Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Orúkọ Rẹ Wà Nínú Ìwé Ìyè?

Ǹjẹ́ Orúkọ Rẹ Wà Nínú Ìwé Ìyè?

Orí 11

Ǹjẹ́ Orúkọ Rẹ Wà Nínú Ìwé Ìyè?

SÁDÍSÌ

1. Báwo ni ìjọ tó wà ní Sádísì ṣe ń ṣe sí nínú ìjọsìn wọn, báwo sì ni Jésù ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tó rán sí wọ́n?

 ÌJỌ tó kàn tí Jésù tó ti dẹni ògo ránṣẹ́ sí wà ní ìlú Sádísì tó jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà mọ́kàndínláàádọ́ta [49] sí gúúsù ìlú Ákísà òde òní (ìyẹn Tíátírà ayé ọjọ́un). Ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Kristẹni, ìlú Sádísì ni olú ìlú tó lókìkí lára àwọn ìlú tí ìjọba Lìdíà ìgbàanì ń ṣàkóso lé lórí, ó sì tún jẹ́ ibùjókòó Ọba Croesus ọlọ́lá tàbùàtabua. Nígbà tó fi máa di ìgbà ayé Jòhánù, nǹkan ò fara rọ mọ́ nílùú Sádísì, ògo tó ní nígbà ìṣàkóso Croesus sì ti di ìtàn lásán. Bákan náà, ìjọ Kristẹni tó wà níbẹ̀ ò fọwọ́ tó yẹ mú ìjọsìn wọn. Fún ìgbà àkọ́kọ́, Jésù ò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn kankan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ní: “Sì kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Sádísì pé: Ìwọ̀nyí ni ohun tí òun wí, ẹni tí ó ní ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run àti ìràwọ̀ méje náà, ‘Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, pé ìwọ ní orúkọ pé o wà láàyè, ṣùgbọ́n o ti kú.’”—Ìṣípayá 3:1.

2. (a) Kí ni “ẹ̀mí méje” tí Jésù ní túmọ̀ sí fáwọn Kristẹni tó wà ní Sádísì? (b) Orúkọ wo ni ìjọ Sádísì ní, ṣùgbọ́n kí ló ń ṣẹlẹ̀ gan an nínú ìjọ náà?

2 Kí ló mú kí Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ni “ẹni tí ó ní ẹ̀mí méje”? Nítorí pé àwọn ẹ̀mí wọ̀nyí túmọ̀ sí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà tó ń ṣàn bó ṣe yẹ. Lẹ́yìn èyí, Jòhánù tún ṣàpèjúwe àwọn ẹ̀mí méje náà gẹ́gẹ́ bí “ojú méje,” èyí tó túmọ̀ sí agbára láti rínú róde tí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà fi jíǹkí Jésù. (Ìṣípayá 5:6) Nípa báyìí, ó lágbára láti jẹ́ kí ọ̀ràn èyíkéyìí di mímọ́, kó sì bójú tó ohunkóhun tó bá tìdí rẹ̀ yọ. (Mátíù 10:26; 1 Kọ́ríńtì 4:5) Ìjọ tó wà ní Sádísì lórúkọ pé ó wà láàyè, àti pé aláápọn ni. Ṣùgbọ́n Jésù rí i pé ìjọ náà ti kú nípa tẹ̀mí. Ẹ̀rí wà pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó wà nínú ìjọ náà ló ti padà sínú ìwà àgunlá tó fara jọ ìwà tí wọ́n ń hù kí wọ́n tó di Kristẹni.—Fi wé Éfésù 2:1-3; Hébérù 5:11-14.

3. (a) Kí nìdí tí “áńgẹ́lì ìjọ tó wà ní Sádísì” fi ní láti fún jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ “ìràwọ̀ méje” ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀? (b) Ìmọ̀ràn líle wo ni Jésù fún ìjọ tó wà ní Sádísì?

3 Jésù tún rán “áńgẹ́lì ìjọ ní Sádísì” létí pé Òun lẹni tó ní “ìràwọ̀ méje.” Ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ló fi di àwọn alàgbà ìjọ wọ̀nyẹn mú, ní ti pé òun ló ní àṣẹ láti darí wọn ní bí wọ́n ṣe gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn. Wọ́n ní láti fi ọkàn wọn sí ‘bó ṣe yẹ kí wọ́n mọ ìrísí agbo ní àmọ̀dunjú.’ (Òwe 27:23) Fún ìdí yìí, kò sóhun tó dáa tó pé kí wọ́n fetí sílẹ̀ dáradára sí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tó tẹ̀ lé e: “Máa kíyè sára, kí o sì fún àwọn ohun tí ó ṣẹ́ kù tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kú lókun, nítorí èmi kò rí i pé ìwọ ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ ní kíkún níwájú Ọlọ́run mi. Nítorí náà, máa bá a lọ ní fífi bí o ṣe gbà àti bí o ṣe gbọ́ sọ́kàn, sì máa bá a lọ ní pípa á mọ́, kí o sì ronú pìwà dà. Dájúdájú, láìjẹ́ pé o jí, èmi yóò wá gẹ́gẹ́ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ̀ rárá ní ti wákàtí tí èmi yóò dé bá ọ.”—Ìṣípayá 3:2, 3.

4. Báwo làwọn ọ̀rọ̀ Pétérù yóò ṣe ran ìjọ tó wà ní Sádísì lọ́wọ́ láti ‘fún àwọn ohun yòókù lókun’?

4 Ó pọn dandan pé káwọn alàgbà tó wà ní Sádísì rántí ayọ̀ tí wọ́n kọ́kọ́ ní nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ àti àwọn ìbùkún tí wọ́n rí gbà nígbà náà. Ṣùgbọ́n ní báyìí, wọ́n ti jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Fìtílà ìjọ wọn ń jó bàìbàì torí àwọn iṣẹ́ ìgbàgbọ́ tí wọn ò ṣe mọ́. Láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sáwọn ìjọ tó wà ní Éṣíà (tó ṣeé ṣe kó ní Sádísì nínú) láti túbọ̀ máa ní ìmọrírì fún ìhìn rere ológo táwọn Kristẹni gbà gbọ́ èyí tí “ẹ̀mí mímọ́ tí a rán jáde láti ọ̀run” polongo—gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ̀mí méje inú ìran Jòhánù túmọ̀ sí. Pétérù tún rán àwọn Kristẹni ara Éṣíà wọnnì létí pé wọ́n jẹ́ ‘ẹ̀yà ìran àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí wọ́n lè polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá ẹni náà tí ó pè wọ́n jáde kúrò nínú òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.’ (1 Pétérù 1:12, 25; 2:9) Ṣíṣe àṣàrò lórí irú àwọn òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì yìí á máa ran ìjọ tó wà ní Sádísì lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà kí wọ́n sì “fún àwọn ohun tí ó ṣẹ́ kù . . . lókun.”—Fi wé 2 Pétérù 3:9.

5. (a) Báwo ni ẹ̀mí ìmọrírì táwọn Kristẹni tó wà ní Sádísì ní ṣe rí? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni tó wà ní Sádísì bí wọn ò bá fi ìmọ̀ràn tí Jésù fún wọn sílò?

5 Ní báyìí ná, ìmọrírì àti ìfẹ́ wọn fún òtítọ́ dà bí iná tí ń kú lọ. Kìkì ìwọ̀nba ẹ̀ṣẹ́ná díẹ̀ ló kù tó ń tàn. Jésù fún wọn níṣìírí láti ko iná náà, ìyẹn ni pé kí wọ́n ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti inú èyí tí ìwà àìnáání wọn ti sìn wọ́n lọ, kí wọ́n sì di ìjọ tó ń fi ọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kan sí i. (Fi wé 2 Tímótì 1:6, 7.) Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà tí Jésù bá dé lójijì—“gẹ́gẹ́ bí olè”—láti mú ìdájọ́ ṣẹ, àìròtẹ́lẹ̀ ló máa bá ìjọ tó wà ní Sádísì.—Mátíù 24:43, 44.

Ó Ń Bọ̀ “Gẹ́gẹ́ bí Olè”

6. Báwo ni Jésù ṣe dé “gẹ́gẹ́ bí olè” lọ́dún 1918, kí ló sì bá tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn tí wọ́n ń pera wọn ní ọmọlẹ́yìn rẹ̀?

6 Ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ tí Jésù sọ, pé òun ń bọ̀ “gẹ́gẹ́ bí olè” nasẹ̀ dé àkókò òde òní. Ó túbọ̀ ṣe pàtàkì fáwọn Kristẹni tí wọ́n wà láàyè lọ́jọ́ Olúwa. Ní gẹ́rẹ́ lẹ́yìn ọdún 1914, àsọtẹ́lẹ̀ Málákì yìí ní ìmúṣẹ kan: “‘Olúwa tòótọ́ yóò sì wá sí tẹ́ńpìlì Rẹ̀ lójijì, ẹni tí ẹ ń wá, àti ońṣẹ́ májẹ̀mú náà, ẹni tí ẹ ní inú dídùn sí. Wò ó! Dájúdájú, òun yóò wá,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.” (Málákì 3:1; Ìṣípayá 1:10) Gẹ́gẹ́ bí “ońṣẹ́ májẹ̀mú náà,” Jésù wá láti ṣèbẹ̀wò àti láti ṣèdájọ́ àwọn tí wọ́n ń pera wọn ní ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (1 Pétérù 4:17) Lákòókò yẹn, ìyẹn lọ́dún 1918, ṣe làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kira bọ ìpakúpa tó wáyé nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, èyí tó mú kí wọ́n di òkú pátápátá sí pípa òfin Ọlọ́run mọ́. Kódà àwọn Kristẹni tòótọ́ tó jẹ́ pé ìtara tí wọ́n fi ń wàásù kí ogun tó bẹ̀rẹ̀ ò lẹ́lẹ́gbẹ́ dẹni tó ń tòògbé lẹ́nu ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Díẹ̀ lára àwọn alàgbà tó ń kó ipa tó jọjú bá ara wọn lẹ́wọ̀n, èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ fòpin sí iṣẹ́ ìwàásù náà. Nígbà tí ẹ̀mí Jèhófà ta àwọn Kristẹni wọ̀nyí jí lọ́dún tó tẹ̀ lé e, kì í ṣe gbogbo wọn ló ṣàtúnṣe. Àwọn kan, tó dà bí àwọn òmùgọ̀ wúńdíá inú àkàwé Jésù, ò gbára dì nípa tẹ̀mí láti lo àǹfààní yẹn fún sísin Jèhófà. Síbẹ̀ inú wa dùn torí pé bíi tàwọn wúńdíá olóye, ọ̀pọ̀ ló gba ìkìlọ̀ tí Jésù fún wọn pé: “Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.”—Mátíù 25:1-13.

7. Kí nìdí tó fi pọn dandan pé káwa Kristẹni lónìí wà lójúfò?

7 Kristẹni ní láti wà lójúfò, èyí kò sì dópin ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan tó fa kíki tí Jésù sọ èyí tó dá lórí “àmì ìgbà tí . . . gbogbo nǹkan wọ̀nyí” yóò ṣẹ, ó fúnni ní ìkìlọ̀ kan tó lágbára pé: “Ní ti ọjọ́ yẹn tàbí wákàtí náà, kò sí ẹni tí ó mọ̀ ọ́n . . . Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí àkókò tí a yàn kalẹ̀ jẹ́. Ṣùgbọ́n ohun tí mo sọ fún yín ni mo sọ fún gbogbo ènìyàn, Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” (Máàkù 13:4, 32, 33, 37) Bẹ́ẹ̀ ni o, bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ yìí, dandan ni kí kálukú wa wà lójúfò ká sì rí i dájú pé a ò sùn ní ti ọwọ́ tá a fi mú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run yálà á jẹ ẹni àmì òróró tàbí ogunlọ́gọ̀ ńlá. Nígbà tí ọjọ́ Jèhófà bá dé “gẹ́gẹ́ bí olè ní òru,” ǹjẹ́ ká rí wa pé a wà lójúfò rekete ká bàa lè gba ìdájọ́ tó bára mu.—1 Tẹsalóníkà 5:2, 3; Lúùkù 21:34-36; Ìṣípayá 7:9.

8. Ọ̀nà wo ni ẹgbẹ́ Jòhánù lónìí gbà fún àwọn èèyàn Ọlọ́run níṣìírí láti túbọ̀ máa fi ọwọ́ tó yẹ mú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run?

8 Ẹgbẹ́ Jòhánù lónìí fúnra rẹ̀ wà lójúfò, ó sì mọ̀ pé dandan ni kóun máa ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fi ọwọ́ tó yẹ mú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run. Kó bàa lè ṣeé ṣe, a máa ń ṣètò àwọn àkànṣe àpéjọ jákèjádò ayé láwọn ìgbà mélòó kan lọ́dún. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àròpọ̀ iye àwọn tí wọ́n wá sí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó dín mọ́kàndínlógún [2,981] àpéjọ àgbègbè tá a ṣe jẹ́ òjì-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé méje ọ̀kẹ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá, ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́rìnlélógójì [10,953,744], a sì batisí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́fà, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìnlá ó lé ẹyọ kan [122,701]. Fún ohun tó lé lọ́gọ́rùn-ún ọdún, ẹgbẹ́ Jòhánù lo ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ láti kéde orúkọ Jèhófà àti ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe. Látàrí àwọn inúnibíni burúkú tí wọ́n ṣe sí wa lákòókò ogun àgbáyé méjèèjì, Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) nípasẹ̀ àwọn àpilẹ̀kọ bíi “Ìbùkún ni fún Àwọn Aláìbẹ̀rù” (1919), “Ìpè Láti Ṣe Ohun Tó Yẹ Ní Ṣíṣe” (1925), àti “Bíborí Inúnibíni” (1942) fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà níṣìírí láti túbọ̀ fi ìtara ṣiṣẹ́ náà.

9. (a) Kí ló yẹ kí gbogbo Kristẹni máa béèrè lọ́wọ́ ara wọn? (b) Ìyànjú wo ni Ilé Ìṣọ́ ti fúnni?

9 Bó ṣe rí ní Sádísì, bẹ́ẹ̀ náà ló rí láwọn ìjọ lónìí, ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo àwa Kristẹni rí i pé à ń ṣàyẹ̀wò ara wa. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ maa bi ara wa nígbà gbogbo pé: Ǹjẹ́ à ń ‘ṣe àwọn iṣẹ́ wa ní kíkún’ níwájú Ọlọ́run wa? Bá a ṣe ń sapá láti fi gbogbo ọkàn wa sin Ọlọ́run, ǹjẹ́ àwa fúnra wa máa ń lo ara wa fáwọn ẹlòmíì láìdá wọn lẹ́jọ́? Lórí ọ̀ràn yìí, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti pèsè ọ̀rọ̀ ìyànjú nígbà tó jíròrò àwọn àkòrí bí “Ẹ Máa Wádìí Ohun Tí Ẹ̀yin Fúnra Yín Jẹ́” àti “Bí A Ò Ṣe Ní Wà Láàyè fún Ara Wa Mọ́.” a Pẹ̀lú irú àwọn ìrànlọ́wọ́ yìí látinú Ìwé Mímọ́, ẹ jẹ́ ká máa yẹ ọkàn wa wò bá a ṣe ń gbìyànjú láti máa rìn tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ tá a sì ń gbàdúrà nínú ìwà títọ́ níwájú Jèhófà.—Sáàmù 26:1-3; 139:23, 24.

“Àwọn Orúkọ Díẹ̀”

10. Apá tó ń fúnni ní ìṣírí wo ni Jésù kíyè sí nínú ìjọ tó wà ní Sádísì, báwo lèyí sì ṣe kàn wá?

10 Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tẹ̀ lé e fún ìjọ tó wà ní Sádísì túbọ̀ fúnni ní ìṣírí. Ó ní: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwọ ní àwọn orúkọ díẹ̀ ní Sádísì tí wọn kò sọ ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn di ẹlẹ́gbin, dájúdájú, wọn yóò bá mi rìn nínú èyí tí ó funfun, nítorí wọ́n yẹ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni a ó fi ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun ṣe ní ọ̀ṣọ́ báyìí; dájúdájú, èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ lọ́nàkọnà kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ mímọ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi àti níwájú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.” (Ìṣípayá 3:4, 5) Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ò fún wa níṣìírí àti okun tó lè jẹ́ ká dúró ti ìpinnu wa láti jẹ́ olùṣòtítọ́? Bí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kan bá ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn nǹkan, ó lè di pé kí ìjọ lódindi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìka ìjọsìn Ọlọ́run sí. Síbẹ̀, a lè rí àwọn kọ̀ọ̀kan tá a máa sapá tìgboyàtìgboyà láti rí i pé àwọn ò sọ ìwà Kristẹni àwọn nù kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ máa bá a lọ láti ní orúkọ rere pẹ̀lú Jèhófà.—Òwe 22:1.

11, 12. (a) Kódà lákòókò ìpẹ̀yìndà ńlá yẹn, ẹ̀rí wo ló wà pé àwọn kan dà bí “àwọn orúkọ díẹ̀” tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ ní Sádísì? (b) Ìtura wo ló dé bá àwọn Kristẹni ẹni bí àlìkámà ní ọjọ́ Olúwa?

11 Bẹ́ẹ̀ ni, “ẹ̀wù àwọ̀lékè” wọ̀nyẹn tọ́ka sí òdodo tẹ́nì kan fi ń ṣèwà hù gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. (Fi wé Ìṣípayá 16:15; 19:8.) Ìyẹn ti gbọ́dọ̀ múnú Jésù dùn pé, láìka ìwà àgunlá téyìí tó pọ̀ jù lára wọn ń hù sí, “àwọn orúkọ díẹ̀,” lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní Sádísì, ṣì ń sapá láti tọ́jú ìwà Kristẹni wọn. Bákan náà, nígbà táwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ ri ara wọn bọ inú Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, láàárín ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tí ìpẹ̀yìndà fi gbilẹ̀, kò sí ká má ti rí àwọn mélòó kan táá máa gbìyànjú láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà láìfọ̀tápè. Àwọn wọ̀nyí jẹ́ olódodo bí àlìkámà tó há sáàárín ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èpò ẹ̀ya ìsìn.—Ìṣípayá 17:3-6; Mátíù 13:24-29.

12 Jésù ṣèlérí pé òun á wà pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹni bí àlìkámà wọ̀nyí “ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” Ó mọ ẹni tí wọ́n jẹ́ àti orúkọ rere tí wọ́n ti ṣe fún ara wọn. (Mátíù 28:20; Oníwàásù 7:1) Ayọ̀ àwọn olùṣòtítọ́ “díẹ̀” wọ̀nyẹn tí wọ́n ṣì wà láàyè ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa ò ní ṣeé fẹnu sọ! Nígbà tó yá, wọ́n kúrò lára àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí kì í pa òfin Ọlọ́run mọ́, wọ́n sì dẹni tó wá sínú ìjọ òdodo tó dà bí ìjọ tí ń bẹ ní Símínà gẹ́lẹ́.—Mátíù 13:40-43.

13. Àwọn ìbùkún wo ló ń dúró de àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọn ò “sọ ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn di ẹlẹ́gbin”?

13 Àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ ní Sádísì tí wọn ò sì sọ ìwà Kristẹni wọn nù rí ìrètí àgbàyanu kan gbà. Lẹ́yìn tí Ìjọba Mèsáyà fìdí múlẹ̀ lọ́dún 1914, wọ́n jíǹde sí ìyè ti ẹ̀mí àti pé gẹ́gẹ́ bí àwọn aṣẹ́gun, wọ́n wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun èyí tó ṣàpẹẹrẹ òdodo wọn tí ò lálèébù tí ò sì lábààwọ́n. Níwọ̀n bí wọ́n ti rìn ní ojú ọ̀nà híhá tí ń sinni lọ sí ìyè, wọ́n á gba èrè ayérayé.—Mátíù 7:14; tún wo Ìṣípayá 6:9-11.

Títí Láé Nínú Ìwé Ìyè!

14. Kí ni “ìwé ìyè,” orúkọ àwọn wo ló sì wà nínú rẹ̀?

14 Kí ni “ìwé ìyè,” orúkọ àwọn wo ló sì máa wà nínú rẹ̀? Ìwé, tàbí àkájọ ìwé ìyè túmọ̀ sí àkọsílẹ̀ nípa àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n tóótun láti gba ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. (Málákì 3:16) Ìṣípayá yìí mẹ́nu ba orúkọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Síbẹ̀ ó tún mẹ́nu ba orúkọ àwọn tí wọ́n tóótun láti gba ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn orúkọ kan lè di ‘àwátì’ nínú ìwé yẹn. (Ẹ́kísódù 32:32, 33) Bó ti wù kó rí, àwọn tí wọ́n jẹ́ ti ẹgbẹ́ Jòhánù tí orúkọ wọn bá wà nínú ìwé ìyè títí tí wọ́n fi kú á gba ìyè àìleèkú ní ọ̀run. (Ìṣípayá 2:10) Àwọn wọ̀nyí ló máa jẹ́ orúkọ tí Jésù fọwọ́ sí ní pàtàkì níwájú Baba rẹ̀ àti níwájú àwọn áńgẹ́lì Rẹ̀. Èrè yẹn má ga lọ́lá o!

15. Ọ̀nà wo ni orúkọ àwọn tó jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe máa wà títí láé nínú ìwé ìyè?

15 Àwọn Ogunlọ́gọ̀ ńlá tí orúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè máa la ìpọ́njú ńlá já láàyè. Bí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ jálẹ̀ Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Jésù tí wọ́n sì yege ìdánwò àṣekágbá tí yóò tẹ̀ lé e, wọ́n á jèrè ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Dáníẹ́lì 12:1; Ìṣípayá 7:9, 14; 20:15; 21:4) Ìgbà yẹn lórúkọ wọn máa wá wà nínú ìwé ìyè títí láé. Bí ẹ̀mí mímọ́ ti ṣe wá jẹ́ kí ohun tó wà níbí yé ọ, ǹjẹ́ o ò ní fẹ́ tara ṣàṣà láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Jésù ń sọ lásọtúnsọ pé: “Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ”?—Ìṣípayá 3:6.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ilé Ìṣọ́ July 15, 2005, àti Ilé Ìṣọ́ March 15, 2005.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 57]

Ǹjẹ́ kí orúkọ rẹ wà títí láé nínú ìwé ìyè