Bíbá Ẹranko Rírorò Méjì Wọ̀jà
Orí 28
Bíbá Ẹranko Rírorò Méjì Wọ̀jà
Ìran 8—Ìṣípayá 13:1-18
Ohun tó dá lé: Ẹranko ẹhànnà olórí méje náà, ẹranko ẹhànnà oníwo méjì, àti ère ẹranko ẹhànnà náà
Ìgbà tó nímùúṣẹ: Láti ọjọ́ Nímírọ́dù títí di ìgbà ìpọ́njú ńlá
1, 2. (a) Kí ni Jòhánù wí nípa dírágónì náà? (b) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ètò tó ṣeé fojú rí tí dírágónì náà ń lò?
ÁÀ, MÁÍKẸ́LÌ ti fi dírágónì náà sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé! Ohun tá a ti rí kọ́ nínú Ìṣípayá ti mú kó ṣe kedere pé Ọlọ́run ò ní gba Ejò náà tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láàyè láé láti padà sọ́run. Àmọ́, a ṣì wà lórí ọ̀rọ̀ “ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” Ohun tí Sátánì ń lò láti fi bá ‘obìnrin náà àti irú-ọmọ rẹ̀ jà’ ni àkọsílẹ̀ tó tẹ̀ lé e sọ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. (Ìṣípayá 12:9, 17) Jòhánù sọ nípa dírágónì tó rí tó dà bí ejò pé: “Ó sì dúró jẹ́ẹ́ lórí iyanrìn òkun.” (Ìṣípayá 13:1a) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí dírágónì náà ń lò.
2 Ọ̀rọ̀ pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń dá wàhálà sílẹ̀ lọ́run tó jẹ́ ibi mímọ́ ti dìtàn báyìí. Àfẹ́kù ti bá wọn lókè ọ̀run, wọn ò sì lè kọjá sàkáání ilẹ̀ ayé tí wọ́n wà báyìí mọ́. Ìdí rèé tí ìwà bí-èṣù-bí-èṣù fi ń pọ̀ sí i lọ́nà tó pabanbarì lóde òní. Ejò alárèékérekè yìí ṣì ní ètò ẹ̀mí tá ò lè fojú rí tó ti díbàjẹ́. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ó ń lo ètò tá a lè fojú rí láti ṣi aráyé lọ́nà? Jòhánù sọ fún wa pé: “Mo sì rí ẹranko ẹhànnà kan tí ń gòkè bọ̀ láti inú òkun, ó ní ìwo mẹ́wàá àti orí méje, adé dáyádémà mẹ́wàá sì wà lórí àwọn ìwo rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn orúkọ tí ó kún fún ọ̀rọ̀ òdì wà ní àwọn orí rẹ̀. Wàyí o, ẹranko ẹhànnà náà tí mo rí dà bí àmọ̀tẹ́kùn, ṣùgbọ́n ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bí ti béárì, ẹnu rẹ̀ sì dà bí ẹnu kìnnìún. Dírágónì náà sì fún ẹranko náà ní agbára rẹ̀ àti ìtẹ́ rẹ̀ àti ọlá àṣẹ ńlá.”—Ìṣípayá 13:1b, 2.
3. (a) Àwọn ẹranko rírorò wo ni wòlíì Dáníẹ́lì rí nínú ìran? (b) Kí ni àwọn ẹranko ẹhànnà títóbi tí Dáníẹ́lì orí 7 sọ̀rọ̀ wọn dúró fún?
3 Kí ni ẹranko abàmì yìí? Bíbélì fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè yẹn. Kó tó di pé àwọn ọmọ ogun ṣẹ́gun Bábílónì lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Kristẹni, Dáníẹ́lì wòlíì tó jẹ́ Júù rí àwọn ìran tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ẹranko rírorò. Nínú Dáníẹ́lì 7:2-8, ó ṣàpèjúwe ẹranko mẹ́rin tí ń jáde wá látinú òkun, èyí àkọ́kọ́ jọ kìnnìún, èkejì jọ béárì, ẹ̀kẹta àmọ̀tẹ́kùn, “sì wò ó! ẹranko kẹrin, tí ń bani lẹ́rù, tí ń jáni láyà, tí ó sì lágbára lọ́nà kíkàmàmà . . . ó sì ní ìwo mẹ́wàá.” Èyí jọ ẹranko ẹhànnà tí Jòhánù rí ní nǹkan bí ọdún 96 Sànmánì Kristẹni gan-an ni. Ẹranko náà fi àwọn nǹkan kan jọ kìnnìún, béárì àti àmọ̀tẹ́kùn, ó sì ní ìwo mẹ́wàá. Kí làwọn ẹranko títóbi tí Dáníẹ́lì rí dúró fún? Ó sọ fún wa pé: “Àwọn ẹranko títóbi fàkìàfakia yìí . . . [jẹ́] ọba mẹ́rin [tí] yóò dìde ní ilẹ̀ ayé.” (Dáníẹ́lì 7:17) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ẹranko wọ̀nyẹn dúró fún ‘àwọn ọba,’ tàbí àwọn ìjọba ayé.
4. (a) Nínú Dáníẹ́lì orí 8, kí ni àgbò àti òbúkọ náà dúró fún? (b) Kí ni ṣíṣẹ́ tí ìwo ńlá ti òbúkọ náà ní ṣẹ, tí ìwo mẹ́rin sì rọ́pò rẹ̀ fi hàn?
4 Nínú ìran mìíràn, Dáníẹ́lì rí àgbò oníwo méjì tí ewúrẹ́ tó ní ìwo ńlá kan lù bolẹ̀. Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí fún un, ó ní: “Àgbò . . . dúró fún àwọn ọba Mídíà àti Páṣíà. Òbúkọ onírun náà sì dúró fún ọba ilẹ̀ Gíríìsì.” Gébúrẹ́lì ń bá a lọ láti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìwo ńlá ti òbúkọ náà ni a óò ṣẹ́ tí ìwo mẹ́rin yóò sì rọ́pò rẹ̀. Èyí ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ ní ohun tó lé ní igba ọdún lẹ́yìn náà nígbà tí Alẹkisáńdà Ńlá kú, tí ìjọba rẹ̀ sì pín sí apá mẹ́rin èyí tí mẹ́rin lára àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ṣàkóso lé lórí.—Dáníẹ́lì 8:3-8, 20-25. a
5. (a) Èrò wo ni ọ̀rọ̀ táwọn Gíríìkì ń lò fún ẹranko gbé wá síni lọ́kàn? (b) Kí ni ẹranko ẹhànnà inú Ìṣípayá 13:1, 2 àti orí méje tó ní, dúró fún?
5 Nítorí náà, ó ṣe kedere pé ẹranko ni Ọlọ́run tó ni Bíbélì ka àwọn ìjọba ayé sí. Àmọ́, irú ẹranko wo? Ẹnì kan tó máa ń ṣàlàyé Bíbélì pe ẹranko ẹhànnà inú Ìṣípayá 13:1, 2 ní “òkú òǹrorò,” ó tún fi kún un pé: “A fara mọ́ gbogbo èrò tí ọ̀rọ̀ náà θηρίον [the·riʹon, ọ̀rọ̀ Gíríìkì fún “ẹranko”] gbé wá síni lọ́kàn, irú bí ẹran abàmì, oníkà, apanirun, ẹran tí ń da jìnnìjìnnì boni, ọ̀yánnú, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.” b Ẹ ò rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣàpèjúwe ètò ìjọba tó ti jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, èyí tí Sátánì ń lò láti jọba lé aráyé lórí! Orí méje tí ẹranko ẹhànnà yìí ní dúró fún àwọn agbára ayé pàtàkì mẹ́fà tí ìtàn inú Bíbélì fi hàn pé ó ti ṣàkóso lé ayé lórí títí dí ọjọ́ Jòhánù. Àwọn agbára ayé náà ni Íjíbítì, Ásíríà, Bábílónì, Mídíà òun Páṣíà, Gíríìsì, àti Róòmù, àti agbára ayé keje tí Bíbélì sọ nígbà ayé Jòhánù pé ó máa gba àkóso nígbà tó bá yá.—Fi wé Ìṣípayá 17:9, 10.
6. (a) Nínú kí ni orí méje ẹranko ẹhànnà náà ti gbapò iwájú? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe lo Róòmù láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ ní kíkún lórí ètò àwọn nǹkan Júù, báwo sì ni nǹkan ṣe rí fáwọn Kristẹni ní Jerúsálẹ́mù?
6 Ìtàn fi hàn lóòótọ́ pé yàtọ̀ sáwọn agbára ayé méje yẹn, àwọn agbára ayé mìíràn ṣì tún wà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹranko ẹhànnà tí Jòhánù rí ní ara kan àti orí méje àti ìwo mẹ́wàá. Àmọ́ orí méje náà dúró fún àwọn méje tó gbapò iwájú lára àwọn agbára ayé wọ̀nyẹn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ti mú ipò iwájú nínú ṣíṣe inúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run. Lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Róòmù ń ṣàkóso ayé, Sátánì lo orí ẹranko ẹhànnà yẹn láti pa Ọmọ Ọlọ́run. Lákòókò yẹn, Ọlọ́run pa ètò àwọn nǹkan Júù aláìnígbàgbọ́ tì, àti pé lẹ́yìn ìyẹn lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, ó yọ̀ǹda kí Róòmù mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ ní kíkún lórí orílẹ̀-èdè náà. Àmọ́, ó múni láyọ̀ pé Ísírẹ́lì Ọlọ́run, ìyẹn ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ti gbọ́ ìkìlọ̀ tẹ́lẹ̀, àwọn tí wọ́n sì wà ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà ti sá lọ sí ibi ààbò ní ìsọdá Odò Jọ́dánì.—Mátíù 24:15, 16; Gálátíà 6:16.
7. (a) Kí ni àkókò tó fún láti ṣẹlẹ̀ nígbà tí ètò àwọn nǹkan dópin tí ọjọ́ Olúwa sì bẹ̀rẹ̀? (b) Kí ni orí keje ẹranko ẹhànnà inú Ìṣípayá 13:1, 2?
7 Àmọ́, nígbà tí ọ̀rúndún kìíní fi máa parí, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà nínú ìjọ ìjímìjí yìí ló ti kúrò nínú òtítọ́, àwọn tí wọ́n sì jẹ́ àlìkámà Kristẹni tòótọ́, ìyẹn “àwọn ọmọ ìjọba náà,” ni àwọn èpò, ìyẹn “àwọn ọmọ ẹni burúkú náà,” ti fún pa. Ṣùgbọ́n nígbà tí ètò àwọn nǹkan yẹn dópin, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fara hàn lẹ́ẹ̀kan sí i gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan tí Ọlọ́run ti mú kó wà létòlétò. Ní ọjọ́ Olúwa, àkókò tó fáwọn olódodo láti máa “tàn yòò bí oòrùn.” Nítorí náà, ìjọ Kristẹni di èyí tá a múra rẹ̀ sílẹ̀ fún iṣẹ́. (Mátíù 13:24-30, 36-43) Nígbà yẹn, Ilẹ̀ Ọba Róòmù kò sí mọ́. Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì àti Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà alágbára ló wá ń ṣàkóso ayé. Ilẹ̀ méjèèjì yìí tó para pọ̀ jẹ́ agbára ayé, ni orí keje ẹranko ẹhànnà náà.
8. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká rí i bí ohun tó burú pé Bíbélì fi ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà tó ń ṣàkóso ayé wé ẹranko?
8 Ǹjẹ́ ohun tó burú jáì kọ́ ni bí Bíbélì ṣe pe ìjọba ayé ni ẹranko ẹhànnà? Ohun táwọn alátakò kan sọ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì nìyẹn, nígbà tí wọ́n pe irú ẹni tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lápapọ̀ àti lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ́ níjà, ní àwọn ilé ẹjọ́ yíká ayé. Àmọ́ rò ó wò ná! Ṣé àwọn orílẹ̀-èdè fúnra wọn kì í lo ẹranko tàbí àwọn ẹ̀dá ẹhànnà gẹ́gẹ́ bí àmì orílẹ̀-èdè wọn ni? Bí àpẹẹrẹ, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń lo kìnnìún, Amẹ́ríkà ń lo idì, Ṣáínà sì ń lo dírágónì. Nítorí náà, kí nìdí tẹ́nì kan fi ní láti ta kò ó bí Ẹni tó ni Bíbélì Mímọ́, ẹni tí ń bẹ ní ọ̀run, bá lo ẹranko láti fi ṣàpẹẹrẹ àwọn ìjọba ayé?
9. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ kéèyàn máa ta ko sísọ tí Bíbélì sọ pé Sátánì ló gbé agbára lé ẹranko ẹhànnà náà lọ́wọ́? (b) Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe Sátánì, báwo ló sì ṣe ń darí àwọn ìjọba?
9 Ẹ̀wẹ̀, kí nìdí tí ẹnikẹ́ni fi ní láti ta ko sísọ tí Bíbélì sọ pé Sátánì ló gbé agbára lé ẹranko ẹhànnà náà lọ́wọ́? Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló sọ gbólóhùn yẹn, àti pé lójú Ọlọ́run ńṣe ni ‘àwọn orílẹ̀-èdè dà bí ẹ̀kán omi kan láti inú korobá àti bí ekuru fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́.’ Ì bá sàn jù báwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí bá gbìyànjú láti wá ojúure Ọlọ́run dípò kí wọ́n máa bínú sí ọ̀nà tí Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ gbà ṣàpèjúwe wọn. (Aísáyà 40:15, 17; Sáàmù 2:10-12) Sátánì kì í ṣe ẹni ìtàn àròsọ kan tí wọ́n ní kó máa dá àwọn ọkàn tó ti kú lóró nínú hẹ́ẹ̀lì oníná. Àní irú ibi bẹ́ẹ̀ kò sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìwé Mímọ́ sọ pé Sátánì jọ “áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀,” olórí ẹlẹ̀tàn, tó ń darí gbogbo ọ̀ràn ìjọba ayé.—2 Kọ́ríńtì 11:3, 14, 15; Éfésù 6:11-18.
10. (a) Kí ni adé dáyádémà tó wà lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwo mẹ́wàá náà dúró fún? (b) Kí ni ìwo mẹ́wàá àti adé dáyádémà mẹ́wàá ṣàpẹẹrẹ?
10 Ẹranko ẹhànnà náà ní ìwo mẹ́wàá ní orí rẹ̀ méje. Bóyá orí mẹ́rin ní ìwo kọ̀ọ̀kan tí orí mẹ́ta sì ní ìwo méjì-méjì. Yàtọ̀ síyẹn, ó ní adé dáyádémà mẹ́wàá lórí àwọn ìwo rẹ̀. Ìwé Dáníẹ́lì ṣàpèjúwe àwọn ẹranko tí ń bani lẹ́rù, iye ìwo tí wọ́n ní sì jẹ́ iye gidi. Bí àpẹẹrẹ, ìwo méjì tó wà lórí àgbò kan dúró fún ilẹ̀ ọba méjì tí wọ́n para pọ̀, ìyẹn Mídíà àti Páṣíà, ìwo mẹ́rin tó wà lórí ewúrẹ́ kan sì dúró fún ilẹ̀ ọba mẹ́rin tó wà nígbà kan náà tí wọ́n jẹ yọ látinú ilẹ̀ ọba Gíríìsì tí Alẹkisáńdà Ńlá ṣàkóso lé lórí. (Dáníẹ́lì 8:3, 8, 20-22) Ṣùgbọ́n, ó jọ pé ńṣe ni ìwo mẹ́wàá tó wà lórí ẹranko tí Jòhánù rí ń ṣàpẹẹrẹ nǹkan kan. (Fi wé Dáníẹ́lì 7:24; Ìṣípayá 17:12.) Wọ́n dúró fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó ti dòmìnira tí wọ́n para pọ̀ di gbogbo ètò ìṣèlú Sátánì pátá. Gbogbo ìwo wọ̀nyí ló jẹ́ oníwà ipá àti oníjàgídíjàgan, àmọ́ gẹ́gẹ́ bí orí méje yẹn ṣe fi hàn, agbára ayé kan ṣoṣo ló máa ń wà ní ipò olórí ní àkókò kan. Bákan náà, adé dáyádémà mẹ́wàá fi hàn pé gbogbo orílẹ̀-èdè tó ti dòmìnira yóò máa ṣàkóso nígbà kan náà pẹ̀lú agbára ayé tó bá jẹ́ olórí lákòókò yẹn.
11. Kí ni níní tí ẹranko ẹhànnà náà ní ‘àwọn orúkọ tí ó kún fún ọ̀rọ̀ òdì ní àwọn orí rẹ̀’ fi hàn?
11 Ẹranko ẹhànnà náà ní ‘àwọn orúkọ tí ó kún fún ọ̀rọ̀ òdì ní àwọn orí rẹ̀,’ nítorí pé ó ń ṣe ohun kan tó fi ìwà àìlọ́wọ̀ ńláǹlà hàn fún Jèhófà Ọlọ́run àti Kristi Jésù. Ó fi orúkọ Ọlọ́run àti ti Kristi ṣe bojúbojú kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ ohun tó ń lé nínú ọ̀rọ̀ ìṣèlú. Ó ń bá ìsìn èké ṣiṣẹ́ pọ̀, àní ó tiẹ̀ gba àwọn àlùfáà láyè láti kópa nínú ìṣèlú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bíṣọ́ọ̀bù wà lára àwọn ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn kádínà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì wà nípò gíga nínú ìjọba ilẹ̀ Faransé àti Ítálì, àti pé láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn àlùfáà ti gba ipò òṣèlú ní Látìn Amẹ́ríkà. Àwọn ìjọba tẹ àwọn ọ̀rọ̀ ìsìn, irú bí “ỌLỌ́RUN LA GBẸ́KẸ̀ LÉ,” sára owó bébà wọn, àti pé wọ́n tún ń fi hàn nípasẹ̀ ohun tí wọ́n kọ sórí ẹyọ owó pé Ọlọ́run fọwọ́ sí àwọn alákòóso wọn. Bí àpẹẹrẹ wọ́n sọ pé “nípasẹ̀ oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run” ni wọ́n fi yan àwọn alákòóso wọ̀nyí. Ọ̀rọ̀ òdì gbáà ni gbogbo èyí jẹ́ nítorí pé ńṣe ni wọ́n ń gbìyànjú láti kọwọ́ Ọlọ́run bọ ìgbòkègbodò ìṣèlú tó ti díbàjẹ́.
12. (a) Kí ni jíjáde tí ẹranko ẹhànnà náà jáde látinú “òkun” túmọ̀ sí, ìgbà wo ló sì bẹ̀rẹ̀ sí í jáde? (b) Kí ni fífún tí dírágónì fún ẹranko ìṣàpẹẹrẹ náà ní agbára ńlá fi hàn?
12 Ẹranko ẹhànnà náà jáde wá látinú “òkun,” èyí tó dúró fún aráyé oníjàgídíjàgan látinú èyí tí ìjọba ẹ̀dá èèyàn ti jáde wá. (Aísáyà 17:12, 13) Àtìgbà ayé Nímírọ́dù (ìyẹn ní nǹkan bí ọ̀rúndún kọkànlélógún ṣááju Sànmánì Kristẹni) ni ẹranko ẹhànnà yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í jáde látinú aráyé oníjàgídíjàgan. Ìgbà yẹn, ìyẹn lẹ́yìn Ìkún-omi, ni ètò àwọn nǹkan tó ta ko Jèhófà kọ́kọ́ fara hàn. (Jẹ́nẹ́sísì 10:8-12; 11:1-9) Ọjọ́ Olúwa lèyí tó kẹ́yìn nínú orí méjèèje wá fara hàn pátápátá. Kíyè sí i pé dírágónì náà ló “fún ẹranko náà ní agbára rẹ̀ àti ìtẹ́ rẹ̀ àti ọlá àṣẹ ńlá.” (Fi wé Lúùkù 4:6.) Ẹranko náà ni ìjọba tí Sátánì dá sílẹ̀ láàárín aráyé. Dájúdájú, Sátánì ni “olùṣàkóso ayé yìí.”—Jòhánù 12:31.
Ọgbẹ́ Ikú
13. (a) Àjálù wo ló dé bá ẹranko ẹhànnà náà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa? (b) Báwo ló ṣe jẹ́ pé gbogbo ara ẹranko ẹhànnà náà lódindi ló ń jẹ̀rora nígbà tí orí kan gba ọgbẹ́ ikú?
13 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa, àjálù dé bá ẹranko ẹhànnà náà. Jòhánù sọ pé: “Mo sì rí ọ̀kan lára àwọn orí rẹ̀ bí ẹni pé a ṣá a pa, ṣùgbọ́n ọgbẹ́ ikú rẹ̀ sàn, gbogbo ilẹ̀ ayé sì tẹ̀ lé ẹranko ẹhànnà náà pẹ̀lú ìkansáárá.” (Ìṣípayá 13:3) Ẹsẹ yìí sọ pé ọ̀kan lára àwọn orí ẹranko ẹhànnà náà gba ọgbẹ́ ikú, ṣùgbọ́n ẹsẹ kejìlá sọ bí ẹni pé gbogbo ara ẹranko náà ló ń jẹ̀rora. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé kì í ṣe gbogbo orí tó wà lára ẹranko náà ló jọ ń ṣàkóso pa pọ̀. Nígbà tó bá yí kan ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, wọ́n á máa jẹ gàba lórí aráyé, ní pàtàkì lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Ìṣípayá 17:10) Ní báyìí tí ọjọ́ Olúwa ti bẹ̀rẹ̀, orí kan ṣoṣo, ìyẹn ìkeje ló mú ipò iwájú láti ṣàkóso ayé. Àmọ́, ọgbẹ́ ikú tí orí yẹn ni kó ìdààmú ńláǹlà bá gbogbo ara ẹranko náà lódindi.
14. Ìgbà wo ni ọkàn lára orí ẹranko náà gba ọgbẹ́ ikú, báwo sì ni ọ̀gágun kan ṣe ṣàpèjúwe ipa tí èyí ní lórí ẹranko ẹhànnà Sátánì?
14 Kí ni ọgbẹ́ ikú náà? Nígbà tó yá, Bíbélì pè é ní ọgbẹ́ idà, ogun jíjà sì ni idà ṣàpẹẹrẹ. Ọgbẹ́ idà tí wọ́n fún orí yìí níbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa ní láti ní í ṣe pẹ̀lú Ogun Àgbáyé Kìíní, èyí tó gbo ẹranko ẹhànnà ìṣèlú Sátánì jìgìjìgì, tó sì sọ ọ́ di ahẹrẹpẹ. (Ìṣípayá 6:4, 8; 13:14) Òǹṣèwé kan tó ń jẹ́ Maurice Genevoix, tó jẹ́ ọ̀gágun nígbà ogun yẹn, sọ nípa ogun náà pé: “Gbogbo èèyàn ló gbà pé látọjọ́ táláyé ti dáyé, ọjọ́ tó jẹ́ mánigbàgbé bí ọjọ́ kejì oṣù August ọdún 1914 kò tó nǹkan. Ogun náà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ Yúróòpù, nígbà tó yá, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn tí ń bẹ láyé ló bára ẹ̀ nínú ogun burúkú yìí. Gbogbo ohun tó jẹ́ ìpìlẹ̀ fún àwùjọ ni ogun náà mì, ó mi àwọn ìlànà táwọn èèyàn ń tẹ̀ lé, ó mi àdéhùn táwọn èèyàn ti ṣe, àtàwọn òfin tó jẹ mọ́ ìwà híhù; láti ọjọ́ dé ọjọ́, àwọn nǹkan ò lọ bó ṣe yẹ. Ìṣẹ̀lẹ̀ náà kì í wulẹ̀ ṣe èrò burúkú téèyàn ń rò lọ́kàn, ó sì kọjá ohun tá a retí pé kó ṣẹlẹ̀. Ó ga jù, yánpọnyánrin gbáà ni, ó bani lẹ́rù gidigidi. Àní ràbọ̀ràbọ̀ rẹ̀ ò tíì tán nílẹ̀.”—Maurice Genevoix, tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Académie Française, tí wọ́n fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú ìwé náà Promise of Greatness (1968).
15. Báwo ni orí keje ẹranko ẹhànnà náà ṣe gba ọgbẹ́ ikú?
15 Ogun yẹn ṣe jàǹbá ńlá fún orí keje tí ẹranko ẹhànnà náà ní. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí àwọn ọ̀dọ́kùnrin ló ṣòfò nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti làwọn orílẹ̀-èdè míì nílẹ̀ Yúróòpù. Nínú Ìjà Ogun Odò Somme tó wáyé lọ́dún 1916 nìkan ṣoṣo, àwọn sójà ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó kú sógun yẹn jẹ́ ọ̀kẹ́ mọ́kànlélógún [420,000], àwọn sójà ilẹ̀ Faransé tó kú tó nǹkan bí ẹgbàá mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún [194,000], ti ilẹ̀ Jámánì sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjìlélógún [440,000]. Áà, gbogbo òkú ọ̀hún lé ní mílíọ̀nù kan! Ètò ọrọ̀ ajé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti tàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tó wà nílẹ̀ Yúróòpù dẹnu kọlẹ̀. Ogun ọ̀hún gbo ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jìgìjìgì, kò sì padà bọ̀ sípò mọ́. Lóòótọ́, ńṣe ni ogun yẹn tí orílẹ̀-èdè méjìdínlọ́gbọ̀n tó jẹ́ òléwájú kópa nínú rẹ̀, mú gbogbo ayé ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n. Ní August 4, 1979, ìyẹn lẹ́yìn ọdún márùnlélọ́gọ́ta péré tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ́ sílẹ̀, ìwé ìròyìn náà The Economist, ti ìlú London nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, sọ pé: “Ọdún 1914 ni gbogbo nǹkan ti wọ́, kò sì tíì tó pa dà látìgbà yẹn.”
16. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, báwo ni orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ apá kan agbára ayé?
16 Pẹ̀lú bí gbogbo nǹkan ṣe rí yìí, Ogun Àgbáyé Kìíní, tí wọ́n pè ní Ogun Ńlá nígbà yẹn, mú kí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fara hàn kedere gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tóun àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jọ jẹ́ agbára ayé. Láwọn ọdún àkọ́kọ́ tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, ohun táwọn èèyàn ń sọ kò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bá wọn lọ́wọ́ sí i. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí òpìtàn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Esmé Wingfield-Stratford ṣe sọ, “ohun tí gbogbo ọ̀ràn náà dá lé lórí ni pé bóyá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà á jẹ́ yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín àwọn méjèèjì lákòókò tí wàhálà bá aráyé nílé lóko yìí, kí wọ́n gbàgbé ọ̀rọ̀ àná níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọwọ́ wọn wọ ọwọ́ gan-an, abẹ́ wọn sì lọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè wà.” Bọ́rọ̀ sì ṣe wá rí gan-an nìyẹn, nítorí pé àwọn méjèèjì gbà fúnra wọn. Lọ́dún 1917, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi owó, ohun ìjà, àtàwọn ológun ṣèrànlọ́wọ́ fáwọn orílẹ̀-èdè tó pawọ́ pọ̀ jagun nígbà ogun àgbáyé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ń dọwọ́ àárẹ̀ fún wọn. Bó ṣe di pé orí keje, ìyẹn àpapọ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ṣẹ́gun nìyẹn o.
17. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ètò Sátánì ti orí ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ogun náà?
17 Lẹ́yìn tí ogun náà parí, gbogbo nǹkan yí padà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọgbẹ́ ikú náà gbo ètò Sátánì ti orí ilẹ̀ ayé jìgìjìgì, síbẹ̀ ó sọ jí ó tún wá lágbára ju ti ìgbàkigbà rí lọ débi pé àwọn èèyàn wá ń kan sáárá sí i nítorí pé ó jèrè okun rẹ̀ pa dà.
18. Ọ̀nà wo ni aráyé gbà ń fi ‘ìkansáárá tẹ̀ lé ẹranko ẹhànnà náà’?
18 Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Charles L. Mee, Kékeré, kọ̀wé pé: “Nígbà tí gbogbo nǹkan ti dorí kodò tí kò rí bó ṣe yẹ kó rí mọ [látàrí Ogun Àgbáyé Kìíní tó jà], ó wá di dandan káwọn èèyàn máa jà fún ìjọba ara wọn, káwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn ẹgbẹ́ máa jà fún òmìnira, àní ariwo òmìnira ló kù táráyé ń pa.” Orí keje ẹranko ẹhànnà náà, èyí tí ọgbẹ́ rẹ̀ ti sàn ló ń mú ipò iwájú nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń wáyé lẹ́yìn ogun, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sì ń tẹ̀ síwájú nísinsìnyí láti kó ipa pàtàkì nínú rẹ̀. Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà wá mú ipò iwájú nínú ṣíṣe alágbàwí àjọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Nígbà tó fi máa di ọdún 2005, ìjọba Amẹ́ríkà ti ran àwọn orílẹ̀-èdè tọ́wọ́ wọn tó ẹnu lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé tó gbé pẹ́ẹ́lí sí i, wọ́n ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbógun ti àrùn, àti láti mú ìmọ̀ ẹ̀rọ tẹ̀ síwájú. Ó tiẹ̀ ti gbé èèyàn méjìlá dénú òṣùpá. Abájọ táráyé ṣe ń fi ‘ìkansáárá tẹ̀ lé ẹranko ẹhànnà náà.’
19. (a) Kí ni nǹkan míì táráyé ń ṣe yàtọ̀ sí pé kí wọ́n máa kan sáárá sí ẹranko ẹhànnà náà? (b) Ta ló ní agbára lórí gbogbo ìjọba ayé, báwo la sì ṣe mọ̀? (d) Báwo ni Sátánì ṣe gbé agbára lé ẹranko ẹhànnà náà lọ́wọ́, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀ lórí ọ̀pọ̀ èèyàn?
19 Ohun táráyé ń ṣe tiẹ̀ ju pé kí wọ́n máa kan sáárá sí ẹranko ẹhànnà náà. Jòhánù sọ pé: “Wọ́n sì jọ́sìn dírágónì náà nítorí pé ó fún ẹranko ẹhànnà náà ní ọlá àṣẹ, wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà: ‘Ta ni ó dà bí ẹranko ẹhànnà náà, ta sì ni ó lè bá a jagun?’” (Ìṣípayá 13:4) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé ńbí, Sátánì sọ pé òun láṣẹ lórí gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé. Jésù kò bá a jiyàn; kódà Jésù fúnra rẹ̀ pe Sátánì ní olùṣàkóso ayé ó sì kọ̀ láti kópa nínú ètò ìṣèlú ìgbà yẹn. Lẹ́yìn náà Jòhánù kọ̀wé nípa àwọn Kristẹni tòótọ́ pé: “A mọ̀ pé a pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19; Lúùkù 4:5-8; Jòhánù 6:15; 14:30) Sátánì gbé agbára lé ẹranko ẹhànnà náà lọ́wọ́, kó lè máa fi agbára náà ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè. Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé dípò tí ìfẹ́ bíi ti Ọlọ́run á fi so aráyé pọ̀ ṣọ̀kan, ńṣe ni ẹ̀mí ẹ̀yà tèmi lọ̀gá, ìran tèmi ló dáa jù, àti orílẹ̀-èdè tèmi làkọ́kọ́ ń pín wọn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ìyẹn gan-an ló fi wá já sí pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló ń jọ́sìn apá èyíkéyìí lára ẹranko ẹhànnà yìí tó bá ṣáà ti ń ṣàkóso nílẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn ń kan sáárá sí ẹranko ẹhànnà náà lódindi, wọ́n sì ń sìn ín.
20. (a) Ọ̀nà wo làwọn èèyàn gbà ń jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà? (b) Kí nìdí táwọn Kristẹni tí ń jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run kò fi bá wọn jọ́sìn ẹranko ẹhànnà yìí, àpẹẹrẹ ta sì ni wọ́n ń tẹ̀ lé?
20 Ọ̀nà wo làwọn èèyàn gbà ń jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà? Wọ́n ń sìn ín ní ti pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wọn ju Ọlọ́run lọ. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló fẹ́ràn ìlú ìbílẹ̀ wọn. Èèyàn rere làwọn Kristẹni tòótọ́ náà láàárín ìlú, wọ́n ń bọ̀wọ̀ fáwọn alákòóso àtohun ìṣàpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé, wọ́n ń pa òfin mọ́, wọ́n sì ń ṣe ohun tó ń ṣe ìlú àtàwọn aládùúgbò wọn láǹfààní. (Róòmù 13:1-7; 1 Pétérù 2:13-17) Àmọ́, kì í ṣe pé wọ́n fẹ́ràn orílẹ̀-èdè kan kí wọ́n wá kórìíra ìyókù. Kò bá ẹ̀kọ́ Kristẹni mu láti máa ní èrò pé “orílẹ̀-èdè wa ló jàre, yálà ohun tó ṣe tọ̀nà tàbí kò tọ̀nà.” Nítorí náà, àwọn Kristẹni tí wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run ò lè máa jọ́sìn apá èyíkéyìí lára ẹranko ẹhànnà náà, nítorí èyí yóò já sí jíjọ́sìn dírágónì náà, ìyẹn ẹni tó fún ẹranko náà ní agbára. Wọn ò lè máa kan sáárá sí i pé: “Ta ló dà bí ẹranko ẹhànnà náà?” Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Máíkẹ́lì, ẹni tórúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Ta Ní Dà Bí Ọlọ́run?” bí wọ́n ṣe ń gbé Jèhófà ga bí ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Ní àkókò tí Ọlọ́run yàn, Máíkẹ́lì yìí, ìyẹn Kristi Jésù, yóò bá ẹranko ẹhànnà náà jagun yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀, gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣẹ́gun Sátánì tó sì lé e kúrò lọ́run.—Ìṣípayá 12:7-9; 19:11, 19-21.
Bíbá Àwọn Ẹni Mímọ́ Jagun
21. Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe bí Sátánì ṣe ń darí ẹranko ẹhànnà náà?
21 Sátánì alárèékérekè mọ bó ṣe ń darí ẹranko ẹhànnà náà láti ṣe ohun tó fẹ́. Jòhánù ṣàlàyé èyí, ó ní: “A sì fún un [ìyẹn ẹranko ẹhànnà olórí méje náà] ní ẹnu tí ń sọ àwọn ohun ńlá àti ọ̀rọ̀ òdì, a sì fún un ní ọlá àṣẹ láti gbéṣẹ́ṣe fún oṣù méjìlélógójì. Ó sì la ẹnu rẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, láti sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ rẹ̀ àti ibùgbé rẹ̀, àní àwọn tí ń gbé ní ọ̀run pàápàá. A sì yọ̀ǹda fún un láti bá àwọn ẹni mímọ́ ja ogun àti láti ṣẹ́gun wọn, a sì fún un ní ọlá àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n àti orílẹ̀-èdè. Gbogbo àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé yóò sì jọ́sìn rẹ̀; a kò kọ orúkọ ẹnì kankan nínú wọn sínú àkájọ ìwé ìyè ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn tí a fikú pa, láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 13:5-8.
22. (a) Ìgbà wo ni oṣù méjìlélógójì náà ń tọ́ka sí? (b) Láàárín oṣù méjìlélógójì náà, báwo ni wọ́n ṣe “ṣẹ́gun” àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró?
22 Ó dà bíi pé ọ̀kan náà ni oṣù méjìlélógójì tí ibí yìí mẹ́nu kàn já sí pẹ̀lú ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ tí ìwo kan tó hù lára ọ̀kan nínú àwọn ẹranko inú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì fi fòòró àwọn ẹni mímọ́. (Dáníẹ́lì 7:23-25; tún wo Ìṣípayá 11:1-4.) Abájọ tó fi jẹ́ pé láti òpin ọdún 1914 títí wọnú 1918, bí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń bára wọn jà tí wọ́n ń fara wọn ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ bí ìgbà tí ẹranko ẹhànnà méjì ń jà, èyí mú kí wọ́n máa fúngun mọ́ àwọn tó ń gbé làwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí láti jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà kí wọ́n lè fi ara jìn fún orílẹ̀-èdè wọn, kí wọ́n sì ṣe tán láti kú fún orílẹ̀-èdè wọn pàápàá. Bí wọ́n ṣe ń fúngun mọ́ wọn yìí mú kí wọ́n fìyà ńlá jẹ ọ̀pọ̀ ẹni àmì òróró, ìyẹn àwọn tó gbà pé Jèhófà Ọlọ́run àti Kristi Jésù, Ọmọ rẹ̀ làwọn gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí. (Ìṣe 5:29) Àdánwò wọ́n dópin ní June 1918, nígbà tí wọ́n ‘ṣẹ́gun’ àwọn ẹni àmì òróró. Ní Amẹ́ríkà, wọ́n sọ àwọn tó ń mú ipò iwájú àtàwọn míì tó jẹ́ aṣojú Watch Tower Society sẹ́wọ̀n láìṣẹ̀ láìrò, èyí sì ṣèdíwọ́ ńláǹlà fún iṣẹ́ ìwàásù táwọn arákùnrin wọn ń ṣe. Nítorí pé ẹranko ẹhànnà náà ní ọlá àṣẹ “lórí gbogbo ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n àti orílẹ̀-èdè,” ó gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ Ọlọ́run kárí ayé.
23. (a) Kí ni “àkájọ ìwé ìyè ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” kí ló sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí látọdún 1918 wá? (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ńṣe ni ètò Sátánì tó ṣeé fojú rí ń tanra ẹ̀ bó bá rò pé òun ti ṣẹ́gun “àwọn ẹni mímọ́” pátápátá?
23 Ó wá dà bíi pé Sátánì àti ètò rẹ̀ ti ṣẹ́gun pátápátá. Ṣùgbọ́n èyí ò lè mú àǹfààní tó tọ́jọ́ kankan wá fún wọn, nítorí pé kò sí ẹnì kankan nínú ètò Sátánì tó ṣeé fojú rí tí orúkọ rẹ̀ wá nínú “àkájọ ìwé ìyè ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Àmọ́, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, orúkọ àwọn tí yóò bá Jésù ṣàkóso nínú Ìjọba rẹ̀ ti ọ̀run wà nínú àkájọ ìwé yìí. Àkọ́kọ́ nínú àwọn orúkọ yìí ni a kọ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Ọ̀pọ̀ orúkọ ni wọ́n sì ti fi kún un látìgbà náà wá. Látọdún 1918 wá, fífi èdìdì di àwọn tó ṣẹ́ kù lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ajogún Ìjọba náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí. Láìpẹ́, orúkọ gbogbo wọn ni a óò kọ sínú àkájọ ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà. Ní ti àwọn alátakò tí ń jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà, kò sí ìkankan nínú wọn tí a kọ orúkọ rẹ̀ sínú àkájọ ìwé yẹn. Nítorí náà, tí wọ́n bá rò pé àwọn ti ṣẹ́gun “àwọn ẹni mímọ́” pátápátá, ńṣe ni wọ́n ń tanra wọn jẹ, fúngbà díẹ̀ lásán ni.
24. Kí ni Jòhánù ní káwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye gbọ́, kí sì ni ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn Ọlọ́run gbọ́ fi hàn pé wọ́n ní láti ṣe?
24 Wàyí o, Jòhánù ké sí àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye pé kí wọ́n fetí sílẹ̀ dáadáa, ó ní: “Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí, kí ó gbọ́.” Lẹ́yìn náà, ó ń bá a lọ láti sọ pé: “Bí a bá pinnu ẹnikẹ́ni fún oko òǹdè, òun a lọ sí oko òǹdè. Bí ẹnikẹ́ni yóò bá fi idà pani, a gbọ́dọ̀ fi idà pa á. Níhìn-ín ni ibi tí ó ti túmọ̀ sí ìfaradà àti ìgbàgbọ́ àwọn ẹni mímọ́.” (Ìṣípayá 13:9, 10) Kó tiẹ̀ tó di 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni ni Jeremáyà ti kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó jọ ìwọ̀nyí láti fi hàn pé ó di dandan kí ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ lé Jerúsálẹ́mù lórí. (Jeremáyà 15:2; tún wo Jeremáyà 43:11; Sekaráyà 11:9.) Lákòókò tí Jésù dojú kọ àdánwò ńlá, ó fi yé àwọn ọmọlẹ́yìn pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wọn. Ó ní: “Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:52) Bákan náà, ní báyìí tá a ti wà ní ọjọ́ Olúwa, àwọn èèyàn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ di ìlànà Bíbélì mú ṣinṣin. Kì yóò sí àjàbọ́ kankan fáwọn aláìronúpìwàdà tí ń jọ́sìn ẹranko ẹhànnà. Gbogbo wa yóò nílò ìfaradà àti ìgbàgbọ́ tí kò ṣeé mì láti lè bọ́ nínú inúnibíni àtàwọn àdánwò tí ń bẹ níwájú.—Hébérù 10:36-39; 11:6.
Ẹranko Ẹhànnà Oníwo Méjì
25. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ mìíràn tó jáde wá? (b) Kí ni ìwo méjì tí ẹranko ẹhànnà tuntun yìí ní àti jíjáde tó jáde wá látinú ilẹ̀ ayé fi hàn?
25 Ẹranko ẹhànnà míì ló wá jáde wá báyìí. Jòhánù ròyìn pé: “Mo sì rí ẹranko ẹhànnà mìíràn tí ń gòkè bọ̀ láti inú ilẹ̀ ayé, ó sì ní ìwo méjì bí ọ̀dọ́ àgùntàn, ṣùgbọ́n ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ bíi dírágónì. Ó sì ń lo gbogbo ọlá àṣẹ ẹranko ẹhànnà àkọ́kọ́ lójú rẹ̀. Ó sì ń mú kí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ jọ́sìn ẹranko ẹhànnà àkọ́kọ́ náà, èyí tí ọgbẹ́ ikú rẹ̀ sàn. Ó sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì ńláǹlà, tó bẹ́ẹ̀ tí yóò tilẹ̀ mú kí iná sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run sí ilẹ̀ ayé lójú aráyé.” (Ìṣípayá 13:11-13) Ẹranko ẹhànnà yìí ní ìwo méjì, tó fi hàn pé ìjọba alágbára méjì ló para pọ̀. Jòhánù sì sọ pé látinú ilẹ̀ ayé ló ti jáde wá, kì í ṣe látinú òkun. Èyí túmọ̀ sí pé ó wá látinú ètò àwọn nǹkan ti Sátánì tó ti fìdí múlẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ó ní láti jẹ́ ìjọba alágbára kan, tó ti wà tẹ́lẹ̀, tó wá ń kó ipa pàtàkì ní ọjọ́ Olúwa.
26. (a) Kí ni ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà, báwo ló sì ṣe tan mọ́ ẹranko ẹhànnà àkọ́kọ́? (b) Báwo ni àwọn ìwo ẹranko náà ṣe dà bíi ti ọ̀dọ́ àgùntàn, báwo ló sì ṣe rí “bíi dírágónì” bó bá ń sọ̀rọ̀? (d) Tá a bá ní ká sọ ọ́, kí làwọn tó bá lẹ́mìí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ń sìn, kí la sì ti fi ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni wé? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
26 Irú ìjọba wo ló lè dúró fún ná? Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà tó jẹ́ agbára ayé, tó sì jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú orí keje ẹranko ẹhànnà àkọ́kọ́ àmọ́ tó ń ko ipa pàtàkì ni! Wíwà tó dá wà gedegbe nínú ìràn yìí gẹ́gẹ́ bí ẹranko ẹhànnà kan láàyè ara ẹ̀ jẹ́ ká túbọ̀ rí i kedere bó ṣe ń ṣe gudugudu lóun nìkan. Ẹranko ẹhànnà ìṣàpẹẹrẹ oníwo méjì yìí jẹ́ àpapọ̀ agbára ìṣèlú méjì tí wọ́n wà nígbà kan náà, tí wọ́n dá dúró, ṣùgbọ́n tí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Ìwo rẹ̀ méjèèjì “bí ọ̀dọ́ àgùntàn” jẹ́ àmì pé ó ń fi ara rẹ̀ hàn bí oníwà tútù àti aláìlè-ṣeniléṣe, ó tún ń fi hàn pé òun ní ìjọba kan tó dára tó yẹ kí gbogbo èèyàn máa wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó ń sọ̀rọ̀ “bí dírágónì” ní ti pé bó ṣe ń fúngun mọ́ni ló ń halẹ̀ mọ́ni tó tún ń lo ìwà ipá pàápàá níbi yòówù táwọn èèyàn ò bá ti fara mọ́ ọ̀nà tó gbà ń ṣàkóso. Kò rọ àwọn èèyàn láti tẹrí ba fún Ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ ìṣàkóso Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, dípò ìyẹn ìfẹ́ inú Sátánì, dírágónì ńlá náà ló ń ṣe. Ó ti rúná sí ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni lọ́kàn àwọn èèyàn, ìyẹn sì ti mú káwọn orílẹ̀-èdè yapa síra wọn, kí wọ́n sì kórìíra ara wọn. Bẹ́ẹ̀, ẹni tó bá nírù ẹ̀mí yìí, ẹranko ẹhànnà àkọ́kọ́ ló ń sìn. c
27. (a) Kí ni mímú tí ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà mú kí iná sọ̀ kalẹ̀ wá látọ̀run fi hàn nípa ìwà rẹ̀? (b) Ojú wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wo alábàádọ́gba ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà lóde òní?
27 Ẹranko ẹhànnà oníwo méjì yìí ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì ńláńlá, kódà ó ń mú kí iná sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run. (Fi wé Mátíù 7:21-23.) Àmì tá a sọ gbẹ̀yìn yìí rán wa létí Èlíjà, wòlíì Ọlọ́run ìgbàanì tó bá àwọn wòlíì Báálì wọ̀jà. Nígbà tó ní kí iná sọ̀ kalẹ̀ wá látọ̀run ní orúkọ Jèhófà tó sì rí bẹ́ẹ̀, èyí fi hàn kedere pé wòlíì tòótọ́ ni, àti pé, wòlíì èké làwọn wòlíì Báálì. (1 Àwọn Ọba 18:21-40) Bíi tàwọn wòlíì Báálì, ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà gbà pé òun ní ẹ̀rí tó pọ̀ tó láti jẹ́ wòlíì. (Ìṣípayá 13:14, 15; 19:20) Họ́wù, ó sọ pé òun ti rẹ́yìn ẹgbẹ́ ogun olubi nínú ogun àgbáyé méjèèjì, ó sì ṣẹ́gun ohun tá a mọ̀ sí ìjọba Kọ́múníìsì tí kò náání Ọlọ́run! Ó dájú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wo ohun tí ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà dúró fún lóde òní gẹ́gẹ́ bí ohun tó máa sọ àwọn èèyàn dòmìnira tó sì máa fún wọn ní àwọn ohun ìní tara tó dára.
Ère Ẹranko Ẹhànnà Náà
28. Báwo ni Jòhánù ṣe fi hàn pé ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà kì í ṣe oníwà tútù gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwo rẹ̀ tí ó dà bíi ti àgùntàn ṣe fi hàn?
28 Ǹjẹ́ oníwà tútù ni ẹranko ẹhànnà oníwo méjì yìí gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwo rẹ̀ tó rí bíi ti ọ̀dọ́ àgùntàn ṣe fi hàn? Jòhánù sọ pé: “Ó sì ń ṣi àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé lọ́nà, nítorí àwọn iṣẹ́ àmì tí a yọ̀ǹda fún un láti ṣe lójú ẹranko ẹhànnà náà, bí ó ti ń sọ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé láti yá ère ẹranko ẹhànnà tí ó ní ọgbẹ́ idà, síbẹ̀ tí ó sọjí. A sì yọ̀ǹda fún un láti fi èémí fún ère ẹranko ẹhànnà náà, kí ère ẹranko ẹhànnà náà lè sọ̀rọ̀, kí ó sì mú kí a pa gbogbo àwọn tí kì yóò jọ́sìn ère ẹranko ẹhànnà náà lọ́nà èyíkéyìí.”—Ìṣípayá 13:14, 15.
29. (a) Kí ni ère ẹranko ẹhànnà náà pinnu láti ṣe, ìgbà wo ni wọ́n sì mọ ère yìí? (b) Kí nìdí tí ère ẹranko ẹhànnà yìí kì í fi í ṣe ère aláìlẹ́mìí?
29 Kí ni “ère ẹranko ẹhànnà” yìí, kí sì lohun tó pinnu láti ṣe? Ó pinnu láti gbé ìjọsìn ẹranko ẹhànnà olórí méje náà ga èyí tí òun jẹ́ ère fún, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹranko ẹhànnà náà wà títí lọ kánrin. Lẹ́yìn tí ẹranko ẹhànnà olórí méje náà sọ jí látinú ọgbẹ́ idà rẹ̀ ni wọ́n mọ ère yìí, ìyẹn lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí. Kì í ṣe ère aláìlẹ́mìí, bí irú èyí tí Nebukadinésárì mọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà o. (Dáníẹ́lì 3:1) Ẹranko ẹhànnà oníwo méjì náà mí èémí ìyè sínú ère yìí kí ère náà lè wà láàyè kó sì kópa nínú ọ̀ràn aráyé.
30, 31. (a) Kí ni ìtàn fi hàn pé ère yìí jẹ́? (b) Ǹjẹ́ wọ́n ti pa ẹnikẹ́ni fún kíkọ̀ láti jọ́sìn ère yìí? Ṣàlàyé.
30 Bí ọ̀ràn ṣe ń lọ sí nínú ayé fi hàn pé ère náà jẹ́ àjọ tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà dábàá, tí wọ́n ń ṣagbátẹrù rẹ̀, tí wọ́n sì jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún, ìyẹn àjọ tá a mọ̀ sí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè níbẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nínú Ìṣípayá orí 17, àjọ yìí yóò fara hàn lẹ́ẹ̀kan sí i lábẹ́ àmì ìṣàpẹẹrẹ mìíràn, ìyẹn gẹ́gẹ́ bí òòyẹ̀ ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tí ń mí, tí ó dá dúró. Àjọ yìí tí ó kárí ayé ‘ń sọ̀rọ̀,’ ní ti pé ó ń fọ́nnu pé òun nìkan ṣoṣo lòun lè mú àlàáfíà àti àìléwu wá fún aráyé. Àmọ́ àjọ yìí ti di ibi táwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú àjọ náà ti sọ òkò ọ̀rọ̀ lura tí wọ́n sì fi ìwọ̀sí lọ ara wọn. Àjọ yìí sọ pé tí orílẹ̀-èdè èyíkéyìí tàbí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ láti tẹrí ba fún ọlá àṣẹ òun, pé ńṣe lòun máa ta á nù lẹ́gbẹ́, tàbí kóun pa á sóòró. Òótọ́ kúkú ni, àjọ Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n kùnà láti tẹ̀ lé àbá rẹ̀. Níbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá, apá tó jẹ́ ti ológun lara “ìwo” ère ẹranko ẹhànnà náà yóò mú àsọtẹ́lẹ̀ kan ṣẹ.—Ìṣípayá 7:14; 17:8, 16.
31 Látìgbà Ogun Àgbáyé Kejì wá ni ère ẹranko ẹhànnà yìí, tó fara hàn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ti ń pààyàn. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1950, agbo ológun àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lọ sójú ogun nígbà tí ogun jà láàárín àwọn ará Àríwá Kòríà àtàwọn ará Gúúsù Kòríà. Nígbà tí wọ́n fojú bu iye àwọn ará Àríwá Kòríà àti ti Ṣáínà táwọn ológun àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti ti Gúúsù Kòríà pa, ó tó nǹkan bí ọ̀kẹ́ mọ́kànléláàádọ́rin [1,420,000]. Bákan náà, látọdún 1960 sí 1964, ẹgbẹ́ ológun àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè jà fitafita ní orílẹ̀-èdè Kóńgò (Kinshasa). Síwájú sí i, àwọn aṣáájú ayé, títí kan Póòpù Paul Kẹfà àti Póòpù John Paul Kejì, ti ń bá a lọ láti polongo pé ère yìí ló máa gba aráyé sílẹ̀, pé òun sì ló máa fún aráyé ní àlàáfíà. Wọ́n tẹnu mọ́ ọn pé, bí aráyé bá kùnà láti sìn ín, ìparun yóò dé bá ìran èèyàn. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ pa gbogbo ẹ̀dá èèyàn tí wọ́n kọ̀ láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ère náà tí wọn ò sì jọ́sìn rẹ̀.—Diutarónómì 5:8, 9.
Àmì Ẹranko Ẹhànnà
32. Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ọ̀nà tí Sátánì gbà ń darí apá tó jẹ́ ti ìṣèlú lára ètò rẹ̀ tó ṣeé fojú rí kó lè kó ìyà jẹ àwọn tó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ obìnrin Ọlọ́run?
32 Jòhánù ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí bí Sátánì ṣe ń darí àwọn apá tó jẹ́ ti ìṣèlú nínú ètò rẹ̀ tó ṣeé fojú rí kó lè fi baríbakú ìyà jẹ àwọn tó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ obìnrin Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ó ń bá àpèjúwe “ẹranko ẹhànnà náà” nìṣó báyìí pé: “Ó sì ṣe é ní ọ̀ranyàn fún gbogbo ènìyàn, ẹni kékeré àti ẹni ńlá, àti ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, àti òmìnira àti ẹrú, pé kí wọ́n fún àwọn wọ̀nyí ní àmì kan ní ọwọ́ ọ̀tún wọn tàbí ní iwájú orí wọn, àti pé kí ẹnì kankan má lè rà tàbí tà àyàfi ẹni tí ó bá ní àmì náà, orúkọ ẹranko ẹhànnà náà tàbí nọ́ńbà orúkọ rẹ̀. Níhìn-ín ni ibi tí ọgbọ́n ti wọlé: Kí ẹni tí ó ní làákàyè gbéṣirò lé nọ́ńbà ẹranko ẹhànnà náà, nítorí pé nọ́ńbà ènìyàn ni; nọ́ńbà rẹ̀ sì ni ọgọ́rùn-ún mẹ́fà, ẹẹ́wàá mẹ́fà, àti ẹyọ mẹ́fà.”—Ìṣípayá 13:16-18.
33. (a) Kí ni orúkọ ẹranko ẹhànnà náà? (b) Kí ni nọ́ńbà náà ẹẹ́fà dúró fún? Ṣàlàyé.
33 Ẹranko ẹhànnà náà ní orúkọ kan, nọ́ńbà sì ni orúkọ yìí, ìyẹn 666. Ẹẹ́fà jẹ́ nọ́ńbà kan tó ṣàpẹẹrẹ àwọn ọ̀tá Jèhófà. Ọkùnrin ará Filísíà kan láti Réfáímù “tóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, . . . àwọn ìka ọwọ́ àti ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ mẹ́fà-mẹ́fà.” (1 Kíróníkà 20:6) Ọba Nebukadinésárì gbé ère wúrà tí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà tí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́ kalẹ̀ láti mú káwọn lọ́gàálọ́gàá tó ń bá a ṣèjọba wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn kan ṣoṣo. Nígbà táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kọ̀ láti jọ́sìn ère wúrà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n jù wọ́n sínú iná ìléru. (Dáníẹ́lì 3:1-23) Nọ́ńbà náà ẹẹ́fà dín sí eéje, bẹ́ẹ̀ kẹ̀ ohun tó pé pérépéré ni eéje dúró fún lójú Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹẹ́fà ní ìlọ́po mẹ́ta dúró fún àìpé tó bùáyà.
34. (a) Kí ni jíjẹ́ tí nọ́ńbà ara ẹranko ẹhànnà náà jẹ́ “nọ́ńbà ènìyàn” fi hàn? (b) Kí nìdí tí 666 fi jẹ́ orúkọ tó bá a mu fún ètò ìṣèlú ayé ti Sátánì?
34 Orúkọ máa ń fi ohun téèyàn jẹ́ hàn. Nítorí náà báwo ni nọ́ńbà yìí ṣe jẹ́ ká mọ irú ẹni tí ẹranko náà jẹ́? Jòhánù sọ pé ó jẹ́ “nọ́ńbà ènìyàn,” kì í ṣe ti ẹni ẹ̀mí, nítorí náà orúkọ náà jẹ́ ká rí i dájú pé ẹranko ẹhànnà náà jẹ́ ti ilẹ̀ ayé, ìjọba èèyàn ló sì dúró fún. Gẹ́gẹ́ bí ẹẹ́fà ti dín sí eéje, bẹ́ẹ̀ náà ni 666, ìyẹn ẹẹ́fà ní ìpele mẹ́ta, jẹ́ orúkọ tó bá a mu fún ètò ìṣèlú ayé èyí tó ti kùnà pátápátá láti kúnjú ìwọ̀n ìlànà Ọlọ́run tó jẹ́ pípé. Ẹranko ẹhànnà ìṣèlú ti ayé ń ṣàkóso ní ipò gíga jù lọ lábẹ́ orúkọ onínọ́ńbà náà 666, àmọ́ àwọn ìṣèlú ńláńlá, ìsìn ńláńlá, àti iṣẹ́ ajé ńláńlá ń mú kí ẹranko ẹhànnà yẹn máa pọ́n aráyé lójú kó sì tún máa ṣe inúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run.
35. Kí ló túmọ̀ sí láti gba àmì orúkọ ẹranko ẹhànnà náà sí iwájú orí tàbí sí ọwọ́ ọ̀tún?
35 Kí ló túmọ̀ sí láti gba àmì orúkọ ẹranko ẹhànnà náà sí iwájú orí tàbí sí ọwọ́ ọ̀tún? Nígbà tí Jèhófà fún Ísírẹ́lì ní Òfin, ó sọ fún wọn pé: “Kí ẹ . . . fi ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí ọkàn-àyà yín àti ọkàn yín, kí ẹ sì dè wọ́n gẹ́gẹ́ bí àmì mọ́ ọwọ́ yín, wọn yóò sì jẹ́ ọ̀já ìgbàjú láàárín àwọn ojú yín.” (Diutarónómì 11:18) Èyí túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti máa fiyè sí Òfin náà nígbà gbogbo, kí ó bàa lè máa nípa lórí gbogbo ìṣesí àti ìrònú wọn. Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ẹni àmì òróró ni a sọ pé wọ́n ní orúkọ Baba àti ti Jésù tí a kọ sí iwájú orí wọn. Èyí fi hàn pé wọ́n jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi. (Ìṣípayá 14:1) Sátánì náà ṣe àfarawé, ó lo àmì ẹlẹ́mìí èṣù ti ẹranko ẹhànnà náà. Ó wá ń sọ ọ́ di dandan fún ẹnikẹ́ni tó bá ń lọ́wọ́ nínú ètò káràkátà ojoojúmọ́ láti máa ṣe àwọn nǹkan lọ́nà tí ẹranko ẹhànnà náà ń gbà ṣe é, àpẹẹrẹ kan ni ti ṣíṣayẹyẹ ọdún. Ó ń retí pé kí wọ́n jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà, kí wọ́n jẹ́ kó máa darí ìgbésí ayé wọn, kí wọ́n bàa lè gba àmì rẹ̀.
36. Ìṣòro wo làwọn tí wọ́n kọ̀ láti gba àmì ẹranko ẹhànnà náà ní?
36 Àwọn tí wọ́n kọ̀ láti gba àmì ẹranko ẹhànnà náà ń ní ìṣòro nígbà gbogbo. Bí àpẹẹrẹ, bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ọdún 1930, àìmọye ìgbà làwọn kan tí fojú ba ilé ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí, àwọn èèyànkéèyàn ti ṣe àwọn míì léṣe, nígbà táwọn míì fojú winá inúnibíni. Láwọn orílẹ̀-èdè ìjọba oníkùmọ̀, wọ́n sọ àwọn míì sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, ọ̀pọ̀ lára wọn sì kú sọ́hùn-ún. Látìgbà Ogun Àgbáyé Kejì, àìmọye ọ̀dọ́kùnrin ni wọ́n fi sẹ́wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ, wọ́n dá àwọn kan lóró, wọ́n pa àwọn míì, nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, kò ṣeé ṣe fáwọn Kristẹni láti rà tàbí kí wọ́n tà; kò tiẹ̀ ṣeé ṣe fáwọn kan láti ní dúkìá tara wọn; wọ́n fipá bá àwọn mìíràn lò pọ̀, wọ́n pa àwọn míì, wọ́n sì lé àwọn míì kúrò ní ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn. Kí nìdí? Nítorí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ra káàdì ẹgbẹ́ ìṣèlú. d—Jòhánù 17:16.
37, 38. (a) Kí nìdí tí ayé fi jẹ́ ibi tó ṣòro fáwọn tí wọ́n kọ̀ láti gba àmì ẹranko ẹhànnà náà? (b) Àwọn wo ni wọn ń pa ìwà títọ́ mọ́, kí ni wọ́n sì ti pinnu láti ṣe?
37 Ní àwọn ibì kan lórí ilẹ̀ ayé, ìsìn ti kó wọ àwọn èèyàn lórí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé ẹnikẹ́ni tó bá mú ìdúró rẹ̀ fún òtítọ́ Bíbélì ni ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ máa ń ta nù. Ó gba pé kéèyàn nígbàgbọ́ tó lágbára láti lè fara dà á. (Mátíù 10:36-38; 17:22) Nínú ayé tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ti ń lé ọrọ̀ yìí, tí ìwà àìṣòótọ́ sì gbòde kan, Kristẹni tòótọ́ ní láti fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kó sì dá a lójú pé Jèhófà ò ní pa òun tì bóun ò bá ṣíwọ́ láti máa ṣe ohun tó tọ́. (Sáàmù 11:7; Hébérù 13:18) Nínú ayé tí ìṣekúṣe ti gbòde yìí, ó gba pé kí wọ́n dúró gbọn-in ti ìpinnu wọn láti wà ní mímọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn dókítà àtàwọn olùtọ́jú aláìsàn máa ń yọ àwọn Kristẹni tí wọ́n dùbúlẹ̀ àìsàn lẹ́nu kí wọ́n lè rú òfin Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀; àwọn Kristẹni wọ̀nyí sì máa ń kọ̀ jálẹ̀ bí ilé ẹjọ́ tiẹ̀ pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ohun tó lòdì sí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (Ìṣe 15:28, 29; 1 Pétérù 4:3, 4) Àti pé láwọn àkókò tí àìníṣẹ́lọ́wọ́ ń ga sí i yìí, ó túbọ̀ ń ṣòro fún Kristẹni tòótọ́ láti kọ iṣẹ́ tó máa mú kó ṣe ohun tó lòdì sí ìwà títọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run.—Míkà 4:3, 5.
38 Kò sírọ́ ńbẹ̀, ayé jẹ́ ibi tó ṣòro fáwọn tí kò gba àmì ẹranko ẹhànnà náà. Àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ń jẹ́ ká rí ọwọ́ agbára Jèhófà àti bó ṣe ń fìbùkún rẹ̀ sórí àwọn tó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ obìnrin náà, tó fi mọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá tí iye wọn lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà tí wọ́n ń pa ìwà títọ́ mọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn náà ní ohun tó ń tì wọ́n gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n kí wọ́n bàa lè rú òfin Ọlọ́run. (Ìṣípayá 7:9) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa jákèjádò ilẹ̀ ayé máa bá a nìṣó ní gbígbé Jèhófà àti àwọn ọ̀nà òdodo rẹ̀ ga, bá a ṣe ń kọ̀ láti gba àmì ẹranko ẹhànnà náà.—Sáàmù 34:1-3.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, jọ̀wọ́ wo ojú ìwé 165 sí 179 nínú ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé náà.
b Ìwé The Interpretation of St. John’s Revelation, láti ọwọ́ R. C. H. Lenski, ojú ìwé 390 sí 391.
c Àwọn ọ̀mọ̀wé sọ pé ìjọsìn ni ẹ̀mí orílẹ̀-èdè tèmi lọ̀gá já sí. Fún ìdí yìí, ńṣe làwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ onífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ń jọ́sìn apá tí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé ń ṣojú fún lára ẹranko ẹhànnà náà. Ohun kan rèé tẹ́nì kan kọ nípa ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó ní: “Ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, tí a wò gẹ́gẹ́ bí ìjọsìn, kò yàtọ̀ sí àwọn ètò ìsìn ńlá ti ìgbà àtijọ́ . . . Ńṣe làwọn tó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wọn ju tàwọn mìíràn lọ ka orílẹ̀-èdè wọn sí ọlọ́run wọn, òun ni wọ́n sì gbára lé. Wọ́n gbà pé òun ló lágbára láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n sì tún gbà pé òun ló lè fún àwọn ní ìjẹ́pípé àti ayọ̀. Òun ni wọ́n ń tẹrí ba fún tó bá di ti ọ̀ràn ìsìn. . . . Wọ́n gbà pé orílẹ̀-èdè àwọn máa wá títí gbére, àti pé ńṣe ni ikú àwọn ọmọ rẹ̀ adúróṣinṣin wúlẹ̀ ń fi kún òkìkí àti ògo rẹ̀ tí kì í pa rẹ́.”—Ọ̀rọ̀ Carlton J. F. Hayes tí wọ́n fà yọ ní ojú ìwé 359 ìwé náà, What Americans Believe and How They Worship, látọwọ́ J. Paul Williams.
d Bí àpẹẹrẹ, wo Ile-Iṣọ Na ti May 15, 1972, ojú ìwé 311 àti 312; December 15, 1974, ojú ìwé 754; December 1, 1975, ojú ìwé 726 àti 727; January 1, 1980, ojú ìwé 23; December 1, 1979, ojú ìwé 20; November 15, 1980, ojú ìwé 10.
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 195]
A yọ̀ǹda fún un láti fi èémí fún ère ẹranko ẹhànnà náà