Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lájorí Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Bíbélì

Lájorí Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Bíbélì

Orí 2

Lájorí Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Bíbélì

Títúmọ̀ Ìwé Mímọ́ Àwọn àdìtú inú ìwé Ìṣípayá ti rú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì olóòótọ́ inú lójú fún ìgbà pípẹ́. Ní àkókò tó tọ́ lójú Ọlọ́run, yóò sọ ìtumọ̀ àwọn àṣírí wọ̀nyẹn di mímọ̀, ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe sọ wọ́n di mímọ̀, ìgbà wo ni yóò sọ wọ́n di mímọ̀, àwọn wo ni yóò sì sọ wọ́n di mímọ̀ fún? Ẹ̀mí Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè sọ ìtumọ̀ náà di mímọ̀ bí àkókò náà ti ń sún mọ́lé. (Ìṣípayá 1:3) Àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ wọ̀nyẹn la óò ṣí payá fún àwọn ẹrú Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn àwọn tí wọ́n jẹ onítara, kí wọ́n lè lókun láti sọ ìdájọ́ rẹ̀ di mímọ̀. (Mátíù 13:10, 11) A ò sọ pé àwọn àlàyé inú ìwé yìí jẹ́ èyí tí kò lè ní àṣìṣe o. Èrò Jósẹ́fù ayé ọjọ́un la ní, pé: “Ìtúmọ̀ kò ha jẹ́ ti Ọlọ́run?” (Jẹ́nẹ́sísì 40:8) Ṣùgbọ́n, a gbà dájúdájú pé àwọn àlàyé tá a ṣe sínú ìwé yìí bá Bíbélì mu jálẹ̀jálẹ̀, ní ti pé ó jẹ́ ká rí bí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé lákòókò oníwàhálà tá a wà yìí ṣe mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run ṣẹ lọ́nà tó pabanbarì.

1. Kí lohun tó jẹ Jèhófà lọ́kàn jù lọ?

 ÒWE Bíbélì kan sọ pé: “Òpin ọ̀ràn kan ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ sàn ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ.” (Oníwàásù 7:8) Inú ìwé Ìṣípayá la ti kà nípa parí-parì ohun tó jẹ Jèhófà lọ́kàn jù lọ, ìyẹn ni láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ níwájú gbogbo ẹ̀dá. Ọlọ́run kéde léraléra nípasẹ̀ ọ̀kan lára àwọn wòlíì rẹ̀ ìṣáájú pé: “Wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”—Ìsíkíẹ́lì 25:17; 38:23.

2. Ìmọ̀ tí ń máyọ̀ wá wo ni Ìṣípayá àtàwọn ìwé tó ṣáájú nínú Bíbélì jẹ́ ká ní?

2 Bí ìwé Ìṣípayá ṣe ṣàlàyé òpin aláyọ̀ tó máa gbẹ̀yìn àwọn ọ̀ràn, bẹ́ẹ̀ làwọn ìwé tó ṣáájú nínú Bíbélì ṣe sọ ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọ̀ràn náà fún wa. Ṣíṣe tá a ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ yìí mú kó ṣeé ṣe fún wa láti lóye àwọn àríyànjiyàn tó wé mọ́ ọn, ó sì jẹ́ ká ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn. Ẹ ẹ̀ rí i pé ayọ̀ ńlá lèyí mú wá fún wa! Ó tún yẹ kó sún wa ṣe ohun tó yẹ, ká lè nípìn-ín nínú ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu tí ń dúró de aráyé. (Sáàmù 145:16, 20) Níbi tá a dé yìí, ó dà bíi pé ohun tó bá a mu ni pé ká jíròrò ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì lódindi àti ìṣẹ̀lẹ̀ ohun tó bí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti fi àríyànjiyàn pàtàkì tó dojú kọ gbogbo aráyé nísinsìnyí sọ́kàn àti àlàyé kedere tí Ọlọ́run ti ṣe pé òun máa yanjú àríyànjiyàn náà.

3. Àsọtẹ́lẹ̀ wo nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì ló sọ ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì látòkèdélẹ̀, tó fi mọ́ ìwé Ìṣípayá?

3 Ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, ìyẹn Jẹ́nẹ́sísì, sọ nípa “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀” ó sì sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe ṣẹ̀dá, tó fi mọ́ bó ṣe ṣẹ̀dá èèyàn, tó jẹ́ ohun tó dá gbẹ̀yìn lórí ilẹ̀ ayé. Jẹ́nẹ́sísì tún jẹ́ ká mọ àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kọ́kọ́ sọ nínú ọgbà Édẹ́nì ní nǹkan bí ẹgbàáta [6,000] ọdún sẹ́yìn. Ẹnì kan ṣẹ̀ṣẹ̀ lò Ejò kan láti tan Éfà, obìnrin àkọ́kọ́ jẹ ni; Éfà pẹ̀lú yí Ádámù, ọkọ rẹ̀, lérò padà láti bá a lọ́wọ́ nínú rírú òfin Jèhófà nípa jíjẹ nínú “igi ìmọ̀ rere àti búburú.” Nígbà tí Ọlọ́run ń ṣe ìdájọ́ tọkọtaya ẹlẹ́ṣẹ̀ náà, ó sọ fún ejò náà pé: “Èmi yóò . . . fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1; 2:17; 3:1-6, 14, 15) Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ló sọ ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì látòkèdélẹ̀, tó fi mọ́ ìwé Ìṣípayá.

4. (a) Lẹ́yìn tí Ọlọ́run sọ àsọtẹ́lẹ̀ kìíní, kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn òbí wa àkọ́kọ́? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló jẹ yọ nípa àsọtẹ́lẹ̀ náà, èé sì ti ṣe tó fi yẹ ká mọ ìdáhùn wọn?

4 Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí Ọlọ́run sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ló lé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì. Ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè ò tún ṣeé ṣe fún wọn mọ́; ibi tí wọ́n á ṣẹ̀ṣẹ̀ fúnra wọn ṣètò rẹ̀ lẹ́yìn òde ọgbà Édẹ́nì ni wọ́n á máa gbé títí tí wọ́n á fi kú. Abẹ́ ìdájọ́ ikú ni wọ́n á ti bímọ, àwọn ọmọ wọn náà á sì ru ẹ̀rù ẹ̀ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:23-4:1; Róòmù 5:12) Àmọ́ o, kí ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ ní Édẹ́nì túmọ̀ sí? Àwọn wo ni ọ̀ràn kàn? Báwo ló ṣe so pọ̀ mọ́ ìwé Ìṣípayá? Kí ló ní í sọ fún wa lónìí? Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Èyí á mú kí kálukú wa rí ìtùnú kúrò lọ́wọ́ àwọn ohun búburú tó jẹ́ àbájáde ìṣẹ̀lẹ̀ bíbani-nínú-jẹ́ tó mú kí Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà.

Àwọn Ẹni Pàtàkì Inú Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Náà

5. Nígbà tí ejò náà tan Éfà jẹ, kí ló ṣẹlẹ̀ sí ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ àti sí orúkọ rẹ̀, báwo sì ni àríyànjiyàn náà yóò ṣe yanjú?

5 Jèhófà darí àsọtẹ́lẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ní tààràtà sí Ejò tó purọ́ fún Éfà, tó sọ fún un pé kò ní kú tó bá ṣàìgbọràn, pé ńṣe ni yóò wulẹ̀ di òmìnira, abo ọlọ́run. Ejò náà tipa báyìí pe Jèhófà ní òpùrọ́, ó sì dọ́gbọ́n sọ pé àwa èèyàn lè mú nǹkan sunwọ̀n sí i fúnra wa tá a bá kọ ìṣàkóso gíga jù lọ ti Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Ó tipa bẹ́ẹ̀ pe ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ níjà ó sì kó àbààwọ́n bá orúkọ rere rẹ̀. Ìwé Ìṣípayá ló sọ bí Jèhófà, Onídàájọ́ òdodo náà, yóò ṣe lo ìṣàkóso Ìjọba Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, láti dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre kó sì mú ẹ̀gàn gbogbo kúrò lórí orúkọ rẹ̀.—Ìṣípayá 12:10; 14:7.

6. Báwo ni Ìṣípayá ṣe jẹ́ ká mọ ẹni tó tipasẹ̀ ejò bá Éfà sọ̀rọ̀?

6 Ǹjẹ́ ejò gidi ni ọ̀rọ̀ náà “ejò” ń tọ́ka sí? Rárá o! Ìwé Ìṣípayá jẹ́ ká mọ ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú tó tipasẹ̀ ejò yẹn sọ̀rọ̀. Òun ni “dírágónì ńlá náà . . . , ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà,” tí ó “sún Éfà dẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀.”—Ìṣípayá 12:9; 2 Kọ́ríńtì 11:3.

7. Kí ló fi hàn pé obìnrin tí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jẹ́ ti ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí?

7 Jẹ́nẹ́sísì 3:15 tún wá sọ̀rọ̀ nípa “obìnrin náà.” Ṣé Éfà ni? Ó ṣeé ṣe kí Éfà pàápàá rò pé òun ni. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 4:1.) Ṣùgbọ́n kò lè ṣeé ṣe pé kí ọ̀tá pípẹ́ títí wà láàárín Éfà àti Sátánì nítorí pé Éfà ti kú láti nǹkan tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáta [5,000] ọdún sẹ́yìn. Síwájú sí i, níwọ̀n bí Ejò tí Jèhófà sọ̀rọ̀ sí náà ti jẹ́ ẹni ẹ̀mí tí ojú kò lè rí, obìnrin náà ní láti jẹ́ ti ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí, ìyẹn ọ̀run. Ìṣípayá 12:1, 2 túbọ̀ fìdí èyí múlẹ̀ nípa títọ́ka sí i pé apá tó jẹ́ ti òkè ọ̀run lára ètò Jèhófà, èyí tí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí para pọ̀ jẹ́, ni obìnrin ìṣàpẹẹrẹ yìí.—Tún wo Aísáyà 54:1, 5, 13.

Irú-Ọmọ Méjì Tí Ń Ta Ko Ara Wọn

8. Èé ṣe tó fi yẹ ká fẹ́ láti mọ̀ nípa ohun tá a sọ nísinsìnyí nípa àwọn irú-ọmọ méjì?

8 Irú-ọmọ méjì ló wà ni Jẹ́nẹ́sísì 3:15. Ó yẹ ká fẹ́ láti mọ àwọn wọ̀nyí dáadáa, nítorí pé wọ́n tan mọ́ àríyànjiyàn ńlá nípa ẹni tó ní ẹ̀tọ́ sí ipò ọba aláṣẹ lórí ayé. Èyí kan olúkúlùkù wa lọ́mọdé-lágbà. Èwo nínú àwọn irú-ọmọ wọ̀nyí ni ìwọ fara mọ́?

9. Àwọn wo ló dájú pé wọ́n jẹ́ ara irú-ọmọ Ejò náà?

9 Lákọ̀ọ́kọ́, irú-ọmọ Ejò náà ń bẹ. Ta ni irú-ọmọ yìí? Ó dájú pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí mìíràn tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ara irú-ọmọ yìí, àwọn ni a sì fi “sọ̀kò sísàlẹ̀ [sàkáání ilẹ̀ ayé] pẹ̀lú rẹ̀.” (Ìṣípayá 12:9) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Sátánì, tàbí Béélísébúbù, ni “olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù,” ó dájú pé àwọn ẹ̀mí èṣù ló para pọ̀ di ètò rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí.—Máàkù 3:22; Éfésù 6:12.

10. Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ apá kan irú-ọmọ Sátánì?

10 Síwájú sí i, Jésù sọ fáwọn aṣáájú ìsìn Júù ìgbà ayé rẹ̀ pé: “Láti ọ̀dọ̀ Èṣù baba yín ni ẹ ti wá, ẹ sì ń fẹ́ láti ṣe àwọn ìfẹ́-ọkàn baba yín.” (Jòhánù 8:44) Bí àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn ṣe ṣe àtakò sí Jésù Ọmọ Ọlọ́run, ohun tí wọ́n fi hàn ni pé àwọn pẹ̀lú jẹ́ ọmọ Sátánì. Wọ́n jẹ́ apá kan irú-ọmọ Sátánì, wọ́n ń sìn ín gẹ́gẹ́ bíi baba wọn ìṣàpẹẹrẹ. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn jálẹ̀ ìtàn aráyé ló ti fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí irú-ọmọ Sátánì nípa ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀, pàápàá nípa ṣíṣe àtakò àti inúnibíni sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. A lè ṣàpèjúwe àwọn èèyàn wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọ́n para pọ̀ di ètò Sátánì tí a lè fojú rí lórí ilẹ̀ ayé.—Wo Jòhánù 15:20; 16:33; 17:15.

A Dá Irú-Ọmọ Obìnrin Náà Mọ̀

11. La ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún já, kí ni Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ nípa irú-ọmọ obìnrin náà?

11 Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 3:15 tọ́ka sí irú-ọmọ obìnrin náà níkẹyìn. Nígbà tí Sátánì ń mú irú-ọmọ tirẹ̀ pọ̀ sí i, Jèhófà ń múra sílẹ̀ fún “obìnrin” rẹ̀, tàbí ètò rẹ̀ ti òkè ọ̀run èyí tó dà bí aya, láti mú irú-ọmọ kan jáde. Fún nǹkan bí ẹgbàajì [4,000] ọdún, Jèhófà ń tẹ̀ síwájú láti máa jẹ́ kí àwọn èèyàn onígbọràn, tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run, mọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó tan mọ́ wíwáa irú-ọmọ náà. (Aísáyà 46:9, 10) Nípa báyìí, ó ṣeé ṣe fún Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù, àtàwọn mìíràn láti nígbàgbọ́ nínú ìlérí náà pé irú-ọmọ tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí yóò tinú ìlà ìdílé wọn wá. (Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18; 26:4; 28:14) Sátánì àtàwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sábà máa ń ṣe inúnibíni sí irúfẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bẹ́ẹ̀ nítorí ìgbàgbọ́ àìyẹsẹ̀ wọn.—Hébérù 11:1, 2, 32-38.

12. (a) Ìgbà wo ni pàtàkì irú-ọmọ obìnrin náà dé, kí ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà náà? (b) Torí ìdí pàtàkì wo la ṣe fòróró yan Jésù?

12 Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, Jésù, ọkùnrin pípé náà wá sí Odò Jọ́dánì, a sì batisí rẹ̀. Níbẹ̀, Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ bí Jésù, ó wí pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:17) Jèhófà fi hàn níbẹ̀ pé látinú ètò tẹ̀mí ti Ọlọ́run ní ọ̀run la ti rán Jésù wá. Ó sì tún fòróró yàn án gẹ́gẹ́ bí Ọba Lọ́la fún Ìjọba ọ̀run tí yóò mú ìṣàkóso lé ilẹ̀ ayé lórí padà bọ̀ sípò ní orúkọ Jèhófà, tí yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ yanjú àríyànjiyàn tó wé mọ́ àkóso, tàbí ipò ọba aláṣẹ lẹ́ẹ̀kan fáàbàdà. (Ìṣípayá 11:15) Nítorí náà, Jésù ni pàtàkì irú-ọmọ obìnrin náà, ìyẹn Mèsáyà náà tá a ti sọ tẹ́lẹ̀.—Fi wé Gálátíà 3:16; Dáníẹ́lì 9:25.

13, 14. (a) Èé ṣe tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu láti mọ̀ pé irú-ọmọ obìnrin náà yóò ní ju kìkì ẹnì kan ṣoṣo tó yọrí ọlá lọ? (b) Ẹni mélòó ni Ọlọ́run ti yàn láàárín aráyé láti di apá onípò kejì irú-ọmọ náà, irú ètò wo ni wọ́n sì para pọ̀ jẹ́? (d) Àwọn mìíràn wo ló ń sìn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú irú-ọmọ náà?

13 Irú-ọmọ obìnrin náà yóò ha wulẹ̀ jẹ́ ẹnì kan ṣoṣo tó yọrí ọlá bí? Ó dáa, irú-ọmọ Sátánì ńkọ́? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé irú-ọmọ Sátánì ní ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì burúkú àtàwọn èèyàn tí kò bọlá fún Ọlọ́run nínú. Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu, nígbà náà, láti gbọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn pé òun á yan ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] àwọn olùpàwà-títọ́mọ́ láti inú aráyé kí wọ́n lè di àlùfáà alájùmọ̀ṣàkóso pẹ̀lú Jésù Kristi tí í ṣe Mèsáyà, Irú-Ọmọ náà. Àwọn wọ̀nyí ni Ìṣípayá ń tọ́ka sí nígbà tó sọ pé, bí Èṣù ṣe ń bá ètò Ọlọ́run tó dà bí obìnrin ṣọ̀tá, ó “lọ láti bá àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ rẹ̀ ja ogun.”—Ìṣípayá 12:17; 14:1-4.

14 Nínú Bíbélì, a pe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní arákùnrin Jésù. Níwọ̀n bí wọ́n sì ti jẹ́ arákùnrin rẹ̀, Bàbá kan náà àti ìyá kan náà ló bí wọn. (Hébérù 2:11) Jèhófà Ọlọ́run ni Bàbá wọn. Fún ìdí yìí, ìyá wọn ní láti jẹ́ “obìnrin náà,” ìyẹn ètò Ọlọ́run ti òkè ọ̀run èyí tó dà bí aya fún un. Wọ́n di apá onípò kejì irú-ọmọ náà, nígbà tí Kristi Jésù jẹ́ apá onípò kìíní. Ìjọ àwọn Kristẹni tá a fi ẹ̀mí bí lórí ilẹ̀ ayé wọ̀nyí ló para pọ̀ di ètò Ọlọ́run tá a lè fojú rí tó ń sìn lábẹ́ ètò rẹ̀ ti ọ̀run tó dà bí obìnrin, níbi tá a ó ti so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù nígbà àjíǹde wọn. (Róòmù 8:14-17; Gálátíà 3:16, 29) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgùntàn mìíràn láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè kì í ṣe apá kan irú-ọmọ náà, ọ̀kẹ́ àìmọye wọn ni à ń so pọ̀ ṣọ̀kan láti sìn pẹ̀lú ètò Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Ìwọ ha jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àgùntàn mìíràn wọ̀nyí bí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìrètí aláyọ̀ tó o ní ni ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 10:16; 17:1-3.

Bí Ọ̀tá Ṣe Di Púpọ̀

15. (a) Sọ bí àwọn èèyàn àti áńgẹ́lì tí í ṣe irú-ọmọ Sátánì ṣe di púpọ̀. (b) Kí ní ṣẹlẹ̀ sí irú-ọmọ Sátánì lákòókò Ìkún-omi nígbà ayé Nóà?

15 Àwọn tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn lára irú-ọmọ Sátánì bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn kedere ní kùtùkùtù ìtàn aráyé gan-an. Àpẹẹrẹ kan ni Kéènì, ìyẹn èèyàn tá a kọ́kọ́ bí “tí ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà, tí ó sì fikú pa arákùnrin rẹ̀” Ébẹ́lì. (1 Jòhánù 3:12) Lẹ́yìn náà, Énọ́kù sọ̀rọ̀ nípa dídé Jèhófà “pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárùn-ún rẹ̀ mímọ́, láti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sí gbogbo ènìyàn, àti láti dá gbogbo aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi nípa gbogbo ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run wọn, èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run, àti nípa gbogbo ohun amúnigbọ̀nrìrì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti sọ lòdì sí i.” (Júúdà 14, 15) Kò mọ síbẹ̀ o, àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ dara pọ̀ mọ́ Sátánì wọ́n sì di apá kan irú-ọmọ rẹ̀. Àwọn wọ̀nyí “ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì” ní ọ̀run kí wọ́n bàa lè gbé ẹran ara èèyàn wọ̀ kí wọ́n sì gbé àwọn ọmọbìnrin èèyàn níyàwó. Wọ́n bí àwọn àdàmọ̀dì ọmọ òṣìkà abúmọ́ni tí wọ́n lágbára ju èèyàn lọ. Ayé ìgbà yẹn di èyí tó kún fún ìwà ipá àti ìwà búburú, tó fi jẹ́ pé Ọlọ́run fi Ìkún-omi pa á run, Nóà olùṣòtítọ́ àti ìdílé rẹ̀ nìkan ni àwọn èèyàn ẹlẹ́ran ara tó là á já. Àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn náà—tí wọ́n ti di ẹ̀mí èṣù lábẹ́ àkóso Sátánì—ni ó di dandan fún láti fi àwọn aya wọn tó jẹ́ èèyàn àti àwọn àdàmọ̀dì ọmọ wọn tí ègbé rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lé lórí sílẹ̀. Wọ́n bọ́ ara èèyàn sílẹ̀, wọ́n sì padà sí ọ̀run níbi tí wọ́n ti ń dúró de ìmúṣẹ ìdájọ́ Ọlọ́run tí ń bọ̀ kánkán lórí Sátánì àti irú-ọmọ rẹ̀.—Júúdà 6; Jẹ́nẹ́sísì 6:4-12; 7:21-23; 2 Pétérù 2:4, 5.

16. (a) Òṣìkà aninilára wo ló bọ́ sójú ọpọ́n lẹ́yìn Ìkún-omi, báwo ló sì ṣe fi hàn pé òun jẹ́ apá kan irú-ọmọ Sátánì? (b) Báwo ni Ọlọ́run kò ṣe jẹ́ kí ìsapá àwọn tí ń gbèrò láti mọ ilé gogoro Bábílónì kẹ́sẹ járí?

16 Ní gẹ́rẹ́ lẹ́yìn Ìkún-omi ńlá náà, òṣìkà kan tá à ń pè ní Nímírọ́dù fara hàn lórí ilẹ̀ ayé. Bíbélì pè é ní “ọdẹ alágbára ńlá ní ìlòdì sí Jèhófà,” apá kan irú-ọmọ Ejò náà ni lóòótọ́. Bíi ti Sátánì, ó fi ẹ̀mí ìṣọ̀tẹ̀ hàn ó sì kọ́ ìlú ńlá Bábélì, tàbí Bábílónì, ní ìlòdì sí ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn pé kí èèyàn tàn káàkiri láti kún ilẹ̀ ayé. Ohun tí ì bá ti jẹ́ ibi tó pàfiyèsí jù lọ ní Bábílónì ni ilé gogoro ńlá kan “tí téńté rẹ̀ dé ọ̀run.” Ọlọ́run ò jẹ́ kí ìsapá àwọn tí ń gbèrò láti mọ ilé gogoro náà kẹ́sẹ járí. Ó da èdè wọn rú ó sì “tú wọn ká kúrò níbẹ̀ sórí gbogbo ilẹ̀ ayé” ṣùgbọ́n ó yọ̀ǹda kí Bábílónì tìkára rẹ̀ máa wà nìṣó.—Jẹ́nẹ́sísì 9:1; 10:8-12; 11:1-9.

Àwọn Agbára Ìṣèlú Fara Hàn

17. Bí aráyé ṣe ń pọ̀ sí i, ohun tí kò sunwọ̀n wo ló yọjú, àwọn ilẹ̀ ọba títóbi wo ló sì tibẹ̀ dìde?

17 Ní ìlú Bábílónì, àwọn ohun kan gbèrú láwùjọ èèyàn tó lòdì sí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí ni ìṣèlú. Bí aráyé ṣe ń pọ̀ sí i, àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ olùlépa àṣeyọrí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Nímírọ́dù nípa jíjá agbára gbà. Èèyàn wá bẹ̀rẹ̀ sí í jọba lórí èèyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀. (Oníwàásù 8:9) Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé Ábúráhámù, ìlú Sódómù, Gòmórà, àtàwọn ìlú ńlá tó wà nítòsí wọn bọ́ sábẹ́ àkóso àwọn ọba láti Ṣínárì àtàwọn ilẹ̀ mìíràn tó jìnnà réré. (Jẹ́nẹ́sísì 14:1-4) Lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn olóye tó jẹ́ ògbóǹtagí nínú iṣẹ́ ológun àti ètò ṣíṣe dá àwọn ilẹ̀ ọba títóbi sílẹ̀ láti wá ọrọ̀ àti ògo fún ara wọn. Bíbélì tọ́ka sí díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí, àwọn ni Íjíbítì, Ásíríà, Bábílónì, Mídíà òun Páṣíà, Gíríìsì, àti Róòmù.

18. (a) Báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ń ṣe sí àwọn òṣèlú? (b) Báwo ni àwọn òṣèlú nígbà mìíràn ṣe ń ṣiṣẹ́ fún ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn? (d) Báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn alákòóso ṣe fi ara wọn hàn pé àwọn jẹ́ apá kan irú-ọmọ Ejò náà?

18 Jèhófà fàyè gba wíwà àwọn agbára ìṣèlú wọ̀nyẹn, àwọn èèyàn Jèhófà sì ń ṣe ìgbọràn tó láàlà sí wọn nígbà tí wọ́n bá ń gbé ní àwọn ilẹ̀ tó wà lábẹ́ àkóso wọn. (Róòmù 13:1, 2) Nígbà mìíràn, àwọn òṣèlú tiẹ̀ ń ṣiṣẹ́ fún ìtẹ̀síwájú àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe tàbí kí wọ́n dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Ẹ́sírà 1:1-4; 7:12-26; Ìṣe 25:11, 12; Ìṣípayá 12:15, 16) Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn òṣèlú ló ti ta ko ìjọsìn tòótọ́ lọ́nà rírorò, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn jẹ́ apá kan irú-ọmọ Ejò náà.—1 Jòhánù 5:19.

19. Kí ni ìwé Ìṣípayá fi hàn pé àwọn agbára ayé jẹ́?

19 Ní ọ̀pọ̀ jù lọ ìgbà, ìṣàkóso èèyàn ti kùnà pátápátá láti mú ayọ̀ wá fún àwa èèyàn tàbí láti yanjú àwọn ìṣòro wa. Jèhófà ti yọ̀ǹda fún aráyé láti dán onírúurú ìjọba wò, ṣùgbọ́n kò fọwọ́ sí ìwà ìbàjẹ́ tàbí ọ̀nà tí àwọn alákòóso ti gbà ṣàkóso àwọn èèyàn lọ́nà tí kò tọ́. (Òwe 22:22, 23) Ìwé Ìṣípayá fi hàn pé àpapọ̀ àwọn agbára ayé aninilára jẹ́ ẹranko ẹhànnà onígbèéraga tí ìrísí rẹ̀ bani lẹ́rù.—Ìṣípayá 13:1, 2.

Àwọn Ọlọ́jà Bìrìbìrì Onímọtara-Ẹni-Nìkan

20, 21. Àwùjọ kejì wo la gbọ́dọ̀ fi kún “àwọn ọ̀gágun” àti “àwọn ọkùnrin alágbára” gẹ́gẹ́ bí ara irú-ọmọ burúkú Sátánì, kí sì nìdí?

20 Àwọn mìíràn tí wọ́n tún fara hàn, tí wọ́n jọ àwọn alákòóso òṣèlú dáadáa ni àwọn olówò bìrìbìrì tí ń ṣe káràkátà àwọn ohun èlò gbogbo. Àwọn àkọsílẹ̀ tá a hú jáde nínú àwókù Bábílónì ìgbàanì fi hàn pè ó wọ́pọ̀ gan-an nígbà yẹn lọ́hùn-ún pé káwọn oníṣòwò máa lo àǹfààní ipò tí kò bára dé táwọn èèyàn wà láti fi kó wọn nífà. Di bá a sì ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn olówò ayé ò yéé ṣiṣẹ́ fún èrè ìmọtara-ẹni-nìkan, tó fi jẹ́ pé ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ àwọn díẹ̀ ti di ọlọ́rọ̀ tabua nígbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn aráàlú ń ráre nínú ipò òṣì. Ní sànmánì oníṣẹ́ àfẹ̀rọṣe yìí, àwọn oníṣòwò àtàwọn tó ń ṣe ohun títà ti jẹ èrè púpọ̀ nípa pípèsè ìtòjọ pelemọ àwọn ohun ìjà aṣèparun tó burú jáì fún àwọn agbára ìṣèlú, títí kan àwọn ohun ìjà tó lè pa àìmọye èèyàn run lẹ́ẹ̀kan náà, èyí tó ń múni láyà pami báyìí. Irú àwọn lọ́gàálọ́gàá bẹ́ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ oníwọra nídìí iṣẹ́ ajé àtàwọn mìíràn tó jọ wọ́n ni a gbọ́dọ̀ fi kún “àwọn ọ̀gágun” àti “àwọn ọkùnrin alágbára” tí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ burúkú ti Sátánì. Gbogbo wọn pátá jẹ́ apá kan ètò ti orí ilẹ̀ ayé èyí tí Ọlọ́run àti Kristi dá lẹ́jọ́ pé ó yẹ fún ìparun.—Ìṣípayá 19:18.

21 Lẹ́yìn àwọn òṣèlú oníwà ìbàjẹ́ àtàwọn oníṣòwò ńlá tí wọ́n jẹ́ oníwọra, a tún gbọ́dọ̀ fi apá kẹta nínú àwùjọ èèyàn tó tọ́ sí ìdájọ́ aláìbáradé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kún un. Èwo nìyẹn? Ohun tí Ìṣípayá sọ nípa apá kẹta náà tó jẹ́ ètò tó kárí ayé yìí, tá a mọ̀ bí ẹni mowó, lè yà ọ́ lẹ́nu.

Bábílónì Ńlá

22. Irú ìsìn wo ló gbèrú ní Bábílónì ìgbàanì?

22 Kíkọ́ ìlú Bábílónì àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kì í wulẹ̀ẹ́ ṣe iṣẹ́ ìṣèlú lásán. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àìka ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ sí ló mú kí wọ́n dá ìlú yẹn sílẹ̀, ọ̀ràn tó kan ìsìn ni. Kódà, ìlú Bábílónì yẹn ni ìsìn ìbọ̀rìṣà ti bẹ̀rẹ̀. Àwọn ẹ̀kọ́ tí ń tàbùkù Ọlọ́run làwọn àlùfáà ìlú náà fi ń kọ́ni, bíi kí wọ́n sọ pé ọkàn èèyàn máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú àti pé ìgbésí ayé lẹ́yìn ikú jẹ́ ibi ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ àti ibi ìdánilóró tí àwọn ẹ̀mí èṣù ń bójú tó. Wọ́n gbé jíjọ́sìn àwọn ohun tí Ọlọ́run dá lárugẹ, tó fi mọ́ jíjọ́sìn ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn ọlọ́run àti abo ọlọ́run. Wọ́n hùmọ̀ àwọn àròsọ àtọwọ́dọ́wọ́ láti ṣàlàyé ìpilẹ̀ṣẹ̀ ilẹ̀ ayé àti èèyàn orí rẹ̀, wọ́n sì ṣe àwọn ààtò ìsìn àti ìrúbọ tí ń tini lójú, èyí tí wọ́n sọ pé àwọn ń ṣe káwọn lè máa bímọ yanturu, kí irè lè máa ṣe dáadáa lóko, káwọn sì lè máa ṣẹ́gun lójú ogun.

23. (a) Bí àwọn èèyàn ṣe ń kúrò ní Bábílónì, kí ni wọ́n mú dání pẹ̀lú wọn, kí sì ni àbájáde rẹ̀? (b) Orúkọ wo ni Ìṣípayá pe ilẹ̀ ọba ìsìn èké tó kárí ayé? (d) Kí ni ìsìn èké ti ń fi ìgbà gbogbo bá jà?

23 Bí onírúurú àwùjọ àwọn èèyàn tí ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe ń kúrò ní Bábílónì ti wọ́n sì ń tàn ká ilẹ̀ ayé, wọ́n mú ìsìn Bábílónì dání pẹ̀lú wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ààtò ìsìn àti ìgbàgbọ́ tó fara jọ ti Bábílónì ìgbàanì gbilẹ̀ láàárín àwọn èèyàn tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbé Yúróòpù, Áfíríkà, ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn ayé, àti ní àwọn òkun tó wà ní ìhà gúúsù; ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn èrò ìgbàgbọ́ wọ̀nyí ṣì ń bá a lọ títí di òní olónìí. Abájọ tó fi bá a mu bí Ìṣípayá ṣe sọ pé gbogbo àwọn ìsìn èké lápapọ̀ jẹ́ ìlú ńlá kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bábílónì Ńlá. (Ìṣípayá, orí 17 àti 18) Níbikíbi tí wọ́n gbin ìsìn èké sí, ó ti hu àwọn ẹgbẹ́ àlùfáà aninilára, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, àìmọ̀kan, àti ìṣekúṣe. Ó ti jẹ́ irinṣẹ́ pàtàkì ní ọwọ́ Sátánì. Ìgbà gbogbo ni Bábílónì Ńlá ti bá ìjọsìn tòótọ́ ti Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ jà fitafita.

24. (a) Lọ́nà wo ló gbà ṣeé ṣe fún Ejò náà láti pa Irú-Ọmọ obìnrin náà “ní gìgísẹ̀”? (b) Èé ṣe tá a fi ṣàpèjúwe pípa irú-ọmọ obìnrin náà lára gẹ́gẹ́ bí ọgbẹ́ gìgísẹ̀ lásánlàsàn?

24 Gẹ́gẹ́ bí apá tó yẹ fún ìbáwí líle koko jù lọ lára irú-ọmọ Ejò náà, àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí nínú ìsìn àwọn Júù ti ọ̀rúndún kìíní mú ipò iwájú nínú ṣíṣe inúnibíni sí aṣojú onípò kìíní irú-ọmọ obìnrin náà, wọ́n sì ṣìkà pa á níkẹyìn. Nípa báyìí, ó ṣeé ṣe fún Ejò náà láti “pa á [ìyẹn “irú-ọmọ” náà] ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Jòhánù 8:39-44; Ìṣe 3:12, 15) Èé ṣe tá a fi sọ pé èyí jẹ́ ọgbẹ́ gìgísẹ̀ lásán? Ó jẹ́ nítorí pé ìgbà kúkúrú ni ọgbẹ́ yìí fi wà lára rẹ̀ níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. Kò wà títí lọ nítorí pé Jèhófà jí Jésù dìde ní ọjọ́ kẹta, ó sì gbé e ga sí ìyè ti ẹ̀mí.—Ìṣe 2:32, 33; 1 Pétérù 3:18.

25. (a) Báwo ni Jésù tá a ti ṣe lógo ṣe gbégbèésẹ̀ lòdì sí Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀? (b) Ìgbà wo ni ìmúkúrò irú-ọmọ Sátánì ti ilẹ̀ ayé yóò ṣẹlẹ̀? (d) Kí ni yóò túmọ̀ sí nígbà tí Irú-Ọmọ obìnrin Ọlọ́run bá pa Sátánì, Ejò náà, “ní orí”?

25 Jésù Kristi tá a ti ṣe lógo nísinsìnyí ń sìn ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ó ń ṣèdájọ́ àwọn ọ̀tá Jèhófà. Ó tiẹ̀ ti gbégbèésẹ̀ lòdì sí Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀, ó fi wọ́n sọ̀kò sísàlẹ̀ ó sì fi ìgbòkègbodò wọn mọ sórí ilẹ̀ ayé yìí—èyí tó ti fa ègbé tí ń pọ̀ sí i ní àkókò wa yìí. (Ìṣípayá 12:9, 12) Ṣùgbọ́n àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúkúrò irú-ọmọ Sátánì ti orí ilẹ̀ ayé yóò wáyé nígbà tí Ọlọ́run bá mú ìdájọ́ ṣẹ sórí Bábílónì Ńlá àti gbogbo ẹ̀ka mìíràn tó jẹ́ ti ètò Sátánì lórí ilẹ̀ ayé. Níkẹyìn, Irú-Ọmọ obìnrin Ọlọ́run, Jésù Kristi, yóò pa Sátánì, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ alárèékérekè náà, “ní orí,” ìyẹn á sì túmọ̀ sí ìparẹ́ ráúráú rẹ̀ àti yíyọwọ́ rẹ̀ kúrò pátápátá nínú àwọn àlámọ̀rí aráyé.—Róòmù 16:20.

26. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì jù lọ pé ká ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìṣípayá?

26 Báwo ni gbogbo èyí yóò ṣe ṣẹlẹ̀? Ohun tá a ṣíbòjú rẹ̀ fún wa nínú Ìwé Bíbélì tó ń jẹ́ Ìṣípayá nìyẹn. A ṣí i payá fún wa nínú ọ̀wọ́ ìran, tá a mú ṣe ketekete nípasẹ̀ àwọn àmì àtàwọn ìṣàpẹẹrẹ tó fakíki. Ẹ jẹ́ ká fi ìháragàgà ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ alágbára yìí. Ní tòótọ́, aláyọ̀ ni wa tá a bá gbọ́ tá a sì ń pa àwọn ọ̀rọ̀ Ìṣípayá mọ́! Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń gbé orúkọ Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ lárugẹ, a óò sì jogún àwọn ìbùkún rẹ̀ títí láé. Jọ̀wọ́ máa kà á nìṣó kó o sì máa fi ohun tó ò ń kọ́ sílò. Ó lè yọrí sí ìgbàlà rẹ ní àkókò òpin yìí nínú ìtàn aráyé.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àkọsílẹ̀ káràkátà rèé lára àwọn wàláà ayé ọjọ́un tí wọ́n gbẹ́ ọ̀rọ̀ sí

Ìwé náà, Ancient Near Eastern Texts, tí James B. Pritchard ṣe àtúnkọ rẹ̀, ṣe àkọsílẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀ọ́dúnrún [300] òfin tí Hammurabi kó jọ ní àwọn àkókò Bábílónì. Àkọsílẹ̀ wọ̀nyí fi hàn pé ó pọn dandan pé kí wọ́n fi òfin de màkàrúrù tó wọ́pọ̀ nínú ìṣòwò ayé ọjọ́ wọnnì. Àpẹẹrẹ kan rèé nínú àwọn òfin náà: “Bí aláṣẹ onípò gíga kan bá ra fàdákà tàbí wúrà tàbí ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin tàbí màlúù tàbí àgùntàn tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí ohunkóhun mìíràn, tàbí pé ṣe ló gbà á pa mọ́ lọ́wọ́ ọmọ tàbí ẹrú aláṣẹ onípò gíga, tí kò sì ní ẹlẹ́rìí àti ìwé àdéhùn, olè ni aláṣẹ onípò gíga náà, pípa ní a óò pa á.”