Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Máa Bá A Nìṣó Ní Dídi Ohun Tí Ìwọ Ní Mú Ṣinṣin”

“Máa Bá A Nìṣó Ní Dídi Ohun Tí Ìwọ Ní Mú Ṣinṣin”

Orí 12

“Máa Bá A Nìṣó Ní Dídi Ohun Tí Ìwọ Ní Mú Ṣinṣin”

FILADẸ́FÍÀ

1. Ìlú wo ni ìjọ tí Jésù ránṣẹ́ kẹfà sí wà, kí sì ni orúkọ ìlú ńyẹn túmọ̀ sí?

 ÌFẸ́ ARÁ—Gbogbo wa ló yẹ ká ní in! Kò síyè méjì pé ohun tí Jésù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó ń ránṣẹ́ kẹfà, èyí tó rán sí ìjọ Filadẹ́fíà ní tààràtà, torí ìtumọ̀ Filadẹ́fíà ni “Ìfẹ́ Ará.” Lẹ́yìn ọgọ́ta [60] ọdún Jòhánù arúgbó ṣì rántí bí Pétérù ṣe tẹnu mọ́ ọn lẹ́ẹ̀mẹ́ta fún Jésù pé òun, Pétérù, nífẹ̀ẹ́ Olúwa dénú. (Jòhánù 21:15-17) Ǹjẹ́ ìfẹ́ ará wà láàárín àwọn Kristẹni tó wà ní Filadẹ́fíà? Ó hàn pé ìfẹ́ ará wà láàárín wọn!

2. Irú ìlú wo ni Filadẹ́fíà, irú ìjọ wo ló wà ńbẹ̀, kí sì ni Jésù sọ fún áńgẹ́lì ìjọ yìí?

2 Nǹkan bíi ọgbọ̀n [30] kìlómítà ni láti gúúsù Sádísì (níbi tí ìlú Alasehir wà ní Turkey òde òní) dé Filadẹ́fíà. Lọ́jọ́ Jòhánù, aásìkí wà níwọ̀nba nílùú Filadẹ́fíà. Bó ti wù kó rí, aásìkí ìjọ Kristẹni tó wà níbẹ̀ ò ṣeé gbójú fò dá. Ṣe layọ̀ wọn túbọ̀ kún rẹ́rẹ́ nígbà tí wọ́n rí òjíṣẹ́ tó wá bẹ̀ wọ́n wò, tó ṣeé ṣe kó gba ọ̀nà Sádísì wá! Ìmọ̀ràn tí ń tani jí ni iṣẹ́ tó jẹ́ fún wọn. Ṣùgbọ́n ó kọ́kọ́ jẹ́ kí wọ́n mọ bí Ẹni tó fi iṣẹ́ ọ̀hún rán òun ṣe ṣe pàtàkì tó. Ó ní: “Sì kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Filadẹ́fíà pé: Ìwọ̀nyí ni ohun tí òun wí, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́, tí ó jẹ́ òótọ́, tí ó ní kọ́kọ́rọ́ Dáfídì, ẹni tí ń ṣí tí kò sí ẹni tí yóò tì, tí ó sì ń tì, tí kò sí ẹni tí yóò ṣí.”—Ìṣípayá 3:7.

3. Kí nìdí tí Jésù fi gbọ́dọ̀ jẹ́ “mímọ́,” ọ̀nà wo ló sì gbà jẹ́ “òótọ́”?

3 Jòhánù ti gbọ́ tí Pétérù sọ fún ọkùnrin náà Jésù Kristi pé: “Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun; àwa sì ti gbà gbọ́, a sì ti wá mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.” (Jòhánù 6:68, 69) Níwọ̀n bí Jèhófà Ọlọ́run ti jẹ́ mímọ́ tinú-tòde ní gbogbo ọ̀nà, Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo náà ní láti jẹ́ “mímọ́.” (Ìṣípayá 4:8) Jésù tún jẹ́ “òtítọ́.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tá a lò yìí (a·le·thi·nosʹ) túmọ̀ sí ìjójúlówó. Èyí fi hàn pé, Jésù ni ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ àti oúnjẹ tòótọ́ tó sọ̀ kalẹ̀ wá látọ̀run. (Jòhánù 1:9; 6:32) Òun ni àjàrà tòótọ́. (Jòhánù 15:1) Jésù tún jẹ́ Òótọ́ ní ti pé, ẹni tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé ní. Òtítọ́ ló máa ń sọ nígbà gbogbo. (Wo Jòhánù 8:14, 17, 26.) Ní tòdodo, Ọmọ Ọlọ́run yìí ló tọ́ kó jẹ́ Ọba àti Onídàájọ́.—Ìṣípayá 19:11, 16.

“Kọ́kọ́rọ́ Dáfídì”

4, 5. Májẹ̀mú wo ni “kọ́kọ́rọ́ Dáfídì” tan mọ́?

4 Ọwọ́ Jésù ní “kọ́kọ́rọ́ Dáfídì” wà. Ó ń lò ó láti “ṣí tí kò sí ẹni tí yóò tì, tí ó sì ń tì, tí kò sí ẹni tí yóò ṣí.” Kí ni “kọ́kọ́rọ́ Dáfídì” yìí?

5 Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ni Jèhófà bá dá májẹ̀mú ìjọba àìnípẹ̀kun. (Sáàmù 89:1-4, 34-37) Ilé Dáfídì ṣàkóso lórí ìtẹ́ Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù látọdún 1070 sí 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni, nígbà tó sì yá, ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí ìjọba yẹn nítorí tó yí padà sí ìwà burúkú. Nípa báyìí, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí mú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tó wà ní Ìsíkíẹ́lì 21:27 ṣẹ pé: “Rírun, rírun, rírun ni èmi yóò run ún [ìyẹn Jerúsálẹ́mù orí ilẹ̀ ayé]. Ní ti èyí pẹ̀lú, dájúdájú, [ọ̀pá aládé ti ipò ọba ní ìlà Dáfídì] kì yóò jẹ́ ti ẹnì kankan títí di ìgbà tí ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin yóò fi dé, èmi yóò sì fi í fún un.”

6, 7. Nígbà wo lẹni tó ní “ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin” yìí máa dé, báwo ló sì ṣe máa dé?

6 Ìgbà wo lẹni tó ní “ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin” yìí máa dé, báwo ló sì ṣe máa dé? Ọ̀nà wo ni ọ̀pá aládé ìjọba Dáfídì máa gbà tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́?

7 Lẹ́yìn nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] ọdún, àtọmọdọ́mọ Dáfídì Ọba, ìyẹn omidan Júù náà tí ń jẹ́ Màríà lóyún nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Ọlọ́run rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì láti sọ fún Màríà pé ó máa bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ á máa jẹ́ Jésù. Gébúrẹ́lì fi kún un pé: “Ẹni yìí yóò jẹ́ ẹni ńlá, a ó sì máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ; Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.”—Lúùkù 1:31-33.

8. Báwo ni Jésù ṣe fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tó tóótun láti jogún ipò ọba Dáfídì?

8 Lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Jésù ṣe batisí nínú odò Jọ́dánì, Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án, ó sì di Ọba Lọ́la ní ìlà ìdílé Dáfídì. Ó fakọ yọ nínú fífi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó sì pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti wàásù lọ́nà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. (Mátíù 4:23; 10:7, 11) Jésù rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, àní títí dé ojú ikú lórí òpó igi oró, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tó tóótun láti jogún ipò ọba Dáfídì. Jèhófà jí Jésù dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí àìleèkú ó sì gbé e ga sí ọwọ́ ọ̀tún Òun fúnra rẹ̀ ní ọ̀run. Ibẹ̀ ló ti jogún gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ìjọba Dáfídì. Bí àkókò bá tó, Jésù á lo ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti “máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá [rẹ̀].”—Sáàmù 110:1, 2; Fílípì 2:8, 9; Hébérù 10:13, 14.

9. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà ń lo kọ́kọ́rọ́ Dáfídì láti fi ṣí kó sì tì?

9 Kò ní pẹ́ tí Jésù á lo kọ́kọ́rọ́ Dáfídì, láti fi ṣílẹ̀kùn àwọn àǹfààní tó tan mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Lẹ́yìn èyí ni Jèhófà máa dá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé nídè nípasẹ̀ Jésù “kúrò lọ́wọ́ ọlá àṣẹ òkùnkùn,” ní ṣíṣí wọn nípò padà lọ “sínú ìjọba Ọmọ ìfẹ́ rẹ̀.” (Kólósè 1:13, 14) Kọ́kọ́rọ́ náà ni ò ní í jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ aláìṣòótọ́ rí irú àwọn àǹfààní bẹ́ẹ̀ gbà. (2 Tímótì 2:12, 13) Níwọ̀n bí Jèhófà ti wà lẹ́yìn ẹni tó máa jogún ìjọba Dáfídì títí láé yìí, kò sí ẹ̀dá kankan tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ yìí yọrí.—Fi wé Mátíù 28:18-20.

10. Ìṣírí wo ni Jésù fún ìjọ tó wà ní Filadẹ́fíà?

10 Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti pàṣẹ, àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Filadẹ́fíà ní láti jẹ́ èyí tí ń tuni nínú lọ́nà àrà ọ̀tọ̀! Ó gbóríyìn fún wọn, ó ní: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ—wò ó! mo ti gbé ilẹ̀kùn ṣíṣísílẹ̀ kalẹ̀ níwájú rẹ, èyí tí ẹnì kankan kò lè tì—pé agbára díẹ̀ ni ìwọ ní, ìwọ sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, ìwọ kò sì já sí èké sí orúkọ mi.” (Ìṣípayá 3:8) Ìjọ náà kì í ṣàárẹ̀, ilẹ̀kùn kan sì ti wà ní ṣíṣí sílẹ̀ níwájú rẹ̀—kò sí tàbí ṣùgbọ́n, ilẹ̀kùn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ni. (Fi wé 1 Kọ́ríńtì 16:9; 2 Kọ́ríńtì 2:12.) Nítorí náà, Jésù fún ìjọ náà níṣìírí láti lo ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àǹfààní náà láti wàásù lọ́nà rere. Wọ́n ti lo ìfaradà, wọ́n sì ti fi hàn pé àwọ́n ní agbára tó pọ̀ tó, àti pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run, àwọn á máa bá a lọ láti ṣe “àwọn iṣẹ́” síwájú sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (2 Kọ́ríńtì 12:10; Sekaráyà 4:6) Wọ́n ti ṣe ohun tí Jésù pa láṣẹ, wọn ò sì tíì sẹ́ Kristi, yálà nípa ọ̀rọ̀ tàbí nípa ìṣe wọn.

‘Wọn Yóò Tẹrí Ba fún Ọ’

11. Ìbùkún wo ni Jésù ṣèlérí fáwọn Kristẹni, ọ̀nà wo lèyí sì ti gbà ní ìmúṣẹ?

11 Fún ìdí yìí, Jésù ṣèlérí ìbùkún fún wọn: “Wò ó! Ṣe ni èmi yóò fi àwọn wọnnì láti inú sínágọ́gù Sátánì fúnni, àwọn tí ń wí pé Júù ni àwọn, síbẹ̀ tí wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n irọ́ ni wọ́n ń pa—wò ó! ṣe ni èmi yóò mú kí wọ́n wá, kí wọ́n sì wárí níwájú ẹsẹ̀ rẹ, èmi yóò sì mú kí wọ́n mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ.” (Ìṣípayá 3:9) Àfàìmọ̀ kí ìjọ náà má ti níṣòro pẹ̀lú àwọn Júù tó wà ládùúgbò wọn bíi ti ìjọ tó wà ní Símínà. Jésù pe àwọn wọ̀nyẹn ní “sínágọ́gù Sátánì.” Síbẹ̀, àwọn kan lára àwọn Júù wọnnì máa tó mọ̀ pé òótọ́ lohun táwọn Kristẹni tó ń wàásù nípa Jésù ń sọ. Ó ṣeé ṣe kí ‘wíwárí’ wọn jẹ́ lọ́nà tí Pọ́ọ̀lù gbà sọ ọ nínú 1 Kọ́ríńtì 14:24, 25, pé wọ́n á ronú pìwà dà, wọ́n á sì di Kristẹni tó mọrírì lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ ìfẹ́ ńlá tí Jésù ní sí àwọn ọmọlẹ́yìn tó fi lè fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ fún wọn.—Jòhánù 15:12, 13.

12. Kí nìdí táwọn tó ń jọ́sìn nínú sínágọ́gù àwọn Júù tó wà ní Filadẹ́fíà ò fi ní ṣàìta gìrì bí wọ́n bá mọ̀ pé àwọn kan lára àwọn á “tẹrí ba” fún àwùjọ àwọn Kristẹni àdúgbò náà?

12 Àfàìmọ̀ làwọn tó ń lọ sí sínágọ́gù Júù ní Filadẹ́fíà ò fi ní ta gìrì bí wọ́n bá mọ̀ pé àwọn kan lára wọn á ní láti “wárí” fún àwùjọ àwọn Kristẹni àdúgbò náà. Torí pé ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Júù ló wà nínú ìjọ yẹn, wọn á retí pé kó má rí bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Nítorí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ọba [tí kì í ṣe ti àwọn Júù] yóò sì di olùtọ́jú fún ọ [ìyẹn àwọn èèyàn Ísírẹ́lì], àwọn ọmọ aládé wọn obìnrin yóò sì di obìnrin olùṣètọ́jú fún ọ. Pẹ̀lú ìdojúbolẹ̀ ni wọn yóò sì tẹrí ba fún ọ.” (Aísáyà 49:23; 45:14; 60:14) Bákan náà, Sekaráyà lábẹ́ ìmísí kọ̀wé pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wọnnì pé ọkùnrin mẹ́wàá [ìyẹn àwọn tí kì í ṣe Júù] láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́, wọn yóò di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú, pé: ‘Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’” (Sekaráyà 8:23) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn tí kì í ṣe Júù ló máa tẹrí ba fáwọn Júù, kì í ṣe òdì kejì rẹ̀!

13. Àwọn Júù wo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà fún Ísírẹ́lì ìgbàanì máa ṣẹ mọ́ lára?

13 Orílẹ̀-èdè àyànfẹ́ Ọlọ́run làwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn wà fún. Nígbà táwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn fi wáyé, Ísírẹ́lì ló gba iyì yẹn. Ṣùgbọ́n nígbà tí orílẹ̀-èdè Júù kọ Mèsáyà sílẹ̀, Jèhófà náà kọ̀ wọ́n. (Mátíù 15:3-9; 21:42, 43; Lúùkù 12:32; Jòhánù 1:10, 11) Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ó yan Ísírẹ́lì tòótọ́ ti Ọlọ́run, ìyẹn ìjọ Kristẹni, rọ́pò wọn. Àwọn tó wà nínú ìjọ náà jẹ́ Júù nípa tẹ̀mí pẹ̀lú ìdádọ̀dọ́ tòótọ́ ti ọkàn-àyà. (Ìṣe 2:1-4, 41, 42; Róòmù 2:28, 29; Gálátíà 6:16) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ọ̀nà kan ṣoṣo tí Júù èyíkéyìí lè gbà padà rí ojú rere Jèhófà ni nípa gbígbàgbọ́ pé Jésù ní Mèsáyà. (Mátíù 23:37-39) Ó dájú pé èyí máa tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn kọ̀ọ̀kan ní Filadẹ́fíà. a

14. Báwo ni Aísáyà 49:23 àti Sekaráyà 8:23 ṣe nímùúṣẹ tó fa kíki lóde òní?

14 Lóde òní, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ irú bí Aísáyà 49:23 àti Sekaráyà 8:23 ti nímùúṣẹ tó fa kíki. Torí pé iṣẹ́ ìwàásù tí ẹgbẹ́ Jòhánù ń ṣe ti mú kí ògìdìgbó àwọn èèyàn bá ilẹ̀kùn ṣíṣísílẹ̀ náà wọlé sínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run. b Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn wọ̀nyí ló jáde wá látinú ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n fi èké pera wọn ní Ísírẹ́lì tẹ̀mí. (Fi wé Róòmù 9:6.) Àwọn wọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, fọ aṣọ wọn, wọ́n sì sọ ọ́ di funfun nípasẹ̀ lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ ìrúbọ Jésù. (Ìṣípayá 7:9, 10, 14) Wọ́n ń ṣègbọràn sí Kristi tó jẹ́ ọba Ìjọba Ọlọ́run kí wọ́n bàa lè jogún àwọn ìbùkún tó máa mú wá sórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n wá sọ́dọ̀ àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù ‘wọ́n sì tẹrí ba’ fún wọn nípa tẹ̀mí, nítorí ‘wọ́n gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn.’ Wọ́n ń ṣèránṣẹ́ fáwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyẹn, bákan náà, wọ́n wà níṣọ̀kan pẹ̀lú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ará kárí ayé.—Mátíù 25:34-40; 1 Pétérù 5:9.

“Wákàtí Ìdánwò”

15. (a) Kí ni Jésù ṣèlérí fáwọn Kristẹni ní Filadẹ́fíà, kí nìyẹn sì máa fún wọn níṣìírí láti ṣe? (b) “Adé” wo làwọn Kristẹni náà ń retí àtigbà?

15 Jésù ń bá a lọ pé: “Nítorí pé ìwọ pa ọ̀rọ̀ nípa ìfaradà mi mọ́, ṣe ni èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, èyí tí yóò dé bá gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò. Mo ń bọ̀ kíákíá. Máa bá a nìṣó ní dídi ohun tí ìwọ ní mú ṣinṣin, kí ẹnì kankan má bàa gba adé rẹ.” (Ìṣípayá 3:10, 11) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni ọjọ́ Jòhánù ò ní wà láàyè títí di ọjọ́ Olúwa (tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914), wọ́n ní ìgbọ́kànlé pé Jésù ń bọ̀, èyí sì máa fún wọn lókun láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó. (Ìṣípayá 1:10; 2 Tímótì 4:2) “Adé” náà, tàbí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun, ń dúró dè wọ́n ní ọ̀run. (Jákọ́bù 1:12; Ìṣípayá 11:18) Bí wọ́n bá jẹ́ olùṣòtítọ́ títí dé ojú ikú, kò sí ẹnì kankan tó lè fi èrè yẹn dù wọ́n.—Ìṣípayá 2:10.

16, 17. (a) Kí ni “wákàtí ìdánwò, tó máa dé bá gbogbo ilẹ̀ ayé tá à ń gbé”? (b) Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni àmì òróró látìbẹ̀rẹ̀ “wákàtí ìdánwò”?

16 Kí wá ni “wákàtí ìdánwò”? Kò síyè méjì pé, àwọn Kristẹni tó wà ní Éṣíà ní láti tún kojú inúnibíni tó burú jáì látọ̀dọ̀ ọba Róòmù. c Ó dájú pé, èyí tó pọ̀ lára àsọtẹ́lẹ̀ náà nímùúṣẹ ní wákàtí ìsẹ́mọ́ àti ìdájọ́ tó dé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ní ọjọ́ Olúwa, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní kíkún látọdún 1918. Ohun tí ìdánwò náà wà fún ni láti mọ ìhà tí kálukú wà, bóyá fún Ìjọba Ọlọ́run tó ti fìdí múlẹ̀ ni tàbí fún ayé Sátánì. Bá a bá fi wé “wákàtí” kan, sáà kúkúrú gbáà ni, ṣùgbọ́n kò tíì parí síbẹ̀. Títí tó fi máa parí, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé láé pé “wákàtí ìdánwò” là ń gbé.—Lúùkù 21:34-36.

17 Lọ́dún 1918, ẹgbẹ́ Jòhánù tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró—bíi ti ìjọ tó dúró gbọn-in ní Filadẹ́fíà—ní láti dojú kọ àtakò látọ̀dọ̀ “sínágọ́gù Sátánì” tòde òní. Àwọn aṣáájú ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ti wọ́n ń sọ pé Júù nípa tẹ̀mí làwọn, fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ darí àwọn alákòóso láti tẹ àwọn Kristẹni tòótọ́ rì. Kò síyè méjì pé ṣe làwọn Kristẹni yẹn ń gbìyànjú kárakára láti ‘pa ọ̀rọ̀ ìfaradà Jésù mọ́’; nítorí èyí, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ìyẹn “agbára díẹ̀,” wọ́n là á já, wọ́n sì rí ìṣírí gbà láti wọnú ilẹ̀kùn tó ṣí sílẹ̀ níwájú wọn. Lọ́nà wo?

“Ilẹ̀kùn Ṣíṣísílẹ̀”

18. Ìyànsípò wo ni Jésù ṣe lọ́dún 1919, ọ̀nà wo sì làwọn tó yàn sípò gbà dà bí olùṣòtítọ́ ìríjú Hesekáyà?

18 Lọ́dún 1919, Jésù mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ ó sì tẹ́wọ́ gba ẹgbẹ́ kékeré ti àwọn ojúlówó Kristẹni ẹni àmì òróró gẹ́gẹ́ bí ‘ẹrú rẹ̀ olóòótọ́ àti olóye.’ (Mátíù 24:45-47) Àwọn wọ̀nyí wọnú àǹfààní kan tó jọra pẹ̀lú èyí tí olùṣòtítọ́ ìríjú náà Élíákímù gbádùn lákòókò Hesekáyà Ọba. d Jèhófà sọ nípa Élíákímù pé: “Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé Dáfídì lé èjìká rẹ̀, yóò sì ṣí láìsí ẹnikẹ́ni tí yóò tì, yóò sì tì láìsí ẹnikẹ́ni tí yóò ṣí.” Iṣẹ́ ńlá ni Élíákímù bá Hesekáyà, tó jẹ́ kábíyèsí ọmọ Dáfídì. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lónìí, ẹni àmì òróró ẹgbẹ́ Jòhánù ti gba “kọ́kọ́rọ́ ilé Dáfídì” sí èjìká ní ti pé àwọn ìṣúra orí ilẹ̀ ayé tó jẹ́ ti Ìjọba Mèsáyà ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. Jèhófà ti fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lókun nítorí àǹfààní yìí, ní ṣíṣàlékún agbára díẹ̀ tí wọ́n ní kí wọ́n bàa lè lágbára tó tó láti jẹ́rìí káàkiri ayé.—Aísáyà 22:20, 22; 40:29.

19. Báwo ni ẹgbẹ́ Jòhánù ṣe bójú tó àwọn iṣẹ́ tí Jésù fún un lọ́dún 1919, kí ló sì yọrí sí?

19 Látọdún 1919 wá ni àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró, ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù, ti bẹ̀rẹ̀ àkànṣe ètò láti máa polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run káàkiri. (Mátíù 4:17; Róòmù 10:18) Ohun tíyẹn yọrí sí ni pé àwọn kan lára “sínágọ́gù Sátánì” tòde òní, ìyẹn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, wá sọ́dọ̀ àṣẹ́kù ẹni àmì òróró yìí, wọ́n ronú pìwà dà wọ́n sì “tẹrí ba,” ní títẹ̀ lé àṣẹ ẹrú náà. Àwọn náà wá láti sin Jèhófà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn àgbà tó jẹ́ ara ẹgbẹ́ Jòhánù. Èyí ń bá a lọ títí tí iye àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù fi pé. Lẹ́yìn èyí ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” wá “tẹrí ba” fún ẹni àmì òróró ẹrú náà. (Ìṣípayá 7:3, 4, 9) Ẹrú náà àti ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí wá jọ ń sìn gẹ́gẹ́ bí agbo kan ṣoṣo ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

20. Kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí fi gbọ́dọ̀ dúró digbí nínú ìgbàgbọ́ ká sì máa ṣe déédéé nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?

20 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà ní kánjúkánjú torí pé ojúlówó ìfẹ́ bíi tàwọn Kristẹni tó wà ní Filadẹ́fíà ló mu wa wà níṣọ̀kan. Láìpẹ́, ìpọ́njú ńlá máa mú ayé Sátánì burúkú yìí wá sópin. Nígbà tí àkókò náà bá dé, ǹjẹ́ kí kálukú wa ṣì dúró digbí nínú ìgbàgbọ́ ká sì máa ṣe déédéé nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run kí orúkọ wá má bàa di àwátì nínú ìwé ìyè Jèhófà. (Ìṣípayá 7:14) Ẹ jẹ́ ká fi ọwọ́ pàtàkì mú ìṣílétí tí Jésù fún ìjọ tó wà ní Filadẹ́fíà, káwa náà bàa lè di àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wa mú ṣinṣin, ká sì rí èrè ìyè àìnípẹ̀kun gbà.

Ìbùkún Àwọn Aṣẹ́gun

21. Báwo làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lónìí ṣe ‘pa ọ̀rọ̀ nípa ìfaradà Jésù mọ́,’ kí ni wọ́n sì ń dúró dè?

21 Ẹgbẹ́ Jòhánù lónìí ti ‘pa ọ̀rọ̀ nípa ìfaradà Jésù mọ́,’ ìyẹn ni pé, wọ́n ti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, wọ́n sì ti lo ìfaradà. (Hébérù 12:2, 3; 1 Pétérù 2:21) Fún ìdí yìí, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tẹ̀lé e fún ìjọ tó wà ní Filadẹ́fíà ti fún wọn níṣìírí gidigidi: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun—ṣe ni èmi yóò fi í ṣe ọwọ̀n nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run mi, lọ́nàkọnà, kì yóò jáde kúrò nínú rẹ̀ mọ́.”—Ìṣípayá 3:12a.

22. (a) Kí ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run tí Jésù ń ṣojú fún? (b) Báwo làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣẹ́gun ṣe máa di ọwọ̀n nínú tẹ́ńpìlì yìí?

22 Àǹfààní kékeré kọ́ ni láti jẹ́ ọwọ̀n nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà! Ní Jerúsálẹ́mù ìgbàanì, tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ síbẹ̀ ni ojúkò ìjọsìn Jèhófà. Láàárín tẹ́ńpìlì náà ni àlùfáà àgbà ti máa ń fi ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹran rúbọ, ní ọjọ́ kan lọ́dọọdún, níwájú ìmọ́lẹ̀ ìyanu tó túmọ̀ sí pé Jèhófà wà nínú ibi “Mímọ́ Jù Lọ.” (Hébérù 9:1-7) Nígbà tí Jésù ṣe batisí, tẹ́ńpìlì mìíràn wá sójú táyé, ìyẹn ìṣètò ńlá kan látọ̀run fún jíjọ́sìn Jèhófà, èyí tó dà bí tẹ́ńpìlì. Ọ̀run ni ibi mímọ́ jù lọ nínú tẹ́ńpìlì yìí wà, níbi tí Jésù ti dúró lọ́nà yíyẹ “níwájú Ọlọ́run.” (Hébérù 9:24) Jésù ni Àlùfáà Àgbà náà, ẹbọ kan ṣoṣo péré ló sì wà fún bíbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀ pátápátá: ìyẹn ni, ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin pípé náà Jésù tá a ta sílẹ̀. (Hébérù 7:26, 27; 9:25-28; 10:1-5, 12-14) Níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ṣì jẹ́ olùṣòtítọ́, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé ló máa jẹ́ àlùfáà lábẹ́ Jésù nínú àwọn àgbàlá tẹ́ńpìlì yìí tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (1 Pétérù 2:9) Ṣùgbọ́n gbàrà tí wọ́n bá ti ṣẹ́gun, àwọn pẹ̀lú á wọ ibi mímọ́ jù lọ ní ọ̀run, wọ́n á sì di alátìlẹyìn tí kò ṣeé ṣí nípò bí ọwọ̀n tó gbé ìṣètò ìjọsìn inú tẹ́ńpìlì ró. (Hébérù 10:19; Ìṣípayá 20:6) Kò sí ìbẹ̀rù pé wọn máa “jáde kúrò nínú rẹ̀ mọ́.”

23. (a) Ìlérí wo ni Jésù ṣe tẹ̀ lé e fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣẹ́gun? (b) Kí ni àbájáde kíkọ orúkọ Jèhófà àti orúkọ Jerúsálẹ́mù tuntun sára àwọn Kristẹni aṣẹ́gun?

23 Jésù ń bá a lọ, pé: “Èmi yóò sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi àti orúkọ ìlú ńlá Ọlọ́run mi, Jerúsálẹ́mù tuntun tí ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi, àti orúkọ mi tuntun yẹn sára rẹ̀.” (Ìṣípayá 3:12b) Bẹ́ẹ̀ ni, orúkọ Jèhófà á wà lára àwọn aṣẹ́gun wọ̀nyí, ìyẹn orúkọ Ọlọ́run wọn tó tún jẹ́ Ọlọ́run tí Jésù ń ṣojú fún. Èyí fi hàn kedere pé Jèhófà àti Jésù jẹ́ ẹni méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, wọn kì í sì í ṣe apá méjì nínú Ọlọ́run ẹlẹ́ni mẹ́ta, tàbí Mẹ́talọ́kan. (Jòhánù 14:28; 20:17) Gbogbo ìṣẹ̀dá sì máa rí i pé àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí jẹ́ ti Jèhófà. Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ni wọ́n. Bákan náà, orúkọ Jerúsálẹ́mù tuntun tún wà lára wọn, ìlú tó wà lọ́run tó sì ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ látọ̀run ní ti pé ìṣàkóso rẹ̀ nasẹ̀ dórí gbogbo aráyé olùṣòtítọ́. (Ìṣípayá 21:9-14) Nípa báyìí, gbogbo àwọn Kristẹni tó jẹ́ àgùntàn lórí ilẹ̀ ayé á lè mọ̀ pé àwọn ẹni àmì òróró aṣẹ́gun wọ̀nyí ní ẹ̀tọ́ láti nípìn-ín nínú ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn Jerúsálẹ́mù ti ọ̀run.—Sáàmù 87:5, 6; Mátíù 25:33, 34; Fílípì 3:20; Hébérù 12:22.

24. Kí lórúkọ Jésù tuntun túmọ̀ sí, báwo ló sì ṣe kọ ọ́ sára àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ ẹni àmì òróró?

24 Lópin gbogbo rẹ̀, orúkọ Jésù tuntun á wà lára àwọn ẹni àmì òróró aṣẹ́gun náà. Èyí túmọ̀ sí oyè Jésù tuntun àtàwọn àǹfààní tí ò láfiwé tí Jèhófà fún un. (Fílípì 2:9-11; Ìṣípayá 19:12) Kò sí ẹlòmíràn tó mọ orúkọ yẹn, ní ti pé kò sí ẹlòmíràn tó nírìírí wọ̀nyẹn tàbí tí irú àwọn àǹfààní wọ̀nyẹn wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. Bó ti wù kó rí, nígbà tí Jésù bá kọ orúkọ rẹ̀ sára àwọn arákùnrin rẹ̀ olùṣòtítọ́, á mú kí àjọṣe tó dán mọ́rán wà láàárín òun àtiwọn ní ọ̀run lọ́hùn-ún kódà wọ́n á tún nípìn-ín nínú àwọn àǹfààní rẹ̀. (Lúùkù 22:29, 30) Abájọ tí Jésù fi kádìí lẹ́tà tó kọ sí irú àwọn ẹni àmì òróró bẹ́ẹ̀ nípa títún ìṣílétí náà sọ pé: “Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.”—Ìṣípayá 3:13.

25. Báwo ni Kristẹni kọ̀ọ̀kan lónìí ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú ìmọ̀ràn tí Jésù fún ìjọ tó wà ní Filadẹ́fíà sílò?

25 Ìṣírí ńláǹlà ni iṣẹ́ tí Jésù rán sí àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ tó wà ní Filadẹ́fíà ti gbọ́dọ̀ jẹ́ fún wọn! Dájúdájú, ìṣírí yẹn tún wúlò lọ́nà tó ṣe pàtàkì fún ẹgbẹ́ Jòhánù nísinsìnyí, ní ọjọ́ Olúwa. Ṣùgbọ́n àwọn ìlànà rẹ̀ ṣe pàtàkì fún gbogbo Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, yálà ẹni àmì òróró ni wa tàbí àgùntàn mìíràn. (Jòhánù 10:16) Ṣe ni kí kálukú wa máa bá a nìṣó ní síso èso Ìjọba Ọlọ́run bíi ti àwọn Kristẹni wọnnì ní Filadẹ́fíà. Gbogbo wa ní agbára díẹ̀, ó kéré tán. Gbogbo wa la ní ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká lo agbára yìí! Ní ti àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run tó ń pọ̀ sí i, ẹ jẹ́ ká wà lójúfò láti wọnú ilẹ̀kùn èyíkéyìí tó bá ṣí sílẹ̀ fún wa. A tiẹ̀ lè gbàdúrà pé kí Jèhófà ṣí irú ilẹ̀kùn bẹ́ẹ̀. (Kólósè 4:2, 3) Bá a bá ní ìfaradà bíi ti Jésù, tá a sì jẹ́ olóòótọ́ sí orúkọ rẹ̀, a ó fi hàn pé a jẹ́ elétí ọmọ tó ń gbọ́ ohun tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń sọ fáwọn ìjọ.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní àkókò Pọ́ọ̀lù, Sótínésì, òṣìṣẹ́ tó jẹ́ alága sínágọ́gù àwọn Júù ní Kọ́ríńtì, di Kristẹni arákùnrin.—Ìṣe 18:17; 1 Kọ́ríńtì 1:1.

b Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, tí ẹgbẹ́ Jòhánù ń tẹ̀ jáde ò tíì yé tẹnu mọ́ bó ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó pé ká lo àǹfààní yìí láti nípìn-ín débi tí agbára wa bá mọ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà; bí àpẹẹrẹ, wo àwọn àpilẹ̀kọ náà “Kí Gbogbo Ènìyàn Máa Kéde Ògo Jèhófà” àti “Ìró Wọn Jáde Lọ sí Gbogbo Ilẹ̀ Ayé” nínú ìtẹ̀jáde January 1, 2004. Nínú ìtẹ̀jáde June 1, 2004, àpilẹ̀kọ náà “Ìbùkún Ni Fún Àwọn Tó Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run,” tẹnu mọ́ bá a ṣe lè wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún èyí tó túmọ̀ sí wíwọnú “ilẹ̀kùn ṣíṣísílẹ̀” yẹn. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí iye wọn jẹ́ àádọ́ta ọ̀kẹ́, ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún, ọ̀tàlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta dín mẹ́jọ [1,093,552] ni wọ́n ṣe irú iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀ láàárín oṣù kan lọ́dún 2005.

c Ìwé Cyclopedia ti McClintock àti Strong (Ìdìpọ̀ Kẹwàá, ojú ìwé 519) ròyìn pé: “Ìtẹ̀síwájú tó fa kíki tó wáyé láàárín àwọn Kristẹni ló mú káwọn Kèfèrí bẹ̀rẹ̀ sí í sún àwọn aráàlú láti máa dá rúgúdù sílẹ̀, èyí tó mú kó pọn dandan fún olú ọba láti bẹ̀rẹ̀ sí í fura sóhun táwọn Kristẹni ń ṣe. Nípa báyìí, Trajan [láàárín ọdún 98 sí ọdún 117 Sànmánì Kristẹni] ṣe àwọn òfin kan láti lè tẹ ẹ̀kọ́ tuntun náà rì. Òfin yìí ló wá mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra àwọn ọlọ́run. Wàhálà bá ìṣàkóso Pliny kékeré tó jẹ́ gómìnà Bithynia [ìyẹn ìlú tó bá ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù pààlà níhà àríwá Éṣíà] látàrí bí ìsìn Kristẹni ṣe ń yára tàn kálẹ̀ tí àwọn Kèfèrí tó ń gbé ní ẹkùn ìpínlẹ̀ tó ń ṣàkóso lé lórí sì tìtorí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bínú burúkú-burúkú.”

d Orúkọ náà Hesekáyà túmọ̀ sí “Jèhófà Ń Fúnni Lókun.” Wo 2 Àwọn Ọba 16:20, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 63]

Ríran Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Lọ́wọ́ Láti Tẹrí Ba

Nínú àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ẹni àmì òróró tí wọn máa jogún Ìjọba ọ̀run, ó jọ pé àṣẹ́kù kan, ẹgbẹ́ Jòhánù, tí iye wọn dín sí ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án [9,000] ló ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. Lẹ́sẹ̀ kan náà, iye àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà àti ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [6,600,000]. (Ìṣípayá 7:4, 9) Kí ló mú kó ṣeé ṣe láti ní iye tó pọ̀ jaburata yìí? Onírúurú ilé ẹ̀kọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń darí jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńlá kan. A yàtọ̀ pátápátá sáwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ pé ìmọ̀ ọ̀ràn ayé tó ń rẹ Bíbélì sílẹ̀ ni wọ́n fi ń kọ́ni nínú àwọn ilé ẹ̀kọ́ wọn, ṣe ni ilé ẹ̀kọ́ àwa Ẹlẹ́rìí ń gbin ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú àwọn èèyàn. Àwọn ẹ̀kọ́ náà ń jẹ́ ká rí bá a ṣe lè jẹ́ mímọ́, bá a ṣe lè jẹ́ ọmọlúwàbí àtẹni tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn. Látọdún 1943 la ti bẹ̀rẹ̀ sí í darí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run nínú gbogbo ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yíká ayé. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń pésẹ̀ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan náà la sì ń tẹ̀ lé.

Látọdún 1959 làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tún bẹ̀rẹ̀ sí í darí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, èyí tá a fi máa ń kọ́ àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ lẹ́kọ̀ọ́. A sì dá Ilé Ẹ̀kọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà sílẹ̀ lọ́dún 1977, láti lè máa kọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn arákùnrin àti arábìnrin lẹ́kọ̀ọ́, àwọn tó ń fi èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn sin Jèhófà nínú iṣẹ́ ìwàásù bíi táwọn ará Filadẹ́fíà gẹ́lẹ́. Nígbà tó di ọdún 1987, a bẹ̀rẹ̀ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ láti lè máa kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa bójú tó àwọn àkànṣe iṣẹ́ nínú pápá, ìyẹn káàkiri ayé.

Èyí tó ta yọ lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń darí ni Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Látọdún 1943 ló ti jẹ́ pé kíláàsì méjì méjì ló ń kẹ́kọ̀ọ́ yege lọ́dọọdún ní ilé ẹ̀kọ́ yìí, èyí tá a kọ́ sí Ìpínlẹ̀ New York láti máa kọ́ àwọn míṣọ́nárì lẹ́kọ̀ọ́. Lápapọ̀, ó ti fún àwọn òjíṣẹ́ Jèhófà tí iye wọn ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin [7,000] ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nárì. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege ilé ẹ̀kọ́ yìí ti sìn làwọn ilẹ̀ tí iye wọn ju ọgọ́rùn-ún lọ, èyí tó pọ̀ ló sì jẹ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run náà níbẹ̀. Títí di bá a ṣe ń sọ yìí, tó jẹ́ nǹkan bí ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn, àwọn kan nínú àwọn míṣọ́nárì àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ pẹ̀lú àwọn míṣọ́nárì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti máa mú ètò Jèhófà kárí ayé tẹ̀ síwájú. Ìtẹ̀síwájú yìí mà ga o!

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 64]

Lọ́dún 1919, Jésù, Ọba tí ń jọba ṣí ilẹ̀kùn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn Kristẹni sílẹ̀. Iye àwọn Kristẹni olùfọkànsìn tí wọn ò yé pọ̀ sí i ti lo àǹfààní yẹn lọ́nà rere.

Ọdún Àwọn Ilẹ̀ Àwọn Kristẹni Àwọn Oníwàásù

Tí Ìwàásù Tí Wọ́n Lọ́wọ́ Alákòókò Kíkún e

ti Dé Nínú Ìwàásù f

1918 14 3,868 591

1928 32 23,988 1,883

1938 52 47,143 4,112

1948 96 230,532 8,994

1958 175 717,088 23,772

1968 200 1,155,826 63,871

1978 205 2,086,698 115,389

1988 212 3,430,926 455,561

1998 233 5,544,059 698,781

2005 235 6,390,022 843,234

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

e Iye tó wà lókè yìí jẹ́ ìpíndọ́gba oṣooṣù.

f Iye tó wà lókè yìí jẹ́ ìpíndọ́gba oṣooṣù.

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 65]

Tọkàntọkàn làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń ṣiṣẹ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, ìwọ wo iye wákàtí tá a ti lò nínú wíwàásù àti kíkọ́ni àti iye àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀fẹ́ tá a darí nínú ilé àwọn èèyàn.

Ọdún Àwọn Wákàtí Tá Àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

A Lò Nínú Ìwàásù Tá A Darí

(Àròpọ̀ Ọdọọdún) (Ìpíndọ́gba Oṣooṣù)

1918 19,116 Kò Sí Àkọsílẹ̀

1928 2,866,164 Kò Sí Àkọsílẹ̀

1938 10,572,086 Kò Sí Àkọsílẹ̀

1948 49,832,205 130,281

1958 110,390,944 508,320

1968 208,666,762 977,503

1978 307,272,262 1,257,084

1988 785,521,697 3,237,160

1998 1,186,666,708 4,302,852

2005 1,278,235,504 6,061,534

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 59]

Irú kọ́kọ́rọ́ táwọn ará Róòmù ń lò ní ọ̀rúndún kìíní