Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Bábílónì Ńlá Ti Ṣubú!”

“Bábílónì Ńlá Ti Ṣubú!”

Orí 30

“Bábílónì Ńlá Ti Ṣubú!”

1. Kí ni áńgẹ́lì kejì kéde rẹ̀, ta sì ni Bábílónì Ńlá?

 WÁKÀTÍ ìdájọ́ Ọlọ́run rèé! Nígbà náà, fetí sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yìí: “Àti òmíràn, áńgẹ́lì kejì, tẹ̀ lé e, ó ń wí pé: ‘Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá ti ṣubú, ẹni tí ó mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mu nínú wáìnì ìbínú àgbèrè rẹ̀!’” (Ìṣípayá 14:8) Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ìwé Ìṣípayá máa sọ̀rọ̀ nípa Bábílónì Ńlá, àmọ́ èyí kọ́ ni ìgbà ìkẹyìn. Níwájú, orí kẹtàdínlógún ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí obìnrin aṣẹ́wó tí ń fi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Ta ni Bábílónì ńlá yìí? Gẹ́gẹ́ bí a ó ti rí i, Bábílónì Ńlá ni ètò kan tó karí ayé, tó jẹ́ ẹ̀sìn, àti ayédèrú ètò tí Sátánì ń lò láti bá irú-ọmọ obìnrin Ọlọ́run jà. (Ìṣípayá 12:17) Òun ni ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, ìyẹn àpapọ̀ gbogbo ìsìn èké tó wà láyé pátá. Ara ohun tó wà nínú ẹ̀ ni gbogbo ìsìn tó ń tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn àti àṣà Bábílónì ìgbàanì tí wọ́n sì ń fi irú ẹ̀mí tó ní hàn.

2. (a) Báwo ló ṣe di pé ìsìn Bábílónì wà káàkiri ilẹ̀ ayé? (b) Kí ni apá tó gbajúmọ̀ jù nínú Bábílónì Ńlá, nígbà wo ló sì jẹ yọ gẹ́gẹ́ bí ètò alágbára kan?

2 Ìlú Bábílónì ni Jèhófà ti da èdè àwọn tí wọ́n fẹ́ kọ́ Ilé Gogoro Bábélì rú ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún sẹ́yìn. Àwọn èèyàn tí wọ́n di elédè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọ̀nyí sì fọ́n káàkiri ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àtàwọn àṣà apẹ̀yìndà wọn tí wọ́n mú lọ́wọ́, èyí tó jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ jù lọ ìsìn títí dòní. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1-9) Bábílónì Ńlá ni apá tó jẹ́ ti ìsìn lára ètò Sátánì. (Fi wé Jòhánù 8:43-47.) Apá tó gbajúmọ̀ jù nínú Bábílónì Ńlá lónìí ni àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ọ̀rúndún kẹrin lẹ́yìn Kristi ló sì jẹ yọ gẹ́gẹ́ bí ètò alágbára àti oníwàkiwà. Látinú ìsìn Bábílónì làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyí sì ti mú èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn àtàwọn àṣà tí wọ́n ń tẹ̀ lé, kì í ṣe látinú Bíbélì.—2 Tẹsalóníkà 2:3-12.

3. Kí nìdí tá a fi sọ pé Bábílónì Ńlá ti ṣubú?

3 O lè béèrè pé, ‘Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìsìn ṣì ń lo agbára lórí ilẹ̀ ayé, kí nìdí tí áńgẹ́lì náà fi kéde pé Bábílónì Ńlá ti ṣubú?’ Ó dáa, kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọdún 539 ṣááju Sànmánì Kristẹni nígbà tí wọ́n gba agbára ìjọba lọ́wọ́ Bábílónì ìgbàanì? Ṣebí ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lómìnira láti padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn tí wọ́n lè mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò níbẹ̀! Nítorí náà bí Ísírẹ́lì tẹ̀mí ṣe padà sínú aásìkí tẹ̀mí lọ́dún 1919, ìyẹn aásìkí tó ń bá a lọ tó sì ń pọ̀ sí i títí dòní, jẹ́ ẹ̀rí pé Bábílónì Ńlá ṣubú lọ́dún yẹn. Kò lágbára mọ́ láti ṣèdíwọ́ fáwọn èèyàn Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, wàhálà ńlá ti bẹ́ sílẹ̀ láàárín rẹ̀. Látọdún 1919 wá, ìwà ìbàjẹ́, ìwà àbòsí, àti ìwà pálapàla rẹ̀ ti di mímọ̀ níbi gbogbo. Ní ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè nílẹ̀ Yúróòpù, ìwọ̀nba àwọn èèyàn díẹ̀ ló ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì báyìí, àti pé ní àwọn orílẹ̀-èdè kan tó jẹ́ elétò ìjọba àjùmọ̀ní, wọ́n ka ìsìn sí “oògùn apanilọ́bọlọ̀ táwọn èèyàn ń lò.” Bábílónì Ńlá ti dẹni ẹ̀tẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ òtítọ́, Jèhófà ò sì ní pẹ́ mú ìdájú òdodo ṣẹ lórí rẹ̀.

Ìṣubú Ẹlẹ́tẹ̀ẹ́ Bábílónì

4-6. Báwo ló ṣe jẹ́ pé “Bábílónì Ńlá . . . mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mu nínú wáìnì ìbínú àgbèrè rẹ̀”?

4 Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó fa ìṣubú ẹlẹ́tẹ̀ẹ́ Bábílónì Ńlá. Níhìn-ín áńgẹ́lì náà sọ fún wa pé “Bábílónì Ńlá . . . mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mu nínú wáìnì ìbínú àgbèrè rẹ̀.” Kí lèyí túmọ̀ sí? Ọ̀rọ̀ ìṣẹ́gun ni ibí yìí ń sọ. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún Jeremáyà pé: “Gba ife wáìnì ìhónú yìí ní ọwọ́ mi, kí o sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè tí èmi yóò rán ọ sí mu ún. Wọn yóò sì mu, wọn yóò sì mì síwá-sẹ́yìn, wọn yóò sì ṣe bí ayírí nítorí idà tí èmi yóò rán sáàárín wọn.” (Jeremáyà 25:15, 16) Ní ọ̀rúndún kẹfà àti ìkeje ṣááju Sànmánì Kristẹni, Jèhófà lo Bábílónì ìgbàanì láti tú ife ìpọ́njú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ jáde fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè láti mu, títí kan Júdà apẹ̀yìndà, tó fi jẹ́ pé wọ́n kó àwọn èèyàn rẹ̀ pàápàá lọ sí ìgbèkùn. Nígbà tó wá yí kan Bábílónì, wọ́n pa òun náà run nítorí pé ọba rẹ̀ gbéra ga sí Jèhófà, “Olúwa ọ̀run.”—Dáníẹ́lì 5:23.

5 Bákan náà, Bábílónì Ńlá ti ṣẹ́gun ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lọ lára ìṣẹ́gun rẹ̀ ló jẹ́ lọ́nà àyínìke. Ó “mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mu” nípa lílo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ bíi ti aṣẹ́wó láti fi mú kí wọ́n bá òun ṣe àgbèrè ní ti ìsìn. Ó fẹ̀tàn mú àwọn olóṣèlú kí wọ́n lè bá a lẹ̀dí àpò pọ́ kí wọ́n sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ti fi ìsìn fa ojú àwọn olóṣèlú àtàwọn olókòwò mọ́ra kó bàa lè máa rí agbára wọn lò láti rẹ́ àwọn èèyàn jẹ. Tìtorí ọ̀rọ̀ ìṣèlú àti òwò, ó ti mú kí ìsìn ṣe inúnibíni sáwọn èèyàn, ó ti fa onírúurú ogun ìsìn àti ogun láàárín orílẹ̀-èdè. Ó ya ogun wọ̀nyí sí mímọ́ nípa sísọ pé wọ́n jẹ́ ohun tí Ọlọ́run fẹ́.

6 Kò sẹ́ni tí kò mọ̀ pé ìsìn lọ́wọ́ sí àwọn ìṣèlú àtàwọn ogun tó jà ní ọ̀rúndún ogún. Àpẹẹrẹ irú ẹ̀ ni àwọn onísìn Ṣintó ní Japan, àwọn onísìn Híńdù ní India, àwọn onísìn Búdà ní Vietnam, àwọn tó pera wọn ní Kristẹni ní Àríwá Ireland àti Látìn Amẹ́ríkà àtàwọn míì bẹ́ẹ̀. Kò mọ síbẹ̀ o, nígbà ogun àgbáyé méjèèjì, bí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ṣe ń ṣètìlẹyìn fáwọn ológun tibí làwọn àlùfáà míì ń ṣètìlẹyìn fáwọn ológun tọ̀hún, tí wọ́n rọ àwọn ọ̀dọ́kùnrin pé kí wọ́n máa pa ara wọn. Ọ̀kan tó pabanbarì nínú ìwà àgbèrè Bábílónì Ńlá ni ipa tó kó nínú Ogun Abẹ́lé Sípéènì tó wáyé lọ́dún 1936 sí ọdún 1939. Ó kéré tán, àwọn èèyàn tó kú sógun yẹn á tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [600,000]. Lára ohun tó sì fa ogun tó gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn yìí ni pé ìjọba ilẹ̀ Sípéènì fẹ́ gba ọlà àti ipò ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, làwọn tó jẹ́ alátìlẹyìn fáwọn àlùfáà Kátólíìkì àtàwọn tó bá wọn lẹ̀dí àpò pọ̀ bá fárígá.

7. Ta ni Bábílónì Ńlá ń fòòró jù, àwọn ọ̀nà wo ló sì ti lò láti fi mú wọn?

7 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Bábílónì Ńlá ni apá tó jẹ́ ti ìsìn lára irú-ọmọ Sátánì, “obìnrin” Jèhófà, ìyẹn “Jerúsálẹ́mù ti òkè,” ló máa ń fòòró jù. Ní ọ̀rúndún kìíní, ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fara hàn ní kedere gẹ́gẹ́ bí irú-ọmọ obìnrin náà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Gálátíà 3:29; 4:26) Bábílónì Ńlá sapá gidigidi láti ṣẹ́gun ìjọ oníwà mímọ́ yẹn nípa títàn án sínú ṣíṣe àgbèrè ìsìn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti àpọ́sítélì Pétérù kìlọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò juwọ́ sílẹ̀ àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò di apẹ̀yìndà. (Ìṣe 20:29, 30; 2 Pétérù 2:1-3) Àwọn iṣẹ́ tí Jésù rán sí ìjọ méjèèje fi hàn pé nígbà tó máa fi máa kù díẹ̀ kí Jòhánù kú, Bábílónì Ńlá ti gbìyànjú gan-an láti yí àwọn kan lèrò padà. (Ìṣípayá 2:6, 14, 15, 20-23) Ṣùgbọ́n Jésù ti fi hàn ṣáájú pé ó níbi tó máa ṣe àṣeyọrí dé.

Àlìkámà àti Èpò

8, 9. (a) Kí ni àkàwé Jésù nípa àlìkámà àti èpò fi hàn? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ “nígbà tí àwọn ènìyàn ń sùn”?

8 Nínú àkàwé Jésù nípa àlìkámà àti èpò, ó sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tó gbin àwọn irúgbìn rere sínú pápá. Ṣùgbọ́n “nígbà tí àwọn ènìyàn ń sùn,” ọ̀tá kan wá ó sì fún èpò lé e. Èyí wá mú kí èpò kún bo àlìkámà mọ́lẹ̀. Nígbà tí Jésù ṣàlàyé àkàwé rẹ̀ yìí, ó ní: “Afúnrúgbìn tí ó fún irúgbìn àtàtà náà ni Ọmọ ènìyàn; pápá náà ni ayé; ní ti irúgbìn àtàtà, àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ìjọba náà; ṣùgbọ́n àwọn èpò ni àwọn ọmọ ẹni burúkú náà, ọ̀tá tí ó sì fún wọn ni Èṣù.” Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù fi hàn pé a ó fi àlìkámà àti èpò sílẹ̀ láti dàgbà pa pọ̀ títí “ìparí ètò àwọn nǹkan,” nígbà táwọn áńgẹ́lì yóò “kó” àwọn èpò ìṣàpẹẹrẹ “jáde.”—Mátíù 13:24-30, 36-43.

9 Ohun tí Jésù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti àpọ́sítélì Pétérù kìlọ̀ nípa rẹ̀ ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. “Nígbà tí àwọn ènìyàn ń sùn,” ìyẹn bóyá lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì sùn nínú ikú tàbí nígbà tí oorun tẹ̀mí kun àwọn Kristẹni alábòójútó lẹ́nu iṣẹ́ ṣíṣọ́ agbo Ọlọ́run, irú ìpẹ̀yìndà bíi ti Bábílónì bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrú nínú ìjọ. (Ìṣe 20:31) Láìpẹ́, èpò wá pọ̀ ju àlìkámà lọ ó sì bò ó mọ́lẹ̀. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ńṣe ló dà bíi pé Bábílónì Ńlá ti gbé irú-ọmọ obìnrin náà mì pátápátá.

10. Kí ló wáyé láti ọdún 1870 síwájú, kí sì ni Bábílónì Ńlá ṣe nípa èyí?

10 Láti ọdún 1870 síwájú, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bẹ̀rẹ̀ sí í sapá láti yọ ara wọn nínú iṣẹ́ aṣẹ́wó ti Bábílónì Ńlá. Wọ́n pa àwọn ẹ̀kọ́ èké táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti mú wọlé látinú ìsìn olórìṣà tì, wọ́n sì fi àìṣojo lo Bíbélì ní wíwàásù pé àwọn àkókò Kèfèrí yóò dópin lọ́dún 1914. Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ pé àwọn ni olórí ohun tí Bábílónì Ńlá ń lò, ta ko àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí bí wọ́n ṣe ń mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, tó jẹ́ pé inú ìbẹ̀rù làwọn èèyàn wà, wọ́n gbìyànjú láti lo àǹfààní yẹn láti pa àwùjọ kékeré ti àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ yìí run. Lọ́dún 1918, tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tẹ ìgbòkègbodò wọn rì pátápátá, ó wá dà bíi pé Bábílónì Ńlá ti kẹ́sẹ járí. Ó dà bí ẹni pé ó ti ṣẹ́gun wọn.

11. Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba agbára ìjọba kúrò lọ́wọ́ Bábílónì ìgbàanì?

11 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ṣáájú, wọ́n gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ Bábílónì tó jẹ́ ìlú agbéraga lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Kristẹni. Nígbà náà ni a gbọ́ igbe náà: “Ó ti ṣubú! Bábílónì ti ṣubú.” Ibùjókòó ńlá ti ilẹ̀ ọba ayé yìí ṣubú sọ́wọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mídíà òun Páṣíà lábẹ́ Kírúsì Ńlá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú náà fúnra rẹ̀ kò pa run, àmọ́ agbára ìjọba ti kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, èyí ló mú kí wọ́n dá àwọn Júù tó wà nígbèkùn sílẹ̀. Àwọn Júù náà padà sí Jerúsálẹ́mù láti fìdí ìjọsìn mímọ́ múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.—Aísáyà 21:9; 2 Kíróníkà 36:22, 23; Jeremáyà 51:7, 8.

12. (a) Ní àkókò tiwa yìí, báwo la ṣe lè sọ pé Bábílónì Ńlá ti ṣubú? (b) Kí ló fi hàn pé Jèhófà ti kọ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀ pátápátá?

12 Ní àkókò tiwa yìí, a ti tún gbọ́ igbe náà pé Bábílónì Ńlá ti ṣubú! Lọ́dún 1918, ó dà bí ẹni pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ ara Bábílónì Ńlá ti ṣẹ́gun àwọn ẹni àmì òróró, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ lọ títí nítorí pé lọ́dún 1919, àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró, ìyẹn ẹgbẹ́ Jòhánù, padà bọ̀ sípò nípasẹ̀ àjíǹde tẹ̀mí. Bábílónì Ńlá ti ṣubú ní ti pé wọn ò lè ráwọn èèyàn Ọlọ́run mú lóǹdè lọ́nà èyíkéyìí mọ́. Ńṣe làwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi tú jáde bí eéṣú kúrò nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. (Ìṣípayá 9:1-3; 11:11, 12) Àwọn ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” òde òní, Ọ̀gá náà sì yàn wọ́n sípò lórí gbogbo ohun ìní rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 24:45-47) Lílò tí ọ̀gá náà lò wọ́n lọ́nà yìí fi hàn pé Jèhófà ti kọ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀ pátápátá bí wọ́n tilẹ̀ ń sọ pé àwọn jẹ́ aṣojú Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Báwọn ẹni àmì òróró ṣe fìdí ìjọsìn mímọ́ múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i nìyẹn, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ fífi èdìdì di àṣẹ́kù àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], ìyẹn àwọn tó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ obìnrin náà, tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá Bábílónì Ńlá látọdúnmọ́dún. Gbogbo èyí fi hàn pé a ti ṣẹ́gun ètò ìsìn Sátánì yìí pátápátá.

Àwọn Ẹni Mímọ́ Gbọ́dọ̀ Ní Ìfaradà

13. (a) Kí ni áńgẹ́lì kẹta kéde rẹ̀? (b) Ìdájọ́ wo ni Jèhófà ṣe fún àwọn tí wọ́n gba àmì ẹranko ẹhànnà náà?

13 Wàyí ó, gbọ́ ohun tí áńgẹ́lì kẹta sọ: “Áńgẹ́lì mìíràn, ẹkẹta, sì tẹ̀ lé wọn, ó ń sọ ní ohùn rara pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni bá jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà àti ère rẹ̀, tí ó sì gba àmì kan sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀, òun yóò mu pẹ̀lú nínú wáìnì ìbínú Ọlọ́run tí a tú jáde láìní àbùlà sínú ife ìrunú rẹ̀.’” (Ìṣípayá 14:9, 10a) Ìṣípayá 13:16, 17 fi hàn pé ní ọjọ́ Olúwa, wọ́n yóò fìyà jẹ àwọn tí kò jọ́sìn ère ẹranko ẹhànnà, wọn yóò sì pa lára wọn. Nísinsìnyí a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ti pinnu láti dá àwọn tí wọ́n “ní àmì náà, orúkọ ẹranko ẹhànnà náà tàbí nọ́ńbà orúkọ rẹ̀” lẹ́jọ́. A ó fipá mú wọn láti mu “ife ìrunú” kíkorò ti ìbínú Jèhófà. Kí ni èyí yóò túmọ̀ sí fún wọn? Ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Jèhófà fipá mú Jerúsálẹ́mù láti mu ‘ife ìrunú rẹ̀,’ àwọn ará Bábílónì ‘fi ìlú náà ṣèjẹ, wọ́n wó o palẹ̀, wọ́n sì fi ebi àti idà pa wọ́n níbẹ̀.’ (Aísáyà 51:17, 19) Bákan náà, nígbà táwọn tó sọ agbára ìṣèlú ayé àti ère wọn, ìyẹn Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, dòrìṣà bá mu ife ìrunú Jèhófà, àgbákò ló máa yọrí sí fún wọn. (Jeremáyà 25:17, 32, 33) Wọ́n máa pa run pátápátá.

14. Kí ìparun tiẹ̀ tó dé bá àwọn tí ń jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà àti ère rẹ̀, kí ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa fara gbá, báwo ni Jòhánù sì ṣe ṣàpèjúwe èyí?

14 Àmọ́ ṣá o, kí èyí tó ṣẹlẹ̀ rárá, àwọn tó ní àmì ẹranko náà máa jìyà torí pé wọn ò rí ojú rere Jèhófà. Nígbà tí áńgẹ́lì náà ń sọ̀rọ̀ fún Jòhánù nípa àwọn tó ń jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà àti ère rẹ̀, ó ní: “Ṣe ni a ó fi iná àti imí ọjọ́ mú un joró níwájú àwọn áńgẹ́lì mímọ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. Èéfín ìjoró wọn yóò sì máa gòkè lọ títí láé àti láéláé, wọn kì yóò sì ní ìsinmi rárá tọ̀sán-tòru, àwọn tí ń jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà àti ère rẹ̀, àti ẹnì yòówù tí ó bá gba àmì orúkọ rẹ̀.”—Ìṣípayá 14:10b, 11.

15, 16. Kí ni ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ náà “iná àti imí ọjọ́” nínú Ìṣípayá 14:10?

15 Àwọn kan wò ó pé “iná àti imí ọjọ́” tí ibí yìí mẹ́nu kan fi hàn pé ọ̀run àpáàdì oníná wà. Ṣùgbọ́n tá a bá kàn wo àsọtẹ́lẹ̀ kan tó jọ ọ́, a ó mọ ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí níbi tí wọ́n ti lò ó yẹn. Nígbà ayé Aísáyà, Jèhófà kìlọ̀ fún orílẹ̀-èdè Édómù pé wọ́n á jìyà nítorí bí wọ́n ṣe ń bá Ísírẹ́lì ṣọ̀tá. Ó ní: “Àwọn ọ̀gbàrá rẹ̀ ni a ó sì sọ di ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀, ekuru rẹ̀ ni a ó sì sọ di imí ọjọ́; ilẹ̀ rẹ̀ yóò sì dà bí ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀ tí ń jó. Ní òru tàbí ní ọ̀sán, a kì yóò pa á; fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èéfín rẹ̀ yóò máa gòkè. Láti ìran dé ìran ni yóò gbẹ hán-ún hán-ún; títí láé àti láéláé, kò sí ẹni tí yóò gbà á kọjá.”—Aísáyà 34:9, 10.

16 Ǹjẹ́ wọ́n fi ìlú Édómù sọ̀kò sínú iná ọ̀run àpáàdì kankan láti máa jó títí láé? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni orílẹ̀-èdè náà pa rẹ́ ráúráú tá ò gbúròó ẹ̀ mọ́, bí ẹni pé wọ́n fi iná àti imí ọjọ́ jó o run. Ohun tó jẹ́ àbájáde ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ yìí kì í ṣe ìdálóró ayérayé bí kò ṣe “òfìfo . . . òfò . . . aláìjámọ́ nǹkan kan.” (Aísáyà 34:11, 12) Èéfín ‘tí ń gòkè fún àkókò tí ó lọ kánrin’ ṣàpèjúwe èyí lọ́nà tó ṣe kedere. Nígbà tí ilé kan bá jó kanlẹ̀, èéfín a ṣì máa rú jáde látinú eérú fúngbà díẹ̀ lẹ́yìn tí iná náà bá ti kú. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tó bá débẹ̀ á mọ̀ pé àgbáàràgbá iná ti jó nǹkan kan run níbẹ̀. Àní lónìí pàápàá, àwọn èèyàn Ọlọ́run rántí ẹ̀kọ́ téèyàn lè rí kọ́ látinú ìparun Édómù. Lọ́nà yìí ‘èéfín ìjóná rẹ̀’ ṣì ń gòkè lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.

17, 18. (a) Kí ni yóò jẹ́ ìgbẹ̀yìn àwọn tó gba àmì ẹranko ẹhànnà náà? (b) Lọ́nà wo ni wọ́n gbà dá àwọn olùjọsìn ẹranko ẹhànnà náà lóró? (d) Báwo ló ṣe jẹ́ pé “èéfín ìjoró wọn yóò sì máa gòkè lọ títí láé àti láéláé”?

17 Àwọn tó ní àmì ẹranko ẹhànnà náà á pa run pátápátá, bíi pé inú iná la sọ wọ́n sí. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà sì ti sọ níwájú, kò sẹ́ni tó máa sin òkú wọn, àwọn ẹranko àtàwọn ẹyẹ ni wọ́n máa fi í sílẹ̀ fún láti jẹ. (Ìṣípayá 19:17, 18) Nítorí náà, ó ṣe kedere pé wọn ò ní máa joró títí láé! Báwo la ṣe wá fi ‘iná àti imí ọjọ́ mú wọn joró’? Bí èyí ṣe ṣẹlẹ̀ ni pé òtítọ́ tá à ń wàásù ń tú àṣírí wọn ó sì ń kìlọ̀ fún wọn nípa ìdájọ́ Ọlọ́run tí ń bọ̀. Ìdí rèé tí wọ́n fi ń pẹ̀gàn àwọn èèyàn Ọlọ́run, níbi tó bá sì ti ṣeé ṣe, wọ́n ń fi ọgbọ́n mú kí ẹranko ẹhànnà ìṣèlú náà ṣe inúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí wọ́n tiẹ̀ pa wọ́n pàápàá. Àmọ́ níkẹyìn, àwọn alátakò wọ̀nyí á pa run bí ẹni pé iná àti imí ọjọ́ ló jó wọn run. Nígbà náà, “èéfín ìjoró wọn yóò sì máa gòkè lọ títí láé àti láéláé” ní ti pé ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe fún wọn yóò jẹ́ gẹ́gẹ́ ìlànà tí Ọlọ́run tún máa tẹ̀ lé bó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan tún fẹ́ jiyàn pé Jèhófà ò lẹ́tọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, ìyẹn tí irú rẹ̀ bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ rárá. Bí ọ̀ràn náà ṣe máa yanjú títí láé nìyẹn.

18 Àwọn wo ló ń jíhìn tí ń dáni lóró náà lóde òní? Rántí pé wọ́n ti fún àwọn eéṣú ìṣàpẹẹrẹ láṣẹ láti mú àwọn tí kò ní èdìdì Ọlọ́run níwájú orí wọn joró. (Ìṣípayá 9:5) Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn wọ̀nyí tí áńgẹ́lì ń darí ló ń dá àwọn èèyàn lóró. Akitiyan àìdabọ̀ àwọn eéṣú ìṣàpẹẹrẹ náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé ‘àwọn tí ń jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà àti ère rẹ̀, àti ẹni yòówù tí ó bá gba àmì orúkọ rẹ̀ kò ní ìsinmi ní ọ̀sán àti ní òru.’ Níkẹyìn, “èéfín ìjoró wọn,” yóò máa gòkè títí láé àti láéláé, àmọ́ ìyẹn á jẹ́ lẹ́yìn ìparun wọn tó jẹ́ ẹ̀rí pípabanbarì tó fi Jèhófà hàn gẹ́gẹ́ ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Ǹjẹ́ kí ẹgbẹ́ Jòhánù máa fara dà á títí gbogbo ìyẹn yóò fi parí! Áńgẹ́lì náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Níhìn-ín ni ibi tí ó ti túmọ̀ sí ìfaradà fún àwọn ẹni mímọ́, àwọn tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jésù mọ́.”—Ìṣípayá 14:12.

19. Kí nìdí táwọn ẹni mímọ́ fi ní láti fara dà á, kí sì ni Jòhánù sọ tó fún wọn lókun?

19 Bẹ́ẹ̀ ni, “ìfaradà fún àwọn ẹni mímọ́” túmọ̀ sí fífi gbogbo ọkàn jọ́sìn Jèhófà nípasẹ̀ Jésù Kristi. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò fẹ́ gbọ́ ìwàásù wọn. Ìwàásù ń yọrí sí àtakò, inúnibíni, àní ikú ajẹ́rìíkú pàápàá. Ṣùgbọ́n, ìṣírí ni ọ̀rọ̀ tí Jòhánù sọ tẹ̀ lé e jẹ́ fún wọn, ó ní: “Mo sì gbọ́ tí ohùn kan láti ọ̀run wá wí pé: ‘Kọ̀wé pé: Aláyọ̀ ni àwọn òkú tí ó kú ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa láti àkókò yìí lọ. Bẹ́ẹ̀ ni, ni ẹ̀mí wí, kí wọ́n sinmi kúrò nínú àwọn òpò wọn, nítorí àwọn ohun tí wọ́n ṣe ń bá wọn lọ ní tààràtà.’”—Ìṣípayá 14:13.

20. (a) Báwo ni ìlérí tí Jòhánù sọ ṣe bá àsọtẹ́lẹ̀ Pọ́ọ̀lù nípa wíwàníhìn-ín Jésù mu? (b) Àǹfààní àkànṣe wo ni a ṣèlérí fáwọn ẹni àmì òróró tó kú lẹ́yìn tí wọ́n ti lé Sátánì kúrò lọ́run?

20 Ìlérí yìí bá àsọtẹ́lẹ̀ Pọ́ọ̀lù nípa wíwà níhìn-ín Jésù mu, ó sọ pé: “Àwọn tí ó kú ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi ni yóò sì kọ́kọ́ dìde. Lẹ́yìn náà, àwa alààyè tí a kù nílẹ̀ [ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró tí ó kù nílẹ̀ di ọjọ́ Olúwa], pa pọ̀ pẹ̀lú wọn, ni a ó gbà lọ dájúdájú nínú àwọsánmà láti pàdé Olúwa nínú afẹ́fẹ́.” (1 Tẹsalóníkà 4:15-17) Lẹ́yìn tí wọ́n lé Sátánì kúrò lọ́run, àwọn tó ti kú ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi ni wọ́n kọ́kọ́ jíǹde. (Fi wé Ìṣípayá 6:9-11.) Lẹ́yìn ìyẹn, ìlérí àǹfààní àkànṣe wà fáwọn ẹni àmì òróró tó kú ní ọjọ́ Olúwa. Àjíǹde wọn sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí jẹ́ ẹsẹ̀kẹsẹ̀, “ní ìpajúpẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:52) Èyí mà ga lọ́lá o! Wọ́n yóò sì máa bá iṣẹ́ òdodo wọn nìṣó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní ọ̀run.

Ìkórè Ilẹ̀ Ayé

21. Kí ni Jòhánù sọ fún wa nípa “ìkórè ilẹ̀ ayé”?

21 Àwọn mìíràn pẹ̀lú yóò jàǹfààní ní ọjọ́ ìdájọ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ṣe sọ fún wa: “Mo sì rí, sì wò ó! àwọsánmà funfun kan, àti lórí àwọsánmà náà ẹnì kan jókòó bí ọmọ ènìyàn, pẹ̀lú adé wúrà ní orí rẹ̀ àti dòjé mímú ní ọwọ́ rẹ̀. Áńgẹ́lì mìíràn [ẹ̀kẹrin] sì yọ láti inú ibùjọsìn tẹ́ńpìlì, ó ń ké pẹ̀lú ohùn rara sí ẹni tí ó jókòó lórí àwọsánmà pé: ‘Ti dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí o sì kárúgbìn, nítorí wákàtí láti kárúgbìn ti tó, nítorí ìkórè ilẹ̀ ayé tí gbó kárakára.’ Ẹni tí ó jókòó lórí àwọsánmà sì ti dòjé rẹ̀ bọ orí ilẹ̀ ayé, a sì kárúgbìn ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 14:14-16.

22. (a) Ta lẹni tó dé adé wúrà tó sì jókòó lórí àwọsánmà funfun? (b) Nígbà wo ni iṣẹ́ ìkórè dé òtéńté rẹ̀, báwo ló sì ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?

22 Kò sí iyèméjì kankan nípa ẹni tó jókòó lórí àwọsánmà funfun. Bí ẹsẹ yẹn ṣe sọ pé ó jókòó lórí àwọsánmà funfun, tó jọ ọmọ ènìyàn, tó sì ní adé wúrà fi hàn kedere pé ẹni náà ni Jésù, Mèsáyà Ọba tí Dáníẹ́lì pẹ̀lú rí nínú ìran. (Dáníẹ́lì 7:13, 14; Máàkù 14:61, 62) Ṣùgbọ́n kí ni ìkórè tí ibí yìí sọ tẹ́lẹ̀? Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn wé kíkórè àwọn èèyàn. (Mátíù 9:37, 38; Jòhánù 4:35, 36) Iṣẹ́ ìkórè yìí dé òtéńté rẹ̀ ní ọjọ́ Olúwa, nígbà tí Jésù di Ọba tó sì bá Baba rẹ̀ ṣe ìdájọ́. Nípa báyìí, àkókò ìṣàkóso rẹ̀, láti ọdún 1914, tún jẹ́ àkókò aláyọ̀ fún ìkórè.—Fi wé Diutarónómì 16:13-15.

23. (a) Ọ̀dọ̀ ta ni àṣẹ náà láti bẹ̀rẹ̀ sí í kárúgbìn ti wá? (b) Iṣẹ́ ìkórè wo ló ti bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1919 títí di ìsinsìnyí?

23 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù jẹ́ Ọba àti Onídàájọ́, síbẹ̀ ó dúró kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ fún un láṣẹ kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í kárúgbìn. Àṣẹ ọ̀hún wá látinú “ibùjọsìn tẹ́ńpìlì” nípasẹ̀ áńgẹ́lì kan. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Jésù sì ṣègbọràn. Lákọ̀ọ́kọ́, láti ọdún 1919 síwájú, ó rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti kórè gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000]. (Mátíù 13:39, 43; Jòhánù 15:1, 5, 16) Lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kó ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn jọ. (Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 7:9) Ìtàn fi hàn pé láàárín ọdún 1931 sí 1935, púpọ̀ lára àwọn àgùntàn mìíràn ni wọ́n ti kó jọ. Lọ́dún 1935, Jèhófà la ẹgbẹ́ Jòhánù lóye láti mọ irú ẹni tí ogunlọ́gọ̀ ńlá tí Ìṣípayá 7:9-17 sọ̀rọ̀ nípa wọn jẹ́. Láti àkókò yẹn síwájú ni wọ́n sì ti túbọ̀ ń kó ogunlọ́gọ̀ yìí jọ. Nígbà tó fi máa di ọdún 2005, iye wọn ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà, ńṣe ni wọ́n sì ń pọ̀ sí i. Dájúdájú, ẹni yẹn tó dà bí ọmọ èèyàn ti ṣe ìkórè púpọ̀ yanturu, tó kún fún ìdùnnú ní àkókò òpin yìí.—Fi wé Ẹ́kísódù 23:16; 34:22.

Títẹ Àjàrà Ilẹ̀ Ayé Fọ́

24. Kí ló wà ní ọwọ́ áńgẹ́lì karùn-ún, kí sì ni áńgẹ́lì kẹfà kéde?

24 Lẹ́yìn tí ìkórè ìgbàlà parí, àkókò wá tó fún ìkórè mìíràn. Jòhánù sọ pé: “Síbẹ̀, áńgẹ́lì mìíràn [ẹ̀karùn-ún] yọ láti inú ibùjọsìn tẹ́ńpìlì tí ó wà ní ọ̀run, òun, pẹ̀lú, ní dòjé mímú lọ́wọ́. Síbẹ̀, áńgẹ́lì mìíràn [ẹ̀kẹfà] yọ láti ibi pẹpẹ, ó sì ní ọlá àṣẹ lórí iná. Ó sì ké jáde pẹ̀lú ohùn rara sí ẹni tí ó ní dòjé mímú lọ́wọ́, ó wí pé: ‘Ti dòjé mímú rẹ bọ̀ ọ́, kí o sì kó àwọn òṣùṣù àjàrà ilẹ̀ ayé jọ, nítorí èso àjàrà rẹ̀ ti pọ́n.’” (Ìṣípayá 14:17, 18) Ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì ni wọ́n fún níṣẹ́ láti máa ṣe ìkórè púpọ̀ ní ọjọ́ Olúwa, kí wọ́n máa ya àwọn ẹni rere sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ẹni búburú!

25. (a) Kí ni wíwá tí áńgẹ́lì karùn-ún wá látinú ibùjọsìn tẹ́ńpìlì fi hàn? (b) Kí nìdí tó fi bá a mu pé àṣẹ náà pé kí ìkórè bẹ̀rẹ̀ wá látọ̀dọ̀ áńgẹ́lì tó “yọ láti ibi pẹpẹ”?

25 Látọ̀dọ̀ Jèhófà nínú ibùjọsìn tẹ́ńpìlì ni áńgẹ́lì karùn-ún ti wá. Èyí fi hàn pé ìkórè ìkẹyìn wáyé ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jèhófà. Áńgẹ́lì mìíràn tó “yọ láti ibi pẹpẹ” ni wọ́n rán pé kó sọ fún áńgẹ́lì yìí pé kó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀. Òtítọ́ yìí ṣe pàtàkì lọ́pọ̀lọpọ̀, níwọ̀n bí àwọn olóòótọ́ ọkàn tó wà lábẹ́ pẹpẹ ti béèrè pé: “Títí di ìgbà wo, Olúwa Ọba Aláṣẹ mímọ́ àti olóòótọ́, ni ìwọ ń fà sẹ́yìn kúrò nínú ṣíṣèdájọ́ àti gbígbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa lára àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé?” (Ìṣípayá 6:9, 10) Kíkórè àjàrà ilẹ̀ ayé ló máa jẹ́ ìdáhùn sí igbe tí wọ́n ń ké pé kí Ọlọ́run gbẹ̀san.

26. Kí ni “àjàrà ilẹ̀ ayé”?

26 Ṣùgbọ́n kí ni “àjàrà ilẹ̀ ayé”? Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ pé orílẹ̀-èdè Júù jẹ́ àjàrà Jèhófà. (Aísáyà 5:7; Jeremáyà 2:21) Bákan náà, Ìwé Mímọ́ sọ pé Jésù Kristi àtàwọn tí yóò bá a ṣèjọba nínú Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àjàrà. (Jòhánù 15:1-8) Níbí tá a bọ́rọ̀ dé yìí, ohun kan tó ṣe pàtàkì tó yẹ ká fi sọ́kàn nípa àjàrà ni pé ó máa ń so èso, àjàrà Kristẹni tòótọ́ sì ti mú èso jáde ní yanturu fún ìyìn Jèhófà. (Mátíù 21:43) Nítorí náà, “àjàrà ilẹ̀ ayé” kì í ṣe ojúlówó àjàrà yẹn bí kò ṣe ayédèrú rẹ̀, ti Sátánì, ìyẹn ìṣàkóso rẹ̀ oníbàjẹ́ lórí aráyé, tóun ti onírúurú “àwọn òṣùṣù” èso rẹ̀ ẹlẹ́mìí èṣù tó mú jáde láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá. Bábílónì Ńlá, èyí tí ìsìn Kristẹni apẹ̀yìndà jẹ́ apá tó tayọ lára rẹ̀ ti lo agbára ńláǹlà lórí àjàrà onímájèlé yìí.—Fi wé Diutarónómì 32:32-35.

27. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí áńgẹ́lì tí ó mú dòjé lọ́wọ́ kó àjàrà ilẹ̀ ayé jọ? (b) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ló fi hàn bí ìkórè náà yóò ti gbòòrò tó?

27 Ìdájọ́ máa dé dandan ni! Àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Áńgẹ́lì náà sì ti dòjé rẹ̀ bọ ilẹ̀ ayé, ó sì kó àjàrà ilẹ̀ ayé jọ, ó sì fi í sọ̀kò sínú ìfúntí wáìnì ńlá ti ìbínú Ọlọ́run. A sì tẹ ìfúntí wáìnì náà lẹ́yìn òde ìlú ńlá náà, ẹ̀jẹ̀ sì tú jáde láti inú ìfúntí wáìnì náà ní gíga sókè dé ìjánu ẹṣin, ó lọ jìnnà tó ẹgbẹ̀jọ ìwọ̀n fọ́lọ́ǹgì.” (Ìṣípayá 14:19, 20) Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ni wọ́n ti kéde ìbínú Jèhófà lòdì sí àjàrà yìí. (Sefanáyà 3:8) Àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú ìwé Aísáyà jẹ́ kó dá wá lójú pé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóò pa run nígbà tí wọ́n bá tẹ ìfúntí wáìnì náà. (Aísáyà 63:3-6) Jóẹ́lì náà sọ tẹ́lẹ̀ pé “ogunlọ́gọ̀” púpọ̀ jaburata, ìyẹn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ni a ó fi “ìfúntí wáìnì” tẹ̀ pa ní “pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu.” (Jóẹ́lì 3:12-14) Ní tòótọ́, àrágbabú ìkórè tí irú ẹ̀ ò ní wáyé mọ́ láé ni! Gẹ́gẹ́ bí ìran Jòhánù ti fi hàn, kì í ṣe kìkì pé a kórè àwọn èso àjàrà nìkan ni, ṣùgbọ́n a tún ké àjàrà ìṣàpẹẹrẹ náà lódindi lulẹ̀ tí a sì jù sínú ìfúntí wáìnì náà kí wọ́n bàa lè tẹ̀ ẹ́. Nítorí náà, àjàrà ilẹ̀ ayé ni a ó tẹ̀ pa tí kì yóò sì tún lè hù mọ́ láé.

28. Àwọn wo ló ń tẹ àjàrà ilẹ̀ ayé, kí ni títẹ̀ tí wọ́n sì “tẹ ìfúntí wáìnì náà lẹ́yìn òde ìlú ńlá náà” túmọ̀ sí?

28 Àwọn ẹṣin ló tẹ àwọn àjàrà tí Jòhánù rí nínú ìran náà, nítorí pé ẹ̀jẹ̀ tó jáde lára àjàrà náà dé “ìjánu ẹṣin.” Níwọ̀n bí ọ̀rọ̀ náà “ẹṣin” ti sábà máa ń tọ́ka sí ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun, èyí ní láti jẹ́ àkókò ogun. Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run tó ń tọ Jésù lẹ́yìn láti bá ètò àwọn nǹkan ti Sátánì ja ogun ìkẹyìn ni wọ́n ń tẹ “ìfúntí wáìnì ìbínú ìrunú Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìṣípayá 19:11-16) Ó ṣe kedere pé àwọn ló ń tẹ àjàrà ilẹ̀ ayé. Wọ́n ń “tẹ ìfúntí wáìnì náà lẹ́yìn òde ìlú ńlá náà,” ìyẹn lẹ́yìn òde Síónì ti ọ̀run. Ní tòótọ́, ó bá a mu pé kí títẹ àjàrà ilẹ̀ ayé wáyé lórí ilẹ̀ ayé níbí. Ṣùgbọ́n wọ́n yóò ‘tẹ̀ ẹ́ lẹ́yìn òde ìlú ńlá náà’ ní ti pé kò ní ṣèpalára kankan fáwọn tó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ obìnrin náà, tí wọ́n ṣojú fún Síónì ti ọ̀run lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn wọ̀nyí àtàwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ni a ó pa mọ́ láìséwu nínú ètò Jèhófà ti orí ilẹ̀ ayé.—Aísáyà 26:20, 21.

29. Báwo ni ẹ̀jẹ̀ tó jáde látinú ìfúntí wáìnì náà ṣe pọ̀ tó, báwo ni ibi tó ṣàn dé ṣe jìnnà tó, kí sì ni gbogbo èyí fi hàn?

29 Ìran tó ṣe kedere yìí bá ohun tí Dáníẹ́lì 2:34, 44 ṣàpèjúwe rẹ̀ mu. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé òkúta Ìjọba Ọlọ́run fọ àwọn ìjọba ayé túútúú. Ìran náà fi hàn pé ìparun yán-ányán-án yóò wáyé. Ẹ̀jẹ̀ tó jáde látinú ìfúntí wáìnì náà pọ̀ gan-an débi pé ó dé ìjánu ẹṣin, ó sì ṣàn dé ibi tí ó tó ẹgbẹ̀jọ [1,600] fọ́lọ́ǹgì. a Iye púpọ̀ yìí, tí a mú jáde nípasẹ̀ fífi ìṣirò mẹ́rin lọ́nà mẹ́rin sọ mẹ́wàá lọ́nà mẹ́wàá di púpọ̀ (ìyẹn 4 x 4 x 10 x 10), jẹ́ ká mọ̀ dájú pé ìparun náà yóò kan gbogbo ilẹ̀ ayé. (Aísáyà 66:15, 16) Ìparun yán-ányán-án ni yóò jẹ́, kò sì ní ṣeé yí padà. Àjàrà Sátánì ti ilẹ̀ ayé kì yóò ta gbòǹgbò mọ́ láé àti láéláé!—Sáàmù 83:17, 18.

30. Kí ni àwọn èso àjàrà Sátánì, kí ló sì yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?

30 Bá a ṣe túbọ̀ ń wọ àkókò òpin yìí lọ jìnnà, ìran ìkórè méjì yìí ṣe pàtàkì gan-an. Àwọn èso àjàrà Sátánì wà káàkiri. Lára wọn ni ìṣẹ́yún àti ìpànìyàn ni onírúurú ọ̀nà; kí ọkùnrin àti ọkùnrin tàbí obìnrin àti obìnrin máa bá ara wọn lòpọ̀, panṣágà, àti oríṣiríṣi ìṣekúṣe; àbòsí àti àìsí ìfẹ́. Gbogbo irú nǹkan wọ̀nyí sọ ayé yìí di ẹlẹ́gbin lójú Jèhófà. Àjàrà Sátánì ń so “èso ọ̀gbìn onímájèlé àti iwọ.” Ìwà tó ń fa ìparun tó ń hù àti ìbọ̀rìṣà rẹ̀ ń tàbùkù sí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá aráyé. (Diutarónómì 29:18; 32:5; Aísáyà 42:5, 8) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá gbáà ló jẹ́ láti máa bá ẹgbẹ́ Jòhánù ṣiṣẹ́ ìkórè ìṣùpọ̀ èso tó dára, èyí tí Jésù ń mú jáde fún ìyìn Jèhófà! (Lúùkù 10:2) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa pinnu pé àjàrà ayé yìí kì yóò fi àbààwọ́n yí wa lára, ká sì tipa báyìí yẹra fún dídi ẹni tí wọ́n tẹ̀ fọ́ pẹ̀lú àjàrà ilẹ̀ ayé nígbà tí Jésù bá mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ẹgbẹ̀jọ [1,600] fọ́lọ́ǹgì jẹ́ nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] kìlómítà, tàbí ọgọ́sàn-án [180] ibùsọ̀.—Ìṣípayá 14:20, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 208]

‘Wáìnì Àgbèrè Rẹ̀’

Apá títayọ nínú Bábílónì Ńlá ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Póòpù tó wà ní Róòmù ló ń ṣàkóso Ṣọ́ọ̀ṣì náà, wọ́n sì sọ pé àpọ́sítélì Pétérù ni póòpù kọ̀ọ̀kan ń rọ́pò. Àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí jẹ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n tẹ̀ jáde nípa àwọn póòpù tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ arọ́pò wọ̀nyí:

Formosus (ọdún 891 sí 896): “Ní oṣù mẹ́sàn-án lẹ́yìn ikú Formosus, wọ́n wú òkú rẹ̀ jáde kúrò nínú sàréè rẹ̀ tó wà ní yàrá abẹ́lẹ̀ ilé póòpù, wọ́n sì gbé e wá sílé ẹjọ́ fún ìjẹ́jọ́ níwájú ìgbìmọ̀ ‘tó ń kun òkú fún àyẹ̀wò,’ níbi tí Stephen [póòpù tuntun] ti ṣalága. Wọ́n fẹ̀sùn kan póòpù tó ti dolóògbé náà pé ìwárapàpà aláìníjàánu ló fi du ipò póòpù, wọ́n ní gbogbo ohun tó ṣe kò bẹ́tọ̀ọ́ mu. . . . Wọ́n bọ́ aṣọ póòpù kúrò lára òkú rẹ̀; wọ́n sì gé àwọn ìka ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.”—Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia.

Stephen Kẹfà (ọdún 896 sí 897): “Láàárín ìwọ̀nba oṣù díẹ̀ [tí wọ́n fi gbé òkú Formosus lọ sílé ẹjọ́,] rúgúdù táwọn kan dá sílẹ̀ fòpin sí ìgbà oyè Póòpù Stephen; wọ́n gba àmì ìdánimọ̀ tó fi í hàn gẹ́gẹ́ bí póòpù lọ́wọ́ rẹ̀, wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n, wọ́n sì fún un lọ́rùn pa.”—Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia.

Sergius Kẹta (ọdún 904 sí 911): “Ńṣe ni wọ́n fún àwọn méjì tó jẹ ṣáájú rẹ̀ . . . lọ́rùn pa lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. . . . Ìdílé Theophylactus wà lẹ́yìn rẹ̀ ní Róòmù, a tiẹ̀ gbọ́ pé Marozia tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Theophylactus, bí ọmọkùnrin kan fún un (ẹni tó wá di Póòpù John Kọkànlá).”—Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia.

Stephen Keje (ọdún 928 sí 931): “Láwọn ọdún tó gbẹ̀yìn ìgbà tí Póòpù John Kẹwàá wà lórí oyè . . . ó ṣe ohun tó múnú bí Marozia, tí í ṣe Donna Senatrix ti Róòmù, ìyẹn sọ ọ́ sẹ́wọ̀n ó sì tún pa á. Lẹ́yìn náà Marozia wá fi oyè póòpù dá Póòpù Leo Kẹfà lọ́lá, ẹni tó kú lẹ́yìn oṣù mẹ́fà ààbọ̀ tó gorí oyè. Stephen Keje ló gbapò rẹ̀, àfàìmọ̀ kó má sì jẹ́ pé Marozia ló mú kí èyí ṣeé ṣe. . . . Láàárín ọdún méjì tí Stephen Keje lò gẹ́gẹ́ bí Póòpù, kò lágbára kankan torí pé Marozia ló ń jẹ gàba lé e lórí.”—Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia.

John Kọkànlá (ọdún 931 sí 935): “Ní gbàrà tí Stephen Keje kú . . . , Marozia, ọmọbìnrin Theophylactus, gba ipò póòpù fún ọmọkùnrin rẹ̀ tó ń jẹ́ John, ẹni tó jẹ́ ọ̀dọ́ tó fi díẹ̀ lé lọ́mọ ogún ọdún. . . . Bí John sì ṣe jẹ́ póòpù yẹn náà, ńṣe ni ìyá rẹ̀ jẹ gàba lé e lórí.”—Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia.

John Kejìlá (ọdún 955 sí 964): “Eku káká ló fi pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, àwọn ìròyìn àkókò yẹn fohùn ṣọ̀kan pé kò nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan tó bá jẹ́ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, pé ńṣe ló ń jayé ní ìjẹkújẹ, àti pé ìgbé ayé oníwà wọ̀bìà ló gbé.”—The Oxford Dictionary of Popes.

Benedict Kẹsàn-án (ọdún 1032 sí 1044; 1045; 1047, 1048): “Gbogbo ibi ni wọ́n ti mọ̀ pé ó ta ipò póòpù fún ẹni tó dúró fún un bíi baba ìsàlẹ̀ nígbà ìsàmì rẹ̀, lẹ́yìn ìyẹn ó tún padà sórí oyè yẹn lẹ́ẹ̀kejì.”—Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica.

Nípa báyìí, kàkà káwọn póòpù yìí àtàwọn míì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pétérù olùṣòtítọ́, ńṣe ni wọ́n ń ṣe ibi. Wọ́n fàyè gba ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú àgbèrè tẹ̀mí àti tara, wọ́n tún fàyè gba àwọn ìwà bíi ti Jésíbẹ́lì, láti sọ ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń ṣàkóso dìbàjẹ́. (Jákọ́bù 4:4) Lọ́dún 1917, ìwé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, The Finished Mystery, sọ púpọ̀ lára àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ní kúlẹ̀kúlẹ̀. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọjọ́ wọnnì gbà ‘fi gbogbo onírúurú ìyọnu kọ lu ilẹ̀ ayé.’—Ìṣípayá 11:6; 14:8; 17:1, 2, 5.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 206]

Kristi tí Ọlọ́run gbé gorí ìtẹ́ ń ṣe ìdájọ́, àwọn áńgẹ́lì sì ń tì í lẹ́yìn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 207]

Lẹ́yìn tí wọ́n gba agbára ìjọba lọ́wọ́ Bábílónì lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Kristẹni, wọ́n dá àwọn tó kó nígbèkùn sílẹ̀