Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fífi Èdìdì Di Ísírẹ́lì Ọlọ́run

Fífi Èdìdì Di Ísírẹ́lì Ọlọ́run

Orí 19

Fífi Èdìdì Di Ísírẹ́lì Ọlọ́run

Ìran 4—Ìṣípayá 7:1-17

Ohun tó dá lé: A fi èdìdì di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], a rí ogunlọ́gọ̀ ńlá tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ Jèhófà àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn

Ìgbà tó nímùúṣẹ: Látìgbà tá a ti gbé Kristi Jésù gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914 títí dìgbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún rẹ̀

1. ‘Ta ló lè dúró’ lọ́jọ́ ìkannú ńlá Ọlọ́run?

 “TA NI ó sì lè dúró?” (Ìṣípayá 6:17) Bẹ́ẹ̀ ni lóòótọ́, ta ló lè dúró? Nígbà tí ètò Sátánì bá pa run ní ọjọ́ ìkannú ńlá Ọlọ́run, àwọn olùṣàkóso àti gbogbo olùgbé ayé lè bi ara wọn ní ìbéèrè yẹn. Lójú wọn á jọ bí ẹni pé ìṣẹ̀lẹ̀ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ náà yóò pa gbogbo ẹ̀dá run pátápátá. Àmọ́, ṣé bọ́rọ̀ á ṣe rí nìyẹn? A láyọ̀ láti mọ̀ pé wòlíì Ọlọ́run mú kó dá wa lójú pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́.” (Jóẹ́lì 2:32) Àpọ́sítélì Pétérù àti Pọ́ọ̀lù túbọ̀ mú kí ìyẹn dáni lójú. (Ìṣe 2:19-21; Róòmù 10:13) Láìsí àníàní, àwọn tó bá ké pe orúkọ Jèhófà ni wọ́n á là á já. Àwọn wo nìyẹn ná? Bí ìran tó tẹ̀ lé e ti ń ṣí payá, a óò máa mọ̀ wọ́n.

2. Kí nìdí tó fi jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu pé a máa rẹ́ni táá la ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà já?

2 Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé a lè rẹ́ni tó máa la ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà kọjá láàyè, nítorí pé òmíràn lára àwọn wòlíì Ọlọ́run ṣàpèjúwe bí ọjọ́ náà ṣe máa rí báyìí pé: “Wò ó! Ìjì ẹlẹ́fùúùfù ti Jèhófà, ìhónú pàápàá, ti jáde lọ, ìjì líle tí ń gbá nǹkan lọ. Yóò fẹ́ yí ká sórí àwọn ẹni burúkú. Ìbínú jíjófòfò Jèhófà kì yóò yí padà títí yóò fi ní ìmúṣẹ ní kíkún àti títí yóò fi mú èrò ọkàn-àyà rẹ̀ ṣẹ.” (Jeremáyà 30:23, 24) Ó jẹ́ kánjúkánjú pé ká gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti la ìjì yẹn kọjá láàyè!—Òwe 2:22; Aísáyà 55:6, 7; Sefanáyà 2:2, 3.

Ẹ̀fúùfù Mẹ́rin Náà

3. (a) Àkànṣe iṣẹ́ táwọn áńgẹ́lì ṣe wo ni Jòhánù rí? (b) Kí ni “ẹ̀fúùfù mẹ́rin” náà ṣàpẹẹrẹ?

3 Kí Jèhófà tó tú ìhónú yìí jáde, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run ṣe àkànṣe iṣẹ́ kan. Ìyẹn ni Jòhánù wá rí nínú ìran báyìí, ó sọ pé: “Lẹ́yìn èyí, mo rí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí wọ́n dúró lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé, wọ́n di ẹ̀fúùfù mẹ́rin ilẹ̀ ayé mú pinpin, kí ẹ̀fúùfù kankan má bàa fẹ́ sórí ilẹ̀ ayé tàbí sórí òkun tàbí sórí igi èyíkéyìí.” (Ìṣípayá 7:1) Kí ni èyí túmọ̀ sí fún wa lónìí? Lọ́nà tó ṣe kedere, “ẹ̀fúùfù mẹ́rin” yìí ń ṣàpẹẹrẹ ìdájọ́ ìparun tí Jèhófà máa tóó tú jáde sórí ẹgbẹ́ àwùjọ ilẹ̀ ayé burúkú kan, sórí “òkun” ríru ti aráyé aláìlófin, àti sórí àwọn olùṣàkóso bí igi gíga fíofío táwọn èèyàn ilẹ̀ ayé ń gbárùkù tì tí wọ́n sì tún jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún.—Aísáyà 57:20; Sáàmù 37:35, 36.

4. (a) Kí làwọn áńgẹ́lì mẹ́rin náà dúró fún? (b) Táwọn áńgẹ́lì náà bá tú ẹ̀fúùfù mẹ́rin yìí sílẹ̀, kí ló máa yọrí sí fún ètò Sátánì ti orí ilẹ̀ ayé?

4 Láìsí iyè méjì, àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin yìí dúró fún àwùjọ àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin, àwọn ẹni tí Jèhófà ń lò láti dá ìmúṣẹ ìdájọ́ dúró títí di àkókò tó ti yàn. Nígbà táwọn áńgẹ́lì náà bá tú ẹ̀fúùfù ìkannú Ọlọ́run wọ̀nyẹn sílẹ̀ láti fẹ́ ní àfẹ́yíká lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láti àríwá, gúúsù, ìlà oòrùn, àti ìwọ̀ oòrùn, ìparun náà yóò pọ̀ rẹpẹtẹ. Yóò fara jọ lílò tí Jèhófà lo ẹ̀fúùfù mẹ́rin láti tú àwọn ará Élámù ká, tó fọ́ wọn túútúú, tó sì pa wọ́n run; lílò tí Jèhófà tún wá fẹ́ lò ó yìí a pabanbarì. (Jeremáyà 49:36-38) Ẹ̀fúùfù ìjì tí ìtóbi rẹ̀ kàmàmà lèyí á jẹ́, agbára ìparun rẹ̀ á pọ̀ ju ti ‘ẹ̀fúùfù líle’ tí Jèhófà fi pa orílẹ̀-èdè Ámónì run. (Ámósì 1:13-15) Kò sí apá kankan lára ètò Sátánì lórí ilẹ̀ ayé tí yóò lágbára láti dúró ní ọjọ́ ìhónú Jèhófà, nígbà tó bá dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre títí láé fáàbàdà.—Sáàmù 83:15, 18; Aísáyà 29:5, 6.

5. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti lóye pé àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run yóò kan gbogbo ilẹ̀ ayé?

5 Ṣó dájú pé ìdájọ́ Ọlọ́run á kan gbogbo ilẹ̀ ayé? Tún tẹ́tí sílẹ̀ sí wòlíì rẹ̀ Jeremáyà: “Wò ó! Ìyọnu àjálù kan ń jáde lọ láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè, ìjì líle sì ni a ó ru dìde láti apá jíjìnnàréré jù lọ ní ilẹ̀ ayé. Àwọn tí Jèhófà pa yóò sì wà dájúdájú ní ọjọ́ yẹn láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ ayé títí lọ dé ìpẹ̀kun kejì ilẹ̀ ayé.” (Jeremáyà 25:32, 33) Àkókò ìjì ẹlẹ́fùúùfù líle yìí ni òkùnkùn yóò bo ayé. Ọlọ́run á mi àwọn aṣojú rẹ̀ tí ń ṣàkóso, wọ́n á sì dẹni ìgbàgbé. (Ìṣípayá 6:12-14) Àmọ́ ṣá o, gbogbo èèyàn kọ́ lọjọ́ ọ̀la máa ṣókùnkùn fún o. Nítorí àwọn wo la ṣe wá dá “ẹ̀fúùfù mẹ́rin” náà dúró?

Fífi Èdìdì Di Àwọn Ẹrú Ọlọ́run

6. Ta ló sọ fáwọn áńgẹ́lì náà pé kí wọ́n dá ẹ̀fúùfù mẹ́rin náà dúró, kí nìyẹn sì ṣí ààyè sílẹ̀ fún?

6 Jòhánù ń bá a lọ láti ṣàpèjúwe bá a ó ṣe sàmì sí àwọn kan fún lílà á já, ó wí pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń gòkè láti ibi yíyọ oòrùn, ó ní èdìdì Ọlọ́run alààyè; ó sì ké pẹ̀lú ohùn rara sí àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí a yọ̀ǹda fún láti pa ilẹ̀ ayé àti òkun lára, pé: ‘Ẹ má ṣe pa ilẹ̀ ayé tàbí òkun tàbí àwọn igi lára, títí di ẹ̀yìn ìgbà tí a bá fi èdìdì di àwọn ẹrú Ọlọ́run wa ní iwájú orí wọn.’”—Ìṣípayá 7:2, 3.

7. Ẹni wo gan-an ni áńgẹ́lì karùn-ún yìí, kí ló sì ràn wá lọ́wọ́ láti fìdí ẹni tó jẹ́ múlẹ̀?

7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò dárúkọ áńgẹ́lì karùn-ún yìí, gbogbo ẹ̀rí fi hàn pé kò lè jẹ́ ẹlòmíì yàtọ̀ sí Jésù Olúwa tá a ti ṣe lógo. A fi hàn níbí pé ó ní ọlá àṣẹ lórí àwọn áńgẹ́lì yòókù, ìyẹn sì bá ipò rẹ̀ mu gẹ́gẹ́ bí olú áńgẹ́lì. (1 Tẹsalóníkà 4:16; Júúdà 9) Ó gòkè wá láti ìlà oòrùn, bí “àwọn ọba láti ibi yíyọ oòrùn” ìyẹn, Jèhófà àti Kristi rẹ̀, tí wọ́n dé láti mú ìdájọ́ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ọba Dáríúsì àti Kírúsì ti ṣe nígbà tí wọ́n rẹ Bábílónì ìgbàanì sílẹ̀. (Ìṣípayá 16:12; Aísáyà 45:1; Jeremáyà 51:11; Dáníẹ́lì 6:1) Áńgẹ́lì yìí tún jọ Jésù pẹ̀lú ní ti pé ìkáwọ́ rẹ̀ ni fífi èdìdì di àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wà. (Éfésù 1:13, 14) Síwájú sí i, nígbà tá a tú àwọn ẹ̀fúùfù náà sílẹ̀, Jésù lẹni tó ṣáájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run láti mú ìdájọ́ ṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè. (Ìṣípayá 19:11-16) Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé kó jẹ́ Jésù lẹni tí yóò pàṣẹ pé kí a dá ìparun ètò Sátánì ti orí ilẹ̀ ayé dúró títí tí a óò fi fi èdìdì di àwọn ẹrú Ọlọ́run.

8. Kí ni fífi èdìdì dì náà jẹ́, nígbà wo ni ó sì bẹ̀rẹ̀?

8 Kí ni fífi èdìdì dì yìí jẹ́, àwọn wo sì ni ẹrú Ọlọ́run wọ̀nyí? Fífi èdìdì dì bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni nígbà tí Ọlọ́run fẹ̀mí mímọ́ yan àwọn Júù tó kọ́kọ́ di Kristẹni. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run pe “àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè,” ó sì fòróró yàn wọ́n. (Róòmù 3:29; Ìṣe 2:1-4, 14, 32, 33; 15:14) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní ẹ̀rí tó dájú pé wọ́n “jẹ́ ti Kristi” ó sì fi kún un pé Ọlọ́run “tún ti fi èdìdì rẹ̀ sórí wa, ó sì ti fún wa ní àmì ìdánilójú ohun tí ń bọ̀, èyíinì ni, ẹ̀mí náà, tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:21, 22; fi wé Ìṣípayá 14:1.) Torí náà, nígbà tí Ọlọ́run sọ àwọn ẹrú wọ̀nyí di ọmọ rẹ̀ tẹ̀mí, wọ́n ń gba àmì ìdánilójú kan, ìyẹn èdìdì ṣáájú ogún wọn ti ọ̀run. (2 Kọ́ríńtì 5:1, 5; Éfésù 1:10, 11) Wọ́n lè sọ nígbà náà pé: “Ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Nígbà náà, bí àwa bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá pẹ̀lú: àwọn ajogún Ọlọ́run ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, kìkì bí a bá jọ jìyà pa pọ̀, kí a lè ṣe wá lógo pa pọ̀ pẹ̀lú.”—Róòmù 8:15-17.

9. (a) Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró ọmọ Ọlọ́run ní ìfaradà? (b) Báwo ni ìdánwò àwọn ẹni àmì òróró yóò ti máa bá a nìṣó pẹ́ tó?

9 “Kìkì bí a bá jọ jìyà pa pọ̀”—kí nìyẹn túmọ̀ sí? Káwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bàa lè gba adé ìyè, wọ́n gbọ́dọ̀ fara dà, kí wọ́n sì ṣòótọ́ títí dójú ikú. (Ìṣípayá 2:10) Kì í ṣe ọ̀ràn ‘ìgbàlà lẹ́ẹ̀kan, ìgbàlà gbogbo ìgbà.’ (Mátíù 10:22; Lúùkù 13:24) Kàkà bẹ́ẹ̀, a ṣí wọn létí pé: “Ẹ túbọ̀ máa sa gbogbo ipá yín láti mú pípè àti yíyàn yín dájú fún ara yín.” Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, wọ́n gbọ́dọ̀ lè sọ níkẹyìn pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.” (2 Pétérù 1:10, 11; 2 Tímótì 4:7, 8) Nítorí náà, lórí ilẹ̀ ayé ńbí, dídán àwọn tí wọ́n ṣẹ́ kù lára àwọn ọmọ Ọlọ́run tá a fẹ̀mí bí wò àti sísẹ́ wọn mọ́ yóò máa bá a lọ títí tí Jésù àtàwọn áńgẹ́lì tó wà pẹ̀lú rẹ̀ á fi lẹ èdìdì náà pa ‘sí iwájú orí’ gbogbo àwọn wọ̀nyí, láti fi hàn láìsí iyè méjì, àti lọ́nà tí kò ṣeé yí pa dà pé wọ́n jẹ́ “àwọn ẹrú Ọlọ́run wa” tá a ti dán wò tí wọ́n sì jẹ́ olùṣòtítọ́. Èdìdì yìí á wá di àmì wíwà títí lọ. A mọ̀ pé nígbà táwọn áńgẹ́lì náà á bá fi tú ẹ̀fúùfù ìpọ́njú mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dà sílẹ̀, gbogbo Ísírẹ́lì tẹ̀mí la óò ti fi èdìdì dì pátápátá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ ṣì lè wà láàyè nínú ẹran ara. (Mátíù 24:13; Ìṣípayá 19:7) Gbogbo àwọn tó wà lára Ísírẹ́lì tẹ̀mí yóò ti pé pérépéré!—Róòmù 11:25, 26.

Àwọn Mélòó La Fi Èdìdì Dì?

10. (a) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló fi hàn pé iye àwọn tá a fi èdìdì dì mọ níwọ̀n? (b) Kí ni àròpọ̀ iye àwọn tá a fi èdìdì dì, báwo la sì ṣe tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ?

10 Jésù sọ fáwọn tá a máa fi èdìdì dì yìí pé: “Má bẹ̀rù, agbo kékeré, nítorí pé Baba yín ti tẹ́wọ́ gba fífi ìjọba náà fún yín.” (Lúùkù 12:32) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn, irú bí Ìṣípayá 6:11 àti Róòmù 11:25, fi hàn pé iye agbo kékeré yìí mọ níwọ̀n gan-an, àti pé a tiẹ̀ ti pinnu iye náà tẹ́lẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ Jòhánù tó tẹ̀ lé e túbọ̀ mú èyí dájú: “Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì dì, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, tí a fi èdìdì dì láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: Láti inú ẹ̀yà Júdà, ẹgbẹ̀rún méjìlá ni a fi èdìdì dì; láti inú ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹgbẹ̀rún méjìlá; láti inú ẹ̀yà Gádì, ẹgbẹ̀rún méjìlá; láti inú ẹ̀yà Áṣérì, ẹgbẹ̀rún méjìlá; láti inú ẹ̀yà Náfútálì, ẹgbẹ̀rún méjìlá; láti inú ẹ̀yà Mánásè, ẹgbẹ̀rún méjìlá; láti inú ẹ̀yà Síméónì, ẹgbẹ̀rún méjìlá; láti inú ẹ̀yà Léfì, ẹgbẹ̀rún méjìlá; láti inú ẹ̀yà Ísákárì, ẹgbẹ̀rún méjìlá; láti inú ẹ̀yà Sébúlúnì, ẹgbẹ̀rún méjìlá; láti inú ẹ̀yà Jósẹ́fù, ẹgbẹ̀rún méjìlá; láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, ẹgbẹ̀rún méjìlá ni a fi èdìdì dì.”—Ìṣípayá 7:4-8.

11. (a) Kí ló fà á tí ẹ̀yà méjìlá tí Bíbélì sọ níbí yìí ò fi lè túmọ̀ sí Ísírẹ́lì tara? (b) Kí ló fà á tí Ìṣípayá fi ṣàkọsílẹ̀ ẹ̀yà méjìlá lẹ́sẹẹsẹ? (d) Kí nìdí tí kò fi sí ẹ̀yà kan tó jẹ́ ti ọlọ́ba tàbí ti àlùfáà nìkan nínú Ísírẹ́lì Ọlọ́run?

11 Àbí ó wa lè jẹ́ pé Ísírẹ́lì tara lèyí ń tọ́ka sí? Bẹ́ẹ̀ kọ́, nítorí pé Ìṣípayá 7:4-8 ò lo àkọsílẹ̀ ẹ̀yà tó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀. (Númérì 1:17, 47) Ó dájú pé a ò lo àkọsílẹ̀ ẹ̀yà tibí yìí láti fi dá ẹ̀yà táwọn Júù tara ti wá mọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe la lò ó láti fi ìṣètò Ísírẹ́lì tẹ̀mí tó fara jọ ọ́ hàn. Ó sì ṣe wẹ́kú. Nítorí pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] géérégé ló gbọ́dọ̀ jẹ́ ara orílẹ̀-èdè tuntun yìí, ẹgbàafà [12,000] látinú ọ̀kọ̀ọ̀kan lára ẹ̀yà méjìlá. Kò sí ẹ̀yà kankan nínú Ísírẹ́lì Ọlọ́run yìí tá a yà sọ́tọ̀ gédégbé fún ipò ọlọ́ba tàbí ti àlùfáà nìkan. Gbogbo orílẹ̀-èdè náà ni yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba, gbogbo wọn náà ni yóò sì sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.—Gálátíà 6:16; Ìṣípayá 20:4, 6.

12. Kí nìdí tó fi bá a mu wẹ́kú pé káwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà fi àwọn ọ̀rọ̀ Ìṣípayá 5:9, 10 kọrin níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà?

12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù àbínibí àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù ló kọ́kọ́ láǹfààní láti di àwọn tí Ọlọ́run yàn sí Ísírẹ́lì tẹ̀mí, ìwọ̀nba kéréje látinú orílẹ̀-èdè yẹn ló tẹ́wọ́ gba àǹfààní náà. Nítorí náà, Jèhófà nasẹ̀ àǹfààní náà dé ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí. (Jòhánù 1:10-13; Ìṣe 2:4, 7-11; Róòmù 11:7) Bó ti rí nínú ọ̀ràn àwọn ará Éfésù, tá a ti sọ di “àjèjì sí ìpínlẹ̀ ìjọba Ísírẹ́lì” tẹ́lẹ̀ rí, ó ti wá ṣeé ṣe báyìí láti lo ẹ̀mí Ọlọ́run láti fi èdìdì dì àwọn tí kì í ṣe Júù, kí wọ́n sì di apá kan ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. (Éfésù 2:11-13; 3:5, 6; Ìṣe 15:14) Bó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ó bá a mu wẹ́kú fáwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] láti kọrin níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà pé: “O sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ ra àwọn ènìyàn fún Ọlọ́run láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè, o sì mú kí wọ́n jẹ́ ìjọba kan àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.”—Ìṣípayá 5:9, 10.

13. Kí nìdí tó fi bá a mu pé Jákọ́bù iyèkan Jésù darí lẹ́tà rẹ̀ “sí ẹ̀yà méjìlá tí ó tú ká káàkiri”?

13 Ìjọ Kristẹni jẹ́ “ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́.” (1 Pétérù 2:9) Nítorí pé ó rọ́pò Ísírẹ́lì àbínibí gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè Ọlọ́run, ó di Ísírẹ́lì tuntun kan tí í ṣe “‘Ísírẹ́lì’ ní ti gidi.” (Róòmù 9:6-8; Mátíù 21:43) a Fún ìdí yìí, ó bá a mu pé Jákọ́bù iyèkan Jésù darí lẹ́tà rẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà agbo “sí ẹ̀yà méjìlá tí ó tú ká káàkiri,” èyíinì ni, sí ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kárí ayé tí iye wọn á wá jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000].—Jákọ́bù 1:1.

Ísírẹ́lì Ọlọ́run Lónìí

14. Kí ló fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò yéé sọ pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, kò-lé-kò-dín ni iye àwọn tó para pọ̀ di Ísírẹ́lì tẹ̀mí?

14 Ó dùn mọ́ni pé Charles T. Russell, mọ̀ pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] géérégé, kò-lé-kò-dín, làwọn tí wọ́n para pọ̀ di Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Nínú ìwé The New Creation, Ìdìpọ̀ Kẹfà nínú Studies in the Scriptures rẹ̀, tá a tẹ̀ jáde lọ́dún 1904, ó kọ̀wé pé: “Ní gbogbo ọ̀nà ló fi yẹ ká gbà gbọ́ pé iye pàtó, tí kò lé tí kò sì dín ti àwọn àyànfẹ́ [ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró] ni iye tá a sọ láwọn ìgbà mélòó kan nínú Ìṣípayá (7:4; 14:1); iye náà ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ‘tí a rà padà láti inú àárín àwọn ènìyàn.’” Bákan náà, nínú ìwé Light, Ìwé Kìíní, táwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ̀ jáde lọ́dún 1930, a sọ bákan náà pé: “Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ara Kristi tipa bẹ́ẹ̀ wà nínú àpéjọ náà tá a fi hàn gẹ́gẹ́ bí àwọn tá a ṣà yàn tá a sì fi òróró yàn, tàbí fi èdìdì dì.” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò yéé sọ pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], kò-lé-kò-dín ni iye àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n para pọ̀ di Ísírẹ́lì tẹ̀mí.

15. Ní gẹ́rẹ́ ṣáájú ọjọ́ Olúwa, kí làwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì olóòótọ́ inú rò pé àwọn Júù àbínibí yóò gbádùn lẹ́yìn òpin Àwọn Àkókò Kèfèrí?

15 Síbẹ̀, ṣé kò yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì àbínibí lóde òní máa gbádùn àkànṣe ojú rere dé àyè kan ni? Gẹ́rẹ́ ṣáájú ọjọ́ Olúwa, nígbà táwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì olóòótọ́ inú ń ṣàwárí ọ̀pọ̀ àwọn òtítọ́ ìpìlẹ̀ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n ronú pé bí òpin Àwọn Àkókò Kèfèrí bá ti dé àwọn Júù á tún padà gbádùn ìdúró rere níwájú Ọlọ́run. Ìyẹn ni C. T. Russell fi gbé ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà 31:29-34 karí àwọn Júù àbínibí nínú ìwé náà, The Time Is at Hand (Ìdìpọ̀ Kejì ti Studies in the Scriptures), tá a tẹ̀ jáde lọ́dún 1889. Ó wá ṣàlàyé báyìí pé: “Gbogbo ayé ló mọ̀ pé látọdún [607] ṣáájú Ìbí Kristi ni Ísírẹ́lì ti ń jìyà bọ̀ lábẹ́ àwọn Kèfèrí tó jẹ gàba lé wọn lórí, ìyà ọ̀hún ò tíì dópin, kò sì sí ìdí kankan tá a fi lè retí àtúntò orílẹ̀-èdè wọn ṣáájú 1914 Lẹ́yìn Ikú Olúwa Wa, lópin ‘ìgbà méje’ wọn, tàbí ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogún [2,520] ọdún.” Ó jọ pé nígbà náà ni àwọn Júù a padà fìdí kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, ìfojúsọ́nà yìí sì dà bí èyí tó túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ sí i lọ́dún 1917, nígbà tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun á kọ́wọ́ ti sísọ Palẹ́sìnì di orílẹ̀-èdè táwọn Júù á fìdí kalẹ̀ sí nínú Ìpolongo Balfour.

16. Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe sapá láti mú ìhìn Kristẹni dé ọ̀dọ̀ àwọn Júù àbínibí, kí ni ìsapá wọn sì yọrí sí?

16 Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, Palẹ́sìnì di àgbègbè tí òfin pín sábẹ́ àkóso Great Britain, ìyẹn sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ àwọn Júù láti padà sí ilẹ̀ yẹn. Lọ́dún 1948, Orílẹ̀-Èdè Ísírẹ́lì olóṣèlú ti wà. Ṣé ìyẹn wá fi hàn pé àwọn Júù á tún padà rí ojúure Ọlọ́run? Fún ọ̀pọ̀ ọdún làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi rò pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ á rí. Nípa báyìí, lọ́dún 1925 wọ́n tẹ ìwé olójú ewé 128 kan, tí wọ́n pè ní Comfort for the Jews. Lọ́dún 1929, wọ́n tẹ ìdìpọ̀ ìwé Life, tó ní ojú ewé 360, tó sì fani mọ́ra. Wọ́n ṣe é láti fi fa àwọn Júù lọ́kàn mọ́ra, ó sì tún dá lórí ìwé Jóòbù tó wà nínú Bíbélì. Àwọn Ẹlẹ́rìí sapá lọ́pọ̀lọpọ̀, pàápàá nílùú New York City, láti mú ìhìn Mèsáyà yìí tọ àwọn Júù lọ. A láyọ̀ pé díẹ̀ lára wọn tẹ́tí gbọ́ wa, àmọ́ ńṣe lọ̀pọ̀ àwọn Júù kọ ẹ̀rí wíwàníhìn-ín Mèsáyà, bíi tàwọn baba ńlá wọn ní ọ̀rúndún kìíní.

17, 18. Kí làwọn ẹrú Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé wá lóye nípa májẹ̀mú tuntun náà àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa ìmúpadàbọ̀sípò?

17 Ó hàn gbangba gbàǹgbà pé kì í ṣe àwọn Júù lódindi tàbí gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, ni Ísírẹ́lì tí Ìṣípayá 7:4-8 tàbí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mìíràn tó tan mọ́ ọjọ́ Olúwa ń ṣàpèjúwe. Àwọn Júù ń tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, wọ́n sì ń bá a nìṣó láti máa yẹra fún lílo orúkọ Ọlọ́run. (Mátíù 15:1-3, 7-9) Nígbà tí ìwé náà, Jehovah, táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ lọ́dún 1934, ń jíròrò Jeremáyà 31:31-34, ibi tó fẹnu ọ̀rọ̀ náà jóná sí ni pé: “Májẹ̀mú tuntun náà ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ-bíbí Ísírẹ́lì àti aráyé ní gbogbo gbòò, ṣùgbọ́n . . . ọ̀dọ̀ Ísírẹ́lì tẹ̀mí ni ìtumọ̀ rẹ̀ mọ sí.” Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò tí Bíbélì mẹ́nu kàn kò tan mọ́ èyíkéyìí lára àwọn Júù àbínibí tàbí Ísírẹ́lì olóṣèlú, èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tó sì jẹ́ apá kan ayé tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú Jòhánù 14:19, 30 àti 18:36.

18 Lọ́dún 1931, àwọn ẹrú Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé, fi ìdùnnú ńláǹlà gba orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n fi tọkàntọkàn fara mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Sáàmù 97:11 pé: “Ìmọ́lẹ̀ ti kọ mànà fún olódodo, àti ayọ̀ yíyọ̀ àní fún àwọn adúróṣánṣán ní ọkàn-àyà.” Ìfòyemọ̀ mú kó yé wọn yékéyéké pé Ísírẹ́lì tẹ̀mí nìkan la mú wọnú májẹ̀mú tuntun. (Hébérù 9:15; 12:22, 24) Àwọn Ísírẹ́lì àbínibí tí wọ́n ti gíràn-án kò ní ipa kankan nínú ẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni aráyé ní gbogbo gbòò. Ohun tó yé wa yìí ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ sórí ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó wọ́pọ̀ nínú àkọsílẹ̀ ìtàn ìjọsìn àwọn èèyàn Ọlọ́run. Èyí wá jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe ń fi àánú, ìṣeun ìfẹ́ àti òtítọ́ rẹ̀ hàn sí gbogbo èèyàn tó bá sún mọ́ ọn. (Ẹ́kísódù 34:6; Jákọ́bù 4:8) Ó dájú pé àwọn míì, yàtọ̀ sí Ísírẹ́lì Ọlọ́run, á jàǹfààní látinú dídá táwọn áńgẹ́lì náà dá ẹ̀fúùfù ìparun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dúró. Àwọn wo làwọn míì yẹn ná? Ṣé o lè jẹ́ ọ̀kan lára wọn? Jẹ́ ká jọ wò ó ná.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Èyí ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìtumọ̀ orúkọ náà Ísírẹ́lì, ìyẹn ni “Ọlọ́run Ń Wọ̀jà; Ẹni Tó Ń Wọ̀jà (Wonkoko) Pẹ̀lú Ọlọ́run.”—Jẹ́nẹ́sísì 32:28, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 114]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 116, 117]

Láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni la ti bẹ̀rẹ̀ sí í yan Ísírẹ́lì tòótọ́ fún Ọlọ́run, ó sì ń bá a lọ tó fi di ọdún 1935 níbi àpéjọ àgbègbè olókìkí kan nínú ìtàn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe nílùú Washington, D.C., níbi tá a ti bẹ̀rẹ̀ sí í tẹnu mọ́ kíkó ogunlọ́gọ̀ ńlá tó máa jogún ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé jọ (Ìṣípayá 7:9)