Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jésù Dé Tòun-Tìṣírí

Jésù Dé Tòun-Tìṣírí

Orí 4

Jésù Dé Tòun-Tìṣírí

1. Àwọn wo ni Jòhánù kọ̀wé sí nísinsìnyí, àwọn wo ló sì yẹ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí èyí gidigidi lónìí?

 Ó YẸ kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó tún kàn báyìí gidigidi. Ohun tó tún kàn náà jẹ́ àwọn iṣẹ́ tá a rán síni. Wọ́n ní ìmúṣẹ pàtó bí “àkókò tí a yàn kalẹ̀” ti ń sún mọ́lé. (Ìṣípayá 1:3) A óò rí àǹfààní ayérayé nínú rẹ̀ tá a bá kọbi ara sí àwọn ìkéde wọ̀nyẹn. Àkọsílẹ̀ náà kà pé: “Jòhánù, sí àwọn ìjọ méje tí ó wà ní àgbègbè Éṣíà: Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ ‘Ẹni náà tí ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀,’ àti láti ọ̀dọ̀ ẹ̀mí méje tí ó wà níwájú ìtẹ́ rẹ̀, àti láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi.”—Ìṣípayá 1:4, 5a.

2. (a) Kí ni nọ́ńbà náà “méje” túmọ̀ sí? (b) Ní ọjọ́ Olúwa, àwọn wo ni àwọn iṣẹ́ tá a rán sí “ìjọ méje” náà kàn?

2 “Ìjọ méje” ni Jòhánù darí ọ̀rọ̀ sí, nígbà tó sì yá, ó sọ orúkọ àwọn ìjọ wọ̀nyí fún wa nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí. Nọ́ńbà náà, “méje,” fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú ìwé Ìṣípayá. Ohun tó dúró fún ni ìpé pérépéré, pàápàá nínú àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run àti ìjọ àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀. Níwọ̀n bí iye ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run kárí ayé ti di ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá mẹ́wàá ní ọjọ́ Olúwa, a lè ní ìdánilójú pé ohun tá a sọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún “ìjọ méje” ti àwọn ẹni àmì òróró tún kan gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí pẹ̀lú. (Ìṣípayá 1:10) Bẹ́ẹ̀ ni, iṣẹ́ pàtàkì tí Jòhánù jẹ́ yìí wà fún gbogbo ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti gbogbo àwọn tí ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn, níbi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé.

3. (a) Nínú ìkíni Jòhánù, ibo ni “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà” ti wá? (b) Ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wo ló jọra pẹ̀lú ìkíni Jòhánù?

3 “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà.” Àwọn ohun wọ̀nyí mà fani lọ́kàn mọ́ra o, pàápàá bá a ṣe mọ ibi tí wọ́n ti wá! “Ẹni” náà tí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣàn wá ni Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀, Jèhófà, “Ọba ayérayé,” ẹni tó wà láàyè “láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.” (1 Tímótì 1:17; Sáàmù 90:2) A tún rí gbólóhùn náà, “ẹ̀mí méje” nínú iṣẹ́ tá a rán sí ìjọ méje náà. Gbólóhùn náà ṣàfihàn ìpé pérépéré iṣẹ́ tí agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ ń ṣe, bí ẹ̀mí náà ṣe ń mú kí gbogbo àwọn tó ń fiyè sí àsọtẹ́lẹ̀ náà ní òye àti ìbùkún. Ẹni mìíràn tó tún wà ní ipò pàtàkì ni “Jésù Kristi.” Òun ni Jòhánù kọ̀wé nípa rẹ̀ lẹ́yìn náà pé: “Ó sì kún fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti òtítọ́.” (Jòhánù 1:14) Nípa báyìí, nínú ìkíni Jòhánù, a rí lára àwọn ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn nígbà tó ń parí lẹ́tà rẹ̀ kejì sí ìjọ Kọ́ríńtì, pé: “Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ti Jésù Kristi Olúwa àti ìfẹ́ Ọlọ́run àti ṣíṣe àjọpín nínú ẹ̀mí mímọ́ wà pẹ̀lú gbogbo yín.” (2 Kọ́ríńtì 13:14) Ǹjẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọnnì pẹ̀lú jẹ́ ti gbogbo àwa tá a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lónìí!—Sáàmù 119:97.

“Ẹlẹ́rìí Aṣeégbíyèlé”

4. Báwo ni Jòhánù ṣe ń bá a lọ láti ṣàpèjúwe Jésù Kristi, kí sì nìdí tí àwọn èdè tó fi ṣàpèjúwe rẹ̀ wọ̀nyí fi bá a mu gan-an?

4 Lẹ́yìn Jèhófà, Jésù ni ẹni tó lógo jù lọ láyé-lọ́run, gẹ́gẹ́ bí Jòhánù ṣe mọ̀ tó sì pè é ní “‘Ẹlẹ́rìí Aṣeégbíyèlé,’ ‘Àkọ́bí nínú àwọn òkú,’ àti ‘Olùṣàkóso àwọn ọba ilẹ̀ ayé.’” (Ìṣípayá 1:5b) Bí òṣùpá lójú ọ̀run, a ti fìdí Jésù múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí títóbi jù lọ fún ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run. (Sáàmù 89:37) Lẹ́yìn tó pa ìwà títọ́ mọ́ títí dé ojú ikú ìrúbọ, ó di ẹni àkọ́kọ́ láàárín aráyé tá a gbé dìde sí ìyè àìleèkú tẹ̀mí. (Kólósè 1:18) Nísinsìnyí tó ti wà ní iwájú Jèhófà, a gbé e ga ju gbogbo àwọn ọba orí ilẹ̀ ayé lọ, bó ti jẹ́ pé a gbé “gbogbo ọlá àṣẹ ní . . . ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé” lé e lọ́wọ́. (Mátíù 28:18; Sáàmù 89:27; 1 Tímótì 6:15) Ní 1914, a fi jẹ Ọba láti máa ṣàkóso láàárín àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé.—Sáàmù 2:6-9.

5. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe ń bá a lọ láti fi ìmọrírì hàn fún Olúwa náà Jésù Kristi? (b) Ta ló jàǹfààní láti inú ẹ̀bùn ìwàláàyè èèyàn pípé ti Jésù, báwo sì ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe nípìn-ín nínú àkànṣe ìbùkún kan?

5 Jòhánù ń bá a lọ láti fi ìmọrírì hàn fún Olúwa, Jésù Kristi, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn wọ̀nyí: “Fún ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa, tí ó sì tú wa kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀—ó sì mú kí a jẹ́ ìjọba kan, àlùfáà fún Ọlọ́run àti Baba rẹ̀—bẹ́ẹ̀ ni, òun ni kí ògo àti agbára ńlá jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.” (Ìṣípayá 1:5d, 6) Jésù fi ìwàláàyè èèyàn pípé tó ní rúbọ kí ọmọ aráyé tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ lè rí ìyè pípé gbà padà. Ìwọ òǹkàwé wa ọ̀wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí! (Jòhánù 3:16) Ṣùgbọ́n ikú ìrúbọ Jésù mú kí àkànṣe ìbùkún ṣeé ṣe fún àwọn tí wọ́n di Kristẹni ẹni àmì òróró bíi ti Jòhánù. Àwọn wọ̀nyí la ti polongo ní olódodo lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù. Níwọ̀n bí wọ́n ti gbà láti yááfì gbogbo àǹfààní tó ní í ṣe pẹ̀lú wíwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe, a fi ẹ̀mí Ọlọ́run bí àwọn tí wọ́n jẹ́ ara agbo kékeré, wọ́n sì ń wọ̀nà fún dídi ẹni tá a jí dìde láti sìn gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Jésù Kristi nínú Ìjọba rẹ̀. (Lúùkù 12:32; Róòmù 8:18; 1 Pétérù 2:5; Ìṣípayá 20:6) Àǹfààní yìí mà tóbi lọ́lá o! Abájọ tí Jòhánù fi fi ìtẹnumọ́ tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ polongo pé kí ògo àti agbára jẹ́ ti Jésù!

“Ń Bọ̀ Pẹ̀lú Àwọsánmà”

6. (a) Kí ni Jòhánù kéde nípa ‘bíbọ̀ Jésù pẹ̀lú àwọsánmà,’ àsọtẹ́lẹ̀ Jésù wo sì ni Jòhánù ti ní láti rántí? (b) Báwo ni Jésù ṣe ‘dé,’ àwọn wo lórí ilẹ̀ ayé ni yóò sì ní ẹ̀dùn-ọkàn ńláǹlà?

6 Lẹ́yìn náà, Jòhánù fayọ̀ kéde pé: “Wò ó! Ó ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà, gbogbo ojú ni yóò sì rí i, àti àwọn tí ó gún un lọ́kọ̀; gbogbo ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóò sì lu ara wọn nínú ẹ̀dùn-ọkàn nítorí rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, Àmín.” (Ìṣípayá 1:7) Láìsí àní-àní, Jòhánù rántí àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ ṣáájú nípa òpin ètò àwọn nǹkan. Jésù sọ pé: “Nígbà náà sì ni àmì Ọmọ ènìyàn yóò fara hàn ní ọ̀run, nígbà náà sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóò lu ara wọn nínú ìdárò, wọn yóò sì rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.” (Mátíù 24:3, 30) Nítorí náà, a lè sọ pé, Jésù ‘dé’ nípa yíyí àfiyèsí rẹ̀ sí mímú àwọn ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè. Èyí yóò yọrí sí ìyípadà pàtàkì lórí ilẹ̀ ayé, àti pé níwọ̀n bí “gbogbo ẹ̀yà ilẹ̀ ayé” kò ti gbà pé òótọ́ ni Jésù jẹ́ ọba, wọn yóò rí “ìbínú ìrunú Ọlọ́run Olódùmarè” ní ti gidi.—Ìṣípayá 19:11-21; Sáàmù 2:2, 3, 8, 9.

7. Báwo ni “gbogbo ojú,” títí kan ti àwọn aláìgbọràn, yóò ṣe “rí” Jésù?

7 Ní alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ayé kì yóò sì rí mi mọ́.” (Jòhánù 14:19) Báwo wá ló ti jẹ́ tí ‘gbogbo ojú yóò fi rí i’? Kò yẹ ká retí pé àwọn ọ̀tá Jésù yóò fi ojúyòójú rí i, nítorí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, lẹ́yìn tí Jésù gòkè re ọ̀run pé nísinsìnyí Jésù “ń gbé nínú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ́,” àti pé “kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tí ó ti rí i tàbí lè rí i.” (1 Tímótì 6:16) Nígbà tí Jòhánù mẹ́nu kan ‘rírí’ Jésù, ó hàn gbangba pé ohun tó ní lọ́kàn ni ‘fífi òye mọ̀.’ Ńṣe ló dà bí àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní tí a kò lè fojú rí, àmọ́ tá a lè rí tàbí tá a lè fòye mọ̀ nínú àwọn tó dá. (Róòmù 1:20) Jésù “ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà” ní ti pé ó jẹ́ ẹni tí a kò lè fi ojúyòójú rí gan-an gẹ́gẹ́ bá a kò ti lè fi ojúyòójú rí oòrùn nígbà tó bá wà lẹ́yìn àwọsánmà. Àní tí àwọsánmà bá bo oòrùn lójú lọ́sàn-án, a mọ̀ pé oòrùn wà níbẹ̀ nítorí ìmọ́lẹ̀ ọ̀sán tó yí wa ká. Bákan náà, bí Jésù Olúwa tilẹ̀ jẹ́ ẹni tí a ò lè fojú rí, a ó ṣí i payá gẹ́gẹ́ bí ‘iná tí ń jó fòfò, bí ó ti ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa rẹ̀.’ Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ni a óò fipá mú láti “rí i.”—2 Tẹsalóníkà 1:6-8; 2:8.

8. (a) Àwọn wo ni “àwọn tí ó gún un lọ́kọ̀” ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn èèyàn wo lónìí sì ni irú àwọn bẹ́ẹ̀? (b) Níwọ̀n bí Jésù kò ti sí lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín, báwo làwọn èèyàn ṣe lè “gún un lọ́kọ̀”?

8 “Àwọn tí ó gún un [ìyẹn Jésù] lọ́kọ̀” yóò “rí” i pẹ̀lú. Ta ni àwọn wọ̀nyí lè jẹ́? Nígbà tí wọ́n pa Jésù ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn jagunjagun Róòmù gún un lọ́kọ̀ ní ti gidi. Àwọn Júù nípìn-ín nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn yẹn, nítorí Pétérù sọ fún àwọn kan lára wọn ní Pẹ́ńtíkọ́sì pé: “Jésù yìí tí ẹ kàn mọ́gi ni Ọlọ́run fi ṣe Olúwa àti Kristi.” (Ìṣe 2:5-11, 36; fi wé Sekaráyà 12:10; Jòhánù 19:37.) Àwọn ará Róòmù àti àwọn Júù tá à ń wí yìí ti kú ní èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn nísinsìnyí. Nítorí náà àwọn tó dúró fún àwọn tí wọ́n “gún un lọ́kọ̀” lónìí ní láti jẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn èèyàn tí wọ́n ní irú ìkórìíra kan náà tí àwọn èèyàn ní nígbà tí wọ́n kan Jésù mọ́gi. Jésù kò sí lórí ilẹ̀ ayé ńbí mọ́. Ṣùgbọ́n nígbà táwọn alátakò bá fi ìtara ṣe inúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń jẹ́rìí nípa Jésù, tàbí tí wọ́n fara mọ́ híhu irú ìwà bẹ́ẹ̀ sí wọn, ńṣe ló dà bíi pé àwọn alátakò bẹ́ẹ̀ ‘ń fi ọ̀kọ̀ gún’ Jésù fúnra rẹ̀.—Mátíù 25:33, 41-46.

“Ááfà àti Ómégà”

9. (a) Ta ló wá sọ̀rọ̀ wàyí, ìgbà mélòó ló sì sọ̀rọ̀ nínú Ìṣípayá? (b) Nígbà tí Jèhófà pe ara rẹ̀ ní “Ááfà àti Ómégà” àti “Olódùmarè,” kí ni èyí túmọ̀ sí?

9 Wàyí o, baba ńlá kàyéfì ṣẹlẹ̀! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ó bá a mu gan-an ni pé kí èyí jẹ́ ọ̀rọ̀ àkọ́sọ fún àwọn ìran tí Jòhánù máa tó rí, nítorí pé Jèhófà ni Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá àti Orísun Ìṣípayá! (Aísáyà 30:20) Ọlọ́run wa sọ pé: “Èmi ni Ááfà àti Ómégà, . . . Ẹni náà tí ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀, Olódùmarè.” (Ìṣípayá 1:8) Èyí ni àkọ́kọ́ nínú ìgbà mẹ́ta tí Jèhófà tìkára rẹ̀ sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá nínú Ìṣípayá. (Tún wo Ìṣípayá 21:5-8; 22:12-15.) Kíákíá làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní á ti mọ̀ pé ááfà àti ómégà jẹ́ lẹ́tà àkọ́kọ́ àti ìkẹyìn nínú álífábẹ́ẹ̀tì èdè Gíríìkì. Pípè tí Jèhófà fi lẹ́tà méjì wọ̀nyí pe ara rẹ̀ tẹnu mọ́ ọn pé ṣáájú rẹ̀, kò sí Ọlọ́run Olódùmarè kankan, kì yóò sì sí èyíkéyìí lẹ́yìn rẹ̀. Òun yóò yanjú àríyànjiyàn nípa jíjẹ́ Ọlọ́run, títí ayérayé. Títí láé ni àwọn èèyàn yóò gbà pé òun ni Ọlọ́run Olódùmarè kan ṣoṣo tó wà, Ọba Aláṣẹ Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀.—Fi wé Aísáyà 46:10; 55:10, 11.

10. (a) Báwo ni Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ara rẹ̀ lẹ́yìn náà, ibo ni wọ́n sì há a mọ́? (b) Àwọn wo ló ti ní láti lọ́wọ́ nínú fífi àkájọ ìwé tí Jòhánù kọ ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ? (d) Báwo la ṣe ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lọ́pọ̀ ìgbà lónìí?

10 Pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pé Jèhófà yóò darí àbárèbábọ̀ àwọn ọ̀ràn, Jòhánù sọ fún àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Èmi Jòhánù, arákùnrin yín àti alájọpín pẹ̀lú yín nínú ìpọ́njú àti ìjọba àti ìfaradà ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Jésù, wá wà ní erékùṣù tí a ń pè ní Pátímọ́sì nítorí sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 1:9) Gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n nítorí ìhìn rere ní erékùṣù Pátímọ́sì, tí ń fara da àwọn ìpọ́njú pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, tó sì ní ìrètí tó fìdí múlẹ̀ pé òun á ní ìpín nínú Ìjọba tí ń bọ̀, Jòhánù arúgbó wá rí àkọ́kọ́ nínú àwọn ìran Ìṣípayá wàyí. Kò sí àní-àní pé àwọn ìran wọ̀nyí fún un ní ìṣírí gidigidi, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìmúṣẹ àwọn ìràn náà ṣe fún ẹgbẹ́ Jòhánù ti òde òní níṣìírí. A ò mọ ọ̀nà tí Jòhánù gbà fi àkájọ ìwé Ìṣípayá ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ, níwọ̀n bí òun ti wà ní àhámọ́ ní àkókò náà. (Ìṣípayá 1:11; 22:18, 19) Ó ní láti ní ọwọ́ àwọn áńgẹ́lì Jèhófà nínú, gan-an gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti máa ń fi ìgbà gbogbo dáàbò bo àwọn olùṣòtítọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń sìn lábẹ́ ìfòfindè àti ìkálọ́wọ́kò lónìí, tó fi ń ṣeé ṣe fún àwọn wọ̀nyí láti mú oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn tí ebi òtítọ́ ń pa.—Sáàmù 34:6, 7.

11. Àǹfààní wo tó fara jọ èyí tí Jòhánù mọrírì ni ẹgbẹ́ Jòhánù kà sí iyebíye lónìí?

11 Ẹ wo bí Jòhánù ṣe ti ní láti mọrírì àǹfààní tó ní láti jẹ́ ẹni tí Jèhófà lò gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tó gbà bá ìjọ sọ̀rọ̀! Lọ́nà tó jọra, ẹgbẹ́ Jòhánù ti òde òní ka àǹfààní pípèsè “oúnjẹ” tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” fún agbo ilé Ọlọ́run sí iyebíye. (Mátíù 24:45) A gbà á ládùúrà pé kí ìpèsè tẹ̀mí yìí fún ìwọ náà lókun kí ọwọ́ rẹ lè tẹ ohun ológo tó ò ń lépa, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun!—Òwe 3:13-18; Jòhánù 17:3.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]

Rírí Oúnjẹ Tẹ̀mí Gbà ní Àwọn Àkókò Ìṣòro

Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jìyà inúnibíni tí a sì ti rí ìnira púpọ̀, ó ti di ọ̀ranyàn pé ká rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà ká lè jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń rí oúnjẹ tẹ̀mí agbẹ́mìíró tó pọ̀ tó nípasẹ̀ ìfihàn agbára Jèhófà lọ́nà tó ga lọ́lá.

Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ Násì oníwà-ìkà fòfin de títẹ Ilé Ìṣọ́ ní Jámánì lábẹ́ àkóso Hitler, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀ ṣe àtúntẹ̀ àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́, wọ́n sì pín wọn kiri. Ní Hamburg àwọn ọlọ́pàáanú tá a mọ̀ sí Gestapo fipá wọnú ilé kan tí wọ́n ti ń ṣe irú àtúntẹ̀ ìwé bẹ́ẹ̀. Ilé náà ò tóbi, kò sì sí ibì kankan tá a lè fi ohunkóhun pa mọ́ sí. Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé àfìkatẹ̀ wà nínú kọ́bọ́ọ̀dù kan, wọ́n sì gbé ẹ̀rọ ìṣàtúntẹ̀ tó ṣòroó gbé kiri pa mọ́ sínú ibi tí wọ́n ń kó ànàmọ́ sí ní àjà ilẹ̀ ilé náà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àpótí ìfàlọ́wọ́ kan tí ìwé ìròyìn kún inú rẹ̀ wà lẹ́yìn ibi tí wọ́n ń kó ànàmọ́ sí yìí! Ó dà bíi pé kò sí báwọn ọlọ́pàá náà ò ṣe ní rí i. Ṣùgbọ́n kí ló ṣẹlẹ̀? Ọ̀gá ọlọ́pàá tó ṣí kọ́bọ́ọ̀dù náà ṣí i lọ́nà tí kò fi rí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé àfìkatẹ̀ náà. Ní ti yàrá tó wà ní àjà ilẹ̀ ilé náà, ẹni tó ń gbé inú ilé náà ròyìn pé: “Àwọn ọ̀gá ọlọ́pàá mẹ́ta dúró láàárín yàrá náà, àpótí ìfàlọ́wọ́ kan tí Ilé Ìṣọ́ kún inú rẹ̀ sì wà lẹ́yìn ibi tá à ń kó ànàmọ́ sí náà. Ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn tó jọ pé ó rí i; ṣe ló dà bíi pé ìfọ́jú bù lù wọ́n.” Ọpẹ́lọpẹ́ àkóyọ Ọlọ́run yìí ló fi ṣeé ṣe fún àwọn tó ń gbé nínú ilé náà láti máa bá a lọ láti jẹ́ kí oúnjẹ tẹ̀mí tẹ àwọn ará lọ́wọ́ ní àwọn àkókò ìṣòro àti eléwu.

Láàárín ọdún 1960 sí 1969, ogun abẹ́lé kan jà láàárín Nàìjíríà àti ẹkùn ìpínlẹ̀ kan tó yapa tí wọ́n pè ní Biafra. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ilẹ̀ Nàìjíríà ló yí Biafra po, ọ̀nà kan ṣoṣo tí ohunkóhun lè gbà débẹ̀ ò ju pápákọ̀ òfuurufú kan lọ. Èyí túmọ̀ sí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n wà ní Biafra wà nínú ewu àìní máa rí ìpèsè oúnjẹ tẹ̀mí gbà. Nígbà tó ṣe, ní ìbẹ̀rẹ̀ 1968, àwọn aláṣẹ Biafra yan ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba rẹ̀ sí ipò iṣẹ́ pàtàkì kan ní Yúróòpù, wọ́n sì yan òmíràn sí pápákọ̀ òfuurufú Biafra. Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn méjèèjì wọ̀nyí jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àti pé nísinsìnyí wọ́n wà ní igun méjèèjì tó jẹ́ ọ̀nà àgbàwọlé àti àgbàjáde kan ṣoṣo fún Biafra. Àwọn méjèèjì mọ̀ dájú pé ó ní láti jẹ́ pé Jèhófà ló ṣètò yìí. Nítorí náà, wọ́n fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe iṣẹ́ ẹlẹgẹ́ àti àfẹ̀mí-ẹni-wewu ti mímú oúnjẹ tẹ̀mí wọ Biafra. Ó sì ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe èyí jálẹ̀ gbogbo àkókò ogun náà. Ọ̀kan nínú wọn sọ pé: “Ètò náà ré kọjá ohun téèyàn lásán lè ṣe.”

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 19]

Àwọn Nọ́ńbà Ìṣàpẹẹrẹ Nínú Ìwé Ìṣípayá

Nọ́ńbà Ohun Tó Dúró Fún

2 Dúró fún mímú kókó ọ̀ràn kan túbọ̀ fìdí múlẹ̀ ṣinṣin.

(Ìṣípayá 11:3, 4; fi wé Diutarónómì 17:6.)

3 Dúró fún ìtẹnumọ́. Ó tún ń fi hàn pé ọ̀ràn náà rinlẹ̀.

(Ìṣípayá 4:8; 8:13; 16:13, 19)

4 Dúró fún kárí ayé, ìyẹn gbogbo gbòò tàbí igun mẹ́rin

lọ́gbọọgba tó gún régé.

(Ìṣípayá 4:6; 7:1, 2; 9:14; 20:8; 21:16)

6 Dúró fún àìpé, ohun kan tí kò rí bó ṣe yẹ kó rí, tó jẹ́

abàmì.

(Ìṣípayá 13: 18; fi wé 2 Sámúẹ́lì 21:20.)

7 Dúró fún ìpé pérépéré tí Ọlọ́run pinnu, nínú àwọn nǹkan

tí Jèhófà ní lọ́kàn láti ṣe tàbí nínú àwọn nǹkan ti Sátánì.

(Ìṣípayá 1:4, 12, 16; 4:5; 5:1, 6; 10:3, 4; 12:3)

10 Dúró fún pátápátá porogodo tàbí ìpé pérépéré nínú àwọn

nǹkan ti orí ilẹ̀ ayé.

(Ìṣípayá 2:10; 12:3; 13:1; 17:3, 12, 16)

12 Dúró fún ètò tí Ọlọ́run fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in yálà ní

ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé.

(Ìṣípayá 7:5-8; 12:1; 21:12, 16; 22:2)

24 Dúró fún ọ̀pọ̀ yanturu (ìlọ́po méjì) ìṣètò Jèhófà.

(Ìṣípayá 4:4)

Àwọn nọ́ńbà kan tá a mẹ́nu kàn nínú Ìṣípayá la ní láti lóye rẹ̀ gẹ́gẹ́ bá a ti sọ ọ́ gan-an. Lọ́pọ̀ ìgbà, àyíká ọ̀rọ̀ máa ń ranni lọ́wọ́ láti pinnu ìtumọ̀ èyí. (Wo Ìṣípayá 7:4, 9; 11:2, 3; 12:6, 14; 17:3, 9-11; 20:3-5.)