Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kíkọ Orin Ayọ̀ Ìṣẹ́gun Tuntun

Kíkọ Orin Ayọ̀ Ìṣẹ́gun Tuntun

Orí 29

Kíkọ Orin Ayọ̀ Ìṣẹ́gun Tuntun

Ìran 9—Ìṣípayá 14:1-20

Ohun tó dá lé: Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] wà lọ́dọ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ní Òkè Ńlá Síónì; àwọn áńgẹ́lì ṣe ìpolongo jákèjádò ilẹ̀ ayé; ìkórè wáyé

Ìgbà tó nímùúṣẹ: Látọdún 1914 títí dìgbà ìpọ́njú ńlá

1. Kí la ti kọ́ nínú Ìṣípayá orí 7, 12, àti 13, kí ni a óò sì kọ́ nísinsìnyí?

 Ẹ WO bó ti tuni lára tó láti gbé ìran tí Jòhánù rí tẹ̀ lé e yẹ̀ wò! Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà adúróṣinṣin ń bá iṣẹ́ Ọlọ́run lọ ní ọjọ́ Olúwa, wọn ò dà bí àwọn àjọ ráuràu àti oníwà-bí-ẹranko ti dírágónì náà. (Ìṣípayá 1:10) Ṣáájú ìsinsìnyí, Ìṣípayá 7:1, 3 ti jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀fúùfù mẹ́rin tó jẹ́ ti ìparun la dá dúró títí a óò fi fi èdìdì di gbogbo ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ẹni àmì òróró tó jẹ́ ẹrú wọ̀nyí. Ìṣípayá 12:17 jẹ́ ká mọ̀ pé “àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ [obìnrin náà]” ni Sátánì tí í ṣe dírágónì náà, dájú sọ láàárín àkókò yẹn. Ìṣípayá orí ìkẹtàlá sì ti fi àwọn àjọ ìṣèlú tí Sátánì gbé kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé láti fúngun mọ́ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà àti láti ṣe inúnibíni sí wọ́n hàn kedere. Àmọ́, olórí ọ̀tá yìí kò lè da ohun tí Ọlọ́run ti pinnu láti ṣe rú láé! Nísinsìnyí, a óò kẹ́kọ̀ọ́ pé láìka àwọn ìwà ibi ti Sátánì ń hù sí, tayọ̀tayọ̀ la fi kó gbogbo ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] jọ.

2. Kí ni Jòhánù sọ fún wa nínú Ìṣípayá 14:1 nípa àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ níkẹyìn, ta sì ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà?

2 Jòhánù, tòun tẹgbẹ́ Jòhánù òde òní, la fún ní àpẹẹrẹ kan nípa àbájáde aláyọ̀ yẹn: “Mo sì rí, sì wò ó! Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà dúró lórí Òkè Ńlá Síónì, àti pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n ní orúkọ rẹ̀ àti orúkọ Baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn.” (Ìṣípayá 14:1) Gẹ́gẹ́ bá a ti rí i níṣàájú, Ọ̀dọ́ Àgùntàn yìí ni Máíkẹ́lì tó fọ ọ̀run mọ́ nípa lílé Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jáde. Òun ni Máíkẹ́lì tí Dáníẹ́lì ṣàpèjúwe pé ó “dúró nítorí àwọn ọmọ àwọn ènìyàn [Ọlọ́run]” bó ṣe ń múra sílẹ̀ láti “dìde dúró” kó bàa lè mú àwọn ìdájọ́ òdodo Jèhófà ṣẹ. (Dáníẹ́lì 12:1; Ìṣípayá 12:7, 9) Látọdún 1914 wá ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run tó fi ara rẹ̀ rúbọ yìí ti ń dúró lórí Òkè Ńlá Síónì gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba.

3. Kí ni “Òkè Ńlá Síónì” lórí èyí tí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] “dúró” sí?

3 Bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gan-an ló rí, ó sọ pé: “Èmi, àní èmi, ti fi ọba mi jẹ lórí Síónì, òkè ńlá mímọ́ mi.” (Sáàmù 2:6; 110:2) Èyí kì í ṣe Òkè Ńlá Síónì ti orí ilẹ̀ ayé, níbi tí Jerúsálẹ́mù ti orí ilẹ̀ ayé wà, ìyẹn ìlú táwọn ọba tí í ṣe ẹ̀dá èèyàn ní ìlà Dáfídì ti fìgbà kan rí jọba. (1 Kíróníkà 11:4-7; 2 Kíróníkà 5:2) Ìdí ni pé lẹ́yìn ikú Jésù àti àjíǹde rẹ̀ lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, a fi Jésù ṣe òkúta ìpìlẹ̀ lórí Òkè Ńlá Síónì ti ọ̀run, ìyẹn àyè ibi tí Jèhófà pinnu láti gbé “ìlú ńlá Ọlọ́run alààyè tí í ṣe Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run” kà. Fún ìdí yìí, “Òkè Ńlá Síónì” tí ibí yìí sọ dúró fún ipò Jésù àtàwọn àjùmọ̀jogún pẹ̀lú rẹ̀ tí a gbé ga, tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run, èyí tí í ṣe Ìjọba náà. (Hébérù 12:22, 28; Éfésù 3:6) Ó jẹ́ àyè ọlọ́ba tó lógo èyí tí Jèhófà fi wọ́n sí ní ọjọ́ Olúwa. Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, gẹ́gẹ́ bí “àwọn òkúta ààyè,” ti ń fi tọkàntọkàn wọ̀nà fún ìgbà tí wọ́n máa dúró lórí Òkè Ńlá Síónì ti ọ̀run yẹn, tí wọ́n á sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Jésù Kristi Olúwa tá a ṣe lógo nínú Ìjọba rẹ̀ ológo.—1 Pétérù 2:4-6; Lúùkù 22:28-30; Jòhánù 14:2, 3.

4. Báwo ló ṣe jẹ́ pé gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ló dúró lórí Òkè Ńlá Síónì?

4 Kì í ṣe Jésù nìkan ni Jòhánù rí tó dúró lórí Òkè Ńlá Síónì, ó tún rí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], tí wọ́n jẹ́ ajùmọ̀jogún Ìjọba ọ̀run. Ní àkókò tí ìran náà dúró fún, ọ̀pọ̀ lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], ti wà ní ọ̀run ní àkókò yẹn, àmọ́ kì í ṣe gbogbo wọn. Lẹ́yìn náà nínú ìran kan náà, Jòhánù gbọ́ pé àwọn kan nínú àwọn ẹni mímọ́ ṣì ní láti fara dà á kí wọ́n sì kú gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́. (Ìṣípayá 14:12, 13) Èyí fi hàn kedere pé àwọn kan lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà báwo ló ṣe jẹ́ pé Jòhánù rí gbogbo wọn tí wọ́n dúró pẹ̀lú Jésù lórí Òkè Ńlá Síónì? a Bó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni pé, gẹ́gẹ́ bí ara ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, wọ́n ti “sún mọ́ Òkè Ńlá Síónì kan àti ìlú ńlá Ọlọ́run alààyè, Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run.” (Hébérù 12:22) Bíi ti Pọ́ọ̀lù nígbà tó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé, ní àkókò yẹn, a ti jí wọn dìde nípa tẹ̀mí láti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù ní ọ̀run. (Éfésù 2:5, 6) Ní àfikún, lọ́dún 1919, wọ́n ṣe ohun tá a ké sí wọn láti ṣe pé, “Ẹ máa bọ̀ lókè níhìn-ín,” àti pé lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ “wọ́n . . . gòkè lọ sínú ọ̀run nínú àwọsánmà.” (Ìṣípayá 11:12) Níbàámu pẹ̀lú ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ, a lè rí i pé, nípa tẹ̀mí, gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ló wà lórí Òkè Ńlá Síónì pẹ̀lú Jésù Kristi.

5. Orúkọ àwọn wo ni a kọ sí iwájú orí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà, kí sì ni ìjẹ́pàtàkì orúkọ kọ̀ọ̀kan?

5 Ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà kò ní àjọṣe kankan pẹ̀lú àwọn olùjọsìn ẹranko ẹhànnà náà, ìyẹn àwọn tí wọ́n gba nọ́ńbà ìṣàpẹẹrẹ náà 666. (Ìṣípayá 13:15-18) Dípò ìyẹn, àwọn adúróṣinṣin wọ̀nyí ni a kọ orúkọ Ọlọ́run àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà sí iwájú orí wọn. Kò sí iyèméjì kankan pé Jòhánù, tí í ṣe Júù, rí orúkọ Ọlọ́run tí a fi àwọn lẹ́tà Hébérù náà, יהוה kọ. b Orúkọ Baba Jésù tó wà níwájú orí àwọn tí a fi èdìdì dì wọ̀nyí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ń jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, àti pé ẹrú Rẹ̀ ni wọ́n. (Ìṣípayá 3:12) Fífi tí wọ́n fi orúkọ Jésù sí iwájú orí wọ́n tún fi hàn pé Jésù ló ni wọ́n. Òun ni “ọkọ” tó ń fẹ́ wọn sọ́nà, wọ́n sì jẹ́ “ìyàwó” rẹ̀ àfẹ́sọ́nà, tàbí “ìṣẹ̀dá tuntun” tí ń sin Ọlọ́run pẹ̀lú ìrètí ìyè ti ọ̀run. (Éfésù 5:22-24; Ìṣípayá 21:2, 9; 2 Kọ́ríńtì 5:17) Àjọṣe wọn tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà àti Jésù Kristi ń nípa lórí gbogbo èrò àti ìṣesí wọn.

Kíkọrin bí Ẹni Pé Orin Tuntun Kan

6. Orin wo ni Jòhánù gbọ́, báwo ló sì ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀?

6 Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, Jòhánù ròyìn pé: “Mo sì gbọ́ ìró kan láti ọ̀run wá bí ìró omi púpọ̀ àti bí ìró ààrá adúnròkè lálá; ìró tí mo sì gbọ́ dà bí ti àwọn akọrin tí ń lo háàpù sí orin wọn bí wọ́n ti ń ta háàpù wọn. Wọ́n sì ń kọrin bí ẹni pé orin tuntun níwájú ìtẹ́ àti níwájú ẹ̀dá alààyè mẹ́rin àti àwọn alàgbà náà; kò sì sí ẹnì kankan tí ó lè dọ̀gá nínú orin yẹn bí kò ṣe ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà, tí a ti rà láti ilẹ̀ ayé wá.” (Ìṣípayá 14:2, 3) Kò ṣeni ní kàyéfì rárá pé nígbà tí Jòhánù gbọ́ ohùn àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jùmọ̀ ń kọ orin atunilára yìí, ó rántí ariwo omi tó máa ń dà wàràwàrà látorí àpáta àti ti ìró ààrá. Orin tó dà bí ẹni pé a ń ta háàpù sí yìí mà dùn o! (Sáàmù 81:2) Ẹgbẹ́ akọrin wo lórí ilẹ̀ ayé ló lè kọrin lọ́nà tó gbámúṣé tó orin tó fa kíki yẹn?

7. (a) Kí ni orin tuntun tí Ìṣípayá 14:3 mẹ́nu kàn? (b) Báwo ni orin inú Sáàmù 149:1 ṣe wá jẹ́ tuntun ní àkókò wa?

7 Kí ni “orin tuntun” yìí? Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ nígbà tá à ń jíròrò Ìṣípayá 5:9, 10, orin náà ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ohun tí Ìjọba Jèhófà pinnu láti ṣe àti ìpèsè àgbàyanu rẹ̀, nípasẹ̀ Jésù Kristi, fún sísọ Ísírẹ́lì ti ẹ̀mí di “ìjọba kan àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa.” Ó jẹ́ orin ìyìn sí Jèhófà, ìyẹn orin tó ń ròyìn àwọn ohun tuntun tó ń ṣe nípasẹ̀ Ísírẹ́lì Ọlọ́run àti nítorí Ísírẹ́lì Ọlọ́run. (Gálátíà 6:16) Àwọn tó jẹ́ ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí yìí ṣe ohun tí olórin náà ní kí wọ́n ṣe pé: “Ẹ yin Jáà! Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà, àti ìyìn rẹ̀ nínú ìjọ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin. Kí Ísírẹ́lì máa yọ̀ nínú Olùṣẹ̀dá rẹ̀ Atóbilọ́lá, àwọn ọmọ Síónì—kí wọ́n kún fún ìdùnnú nínú Ọba wọn.” (Sáàmù 149:1, 2) Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn làwọn ọ̀rọ̀ orin yìí ti wà lákọọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ní àkókò wa yìí, wọ́n ti ń lo òye tuntun tí wọ́n ní nípa wọn láti fi wọ́n kọrin. Lọ́dún 1914, a bí Ìjọba Mèsáyà. (Ìṣípayá 12:10) Lọ́dún 1919, àwọn èèyàn Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìtara kéde “ọ̀rọ̀ ìjọba náà.” (Mátíù 13:19) Bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 1919 (ìyẹn Aísáyà 54:17) ṣe ta wọ́n jí, tí pípadà tí wọ́n padà sínú párádísè tẹ̀mí sì fún wọn níṣìírí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ lọ́dún yẹn láti máa ‘fọkàn wọn kọrin sí Jèhófà.’—Éfésù 5:19.

8. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì nìkan ló lè kọ orin tuntun tí Ìṣípayá 14:3 mẹ́nu kàn?

8 Àmọ́, kí nìdí tó fi jẹ́ pé kìkì àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] nìkan ni ó lè kọ orin tí a mẹ́nu kàn nínú Ìṣípayá 14:3? Èyí jẹ́ nítorí pé ó ní í ṣe pẹ̀lú ìrírí wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn àyànfẹ́ ajogún Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn nìkan ni a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn tí Ọlọ́run sì sọ dọmọ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹ̀mí. Àwọn nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run rà láti ilẹ̀ ayé láti di apá kan Ìjọba ọ̀run yẹn, àwọn nìkan ṣoṣo sì ni “yóò jẹ́ àlùfáà . . . wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba” pẹ̀lú Jésù Kristi fún ẹgbẹ̀rún ọdún láti mú aráyé dé ìjẹ́pípé. Àwọn nìkan ṣoṣo ni a rí tí “ń kọrin bí ẹni pé orin tuntun kan” níwájú Jèhófà. c Àwọn ìrírí àti ìrètí aláìlẹ́gbẹ́ wọ̀nyí jẹ́ kí wọ́n mọrírì Ìjọba náà lọ́nà tó ta yọ, ó sì mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti kọrin nípa rẹ̀ ní ọ̀nà tí ẹnikẹ́ni mìíràn kò lè ṣe.—Ìṣípayá 20:6; Kólósè 1:13; 1 Tẹsalóníkà 2:11, 12.

9. Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ orin tí àwọn ẹni àmì òróró ń kọ, ọ̀rọ̀ ìṣítí wo ni wọ́n sì ti tipa báyìí mú ṣẹ?

9 Àmọ́, àwọn mìíràn ń tẹ́tí sí orin náà, wọ́n sì ń ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ orin náà wí. Láti ọdún 1935, ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn tí iye wọn ń pọ̀ sí i ń gbọ́ orin ìṣẹ́gun yìí, wọ́n sì ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni mímọ́ náà láti polongo Ìjọba Ọlọ́run. (Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 7:9) Lóòótọ́, àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé wọ̀nyí kò lè kọ orin tuntun náà táwọn ọba lọ́la nínú Ìjọba Ọlọ́run ń kọ. Àmọ́ àwọn náà ń kọ orin atunilára láti fi yin Jèhófà nítorí àwọn nǹkan tuntun tó ń ṣe. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ mú ọ̀rọ̀ ìṣítí onísáàmù náà ṣẹ pé: “Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà. Ẹ kọrin sí Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ ayé. Ẹ kọrin sí Jèhófà, ẹ fi ìbùkún fún orúkọ rẹ̀. Ẹ máa sọ ìhìn rere ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́. Ẹ máa polongo ògo rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ láàárín gbogbo ènìyàn. Ẹ gbé e fún Jèhófà, ẹ̀yin ìdílé àwọn ènìyàn, ẹ gbé ògo àti okun fún Jèhófà. Ẹ wí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé: ‘Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba.’”—Sáàmù 96:1-3, 7, 10; 98:1-9.

10. Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fáwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì láti kọrin “níwájú” àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún ìṣàpẹẹrẹ náà?

10 Báwo làwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ṣe lè kọrin “níwájú” àwọn alàgbà náà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún kan náà ni àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì nínú ipò ológo wọn ní ọ̀run? Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa, àwọn tí wọ́n “kú ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi” ni a jí dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. Nípa báyìí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́ tí wọ́n ti ṣẹ́gun wà lọ́run nísinsìnyí. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, wọ́n ń ṣe àwọn iṣẹ́ àkànṣe tó jọ ti ẹgbẹ́ mẹ́rìnlélógún tá a pin àwọn alàgbà tí í ṣe àlùfáà sí. Wọ́n wà nínú ìran ètò Jèhófà ti ọ̀run. (1 Tẹsalóníkà 4:15, 16; 1 Kíróníkà 24:1-18; Ìṣípayá 4:4; 6:11) Báyìí ló ṣe jẹ́ pé àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé ń kọ orin tuntun náà níwájú àwọn arákùnrin wọn tí a ti jí dìde tí wọ́n wà ní ọ̀run.

11. Kí nìdí tá a fi pe àwọn ẹni àmì òróró aṣẹ́gun ní alàgbà mẹ́rìnlélógún àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì?

11 A wá lè béèrè pé: Kí nìdí tá a fi pe àwọn ẹni àmì òróró aṣẹ́gun wọ̀nyí ní alàgbà mẹ́rìnlélógún àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì? Èyí jẹ́ nítorí pé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ nípa àwùjọ kan ṣoṣo yìí lọ́nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà máa ń wà ní ipò wọn nígbà gbogbo yí ká ìtẹ́ Jèhófà, ọba àti àlùfáà sì ni wọ́n lọ́run. Wọ́n dúró fún gbogbo ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì nínú ipò wọn ti ọ̀run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ lára wọn ṣì kù lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 4:4, 10; 5:5-14; 7:11-13; 11:16-18) Àmọ́, Ìṣípayá orí 7 sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a mú jáde látinú ayé, ó sì tẹnu mọ́ ohun ńláǹlà tí Jèhófà fẹ́ ṣe, ìyẹn láti fi èdìdì di iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ẹ̀mí lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti láti gba ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ẹnikẹ́ni ò lè ka iye wọn là. Ìṣípayá orí kẹrìnlá jẹ́ ká rí i kedere pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n máa ṣèjọba pẹ̀lú Jésù yóò pé jọ sọ́dọ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lórí Òkè Síónì. Ó tún sọ àwọn ohun tí ẹnì kan gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ kó tó lè di ara àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, gẹ́gẹ́ bí a óò ti rí i nísinsìnyí. d

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Ọ̀dọ́ Àgùntàn Náà

12. (a) Báwo ni Jòhánù tún ṣe ṣàpèjúwe àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì? (b) Ọ̀nà wo làwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì gbà jẹ́ wúńdíá?

12 Nígbà tí Jòhánù ń bá àpèjúwe rẹ̀ lọ nípa àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí a “rà láti ilẹ̀ ayé,” ó sọ fún wa pé: “Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí kò fi obìnrin sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin; ní ti tòótọ́, wúńdíá ni wọ́n. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tí ó bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a rà lára aráyé gẹ́gẹ́ bí àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, a kò sì rí èké kankan lẹ́nu wọn; wọ́n wà láìní àbààwọ́n.” (Ìṣípayá 14:4, 5) Pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yìí jẹ́ “wúńdíá” ò túmọ̀ sí pé a ò rí lára wọn tó ṣègbéyàwó. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni tí wọ́n ní ìpè ti ọ̀run pé, òótọ́ ni pé àǹfààní ń bẹ nínú wíwà láìṣègbéyàwó, àmọ́ ó sọ pé ìgbéyàwó sàn jù lábẹ́ àwọn ipò kan. (1 Kọ́ríńtì 7:1, 2, 36, 37) Ohun kan tá a fi mọ ẹgbẹ́ yìí ni pé wọ́n jẹ́ wúńdíá nípa tẹ̀mí. Wọ́n yẹra fún bíbá ìṣèlú ayé àti ìsìn èké ṣe panṣágà tẹ̀mí. (Jákọ́bù 4:4; Ìṣípayá 17:5) Nítorí pé àfẹ́sọ́nà Kristi ni wọ́n, wọ́n pa ara wọn mọ́ tónítóní, “láìní àbààwọ́n láàárín ìran oníwà wíwọ́ àti onímàgòmágó.”—Fílípì 2:15.

13. Kí nìdí táwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì fi jẹ́ ìyàwó yíyẹ fún Jésù Kristi, báwo ni wọ́n sì ṣe “ń tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tó bá ń lọ”?

13 Ìyẹn nìkan kọ́ o, “a kò . . . rí èké kankan lẹ́nu wọn.” Nínú èyí, wọ́n dà bí Ọba wọn, Jésù Kristi. Nígbà tí Jésù wà láyé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn pípé, “kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀.” (1 Pétérù 2:21, 22) Níwọ̀n bí wọ́n ti jẹ́ aláìní àbààwọ́n àti olóòótọ́, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ni a múra sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó oníwà mímọ́ fún Àlùfáà Àgbà ńlá ti Jèhófà. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó ní káwọn ọlọ́kàn títọ́ tẹ̀ lé òun. (Máàkù 8:34; 10:21; Jòhánù 1:43) Àwọn tí wọ́n sì tẹ̀ lé e gbé ìgbé ayé bíi tirẹ̀ wọ́n sì tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. Nípa báyìí, nígbà táwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yìí wà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n “ń tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tí ó bá ń lọ” bó ṣe ń tọ́ wọn sọ́nà kí wọ́n lè la ayé Sátánì yìí já.

14. (a) Báwo làwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ṣe jẹ́ “àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà”? (b) Ọ̀nà wo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá gbà jẹ́ àkọ́so pẹ̀lú?

14 Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà ni a “rà láti ilẹ̀ ayé wá,” a “rà [wọ́n] lára aráyé.” Ọlọ́run sọ wọ́n dọmọ, àti pé lẹ́yìn àjíǹde wọn, wọn kì yóò jẹ́ ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ran ara àti ẹlẹ́jẹ̀ lásánlàsàn mọ́. Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ ìkẹrin ṣe sọ, wọ́n di “àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Òótọ́ ni pé ní ọ̀rúndún kìíní, Jésù ni “àkọ́so nínú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú.” (1 Kọ́ríńtì 15:20, 23) Ṣùgbọ́n, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì jẹ́ “àkọ́so kan” láàárín aráyé aláìpé, tí a fi ẹbọ Jésù rà. (Jákọ́bù 1:18) Síbẹ̀, àwọn nìkan kọ́ ni wọ́n máa kórè látinú aráyé. Ìwé Ìṣípayá tọ́ka sí ìkórè ogunlọ́gọ̀ ńlá tí wọ́n kò níye tí wọ́n ń fi ohùn rara sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.” Ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí yóò la ìpọ́njú ńlá já, bí wọ́n sì ti ń bá a lọ láti gba ìtura nípasẹ̀ “àwọn ìsun omi ìyè,” wọ́n yóò di ẹni pípé lórí ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn ìpọ́njú ńlá, Hédíìsì ni a óò sọ di òfìfo, nítorí pé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni yóò jíǹde, wọn yóò sì ní àǹfààní láti mu omi ìyè kan náà. Fún ìdí yìí, yóò tọ̀nà láti sọ pé ogunlọ́gọ̀ ńlá ni àkọ́so àwọn àgùntàn mìíràn. Àwọn ló kọ́kọ́ ‘fọ aṣọ wọn, tí wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà’ tí wọ́n sì ní ìrètí pé àwọn máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 7:9, 10, 14, 17; 20:12, 13.

15. Àwọn ohun wo nínú àwọn àjọyọ̀ tí wọ́n ń ṣe lábẹ́ Òfin Mósè ló ṣe rẹ́gí pẹ̀lú àkọ́so mẹ́tẹ̀ẹ̀ta?

15 Nínú àwọn àjọyọ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì máa ń ṣe níbàámu pẹ̀lú Òfin Mósè, àwọn ohun kan wà tó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú àwọn àkọ́so mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí (ìyẹn Jésù Kristi, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, àti ogunlọ́gọ̀ ńlá). Ní Nísàn 16, lákòókò Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú, wọ́n máa ń fi ìtí àkọ́so ọkà báálì tí wọ́n kórè rúbọ sí Jèhófà. (Léfítíkù 23:6-14) Nísàn 16 ni ọjọ́ tí Jésù jíǹde. Ní àádọ́ta ọjọ́ láti Nísàn 16, ní oṣù kẹta, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe àjọyọ̀ ìkórè àkọ́pọ́n èso ọkà àlìkámà. (Ẹ́kísódù 23:16; Léfítíkù 23:15, 16) Nígbà tó yá, wọ́n wá ń pe àjọyọ̀ yìí ni Pẹ́ńtíkọ́sì (láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “àádọ́ta”). Ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni a sì fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn ẹni àkọ́kọ́ lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì. Níkẹyìn, ní oṣù keje nígbà tí wọ́n bá ti kó gbogbo ìkórè jọ tán, wọ́n á wá ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà. Èyí jẹ́ àkókò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń dúpẹ́ tí wọ́n á sì lo ọ̀sẹ̀ kan nínú àtíbàbà, tí wọ́n fi imọ̀ ọ̀pẹ ṣe. (Léfítíkù 23:33-43) Bákan náà, ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí wọ́n jẹ́ ara àwọn tí wọ́n kórè, ń dúpẹ́ níwájú ìtẹ́ náà pẹ̀lú “imọ̀ ọ̀pẹ . . . ní ọwọ́ wọn.”—Ìṣípayá 7:9.

Pípolongo Ìhìn Rere Àìnípẹ̀kun

16, 17. (a) Ibo ni áńgẹ́lì tí Jòhánù rí ti ń fò, ìpolongo wo sì ni áńgẹ́lì náà ń ṣe? (b) Àwọn wo ló ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà, àwọn ìrírí wo ló sì fi èyí hàn?

16 Lẹ́yìn ìyẹn, Jòhánù kọ̀wé pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn, ó ń sọ ní ohùn rara pé: ‘Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé, nítorí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.’” (Ìṣípayá 14:6, 7) Áńgẹ́lì náà “ń fò ní agbedeméjì ọ̀run,” níbi tí àwọn ẹyẹ ti ń fò. (Fi wé Ìṣípayá 19:17.) Fún ìdí yìí, ohùn rẹ̀ ni a lè gbọ́ káàkiri ilé ayé. Ẹ ò rí i pé igbe ìpòkìkí kárí ayé tí áńgẹ́lì yìí ń ké á rìn jìnnà ju ìhìn ṣókí lórí tẹlifíṣọ̀n èyíkéyìí lọ!

17 A rọ olúkúlùkù èèyàn pé kí wọ́n má ṣe bẹ̀rù ẹranko ẹhànnà náà àti ère rẹ̀, àmọ́ kí wọ́n bẹ̀rù Jèhófà, ẹni tó lágbára ju ẹranko ìṣàpẹẹrẹ èyíkéyìí tí Sátánì ń ṣàkóso lọ fíìfíì. Ó ṣe tán, Jèhófà ló dá ọ̀run òun ayé, ó sì tí tó àkókò lójú rẹ̀ báyìí láti ṣèdájọ́ ayé! (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 1:1; Ìṣípayá 11:18.) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò wa yìí pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń ṣe ohun tí Jésù pa láṣẹ yìí. (1 Kọ́ríńtì 9:16; Éfésù 6:15) Níhìn-ín, Ìṣípayá fi yé wa pé àwọn áńgẹ́lì tí kò ṣeé fojú rí ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù yìí pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti hàn gbangba pé àwọn áńgẹ́lì máa ń darí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sílé àwọn tí ìṣòro ti wọ̀ lọ́rùn, tó jẹ́ pé wọ́n ti ń gbàdúrà pé káwọn rẹ́ni tó máa wá fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ran àwọn lọ́wọ́!

18. Gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run ṣe wí, wákàtí kí ni ó dé, ta ni yóò sì máa ṣe ìpolongo síwájú sí i?

18 Gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run ti polongo, wákàtí ìdájọ́ ti dé. Àmọ́, ìdájọ́ wo ni Ọlọ́run yóò ṣe nísinsìnyí? Nígbà táwọn áńgẹ́lì kejì, ìkẹta, ìkẹrin, àti ìkarùn-ún bá bẹ̀rẹ̀ ìpolongo wọn, ńṣe ni etí àwọn èèyàn máa hó yee.—Jeremáyà 19:3.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Gẹ́gẹ́ bí 1 Kọ́ríńtì 4:8 ti fi hàn, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba nígbà tí wọ́n wà níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìṣípayá 14:3, 6, 12, 13, wọ́n ń kọ orin tuntun náà nípa wíwàásù ìhìn rere bí wọ́n ti ń fara dà á títí dé òpin ìgbésí ayé wọn lórí ilẹ̀ ayé.

b Bí wọ́n ṣe lo àwọn orúkọ Hébérù nínú àwọn ìran mìíràn ti ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn; Jésù ni a fún ní orúkọ Hébérù náà “Ábádónì” (tí ó túmọ̀ sí “Ìparun”), tó sì máa mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún ní ibì kan “tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.”—Ìṣípayá 9:11; 16:16.

c Ìwé Mímọ́ lo gbólóhùn náà “bí ẹni pé orin tuntun kan,” nítorí pé orin náà fúnra rẹ̀ ni a kọ sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ ní ìgbàanì. Ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan tó kúnjú ìwọ̀n láti kọ ọ́. Nísinsìnyí tí Ìjọba náà ti fìdí múlẹ̀, tí àwọn ẹni mímọ́ sì ti ń jíǹde, àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ti ní ìmúṣẹ, nítorí náà ó ti tó àkókò láti fi ìtara kọ orin náà sókè.

d A lè fi ọ̀ràn náà wé ti ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ń fi oúnjẹ fún àwọn ara ilé ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu. (Mátíù 24:45) Iṣẹ́ ẹgbẹ́ ẹ̀rú ní pé kó pèsè oúnjẹ tẹ̀mí, àmọ́ àwọn ará ilé, ìyẹn ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó wà nínu ẹgbẹ́ náà, ń jẹ lára oúnjẹ tẹ̀mí yìí. Ẹgbẹ́ kan náà ni wọ́n, àmọ́ wọ́n fi èdè tó yàtọ̀ síra ṣàpèjúwe wọn, lápapọ̀ àti lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 202, 203]

Ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì

Alàgbà mẹ́rìnlélógún

Àwọn àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi Jésù tí í ṣe Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà bá a ṣe wò wọ́n láti ìhà méjì tó yàtọ̀ síra