Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Rí Ìtumọ̀ Àṣírí Ọlọ́wọ̀ Kan

A Rí Ìtumọ̀ Àṣírí Ọlọ́wọ̀ Kan

Orí 6

A Rí Ìtumọ̀ Àṣírí Ọlọ́wọ̀ Kan

1. Kí ló yẹ kí ìran ológo tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà nínú Ìṣípayá 1:10-17 sún wa ṣe?

 DÁJÚDÁJÚ, ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ni ìran tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nípa Jésù tí Ọlọ́run ti gbé ga! Ká ní àwa àti Jòhánù la jọ rí ìran náà ni, ó dájú pé ògo tó ń kọ mànà yẹn ì bá ti da jìnnìjìnnì bo àwa náà, à bá sì ti dọ̀bálẹ̀ bíi tiẹ̀. (Ìṣípayá 1:10-17) A pa ìran onímìísí tó dára gan-an yìí mọ́ kó lè sún wa ṣe ohun tó yẹ lónìí. Bíi ti Jòhánù, ó yẹ ká fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ mọrírì gbogbo ohun tí ìran náà túmọ̀ sí. Ẹ jẹ́ ká máa fi ìgbà gbogbo ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ipò Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Ọlọ́run ti gbé gorí ìtẹ́, Àlùfáà Àgbà, àti Onídàájọ́.—Fílípì 2:5-11.

“Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn”

2. (a) Orúkọ oyè wo ni Jésù pe ara rẹ̀? (b) Kí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ, pé “Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ èmi sì ni ẹni ìkẹyìn” túmọ̀ sí? (d) Kí ni orúkọ oyè Jésù náà “Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn” pe àfiyèsí sí?

2 Àmọ́ ṣá o, kò yẹ kí ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tá a ní fa ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì fún wa. Jésù fi àpọ́sítélì Jòhánù lọ́kàn balẹ̀, ìyẹn sì lohun tí Jòhánù sọ tẹ̀ lé e. Ó ní: “Ó sì gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó sì wí pé: ‘Má bẹ̀rù. Èmi ni Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn, àti alààyè.’” (Ìṣípayá 1:17b, 18a) Nínú Aísáyà 44:6, Jèhófà fi ẹ̀tọ́ sọ ipò tóun wà, ó ní òun nìkan ni Ọlọ́run Olódùmarè. Bó ṣe sọ ọ́ rèé: “Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn, yàtọ̀ sí mi, kò sí Ọlọ́run kankan.” a Nígbà tí Jésù lo orúkọ oyè náà “Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn” fún ara rẹ̀, kò sọ pé òun bá Jèhófà tó jẹ́ Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá dọ́gba. Ọlọ́run ló fi orúkọ oyè tó lò yìí jíǹkí rẹ̀ lọ́nà ẹ̀tọ́. Nínú ìwé Aísáyà yẹn, Jèhófà sọ pé ipò Òun ò lẹ́gbẹ́, pé Òun ni Ọlọ́run tòótọ́ náà. Òun ni Ọlọ́run ayérayé, àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí òun. (1 Tímótì 1:17) Nínú ìwé Ìṣípayá, nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa orúkọ oyè tí Ọlọ́run fi jíǹkí rẹ̀, àjíǹde rẹ̀ tó jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ ló ń pe àfiyèsí sí.

3. (a) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn”? (b) Kí ni níní tí Jésù ní “kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Hédíìsì” túmọ̀ sí?

3 Lóòótọ́, Jésù ni “Ẹni Àkọ́kọ́” nínú àwọn tó jíǹde sí ìwàláàyè àìleèkú ti ẹ̀mí. (Kólósè 1:18) Yàtọ̀ síyẹn òun ni “Ẹni Ìkẹyìn” tí Jèhófà fọwọ́ ara rẹ̀ jí dìde. Nípa bẹ́ẹ̀, ó di “alààyè . . . [tó] wà láàyè títí láé àti láéláé.” Ó jẹ́ ẹ̀dá aláìleèkú. Ó fèyí jọ Baba rẹ̀ aláìleèkú, tá à ń pè ní “Ọlọ́run alààyè.” (Ìṣípayá 7:2; Sáàmù 42:2) Jésù ni “àjíǹde àti ìyè” fún gbogbo ẹ̀dá èèyàn yòókù. (Jòhánù 11:25) Níbàámu pẹ̀lú èyí, ó sọ fún Jòhánù pé: “Mo sì ti di òkú tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n, wò ó! mo wà láàyè títí láé àti láéláé, mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Hédíìsì lọ́wọ́.” (Ìṣípayá 1:18b) Jèhófà ti fún Jésù láṣẹ láti jí àwọn òkú dìde. Ìdí nìyẹn tó fi lè sọ pé òun ní kọ́kọ́rọ́ láti ṣí ibodè fún àwọn tí ikú àti Hédíìsì (ìyẹn ipò òkú) gbé dè.—Fi wé Mátíù 16:18.

4. Àṣẹ wo ni Jésù ṣe àtúnsọ rẹ̀, fún àǹfààní àwọn wo sì ni?

4 Jésù tún pàṣẹ lẹ́ẹ̀kan sí i pé kí Jòhánù ṣe àkọsílẹ̀ ìran náà, ó ní: “Nítorí náà, kọ àwọn ohun tí ìwọ rí sílẹ̀, àti àwọn ohun tí ó wà àti àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìwọ̀nyí.” (Ìṣípayá 1:19) Àwọn ohun amárayágágá wo ni Jòhánù ṣì máa sọ di mímọ̀ ká lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú rẹ̀?

Ìràwọ̀ àti Ọ̀pá Fìtílà

5. Báwo ni Jésù ṣe ṣàlàyé ohun tí “ìràwọ̀ méje” àti “ọ̀pá fìtílà méje” náà jẹ́?

5 Jòhánù ti rí Jésù láàárín ọ̀pá fìtílà méje tí wọ́n fi wúrà ṣe tí ìràwọ̀ méje sì wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. (Ìṣípayá 1:12, 13, 16) Jésù ṣàlàyé ohun tí èyí jẹ́, ó ní: “Ní ti àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìràwọ̀ méje tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ti ọ̀pá fìtílà méje oníwúrà náà: Ìràwọ̀ méje náà túmọ̀ sí àwọn áńgẹ́lì ìjọ méje, ọ̀pá fìtílà méje náà sì túmọ̀ sí ìjọ méje.”—Ìṣípayá 1:20.

6. Kí ni ìràwọ̀ méje náà dúró fún, kí sì nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn ní pàtó ni Jésù fiṣẹ́ ránni sí?

6 Àwọn “ìràwọ̀” náà ni “àwọn áńgẹ́lì ìjọ méje.” Nínú Ìṣípayá, ìràwọ̀ máa ń ṣàpẹẹrẹ àwọn áńgẹ́lì gidi nígbà míì, ṣùgbọ́n kò jọ bí ẹni pé Jésù yóò lo akọ̀wé tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn láti kọ̀wé sí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tá ò lè fojú rí. Nítorí náà àwọn “ìràwọ̀” náà ní láti jẹ́ àwọn èèyàn tó jẹ́ alábòójútó, tàbí àwọn alàgbà ìjọ, tá à ń wò gẹ́gẹ́ bí ońṣẹ́ Jésù. b Àwọn ìràwọ̀ náà ni Jésù fiṣẹ́ ránni sí, nítorí àwọn ni ẹrù iṣẹ́ bíbójútó agbo Jèhófà já lé léjìká.—Ìṣe 20:28.

7. (a) Kí ló fi hàn pé bí Jésù ṣe bá áńgẹ́lì kan ṣoṣo péré nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan sọ̀rọ̀ kò túmọ̀ sí pé kìkì alàgbà kan ṣoṣo ni ìjọ kọ̀ọ̀kan ní? (b) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn wo ni ìràwọ̀ méje tó wà lọ́wọ́ ọ̀tún Jésù dúró fún?

7 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “áńgẹ́lì” kan ṣoṣo ni Jésù bá sọ̀rọ̀ nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan, ṣé ìyẹn túmọ̀ sí pé alàgbà kan ṣoṣo ni ìjọ kọ̀ọ̀kan ní? Ó tì o. Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn nígbà ayé Pọ́ọ̀lù, alàgbà kan ṣoṣo kọ́ ni ìjọ Éfésù ní. (Ìṣípayá 2:1; Ìṣe 20:17) Nítorí náà, nígbà tí Jésù fiṣẹ́ ránni sí ìràwọ̀ méje pé kí wọ́n kà á fún àwọn ìjọ nígbà ayé Jòhánù (tó fi mọ́ ìjọ tó wà ní Éfésù), àwọn ìràwọ̀ náà ní láti dúró fún gbogbo àwọn tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà nínú ìjọ àwọn ẹni àmì òróró Jèhófà. Bíi tìgbà yẹn, àwọn alábòójútó lónìí máa ń ka lẹ́tà tí wọ́n ń rí gbà látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí fún ìjọ, àwọn alábòójútó kan tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró tí wọ́n ń sìn lábẹ́ ipò orí Kristi ló sì para pọ̀ di Ìgbìmọ̀ Olùdarí yìí. Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà nínú ìjọ ní láti rí i dájú pé ìjọ tí wọ́n wà ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù. Àmọ́ ṣá o, ìmọ̀ràn náà wà fún àǹfààní gbogbo àwọn tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ, kì í ṣe fún àǹfààní àwọn alàgbà nìkan.—Wo Ìṣípayá 2:11a.

8. Kí ni wíwà tí àwọn alàgbà náà wà ní ọwọ́ ọ̀tún Jésù fi hàn?

8 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jésù ni Orí ìjọ, Jésù sọ lọ́nà tó tọ́ pé àwọn alàgbà náà wà ní ọwọ́ ọ̀tún òun, ìyẹn ni pé, wọ́n wà lábẹ́ àkóso àti ìdarí òun. (Kólósè 1:18) Jésù ni Olórí Olùṣọ́ Àgùntàn, àwọn alàgbà sì jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tó ń sìn lábẹ́ rẹ̀.—1 Pétérù 5:2-4.

9. (a) Àwọn nǹkan wo ni ọ̀pá fìtílà méje náà dúró fún, kí sì nìdí tó fi jẹ́ pé ọ̀pá fìtílà ni ohun ìṣàpẹẹrẹ tó bá àwọn nǹkan náà mu? (b) Kí ló ṣeé ṣe kí ìran náà rán àpọ́sítélì Jòhánù létí rẹ̀?

9 Ọ̀pá fìtílà méje náà ni ìjọ méje tí Jòhánù kọ ìwé Ìṣípayá sí, ìyẹn: Ìjọ Éfésù, Símínà, Págámù, Tíátírà, Sádísì, Filadéfíà, àti Laodíkíà. Kí nìdí tí Jésù fi fi ọ̀pá fìtílà ṣàpẹẹrẹ ìjọ? Ìdí ni pé àwọn Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tàbí lápapọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, ní láti ‘jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọ́n máa tàn níwájú àwọn ènìyàn’ nínú ayé tó ti ṣókùnkùn biribiri yìí. (Mátíù 5:14-16) Láfikún, ọ̀pá fìtílà wà lára àwọn ohun èlò inú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì. Ó ṣeé ṣe kí pípè tí Jésù pe àwọn ìjọ náà ní ọ̀pá fìtílà rán Jòhánù létí pé, lọ́nà àpèjúwe, ìjọ kọ̀ọ̀kan ti àwọn ẹni àmì òróró jẹ́ “tẹ́ńpìlì Ọlọ́run,” ìyẹn ibùgbé ẹ̀mí Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 3:16) Yàtọ̀ síyẹn, nínú ètò tí tẹ́ńpìlì àwọn Júù ṣàpẹẹrẹ, àwọn tó jẹ́ ara ìjọ àwọn ẹni àmì òróró ń sìn gẹ́gẹ́ bí “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé” nínú ètò tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí Jèhófà. Jésù ni Àlùfáà Àgbà nínú ètò tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí yìí, ibẹ̀ sì ni Jèhófà ń gbé nínú ibi Mímọ́ Jù Lọ ní ọ̀run.—1 Pétérù 2:4, 5, 9; Hébérù 3:1; 6:20; 9:9-14, 24.

Ìpẹ̀yìndà Ńlá Náà

10. Lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, kí ló ṣẹlẹ̀ sí ètò àwọn nǹkan Júù àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ tí kò ronú pìwà dà?

10 Nígbà tí Jòhánù kọ Ìṣípayá, ó ti lé ní ọgọ́ta [60] ọdún tí ìsìn Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀. Látìgbà tí ìsìn Kristẹni sì ti bẹ̀rẹ̀ làwọn onísìn Júù ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtakò sí i, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ogójì ọdún, àmọ́ ó là á já. Lẹ́yìn náà, ètò àwọn nǹkan Júù fara gba ọgbẹ́ ikú lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni nígbà tí àwọn Júù aláìronúpìwàdà pàdánù àǹfààní mímọ̀ tá a mọ̀ wọ́n sí orílẹ̀-èdè tí wọ́n sì tún pàdánù tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, èyí tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ sọ di òrìṣà.

11. Kí nìdí tó fi jẹ́ àkókò tó bá a mu gẹ́ẹ́ pé kí Olórí Olùṣọ́ Àgùntàn kìlọ̀ fún àwọn ìjọ nípa àwọn ohun búburú tó ń jẹ yọ?

11 Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìpẹ̀yìndà kan yóò wà láàárín àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, iṣẹ́ tí Jésù fi rán Jòhánù sì fi hàn pé ìpẹ̀yìndà yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ yọ nígbà ọjọ́ ogbó Jòhánù. Jòhánù lẹni tó gbẹ̀yìn nínú àwọn tó ṣèdíwọ́ fún ìyànjú tí Sátánì ń fi gbogbo agbára rẹ̀ gbà láti sọ irú-ọmọ obìnrin náà dìbàjẹ́. (2 Tẹsalóníkà 2:3-12; 2 Pétérù 2:1-3; 2 Jòhánù 7-11) Nítorí náà, ó jẹ́ àkókò tó bá a mu pé kí Olórí Olùṣọ́ Àgùntàn Jèhófà kọ̀wé sáwọn alàgbà ìjọ láti kìlọ̀ nípa àwọn ohun búburú tó ti ń jẹ yọ kó sì fún àwọn tó ní ọkàn rere níṣìírí pé kí wọ́n dúró gbọn-in nínú òdodo.

12. (a) Báwo ni ìpẹ̀yìndà náà ṣe tàn kálẹ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà ayé Jòhánù? (b) Báwo ni ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe bẹ̀rẹ̀?

12 A ò mọ ohun tí àwọn ìjọ ní ọdún 96 Sànmánì Kristẹni ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ iṣẹ́ tí Jésù ránni sí wọn. Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé kíákíá ni ìpẹ̀yìndà náà tàn kálẹ̀ lẹ́yìn ikú Jòhánù. Àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ ṣíwọ́ lílo orúkọ Jèhófà wọ́n sì fi “Olúwa” tàbí “Ọlọ́run” rọ́pò rẹ̀ nínú àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹrin, ẹ̀kọ́ èké Mẹ́talọ́kan ti yọ́ wọnú àwọn ìjọ. Láàárín àkókò yẹn kan náà, wọ́n mú ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn wọnú ìjọ. Níkẹyìn, Ọba Kọnsitatáìnì ti Róòmù sọ ìsìn Kristẹni aláfẹnujẹ́ náà di ìsìn tí ìjọba fọwọ́ sí, bí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sì ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, níbi tí Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba ti pa agbára wọn pọ̀ láti ṣàkóso fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Lákòókò yẹn, ó rọrùn láti di “Kristẹni” alárà tuntun. Àwọn ẹ̀yà kan lódindi ṣe àtúnṣe sí ìgbàgbọ́ Kèfèrí tí wọ́n ní kó lè bá ìsìn Kristẹni aláfẹnujẹ́ náà mu. Ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì ló di òṣìkà òṣèlú tí ń nini lára, tí wọ́n ń lo idà láti fipá mú àwọn èèyàn tẹ́wọ́ gba ìgbàgbọ́ apẹ̀yìndà wọn.

13. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kìlọ̀ pé kéèyàn yẹra fún ẹ̀ya ìsìn, síbẹ̀, kí làwọn Kristẹni apẹ̀yìndà ṣe?

13 Àwọn Kristẹni apẹ̀yìndà náà kò ka àwọn ohun tí Jésù sọ fún ìjọ méje náà sí rárá. Jésù kìlọ̀ fáwọn ará Éfésù pé kí wọ́n padà ní ìfẹ́ tí wọ́n ní lákọ̀ọ́kọ́. (Ìṣípayá 2:4) Síbẹ̀, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ja àwọn ogun rírorò wọ́n sì ṣe inúnibíni sí ara wọn lọ́nà ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ nítorí pé ìfẹ́ fún Jèhófà kọ́ ló so wọ́n pọ̀. (1 Jòhánù 4:20) Jésù kìlọ̀ fún ìjọ tó wà ní Págámù pé kí wọ́n yẹra fún ẹ̀ya ìsìn. Síbẹ̀, kíákíá ni ẹ̀ya ìsìn fara hàn ní ọ̀rúndún kejì. Lónìí sì rèé, ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì pín sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìsìn àti ẹ̀ya ìsìn tí ìmọ̀ wọn ò ṣọ̀kan.—Ìṣípayá 2:15.

14. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kìlọ̀ lòdì sí jíjẹ́ òkú nípa tẹ̀mí, síbẹ̀ kí làwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ ṣe? (b) Àwọn ọ̀nà wo làwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ gbà kùnà láti fiyè sí ìkìlọ̀ Jésù nípa ìbọ̀rìṣà àti ìṣekúṣe?

14 Jésù kìlọ̀ fún ìjọ tó wà ní Sádísì lòdì sí dídi òkú nípa tẹ̀mí. (Ìṣípayá 3:1) Bíi tàwọn tó wà ní Sádísì, kíákíá làwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ gbàgbé nípa iṣẹ́ Kristẹni, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi yan iṣẹ́ ìwàásù tó ṣe pàtàkì gan-an fún kìkì ẹgbẹ́ àlùfáà táṣẹ́rẹ́ tí wọ́n ń sanwó fún. Jésù kìlọ̀ fún ìjọ tó wà ní Tíátírà pé kí wọ́n yẹra fún ìbọ̀rìṣà àti àgbèrè. (Ìṣípayá 2:20) Síbẹ̀, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń fọwọ́ sí lílò ère wọ́n sì ń ṣe agbátẹrù ìbọ̀rìṣà ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, ìyẹn, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni àti ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì. Kò sì tíì sígbà kan tí wọn ò fàyè gba ìṣekúṣe bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń wàásù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé kò dáa.

15. Àṣírí wo nípa àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni àwọn ohun tí Jésù sọ fún ìjọ méje náà tú, kí sì ni àwọn ẹgbẹ́ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ti fẹ̀rí hàn pé àwọn jẹ́?

15 Nítorí náà, àwọn ohun tí Jésù sọ fún ìjọ méje náà tú àṣírí gbogbo àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì pé wọ́n ti kùnà pátápátá láti jẹ́ àkànṣe èèyàn Jèhófà. Ká sòótọ́ àwọn ẹgbẹ́ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ló yọrí ọlá jù lọ nínú irú-ọmọ Sátánì. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ‘ẹni aláìlófin náà,’ ó sọ tẹ́lẹ̀ pé “wíwà níhìn-ín [wọn] jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́ Sátánì pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ agbára àti àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn àmì àgbàyanu irọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀tàn àìṣòdodo.”—2 Tẹsalóníkà 2:9, 10.

16. (a) Àwọn wo ni àwọn aṣáájú ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì ní ìkórìíra ńlá fún? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ nínú ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ní Ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbà Ọ̀làjú? (d) Ǹjẹ́ àtakò àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tàbí àtúnṣe wọn yí ìpẹ̀yìndà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì padà?

16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣáájú ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì sọ pé àwọn jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run, wọ́n ní ìkórìíra ńlá fún ẹnikẹ́ni tó bá gbìyànjú láti fún àwọn ẹlòmíì níṣìírí láti ka Bíbélì tàbí ẹnikẹ́ni tó bá túdìí àṣírí àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. John Hus àti William Tyndale tó jẹ́ olùtumọ̀ Bíbélì ni wọ́n ṣenúnibíni sí tí wọ́n sì pa. Ní Ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbà Ọ̀làjú, ìṣàkóso àwọn Kristẹni apẹ̀yìndà bá a débi pé ìjọ Kátólíìkì gbé ilé ẹjọ́ kan kalẹ̀ tó ń fi ìwà ìkà ṣèwádìí àwọn tó bá sọ tàbí tó ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì. Ẹnikẹ́ni tó bá ta ko ẹ̀kọ́ tàbí àṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n fìyà jẹ láìsí ojú àánú, àìlóǹkà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí wọ́n pè ní olùyapa ni wọ́n sì dá lóró títí tí wọ́n fi kú tàbí tí wọ́n dáná sun lórí òpó igi. Báyìí ni Sátánì ṣe gbìyànjú láti rí i dájú pé òun tètè gbẹ̀mí ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ ojúlówó irú-ọmọ ètò Ọlọ́run tó dà bí obìnrin. Nígbà táwọn Pùròtẹ́sítáǹtì ta ko ẹ̀kọ́ Kátólíìkì, ìyẹn ni pé, nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣàtúnṣe sí àwọn ẹ̀kọ́ Kátólíìkì (láti ọdún 1517 síwájú), ọ̀pọ̀ lára àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì fi irú ẹ̀mí yìí kan náà hàn, wọ́n fi hàn pé àwọn ò lè fàyè gba ohun táwọn ò fẹ́. Àwọn náà jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ nípa fífi ikú pa àwọn tí wọ́n gbìyànjú láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run àti Kristi. Ní tòdodo, wọ́n tú “ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́” jáde yàlàyàlà!—Ìṣípayá 16:6; fi wé Mátíù 23:33-36.

Irú-Ọmọ Náà Wà Pẹ́ Títí

17. (a) Kí ni àkàwé Jésù nípa àlìkámà àti èpò sọ tẹ́lẹ̀? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ ní 1918, ìkọ̀sílẹ̀ wo ló yọrí sí, ìyannisípò wo ló sì wáyé?

17 Nínú àkàwé Jésù nípa àlìkámà àti èpò, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìgbà òkùnkùn kan tó máa wà nígbà tí ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì bá ń ṣe bó ṣe wù ú. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, jálẹ̀ gbogbo ọ̀rúndún ìpẹ̀yìndà, àwọn Kristẹni kọ̀ọ̀kan wà tí wọ́n dà bí àlìkámà, ìyẹn àwọn ojúlówó ẹni àmì òróró. (Mátíù 13:24-29, 36-43) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀ ní oṣù October ọdún 1914. (Ìṣípayá 1:10) Ó jọ pé Jèhófà wá sínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ tẹ̀mí fún ìdájọ́ ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ lẹ́yìn náà, ìyẹn ní 1918, Jésù “ońṣẹ́ májẹ̀mú” rẹ̀ sì bá a wá. (Málákì 3:1; Mátíù 13:47-50) Ìgbà yẹn jẹ́ àkókò fún Ọ̀gá náà láti kọ àwọn èké Kristẹni sílẹ̀ pátápátá kó sì yan ‘ẹrú olóòótọ́ àti olóye sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.’—Mátíù 7:22, 23; 24:45-47.

18. “Wákàtí” wo ló dé ní 1914, kí sì ni ìgbà yẹn jẹ́ àkókò fún ẹrú náà láti ṣe?

18 Ìgbà yẹn tún jẹ́ àkókò fún ẹrú yìí láti kíyè sí ohun tó wà nínú iṣẹ́ tí Jésù ránni sí ìjọ méje, bá a ṣe rí i nínú àkọsílẹ̀ tó wà nínú iṣẹ́ náà. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ nípa bí òun ṣe máa wá láti ṣèdájọ́ àwọn ìjọ, ọdún 1918 sì ni ìdájọ́ náà bẹ̀rẹ̀. (Ìṣípayá 2:5, 16, 22, 23; 3:3) Bákan náà, Jésù sọ̀rọ̀ nípa bí òun yóò ṣe dáàbò bo ìjọ Filadéfíà kúrò nínú “wákàtí ìdánwò, èyí tí yóò dé bá gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Ìṣípayá 3:10, 11) Ẹ̀yìn tí ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀ ní 1914 ni “wákàtí ìdánwò” yìí tóó dé, ẹ̀yìn ìgbà náà sì làwọn Kristẹni rí ìdánwò kó lè hàn bóyá Ìjọba Ọlọ́run tí Jèhófà ti gbé kalẹ̀ ni wọ́n dúró tì gbágbáágbá tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.—Fi wé Mátíù 24:3, 9-13.

19. (a) Kí ni ìjọ méje náà dúró fún lónìí? (b) Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn wo ló dara pọ̀ mọ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, kí sì nìdí tí ìmọ̀ràn Jésù àti àwọn ohun tó sọ pé òun rí nínú ìjọ méje náà fi kan àwọn náà? (d) Ojú wo ló yẹ ká fi wo iṣẹ́ tí Jésù rán sí ìjọ méje náà ní ọ̀rúndún kìíní?

19 Fún ìdí yìí, ọ̀rọ̀ tí Jésù bá àwọn ìjọ náà sọ ti ní ìfisílò pàtàkì láti 1914. Ní àkókò ìfisílò pàtàkì yìí, ìjọ méje náà dúró fún gbogbo ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní ọjọ́ Olúwa. Yàtọ̀ síyẹn, láàárín ohun tó ti lé ní àádọ́rin [70] ọdún báyìí, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn onígbàgbọ́ tí wọ́n nírètí láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé ti dara pọ̀ mọ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí Jòhánù jẹ́ àpẹẹrẹ fún. Bí ìmọ̀ràn Jésù tí Ọlọ́run ti ṣe lógo àtohun tó rí nínú ìjọ méje náà nígbà tó ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ ṣe kan àwọn ẹni àmì òróró, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló ṣe kan àwọn onígbàgbọ́ tí wọ́n ní ìrètí orí ilẹ̀ ayé náà, nítorí pé ìlànà òdodo àti ìṣòtítọ́ kan ṣoṣo ló wà fún gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà. (Ẹ́kísódù 12:49; Kólósè 3:11) Nítorí náà, iṣẹ́ tí Jésù rán sí ìjọ méje tó wà ní Éṣíà Kékeré ní ọ̀rúndún kìíní kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe ìtàn lásán tá a kàn ń wá fìn-ín ìdí kókò rẹ̀. Ọwọ́ tá a bá fi mú un lè túmọ̀ sí ìyè tàbí ikú fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká baralẹ̀ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ Jésù.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú èdè Hébérù tí wọ́n fi kọ Bíbélì, Aísáyà 44:6 kò lo ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń tọ́ka nǹkan pàtó mọ́ ọ̀rọ̀ náà, “àkọ́kọ́” àti “ìkẹyìn.” Àmọ́ Jésù lo ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń tọ́ka nǹkan pàtó nínú èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì nígbà tó sọ ohun tó wà ní Ìṣípayá 1:17. Nítorí náà, tá a bá fi ìlànà gírámà wò ó, orúkọ oyè ni Ìṣípayá 1:17 fi hàn, nígbà tó jẹ́ pé Aísáyà 44:6 ṣàpèjúwe jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run.

b Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà agʹge·los (tí pípè rẹ̀ jẹ́ “áńjẹ́lọ́ọ̀sì”) túmọ̀ sí “ońṣẹ́” ó sì tún túmọ̀ sí “áńgẹ́lì.” Málákì 2:7 tọ́ka sí àlùfáà ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí “ońṣẹ́” (ìyẹn mal·’akhʹ lédè Hébérù).—Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé Bíbélì atọ́ka New World Translation, lédè Gẹ̀ẹ́sì.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 32]

Àkókò Ìdánwò àti Ìdájọ́

A ri Jésù bọmi, Ọlọ́run sì fẹ̀mí yàn án gẹ́gẹ́ bí Ọba Lọ́la ní Odò Jọ́dánì ní nǹkan bí oṣù October ọdún 29 Sànmánì Kristẹni. Ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ lẹ́yìn náà, lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, ó wá sí tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù ó sì lé àwọn tí ń sọ ọ́ di hòrò ọlọ́ṣà jáde. Ó jọ pé ohun kan tó bá èyí dọ́gba wáyé ní sáà ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí Jésù ti gorí ìtẹ́ lọ́run ní October ọdún 1914 títí di ìgbà tó wá láti bẹ àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ wò nígbà tí ìdájọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run. (Mátíù 21:12, 13; 1 Pétérù 4:17) Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1918, ìgbòkègbodò àwọn èèyàn Jèhófà nípa Ìjọba Ọlọ́run bá àtakò tó pọ̀ pàdé. Ó jẹ́ àkókò ìdánwò jákèjádò ilẹ̀ ayé, àwọn tí ẹ̀rù bà ni a sì sẹ́ kúrò, ìyẹn ni pé wọ́n kúrò láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ní May 1918 ẹgbẹ́ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣokùnfà ìfisẹ́wọ̀n àwọn òṣìṣẹ́ Watch Tower Society, ṣùgbọ́n oṣù mẹ́sàn-án lẹ́yìn náà, a dá wọn sílẹ̀. Nígbà tó yá, wọ́n sọ pé wọn ò jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn wọ́n. Láti ọdún 1919, ètò àwọn èèyàn Ọlọ́run tí a ti dán wò tí a sì ti yọ́ mọ́ ń fi ìtara tẹ̀ síwájú láti kéde Ìjọba Jèhófà tó wà lọ́wọ́ Kristi Jésù gẹ́gẹ́ bí ìrètí aráyé.—Málákì 3:1-3.

Kò sí àní-àní pé ìdájọ́ ẹ̀bi ni ẹgbẹ́ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì gbà nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ àbẹ̀wò rẹ̀ lọ́dún 1918. Yàtọ̀ sí pé àwọn àlùfáà náà ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run, wọ́n tún mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ńlá wá sórí ara wọn nípa ṣíṣètìlẹyìn fún àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń bára wọn jagun nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. (Ìṣípayá 18:21, 24) Lẹ́yìn náà, àwọn àlùfáà wọ̀nyẹn fi ìrètí wọn sínú Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè téèyàn dá sílẹ̀. Nígbà tó fi máa di ọdún 1919, ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti gbogbo ìsìn èké àgbáyé lápapọ̀ ti pàdánù ojú rere Ọlọ́run.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 28, 29]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÉFÉSÙ

SÍMÍNÀ

PÁGÁMÙ

TÍÁTÍRÀ

SÁDÍSÌ

FILADÉFÍÀ

LAODÍKÍÀ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ńlá wá sórí ara wọn. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ní ti pé wọ́n ṣe inúnibíni, wọ́n sì pa àwọn tí wọ́n ń ṣètumọ̀ Bíbélì, àwọn tí wọ́n ń kà á, tàbí àwọn tí wọ́n tilẹ̀ ní in lọ́wọ́