]” ṣe ń fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀, wọ́n sì gbà tipátipá pé Ọlọ́run ẹgbẹ́ Jòhánù lágbára ju ọlọ́run àwọn lọ. Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, wọn rí èyí lọ́nà tó túbọ̀ ṣe kedere, bí ọ̀pọ̀ nínú agbo wọn ti túbọ̀ ń jáde kúrò, tí wọ́n sì ń sọ ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn sọ nígbà tí Èlíjà borí àwọn onísìn Báálì ní Òkè Kámélì pé: “Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́! Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́!”—1 Àwọn Ọba 18:39.

29. Kí ni Jòhánù sọ pé ó ń bọ̀ ní kíákíá, mímì wo ló ṣì ń dúró de àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì?

29 Ṣùgbọ́n fetí sílẹ̀! Jòhánù sọ fún wa pé: “Ègbé kejì ti kọjá. Wò ó! Ègbé kẹta ń bọ̀ kíákíá.” (Ìṣípayá 11:14) Bí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn yìí bá mi ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì jìgìjìgì, kí ni wọn yóò wá ṣe o nígbà tá a bá kéde ègbé kẹta, èyí tí áńgẹ́lì keje fun kàkàkí rẹ̀, tí àṣírí mímọ́ ti Ọlọ́run sì wá dópin níkẹyìn?—Ìṣípayá 10:7.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìjíròrò kíkún nípa tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí yìí, wo àpilẹ̀kọ náà “Tẹ́ḿpìlì Ńlá Jèhófà Nípa Tẹ̀mí” nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 1996, àti “Tempili Otitọ Kanṣoṣo na nínú Eyiti Ao Ti Jọsin” nínú Ile-Iṣọ Na ti August 15, 1973.

b “Ọ̀gbun àìnísàlẹ̀” (Gíríìkì, aʹbys·sos; Hébérù, tehohmʹ) lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, túmọ̀ sí ibi àìlèṣiṣẹ́mọ́. (Wo Ìṣípayá 9:2.) Àmọ́ ṣá o, ní ìtumọ̀ ṣangiliti, ó tún lè tọ́ka sí alagbalúgbú òkun. Wọ́n sábà máa ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù yìí sí “ibú omi.” (Sáàmù 71:20; 106:9; Jónà 2:5) Nípa báyìí, a lè sọ pé “ẹranko ẹhànnà tó gòkè wá látinú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀” jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú “ẹranko ẹhànnà kan tó ń gòkè bọ̀ láti inú òkun.”—Ìṣípayá 11:7; 13:1.

c Ṣàkíyèsí pé bá a ti ń ṣàyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn Ọlọ́run lákòókò yìí, ó jọ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé oṣù méjìlélógójì [42] náà dúró fún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ ní ti gidi, ọjọ́ mẹ́ta àtààbọ̀ kò túmọ̀ sí ọjọ́ mẹ́ta àtààbọ̀ gidi tó jẹ́ wákàtí mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84]. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí tí wọ́n fi mẹ́nu kan ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ lẹ́ẹ̀mejì (ní ẹsẹ 9 àti 11) jẹ́ láti fi hàn gbangba pé sáà kúkúrú kan ni yóò jẹ́ tá a bá fi wé ìgbòkègbodò ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó ṣáájú rẹ̀.

d Fi èyí wé ọ̀nà tá a gbà lo àwọn ọ̀rọ̀ náà “òkú,” “kú,” àti “wà láàyè” nínú irú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Róòmù 6:2, 10, 11; 7:4, 6, 9; Gálátíà 2:19; Kólósè 2:20; 3:3.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 168]

Ayọ̀ Yíyọ̀ Inú Ìṣípayá 11:10

Nínú ìwé tí ọ̀gbẹ́ni Ray H. Abrams tẹ̀ jáde lọ́dún 1933 tó pè ní Preachers Present Arms, ó sọ nípa bí ẹgbẹ́ àlùfáà ṣe ta ko ìwé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà gidigidi, ìyẹn ìwé The Finished Mystery. Ó tún kọ ọ̀rọ̀ lórí ìsapá àwùjọ àlùfáà láti rẹ́yìn àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, àtohun táwọn àlùfáà yìí kà sí ìyíniléròpadà wọn tó ń múnú bíni. Èyí ló yọrí sí ẹjọ́ kóòtù tó mú kí ìjọba dá ẹ̀wọ̀n ọlọ́dún gbọọrọ fún J. F. Rutherford àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ méje. Dókítà Abrams fi kún un pé: “Àgbéyẹ̀wò ẹjọ́ náà látòkèdélẹ̀ múni gbà pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àti àwùjọ àlùfáà ló wà lẹ́yìn ìsapá náà láti pa àwọn tó ń tẹ̀ lé Russell rẹ́. Lórílẹ̀-èdè Kánádà, ní February, 1918, àwọn òjíṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ ìkéde kan tí kò dáwọ́ dúró láti fi ta ko àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìwé wọn, ní pàtàkì ìwé The Finished Mystery. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Tribune ti ìlú Winnipeg ti wí, . . . àwọn kan gbà pé àtọ̀dọ̀ ‘àwọn aṣojú àwùjọ àlùfáà’ ni títẹ ìwé wọn rì ti wá ní tààràtà.’”

Dókítà Abrams ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Nígbà tí ìròyìn pé wọ́n ti dájọ́ ẹ̀wọ̀n ogún ọdún fún wọn dé etígbọ̀ọ́ àwọn olóòtú ìwé ìròyìn ìsìn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé nínú gbogbo àwọn ìtẹ̀jáde wọn, àti kékeré àti ńlá, ni wọ́n ti yọ̀ nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí. Kò tíì ṣeé ṣe fún mi láti rí ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn èyíkéyìí nínú àwọn ìwé ìròyìn ìsìn tó gbajúmọ̀. Ọ̀gbẹ́ni Upton Sinclair ní tiẹ̀ wá sọ pé: ‘Kò sí iyè méjì kankan pé ohun tó fa inúnibíni náà lápá kan . . . ni pé àwọn ẹgbẹ́ ìsìn “gbígbajúmọ̀” kórìíra wọn.’ Ohun tí ìsapá àwọn ṣọ́ọ̀ṣì lápapọ̀ kò lè ṣe ló wá dà bíi pé ìjọba ti kẹ́sẹ járí nísinsìnyí láti bá wọn ṣe.” Lẹ́yìn tẹ́ni tó kọ̀wé yìí fa àwọn ọ̀rọ̀ àbùkù yọ látinú díẹ̀ lára àwọn ìtẹ̀jáde ìsìn kan, ó wá sọ̀rọ̀ lórí yíyí tí Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn yí ìdájọ́ náà pa dà, ó ní: “Ńṣe làwọn ṣọ́ọ̀ṣì dákẹ́ fẹ́mú nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa ìdájọ́ yìí.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 163]

Jòhánù díwọ̀n tẹ́ńpìlì tẹ̀mí—àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ àlùfáà gbọ́dọ̀ mú ara wọn bá àwọn ìlànà mu

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 165]

Iṣẹ́ àtúnkọ́ tí Serubábélì àti Jóṣúà ṣe fi hàn pé ní ọjọ́ Olúwa, ìbísí ńláǹlà yóò tẹ̀ lé àwọn ìbẹ̀rẹ̀ kékeré láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ilé, bí irú àwọn tá a fi hàn lókè yìí, tí wọ́n wà ní Brooklyn, New York, ló ti di dandan pé ká mú gbòòrò sí i lọ́nà tó ga lọ́lá ká lè pèsè àwọn ohun tẹ̀mí táwọn tó ń di Ẹlẹ́rìí nílò

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 166]

Iṣẹ́ alásọtẹ́lẹ̀ tí Mósè àti Èlíjà ṣe ṣàpẹẹrẹ àwọn ìdájọ́ mímúná táwọn ẹlẹ́rìí méjì náà kéde rẹ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 169]

Bíi tàwọn egungun gbígbẹ inú Ìsíkíẹ́lì orí 37, a mú àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà sọ jí kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù ti òde òní